Ẹ̀KỌ́ 41
Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù
Lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì, Ọba Sọ́ọ̀lù sọ Dáfídì di ọ̀gá àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Dáfídì máa ń lọ jagun tó sì máa ń ṣẹ́gun. Ìyẹn mú kí àwọn èèyàn gba ti Dáfídì gan-an. Tí Dáfídì bá ti ogun dé, àwọn obìnrin máa ń kọrin fún un, wọ́n á sì máa jó. Wọ́n máa ń kọrin pé: ‘Ẹgbẹ̀rún, ẹgbẹ̀rún ni Sọ́ọ̀lù pa lójú ogun, àmọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá mẹ́wàá ni Dáfídì pa ní tiẹ̀!’ Sọ́ọ̀lù wá bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Dáfídì, ó sì ń wá ọ̀nà láti pa Dáfídì.
Dáfídì mọ bí wọ́n ṣe máa ń fi háàpù kọrin gan-an. Lọ́jọ́ kan tí Dáfídì ń fi háàpù kọrin fún Sọ́ọ̀lù, ńṣe ni Sọ́ọ̀lù ju ọ̀kọ̀ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ fún Dáfídì kó lè pa á. Àmọ́ Dáfídì yẹ̀ ẹ́, ọ̀kọ̀ náà sì gún ògiri. Lẹ́yìn ìyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Sọ́ọ̀lù tún wá bó ṣe máa pa Dáfídì. Nígbà tó yá, Dáfídì sá lọ, ó sì sá pa mọ́ sínú aginjù.
Ni Sọ́ọ̀lù bá kó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] àwọn ọmọ ogun, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Dáfídì kiri. Sọ́ọ̀lù wọ inú ihò kan tó wà nínú àpáta, inú ihò yẹn sì ni Dáfídì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sá pa mọ́ sí. Àwọn ọmọ ogun Dáfídì sọ fún Dáfídì pé: ‘Wò ó, ọwọ́ rẹ ti ba Sọ́ọ̀lù báyìí.’ Dáfídì wá rọra lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó sì gé díẹ̀ lára aṣọ tó wọ̀. Sọ́ọ̀lù ò tiẹ̀ mọ̀ rárá. Àmọ́, inú Dáfídì kò dùn pé òun gé aṣọ Sọ́ọ̀lù torí ó gbà pé òun kò bọ̀wọ̀ fún ọba tí Jèhófà yàn. Torí náà, kò jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pa Sọ́ọ̀lù. Dáfídì wá pe Sọ́ọ̀lù, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun ò bá ti pa á, àmọ́ òun kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé Sọ́ọ̀lù máa yíwà pa dà, tí kò sì ní máa lé Dáfídì kiri mọ́?
Kò ṣe bẹ́ẹ̀ o. Ńṣe ni Sọ́ọ̀lù tún ń wá bó ṣe máa pa Dáfídì. Ní òru ọjọ́ kan, Dáfídì àti Ábíṣáì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n Dáfídì rọra yọ́ lọ síbi tí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà. Ábínérì tó máa ń ṣọ́ ọba pàápàá ti sùn. Ábíṣáì wá sọ pé: ‘Ọwọ́ tẹ Sọ́ọ̀lù! Jẹ́ kí n pa á dànù.’ Àmọ́ Dáfídì sọ fún un pé: ‘Jèhófà máa jẹ Sọ́ọ̀lù níyà. Jẹ́ ká mú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ká sì gbé ìkòkò omi rẹ̀, ká máa lọ.’
Dáfídì wá gun orí òkè kan tó wà nítòsí, ó ń wo Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti ibẹ̀. Ó wá ké sí Ábínérì pé: ‘Ábínérì, kí ló dé tí o kò ṣe iṣẹ́ rẹ bí iṣẹ́, ṣebí ọba ló yẹ kí o máa ṣọ́? Ó dára, ọ̀kọ̀ àti ìkòkò omi ọba dà?’ Sọ́ọ̀lù dá ohùn Dáfídì mọ̀, ó wá sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé o fẹ́ pa mí ni, wàá ti pa mí, àmọ́ o kò ṣe bẹ́ẹ̀. Mo gbà pé ìwọ lo máa di ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn mi.’ Bí Sọ́ọ̀lù ṣe pa dà sí ààfin rẹ̀ nìyẹn. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ẹbí Sọ́ọ̀lù ló kórìíra Dáfídì.
“Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú.”—Róòmù 12:18, 19