Jèhófà Máa Ń Bá Àwa Èèyàn Sọ̀rọ̀
“Jọ̀wọ́, gbọ́, èmi alára yóò sì sọ̀rọ̀.”—JÓÒBÙ 42:4.
1-3. (a) Kí nìdí tí èrò Ọlọ́run àti ọ̀nà tó ń gbà sọ̀rọ̀ fi ga ju ti àwa èèyàn lọ fíìfíì? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
JÈHÓFÀ fẹ́ káwọn míì náà wà láàyè kí wọ́n sì máa láyọ̀, torí náà, ó dá àwọn áńgẹ́lì, nígbà tó sì yá, ó dá àwa èèyàn. (Sm. 36:9; 1 Tím. 1:11) Àpọ́sítélì Jòhánù pe ẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá ní “Ọ̀rọ̀ náà,” ó sì tún pè é ní “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Jòh. 1:1; Ìṣí. 3:14) Jèhófà Ọlọ́run máa ń sọ èrò rẹ̀ àtohun tó fẹ́ ṣe fún àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ yìí. (Jòh. 1:14, 17; Kól. 1:15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ‘ahọ́n àwọn áńgẹ́lì,’ ìyẹn èdè tí wọ́n ń sọ lọ́run tó sì jinlẹ̀ ju èyí táwa èèyàn ń sọ lọ.—1 Kọ́r. 13:1.
2 Kò sóhun tí Jèhófà ò mọ̀ nípa gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó dá sọ́run àti àwa èèyàn tó dá sórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀pọ̀ èèyàn lè máa gbàdúrà sí Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan náà lédè tí kálukú wọn ń sọ. Bó sì ṣe ń tẹ́tí sí àdúrà ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn yìí, bẹ́ẹ̀ láá tún máa bá àwọn áńgẹ́lì sọ̀rọ̀ táá sì máa fún wọn ní ìtọ́ni. Gbogbo èyí fi hàn pé èrò Ọlọ́run, èdè rẹ̀ àti ọ̀nà tó ń gbà sọ̀rọ̀ gbọ́dọ̀ ga ju tèèyàn lọ fíìfíì. (Ka Aísáyà 55:8, 9.) Ó ṣe kedere nígbà náà pé tí Jèhófà bá fẹ́ bá àwa èèyàn sọ̀rọ̀, àfi kó mú kí ohun tó ń sọ rọrùn kó bàa lè yé wa.
3 Ẹ jẹ́ ká wá ṣàgbéyẹ̀wò bí Ọlọ́run tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n gbogbo yìí ṣe ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó rọrùn lóye látìgbà táláyé ti dáyé. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa ń yí ọ̀nà tó ń gbà sọ̀rọ̀ pa dà kó lè bá ipò kálukú mu.
ỌLỌ́RUN BÁ ÀWỌN ÈÈYÀN SỌ̀RỌ̀
4. (a) Èdè wo ni Jèhófà fi bá Mósè, Sámúẹ́lì àti Dáfídì sọ̀rọ̀? (b) Kí ló wà nínú Bíbélì?
4 Nígbà tí Jèhófà bá Ádámù sọ̀rọ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, èdè tó gbọ́ ni Ọlọ́run fi bá a sọ̀rọ̀. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èdè Hébérù àtijọ́ ló lò. Nígbà tó yá, Ọlọ́run bá àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì bíi Mósè, Sámúẹ́lì àti Dáfídì sọ̀rọ̀. Èdè Hébérù tí wọ́n ń sọ ni wọ́n sì fi kọ àwọn ohun tó sọ sílẹ̀ lọ́nà tí wọ́n gbà ń kọ̀wé. Yàtọ̀ sí pé wọ́n ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá wọn sọ ní tààràtà, wọ́n kọ nípa àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣàkọsílẹ̀ bí wọ́n ṣe lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti bí wọ́n ṣe fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Wọ́n tiẹ̀ tún sọ àwọn àṣìṣe tí wọ́n ṣe àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n kọ Ọlọ́run sílẹ̀. Gbogbo ohun tí wọ́n kọ yìí wúlò gan-an fún wa lónìí.—Róòmù 15:4.
5. Ṣé Jèhófà fi dandan lé e pé èdè Hébérù nìkan ni káwọn èèyàn rẹ̀ máa lò? Ṣàlàyé.
5 Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Jèhófà lo èdè míì láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn táwọn èèyàn Ọlọ́run kúrò nígbèkùn ní Bábílónì, èdè Árámáíkì làwọn kan lára wọn ń sọ lójoojúmọ́. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi mí sí àwọn wòlíì bíi Dáníẹ́lì àti Jeremáyà àti Ẹ́sírà àlùfáà láti fi èdè Árámáíkì kọ àwọn kan lára àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ.a
6. Kí ló mú kí wọ́n túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sáwọn èdè míì yàtọ̀ sí èdè Hébérù?
6 Nígbà tó yá, Alẹkisáńdà Ńlá ṣẹ́gun èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìlú tó wà láyé ìgbà yẹn, nítorí èyí èdè Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní Koine tó wọ́pọ̀ jù lọ nígbà yẹn wá di èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ kárí ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè yẹn, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n tú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì. Ìtumọ̀ Bíbélì yìí làwọn èèyàn wá mọ̀ sí Bíbélì Septuagint, ọ̀pọ̀ sì gbà pé èèyàn méjìléláàádọ́rin [72] ló túmọ̀ rẹ̀. Ohun ni ìtumọ̀ Bíbélì àkọ́kọ́, ó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tó ṣe pàtàkì jù.b Bó ṣe jẹ́ pé kì í ṣe ẹnì kan ló tú Bíbélì yìí mú kí ọ̀nà tí wọ́n gbà tú àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yàtọ̀ síra, àwọn kan tú u lólówuuru, àwọn kan ò sì ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì àtàwọn Kristẹni tó wá lo Bíbélì Septuagint lẹ́yìn náà gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni.
7. Èdè wo ni Jésù fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
7 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èdè Hébérù ni Jésù ń sọ tó sì fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 19:20; 20:16; Ìṣe 26:14) Torí pé èdè Hébérù àti èdè Árámáíkì làwọn èèyàn ń sọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ó tún ṣeé ṣe kí Jésù máa ki àwọn ọ̀rọ̀ tó wá látinú èdè Árámáíkì bọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tó bá ń sọ̀rọ̀. Àmọ́, ó tún mọ èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Mósè àti àwọn wòlíì sọ tí wọ́n sì fi kọ àwọn ìwé wọn táwọn Júù máa ń kà nínú sínágọ́gù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Lúùkù 4:17-19; 24:44, 45; Ìṣe 15:21) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń sọ èdè Gíríìkì àti èdè Látìn ní Ísírẹ́lì. Àmọ́ Ìwé Mímọ́ ò sọ bóyá Jésù sọ àwọn èdè yìí tàbí kò sọ ọ́.
8, 9. Bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe ń gbilẹ̀ sí i, kí nìdí tó fi jẹ́ pé èdè Gíríìkì ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ń lò jù nígbà yẹn, kí lèyí sì jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
8 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́ èdè Hébérù dáadáa, àmọ́ lẹ́yìn ikú Jésù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn èdè míì. (Ka Ìṣe 6:1.) Bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe ń gbilẹ̀ sí i, èdè Gíríìkì ni àwọn Kristẹni ń sọ jù lọ láàárín ara wọn. Kódà, èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere, ìyẹn ìwé Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lọ́wọ́. Torí náà, èdè Gíríìkì ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń sọ nígbà yẹn dípò èdè Hébérù.c Èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ àwọn lẹ́tà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn Ìwé Mímọ́ míì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lọ́wọ́ nígbà yẹn.
9 Inú Bíbélì Septuagint ni àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì ti sábà máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ tí wọ́n bá fẹ́ tọ́ka sí àwọn ẹsẹ kan nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Ìyẹn sì jẹ́ ká rí bí Bíbélì Septuagint ti ṣe pàtàkì tó. Àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn òǹkọ̀wé yìí fà yọ látinú Bíbélì Septuagint wá di ara Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí, bó tílẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ náà lè yàtọ̀ díẹ̀ sí bí wọ́n ṣe kọ ọ́ lédè Hébérù. Ìtumọ̀ tí àwọn atúmọ̀ èdè aláìpé yìí ṣe wá di ara àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí, níwọ̀n bó ti jẹ́ Ọlọ́run tí kì í gbé èdè tàbí ẹ̀yà kan ga ju òmíràn lọ.—Ka Ìṣe 10:34.
10. Kí la rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà lónírúurú èdè?
10 Lẹ́yìn tá a ti ṣàgbéyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ó ti wá ṣe kedere pé ó máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó bá ipò kálukú mu. Kò fi dandan mú wa pé ká kọ́ èdè kan pàtó ká tó lè mọ òun àtàwọn ohun tóun fẹ́ ṣe fáráyé. (Ka Sekaráyà 8:23; Ìṣípayá 7:9, 10.) Jèhófà ló mí sí àwọn tó kọ Bíbélì, àmọ́ ó jẹ́ kí wọ́n kọ ọ́ lónírúurú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ̀wé.
ỌLỌ́RUN Ò JẸ́ KÍ WỌ́N PA Ọ̀RỌ̀ RẸ̀ RUN
11. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú èdè làwọn èèyàn ń sọ, kí nìdí tíyẹn ò fi ní kí Ọlọ́run máà bá wọn sọ̀rọ̀?
11 Ṣé àwọn ìyàtọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó wà nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì àti bí àwọn èèyàn ṣe ń sọ onírúurú èdè mú kó ṣòro fún Ọlọ́run láti bá wọn sọ̀rọ̀? Rárá o. Bí àpẹẹrẹ, o lè ti kíyè sí i pé díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n kọ sílẹ̀ bó ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́. (Mát. 27:46; Máàkù 5:41; 7:34; 14:36) Àmọ́, Jèhófà rí i dájú pé wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sílẹ̀ lédè Gíríìkì, wọ́n sì tún tú u sí àwọn èdè míì nígbà tó yá. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn Júù àtàwọn Kristẹni nígbà yẹn ṣe àdàkọ àwọn ìwé àfọwọ́kọ náà, kí wọ́n má bàa pa run. Wọ́n wá tú àwọn ìwé tí wọ́n ṣe àdàkọ rẹ̀ yìí sí ọ̀pọ̀ èdè. Ọ̀gbẹ́ni John Chrysostom tó gbé láyé láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin sí ìkarùn-ún Sànmánì Kristẹni sọ pé nígbà ayé òun, wọ́n ti tú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù sí àwọn èdè àwọn ará Síríà, Íjíbítì, Íńdíà, Páṣíà, Etiópíà àtàwọn èdè tí wọ́n ń sọ láwọn orílẹ̀-èdè míì.
12. Báwo làwọn kan ṣe gbìyànjú láti pa Bíbélì run?
12 Bí Jèhófà ṣe mú kí Bíbélì wà ní onírúurú èdè sọ ìmọ̀ àwọn ọkùnrin tó fẹ́ láti tẹ Ìwé Mímọ́ rì dòfo. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 303 Sànmánì Kristẹni, Olú Ọba Róòmù Diocletian pàṣẹ pé kí wọ́n dáná sun gbogbo ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ tó wà pátá. Àìmọye ìgbà ni wọ́n gbìyànjú láti pa Bíbélì run, wọ́n sì fojú àwọn tó ń tú u àtàwọn tó ń tẹ̀ ẹ́ rí màbo. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, Ọ̀gbẹ́ni William Tyndale bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì láti èdè Hébérù àti èdè Gíríìkì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ó sọ fún ọkùnrin kan tó kàwé dáadáa pé: “Bí Ọlọ́run bá dá ẹ̀mí mi sí, ní ọdún díẹ̀ sí i, n óò mú kí ọmọdékùnrin tí ń túlẹ̀ mọ Ìwé Mímọ́ jù ọ́ lọ.” Nígbà tó yá, Tyndale ní láti sá kúrò ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù kó lè parí ìtumọ̀ rẹ̀ níbẹ̀ kó sì tẹ̀ ẹ́ jáde. Pàbó ni gbogbo kùkùfẹ̀fẹ̀ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì láti dáná sun gbogbo àwọn Bíbélì tí wọ́n bá rí já sí, torí pé Bíbélì náà dọ́wọ́ àwọn èèyàn nílé lóko. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ẹnì kan da Tyndale, wọ́n mú un, wọ́n yí i lọ́rùn pa, wọ́n sì dáná sun òkú rẹ̀ lórí igi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tyndale ti kú, ìtumọ̀ Bíbélì rẹ̀ ṣì wà títí dòní. Ọ̀pọ̀ ohun tó wà nínú rẹ̀ ni wọ́n sì lò nígbà tí wọ́n fẹ́ túmọ̀ Bíbélì King James tọ́pọ̀ èèyàn ń lò lónìí.—Ka 2 Tímótì 2:9.
13. Kí ni ìwádìí táwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ṣe nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ́ àtijọ́ jẹ́ ká mọ̀?
13 Òótọ́ ni pé àwọn àṣìṣe díẹ̀díẹ̀ wà nínú àwọn ẹ̀dà Bíbélì tó ti pẹ́ gan-an, ọ̀rọ̀ inú wọn ò sì jọra láwọn ibì kan. Àmọ́, àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀pọ̀ àwọn àjákù Bíbélì tí wọ́n rí àtàwọn tí wọ́n fọwọ́ kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ títí kan àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tó ti pẹ́ gan-an, wọ́n fara balẹ̀ yẹ̀ wọ́n wò síra, wọ́n sì ti rí i pé Ìwé Mímọ́ lódindi ṣeé gbára lé torí pé àṣìṣe táwọn adàwékọ ṣe ò tó nǹkan. Àwọn ẹsẹ díẹ̀ tí ohun tó sọ ò fi bẹ́ẹ̀ yé wọn pàápàá ò yí àwọn ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa dà. Ìwádìí fínnífínní táwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ṣe nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ́ àtijọ́ ti jẹ́ kó dá àwọn tó ń ka Bíbélì lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì.—Aísá. 40:8.d
14. Báwo ni Bíbélì ṣe pọ̀ tó lónìí?
14 Láìka bí àwọn ọ̀tá ṣe jà fitafita tó láti pa Bíbélì run, òun ni ìwé tí wọ́n tíì túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ nínú ìtàn. Kódà nígbà táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tàbí tí wọn ò gbà pé Ọlọ́run wà, Bíbélì ni ìwé tó tà jù lọ, odindi tàbí apá kan rẹ̀ sì ti wá wà ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [2,800] báyìí. Kò sí ìwé míì tó délé dóko táwọn èèyàn sì tún lè rí rà bíi ti Bíbélì. Àwọn ọ̀rọ̀ inú ìtumọ̀ Bíbélì kan lè má fi bẹ́ẹ̀ yéni tàbí kí wọ́n má tọ̀nà, síbẹ̀, èèyàn á rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó ń fúnni nírètí tó sì lè jẹ́ kéèyàn rí ìgbàlà kọ́ nínú wọn.
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ ṢÀTÚNṢE BÍBÉLÌ TÁ À Ń LÒ TẸ́LẸ̀
15. (a) Kí ni ètò Ọlọ́run ti ṣe kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn lónìí? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì la fi ń kọ àwọn ìwé wa ká tó túmọ̀ wọn sáwọn èdè míì?
15 Nígbà tí Jésù yan àwùjọ àwọn èèyàn kéréje kan láti jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lọ́dún 1919, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n sábà máa ń lò láti kọ́ “àwọn ará ilé” ìgbàgbọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Mát. 24:45) “Ẹrú” náà ti ṣe gudugudu méje kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè wà ní èdè tó pọ̀ sí i, èdè tí wọ́n sì fi ń tẹ àwọn ìwé wa báyìí ti lé ní ọgọ́rùn-ún méje [700]. Bó ṣe rí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní táwọn èèyàn ń sọ èdè Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní Koine, èdè Gẹ̀ẹ́sì náà ti di èdè táwọn èèyàn ń sọ nílé lóko, wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ níléèwé, àwọn oníṣòwò náà sì ń lò ó láàárín ara wọn. Torí náà, èdè Gẹ̀ẹ́sì la fi ń kọ àwọn ìwé wa ká tó wá máa túmọ̀ wọn sáwọn èdè míì.
16, 17. (a) Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run nílò nígbà kan? (b) Báwo ni irú ìtumọ̀ Bíbélì bẹ́ẹ̀ ṣe tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́? (d) Kí ni Arákùnrin Knorr sọ nípa Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lọ́dún 1950?
16 Bíbélì gan-an ni ètò Ọlọ́run fi ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Torí náà, Bíbélì King James Version ti ọdún 1611 la kọ́kọ́ ń lò. Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú Bíbélì náà ti di èdè àtijọ́ kò sì yé àwọn èèyàn mọ́. Yàtọ̀ síyẹn ibi mélòó kan péré ni orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn nínú Bíbélì yìí nígbà tó sì jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà ló fara hàn nínú àwọn ẹ̀dà Bíbélì àtijọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ. Láfikún síyẹn, ó ní àwọn àṣìṣe nínú, àwọn ẹsẹ kan sì wà níbẹ̀ tí kò sí nínú àwọn ẹ̀dà Bíbélì àtijọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ, èyí táwọn èèyàn gbà pó jẹ́ ojúlówó. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì tó wà náà sì tún ní kùdìẹ̀-kudiẹ tiwọn.
17 Èyí ló fà á táwọn èèyàn Ọlọ́run fi nílò Bíbélì tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ á bá àwọn ohun tó wà nínú èyí tí wọ́n fọwọ́ kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu gẹ́lẹ́ tó sì jẹ́ pé èdè tó bóde mu tó sì rọrùn lóye ni wọ́n á fi kọ ọ́. Torí náà, ètò Ọlọ́run dá ìgbìmọ̀ kan sílẹ̀, ìyẹn Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun. Láàárín ọdún 1950 sí 1960, ìgbìmọ̀ yìí tẹ Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì jáde ní ìdìpọ̀ mẹ́fà. Nígbà tí Arákùnrin N. H. Knorr ń mú ìdìpọ̀ àkọ́kọ́ jáde ní àpéjọ kan tí wọ́n ṣe ní August 2, 1950, ó sọ fún àwọn tó wá sí àpéjọ náà pé: “Ó ti pẹ́ tá a ti ń retí irú ìtumọ̀ Bíbélì yìí, èyí tí wọ́n fi èdè tó bóde mu kọ, tó bá ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ wa mu, tó sì gbé èrò Ọlọ́run yọ gẹ́lẹ́ bó ṣe wà nínú ẹ̀dà ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ká lè túbọ̀ lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́; ìtumọ̀ Bíbélì tó yé àwọn tó ń kà á lóde òní bí ìwé táwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi kọ ṣe yé onírúurú èèyàn tó wà nígbà ayé wọn.” Arákùnrin Knorr tún wá jẹ́ kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà mọ̀ pé Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun máa mú kó rọrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
18. Kí ni ètò Ọlọ́run rí i pé ó pọn dandan kí títúmọ̀ Bíbélì lè túbọ̀ yára kánkán?
18 Lọ́dún 1963, ètò Ọlọ́run tẹ Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ni Ìtumọ̀ Ayé Titun tó ti wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì jáde ní èdè mẹ́fà sí i, ìyẹn èdè Dutch, Faransé, Ítálì, Jámánì, Potogí àti Sípáníìṣì. Nígbà tó sì di ọdún 1989, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá ẹ̀ka kan sílẹ̀ ní oríléeṣẹ́ láti máa bójú tó iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì. Lẹ́yìn náà, lọ́dún 2005, ètò Ọlọ́run wá rí i pé ó pọn dandan kí gbogbo èdè tí wọ́n ń túmọ̀ Ilé Ìṣọ́ sí bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì sí èdè wọn. Ní báyìí, odindi tàbí apá kan Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti wà ní èdè tó ju àádóje [130] lọ.
19. Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé wo ló wáyé lọ́dún 2013, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àtúnṣe dé bá èdè Gẹ̀ẹ́sì, torí náà ètò Ọlọ́run rí i pé ó yẹ ká tún Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì ṣe kó lè bá èdè Gẹ̀ẹ́sì òde oní mu. Ní ìpàdé ọdọọdún tí àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ṣe, ìkọkàndínláàádóje irú rẹ̀ tó wáyé ní October 5 àti 6, lọ́dún 2013, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan ààbọ̀ [1,413,676] èèyàn tó pé jọ síbẹ̀ tàbí tí wọ́n ń wò ó lórí tẹlifíṣọ̀n bó ṣe ń lọ lọ́wọ́. Inú gbogbo wọn dùn nígbà tí wọ́n gbọ́ bí mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Olùdarí kan ṣe ń kéde pé ètò Ọlọ́run ti mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì àtúnṣe ti ọdún 2013 jáde. Omijé ayọ̀ ń já bọ́ lójú ọ̀pọ̀ èèyàn bí àwọn tó ń bójú tó èrò ṣe ń pín ẹ̀dà tá a tún ṣe náà fáwọn èèyàn. Bí wọ́n ṣe ń ka àwọn ẹsẹ kan jáde látinú rẹ̀ lọ́jọ́ náà, gbogbo wọn kíyè sí i pé kò tíì sí ìtumọ̀ Bíbélì kankan tí Gẹ̀ẹ́sì inú rẹ̀ dùn lóye tóyẹn rí. Àwọn àtúnṣe tá a ṣe nínú Bíbélì tuntun yìí àti bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ rẹ̀ sí àwọn èdè míì la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
a Bí àpẹẹrẹ, èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ Ẹ́sírà 4:8; 7:12; Jeremáyà 10:11 àti Dáníẹ́lì 2:4.
b Septuagint túmọ̀ sí “Àádọ́rin” [70]. Àwọn kan sọ pé ìlú Íjíbítì ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì yìí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àádọ́jọ [150] ọdún ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n parí rẹ̀. Ìtumọ̀ Bíbélì yìí ṣì ṣe pàtàkì gan-an, torí pé ó jẹ́ káwọn ọ̀mọ̀wé lóye àwọn ọ̀rọ̀ kan àtàwọn ẹsẹ kan tó ṣòroó lóye nínú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fi èdè Hébérù kọ.
c Àwọn kan gbà pé èdè Hébérù ni Mátíù fi kọ ìwé Ìhìn Rere tó kọ àti pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ ló wá pa dà tú u sí èdè Gíríìkì.
d Wo Àfikún A3 tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ọdún 2013 lédè Gẹ̀ẹ́sì; tún wo àpilẹ̀kọ kan tó ní àkòrí náà, “Báwo Ni Ìwé Náà Ṣe Là á Já?” ní ojú ìwé 7 sí 9 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn.