Ẹ̀KỌ́ 06
Ṣé Ayé àti Ọ̀run Ní Ìbẹ̀rẹ̀?
“Ọ̀dọ̀ [Ọlọ́run] ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Ṣó o gbà bẹ́ẹ̀? Èrò àwọn kan ni pé ńṣe ni gbogbo nǹkan tó wà láyé ṣàdédé wà, tí ò sẹ́nì tó dá wọn. Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, á jẹ́ pé àwa èèyàn ṣèèṣì wà ni. Tó bá jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ni Orísun ìyè, ó gbọ́dọ̀ ní ìdí pàtàkì tó fi dá àwọn nǹkan, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?a Ṣé ayé àti ọ̀run ní ìbẹ̀rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ àti ìdí tó fi yẹ ká gbà pé òótọ́ ni ohun tó sọ.
1. Ṣé ayé àti ọ̀run ní ìbẹ̀rẹ̀?
Bíbélì sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló gbà pé ayé àti ọ̀run ní ìbẹ̀rẹ̀. Báwo ni Ọlọ́run ṣe dá wọn? Ó lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ìyẹn agbára tó fi ń ṣiṣẹ́ láti dá ayé àti ọ̀run, títí kan àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀, àwọn ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó kù.—Jẹ́nẹ́sísì 1:2.
2. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé?
Jèhófà ‘kò kàn dá ayé lásán, àmọ́ ó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀.’ (Àìsáyà 45:18) Ó dá ayé yìí lọ́nà tó tura fún àwa èèyàn láti máa gbé títí láé. (Ka Àìsáyà 40:28; 42:5.) Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé ayé yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an! Ìdí sì ni pé ayé nìkan ló ní gbogbo nǹkan tó ń gbé ẹ̀mí èèyàn ró.
3. Kí ló mú káwa èèyàn yàtọ̀ sáwọn ẹranko?
Lẹ́yìn tí Jèhófà dá ayé, ó dá àwọn ohun abẹ̀mí sínú ẹ̀. Àwọn ewéko àtàwọn ẹranko ló kọ́kọ́ dá. Lẹ́yìn náà, “Ọlọ́run sì dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀.” (Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:27.) Kí ló mú káwa èèyàn ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá? Ohun tó mú ká ṣàrà ọ̀tọ̀ ni pé àwòrán Ọlọ́run ni wá, torí náà a lè ní àwọn ìwà àti ìṣe tí Ọlọ́run ní, irú bí ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo. Ó tún dá wa lọ́nà tá a fi lè kọ́ àwọn èdè tuntun, a lè mọyì àwọn ohun tó rẹwà, a sì lè gbádùn orin lóríṣiríṣi. Ohun míì tá a tún lè ṣe àmọ́ táwọn ẹranko ò lè ṣe ni pé a lè jọ́sìn Ẹlẹ́dàá wa.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo ẹ̀rí tó fi hàn pé ẹnì kan wà tó dá ayé àtọ̀run àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn àti pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìwà àti ìṣe àwa èèyàn ṣe jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́.
4. Ẹnì kan ló dá ọ̀run àti ayé
Táwọn èèyàn bá wo àwọn ohun tí Ọlọ́run dá láti fi ṣe nǹkan, àwọn tó ṣe àwọn nǹkan náà làwọn èèyàn máa ń yìn. Ta ló wá yẹ kó gba ìyìn àti ẹ̀yẹ àwọn ohun tí wọ́n wò fi ṣe nǹkan ti wọ́n ṣe yẹn? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn nǹkan wo làwọn èèyàn ti ṣe tó jẹ́ pé àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ni wọ́n wò fi ṣe wọ́n?
Tó bá jẹ́ pé gbogbo ilé ló ní ẹni tó kọ́ ọ, ta ló wá dá àwọn nǹkan tó wà ní ayé àti ọ̀run? Ka Hébérù 3:4, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Èwo ló wù ẹ́ nínú àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sáyé?
Ṣó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ẹnì kan ló dá gbogbo nǹkan tó wà ní ayé àti ọ̀run? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ǹjẹ́ o mọ̀?
Tó o bá lọ sórí ìkànnì jw.org, wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Àwọn ẹ̀kọ́ náà la pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” àti “Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ìṣẹ̀dá.”
“Ó dájú pé, gbogbo ilé ló ní ẹni tó kọ́ ọ, àmọ́ Ọlọ́run ló kọ́ ohun gbogbo”
5. Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀
Nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní, Bíbélì sọ bí ayé àtàwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀. Ṣó o gbà pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ, àbí ìtàn àròsọ lásán ni? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé ohun tí Bíbélì sọ ni pé ọjọ́ mẹ́fà oníwákàtí-mẹ́rìnlélógún (24) ni Ọlọ́run fi dá ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀?
Ṣé o rò pé ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀ bọ́gbọ́n mu? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:1, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ayé àti ọ̀run ní ìbẹ̀rẹ̀. Báwo ni ohun tí wọ́n sọ yìí ṣe bá ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán nínú Bíbélì yẹn mu?
Èrò àwọn kan ni pé ńṣe ni Ọlọ́run jẹ́ kí àwọn ohun kéékèèké kan bẹ̀rẹ̀ sí í yíra pa dà, tí wọ́n sì di oríṣiríṣi àwọn ohun alààyè. Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:21, 25, 27, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé ohun tí Bíbélì sọ ni pé ńṣe ni Ọlọ́run kọ́kọ́ ṣe àwọn ohun kéékèèké kan táwọn nǹkan náà wá ń yíra pa dà di ẹja, oríṣiríṣi ẹranko, àtàwa èèyàn? Àbí ńṣe ló dá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní “irú tiwọn”?b
6. Ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run gbà dá àwa èèyàn
Àwa èèyàn yàtọ̀ pátápátá sáwọn ẹranko tí Jèhófà dá. Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:26, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara ẹ̀, àwa èèyàn máa ń fi ìfẹ́ àti àánú hàn, kí nìyẹn ń sọ fún wa nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ìtàn àròsọ lásán ni ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀.”
Kí lèrò tìẹ? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jèhófà ló dá ayé àti ọ̀run àtàwọn ohun tó wà nínú wọn.
Kí lo rí kọ́?
Kí ni Bíbélì sọ nípa bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀?
Ṣé Ọlọ́run jẹ́ káwọn ohun kéékèèké kan bẹ̀rẹ̀ sí í yíra pa dà di oríṣiríṣi àwọn ohun alààyè ni, àbí ńṣe ló dá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn?
Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àwa èèyàn?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo àwọn ohun àrà tí Ọlọ́run dá.
Wo bí bàbá kan ṣe ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá ayé àtọ̀run àtàwọn nǹkan tó wà nínú wọn fún ọmọ rẹ̀.
Wò ó bóyá ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n bá Bíbélì mu.
“Ṣé Ẹfolúṣọ̀n Ni Ọlọ́run Lò Láti Dá Àwọn Nǹkan?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
b Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “irú tiwọn” ń tọ́ka sí ọ̀wọ́ àwọn ohun alààyè.