Ojú Ìwòye Bíbélì
Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀?
ÌBÉÈRÈ lásán kọ́ ni ìbéèrè yìí o. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé títí dòní olónìí, àìgbọràn Ádámù àti Éfà ń fìyà jẹ gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Àmọ́, báwo ni wíwulẹ̀ mú èso igi kan àti jíjẹ èso náà ṣe yọrí sí àgbákò ńláǹlà bẹ́ẹ̀ yẹn?
Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, ó fi wọ́n sínú ọgbà ẹlẹ́wà kan tó kún fún oríṣiríṣi ohun ọ̀gbìn tẹ́nu ń jẹ àtàwọn igi eléso. Ọ̀kan ṣoṣo lára àwọn igi náà ni Ọlọ́run pàṣẹ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn, ìyẹn ni “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀dá tó lómìnira láti dá ṣèpinnu ni Ádámù àti Éfà, wọ́n lè yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run tàbí kí wọ́n ṣàìgbọràn sí i. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run kìlọ̀ fún Ádámù pé “ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú [igi ìmọ̀ rere àti búburú], dájúdájú, ìwọ yóò kú.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:29; 2:17.
Kò Burú bí Òmìnira Wọn Ṣe Ní Ààlà
Ohun kan ṣoṣo tí Ọlọ́run ní kí Ádámù àti Éfà má ṣe yìí ò fa ìnira kankan nítorí pé wọ́n lè jẹ lára èso gbogbo igi yòókù tó wà nínú ọgbà. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16) Àti pé ìkàléèwọ̀ ọ̀hún ò fi tọkọtaya náà hàn bí elérò búburú, bẹ́ẹ̀ ni ò sì fàbùkù kàn wọ́n. Bó bá jẹ́ pé ṣe ni Ọlọ́run sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá ẹranko lò pọ̀ tàbí tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ pààyàn ni, àwọn kan ì bá sọ pé àwọn èèyàn pípé náà lérò ibi kan lọ́kàn tí Ọlọ́run ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n hù níwà. Àmọ́ kò sí ohun tó burú nínú pé kí wọ́n jẹun.
Ṣé ìbálòpọ̀ takọtabo tiẹ̀ ni èso ọ̀hún, báwọn kan ṣe máa ń sọ ọ́? Irú èrò bẹ́ẹ̀ ò bá ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ mu. Ohun tá ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ni pé nígbà tí Ọlọ́run ń sọ fún Ádámù pé kò gbọ́dọ̀ jẹ èso yẹn, òun nìkan ló wà, ó sì ṣe díẹ̀ tó fi wà bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:23) Èkejì ni pé, Ọlọ́run sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n “di púpọ̀, kí [wọ́n] sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ré òfin òun kọjá tán, kó tún wá sọ pé ikú ló tọ́ sí wọn nítorí pé wọ́n pa àṣẹ òun mọ́! (1 Jòhánù 4:8) Ẹ̀kẹta wá ni pé, Éfà ló kọ́kọ́ jẹ èso náà, lẹ́yìn náà ló fún ọkọ ẹ̀ ní díẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Látàrí èyí, ó ṣe kedere pé èso náà kì í ṣe ìbálòpọ̀.
Wọ́n Fẹ́ Máa Ṣe Ìfẹ́ Inú Ara Wọn
Igi ìmọ̀ náà ò yàtọ̀ sáwọn igi yòókù. Àmọ́, ó dúró fún ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní gẹ́gẹ́ bí Alákòóso láti pinnu fáwọn ẹ̀dá tó dá, pé ohun kan dára tàbí pé ó burú. Nítorí náà, béèyàn bá jẹ nínú èso igi náà, kì í ṣe pé ó jalè nìkan, ní ti pé ó mú ohun tó jẹ́ ti Ọlọ́run. Ó tún túmọ̀ sí pé onítọ̀hún fẹ́ máa ṣe ìfẹ́ inú ara ẹ̀, ó fẹ́ máa dá pinnu ohun tó wù ú. Ẹ kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Sátánì ti purọ́ fún Éfà pé bí òun àti ọkọ rẹ̀ bá jẹ nínú èso náà, wọn ò ní kú, ó sọ pé: “Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5.
Àmọ́, nígbà tí Ádámù àti Éfà pàpà jẹ èso náà, wọn ò rí ìlàlóye kankan tó mú kí wọ́n dà bí Ọlọ́run nípa mímọ rere àti búburú. Kódà, Éfà sọ fún Ọlọ́run pé: “Ejò—òun ni ó tàn mí.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:13) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó mọ ohun tí òfin Ọlọ́run sọ, kódà ó sọ ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún ejò tó gbẹnu sọ fún Sátánì. (Ìṣípayá 12:9) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ńṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-3) Kò sẹ́ni tó tan Ádámù jẹ ní tiẹ̀ ṣá o. (1 Tímótì 2:14) Dípò kó dúró ṣinṣin nípa ṣíṣègbọràn sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ó gbọ́ tí aya rẹ̀, ó sì gbà kí wọ́n jọ ṣe ìfẹ́ inú ara wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:6, 17.
Ńṣe ni gbígbà tí Ádámù àti Éfà gbà láti máa ṣèfẹ́ inú ara wọn yìí ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ kọjá àlà, tí ẹ̀ṣẹ̀ sì jọba nínú ayé wọn, débi tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í ba àgọ́ ara wọn jẹ́ tó fi mọ́ àbùdá wọn tí Ọlọ́run dá ní pípé. Lóòótọ́ ni wọ́n gbé láyé fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, àmọ́ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kú ‘ní ọjọ́’ náà gan-an tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, bí ẹ̀ka tá a gé kúrò lára igi ṣe máa ń kú díẹ̀díẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 5:5) Síwájú sí i, ìgbà àkọ́kọ́ tí ọkàn wọn dà rú nìyẹn. Wọ́n rí i pé ìhòòhò làwọn wà, wọ́n sì gbìyànjú láti fara pa mọ́ fún Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:7, 8) Ọkàn wọn tún bẹ̀rẹ̀ sí í dá wọn lẹ́bi, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n, ojú sì ń tì wọ́n. Ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá kó ṣìbáṣìbo bá wọn, ẹ̀rí ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí dá wọn lẹ́bi pé wọ́n ti hùwà àìtọ́.
Kí Ọlọ́run bàa lè mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ kó sì hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà mímọ́ rẹ̀, ó tọ́ pé kó dájọ́ ikú fún Ádámù àti Éfà kó sì lé wọn kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19, 23, 24) Wọ́n tipa báyìí pàdánù Párádísè, ayọ̀ àti ìyè ayérayé, àbájáde èyí tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ìjìyà àti ikú. Bí gbogbo aráyé ṣe kàgbákò nìyẹn o! Àmọ́ ṣá o, lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti dájọ́ ikú fún tọkọtaya náà, ó ṣèlérí pé òun á mú gbogbo ìpalára tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mú wá kúrò láìré àwọn ìlànà òdodo òun kọjá
Jèhófà ṣèlérí pé òun á mú kó ṣeé ṣe fún àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà láti bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ó mú ìlérí yìí ṣẹ nípasẹ̀ Jésù Kristi. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Mátíù 20:28; Gálátíà 3:16) Nípasẹ̀ rẹ̀, Ọlọ́run yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ àti gbogbo ọṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá yóò sì sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di párádísè gẹ́gẹ́ bó ti fẹ́ kó rí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.—Lúùkù 23:43; Jòhánù 3:16.
ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?
◼ Báwo la ṣe mọ̀ pé èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà kì í ṣe ìbálòpọ̀ takọtabo?—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
◼ Kí ni jíjẹ nínú èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà túmọ̀ sí?—Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5.
◼ Ètò wo ni Ọlọ́run ti ṣe kó bàa lè mú ọṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò?—Mátíù 20:28.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
Èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà kì í ṣe ìbálòpọ̀ takọtabo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
Éfà fẹ́ láti dà bí Ọlọ́run, ó fẹ́ láti máa pinnu fúnra ẹ̀ bóyá ohun kan burú tàbí ó dára