Kò Yẹ Kí A Dẹ́bi fun Jehofa
“Bii baba kan tií ṣe ìyọ́nú si awọn ọmọ, bẹẹ ni Oluwa ń ṣe ìyọ́nú si awọn ti o bẹru rẹ̀. Nitori ti o mọ iṣẹda wa, ó ranti pe erupẹ ni wa.”—ORIN DAFIDI 103:13, 14.
1, 2. Ta ni Abrahamu, bawo si ni ọmọkunrin arakunrin rẹ̀ Loti ṣe di olùgbé ni ilu-nla Sodomu buruku naa?
JEHOFA kọ́ ní ń ṣokunfa awọn inira ti a lè niriiri rẹ nitori awọn aṣiṣe wa. Ni ọ̀nà yii gbé ohun ti o ṣẹlẹ ni nǹkan bii 3,900 ọdun sẹhin yẹwo. Ọ̀rẹ́ Ọlọrun Abrahamu (Abramu) ati ọmọkunrin arakunrin rẹ̀ Loti ti di alaasiki gidigidi. (Jakọbu 2:23) Niti tootọ, awọn ohun-ìní ati ohun ọ̀sìn wọn pọ tobẹẹ ti o fi jẹ pe ‘ilẹ naa kò si gbà wọn lati gbé papọ.’ Ju bẹẹ lọ, aáwọ̀ ṣẹlẹ laaarin awọn darandaran awọn ọkunrin mejeeji naa. (Genesisi 13:5-7) Ki ni wọn le ṣe nipa eyi?
2 Lati pari aáwọ̀ naa, Abrahamu damọran pe ki ipinya kan ṣẹlẹ, oun si yọnda ki Loti ṣe yíyàn akọkọ. Bi o tilẹ jẹ pe Abrahamu ni o dagba ju ti yoo si ti jẹ́ ohun yíyẹ pe ki ọmọkunrin arakunrin rẹ̀ jẹ ki oun mú ààyè ilẹ ibi ti o dara julọ, Loti yan ẹkùn ayanlaayo julọ—gbogbo agbegbe Jordani Titẹju ti ó lómi daadaa. Awọn irisi ode jẹ́ atannijẹ, nitori nitosi ni awọn ilu-nla Sodomu ati Gomorra ti wọn ti niriiri iwolulẹ iwarere wà. Ni asẹhinwa-asẹhinbọ Loti ati idile rẹ̀ ṣilọ si Sodomu, ti eyi si fi wọn sinu ewu nla nipa tẹmi. Siwaju sii, a mu wọn lẹru nigba ti Ọba Kedorlaomeri ati awọn onígbèjà rẹ̀ ṣẹgun ọba Sodomu. Abrahamu ati awọn eniyan rẹ̀ gbà wọn silẹ, ṣugbọn Loti ati idile rẹ̀ pada si Sodomu.—Genesisi 13:8-13; 14:4-16.
3, 4. Ki ni o ṣẹlẹ si Loti ati awọn mẹmba idile rẹ̀ nigba ti Ọlọrun pa Sodomu ati Gomorra run?
3 Nitori ibalopọ takọtabo ti a gbégbòdì ati ìrẹ̀nípòwálẹ̀ Sodomu ati Gomorra, Jehofa pinnu lati pa awọn ilu-nla wọnni run. Nitori aanu rẹ̀ oun rán awọn angẹli meji lati mú Loti, iyawo rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin wọn mejeeji jade kuro ni Sodomu. Wọn ko nilati bojuwo ẹhin, ṣugbọn iyawo Loti ṣe bẹẹ, boya ni yíyánhànhàn fun awọn ohun-ìní ti ara ti wọn ti fisilẹ sẹhin. Lori koko yẹn, oun di ọ̀wọ̀n iyọ̀.—Genesisi 19:1-26.
4 Ẹ wo iru àdánù ti Loti ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ faragbá! Awọn ọmọdebinrin naa nilati fi awọn ọkunrin ti wọn yoo fẹ́ silẹ. Nisinsinyi Loti wà laisi iyawo rẹ̀ ati awọn ohun-ìní ti ara rẹ̀. Niti tootọ, oun ní asẹhinwa-asẹhinbọ ni a fipá mú lati gbé inu iho pẹlu awọn ọmọbinrin rẹ̀. (Genesisi 19:30-38) Ohun ti o ti dara loju rẹ̀ wa yipada si odikeji rẹ̀ gan-an. Bi o tilẹ jẹ pe ó hàn kedere pe o ti ṣe awọn aṣiṣe wiwuwo, oun lẹhin naa ni a pe ni ‘Loti oloootọ.’ (2 Peteru 2:7, 8) Dajudaju kò yẹ ki a dẹ́bi fun Jehofa Ọlọrun fun awọn aṣiṣe Loti.
“Awọn Aṣiṣe—Ta Ni O Lè Fòyemọ̀?”
5. Ki ni imọlara Dafidi nipa awọn aṣiṣe ati ìkùgbùù?
5 Bi a ti jẹ alaipe ati ẹlẹṣẹ, gbogbo wa ni a ń ṣe aṣiṣe. (Romu 5:12; Jakọbu 3:2) Bii Loti, a le tàn wá jẹ nipasẹ irisi ode a si lè ṣìnà ninu idajọ. Nipa bayii, olorin naa Dafidi jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pe: “Awọn aṣiṣe—ta ni o lè fòyemọ̀? Lati inu awọn ẹṣẹ ìkọ̀kọ̀ kede mi ni alaimọwọmẹsẹ. Ati pẹlu lati inu awọn iṣe ìkùgbùù dá iranṣẹ rẹ̀ duro; maṣe jẹ ki wọn jọba lé mi lori. Nipa bẹẹ emi yoo pe perepere, emi yoo si ti wà ni alaimọwọmẹsẹ ninu awọn irelanakọja pupọ.” (Orin Dafidi 19:12, 13, NW) Dafidi mọ pe oun le ṣẹ awọn ẹṣẹ kan eyi ti oun kò tilẹ ni mọ̀ paapaa. Nipa bayii, oun beere fun idariji kuro ninu awọn irelanakọja ti o ti le farapamọ àní fun oun. Nigba ti oun ṣe aṣiṣe wiwuwo nitori pe ẹran ara alaipe rẹ̀ sun un lati gbé igbesẹ ti kò tọna, oun fọkanfẹ iranlọwọ Jehofa gan-an. Oun fẹ ki Ọlọrun ṣediwọ fun oun ninu awọn ìṣe ìkùgbùù. Dafidi kò fẹ́ ki ìkùgbùù di ẹmi ironu ti ń jọba lé oun lori. Kaka bẹẹ, o fọkanfẹ lati pe perepere ninu ifọkansin rẹ̀ si Jehofa Ọlọrun.
6. Itunu wo ni a lè ri fayọ lati inu Orin Dafidi 103:10-14?
6 Gẹgẹ bi awọn iranṣẹ oluṣeyasimimọ Jehofa ti ode-oni, awa pẹlu jẹ alaipe ti a si tipa bẹẹ maa ń ṣe awọn aṣiṣe. Fun apẹẹrẹ, bii Loti, a le ṣe awọn yíyàn ti o buru niti ibugbe wa. Boya a ń jẹ ki anfaani lati mú iṣẹ-isin mimọ ọlọ́wọ̀ wa si Ọlọrun gbooro sii rekọja lọ. Bi o tilẹ jẹ pe Jehofa ri iru awọn aṣiṣe bẹẹ, ó mọ̀ awọn wọnni ti wọn ní ọkan-aya ti o tẹsiha ododo. Bi a bá tilẹ ṣẹ ẹṣẹ wiwuwo paapaa ṣugbọn ti a bá ronupiwada, Jehofa ń pese idariji ati iranlọwọ ó si ń baa lọ lati wò wa gẹgẹ bi ẹni ti o ní ifọkansin. “Oun kìí ṣe si wa gẹgẹ bi ẹṣẹ wa; bẹẹ ni kìí san án fun wa gẹgẹ bi aiṣedeedee wa,” ni Dafidi polongo. “Nitori pe, bi ọrun ti ga si ilẹ, bẹẹ ni aanu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹru rẹ̀. Bi ila-oorun ti jinna si iwọ-oorun, bẹẹ ni ó mú irekọja wa jinna kuro lọdọ wa. Bi baba tií ṣe ìyọ́nú si awọn ọmọ, bẹẹ ni Oluwa ń ṣe ìyọ́nú si awọn ti o bẹru rẹ̀. Nitori ti o mọ ẹ̀dá wa; ó ranti pe erupẹ ni wa.” (Orin Dafidi 103:10-14) Baba wa ọrun alaaanu tun lè fun wa lagbara lati ṣatunṣe awọn iṣina wa tabi ki o yọnda anfaani miiran fun wa lati mu iṣẹ-isin mimọ ọlọ́wọ̀ wa gbooro sii, si iyin rẹ̀.
Aṣiṣe ti Dídẹ́bi fun Ọlọrun
7. Eeṣe ti a fi ń jiya awọn túláàsì?
7 Nigba ti awọn nǹkan ko ba lọ deedee, o jẹ itẹsi ẹ̀dá eniyan lati dẹ́bi fun ẹnikan tabi ohun kan fun ohun ti o ti ṣẹlẹ. Awọn miiran tilẹ ń dẹ́bi fun Ọlọrun. Ṣugbọn Jehofa kìí mu iru awọn inira bẹẹ wá fun awọn eniyan. O ń ṣe rere, kìí ṣe awọn ohun tí ń panilara. Họwu, “ó ń mú oorun rẹ̀ ràn sára eniyan buburu ati sára eniyan rere, o sì ń rọ̀jò fun awọn oloootọ ati fun awọn alaiṣootọ”! (Matteu 5:45) Idi ti o gba ipo iwaju julọ ti a fi ń jiya túlàásì ni pe a ń gbe ninu ayé kan ti a ń fi awọn ilana imọtara-ẹni-nikan darí ti o si sinmi le agbara Satani Eṣu.—1 Johannu 5:19.
8. Ki ni Adamu ṣe nigba ti awọn nǹkan kò lọ bi o ti tọ́ fun un?
8 Dídẹ́bi fun Jehofa Ọlọrun fun awọn inira tí awọn aṣiṣe wa mú wá sori wa kò bọ́gbọ́n mu ó sì léwu. Ṣiṣe bẹẹ tilẹ le ná wa ni iwalaaye wa gan-an. Ọkunrin akọkọ, Adamu, ti yẹ ki o fun Ọlọrun ni iyìn-ọlá fun gbogbo ohun rere ti ó rí gbà. Bẹẹni, ó yẹ ki Adamu ti kun fun imoore jijinlẹ si Jehofa fun iwalaaye fúnraarẹ̀ ati fun awọn ibukun ti oun gbadun ninu ile bii ọgbà itura, ọgbà Edeni. (Genesisi 2:7-9) Ki ni ohun ti Adamu ṣe nigba ti awọn nǹkan ko lọ daradara nitori pe ó ṣaigbọran si Jehofa ti o si jẹ eso ti a ti kaleewọ naa? Adamu ráhùn fun Ọlọrun pe: “Obinrin ti iwọ fi pẹlu mi, oun ni ó fun mi ninu eso igi naa, emi si jẹ.” (Genesisi 2:15-17; 3:1-12) Dajudaju, awa kò gbọdọ dẹ́bi fun Jehofa, bi Adamu ti ṣe.
9. (a) Bi a bá bá awọn inira pade nitori awọn igbesẹ wa ti kò bọ́gbọ́n mu, lati inu ki ni a ti le ri itunu fayọ? (b) Ni ibamu pẹlu Owe 19:3, ki ni awọn kan ń ṣe nigba ti wọn bá mú awọn iṣoro wá sori araawọn?
9 Bi a bá bá awọn inira pade nitori pe awọn igbeṣẹ wa kò bọ́gbọ́n mu, a lè ri itunu fàyọ lati inu ìmọ̀ naa pe Jehofa loye ailera wa ju bi a ṣe mọ̀ wọ́n lọ ti yoo si dá wa nídè kuro ninu ipo-ọran-iṣoro wa bi a bá fun un ni ifọkansin ti a yasọtọ gédégbé. A nilati mọriri iranlọwọ atọrunwa ti a ń rígbà, ki a maṣe dẹ́bi fun Ọlọrun fun awọn ipo àìrọ́nàgbegbà ati awọn iṣoro ti a mú wa sori araawa. Ni ọ̀nà yii owe ọlọgbọn kan sọ pe: “Wèrè eniyan yi ọ̀nà rẹ̀ po: nigba naa ni àyà rẹ̀ binu si Oluwa.” (Owe 19:3) Itumọ miiran sọ pe: “Awọn eniyan kan ń run araawọn nipa awọn igbesẹ arìndìn wọn lẹhin naa wọn a sì dẹbi fun OLUWA.” (Today’s English Version) Sibẹ itumọ miiran sọ pe: “Aimọkan eniyan doju àlámọ̀rí rẹ̀ rú ó sì ru ibinu dide lodisi Jehofa.”—Byington.
10. Bawo ni iwa òmùgọ̀ Adamu ṣe ‘yí ọ̀nà rẹ̀ po’?
10 Ni ibaramu pẹlu ilana owe yii, Adamu huwa lọna imọtara-ẹni-nikan ti ironu arìndìn rẹ̀ si “yí ọ̀nà rẹ̀ po.” Ọkan-aya rẹ̀ yipada kuro lọdọ Jehofa Ọlọrun, ó sì muratan lati gba ipa-ọna onimọtara-ẹni-nikan, olominira tirẹ̀ fúnraarẹ̀. Họwu, Adamu di iru alaimoore kan bẹẹ debi ti o fi dẹ́bi fun Ẹlẹdaa rẹ̀ ti o si tipa bayii sọ araarẹ̀ di ọ̀tá Ẹni Giga Julọ naa! Ẹṣẹ Adamu mu ọ̀nà rẹ̀ ati ti idile rẹ̀ wa si iparun. Ẹ wo iru ikilọ ti o wà ninu eyi! Awọn wọnni ti wọn nitẹsi lati dẹ́bi fun Jehofa fun awọn ipo ti ko fanilọkanmọra le ṣe daradara lati beere lọwọ araawọn pe: Mo ha ń fun Ọlọrun ni iyìn-ọlá fun awọn nǹkan rere ti mo ń gbadun bi? Mo ha dupẹ pe mo ni iwalaaye gẹgẹ bi ọ̀kan lara awọn iṣẹda rẹ̀ bi? O ha lè jẹ pe awọn iṣina mi ti mú awọn inira wá sori mi? Mo ha lẹtọọsi ojurere tabi iranlọwọ Jehofa nitori pe mo ń tẹle itọsọna rẹ̀, gẹgẹ bi a ti lana rẹ̀ silẹ ninu Bibeli, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti o ni imisi?
Ewu kan fun Awọn Iranṣẹ Ọlọrun Paapaa
11. Niti Ọlọrun, ki ni awọn aṣaaju isin Ju ọrundun kìn-ín-ní jẹbi rẹ̀?
11 Awọn aṣaaju isin Ju ni ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní Sanmani Tiwa jẹwọ pe awọn ń ṣiṣẹsin Ọlọrun ṣugbọn wọn ṣá ọ̀rọ̀ otitọ rẹ̀ tì wọn si sinmi le òye tiwọn funraawọn. (Matteu 15:8, 9) Nitori pe Jesu Kristi taṣiiri awọn ironu òdì wọn, wọn ṣekupa á. Lẹhin naa, wọn fi ẹ̀hónú ńláǹlà hàn lodisi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. (Iṣe 7:54-60) Ọ̀nà awọn eniyan wọnyẹn lọ́po tobẹẹ ti o fi jẹ́ pe inu wọn ru si Jehofa fúnraarẹ̀ gan-an niti gidi.—Fiwe Iṣe 5:34, 38, 39.
12. Apẹẹrẹ wo ni o fihàn pe awọn kan tí ń darapọ mọ ijọ Kristian paapaa ń gbiyanju lati dẹ́bi fun Jehofa fun awọn iṣoro wọn?
12 Àní awọn kọọkan ninu ijọ Kristian paapaa ti mú ironu lilewu dagba, ni gbigbiyanju lati sọ pe Ọlọrun ni okunfa fun awọn iṣoro ti wọn ti bá pade. Fun apẹẹrẹ, awọn alagba ti a yàn ninu ijọ kan ri í pe o pọndandan lati fun ọdọbinrin kan ti o ti ṣegbeyawo ni imọran oninuure ti o bá Iwe Mimọ mu sibẹ ti o fidimulẹ gbọnyin lodisi kikẹgbẹpọ pẹlu ọkunrin ẹni ayé kan. Lakooko ijumọsọrọpọ kan, o dẹ́bi fun Ọlọrun fun ṣiṣai ràn án lọwọ lati le kọjú ìjà si idẹwo naa tí ibakẹgbẹpọ oun tí ń baa lọ pẹlu ọkunrin naa mú wa sori oun. Ó sọ niti gidi pe ori oun gbóná si Ọlọrun! Awọn ibanironupọ ti o bá Iwe Mimọ mu ati awọn isapa àṣetúnṣe lati ràn án lọwọ jẹ́ alaikẹsẹjari, ipa-ọna oniwa palapala kan laipẹ si jálẹ̀ si lílé e jade kuro ninu ijọ Kristian.
13. Eeṣe ti o fi yẹ ki a yẹra fun ẹmi-ironu oníràáhùn?
13 Ẹmi ìráhùn lè ṣamọna ẹnikan si dídẹ́bi fun Jehofa. “Awọn alaiwa-bi-Ọlọrun” ti wọn yọ́ wọ inu ijọ ọrundun kìn-ín-ní ni iru ẹmi buburu bẹẹ, iru ironu ti ń sọnidibajẹ miiran si tun ba á rìn pẹlu. Gẹgẹ bi Juda ọmọ-ẹhin naa ti sọ ọ́, awọn eniyan wọnyi “ń yi oore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti wọn sì ń sẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo naa, àní Jesu Kristi Oluwa.” Juda tun sọ pe: “Awọn wọnyi ni awọn ti ń kùn, awọn aláròyé.” (Juda 3, 4, 16) Awọn aduroṣinṣin iranṣẹ Jehofa yoo fi ọgbọ́n gbadura pe ki wọn ni ẹmi imọriri, kìí ṣe ẹmi-ironu oníràáhùn ti o lè mú wọn binu kikoro ni asẹhinwa-asẹhinbọ de ayé naa ti wọn yoo fi padanu igbagbọ wọn ninu Ọlọrun ki wọn si jin ipo-ibatan wọn pẹlu rẹ̀ lẹsẹ.
14. Bawo ni ẹnikan ṣe le huwapada bi Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan bá ṣe laifi si i, ṣugbọn eeṣe ti eyi kò fi le jẹ́ ipa-ọna titọna?
14 Iwọ le nimọlara pe eyi ko lè ṣẹlẹ si ọ. Sibẹ, awọn nǹkan ti kò lọ deedee nitori awọn aṣiṣe wa tabi ti awọn ẹlomiran lè mú wa dẹ́bi fun Ọlọrun nikẹhin. Fun apẹẹrẹ, a lè ṣe laifi si ẹnikan nipasẹ ohun ti onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan sọ tabi ṣe. Ẹni ti a ṣe laifi si naa—boya ẹnikan ti o ti fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa fun ọpọlọpọ ọdun—le sọ nigba naa pe: ‘Bi ẹni yẹn bá wà ninu ijọ naa, emi kì yoo lọ si awọn ipade.’ Ọkàn ẹnikan lè gbọgbẹ́ tobẹẹ ti yoo fi sọ ninu ọkan-aya rẹ̀ pe: ‘Bi nǹkan bá ń baa lọ bayii, emi kì yoo fẹ́ lati jẹ apakan ijọ naa.’ Ṣugbọn ǹjẹ́ ó yẹ ki Kristian kan ni iru ẹmi-ironu yẹn bi? Bi eniyan alaipe miiran ba ṣe laifi si wa, eeṣe ti a fi nilati binu ki ọkàn wa si gbọgbẹ́ si gbogbo ijọ awọn eniyan ti o ṣetẹwọgba si Ọlọrun ti wọn si ń fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin in? Eeṣe ti ẹnikan ti o ti ṣe iyasimimọ si Jehofa fi gbọdọ dá ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun duro ki o binu ki ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́ si Ọlọrun? Ọgbọ́n wo ni o wà ninu jíjẹ́ ki eniyan kan tabi ọ̀wọ́ awọn ayika-ipo pa ipo-ibatan rere ti ẹnikan ni pẹlu Jehofa run? Dajudaju, yoo jẹ́ iwa òmùgọ̀ ti o si kun fun ẹṣẹ lati dáwọ́ jijọsin Jehofa Ọlọrun duro fun idi eyikeyii.—Jakọbu 4:17.
15, 16. Ki ni Diotrefe jẹbi rẹ̀, ṣugbọn ọ̀nà wo ni Gaiu gbà huwa?
15 Ronuwoye pe o wà ninu ijọ kan-naa pẹlu Kristian onifẹẹ naa Gaiu. O “ń ṣe iṣẹ igbagbọ” ni ninawọ alejo-ṣiṣe si awọn olujọsin ẹlẹgbẹ rẹ̀ tí ń ṣebẹwo—pẹlupẹlu pe wọn tun jẹ awọn ajeji! Ṣugbọn dajudaju ninu ijọ kan-naa, ni ọkunrin agberaga kan ti ń jẹ Diotrefe wà. Oun kì yoo tẹwọgba ohunkohun pẹlu ọ̀wọ̀ lati ọ̀dọ̀ Johannu, ọ̀kan lara awọn aposteli Jesu Kristi. Niti tootọ, Diotrefe tilẹ wírèégbè kaakiri nipa Johannu pẹlu awọn ọ̀rọ̀ buruku. Aposteli naa sọ pe: “Eyiini kò si tẹ́ ẹ lọ́rùn, bẹẹ ni [Diotrefe] tìkáraarẹ̀ kò gba awọn ará, awọn ti o si ń fẹ gbà wọn, ó ń dá wọn lẹkun, ó sì ń le wọn jade kuro ninu ijọ.”—3 Johannu 1, 5-10.
16 Bi Johannu ba wá sinu ijọ naa, o pète lati pe awọn iṣẹ́ ti Diotrefe ń ṣe wa si iranti. Laaarin akoko naa, bawo ni Gaiu ati awọn Kristian olufẹ alejo-ṣiṣe miiran ninu ijọ ṣe huwapada? Kò si itọka kankan ninu Iwe Mimọ pe eyikeyii ninu wọn sọ pe: ‘Niwọn ìgbà ti Diotrefe bá ṣì wà ninu ijọ, emi kò fẹ lati jẹ apakan rẹ̀. Ẹyin kì yoo ri mi ni awọn ipade.’ Laiṣiyemeji Gaiu ati awọn miiran bii tirẹ̀ duro gbọnyin. Wọn kò jẹ ki ohunkohun dá wọn duro ninu ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun, dajudaju wọn kò si jẹ ki inu wọn ru lodisi Jehofa. Bẹẹkọ, niti gidi, wọn kò si jọ̀gọ̀nù fun awọn ọgbọ́n arekereke Satani Eṣu, ẹni ti iba ti yọ̀ bi wọn ba di alaiṣootọ si Jehofa ki wọn si dẹ́bi fun Ọlọrun.—Efesu 6:10-18.
Maṣe Jẹ Ki Inu Rẹ Ru si Jehofa Lae!
17. Bawo ni o ṣe yẹ ki a huwa bi awọn kan tabi ipo kan bá bi wa ninu tabi ṣàìtẹ́ wa lọ́rùn?
17 Koda bi awọn kan tabi ipo kan ninu ijọ ba ṣàìtẹ́ iranṣẹ Ọlọrun kan lọ́rùn tabi mú un binu, ẹni naa ti o ń binu niti gidi yoo maa yí ọ̀nà rẹ̀ po bi o ba dawọ ibakẹgbẹpọ pẹlu awọn eniyan Jehofa duro. Iru ẹni bẹẹ kì yoo fi agbara ìwòye rẹ̀ si ìlò daradara. (Heberu 5:14) Nitori naa pinnu lati dojukọ gbogbo tulaasi bi olupa iwatitọ mọ kan. Di iduroṣinṣin rẹ si Jehofa Ọlọrun, Jesu Kristi, ati ijọ Kristian mu ṣinṣin. (Heberu 10:24, 25) A kò le ri otitọ ti ń sinni lọ si ìyè ayeraye ni ibomiran kankan mọ́.
18. Bi o tilẹ jẹ pe a kìí figba gbogbo loye awọn ibalo atọrunwa, ki ni o le da wa loju nipa Jehofa Ọlọrun?
18 Ranti, pẹlu, pe Jehofa kìí fi ohun buburu dán ẹnikẹni wò. (Jakobu 1:13) Ọlọrun, ẹni ti o jẹ ẹ̀dàyà-àpẹẹrẹ ifẹ, ń ṣe rere, paapaa ni pataki fun awọn wọnni ti wọn nifẹẹ rẹ̀. (1 Johannu 4:8) Bi o tilẹ jẹ pe a kìí loye ibalo Ọlọrun ni gbogbo ìgbà, a lè ni igbọkanle pe Jehofa Ọlọrun kì yoo kuna lae lati ṣe ohun ti o dara julọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀. Gẹgẹ bi Peteru ti sọ: “Nitori naa ẹ rẹ ara yin silẹ labẹ ọwọ́ agbara Ọlọrun, ki oun ki o le gbé yin ga ni akoko. Ẹ maa ko gbogbo aniyan yin lé e; nitori ti oun ń ṣe itọju yin.” (1 Peteru 5:6, 7) Bẹẹni, Jehofa bikita nipa awọn eniyan rẹ̀ nitootọ.—Orin Dafidi 94:14.
19, 20. Bawo ni o ṣe yẹ ki a huwa, ani bi awọn adanwo wa ba mu wa sorikọ nigba miiran?
19 Nitori naa, ẹ maṣe jẹ ki ohunkohun tabi ẹnikẹni mú yin kọsẹ. Bi olorin naa ti sọ ọ́ daradara pe, “alaafia pupọ ni awọn ti o fẹ ofin [Jehofa Ọlọrun] ni: kò sì sí ohun ikọsẹ fun wọn.” (Orin Dafidi 119:165) Gbogbo wa ni a ń ni iriri adanwo, iwọnyi sì lè mú wa sorikọ ki a si sọretinu lọna kan ṣáá nigba miiran. Ṣugbọn maṣe jẹ ki ibinu kikoro gbèrú ninu ọkan-aya rẹ, paapaa ni pataki lodisi Jehofa. (Owe 4:23) Pẹlu iranlọwọ rẹ̀ ati nitori awọn idi ti o bá Iwe Mimọ mu, bojuto awọn iṣoro naa ti o lè yanju ki o si farada awọn ti o ń baa lọ laiduro.—Matteu 18:15-17; Efesu 4:26, 27.
20 Maṣe yọnda ki ero-imọlara rẹ sún ọ lati huwapada bi òmùgọ̀ ki o si tipa bẹẹ lọ́ ọ̀nà rẹ po. Sọrọ ki o si huwa ni iru-ọna ti yoo mú ọkan-aya Ọlọrun yọ. (Owe 27:11) Kepe Jehofa ninu adura onígbòóná-ọkàn, ni mimọ pe oun ń bikita nipa rẹ gẹgẹ bi ọ̀kan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ ti yoo sì fun ọ ni òye ti o nilo lati duro ni ipa-ọna iye pẹlu awọn eniyan rẹ̀. (Owe 3:5, 6) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, maṣe jẹ ki inu rẹ ru lodisi Ọlọrun. Bi awọn nǹkan kò bá lọ deedee, maa ranti nigbagbogbo pe kò yẹ kí a dẹ́bi fun Jehofa.
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Aṣiṣe wo ni Loti ṣe, ṣugbọn oju wo ni Ọlọrun fi wò ó?
◻ Ki ni imọlara Dafidi nipa awọn aṣiṣe ati ìkùgbùù?
◻ Nigba ti awọn nǹkan kò bá lọ deedee, eeṣe ti kò fi yẹ ki a dẹ́bi fun Ọlọrun?
◻ Ki ni yoo ràn wá lọwọ lati yẹra fun jijẹ ki inu wa ru lodisi Jehofa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Nigba ti o ń pinya kuro lọdọ Abrahamu, Loti ṣe yiyan ti kò dara tó niti ibugbe rẹ̀