Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) Dájúdájú, Bíbélì jẹ́ ìwé òtítọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́.—Sáàmù 83:18.
Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, títí kan àwa èèyàn, ó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà táa bá kú. (Hébérù 3:4; Ìṣípayá 4:11) Inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ táa mí sí, ló sì ti fún wa ní àwọn ìdáhùn tó jẹ́ òtítọ́, tó sì tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú.
Kí Ni Ẹ̀mí?
Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà táa tú sí “ẹ̀mí” wulẹ̀ túmọ̀ sí “èémí.” Àmọ́, èyí ju kìkì ọ̀ràn mímí lọ. Fún àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé Bíbélì náà Jákọ́bù sọ pé: “Ara láìsí ẹ̀mí . . . jẹ́ òkú.” (Jákọ́bù 2:26) Nítorí náà, ẹ̀mí ni ohun tó ń mú kí ara ṣiṣẹ́.
Ipá tó ń mú kí ara ṣiṣẹ́ yìí kò wulẹ̀ lè jẹ́ èémí, tàbí atẹ́gùn tó ń lọ káàkiri inú ẹ̀dọ̀fóró. Kí nìdí? Nítorí pé bí èémí bá dáwọ́ dúró, ìwàláàyè á ṣì wà nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ara fún ìgbà díẹ̀—“fún ìṣẹ́jú bíi mélòó kan,” gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣe sọ. Fún ìdí yìí, ó ṣì ṣeé ṣe láti mú un sọ jí. Àmọ́ bí ẹ̀mí tó ń mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe bá kúrò nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ara, òfúùtùfẹ́ẹ̀tẹ̀ ni gbogbo akitiyan láti mú ẹni yẹn sọ jí máa já sí. Kò sí iye èémí tàbí atẹ́gùn tó lè mú sẹ́ẹ̀lì kan péré sọ jí. Nígbà náà, ẹ̀mí jẹ́ agbára ìwàláàyè tí kò ṣeé fojú rí—ohun tó mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe, tó ń mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì àti èèyàn wà láàyè. Èémí ló ń gbé agbára ìwàláàyè yìí ró.— Jóòbù 34:14, 15.
Ṣé inú èèyàn nìkan ni ẹ̀mí yẹn ti ń ṣiṣẹ́ ni? Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ̀nà nípa ọ̀ràn yìí. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba gbà pé àtèèyàn àtẹranko, “ẹ̀mí kan ṣoṣo . . . ni gbogbo wọ́n ní,” ó sì béèrè pé: “Ta ní ń bẹ tí ó mọ ẹ̀mí àwọn ọmọ aráyé, bóyá ó ń gòkè lọ sókè; àti ẹ̀mí ẹranko, bóyá ó ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sísàlẹ̀ ilẹ̀?” (Oníwàásù 3:19-21) Nítorí náà, àtèèyàn àtẹranko la sọ pé wọ́n ní ẹ̀mí. Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀?
A lè fi ẹ̀mí tàbí agbára ìwàláàyè wé agbára iná mànàmáná tó ń lọ tó ń bọ̀ nínú ẹ̀rọ kan tàbí ohun èèlò tó ń lo iná. Iná mànàmáná tí a kò lè rí náà ni a lè lò fún oríṣiríṣi nǹkan, ó sinmi lórí irú ohun èèlò tó ń mú ṣiṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ó lè mú kí sítóòfù mú nǹkan gbóná, ó lè mú kí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà pèsè àwọn ìsọfúnni, ó sì lè mú kí tẹlifíṣọ̀n mú àwòrán àti ohùn jáde. Síbẹ̀, agbára mànàmáná yìí kò lè wá sọ ara rẹ̀ di ohun èèlò tó ń mú ṣiṣẹ́. Agbára tó ń mú nǹkan ṣiṣẹ́ ni. Bákan náà, agbára ìwàláàyè kì í sọ ara rẹ̀ di èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀dá tó ń mú wà láàyè. Kò mọ béèyàn ṣe ń hùwà, kò sì mọ inú rò. “Ẹ̀mí kan ṣoṣo” lèèyàn àtẹranko ní. (Oníwàásù 3:19) Nítorí náà, bí ẹnì kan bá kú, ẹ̀mí rẹ̀ kì í lọ gbé níbòmíràn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí.
Ipò wo wá làwọn òkú wà? Kí ló sì máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀mí nígbà tí ẹnì kan bá kú?
‘Ìwọ Yóò Padà sí Ekuru’
Nígbà tí ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, Ádámù, mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, Ó sọ fún un pé: “Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ibo ni Ádámù wà kí Jèhófà tó dá a láti inú ekuru? Kò mà sí níbì kankan o! Àní kò fìgbà kankan wà rí. Nítorí náà, nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run sọ pé Ádámù yóò “padà sí ilẹ̀,” ohun tó ń sọ ni pé Ádámù yóò kú, yóò sì dà pọ̀ mọ́ àwọn èròjà tó wà nínú ilẹ̀. Kì í ṣe pé Ádámù yóò ré kọjá sí ilẹ̀ ẹ̀mí. Nígbà tí Ádámù bá kú yóò tún padà di ẹni tí kò sí mọ́. Ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—tí í ṣe àìsí—kì í ṣe ìpapòdà síbòmíràn.— Róòmù 6:23.
Àwọn tí wọ́n ti wá kú ńkọ́? A mú ipò táwọn òkú wà ṣe kedere nínú Oníwàásù 9:5, 10, níbi tí a ti kà pé: “Òkú kò mọ̀ nǹkan kan . . . Kò sí ìlépa ohunkóhun, kò sí ìpète, kò sí ìmọ̀ tàbí làákàyè kankan nínú ibojì.” (Moffatt) Nípa bẹ́ẹ̀, ikú jẹ́ ipò àìsí. Onísáàmù náà kọ̀wé pé nígbà tí ẹnì kan bá kú, “ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:4.
Ó hàn gbangba pé àwọn òkú kò sí níbì kankan. Wọn ò lè mọ ohunkóhun. Wọn kò lè rí ọ, wọn kò lè gbọ́ ohun tí o ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè bá ọ sọ̀rọ̀. Wọn kò lè ràn ọ́ lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè pa ọ́ lára. Dájúdájú, kò yẹ kí o máa bẹ̀rù àwọn òkú. Àmọ́ báwo lẹ̀mí èèyàn ṣe ń “jáde lọ” nígbà tẹ́nì kan bá kú?
Ẹ̀mí Náà ‘Yóò Padà Sọ́dọ̀ Ọlọ́run Tòótọ́’
Bíbélì sọ pé nígbà tí ẹnì kan bá kú, ‘ẹ̀mí yóò padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó fi í fúnni.’ (Oníwàásù 12:7) Èyí ha túmọ̀ sí pé ńṣe ni ẹ̀mí kan máa ń gba òfuurufú lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní ti gidi bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ o! Ọ̀nà tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “padà” kò túmọ̀ sí pé kí nǹkan rìn láti ibì kan lọ sí ibòmíràn ní ti gidi. Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ pé: “‘Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” (Málákì 3:7) ‘Pípadà’ tí Ísírẹ́lì yóò padà sọ́dọ̀ Jèhófà túmọ̀ sí yíyí padà kúrò nínú ipa ọ̀nà tó lòdì, kí wọ́n sì wá mú ara wọn bá ipa ọ̀nà òdodo Ọlọ́run mu. ‘Pípadà’ tí Jèhófà náà yóò padà sọ́dọ̀ Ísírẹ́lì túmọ̀ sí pípadà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àfiyèsí tí yóò ṣe wọ́n láǹfààní lẹ́ẹ̀kan sí i. Nínú àwọn ọ̀ràn méjèèjì, “padà” ní í ṣe pẹ̀lú ìwà, kì í ṣe rírìn láti àgbègbè kan lọ sí òmíràn.
Bákan náà, nígbà téèyàn bá kú, kò sí gbígbéra láti ayé lọ sí ọ̀run nígbà tí ẹ̀mí bá “padà” sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Bí agbára yẹn bá ti kúrò lára ẹnì kan, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló ní agbára láti dá a padà fún ẹni náà. Nítorí náà, ẹ̀mí “padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́” ní ti pé ọwọ́ Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ìrètí èyíkéyìí wà pé onítọ̀hún lè padà wà láàyè lọ́jọ́ ọ̀la.
Fún àpẹẹrẹ, ṣàyẹ̀wò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ikú Jésù Kristi. Òǹkọ̀wé ìhìn rere náà Lúùkù sọ pé: “Jésù sì fi ohùn rara kígbe, ó sì wí pé: ‘Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.’ Nígbà tí ó ti sọ èyí, ó gbẹ́mìí mì.” (Lúùkù 23:46) Bí ẹ̀mí Jésù ṣe fi ara rẹ̀ sílẹ̀, kì í ṣe pé ó lọ sí ọ̀run ní ti gidi. Ọjọ́ kẹta la tó jí Jésù dìde nínú ikú. Ogójì ọjọ́ gbáko ló sì lò kó tó gòkè lọ sí ọ̀run. (Ìṣe 1:3, 9) Bó ti wù kó rí, nígbà ikú rẹ̀, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé ni Jésù fi fi ẹ̀mí rẹ̀ síkàáwọ́ Bàbá rẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní kíkún pé ó ní agbára láti mú òun padà wà láàyè.
Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run lè mú kéèyàn padà wà láàyè. (Sáàmù 104:30) Àǹfààní ìrètí gígadabú mà lèyí ṣí sílẹ̀ fún wa o!
Ìrètí Tó Dájú
Bíbélì sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù] wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù Kristi ṣèlérí pé gbogbo àwọn tó wà ní ìrántí Jèhófà la óò jí dìde, tàbí mú padà wà láàyè. Àwọn tó ti tọ ipa ọ̀nà òtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà yóò wà lára wọn. Àmọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti kú láìfi hàn bóyá àwọn máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ pé wọn ò mọ ohun tí Jèhófà béèrè tàbí kó jẹ́ pé wọn ò ní àkókò tó láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ ní ṣíṣe. Irú àwọn èèyàn yìí náà wà lára àwọn tó wà ní ìrántí Ọlọ́run, a ó sì jí wọn dìde, nítorí Bíbélì sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
Lóde òní, ayé kún fún ìkórìíra àti gbọ́nmi-si omi-ò-to, ìwà ipá àti ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìbàyíkájẹ́ àti àrùn. Tó bá jẹ́ pé inú irú ayé bẹ́ẹ̀ ni a máa jí àwọn òkú dìde sí, ó dájú pé bó ti wù kínú wọn dùn tó, ayọ̀ náà kò ní tọ́jọ́. Àmọ́, Ẹlẹ́dàá ti ṣèlérí pé láìpẹ́ òun yóò mú òpin dé bá ayé ìsinsìnyí, tí ó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì Èṣù. (Òwe 2:21, 22; Dáníẹ́lì 2:44; 1 Jòhánù 5:19) Àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn olódodo—“ilẹ̀ ayé tuntun”—yóò wá wà ní ti gidi nígbà náà.—2 Pétérù 3:13.
Ní àkókò náà, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Àní ẹ̀dùn ọkàn tí ikú ń mú wá kò ní sí mọ́, nítorí Ọlọ́run “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) Àǹfààní ńlá mà lèyí jẹ́ fáwọn tó wà “nínú ibojì ìrántí” o!
Nígbà tí Jèhófà bá mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, kò ní pa àwọn olódodo run pẹ̀lú àwọn ẹni ibi. (Sáàmù 37:10, 11; 145:20) Àní sẹ́, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn èèyàn “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” yóò la “ìpọ́njú ńlá,” tó máa pa ayé búburú ìsinsìnyí run, já. (Ìṣípayá 7:9-14) Nípa bẹ́ẹ̀, ògìdìgbó ńláǹlà yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti kí àwọn òkú káàbọ̀.
Ṣé ó wù ọ́ láti rí àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́ẹ̀kan sí i? Ṣé o fẹ́ wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé? Nítorí náà, o ní láti gba ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ sínú. (Jòhánù 17:3) Ìfẹ́ Jèhófà ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:3, 4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
“Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
A lè fi ẹ̀mí wé iná mànàmáná
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àjíǹde yóò mú ayọ̀ pípẹ́ títí wá