Ǹjẹ́ O Máa Ń fi Hàn Pé O Moore?
Nílé àwọn míṣọ́nnárì kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, wọ́n ní ajá kan níbẹ̀ nígbà kan rí tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Teddy. Téèyàn bá ju ekìrí ẹran kan sí Teddy, káló ni yóò gbé e mì lójú ẹsẹ̀, kò ní fimú rùn ún wò, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní jẹ ẹ́ lẹ́nu. Nínú oòrùn ilẹ̀ olóoru tó mú hánhán nì, ṣe ni yóò máa pọ́nnu lá tókítókí, ohun tó sì ń dúró dè ni pé kí onítọ̀hún ju ekìrí ẹran mìíràn sí i. Kí ẹran náà má tí ì tán ni, ó ti pẹ̀yìn dà bírí, ó ń bá tirẹ̀ lọ nìyẹn.
Teddy kò fi ìmoore eléépìnnì hàn fún ohun táa ṣe fún un rí. Kò kúkú sẹ́ni tó retí kó fi ìmoore hàn tẹ́lẹ̀. Ọ́ ṣe tán, ajá lásánlàsàn ni.
TÓ BÁ jẹ́ ti ìmoore, a sábà máa ń retí rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa ju báa ti ń retí rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ẹranko lọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni àwọn èèyàn máa ń já wa kulẹ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló jẹ́ pé láìka ohun tí wọ́n ti rí kó jọ nínú ayé sí, múwámúwá náà lapá ẹyẹlé wọn ń wí. Èyí pẹ̀lú kò yani lẹ́nu. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn yóò ya aláìlọ́pẹ́.—2 Tímótì 3:1, 2.
Ṣùgbọ́n o, ẹ̀mí tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní yàtọ̀ pátápátá. Wọ́n fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, ẹni tó gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ sì fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.”—Kólósè 3:15.
Jèhófà Ń Fi Ara Rẹ̀ Hàn Ní Ẹni Tó Moore
Jèhófà Ọlọ́run fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ nínú fífi ìmoore hàn. Ronú ná nípa ojú tó fi ń wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Lábẹ́ ìmísí, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.”—Hébérù 6:10.
Àpẹẹrẹ ìmọrírì tí Jèhófà fi hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lọ jàra. Ó bù kún Ábúráhámù nípa sísọ ọmọ rẹ̀ di púpọ̀, kí wọ́n bàa lè dà bí “àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:17) Nígbà tí Jèhófà ń fi ìmoore hàn fún ìṣòtítọ́ Jóòbù lábẹ́ àdánwò, kì í ṣe pé ó dá ọrọ̀ ńlá tí Jóòbù ní tẹ́lẹ̀ padà fún un nìkan ni, àmọ́ ó tún fún un ní “ìlọ́po méjì.” (Jóòbù 42:10) Ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà bá àwọn ènìyàn lò láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn fi hàn pé òótọ́ ní ọ̀rọ̀ náà pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 Kíróníkà 16:9.
Apá kan àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ni pé ó ń fi ìmoore hàn fún àwọn tí wọ́n bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó sì ń fẹ́ san ẹ̀san fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Mímọ èyí ṣe pàtàkì nínú ìgbàgbọ́ Kristẹni. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé . . . òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.
Dípò èyí, ká ní Jèhófà ń fi ẹ̀mí òǹrorò, ẹ̀mí àríwísí bá wa lò ni, kò sẹ́ni tí ì bá ríbi yàn sí lọ́dọ̀ rẹ̀. Onísáàmù náà mú kí kókó ọ̀rọ̀ yìí ṣe kedere nígbà pípẹ́ sẹ́yìn, nígbà tó wí pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sáàmù 130:3) Jèhófà kì í ṣe aláìmoore, kì í sì í ṣe alárìíwísí. Ó ń ṣìkẹ́ àwọn tó bá ń sìn ín. Ó ń fara rẹ̀ hàn ní ẹni tó moore.
Jésù—Ẹ̀dá Kan Tó Ń Fi Ìmọrírì Jíjinlẹ̀ Hàn
Láti lè fi àwọn ànímọ́ Baba rẹ̀ ọ̀run hàn lọ́nà pípé, Jésù Kristi fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó mọrírì àwọn nǹkan tí àwọn ẹlòmíràn fi ìgbàgbọ́ ṣe. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù pé: “Wàyí o, bí [Jésù] ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ tí wọ́n ń sọ ẹ̀bùn wọn sínú àwọn àpótí ìṣúra. Nígbà náà ni ó rí opó aláìní kan tí ó sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an síbẹ̀, ó sì wí pé: ‘Lótìítọ́ ni mo sọ fún yín, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé opó yìí jẹ́ òtòṣì, ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ. Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí sọ ẹ̀bùn sílẹ̀ láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n obìnrin yìí láti inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní sínú rẹ̀.’”—Lúùkù 21:1-4.
Táa bá ronú nípa owó, ọrẹ yìí kò tó nǹkan, pàápàá báa bá fi wé ohun tí àwọn ọlọ́rọ̀ fi sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà ni kò ní kíyè sí obìnrin yẹn. Síbẹ̀, Jésù rí opó náà. Ó lóye ipò tó wà. Jésù rí obìnrin náà, ìwà rẹ̀ sì jọ ọ́ lójú gidigidi.
Ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn jẹ́ ti obìnrin kan tó rí towó ṣe, Màríà lorúkọ rẹ̀. Ìdí oúnjẹ ni Jésù rọ̀gbọ̀kú sí, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin yìí dé, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí da òróró olówó ńlá sí Jésù lẹ́sẹ̀, tó tún dà á sí i lórí. Ní àwọn kan bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàròyé nítorí ohun tí obìnrin yìí ṣe, èrò tiwọn ni pé, ì bá ti jẹ́ káwọn lọ ta òróró náà, kí wọ́n sì fi owó rẹ̀ ran àwọn òtòṣì lọ́wọ́. Báwo ni Jésù ṣe fèsì? Ó wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́. Èé ṣe tí ẹ fi ń gbìyànjú láti dà á láàmú? Ó ṣe iṣẹ́ tí ó dára púpọ̀ sí mi. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ibikíbi tí a bá ti wàásù ìhìn rere ní gbogbo ayé, ohun tí obìnrin yìí ṣe ni a ó sọ pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”—Máàkù 14:3-6, 9; Jòhánù 12:3.
Jésù kò kanjú ko, kò sì wá máa ṣàríwísí pé wọn kò lo òróró iyebíye yẹn lọ́nà mìíràn. Ó mọrírì ìwà ọ̀làwọ́ àti ìfẹ́ tí Màríà fi hàn. Àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ náà wà nínú Bíbélì kí a lè máa rántí ìwà rere obìnrin yìí. Àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí àti àwọn mìíràn fi hàn pé ẹ̀dá tó ń fi ìmọrírì jínjinlẹ̀ hàn ni Jésù jẹ́.
Bí o bá jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, mọ̀ dájú pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún ìsapá rẹ láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ń mú kí a túbọ̀ sún mọ́ wọn, ó sì ń sún wa láti fara wé wọn nípa fífihàn pé a moore.
Ẹ̀mí Àríwísí Lèṣù Ní
Wàyí o, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àpẹẹrẹ ẹnì kan tí kò moore rárá—Sátánì Èṣù. Torí pé Sátánì kò moore ló fà á tó fi ṣagbátẹrù ṣíṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, èyí tó yọrí sí jàǹbá.
Lẹ́yìn tó ti mú ẹ̀mí àríwísí, ẹ̀mí àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, dàgbà nínú ara rẹ̀, Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí gbìn ín sínú àwọn ẹlòmíràn. Ronú nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Jèhófà ti dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó ti fi wọ́n sínú ọgbà párádísè, ó sì sọ fún wọn pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn.” Àmọ́ ṣá o, ó fún wọn lófin kan. Ọlọ́run wí pé: “Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17.
Àmọ́ ṣá o, láìpẹ́, Sátánì sọ pé Jèhófà kò ṣeé gbára lé. Títí dé àyè kan, ó fẹ́ sọ Éfà di ẹni tí kò fi ìmoore hàn sí Jèhófà, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi sún obìnrin yìí láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bí Sátánì fúnra rẹ̀ ti ṣọ̀tẹ̀ sí i. Sátánì béèrè pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” (Jẹ́nẹ́sísì 3:1) Ohun tó ṣe kedere pé Èṣù ń sọ ni pé, Ọlọ́run ń fawọ́ ire ńláǹlà kan sẹ́yìn fún Éfà, ohun kan tó lè jẹ́ kí ojú rẹ̀ là, kí ó sì mú kí ó dà bí Ọlọ́run alára. Dípò tí yóò fi fi hàn pé òun moore ọ̀pọ̀ ìbùkún tí Jèhófà ti rọ̀jò rẹ̀ sórí òun, ọkàn Éfà bẹ̀rẹ̀ sí fà sí ohun táa ti kà léèwọ̀ fún un.—Jẹ́nẹ́sísì 3:5, 6.
Gbogbo wa la mọ jàǹbá tó yọrí sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a fún un lórúkọ náà Éfà “nítorí pé òun ni yóò di ìyá gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè,” lọ́nà mìíràn, òun náà ló di ìyá gbogbo ẹni tí ń kú. Láti ọ̀dọ̀ Ádámù ni gbogbo ẹ̀dá ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó yọrí sí ikú.—Jẹ́nẹ́sísì 3:20; Róòmù 5:12.
Fara Wé Ọlọ́run àti Kristi
Ronú lórí ìyàtọ̀ tó wà láàárín Sátánì àti Jésù. A ṣàpèjúwe Sátánì gẹ́gẹ́ bí “olùfisùn àwọn arákùnrin wa . . . , ẹni tí ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sántòru níwájú Ọlọ́run wa.” (Ìṣípayá 12:10) Jésù “lè gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.”—Hébérù 7:25.
Sátánì máa ń fi àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run sùn ni ní tirẹ̀. Àmọ́ Jésù kà wọ́n sí èèyàn pàtàkì, ó sì ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn. Gégẹ́ bí aláfarawé Kristi, àwọn Kristẹni ní láti sapá láti máa rí ànímọ́ rere tí ọmọnìkejì wọn ní, kí wọ́n máa kà wọ́n sí, kí wọ́n sì máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀. Bí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi hàn pé àwọn ń fi ìmoore hàn sí ẹni náà tó fi àpẹẹrẹ gíga jù lọ hàn ní ti ìmoore, ìyẹn ni Jèhófà Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 11:1.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jésù fi ìmọrírì hàn fún iṣẹ́ rere Màríà