Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
NÍ NǸKAN bí ẹgbàata ọdún sẹ́yìn, a bí ọmọ ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́. Lẹ́yìn ìbí rẹ̀, ìyá rẹ̀, Éfà, sọ pé: “Mo rí ọkùnrin kan gbà lọ́wọ́ OLÚWA.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:1) Gbólóhùn rẹ̀ fi hàn pé, bí a tilẹ̀ ti dá wọn lẹ́bi ikú nítorí ìṣọ̀tẹ̀ wọn, Éfà àti ọkọ rẹ̀, Ádámù, ṣì lóye jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run. Lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n bí ọmọkùnrin kejì. A sọ àwọn ọmọdékùnrin náà ní Kéènì àti Ébẹ́lì.
Bí àwọn ọmọkùnrin náà ti ń dàgbà, ní kedere, wọ́n kọ́ púpọ̀ nípa ìfẹ́ Jèhófà nípa wíwulẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀. Wọ́n gbádùn àwọn àwọ̀ rírẹwà ti ìṣẹ̀dá àti onírúurú àwọn ẹranko àti ewéko. Kì í ṣe kìkì pé Ọlọ́run fún wọn ní ìwàláàyè nìkan ni, ṣùgbọ́n, ó tún fún wọn ní agbára láti rí ìgbádùn nínú ìgbésí ayé.
Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé a dá àwọn òbí wọn ní pípé àti pé ète Jèhófà ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni pé kí ẹ̀dá ènìyàn wà láàyè títí láé. Ó ṣeé ṣe pé Ádámù àti Éfà ṣàpèjúwe ọgbà ẹlẹ́wà Édẹ́nì fún wọn, wọ́n sì ti ní láti ṣàlàyé bákan ṣáá, ìdí tí a fi lé wọn jáde kúrò nínú ilé párádísè kan bẹ́ẹ̀. Kéènì àti Ébẹ́lì pẹ̀lú ti lè mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ àtọ̀runwá tí a kọ sílẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Nípasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, Jèhófà sọ ète rẹ̀ jáde láti mú ọ̀ràn tọ́ ní àkókò yíyẹ fún àǹfààní àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i.
Kíkọ́ nípa Jèhófà àti àwọn ànímọ́ rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ mú kí Kéènì àti Ébẹ́lì ní ìfẹ́ ọkàn fún ojú rere Ọlọ́run. Nítorí náà, wọ́n tọ Jèhófà lọ nípa rírúbọ sí i. Ìròyìn Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣe, ní òpin ọjọ́ wọnnì tí Kéènì mu ọrẹ nínú èso ilẹ̀ fún OLÚWA wá. Àti Ébẹ́lì, òun pẹ̀lú mú nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn àní nínú àwọn tí ó sanra.”—Jẹ́nẹ́sísì 4:3, 4.
Ìfẹ́ ọkàn wọn fún ojú rere Ọlọ́run fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ipò ìbátan pẹ̀lú rẹ̀. Kéènì parí rẹ̀ sí ṣíṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, nígbà tí ojúlówó ìfẹ́ fún Ọlọ́run sì ń bá a nìṣó láti máa sún Ébẹ́lì ṣiṣẹ́. Ébẹ́lì kì bá tí mú irú ipò ìbátan bẹ́ẹ̀ dàgbà pẹ̀lú Ọlọ́run láé, bí kì í báá ṣe pé ó kọ́kọ́ gba ìmọ̀ nípa àwọn àkópọ̀ ìwà Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀.
Ìwọ pẹ̀lú lè mọ Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì, o lè kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi, kì í ṣe agbára aláìlẹ́mìí kan lásán tí ó ṣẹ̀dá àwọn nǹkan nípasẹ̀ èèṣì. (Fi wé Jòhánù 7:28; Hébérù 9:24; Ìṣípayá 4:11.) Bíbélì tún kọ́ni pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, onípamọ́ra, àti ẹni tí ó pọ̀ ní oore àti òtítọ́.”—Ẹ́kísódù 34:6.
“Ìgbọràn Sàn Ju Ẹbọ Lọ”
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkàwé nípasẹ̀ ìròyìn Kéènì àti Ébẹ́lì, níní ìmọ̀ Ọlọ́run àti ìfẹ́ ọkàn fún ipò ìbátan pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú rẹ̀ kò tó. Ní tòótọ́, àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò méjèèjì náà mú ẹbọ tọ Ọlọ́run lọ. Ṣùgbọ́n, “OLÚWA sì fi ojú rere wo Ébẹ́lì àti ọrẹ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Kéènì àti ọrẹ rẹ̀ ni kò náání. Kéènì sì bínú gidigidi, ojú rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì.”—Jẹ́nẹ́sísì 4:3-5.
Èé ṣe tí Jèhófà fi kọ ẹbọ Kéènì? Ohun kan ha ṣàìtọ́ pẹ̀lú ìjójúlówó ọrẹ rẹ̀ bí? Inú ha bí Jèhófà nítorí pé Kéènì fi “èso ilẹ̀” rúbọ dípò ẹbọ ẹran bí? Ó lè ṣàìjẹ́ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ọlọ́run fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ọrẹ ọkà àti àwọn èso ilẹ̀ míràn láti ọwọ́ ọ̀pọ̀ olùjọsìn rẹ̀. (Léfítíkù 2:1-16) Dájúdájú, nígbà náà, ohun kan ṣàìtọ́ nínú ọkàn-àya Kéènì. Jèhófà lè mọ ọkàn-àya Kéènì, ó sì kìlọ̀ fún un pé: “Èé ṣe tí inú fi ń bí ọ? èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì? Bí ìwọ́ bá ṣe rere, ara kì yóò ha yá ọ? Bí ìwọ kò bá sì ṣe rere, ẹ̀ṣẹ́ ba ní ẹnu ọ̀nà, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí.”—Jẹ́nẹ́sísì 4:6, 7.
Ojúlówó ìfẹ́ fún Ọlọ́run ju wíwulẹ̀ ṣèrúbọ lásán lọ. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi fún Kéènì níṣìírí láti ‘yí padà sí ṣíṣe rere.’ Ọlọ́run fẹ́ ìgbọràn. Irú ìgbọràn bẹ́ẹ̀ sí Ọlọ́run ì bá ti ran Kéènì lọ́wọ́ láti fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún ipò ìbátan onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá. Bíbélì tẹnu mọ́ ìníyelórí ìgbọràn pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Olúwa ha ní inú dídùn sí ọrẹ sísun àti ẹbọ bíi pé kí a gba ohùn Olúwa gbọ́? Kíyè sí i, ìgbọràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.”—Sámúẹ́lì Kìíní 15:22.
Èròǹgbà yìí ni a tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ dáradára pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ inú Jòhánù Kìíní 5:3 pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í sì í ṣe ẹrù ìnira.” Kò sí ọ̀nà tí ó sàn jù láti fi ìfẹ́ wa hàn fún Jèhófà ju nípa fífi ara wa sábẹ́ ọlá àṣẹ rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí ìgbọràn sí àwọn ìlànà ìwà híhù ti Bíbélì. (Kọ́ríńtì Kìíní 6:9, 10) Ó túmọ̀ sí nínífẹ̀ẹ́ ohun rere àti kíkórìíra ohun búburú.—Sáàmù 97:10; 101:3; Òwe 8:13.
Ọ̀kan pàtàkì lára ìfihàn ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run ni ìfẹ́ wa fún aládùúgbò. Bíbélì sọ fún wa pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,’ síbẹ̀ tí ó sì ń kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni. Nítorí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òún rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí òun kò rí.”—Jòhánù Kìíní 4:20.
Ìbárẹ́ Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run Ṣeé Ṣe
Àwọn kan lè sọ pé, ‘Mo ń jọ́sìn Jèhófà. Mo ń ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀. Mo ń bá ọmọnìkejì mi lò láìṣojúsàájú. Mo ń ṣe gbogbo ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀, n kò nímọ̀lára pé mo sún mọ́ Ọlọ́run ní ti gidi. N kò nímọ̀lára ìfẹ́ lílágbára fún un, ìyẹn sì ń mú mi nímọ̀lára ẹ̀bi.’ Àwọn kan lè ronú pé wọn kò yẹ láti ní irú ipò ìbátan tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà.
Lẹ́yìn ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún 37 nínú iṣẹ́ ìsìn oníyàsímímọ́ sí Jèhófà, Kristian kan kọ̀wé pé: “Ní ọ̀pọ̀ ìgbà nínú ìgbésí ayé mi, mo ti nímọ̀lára pé iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà jẹ́ afaraṣe máfọkànṣe. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà ni ohun tí ó tọ̀nà láti ṣe, n kò sì ní fàyè gba ara mi láti dáwọ́ dúró. Ṣùgbọ́n, nígbà gbogbo tí mo bá kà nípa ẹnì kan tí ó sọ pé ‘ọkàn-àyà òun kún fún ìfẹ́ fún Jèhófà,’ mo máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ní ń ṣe mí, níwọ̀n bí n kò ti nímọ̀lára lọ́nà yẹn rí?’” Báwo ni a ṣe lè ní ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run?
Nígbà tí o bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan ní tòótọ́, ìwọ yóò sábà máa ronú nípa ẹni yẹn. O ní ìfẹ́ ọkàn lílágbára láti sún mọ́ ọn nítorí pé o bìkítà fún un. Bí o bá ti ń rí i tó, tí o ń sọ̀rọ̀ sí i tó, tí o sì ń ronú nípa rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ fún un yóò ṣe máa pọ̀ sí i tó. Ìlànà yìí kan bí o ṣe ń mú ìfẹ́ rẹ fún Ọlọ́run dàgbà pẹ̀lú.
Nínú Sáàmù 77:12, òǹkọ̀wé tí a mí sí náà sọ pé: “Èmi óò má ṣe àṣàrò gbogbo iṣẹ́ rẹ pẹ̀lú, èmi óò sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.” Ṣíṣàṣàrò ṣe kókó nínú mímú ìfẹ́ fún Ọlọ́run dàgbà. Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì lójú ìwòye òtítọ́ náà pé a kò lè fojú rí i. Ṣùgbọ́n bí o bá ṣe ń ronú nípa rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò túbọ̀ máa jẹ́ ẹni gidi sí ọ tó. Kìkì ìgbà náà ni o tó lè mú ipò ìbátan àtọkànwá àti onífẹ̀ẹ́ni pẹ̀lú rẹ̀ dàgbà—nítorí pé ó jẹ́ ẹni gidi sí ọ.
Ìtẹ̀sí rẹ láti ṣàṣàrò lóòrèkóòrè lórí àwọn ọ̀nà àti ìbálò Jèhófà yóò sinmi lórí bí o bá ti ń fetí sí i tó. O ń fetí sílẹ̀ nípasẹ̀ kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé. Onísáàmù sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin aláyọ̀ pé ó jẹ́ ẹni tí “dídùn inú rẹ̀ wà ní òfin Olúwa; àti nínú rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti ní òru.”—Sáàmù 1:1, 2.
Kókó pàtàkì míràn ni àdúrà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú léraléra láti máa gbàdúrà—“ní gbogbo ìgbà,” ‘máa ya àkókò sọ́tọ̀ fún àdúrà,’ “máa ní ìforítì nínú àdúrà,” kí a sì “máa gbàdúrà láìdabọ̀.” (Éfésù 6:18; Kọ́ríńtì Kìíní 7:5; Róòmù 12:12; Tẹsalóníkà Kìíní 5:17) Àdúrà wa sí Jèhófà láìdabọ̀ yóò mú kí a ṣeyebíye fún un, ìdánilójú pé ó ń fetí sílẹ̀ yóò sì fà wá sún mọ́ ọn. Onísáàmù jẹ́rìí sí èyí nígbà tí ó polongo pé: “Èmí fẹ́ Olúwa nítorí tí ó gbọ́ ohùn mi àti ẹ̀bẹ̀ mi. Nítorí tí ó dẹ etí rẹ̀ sí mi, nítorí náà ni èmi óò máa ké pè é níwọ̀n ọjọ́ mi.”—Sáàmù 116:1, 2.
Fífara Wé Ọlọ́run Ìfẹ́
Jèhófà jẹ́ ẹni rere sí wa. Bí òún ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá àgbáyé, òun dájúdájú ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti fi sọ́kàn, kí ó sì bójú tó wọn. Síbẹ̀, Bíbélì sọ fún wa pé bí ó ti tóbi lọ́lá tó, síbẹ̀ ó ń bìkítà fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Pétérù Kìíní 5:6, 7) Onísáàmù jẹ́rìí sí èyí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “OLÚWA, Olúwa wa, orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé! ìwọ tí ó gbé ògo rẹ ka orí àwọn ọ̀run. Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ̀, iṣẹ́ ìka rẹ̀, òṣùpá àti ìràwọ̀, tí ìwọ́ ti ṣe ìlànà sílẹ̀. Kí ni ènìyàn, tí ìwọ́ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀? àti ọmọ ènìyàn, tí ìwọ́ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò.”—Sáàmù 8:1,3, 4.
Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣe ìrántí ènìyàn kíkú? Bíbélì dáhùn pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ naa jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òún nífẹ̀ẹ́ wa ó sì rán Ọmọkùnrin rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—Jòhánù Kìíní 4:9, 10.
Báwo ni ẹbọ ìpẹ̀tù yìí ṣe jẹ́ ẹ̀rí títóbi jù lọ ti ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa? Jẹ́ kí á ṣàyẹ̀wò ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Ádámù àti Éfà dojú kọ ìpinnu náà yálà láti fi ara wọn sábẹ́ òfin Jèhófà pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún ìwàláàyè pípé títí láé, tàbí láti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà pẹ̀lú ikú gẹ́gẹ́ bí àbáyọrí rẹ̀. Wọ́n yàn láti ṣọ̀tẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n dá gbogbo aráyé lẹ́bi ikú pẹ̀lú. (Róòmù 5:12) Wọ́n fi ìkùgbùù já àǹfààní láti pinnu fúnra wa gbà mọ́ wa lọ́wọ́. A kò ní àǹfààní láti ṣe ìpinnu fúnra wa nínú ọ̀ràn náà.
Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà ti fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣèrántí ènìyàn kíkú, ní mímọ ipò ìṣòro rẹ̀. Nípasẹ̀ ikú ìrúbọ Ọmọkùnrin Rẹ̀, Jésù Kristi, Jèhófà ti pèsè ìpìlẹ̀ bíbófin mu fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti yàn fúnra rẹ̀, ìyè tàbí ikú, ìgbọràn tàbí ìṣọ̀tẹ̀. (Jòhánù 3:16) Ń ṣe ni ó dà bíi pé Jèhófà gbọ̀ràn wa rò nílé ẹjọ́—ká sọ ọ́ lédè ìṣàpẹẹrẹ, àǹfààní kan láti padà sí Édẹ́nì, kí a sì ṣe ìpinnu tiwa fúnra wa. Èyí jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ títóbi jù lọ tí a tí ì ṣe rí.
Finú wòye ìrora tí Jèhófà fara dà bí ó ti rí i tí a fìwọ̀sí lọ àkọ́bí rẹ̀, tí a dá a lóró, tí a sì kàn án mọ́gi bí ọ̀daràn. Ọlọ́run sì fara da ìyẹn nítorí wa. Mímọ̀ tí a mọ̀ bí Jèhófà ti lo àtinúdá ní kíkọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa, bákan náà yẹ kí ó sún wa láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí ó sì gún wa ní kẹ́ṣẹ́ láti wá a kiri. (Jákọ́bù 1:17; Jòhánù Kìíní 4:19) Bíbélì ké sí wa láti, “máa wá Olúwa àti ipá rẹ̀: ẹ máa wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ máa rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ tí ó ti ṣe; iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti ìdájọ́ ẹnu rẹ̀.”—Sáàmù 105:4, 5.
Láti ní ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí ti ara ẹni àti ipò ìbátan onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, láti jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe. Ó ṣeé ṣe. Láìsí àníàní, a kò lè fi ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run wéra pátápátá pẹ̀lú ipò ìbátan láàárín ẹ̀dá ènìyàn. Ìfẹ́ tí a ń ní sí alábàáṣègbéyàwó ẹni, òbí, alájọbí, ọmọ, tàbí àwọn ọ̀rẹ́, yàtọ̀ sí ìfẹ́ tí a ní fún Ọlọ́run. (Mátíù 10:37; 19:29) Nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà kan ìfọkànsìn, ìjọsìn, àti ìyàsímímọ́ pátápátá wa sí i. (Diutarónómì 4:24) Kò sí ipò ìbátan mìíràn tí ó ní irú ipa ìdarí bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, a lè mú èrò ìmọ̀lára mímúná, tí ó sì jinlẹ̀ fún Ọlọ́run dàgbà ní ọ̀nà onítẹríba, pẹ̀lú ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.—Sáàmù 89:7.
Bí o tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, bíi ti Kéènì àti Ébẹ́lì, o ní agbára fún nínífẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ. Kéènì ṣe yíyàn tirẹ̀, ó dara pọ̀ mọ́ Sátánì, ó sì di ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, tí ó jẹ́ apànìyàn. (Jòhánù Kìíní 3:12) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Jèhófà yóò rántí Ébẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ìgbàgbọ́ àti olódodo, a óò sì san èrè ẹ̀san ìyè fún un nínú Párádísè tí ń bọ̀.—Hébérù 11:4.
Ìwọ pẹ̀lú ní yíyàn kan. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, o lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní tòótọ́ ‘pẹ̀lú gbogbo aya rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ.’ (Diutarónómì 6:5) Lẹ́yìn náà, Jèhófà yóò máa bá a nìṣó láti nífẹ̀ẹ́ rẹ, nítorí òun ni “olùsẹ̀san fún àwọn wọnnì tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì