Ojú Ìwòye Bíbélì
Kí Ló Yẹ Kó Jẹ́ Àfojúsùn Àwọn Òbí?
IRÚ èèyàn wo lo fẹ́ kí ọmọ rẹ tó ti bàlágà jẹ́?
A. Irú èèyàn tí ìwọ fúnra rẹ jẹ́.
B. Ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tó jẹ́ òdìkejì irú èèyàn tí ìwọ jẹ́.
D. Àgbàlagbà tó dáńgájíá, tó sì ń ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.
Àwọn òbí tó mú “D” lè máa ṣe bíi pé “A” ni àwọn fẹ́. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ lè fẹ́ fipá mú kí àwọn ọmọ wọn tó ti bàlágà gba ohun tí àwọn fẹ́, irú bíi kí wọ́n máa sọ irú iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ kí ọmọ wọn ṣe fún un. Kí ló máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ní gbàrà tí ọmọ náà bá ti ní òmìnira díẹ̀, òdìkejì ohun tí wọ́n fẹ́ ní yóò máa ṣe. Àmọ́, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé ọ̀pọ̀ òbí tí wọ́n fẹ́ kí ọmọ wọn dà bí àwọn fúnra wọn ló sábà máa ń jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tó jẹ́ òdìkejì irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ ni ọmọ náà máa ń yà.
Ìdí Tí Àwọn Òbí Tó Fẹ́ Máa Darí Gbogbo Ohun Tí Ọmọ Ń Ṣe Kò Fi Lè Ṣàṣeyọrí
O fẹ́ kí ọmọ rẹ tó ti bàlágà di àgbàlagbà tó mọ iṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, tó sì máa ń ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ báwo ni ọwọ́ rẹ ṣe lè tẹ àfojúsùn yìí? Ohun kan dájú: Dídarí gbogbo ohun tí ọmọ ń ṣe kọ́ ló máa jẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ àfojúsùn yìí. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìdí méjì.
1. Ìwé Mímọ́ kò fọwọ́ sí i pé kí òbí máa darí gbogbo ohun tí ọmọ ń ṣe. Jèhófà Ọlọ́run dá àwa èèyàn láti yan ohun tá a bá fẹ́ fúnra wa. Ó gba àwọn èèyàn láyè láti yan ipa ọ̀nà tí wọ́n á tọ̀ nígbèésí ayé wọn, bóyá rere tàbí búburú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Kéènì ń gbèrò láti pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀, Jèhófà sọ fún un pé: “Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ; ní tìrẹ, ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?”—Jẹ́nẹ́sísì 4:7.
Ṣàkíyèsí pé nígbà tí Jèhófà fún Kéènì ní ìkìlọ̀ tó ṣe kedere yẹn, kò fipá mú un láti tẹ̀ lé e. Kéènì fúnra rẹ̀ ló máa pinnu bóyá kí òun kápá ìbínú òun tàbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ wa? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà kì í fipá mú àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ láti máa ṣègbọràn sí i, ìwọ náà kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n ti bàlágà.a
2. Dídarí gbogbo ohun tí ọmọ ń ṣe kì í yọrí sí rere. Ká sọ pé ọlọ́jà kan fẹ́ kó o rajà lọ́wọ́ òun lọ́ranyàn. Bó bá ṣe ń gbìyànjú láti tá ọjà náà lọ́ranyàn, bẹ́ẹ̀ náà ni wàá ṣe máa kọ̀ jálẹ̀. Ká tiẹ̀ sọ pé o nílò nǹkan náà, ìwà ẹni yẹn lè mú kó o má ra ọjà náà. Ńṣe ni wàá kúrò níwájú rẹ̀.
Ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ tó o bá fẹ́ fipá mú ọmọ rẹ láti gba ohun tó o nífẹ̀ẹ́ sí, ohun tó o gbà gbọ́ àtàwọn àfojúsùn rẹ. Ṣé ó máa gbà wọ́n? Kò dájú! Kódà, ó lè jẹ́ pé òdìkejì ohun tó o fẹ́ ló máa yọrí sí, ọmọ rẹ lè wá kórìíra àwọn ìlànà tó o fẹ́ kó máa tẹ̀ lé. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé bí òbí bá fẹ́ máa darí gbogbo ohun tí ọmọ ńṣe, kì í sí àṣeyọrí kankan. Kí lo wá lè ṣe nígbà náà?
Dípò tí wàá fi máa darí ìgbésí ayé ọmọ rẹ tó ti bàlágà, tí wàá máa fẹ́ kó ṣe gbogbo ohun tó o bá fẹ́, bó o ṣe máa ń ṣe nígbà tó ṣì kéré, ńṣe ni kó o ràn án lọ́wọ́ kó lè rí ọgbọ́n tó wà nínú ṣíṣe ohun tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé Kristẹni ni ẹ́, jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé tó bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run nígbèésí ayé rẹ̀, ó máa ní ìfọ̀kànbalẹ̀ jálẹ̀ ọjọ́ ayé rẹ̀.—Aísáyà 48:17, 18.
Bó o ṣe ń ṣe èyí, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Irú ẹni tó o fẹ́ kí ọmọ rẹ jẹ́ ni kí ìwọ fúnra rẹ jẹ́. (1 Kọ́ríńtì 11:1) Jẹ́ kí àwọn ìlànà tí ìwọ fúnra rẹ ń tẹ̀ lé ṣe kedere sí ọmọ rẹ. (Òwe 4:11) Bí ọmọ rẹ tó ti bàlágà fúnra rẹ̀ bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ìlànà rẹ̀, ó máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, kódà nígbà tí ìwọ òbí rẹ̀ kò bá sí níbẹ̀.—Sáàmù 119:97; Fílípì 2:12.
Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Àwọn Ohun Tó Wúlò
Bá a ṣe sọ ní ojú ìwé 2 nínú ìwé ìròyìn yìí, ọjọ́ náà máa wọlé wẹ́rẹ́ tí ọmọ rẹ tó ti dàgbà máa fi “baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀,” ó sì ṣeé ṣe kí àkókò náà yá ju bó o ṣe rò lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Gẹ́gẹ́ bí òbí, ó yẹ kó o rí i dájú pé o kọ́ ọmọ rẹ ní àwọn ohun tó máa nílò kó lè di àgbàlagbà tó máa lè dá dúró láyè ara rẹ̀. Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan díẹ̀ tó o lè kọ́ ọmọ rẹ ní báyìí tó ṣì wà nílé.
Àwọn Iṣẹ́ Ilé. Ǹjẹ́ ọmọ rẹ tó ti bàlágà lè gbọ́ oúnjẹ? Ṣé ó lè fọ aṣọ kó sì lọ̀ ọ́? Ṣé ó lè tún yàrá rẹ̀ ṣe kó wà ní mímọ́ kó sì wà létòlétò? Ṣé ó lè ṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lára ọkọ̀? Bí ọmọ rẹ bá ti mọ àwọn nǹkan yìí ṣe, ó máa jẹ́ kí òun náà lè bójú tó ilé ara rẹ̀ nígbà tó bá yá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́, nínú àwọn ipò yòówù tí mo bá wà, láti máa ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi.”—Fílípì 4:11.
Àjọṣe Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn. (Jákọ́bù 3:17) Báwo ni àjọṣe ọmọ rẹ tó ti bàlágà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì ṣe rí? Ǹjẹ́ ó lè yanjú èdèkòyédè ní ìtùnbí-ìnùbí? Ǹjẹ́ o ti fún un ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí bá a ṣe máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn tá a sì máa yanjú aáwọ̀ tí àlàáfíà á sì jọba. (Éfésù 4:29, 31, 32) Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn.”—1 Pétérù 2:17.
Ṣíṣọ́ Owó Ná. (Lúùkù 14:28) Ǹjẹ́ o lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti kọ́ iṣẹ́ kan, kó máa ṣọ́wó ná, kó má sì máa jẹ gbèsè? Ǹjẹ́ o ti kọ́ ọ láti máa tọ́jú owó fún àwọn nǹkan tó bá fẹ́ rà, kó má ṣe máa ra gbogbo nǹkan tó bá ṣáà ti rí, kó sì ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun kòṣeémánìí? (Òwe 22:7) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:8.
Bí ọmọ tó ti bàlágà bá kẹ́kọ̀ọ́ láti gbé ìgbé ayé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà tó tọ́, tó sì kọ́ àwọn ohun tó máa wúlò fún un, ńṣe ni èyí ń fi hàn pé ó ti ṣe tán láti bọ́ sípò àgbà. Ọwọ́ àwọn òbí wọn sì ti tẹ àfojúsùn wọn nìyẹn!—Òwe 23:24.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo Ilé Ìṣọ́ February 1, 2011, ojú ìwé 18 sí 19.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí ni àfojúsùn rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí?—Hébérù 5:14.
● Kí ló máa jẹ́ ojúṣe ọmọ rẹ tó ti bàlágà nígbà tó bá di àgbàlagbà? —Jóṣúà 24:15.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Irú èèyàn wo lo fẹ́ kí ọmọ rẹ tó ti bàlágà jẹ́?
Irú èèyàn tó o jẹ́ . . .
Ọlọ̀tẹ̀ ọmọ . . .
Àgbàlagbà tó dáńgájíá