Orí 17
‘Àwọn Ọkàn Tí A Pa’ Gba Èrè
1. Àkókò wo là ń gbé yìí, báwo la sì ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
ÌJỌBA Ọlọ́run ń ṣàkóso! Agẹṣin funfun náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣẹ́gun tán pátápátá! Ẹṣin pupa, ẹṣin dúdú, àti ẹṣin ràndánràndán ń sáré kútúpà kútúpà jákèjádò ilẹ̀ ayé! Ó dájú hán-ún hán-ún pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ti ń ní ìmúṣẹ. (Mátíù, orí 24, 25; Máàkù, orí 13; Lúùkù, orí 21) Bẹ́ẹ̀ ni, a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan yìí. (2 Tímótì 3:1-5) Nítorí èyí, ẹ jẹ́ ká darí gbogbo àfiyèsí wa sí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi, bó ṣe ń ṣí èdìdì karùn-ún lára àkájọ ìwé yẹn. Kí ló tún kàn tó fẹ́ ṣí payá fún wa báyìí o?
2. (a) Kí ni Jòhánù rí nígbà tí Jésù ṣí èdìdì karùn-ún? (b) Kí nìdí tí ò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu pé pẹpẹ ìrúbọ ìṣàpẹẹrẹ wà lọ́run?
2 Jòhánù ṣàpèjúwe ìran kan tó gbani láfiyèsí, ó sọ pé: “Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a fikú pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nítorí iṣẹ́ ìjẹ́rìí tí wọ́n ti máa ń ṣe.” (Ìṣípayá 6:9) Kí nìyẹn ná? Pẹpẹ ìrúbọ lókè ọ̀run kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni! Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Jòhánù mẹ́nu kan pẹpẹ. Àmọ́, ṣáájú ìsinsìnyí, ó ti ṣàpèjúwe Jèhófà lórí ìtẹ́ Rẹ̀, àwọn kérúbù tí wọ́n yí i ká, òkun tó dà bíi gíláàsì, àwọn fìtílà àti alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] tí wọ́n gbé tùràrí lọ́wọ́, ṣe ni ìran náà rí bí àgọ́ ìjọsìn ti orí ilẹ̀ ayé, ìyẹn ibùjọsìn Jèhófà ní Ísírẹ́lì. (Ẹ́kísódù 25:17, 18; 40:24-27, 30-32; 1 Kíróníkà 24:4) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣó wá yẹ kó yà wá lẹ́nu láti gbọ́ pé pẹpẹ ìrúbọ ìṣàpẹẹrẹ wà lọ́run?—Ẹ́kísódù 40:29.
3. (a) Nínú àgọ́ ìjọsìn Júù ìgbàanì, báwo làwọn àlùfáà ṣe ń da àwọn ọkàn sí “ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ”? (b) Kí ló fà á tí Jòhánù fi rí ọkàn àwọn ẹlẹ́rìí tí a pa lábẹ́ pẹpẹ ìṣàpẹẹrẹ ní ọ̀run?
3 “Ọkàn àwọn tá a fikú pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nítorí iṣẹ́ ìjẹ́rìí tí wọ́n ti máa ń ṣe” wà lábẹ́ pẹpẹ yìí. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Àwọn ọkàn náà ò lè jẹ́ ọkàn tó tinú ara jáde, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórìṣà Gíríìkì ṣe gbà gbọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Ìsíkíẹ́lì 18:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, Jòhánù mọ̀ pé ọkàn, tàbí ìwàláàyè, ni ẹ̀jẹ̀ dúró fún, àti pé nígbà táwọn àlùfáà nínú àgọ́ ìjọsìn Júù ìgbàanì bá pa ẹran ìrúbọ kan, wọ́n máa ń wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ “sórí pẹpẹ yíká-yíká” tàbí kí wọ́n dà á sí “ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun.” (Léfítíkù 3:2, 8, 13; 4:7; 17:6, 11, 12) Fún ìdí yìí, ọkàn ẹran tí wọ́n máa ń lò níbi pẹpẹ ìrúbọ là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́, kí ló fà á tí ọkàn, tàbí ẹ̀jẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyí fi wà ní ìsàlẹ̀ pẹpẹ ìṣàpẹẹrẹ lọ́run? Ìdí ni pé Ọlọ́run wo ikú wọn gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ.
4. Ọ̀nà wo ni ikú àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí bí gbà jẹ́ ìrúbọ?
4 Ní tòótọ́, gbogbo àwọn tá a fẹ̀mí bí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀mí ti Ọlọ́run ló kú ikú ìrúbọ. Nítorí ipa tí wọ́n máa kó nínú Ìjọba Jèhófà lókè ọ̀run, Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n kọ ìrètí èyíkéyìí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé lákọ̀tán kí wọ́n sì fi í rúbọ. Lọ́nà yìí, wọ́n gbà láti kú ikú ìrúbọ nítorí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. (Fílípì 3:8-11; fi wé Fílípì 2:17.) Bí ọ̀rọ̀ àwọn tí Jòhánù rí lábẹ́ pẹ́pẹ́ ṣe jẹ́ gan-an nìyí. Wọ́n jẹ́ àwọn ẹni àmì òróró tó kú ikú ajẹ́rìíkú nígbà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé nítorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ onítara tí wọ́n ń ṣe láti máa gbé Ọ̀rọ̀ Jèhófà àti ipò Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lárugẹ. “Ọkàn [wọn ni a] fikú pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nítorí iṣẹ́ ìjẹ́rìí [mar·ty·riʹan] tí wọ́n ti máa ń ṣe.”
5. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùṣòtítọ́ ti kú, báwo lọkàn wọn ṣe ń ké jáde fún ìgbẹ̀san?
5 Jòhánù ń rí i bí ìran náà ṣe ń ṣí payá nìṣó, ó sọ pé: “Wọ́n sì ké pẹ̀lú ohùn rara, pé: ‘Títí di ìgbà wo, Olúwa Ọba Aláṣẹ mímọ́ àti olóòótọ́, ni ìwọ ń fà sẹ́yìn kúrò nínú ṣíṣèdájọ́ àti gbígbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé?’” (Ìṣípayá 6:10) Báwo ni ẹ̀jẹ̀ àwọn olùṣòtítọ́ ṣe lè máa ké fún ìgbẹ̀san, níwọ̀n bí Bíbélì ti fi hàn pé àwọn òkú kò mọ nǹkan kan? (Oníwàásù 9:5) Ó dára, ṣe bí ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì olódodo ké jáde lẹ́yìn tí Kéènì ṣìkà pa á? Tí Jèhófà sì wá sọ fún Kéènì pé: “Kí ni ìwọ ṣe? Fetí sílẹ̀! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń ké jáde sí mi láti inú ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:10, 11; Hébérù 12:24) Ó dájú pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀yẹ́jẹ̀ Ébẹ́lì ló ń sọ̀rọ̀. Bó ṣe jẹ́ ni pé Ébẹ́lì kú láìṣẹ̀ láìrò, àmọ́ ẹ̀san ń ké lórí ẹni tó pa á pé ìyà tọ́ sí òun náà. Lọ́nà kan náà, àwọn Kristẹni ajẹ́rìíkú wọ̀nyẹn ò ṣẹ̀, wọn ò rò, ẹ̀san sì gbọ́dọ̀ ké lórí àwọn tó pa wọ́n. (Lúùkù 18:7, 8) Igbe ẹ̀san ń ké rara nítorí pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùṣòtítọ́ ni wọ́n ti kú láìṣẹ̀ láìrò bẹ́ẹ̀.—Fi wé Jeremáyà 15:15, 16.
6. Ìtasílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ aláìrò wo ni Jèhófà gbẹ̀san rẹ̀ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni?
6 A tún lè fi ipò táwọn olùṣòtítọ́ yìí wà wé bí nǹkan ṣe rí pẹ̀lú ẹ̀yà Júdà apẹ̀yìndà nígbà tí Ọba Mánásè gorí ìtẹ́ lọ́dún 716 ṣááju Sànmánì Kristẹni. Ọba náà ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ aláìrò púpọ̀ sílẹ̀, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ṣe ni ó ‘fayùn rẹ́’ wòlíì Aísáyà. (Hébérù 11:37; 2 Àwọn Ọba 21:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mánásè ronú pìwà dà lẹ́yìn náà tó sì tún ìwà rẹ̀ ṣe, ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ náà ń wà nìṣó. Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ará Bábílónì sọ ìjọba Júdà dahoro, “nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà ni ó fi ṣẹlẹ̀ sí Júdà, láti mú un kúrò níwájú rẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Mánásè, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ṣe; àti nítorí ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ pẹ̀lú, tí ó fi jẹ́ pé ó fi ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kún Jerúsálẹ́mù, Jèhófà kò sì gbà láti dárí jì.”—2 Àwọn Ọba 24:3, 4.
7. Ta ló jẹ̀bi tó pọ̀ jù nítorí títa “ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́” sílẹ̀?
7 Gẹ́gẹ́ bó ti rí láwọn àkókò tá a kọ Bíbélì, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó pa àwọn ẹlẹ́rìí Ọlọ́run yìí lè ti kú tipẹ́tipẹ́. Àmọ́, ètò tó fa ikú ìjẹ́rìíkú wọn ṣì wà síbẹ̀, tòun tẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lọ́rùn rẹ̀. Ètò Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé ni, irú-ọmọ rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé. Èyí tó ta yọ nínú rẹ̀ ni Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé.a Bíbélì ṣàpèjúwe obìnrin náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó “mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí Jésù ní àmupara.” Bẹ́ẹ̀ ni, “nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́ àti ti gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 17:5, 6; 18:24; Éfésù 4:11; 1 Kọ́ríńtì 12:28) Ẹrù ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ yìí mà pọ̀ o! Níwọ̀n ìgbà tí Bábílónì Ńlá bá wà, ẹ̀jẹ̀ àwọn tó pa yóò máa ké jáde fún ìdájọ́ òdodo.—Ìṣípayá 19:1, 2.
8. (a) Àwọn wo ló kú ikú ajẹ́rìíkú nígbà tí Jòhánù ṣì wà láyé? (b) Inúnibíni wo làwọn olú ọba Róòmù ṣe?
8 Jòhánù fúnra ẹ̀ rí àwọn tí wọ́n kú ikú ìjẹ́rìíkú ní ọ̀rúndún kìíní nígbà tí Ejò oníkà àti irú-ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé bá ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i jagun. Jòhánù ti rí bí wọ́n ṣe kan Olúwa wa mọ́gi ó sì wà láàyè ní gbogbo ìgbà tí wọ́n pa Sítéfánù, Jákọ́bù arákùnrin òun fúnra rẹ̀, Pétérù, Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì tí wọ́n jọ jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ tímọ́tímọ́. (Jòhánù 19:26, 27; 21:15, 18, 19; Ìṣe 7:59, 60; 8:2; 12:2; 2 Tímótì 1:1; 4:6, 7) Lọ́dún 64 Sànmánì Kristẹni, olú ọba Róòmù, Nérò mú káwọn Kristẹni jìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn, ó fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n dáná sun ìlú ńlá náà, kó bàa lè fìyẹn bo àgbọ́sọ táwọn èèyàn ń sọ pé òun ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀. Òpìtàn Tacitus ròyìn pé: “Wọ́n [ìyẹn àwọn Kristẹni] kú ikú ẹlẹ́yà; wọ́n da awọ ẹranko bò àwọn kan, ẹ̀yìn èyí ni ajá sì wá fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, wọ́n kan àwọn kan [mọ́gi],b wọ́n jó àwọn kan gẹ́gẹ́ bí ètùfù láti tànmọ́lẹ̀ ní alẹ́.” Ńṣe ni inúnibíni ń gorí inúnibíni lábẹ́ Olú Ọba Domitian (tó jẹ láàárín ọdún 81 sí ọdún 96 Sànmánì Kristẹni), ìyẹn sì mú kí wọ́n lé Jòhánù lọ sí erékùṣù Pátímọ́sì. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti wí: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.”—Jòhánù 15:20; Mátíù 10:22.
9. (a) Olórí ẹlẹ̀tàn wo ni Sátánì bí lọ́mọ ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Kristẹni, ó sì jẹ́ apá pàtàkì lára ètò wo? (b) Ìwà wo làwọn olùṣàkóso kan láwọn ibi tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀ hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní àti Ìkejì?
9 Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Kristẹni, ejò ògbólógbòó nì, Sátánì Èṣù, ti bí olórí ẹlẹ̀tàn lọ́mọ, ìyẹn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n jẹ́ apẹ̀yìndà àti ara ètò Bábílónì tó ń fi orúkọ náà, “Kristẹni,” ṣe bojú-bojú. Olórí ẹlẹ̀tàn yìí ni apá pàtàkì lára irú-ọmọ Ejò náà, ó sì ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ sí onírúurú ẹ̀ya ìsìn tó ta kora. Bíi ti ẹ̀yà Júdà ìgbàanì tó jẹ́ aláìṣòótọ́, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ru ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wíwúwo, nítorí pé gbogbo ọ̀nà ni wọ́n gbà lọ́wọ́ níhà méjèèjì nínú Ogun Àgbáyé Kìíní àti Ìkejì. Àwọn òṣèlú kan láwọn ibi tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀ tiẹ̀ ti fàwọn ogun yìí bojú láti pa àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tó ń ròyìn lórí inúnibíni tí Hitler ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àtúnyẹ̀wò ìwé náà Kirchenkampf in Deutschland (Ìjà Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì ní Jámánì) láti ọwọ́ Friedrich Zipfel sọ pé: “Ìdá mẹ́ta nínú wọn [ìyẹn àwọn Ẹlẹ́rìí] ni wọ́n pa, yálà kí wọ́n yìnbọn fún wọn, kí wọ́n hùwà ipá mìíràn sí wọn, kí wọ́n febi pa wọ́n, kí wọ́n ṣàìsàn tàbí kí wọ́n lò wọ́n nílò ẹrú. Kò tíì sí ìtẹnilóríba tó burú bí èyí rí, ohun tó sì fà á ni pé ìgbàgbọ́ wọn tí ò ṣeé fi báni dọ́rẹ̀ẹ́ ta ko èròǹgbà Ìjọba Àjùmọ̀ní ti Orílẹ̀-Èdè.” Lóòótọ́, a lè sọ nípa àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti ẹgbẹ́ àlùfáà rẹ̀ pé: “A ti rí àmì ẹ̀jẹ̀ ọkàn àwọn òtòṣì aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ nínú ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ.”—Jeremáyà 2:34.c
10. Ìyà inúnibíni wo làwọn ọ̀dọ́kùnrin ogunlọ́gọ̀ ńlá ti jẹ lọ́pọ̀ ilẹ̀?
10 Láti ọdún 1935, àwọn ọ̀dọ́kùnrin olùṣòtítọ́ ti ogunlọ́gọ̀ ńlá ti fàyà rán ìnira inúnibíni ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀. (Ìṣípayá 7:9) Àní bí Ogun Àgbáyé Kejì ṣe ń parí nílẹ̀ Yúróòpù, àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìnlá [14] ni wọ́n yẹgi fún nínú ìlú kan ṣoṣo. Kí lẹ̀ṣẹ̀ wọn? Wọ́n kọ̀ láti “kọ́ṣẹ́ ogun.” (Aísáyà 2:4) Lẹ́nu àìpẹ́ yìí pàápàá, a rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin láwọn ilẹ̀ Ìlà Oòrùn ayé àti ní Áfíríkà tí wọ́n lù títí dójú ikú tàbí tí wọ́n tiẹ̀ yìnbọn pa nítorí pé wọn ò kọ́ṣẹ́ ogun. Ó dájú pé àwọn ọ̀dọ́ ajẹ́rìíkú yìí, tí wọ́n yẹ lẹ́ni tó ń ti àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù lẹ́yìn, yóò jíǹde sínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.—2 Pétérù 3:13; fi wé Sáàmù 110:3; Mátíù 25:34-40; Lúùkù 20:37, 38.
Aṣọ Funfun Kan
11. Lọ́nà wo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n kú ikú ajẹ́rìíkú fi gba “aṣọ funfun kan”?
11 Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣàkọsílẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ àwọn ará ìgbàanì tí wọ́n pàwà títọ́ mọ́, ó wí pé: “Síbẹ̀síbẹ̀, bí wọ́n tilẹ̀ ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí wọn nípa ìgbàgbọ́ wọn, gbogbo àwọn wọ̀nyí kò rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti rí ohun tí ó dára jù tẹ́lẹ̀ fún wa, kí a má bàa sọ wọ́n di pípé láìsí àwa.” (Hébérù 11:39, 40) Kí ni “ohun tí ó dára jù” yẹn tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yòókù ń wọ̀nà fún? Jòhánù rí i níhìn-ín nínú ìran: “A sì fi aṣọ funfun kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; a sì sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi fún ìgbà díẹ̀ sí i, títí iye àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn arákùnrin wọn pẹ̀lú tí a máa tó pa bí a ti pa àwọn náà yóò fi pé.” (Ìṣípayá 6:11) Gbígbà tí wọ́n gba “aṣọ funfun kan” ní í ṣe pẹ̀lú dídi tí wọ́n máa di ẹ̀dá ẹ̀mí aláìleèkú lẹ́yìn tí wọ́n bá jíǹde. Wọn ò tún ní wà nílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkàn tí a pa lábẹ́ pẹpẹ mọ́, ṣùgbọ́n a óò gbé wọn dìde láti jẹ́ apá kan àwùjọ alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] tí ń jọ́sìn níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run lọ́run. Níbẹ̀, àwọn tìkára wọn ni a ti fún ní ìtẹ́, tó fi hàn pé àǹfààní jíjẹ́ ọba ti tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. “Wọ́n wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun,” èyí tó túmọ̀ sí pé a ti polongo wọn ní olódodo lọ́nà òfin, wọ́n sì yẹ fún ipò ńlá níwájú Jèhófà nínú àgbàlá ọ̀run yẹn. Èyí pẹ̀lú jẹ́ ní ìmúṣẹ ìlérí Jésù fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ nínú ìjọ Sádísì pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni a ó fi ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun ṣe ní ọ̀ṣọ́ báyìí.”—Ìṣípayá 3:5; 4:4; 1 Pétérù 1:4.
12. Lọ́nà wo làwọn ẹni àmì òróró tí Jésù jí dìde gbà “sinmi fún ìgbà díẹ̀ sí i,” títí di ìgbà wo sì ni?
12 Gbogbo ẹ̀rí fi hàn pé àjíǹde ti ọ̀run yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1918, lẹ́yìn tí Jésù gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914 tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gẹṣin lọ láti bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́gun rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba nípa lílé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run. Síbẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró tí Jésù jí dìde yìí la sọ fún pé kí wọ́n “sinmi fún ìgbà díẹ̀ sí i, títí iye àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn” yóò fi pé. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ẹgbẹ́ Jòhánù tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn ń pa ìwà títọ́ mọ́ lábẹ́ àdánwò àti inúnibíni, nítorí pé àwọn alátakò ṣì lè pa àwọn kan lára wọn. Àmọ́, níkẹyìn, ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn olódodo tí Bábílónì Ńlá àti àwọn òṣèlú àlè rẹ̀ ta sílẹ̀ ni Jésù máa gbẹ̀san rẹ̀. Ní báyìí ná, kò sí iyè méjì pé àwọn tí Jésù ti jí dìde lára wọn ti ń ṣiṣẹ́ ní ọ̀run. Wọ́n ń sinmi, kì í ṣe nípa jíjókòó tẹtẹrẹ láìṣiṣẹ́, bí kò ṣe pé wọ́n ń fi sùúrù dúró de ọjọ́ ẹ̀san Jèhófà. (Aísáyà 34:8; Róòmù 12:19) Ìsinmi wọn yóò dópin nígbà tí wọ́n ba fojú rí ìparun ìsìn èké àti pé, gẹ́gẹ́ bí àwọn “tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́,” wọ́n wà pẹ̀lú Jésù Kristi Olúwa bó ṣe ń mú ìdájọ́ ṣẹ lórí gbogbo apá yòókù irú-ọmọ burúkú ti Sátánì níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 2:26, 27; 17:14; Róòmù 16:20.
‘Àwọn Tí Wọ́n Kú Kọ́kọ́ Dìde’
13, 14. (a) Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti wí, ìgbà wo ni àjíǹde ti ọ̀run bẹ̀rẹ̀, àwọn wo sì ni Jésù jí dìde? (b) Ìgbà wo ni Jésù jí àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣẹ́ kù nílẹ̀ di ọjọ́ Olúwa dìde lọ sọ́run?
13 Ìjìnlẹ̀ òye tí ṣíṣí èdìdì karùn-ún jẹ́ ká ní bá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yòókù tí wọ́n dá lórí àjíǹde ti ọ̀run mu rẹ́gí. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí èyí ni ohun tí a sọ fún yín nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà, pé àwa alààyè tí a kù nílẹ̀ di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa kì yóò ṣáájú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú lọ́nàkọnà; nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú-áńgẹ́lì àti pẹ̀lú kàkàkí Ọlọ́run, àwọn tí ó kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ni yóò sì kọ́kọ́ dìde. Lẹ́yìn náà, àwa alààyè tí a kù nílẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú wọn, ni a ó gbà lọ dájúdájú nínú àwọsánmà láti pàdé Olúwa nínú afẹ́fẹ́; a ó sì tipa báyìí máa wà pẹ̀lú Olúwa nígbà gbogbo.”—1 Tẹsalóníkà 4:15-17.
14 Ìtàn amóríyá tí àwọn ẹsẹ wọ̀nyí sọ mà ga o! Àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù tí wọ́n kù nílẹ̀ di ìgbà wíwàníhìn-ín Jésù, ìyẹn ni pé, àwọn tí wọ́n ṣì ń bẹ láàyè lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò wíwàníhìn-ín rẹ̀, ni àwọn tí wọ́n ti kú tẹ́lẹ̀ yóò ṣáájú dé ọ̀run. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, àwọn òkú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ni ó kọ́kọ́ jí dìde. Jésù sọ̀ kalẹ̀, ìyẹn ni pé, ó yí àfiyèsí rẹ̀ sí wọn, ó sì jí wọn dìde sí ìyè ti ẹ̀mí, nípa fífún wọn ní “aṣọ funfun kan.” Lẹ́yìn náà, àwọn tí wọ́n ṣì wà láàyè gẹ́gẹ́ bí èèyàn lórí ilẹ̀ ayé parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé, àwọn alátakò ń pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ní ìpa ìkà. Àmọ́ ṣáá, wọn kò sùn nínú ikú bí àwọn tó wà ṣáájú wọn ti sùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọ́n bá kú, a óò yí wọn padà ní ìṣẹ́jú akàn, “ní ìpajúpẹ́,” a óò mú wọn lọ sí ọ̀run láti wà pẹ̀lú Jésù àtàwọn tí wọ́n jọ para pọ̀ jẹ́ ara Kristi. (1 Kọ́ríńtì 15:50-52; fi wé Ìṣípayá 14:13.) Nípa báyìí, àjíǹde àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bẹ̀rẹ̀ kété lẹ́yìn táwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Àpókálíìsì bẹ̀rẹ̀ sí í gẹṣin.
15. (a) Ìhìn rere wo ni ṣíṣí èdìdì karùn-ún ti fún wa gbọ́? (b) Báwo ni ìgẹṣin Aṣẹ́gun tó wà lórí ẹṣin funfun náà ṣe dé òpin?
15 Ṣíṣí èdìdì karùn-ún àkájọ ìwé yìí ti mú ká gbọ́ ìhìn rere nípa àwọn ẹni àmì òróró olùpa-ìwà-títọ́-mọ́ tí wọ́n ti ṣẹ́gun, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ títí dójú ikú. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìhìn rere páàpáà létí Sátánì àti irú-ọmọ rẹ̀. Ìgẹṣin Aṣẹ́gun náà tí ń bẹ lórí ẹṣin funfun ń bá a lọ láìsẹ́ni tó lè dá a dúró yóò sì dé òpin ní àkókò ìjíhìn ayé tó “wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Èyí la mú ṣe kedere nígbà tí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣí èdìdì kẹfà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Fi wé New World Translation Reference Bible, ojú ìwé 1577, appendix 5C, “Torture Stake” [Òpó Igi Ìdálóró].
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 102]
‘Àwọn ọkàn tí a pa’
Ìwé Cyclopedia ti McClintock àti Strong ṣàyọlò ọ̀rọ̀ John Jortin, onísìn Pùròtẹ́sítáǹtì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ọ̀rúndún kejìdínlógún, tí àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ French Huguenot, báyìí pé: “Níbi tí inúnibíni ti bẹ̀rẹ̀, ni ìsìn Kristẹni parí sí . . . Lẹ́yìn tí ìsìn Kristẹni ti fìdí múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsìn ilẹ̀ ọba [Róòmù], àti lẹ́yìn táwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ti gba ọlà tí wọ́n sì ti dá wọn lọ́lá, ni iná ìwà ibi bíburú jáì nípasẹ̀ inúnibíni wá bẹ̀rẹ̀ sí í bù làlà bí wọ́n ṣe ń lò ó láti gbéjà ko ẹ̀sìn tá a gbé kárí Ìhìn Rere.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 103]
“A sì fi aṣọ funfun kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn”