Bíbá Ọlọ́run Rìn—Àwọn Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́
“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—JÁKỌ́BÙ 4:8.
1, 2. Èé ṣe tí o fi lè sọ pé àǹfààní ńláǹlà ni ó jẹ́ láti sin Jèhófà?
ỌKÙNRIN náà ti jìyà lẹ́wọ̀n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Lẹ́yìn náà, a pè é kí ó wá fara hàn níwájú alákòóso ilẹ̀ náà. Àwọn nǹkan yí padà bíríbírí. Lójijì, ẹlẹ́wọ̀n náà wá rí i pé òun ń ṣiṣẹ́ fún ọba tí ó lágbára jù lọ lórí ilẹ̀ ayé nígbà yẹn. Ẹlẹ́wọ̀n tẹ́lẹ̀ rí yìí ni a fi sí ipò iṣẹ́ tí ó ga, ó sì ń gbádùn ipò ọlá tí ó kọyọyọ. Jósẹ́fù—ọkùnrin tí a ń fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè lẹ́sẹ̀ nígbà kan rí—ń bá ọba rìn nísinsìnyí!—Jẹ́nẹ́sísì 41:14, 39-43; Sáàmù 105:17, 18.
2 Lónìí, àwọn ènìyàn láǹfààní láti bá ẹnì kan tí ó tóbi ju Fáráò ti Íjíbítì ṣiṣẹ́. Onípò Àjùlọ ní àgbáyé ń ké sí gbogbo wa láti sin òun. Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ àǹfààní tí ó múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tó láti ṣe bẹ́ẹ̀, kí a sì ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè! Nínú Ìwé Mímọ́, agbára gíga lọ́lá àti ògo pẹ̀lú ìtòròmini, ẹwà àti inú dídùn ni a fi ṣàpèjúwe rẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 1:26-28; Ìṣípayá 4:1-3) Ìfẹ́ máa ń fara hàn gbangba nínú gbogbo bí ó ṣe ń báni lò. (1 Jòhánù 4:8) Kì í purọ́. (Númérì 23:19) Jèhófà kì í sì í já àwọn tí ó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i kulẹ̀ láé. (Sáàmù 18:25) Bí a bá gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo rẹ̀, a lè gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀, tí ó nítumọ̀ nísinsìnyí àti ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. (Jòhánù 17:3) Kò sí alákòóso ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí tí ó lè fúnni ní ohunkóhun tí ó jọ irú àwọn ìbùkún àti àǹfààní bẹ́ẹ̀.
3. Ọ̀nà wo ni Nóà gbà ‘bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn’?
3 Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, baba ńlá ìgbàanì náà, Nóà, pinnu láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run àti ète rẹ̀. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Nóà jẹ́ olódodo. Ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀. Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9) Dájúdájú, Nóà kò bá Jèhófà rìn lójúkojú, níwọ̀n bí kò ti sí ènìyàn kankan tí ó “rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.” (Jòhánù 1:18) Kàkà bẹ́ẹ̀, Nóà bá Ọlọ́run rìn ní ti pé ó ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ fún un pé kí ó ṣe. Nítorí pé Nóà ya ìgbésí ayé rẹ̀ sọ́tọ̀ fún ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà, ó gbádùn ipò ìbátan ọlọ́yàyà, tí ó ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run Olódùmarè. Gẹ́gẹ́ bí Nóà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ‘ń bá Ọlọ́run rìn’ lónìí nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni Jèhófà. Báwo ni ẹnì kan ṣe ń bẹ̀rẹ̀ irú ipa ọ̀nà bẹ́ẹ̀?
Ìmọ̀ Pípéye Ṣe Pàtàkì
4. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni?
4 Kí a tó lè bá Jèhófà rìn, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ̀ ọ́n. Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀. Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’ Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde lọ, ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò sì jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù.” (Aísáyà 2:2, 3) Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò fún gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀ nítọ̀ọ́ni. Jèhófà ti pèsè Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀. Ọ̀nà kan tí ó gbà ń ṣe èyí jẹ́ nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45-47) Jèhófà ń lo “ẹrú olóòótọ́” láti pèsè ìtọ́ni tẹ̀mí nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì, ìpàdé Kristẹni, àti ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí a ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́. Ọlọ́run tún ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 2:10-16.
5. Èé ṣe tí òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ fi ṣe iyebíye tó bẹ́ẹ̀?
5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í sanwó fún òtítọ́ Bíbélì, ó ṣe iyebíye. Bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ń kọ́ nípa Ọlọ́run fúnra rẹ̀—orúkọ rẹ̀, àkópọ̀ ìwà rẹ̀, ète rẹ̀, àti ọ̀nà tí ó gbà ń bá àwọn ènìyàn lò. A tún ń rí àwọn ìdáhùn tí ń sọni dòmìnira gbà ní ti àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé: Èé ṣe tí a fi wà níhìn-ín? Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà? Kí ni ohun tí ó wà ní ọjọ́ iwájú? Èé ṣe tí a fi ń darúgbó tí a sì ń kú? Ìwàláàyè ha wà lẹ́yìn ikú bí? Síwájú sí i, a ń kọ́ nípa ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa, ìyẹn ni pé, bí ó ṣe yẹ kí a máa rìn kí a bàa lè mú inú rẹ̀ dùn ní kíkún. A kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn ohun tí ó ń béèrè bọ́gbọ́n mu, wọ́n sì ń ṣàǹfààní lọ́nà tí ó kàmàmà nígbà tí a bá gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Láìsí ìtọ́ni Ọlọ́run, a kò lè lóye irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ láé.
6. Ipa ọ̀nà wo ni ìmọ̀ pípéye inú Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti rìn?
6 Òtítọ́ Bíbélì lágbára, ó sì ń sún wa láti ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé wa. (Hébérù 4:12) Ṣáájú kí a tó gba ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ sínú, a máa ń rìn kìkì “ní ìbámu pẹ̀lú ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí.” (Éfésù 2:2) Ṣùgbọ́n ìmọ̀ pípéye inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ipa ọ̀nà tí ó yàtọ̀ sílẹ̀ fún wa kí a bàa lè “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” (Kólósè 1:10) Ẹ wo bí ó ṣe jẹ́ ohun ayọ̀ tó pé kí a gbé àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ní bíbá Jèhófà rìn, Ẹni ọlọ́lá ńlá jù lọ ní gbogbo àgbáyé!—Lúùkù 11:28.
Ìgbésẹ̀ Pàtàkì Méjì —Ìyàsímímọ́ àti Ìbatisí
7. Bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ wo nípa ìṣàkóso ènìyàn ni ó máa ń ṣe kedere?
7 Nígbà tí òye wa nínú Bíbélì bá ń pọ̀ sí i, a óò bẹ̀rẹ̀ sí fi ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ àwọn àlámọ̀rí ènìyàn àti ìgbésí ayé tiwa wò. Òtítọ́ pàtàkì kan yóò wá tipa bẹ́ẹ̀ ṣe kedere. Òtítọ́ yẹn ni wòlíì Jeremáyà ti sọ tipẹ́tipẹ́, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Gbogbo ènìyàn—àní gbogbo wa—nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.
8. (a) Kí ló máa ń sún àwọn ènìyàn láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run? (b) Kí ni ìyàsímímọ́ Kristẹni jẹ́?
8 Lílóye òtítọ́ pàtàkì yìí ń mú kí a wá ìdarí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Ìfẹ́ fún Ọlọ́run sì ń sún wa láti ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún un. Láti ya ara ẹni sí mímọ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí títọ̀ ọ́ lọ nínú àdúrà, kí a sì ṣèlérí lọ́nà tí ó jinlẹ̀ láti fi ìgbésí ayé wa sìn ín, kí a sì máa fi ìṣòtítọ́ rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. Bí a bá ń ṣe èyí, a ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún Jèhófà pẹ̀lú ìpinnu tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Hébérù 10:7.
9. Èé ṣe tí àwọn ènìyàn fi máa ń ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà?
9 Jèhófà Ọlọ́run kì í fipá tàbí agbára mú ẹnikẹ́ni láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún òun. (Fi wé 2 Kọ́ríńtì 9:7.) Síwájú sí i, Ọlọ́run kò retí pé kí ẹnì kan ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Òun nítorí níní ìmọ̀lára kan tí kì í pẹ́ pòórá. Kí a tó batisí ẹnì kan, ó yẹ kí ó ti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn, ìyẹn sì ń béèrè ìsapá aláápọn láti gba ìmọ̀ sínú. (Mátíù 28:19, 20) Pọ́ọ̀lù pàrọwà fún àwọn tí wọ́n ti ṣe batisí láti ‘fi ara wọn fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò wọn.’ (Róòmù 12:1) Nípa lílo agbára ìmọnúúrò wa lọ́nà bẹ́ẹ̀ ni a fi ń ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Lẹ́yìn kíkọ́ nípa ohun tí ó ń béèrè àti fífarabalẹ̀ ronú lórí ọ̀ràn náà, a ń fi tinútinú àti ìdùnnú ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run.—Sáàmù 110:3.
10. Báwo ni ìyàsímímọ́ ṣe tan mọ́ batisí?
10 Lẹ́yìn títọ Ọlọ́run lọ nínú àdúrà ìdákọ́ńkọ́ láti fi ìpinnu wa láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ hàn, a óò gbé ìgbésẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. A óò jẹ́ kí ìyàsímímọ́ wa di mímọ̀ ní gbangba nípa ṣíṣe batisí nínú omi. Èyí jẹ́ ìpolongo ní gbangba pé a ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Jòhánù batisí rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa. (Mátíù 3:13-17) Lẹ́yìn náà, Jésù yanṣẹ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì batisí wọn. Nítorí náà, ìyàsímímọ́ àti ìbatisí jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti bá Jèhófà rìn.
11, 12. (a) Ọ̀nà wo ni a lè gbà fi batisí wé ayẹyẹ ìgbéyàwó? (b) Ìbádọ́gba wo ni a lè rí láàárín ipò ìbátan tí a ní pẹ̀lú Jèhófà àti èyí tí ó wà láàárín tọkọtaya?
11 Dídi ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́, tí ó sì ti ṣe batisí dà bí gbígbéyàwó. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésẹ̀ ni a máa ń gbé ṣáájú ọjọ́ ìgbéyàwó. Ọkùnrin àti obìnrin a pàdé, wọ́n á dojúlùmọ̀ ara wọn, wọ́n á sì kó sínú ìfẹ́. Lẹ́yìn náà, wọn á ṣàdéhùn ìgbéyàwó. Ayẹyẹ ìgbéyàwó á fi ohun tí wọ́n ti pinnu níkọ̀kọ̀ hàn ní gbangba—láti wọnú ìdè ìgbéyàwó, kí wọ́n sì máa gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya lẹ́yìn náà. Ayẹyẹ ìgbéyàwó ni ó sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ipò ìbátan pàtàkì yẹn ní gbangba. Ọjọ́ yẹn sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbéyàwó náà. Ní ìfiwéra, batisí sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tí a yà sọ́tọ̀ fún bíbá Jèhófà rìn nínú ipò ìbátan kan tí a yà sí mímọ́.
12 Gbé ìjọra mìíràn yẹ̀wò. Lẹ́yìn ọjọ́ ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn, ó yẹ kí ìfẹ́ tí ó wà láàárín tọkọtaya túbọ̀ jinlẹ̀, kí ó sì máa pọ̀ sí i. Kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí, tọkọtaya gbọ́dọ̀ máa fi àìmọtara-ẹni-nìkan sapá láti mú kí ipò ìbátan ìgbéyàwó wọn máa bá a nìṣó, kí wọ́n sì mú kí ó túbọ̀ lágbára sí i. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í wọnú ìgbéyàwó pẹ̀lú Ọlọ́run, lẹ́yìn tí a bá ti ṣe batisí, a gbọ́dọ̀ sakun láti máa jẹ́ kí ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà máa bá a nìṣó. Ó ń rí ìsapá tí a ń ṣe láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó mọrírì rẹ̀, ó sì ń sún mọ́ wa. Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
Rírìn ní Ìṣísẹ̀ Jésù
13. Ní bíbá Ọlọ́run rìn, àpẹẹrẹ ta ni a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé?
13 Kí a tó lè bá Jèhófà rìn, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù Kristi fi lélẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ ẹni pípé, tí àwa sì jẹ́ aláìpé, a kò lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí ó fi lélẹ̀ lọ́nà pípé pérépéré. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ń retí pé kí a ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe. Ẹ jẹ́ kí a gbé apá márùn-ún yẹ̀ wò nínú ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù tí àwọn Kristẹni tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ gbọ́dọ̀ sakun láti fara wé.
14. Kí ló túmọ̀ sí láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
14 Jésù ní ìmọ̀ tí ó péye tí ó sì jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó fa ọ̀rọ̀ yọ léraléra láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. (Lúùkù 4:4, 8) Dájúdájú, àwọn aṣáájú ìsìn òǹrorò ọjọ́ wọnnì pẹ̀lú fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Ìwé Mímọ́. (Mátíù 22:23, 24) Ìyàtọ̀ ibẹ̀ ni pé Jésù lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ túmọ̀ sí, ó sì fi í sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Kì í ṣe kìkì ohun tí a kọ sínú Òfin náà nìkan ni ó lóye, ṣùgbọ́n ó tún mọ ìtumọ̀ rẹ̀. Bí a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, ó yẹ kí àwa pẹ̀lú sakun láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí a mọ ohun tí ó ń sọ, tàbí kí a mọ ìtumọ̀ rẹ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a lè di òṣìṣẹ́ tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà tí ‘ń fi ọwọ́ tí ó tọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.’—2 Tímótì 2:15.
15. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run?
15 Kristi Jésù bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Baba rẹ̀ ọ̀run. Jésù kò fi ìmọ̀ tí ó ní nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Àní àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá pè é ní “Olùkọ́,” nítorí pé ibikíbi tí ó bá lọ, ó máa ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti àwọn ète Rẹ̀. (Mátíù 12:38) Jésù wàásù ní gbangba ní àgbègbè tẹ́ńpìlì, nínú sínágọ́gù, ní àwọn ìlú ńlá àti ní ìgbèríko. (Máàkù 1:39; Lúùkù 8:1; Jòhánù 18:20) Ó ń fi ìyọ́nú àti inú rere kọ́ni, ó ń fi ìfẹ́ hàn fún àwọn tí ó ràn lọ́wọ́. (Mátíù 4:23) Àwọn tí wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tún rí ọ̀pọ̀ ibi àti ọ̀nà tí wọ́n lè gbà kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ète àgbàyanu rẹ̀.
16. Báwo ni ipò ìbátan tí ó wà láàárín Jésù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí ń jọ́sìn Jèhófà ti ṣe tímọ́tímọ́ tó?
16 Jésù ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn mìíràn tí ń jọ́sìn Jèhófà. Nígbà tí Jésù ń bá àwùjọ kan sọ̀rọ̀ nígbà kan, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ wá láti bá a sọ̀rọ̀. Àkọsílẹ̀ Bíbélì náà sọ pé: “Ẹnì kan wí fún un pé: ‘Wò ó! Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọ́n ń wá ọ̀nà láti bá ọ sọ̀rọ̀.’ Ní dídáhùn, ó wí fún ẹni tí ń sọ fún un pé: ‘Ta ni ìyá mi, ta sì ni àwọn arákùnrin mi?’ Àti ní nína ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé: ‘Wò ó! Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi! Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, òun kan náà ni arákùnrin, àti arábìnrin, àti ìyá mi.’” (Mátíù 12:47-50) Èyí kò túmọ̀ sí pé Jésù ṣá ìdílé rẹ̀ tì, nítorí pé àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fi hàn pé òun kò ṣe bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 19:25-27) Síbẹ̀, àkọsílẹ̀ yìí tẹnu mọ́ ìfẹ́ tí Jésù ní fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Bákan náà lónìí, àwọn tí ń bá Ọlọ́run rìn máa ń bá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yòókù kẹ́gbẹ́, wọ́n sì túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ wọn gidigidi.—1 Pétérù 4:8.
17. Báwo ni Jésù ṣe nímọ̀lára nípa ṣíṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run, báwo sì ni ó ṣe yẹ kí ìyẹn nípa lórí wa?
17 Nípa ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, Jésù fi ìfẹ́ hàn fún Baba rẹ̀ ọ̀run. Jésù ṣègbọràn sí Jèhófà nínú ohun gbogbo. Ó sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 4:34) Kristi tún sọ pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wu [Ọlọ́run].” (Jòhánù 8:29) Jésù nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi “rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” (Fílípì 2:8) Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà bù kún Jésù, ó gbé e ga sí ipò àṣẹ àti ọlá tí ó tẹ̀ lé ti Jèhófà fúnra rẹ̀. (Fílípì 2:9-11) Bí ti Jésù, a ń fi ìfẹ́ wa hàn fún Ọlọ́run nípa pípa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti nípa ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀.—1 Jòhánù 5:3.
18. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú ọ̀ràn àdúrà?
18 Jésù jẹ́ ẹni tí ó máa ń gbàdúrà. Ó gbàdúrà nígbà tí ó ṣe batisí. (Lúùkù 3:21) Kí ó tó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ 12, ó gbàdúrà ní gbogbo òru. (Lúùkù 6:12, 13) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n yóò ṣe máa gbàdúrà. (Lúùkù 11:1-4) Ní òru tí ó ṣáájú ikú rẹ̀, ó gbàdúrà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì gbàdúrà pẹ̀lú wọn. (Jòhánù 17:1-26) Àdúrà jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé Jésù, àní bí ó ṣe yẹ kí ó jẹ́ pàtàkì nínú ìgbésí ayé tiwa, níwọ̀n bí a ti jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ẹ wo bí ó ṣe jẹ́ nǹkan ọlá tó láti bá Ọba Aláṣẹ Àgbáyé sọ̀rọ̀ nínú àdúrà! Síwájú sí i, Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà, nítorí Jòhánù kọ̀wé pé: “Èyí . . . ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa. Síwájú sí i, bí a bá mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohun yòówù tí a ń béèrè, a mọ̀ pé dájúdájú a óò rí àwọn ohun tí a béèrè gbà níwọ̀n bí a ti béèrè wọn lọ́wọ́ rẹ̀.”—1 Jòhánù 5:14, 15.
19. (a) Àwọn ànímọ́ Jésù wo ni ó yẹ kí a fara wé? (b) Ọ̀nà wo ni a ń gbà jàǹfààní láti inú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù?
19 Ọ̀pọ̀ nǹkan rẹpẹtẹ ni a lè kọ́ nípa yíyẹ ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi lórí ilẹ̀ ayé wò fínnífínní! Ronú lórí àwọn ànímọ́ tí ó fi hàn: ìfẹ́, ìyọ́nú, inú rere, okun, ìwàdéédéé, ìfòyebánilò, ìrẹ̀lẹ̀, ìgboyà, àti àìmọtara-ẹni-nìkan. Bí a bá ṣe kọ́ nípa Jésù tó, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́-ọkàn wa láti jẹ́ olùṣòtítọ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò ṣe pọ̀ tó. Ìmọ̀ nípa Jésù tún ń mú kí a túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ó ṣe tán, Jésù jẹ́ àwòrán Baba rẹ̀ ọ̀run lọ́nà pípé pérépéré. Ó sún mọ́ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi lè sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.”—Jòhánù 14:9.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run Láti Gbé Ọ Ró
20. Báwo ni a ṣe lè jèrè ìgboyà ní bíbá Jèhófà rìn?
20 Nígbà tí àwọn ọmọdé bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bí a ṣe ń rìn, ẹsẹ̀ wọn kì í ranlẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe ń kọ́ bí a ṣe ń fi ìgboyà rìn? Kìkì nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ déédéé àti títẹpẹlẹ mọ́ ọn. Tóò, àwọn tí ń bá Jèhófà rìn ń sakun láti fi ìgboyà gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe déédéé. Èyí pẹ̀lú ń béèrè àkókò àti ìtẹpẹlẹmọ́. Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí bí ìtẹpẹlẹmọ́ ti ṣe pàtàkì tó ní bíba Ọlọ́run rìn nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Lákòótán, ẹ̀yin ará, a ń béèrè lọ́wọ́ yín, a sì ń gbà yín níyànjú nípasẹ̀ Jésù Olúwa, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ wa lórí bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa rìn, kí ẹ sì máa wu Ọlọ́run, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń rìn ní ti tòótọ́, pé kí ẹ tẹra mọ́ títúbọ̀ ṣe é lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.”—1 Tẹsalóníkà 4:1.
21. Bí a ṣe ń bá Jèhófà rìn, àwọn ìbùkún wo ni a lè gbádùn?
21 Bí a bá ya ara wa sọ́tọ̀ pátápátá fún Ọlọ́run, òun yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó ní bíbá a rìn. (Aísáyà 40:29-31) Kò sí nǹkan kan tí ayé yìí lè fi fúnni tí a lè fi wé àwọn ìbùkún tí ó ń fún àwọn tí ó bá ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Òun ni ‘Ẹni tí ń kọ́ wa kí a lè ṣe ara wa láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí a tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí a máa rìn. Bí a bá sì fetí sí àwọn àṣẹ rẹ̀ ní tòótọ́, àlàáfíà wa yóò dà bí odò, òdodo wa yóò sì dà bí ìgbì òkun.’ (Aísáyà 48:17, 18) Nípa títẹ́wọ́gba ìkésíni yìí láti bá Ọlọ́run rìn àti nípa fífi ìṣòtítọ́ ṣe bẹ́ẹ̀, a lè gbádùn àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀ títí láé.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tí ó fi jẹ́ nǹkan ọlá láti bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn?
◻ Èé ṣe tí ìkẹ́kọ̀ọ́, ìyàsímímọ́, àti batisí fi jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ní bíbá Jèhófà rìn?
◻ Báwo ni a ṣe lè tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù?
◻ Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà yóò gbé wa ró bí a ṣe ń bá a rìn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìkẹ́kọ̀ọ́, ìyàsímímọ́, àti batisí jẹ́ àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ní bíbá Ọlọ́run rìn