Àkókò Yìí Gan-an Ló Yẹ Ká Máa Ṣọ́nà Ju Ti Tẹ́lẹ̀ Lọ
“Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.”—MÁTÍÙ 24:42.
1, 2. Kí ló fi hàn pé à ń gbé ní ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí?
ÒǸKỌ̀WÉ nì, Bill Emmott sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn lọ, ogun jíjà pọ̀ gan-an ní ọ̀rúndún ogún.” Bó tilẹ̀ gbà pé gbogbo ìgbà nínú ìtàn ìran ènìyàn ni ogun ti máa ń jà tí ìwà ipá sì pọ̀ rẹpẹtẹ, síbẹ̀ ó fi kún un pé: “Ọ̀rúndún ogún ò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rúndún mìíràn nípa ọ̀ràn ogun jíjà, ohun tó kàn yàtọ̀ níbẹ̀ ni bí ogun náà ṣe pọ̀ tó àti ibi tó nasẹ̀ dé. Òun ni ọ̀rúndún táwọn èèyàn ti kọ́kọ́ ja ogun tó kárí ayé . . . Ohun tó dà bíi pé ó túbọ̀ fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ ni pé, kì í ṣe ogun àgbáyé kan ṣoṣo ló wáyé, bí kò ṣe méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”
2 Jésù Kristi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ogun tí ‘orílẹ̀-èdè yóò gbé dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.’ Àmọ́ ṣá o, ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ jẹ́ apá kan ‘àmì wíwàníhìn-ín Kristi àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan.’ Nínú àsọtẹ́lẹ̀ pípabanbarì yìí, Jésù tún mẹ́nu kan ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, àti ìsẹ̀lẹ̀. (Mátíù 24:3, 7, 8; Lúùkù 21:6, 7, 10, 11) Irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ ti wá pọ̀ gan-an ó sì ti burú sí i gan-an ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Ìwà ibi àwọn èèyàn ti wá pọ̀ gan-an, gẹ́gẹ́ bá a ṣe ń rí i nínú ìwà tí wọ́n ń hù sí Ọlọ́run àti sí ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. Ìwà rere ń kásẹ̀ nílẹ̀, ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá sì gbòde kan. Àwọn èèyàn ti di olùfẹ́ owó dípò kí wọ́n jẹ́ olùfẹ́ Ọlọ́run, kìkì ayé jíjẹ́ ni wọ́n ń bá kiri. Gbogbo èyí fi hàn pé à ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko.”—2 Tímótì 3:1-5.
3. Báwo ló ṣe yẹ kí “àwọn àmì àkókò” nípa lórí wa?
3 Ojú wo lo fi ń wo bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i nínú ìtàn ìran ènìyàn? Ọ̀pọ̀ ló ń dágunlá, kódà tí wọ́n ń ṣe bí ẹni pé ohun tó ń lọ nínú ayé lónìí kò kan àwọn. Àwọn ọlọ́lá ayé àtàwọn amòye inú ayé kò mọ ìtumọ̀ “àwọn àmì àkókò”; bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn aṣáájú ìsìn kò fúnni ní ìtọ́sọ́nà tó tọ́ lórí ọ̀ràn náà. (Mátíù 16:1-3) Àmọ́ Jésù gbà àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.” (Mátíù 24:42) Kì í ṣe pé ká kàn ṣọ́nà nìkan ni Jésù ń sọ níhìn-ín bí kò ṣe pé ká “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” Ká tó lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, a ní láti wà lójúfò ká má sì dẹra nù. Ohun tá a ń sọ níhìn-ín kọjá ká kàn mọ̀ pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé, ó kọjá kéèyàn kàn mọ̀ pé àkókò líle koko la wà. Ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú dáadáa pé “òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.” (1 Pétérù 4:7) Kìkì ìgbà tá a bá ní irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀ la tó lè máa fi ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú ṣọ́nà. Nítorí náà, ìbéèrè tó yẹ ká máa ronú lé lórí ni pé: ‘Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ kó dá wa lójú pé òpin ti sún mọ́lé?’
4, 5. (a) Kí ni yóò túbọ̀ jẹ́ kó dá wa lójú pé òpin ètò nǹkan búburú yìí ti sún mọ́lé, kí sì nìdí? (b) Kí ni ohun kan tí ọjọ́ Nóà àti wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn fi jọra?
4 Ṣàgbéyẹ̀wò bí ipò nǹkan ṣe rí làwọn àkókò tó ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí kò sí irú rẹ̀ rí nínú ìtàn ìran ènìyàn, ìyẹn ìṣẹ̀lẹ̀ Àkúnya Omi ọjọ́ Nóà. Àwọn èèyàn burú débi pé ọ̀ràn náà ‘dun Jèhófà ní ọkàn-àyà.’ Ó sì polongo pé: “Èmi yóò nu àwọn ènìyàn tí mo ti dá kúrò lórí ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:6, 7) Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Nígbà tí Jésù ń fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún wé bí nǹkan ṣe rí lónìí, ó sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.”—Mátíù 24:37.
5 Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé bí ọ̀ràn nípa ayé tó ṣáájú Ìkún Omi ṣe rí lára Jèhófà gẹ́lẹ́ ni ọ̀ràn nípa ayé ìsinsìnyí ṣe rí lára rẹ̀. Níwọ̀n bó ti fòpin sí ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti ọjọ́ Nóà, ó dájú pé yóò pa ayé búburú ti òde òní náà run. Níní òye tó ṣe kedere nípa bí ayé ìgbàanì ṣe fara jọ àkókò tá a wà yìí yóò túbọ̀ jẹ́ kó dá wa lójú pé òpin ayé ìsinsìnyí ti sún mọ́lé. Kí wá làwọn ohun tí wọ́n fi jọra? Ó kéré tán, a rí nǹkan márùn-ún. Ìkíní ni pé a fúnni ní ìkìlọ̀ tó ṣe kedere kí ìparun tó dé.
A Kìlọ̀ Fún Un Nípa “Ohun Tí A Kò Tíì Rí”
6. Ìkìlọ̀ wo ló dájú pé Jèhófà kọ́kọ́ fún àwọn ènìyàn ní ọjọ́ Nóà?
6 Jèhófà polongo ní ọjọ́ Nóà pé: “Ẹ̀mí mi kò ní fi àkókò tí ó lọ kánrin gbé ìgbésẹ̀ sí ènìyàn nítorí pé ó jẹ́ ẹlẹ́ran ara pẹ̀lú. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọgọ́fà ọdún.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:3) Ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ ní ọdún 2490 ṣááju Sànmánì Tiwa yìí ló sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà tí òpin yóò dé bá ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yẹn. Ìwọ ro ohun tíyẹn túmọ̀ sí fún àwọn tó wà láyé lákòókò yẹn! Kìkì ọgọ́fà ọdún péré ló kù tí Jèhófà máa mú “àkúnya omi wá sórí ilẹ̀ ayé láti run gbogbo ẹran ara tí ipá ìyè ń ṣiṣẹ́ nínú wọn lábẹ́ ọ̀run.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:17.
7. (a) Kí ni Nóà ṣe nígbà tá a kìlọ̀ fún un nípa Ìkún Omi? (b) Kí ló yẹ kí á ṣe lórí àwọn ìkìlọ̀ tá a fún wa nípa òpin ètò ìsinsìnyí?
7 A ti kìlọ̀ fún Nóà nípa àjálù tó ń bọ̀ náà ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ṣáájú àkókò yẹn, ó sì fọgbọ́n lo àkókò náà láti múra sílẹ̀ fún lílà á já. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Lẹ́yìn fífún Nóà ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí kò tíì rí, o fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.’ (Hébérù 11:7) Àwa náà ńkọ́? Nǹkan bí àádọ́rùn-ún ọdún ti kọjá báyìí látìgbà tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914. Ó dá wa lójú gbangba pé “àkókò òpin” la wà. (Dáníẹ́lì 12:4) Kí ló yẹ ká wa ṣe nípa àwọn ìkìlọ̀ tá a fún wa? Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Nítorí náà, àkókò yìí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ máa fi ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú ṣe ìfẹ́ Jèhófà.
8, 9. Àwọn ìkìlọ̀ wo ni à ń rí gbà lóde òní, báwo la sì ṣe ń rí àwọn ìkìlọ̀ náà gbà?
8 Ní ayé òde òní, àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti kà á nínú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí pé ètò ìsinsìnyí yóò pa run ṣáá ni. Ǹjẹ́ a gba èyí gbọ́? Ṣàkíyèsí ohun tí Jésù Kristi sọ ní kedere pé: “Ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mátíù 24:21) Jésù tún sọ pé òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń ya àgùntàn kúrò lára ewúrẹ́. Àwọn tó jẹ́ aláìyẹ yóò “lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mátíù 25:31-33, 46.
9 Jèhófà ti pe àfiyèsí àwọn èèyàn rẹ̀ sí àwọn ìkìlọ̀ yìí nípa ìránnilétí àtìgbàdégbà tá a ń rí gbà nípasẹ̀ oúnjẹ tẹ̀mí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè. (Mátíù 24:45-47) Ìyẹn nìkan kọ́ o, gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, ahọ́n, àtàwọn èèyàn la pè láti ‘bẹ̀rù Ọlọ́run, kí wọ́n sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé.’ (Ìṣípayá 14:6, 7) Ìkìlọ̀ tó sọ pé Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ìṣàkóso èèyàn kúrò láìpẹ́ jẹ́ apá pàtàkì lára ìhìn Ìjọba Ọlọ́run táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀ kárí ayé. (Dáníẹ́lì 2:44) Ìkìlọ̀ yìí kì í ṣe ohun téèyàn ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú o. Awímáyẹhùn ni Ọlọ́run Olódùmarè. (Aísáyà 55:10, 11) Ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ ní ọjọ́ Nóà, ó sì tún máa mú un ṣẹ lákòókò tiwa yìí pẹ̀lú.—2 Pétérù 3:3-7.
Ìwà Ìbàjẹ́ Takọtabo Gbòde Kan
10. Kí la lè sọ nípa bí ìwà ìbàjẹ́ takọtabo ṣe gbòde kan ní ọjọ́ Nóà?
10 Àkókò tá a wà yìí tún fara jọ ọjọ́ Nóà lọ́nà mìíràn. Jèhófà pàṣẹ fún ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ láti fi àwọn èèyàn bíi tiwọn “kún ilẹ̀ ayé,” kí wọ́n lo agbára ìbímọ tí Ọlọ́run fún wọn nínú ètò ìgbéyàwó lọ́nà tó ní ọlá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn fi ìbálòpọ̀ tó lòdì sí ti ẹ̀dá sọ ìràn ènìyàn di eléèérí ní ọjọ́ Nóà. Wọ́n sọ kalẹ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé, wọn sọ ara wọn di ènìyàn, wọ́n fẹ́ àwọn arẹwà obìnrin, wọ́n sì bí àwọn abàmì ọmọ, ìyẹn àwọn Néfílímù. (Jẹ́nẹ́sísì 6:2, 4) Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn áńgẹ́lì oníṣekúṣe yìí la fi wé ìbálòpọ̀ táwọn èèyàn gbé gbòdì ní Sódómù àti Gòmórà. (Júúdà 6, 7) Nípa bẹ́ẹ̀ ìwà ìbàjẹ́ takọtabo wá gbòde kan láyé ọjọ́hun.
11. Irú ìwà tó gbòde kan wo ló mú kí àkókò tiwa yìí fara jọ ti ọjọ́ Nóà?
11 Ìwàkiwà tó gbòde kan lóde òní wá ńkọ́? Ọ̀ràn ìbálòpọ̀ ló gba ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó yéni kedere pé “wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere”; ọ̀pọ̀ sì ti fi ara wọn fún “ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.” (Éfésù 4:19) Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, níní ìbálòpọ̀ láìṣe ìgbéyàwó, fífi ìbálòpọ̀ fìtínà àwọn ọmọdé, àti ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ti gbòde kan báyìí. Àwọn kan ti “ń gba èrè iṣẹ́ kíkún nínú ara wọn” nípa kíkó àwọn àrùn tí ń ranni nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, ìdílé wọn ti dà rú, wọ́n sì tún ń ní àwọn ìṣòro mìíràn láwùjọ.—Róòmù 1:26, 27.
12. Kí nìdí tó fi yẹ ká kórìíra ohun búburú?
12 Ní ọjọ́ Nóà, Jèhófà rán Àkúnya Omi ńlá láti fòpin sí ayé tí ìbálòpọ̀ ń sín níwín yẹn. A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé àkókò tá a wà yìí kò yàtọ̀ rárá sí ti ọjọ́ Nóà. “Ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀ yóò fọ ilẹ̀ ayé mọ́ tí kò fi ní si ‘àwọn àgbèrè, àwọn panṣágà, àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún ètè tó lòdì sí ti ẹ̀dá, àti àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀’ mọ́ níbẹ̀. (Mátíù 24:21; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Ìṣípayá 21:8) Ẹ ò rí i bó ṣe di ọ̀ràn kánjúkánjú fún wa tó pé ká kórìíra ohun búburú, ká sì yàgò pátápátá fún àwọn ipò tó lè mú wa hu ìwà pálapàla!—Sáàmù 97:10; 1 Kọ́ríńtì 6:18.
Ilẹ̀ Ayé “Kún fún Ìwà Ipá”
13. Kí nìdí tí ilẹ̀ ayé fi “kún fún ìwà ipá” ní ọjọ́ Nóà?
13 Nígbà tí Bíbélì tún ń sọ̀rọ̀ nípa ohun mìíràn tó wáyé ní ọjọ́ Nóà, ó ní: “Ilẹ̀ ayé sì wá bàjẹ́ ní ojú Ọlọ́run tòótọ́, ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:11) Kì í ṣe pé ìwà ipá jẹ́ ohun tuntun nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Kéènì tó jẹ́ ọmọ Ádámù pa àbúrò rẹ̀ tó jẹ́ olódodo. (Jẹ́nẹ́sísì 4:8) Láti fi bí ìwà ipá ṣe gbilẹ̀ tó ṣáájú àkókò yẹn hàn, Lámékì kọ ewì kan tó fi yangàn nípa bí òun ṣe pa ọ̀dọ́kùnrin kan, láti gbẹ̀san ohun tó ṣe sí òun. (Jẹ́nẹ́sísì 4:23, 24) Ohun tó jẹ́ tuntun ní ọjọ́ Nóà ni bí ìwà ipá ṣe pọ̀ rẹpẹtẹ. Bí àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ṣe ń fẹ́ àwọn obìnrin lórí ilẹ̀ ayé, táwọn yẹn sì bí àwọn ọmọ, ìyẹn àwọn Néfílímù, ló wá jẹ́ kí ìwà ipá pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àwọn òmìrán oníwà ipá yìí ni “àwọn Abiniṣubú,” ìyẹn “àwọn tó ń jẹ́ káwọn ẹlòmíràn ṣubú.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Nípa bẹ́ẹ̀, ilẹ̀ ayé wá “kún fún ìwà ipá.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:13) Fojú inú wo àwọn ìṣòro tí Nóà á ti dojú kọ kó tó lè tọ́ ìdílé rẹ̀ dàgbà nínú irú àyíká bẹ́ẹ̀! Síbẹ̀, Nóà fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ‘olódodo níwájú Jèhófà nínú ìran yẹn.’—Jẹ́nẹ́sísì 7:1.
14. Báwo ni ayé òde òní ṣe “kún fún ìwà ipá tó”?
14 Látọjọ́ tó ti pẹ́ ni ìwà ipá ti wà. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ayé ọjọ́ Nóà ti kún fún ìwà ipá lọ́nà tí irú rẹ̀ kò wáyé rí, bẹ́ẹ̀ náà ni àkókò tiwa yìí rí. Gbogbo ìgbà la máa ń gbọ́ nípa ìwà ipá nínú ilé, tá à ń gbọ́ nípa àwọn apániláyà, àwọn èèyàn ń pa odindi ẹ̀yà run, àwọn kan ń yìnbọn pa ọ̀pọ̀ èèyàn láìnídìí. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀ tí ogun ń fà. Ilẹ̀ ayé tún ti kún fún ìwà ipá báyìí. Kí nìdí? Kí ló fà á tó fi wá pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí tún jẹ́ ká rí ọ̀nà mìíràn tí àkókò wa yìí fi jọ ti ọjọ́ Nóà.
15. (a) Kí ni ohun tó mú kí ìwà ipá pọ̀ gan-an láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí? (b) Kí ni ohun tó dá wa lójú pé yóò ṣẹlẹ̀?
15 Nígbà tá a fìdí Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ Mèsáyà múlẹ̀ ní ọ̀rún lọ́dún 1914, Jésù Kristi, Ọba tí a gbé gorí ìtẹ́ náà ṣe ohun kan tó pabanbarì. Ó lé Sátánì Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ gbogbo kúrò lọ́run wá sórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:9-12) Ṣáájú Ìkún Omi, ńṣe làwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn wọ̀nyẹn mọ̀ọ́mọ̀ fi ipò wọn sílẹ̀ ní ọ̀run; àmọ́ lóde òní, lílé la lé wọn kúrò nípò wọn lọ́run. Àti pé, kò tún ṣeé ṣe fún wọn mọ́ láti gbé ara èèyàn wọ lórí ilẹ̀ ayé kí wọ́n sì wá jẹ adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara. Nítorí ìjákulẹ̀ tí wọ́n ní yìí, tí inú sì ń bí wọn, tí wọ́n tún ń bẹ̀rù ìdájọ́ tó ń bọ̀ sórí wọn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí mú kí àwọn èèyàn àtàwọn ètò àjọ hu ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá tó burú jáì tó sì pọ̀ gan-an ju ti ọjọ́ Nóà lọ. Jèhófà pa ayé tó wà ṣáájú Ìkún Omi yẹn rẹ́ ráúráú lẹ́yìn tí àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn àtàwọn ọmọ wọn ti fi ìwà ibi kún inú rẹ̀. Ó sì dájú pé ohun tó máa ṣe fún ayé òde oní náà nìyẹn! (Sáàmù 37:10) Àmọ́ ṣá o, gbogbo àwọn tó ń ṣọ́nà lónìí ló mọ̀ pé ìdáǹdè àwọn ti kù sí dẹ̀dẹ̀.
A Wàásù Nípa Ìṣẹ̀lẹ̀ Náà
16, 17. Kí ni ohun kẹrin tí ọjọ́ Nóà fi jọ ọjọ́ tiwa yìí?
16 Ohun kẹrin tí ọjọ́ òní fi jọ ayé tó ṣáájú Ìkún Omi ni ohun tá a rí nínú iṣẹ́ tá a yàn fún Nóà láti ṣe. Nóà kan ọkọ̀ áàkì gìrìwò kan. Ó tún jẹ́ “oníwàásù.” (2 Pétérù 2:5) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wàásù nípa rẹ̀? Ó hàn gbangba pé ìwàásù Nóà ní í ṣe pẹ̀lú sísọ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n ronú pìwà dà àti kíkìlọ̀ fún wọn nípa ìparun tó ń bọ̀. Jésù sọ pé àwọn èèyàn ọjọ́ Nóà “kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—Mátíù 24:38, 39.
17 Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń polongo ìhìn Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé nípa fífi aápọn tẹ̀lé àṣẹ tá a pa fún wọn láti wàásù. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ibi gbogbo lágbàáyé ni àwọn èèyàn ti lè gbọ́ kí wọ́n sì kà nípa ìhìn Ìjọba náà ní èdè tiwọn. A ti ń tẹ ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000,000] ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, tó ń kéde Ìjọba Jèhófà, jáde ní èdè tó lé ní ogóje [140] báyìí. Láìsí àní-àní, a ti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” Nígbà tá a bá ṣe iṣẹ́ yẹn dé ibi tó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn, ó dájú pé òpin yóò dé.—Mátíù 24:14.
18. Báwo ni ojú tí ọ̀pọ̀ fi ń wo iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe rí tá a bá fi wé ojú tí ọ̀pọ̀ jù lọ fi wò ó ní ọjọ́ Nóà?
18 Tá a bá tún ronú nípa báwọn èèyàn ò ṣe ka ohun tẹ̀mí sí rárá àti bí ìwà wọn ṣe burú jáì láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìkún Omi, kò ní ṣòro fún wa láti lóye ohun tójú Nóà àti ìdílé rẹ̀ rí nígbà táwọn aládùúgbò wọn tí kò fẹ́ gbọ́ ń fi wọ́n ṣẹ̀sín, táwọn èèyàn ń bú wọn, tí wọ́n sì ń yọ ṣùtì sí wọn. Síbẹ̀ òpin náà dé. Bákan náà ni ‘àwọn olùyọṣùtì pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn’ pọ̀ bí nǹkan míì láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Bíbélì sì sọ pé: “Síbẹ̀ ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè.” (2 Pétérù 3:3, 4, 10) Ó dájú pé yóò dé ní àkókò tí a yàn kalẹ̀. Kì yóò sì pẹ́. (Hábákúkù 2:3) Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu gan-an fún wa láti máa bá a lọ ní ṣíṣọ́nà!
Àwọn Èèyàn Díẹ̀ Ló Là Á Já
19, 20. Ìjọra wo ló wà láàárín Ìkún Omi àti ìparun ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí?
19 Kì í ṣe ìwà ibi àwọn èèyàn náà àti ìparun tó dé bá wọn nìkan ni ọjọ́ Nóà fi jọ ọjọ́ tiwa yìí. Bí àwọn kan ṣe la Ìkún Omi náà já, bẹ́ẹ̀ náà la máa rí àwọn tó máa la òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já. Àwọn ọlọ́kàntútù èèyàn tí kò gbé irú ìgbésí ayé tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn gbé lákòókò yẹn ló la Ìkún Omi náà já. Wọ́n kọbi ara sí ìkìlọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé búburú àkókò yẹn. Bíbélì sọ pé: “Nóà rí ojú rere ní ojú Jèhófà. . . . Ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:8, 9) Nínú gbogbo aráyé, ìdílé kan ṣoṣo, ìyẹn “àwọn ènìyàn díẹ̀ la omi já láìséwu, èyíinì ni, ọkàn mẹ́jọ.” (1 Pétérù 3:20) Àwọn wọ̀nyí sì ni Jèhófà Ọlọ́run pàṣẹ fún pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 9:1.
20 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yóò “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà.” (Ìṣípayá 7:9, 14) Àwọn mélòó ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà yóò jẹ́? Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Àwọn tó máa la ìpọ́njú ńlá tó ń bọ́ náà já yóò kéré níye gan-an tá a bá fi wọ́n wéra pẹ̀lú bílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí. Àmọ́ àwọn náà tún lè ní irú àǹfààní kan náà tí Ọlọ́run fún àwọn tó la Ìkún Omi já. Ó ṣeé ṣe káwọn olùlàájá láǹfààní láti bímọ fún àkókò díẹ̀, káwọn ọmọ náà lè jẹ́ ara àwùjọ tuntun lórí ilẹ̀ ayé.—Aísáyà 65:23.
“Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”
21, 22. (a) Àǹfààní wo ni gbígbé tá a gbé ìtàn nípa Ìkún Omi yẹ wò yìí ṣe fún ọ? (b) Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2004, kí sì nìdí tó fi yẹ ká kọbi ara sí ìmọ̀ràn tó fúnni?
21 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìkún Omi náà dà bí ohun tó ti pẹ́ gan-an sí ọjọ́ tiwa yìí, síbẹ̀ ó hàn gbangba pé ó fún wa ní ìkìlọ̀ kan tá a gbọ́dọ̀ fiyè sí. (Róòmù 15:4) Bí ọjọ́ Nóà àti ọjọ́ tiwa ṣe jọra yẹn gbọ́dọ̀ jẹ́ ká túbọ̀ mọ ìjẹ́pàtàkì ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ká sì wà lójúfò sí bíbọ̀ tí Jésù ń bọ̀ láìròtẹ́lẹ̀ láti wá dá àwọn ẹni ibi lẹ́jọ́.
22 Jésù Kristi ń darí iṣẹ́ bàǹtà-banta kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ilé kíkọ́ nípa tẹ̀mí lóde òní. Párádísè tẹ̀mí kan tó fara jọ ọkọ̀ áàkì ti wà báyìí láti dáàbò bo àwọn olùjọsìn tòótọ́ kí wọ́n lè la ewu tó ń bọ̀ já. (2 Kọ́ríńtì 12:3, 4) A gbọ́dọ̀ dúró sínú Párádísè yẹn ká bàa lè la ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ já. Ayé Sátánì ló yí Párádísè tẹ̀mí náà ká, ó sì múra tán láti gbé ẹnikẹ́ni tó bá ń tòògbé nípa tẹ̀mí mì. Ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà” ká sì wà ní ìmúratán de ọjọ́ Jèhófà.—Mátíù 24:42, 44.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ìṣílétí wo ni Jésù fúnni nípa wíwá rẹ̀?
• Kí ni Jésù fi àkókò wíwàníhìn-ín rẹ̀ wé?
• Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn àkókò wa yìí gbà fara jọ àwọn ọjọ́ Nóà?
• Báwo ni ríronú jinlẹ̀ nípa ìjọra tó wà láàárín ọjọ́ Nóà àti ọjọ́ tiwa yìí ṣe yẹ kó nípa lórí ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú tá a ní?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 18]
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2004 yóò jẹ́: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà . . . Ẹ wà ní ìmúratán.”—Mátíù 24:42, 44.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Nóà kọbi ara sí ìkìlọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ àwa náà ń ṣe bẹ́ẹ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
“Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí”