Àkọsílẹ̀ Nípa Ọjọ́ Nóà—Ǹjẹ́ ó Ṣe Pàtàkì Fún wa?
NÍGBÀ tí Jésù ń sàsọtẹ́lẹ̀ nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti òpin ètò àwọn nǹkan, ó sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” (Mátíù 24:3, 37) Jésù sọ tẹ́lẹ̀ ní kedere pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa bá ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà mu. Àkọsílẹ̀ tó ṣe é gbára lé tó sì pé pérépéré nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà ṣe pàtàkì gan-an.
Ṣé bẹ́ẹ̀ ni àkọsílẹ̀ nípa ọjọ́ Nóà ṣe pàtàkì tó ni? Ṣé ẹ̀rí wà tó fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni àkọsílẹ̀ náà? Ṣé a lè mọ àkókò náà gan-an tí Ìkún Omi ọ̀hún ṣẹlẹ̀?
Ìgbà Wo Ni Ìkún Omi Náà Wáyé?
Bíbélì to àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ tó mú kó ṣeé ṣe láti ṣírò àwọn àkókò padà sẹ́yìn sí ìgbà ìwáṣẹ̀ ẹ̀dá èèyàn. Ní Jẹ́nẹ́sísì 5:1-29, a rí àkọsílẹ̀ nípa ìlà ìran látìgbà tá a ti dá ọkùnrin àkọ́kọ́ náà Ádámù títí dìgbà tá a bí Nóà. Ìkún Omi náà bẹ̀rẹ̀ “ní ẹgbẹ̀ta ọdún ìwàláàyè Nóà.”—Jẹ́nẹ́sísì 7:11.
Láti lè mọ àkókò tí Ìkún Omi náà wáyé, ńṣe la máa fi àkókò pàtàkì kan ṣe ìṣirò náà. Ìyẹn ni pé a máa lo àkókò kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn fara mọ́ nínú ìtàn tó sì tún bá ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó kan tá a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì mu. Tá a bá lo irú àkókò kan pàtó bẹ́ẹ̀, àá lè fi kàlẹ́ńdà ti Póòpù Gregory tí gbogbo èèyàn ń lò báyìí ṣèṣirò tá a máa fi tọ́ka sí àkókò kan pàtó tí Ìkún Omi náà ṣẹlẹ̀.
Àkókò pàtàkì kan tá a lè lò ni ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, ìyẹn ọdún tí Kírúsì Ọba Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì. Ìtàn nípa àkókò tí ọba náà ń ṣàkóso wà lára wàláà àwọn ará Bábílónì àtàwọn àkọsílẹ̀ tí Diodorus, Africanus, Eusebius àti Tọ́lẹ́mì kọ. Àwọn Júù tó ṣẹ́ kù sí Bábílónì kúrò níbẹ̀ wọ́n sì padà sí ìlú wọn lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, nítorí òfin kan tí Kírúsì gbé kalẹ̀. Èyí ló fòpin sí sísọ tá a sọ Júdà dahoro fún àádọ́rin ọdún, èyí tí Bíbélì sọ pé ó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Tá a bá ṣírò àkókò àwọn onídàájọ́ àti àkókò táwọn ọba Ísírẹ́lì fi ṣàkóso mọ́ ọn, ibi tá a máa gúnlẹ̀ sí ni pé ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Tiwa làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì. Tá a bá ka ọgbọ̀n lé nírínwó [430] ọdún lákàsẹ́yìn látọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá a tò lẹ́sẹẹsẹ nínú Bíbélì fi hàn pé ọdún 1943 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Ọlọ́run dá májẹ̀mú náà pẹ̀lú Ábúráhámù. Bákan náà la tún gbọ́dọ̀ ṣírò àkókò tá a bí Térà, Náhórì, Sérúgù, Réù, Pélégì, Ébérì, Ṣélà àti Ápákíṣádì tá a bí ní “ọdún kejì lẹ́yìn àkúnya omi,” ká sì tún ṣírò iye ọdún tí wọ́n lò láyé. (Jẹ́nẹ́sísì 11:10-32) Pẹ̀lú ìṣirò yìí, a wá lè sọ pé ọdún 2370 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Ìkún Omi náà bẹ̀rẹ̀.a
Ìkún Omi Náà Bẹ̀rẹ̀
Ká tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ ka Jẹ́nẹ́sísì orí keje ẹsẹ ìkọkànlá sí orí kẹjọ ẹsẹ ìkẹrin. Ohun tá a sọ fún wa nípa òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá náà ni pé: “Ní ẹgbẹ̀ta ọdún ìwàláàyè Nóà [2370 ṣááju Sànmánì Tiwa], ní oṣù kejì, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù, ní ọjọ́ yìí, gbogbo ìsun alagbalúgbú ibú omi ya, àwọn ibodè ibú omi ọ̀run sì ṣí.”—Jẹ́nẹ́sísì 7:11.
Nóà pín ọdún kan sí oṣù méjìlá, oṣù kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ọgbọ̀n ọjọ́. Láyé àtijọ́, nǹkan bí ìdajì oṣù September tòde òní ni oṣù àkọ́kọ́ nínú ọdún máa ń bẹ̀rẹ̀. Òjò ńlá náà bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ní “oṣù kejì, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù,” ó sì rọ̀ fún odidi ogójì ọ̀sán àti ogójì òru láàárín oṣù November àti December, ọdún 2370 ṣááju Sànmánì Tiwa.
A tún sọ fún wa nípa Ìkún Omi náà pé: “Omi náà sì ń bá a lọ ní kíkún bo ilẹ̀ ayé fún àádọ́jọ ọjọ́. . . . Omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ó ń fọn; àti ní òpin àádọ́jọ ọjọ́, omi náà ti dín kù. Ní oṣù keje, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù, áàkì náà sì wá gúnlẹ̀ sórí òkè ńlá Árárátì.” (Jẹ́nẹ́sísì 7:24–8:4) Nítorí náà, látìgbà tí omi náà ti bo gbogbo ilẹ̀ ayé pátápátá títí dìgbà tó fọn ráúráú jẹ́ àádọ́jọ ọjọ́, tàbí oṣù márùn-ún. Ọkọ̀ áàkì náà wá gúnlẹ̀ sórí òkè Árárátì ní oṣù April ọdún 2369 ṣááju Sànmánì Tiwa.
Ní báyìí, jọ̀wọ́ ka Jẹ́nẹ́sísì 8:5-17. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó oṣù méjì àtààbọ̀ (ọjọ́ mẹ́tàléláàádọ́rin) lẹ́yìn náà kí ṣóńṣó orí àwọn òkè tó fara hàn, “ní oṣù kẹwàá [June], ní ọjọ́ kìíní oṣù.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:5)b Oṣù mẹ́ta (àádọ́rùn-ún ọjọ́) lẹ́yìn náà—ìyẹn ní “ọdún kọkàn-lé-lẹ́gbẹ̀ta [tí Nóà ti wà láyé], ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kìíní oṣù,” tàbí ní ìdajì oṣù September, ọdún 2369 ṣááju Sànmánì Tiwa—Nóà ṣí ìbòrí áàkì náà kúrò. Ìgbà yẹn ló wá rí i pé “orí ilẹ̀ ti gbẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:13) Ní oṣù kan àti ọjọ́ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (ọjọ́ mẹ́tàdínlọ́gọ́ta) lẹ́yìn èyí, “ní oṣù kejì, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù [ní ìdajì oṣù November, ọdún 2369 ṣááju Sànmánì Tiwa], ilẹ̀ ayé sì ti gbẹ tán.” Nóà àti ìdílé rẹ̀ wá jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì náà sórí ilẹ̀ tó ti gbẹ táútáú. Nítorí náà, odindi ọdún kan gbáko àti ọjọ́ mẹ́wàá (ọgbọ̀n dín nírínwó ọjọ́) ni Nóà àtàwọn tó kù lò nínú ọkọ̀ áàkì náà.—Jẹ́nẹ́sísì 8:14.
Kí làwọn àkọsílẹ̀ tó ṣe gúnmọ́ yìí nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé, kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn àti àkókò tí wọ́n ṣẹlẹ̀ fẹ̀rí rẹ̀ hàn? Wọ́n fẹ̀rí hàn pé: Òtítọ́ pọ́ńbélé làwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè, wòlíì Hébérù nì kọ, ẹni tó hàn gbangba pé orí àwọn àkọsílẹ̀ tó rí gbà ló gbé ìwé Jẹ́nẹ́sísì kà, kì í ṣe ìtàn èké. Nítorí ìdí èyí, Àkúnya Omi náà ṣe pàtàkì gan-an fún wa lónìí.
Kí ni Àwọn Mìíràn Tó Jẹ́ Òǹkọ̀wé Bíbélì Sọ Nípa Ìkún Omi Náà?
Yàtọ̀ sí àkọsílẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì, àwọn ibi tá a tún ti tọ́ka sí Nóà tàbí sí Àkúnya Omi náà nínú Bíbélì pọ̀ jaburata. Àwọn àpẹẹrẹ kan rèé:
(1) Olùwádìí náà Ẹ́sírà dárúkọ Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀ (Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì) sínú ìtàn ìlà ìdílé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.—1 Kíróníkà 1:4-17.
(2) Lúùkù tó jẹ́ onísègùn àti òǹkọ̀wé Ìhìn Rere kọ orúkọ Nóà mọ́ orúkọ àwọn baba ńlá Jésù Kristi.—Lúùkù 3:36.
(3) Àpọ́sítélì Pétérù mẹ́nu ba ìtàn Ìkún Omi náà láwọn ìgbà kan nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.—2 Pétérù 2:5; 3:5, 6.
(4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ ńláǹlà tí Nóà lò pẹ̀lú bó ṣe kan ọkọ̀ áàkì náà fún ìgbàlà ìdílé rẹ̀.—Hébérù 11:7.
Ǹjẹ́ iyèméjì èyíkéyìí wà pé àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì wọ̀nyí tí Ọlọ́run mí sí fara mọ́ àkọsílẹ̀ Ìkún Omi náà tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì? Kò sí tàbí ṣùgbọ́n níbẹ̀ pé wọ́n kà á sí òtítọ́ pọ́ńbélé.
Jésù àti Ìkún Omi Náà
Jésù Kristi ti wà tẹ́lẹ̀ kó tó di ẹ̀dá èèyàn. (Òwe 8:30, 31) Ẹ̀dá ẹ̀mí ni lókè ọ̀run ní gbogbo àkókò Ìkún Omi náà. Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú Jésù kòró, èyí ló fi fún wa ní ẹ̀rí tó ju gbogbo ẹ̀rí lọ nínú Ìwé Mímọ́ nípa Nóà àti Àkúnya Omi náà. Jésù sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí. Nítorí bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.”—Mátíù 24:37-39.
Ǹjẹ́ Jésù lè fi ìtàn àròsọ ṣèkìlọ̀ fún wa nípa òpin ètò àwọn nǹkan yìí? Ó dájú pé kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀! Ó dá wa lójú pé ojúlówó àpẹẹrẹ nípa bí Ọlọ́run ṣe ṣèdájọ́ àwọn ẹni búburú ló lò. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló lọ sí Ìkún Omi náà, àmọ́ a lè rí ìtùnú nínú bá a ṣe mọ̀ pé Nóà àti ìdílé rẹ̀ là á já.
“Àwọn ọjọ́ Nóà” ṣe pàtàkì gan-an fáwọn tó wà láàyè lónìí, ní àkókò “wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn,” ìyẹn Jésù Kristi. Bá a ṣe ń ka kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn Ìkún Omi náà tó wà nínú àkọsílẹ̀ tí Nóà pa mọ́, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé ojúlówó ni àkọsílẹ̀ náà kì í ṣe ayédèrú. Bákan náà ni àkọsílẹ̀ inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tí Ọlọ́run mí sí nípa Àkúnya náà lè ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ gan-an. Bí Nóà, àwọn ọmọ rẹ̀ àtàwọn ìyàwó wọn ṣe nígbàgbọ́ nínú ọ̀nà tí Ọlọ́run fi gbà wọ́n là, àwa náà lónìí wà lábẹ́ ààbò Jèhófà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. (Mátíù 20:28) Kò tán síbẹ̀ o, a tún lè máa wọ̀nà láti wà lára àwọn tó máa la ètò búburú yìí já gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa ọjọ́ Nóà ṣe fi hàn pé òun àti ìdílé rẹ̀ la Ìkún Omi náà já, èyí tó fòpin sí ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti àkókò yẹn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé kíkún lórí àkókò tí Ìkún Omi náà ṣẹlẹ̀, wo ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 458 sí 460, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Ìwé Keil-Delitzsch Commentary on the Old Testament, Apá Kìíní, ojú ìwé 148, sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọjọ́ kẹtàléláàádọ́rin [73] lẹ́yìn tí ọkọ̀ áàkì náà gúnlẹ̀ ni ṣóńṣó orí àwọn òkè tó fara hàn, ìyẹn ṣóńṣó orí àwọn òkè Armenia tó yí ọkọ̀ áàkì náà ká lọ́tùn-ún lósì.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ṣé Bẹ́ẹ̀ Ni Wọ́n Ṣe Pẹ́ Láyé Tó Ni?
BÍBÉLÌ sọ pé: “Gbogbo ọjọ́ Nóà jẹ́ àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀rún ọdún, ó sì kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:29) Mètúsélà tó jẹ́ bàbá bàbá Nóà lo “ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n” [969] láyé—kò tún sí ẹ̀dá èèyàn mìíràn tó pẹ́ láyé tó báyìí. Ìpíndọ́gba iye ọdún táwọn ìran mẹ́wàá látìgbà Ádámù sí ìgbà ayé Nóà lò láyé kọjá àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rin ọdún [850]. (Jẹ́nẹ́sísì 5:5-31) Ṣé bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ìgbà yẹn pẹ́ láyé tó?
Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ pàá ni pé kéèyàn máa wà láàyè títí láé. A dá ọkùnrin àkọ́kọ́ náà Ádámù pé kó gbádùn ìwàláàyè tí ò lópin tó bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17) Ṣùgbọ́n Ádámù ṣàìgbọràn ó sì sọ àǹfààní náà nù. Nígbà tí Ádámù fi máa lo ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n [930] láyé, ó ti ń sún mọ́ bèbè ikú, ó sì padà sínú ilẹ̀ níbi tá a ti mú un jáde. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19; 5:5) Ọkùnrin àkọ́kọ́ náà fi ogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú sílẹ̀ fún gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀.—Róòmù 5:12.
Àmọ́ ṣá, àwọn èèyàn tó wà láyé nígbà yẹn kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ìjẹ́pípé tá a fi ṣẹ̀dá Ádámù níbẹ̀rẹ̀, ẹ̀rí sì fi hàn pé ìdí rèé tí wọ́n fi ń pẹ́ láyé ju àwọn tó jìnnà sí ìjẹ́pípé yẹn. Ìdí rèé tí ìpíndọ́gba iye ọdún téèyàn ń lò láyé fi fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú Ìkún Omi náà, àmọ́ iye náà wá lọ sílẹ̀ gan-an lẹ́yìn Àkúnya Omi. Bí àpẹẹrẹ, ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án [175] péré ni Ábúráhámù lò láyé. (Jẹ́nẹ́sísì 25:7) Nígbà tó sì tó nǹkan bí irínwó [400] ọdún lẹ́yìn tí baba ńlá olódodo náà kú, wòlíì Mósè kọ̀wé pé: “Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún; bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá, síbẹ̀, wíwà nìṣó wọn jẹ́ lórí ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́.” (Sáàmù 90:10) Ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn lónìí kò yàtọ̀ sí èyí.
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
Tá A Bá Kà Á Lákàsẹ́yìn Láti Àkókò Tí Kírúsì Ṣòfin Tó Jẹ́ Káwọn Júù Kúrò Nígbèkùn, Dé Ìgbà Ìkún Omi Ọjọ́ Nóà
537 Òfin Kírúsìc
539 Ìgbà tí Kírúsì ará Páṣíà Ṣẹ́gun Bábílónì
Ọdún
méjìdínláàádọ́rin?
607 Àádọ́rin ọdún tí Júdà fi dahoro bẹ̀rẹ̀
Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún
ó lé mẹ́fà [906]
táwọn aṣáájú,
àwọn onídàájọ́
àtàwọn ọba
Ísírẹ́lì fi ṣe
alábòójútó
1513 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì
Irínwó ọdún ó Irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n [430] táwọn
lé ọgbọ́n [430] ọmọ Ísírẹ́lì fi gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì àti
ní ilẹ̀ Kénáánì (Ẹ́kísódù 12:40, 41)
1943 Fífìdí májẹ̀mú Ábúráhámù múlẹ̀
Igba ọdún ó lé
márùn-ún [205]
2148 Ìbí Térà
Okòó lé rúgba
ọdún ó lé méjì
[222]
2370 Ìbẹ̀rẹ̀ Ìkún Omi náà
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
c Ìkéde tí Kírúsì ṣe láti dá àwọn Júù nídè kúrò nígbèkùn wáyé “ní ọdún kìíní Kírúsì ọba Páṣíà,” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọdún 538 ṣááju Sànmánì Tiwa tàbí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa. (Ẹ́sírà 1:1-4)