Ní Ìgbàgbọ́ Tó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin Nínú Ìjọba Ọlọ́run
“Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí.”—HÉB. 11:1.
1, 2. Kí ló máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Ìjọba náà máa mú ìfẹ́ Ọlọ́run fún aráyé ṣẹ, kí sì nìdí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
ÀWA Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń sọ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni ojútùú sí gbogbo ìṣòro aráyé, a sì máa ń fìtara sọ òótọ́ pàtàkì yìí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ fáwọn èèyàn. Àwọn ohun tá à ń retí láti gbádùn nínú Ìjọba náà ń tù wá nínú gan-an. Àmọ́, báwo ló ṣe jinlẹ̀ lọ́kàn wa tó pé Ìjọba yẹn máa dé lóòótọ́ àti pé ó máa mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ? Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú Ìjọba Ọlọ́run?—Héb. 11:1.
2 Olódùmarè fúnra rẹ̀ ló gbé Ìjọba Mèsáyà kalẹ̀ kó lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ fún àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀. Orí ìpìlẹ̀ tí kò lè yẹ̀ ni Jèhófà gbé Ìjọba náà kà, ìyẹn ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso. Àwọn tó jẹ́ apá pàtàkì nínú Ìjọba náà, irú bí Ọba Ìjọba náà, àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ àti ibi tí wọ́n máa ṣàkóso lé lórí ni Ọlọ́run ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ májẹ̀mú. Ọlọ́run tàbí Jésù Kristi ọmọ rẹ̀ ló máa ń jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn tí májẹ̀mú náà kàn. Tá a bá ronú lórí àwọn májẹ̀mú yìí, ó máa jẹ́ ká túbọ̀ mọ bí ìfẹ́ Jèhófà ṣe máa ṣẹ láìkùnà, á sì jẹ́ ká mọ bí ètò tí Jèhófà ṣe yìí ṣe fìdí múlẹ̀ tó.—Ka Éfésù 2:12.
3. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e?
3 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa májẹ̀mú pàtàkì mẹ́fà tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Mèsáyà, èyí tí Jèhófà ti gbé lé Kristi Jésù lọ́wọ́. Àwọn májẹ̀mú náà ni (1) májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá, (2) májẹ̀mú Òfin, (3) májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá, (4) májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pé Jésù yóò di àlùfáà bíi ti Melikisédékì, (5) májẹ̀mú tuntun, àti (6) májẹ̀mú Ìjọba. Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò bí májẹ̀mú kọ̀ọ̀kan ṣe tan mọ́ Ìjọba náà àti ipa tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn máa kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run fún ayé àti aráyé lápapọ̀ ṣẹ.—Wo àpótí tó ní àkòrí náà, “Bí Ọlọ́run Ṣe Máa Mú Ìfẹ́ Rẹ̀ Ṣẹ.”
ÌLÉRÍ TÓ JẸ́ KÁ MỌ BÍ JÈHÓFÀ ṢE MÁA MÚ ÌFẸ́ RẸ̀ ṢẸ
4. Bó ṣe wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, àwọn àṣẹ wo ni Jèhófà gbé kalẹ̀ tó kan àwọn èèyàn?
4 Lẹ́yìn tí Jèhófà sọ ayé di ibi ẹlẹ́wà fáwọn èèyàn, ó gbé àṣẹ mẹ́ta tó kan àwọn èèyàn kalẹ̀. Àwọn àṣẹ náà ni: Àkọ́kọ́, Ọlọ́run máa dá èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. Ìkejì, àwọn èèyàn máa mú kí Párádísè gbòòrò dé gbogbo ayé, kí àwọn olódodo tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù sì kún ilẹ̀ ayé. Ìkẹ́ta, Ọlọ́run kà á léèwọ̀ pé àwọn èèyàn kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. (Jẹ́n. 1:26, 28; 2:16, 17) Kò sídìí láti tún gbé àṣẹ míì kalẹ̀ mọ́. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá èèyàn, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí àṣẹ méjì tó kẹ́yìn kí ìfẹ́ Ọlọ́run fún ayé àtàwọn èèyàn bàa lè ṣẹ. Àmọ́, báwo ni ọ̀rọ̀ májẹ̀mú ṣe wọ̀ ọ́?
5, 6. (a) Báwo ni Sátánì ṣe gbìyànjú láti ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run fún aráyé? (b) Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí Sátánì fẹ̀sùn kàn án nínú ọgbà Édẹ́nì?
5 Sátánì Èṣù dáná ọ̀tẹ̀ sílẹ̀, ó dá ọgbọ́n burúkú kó lè ta ko ète Ọlọ́run. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nípa bó ṣe mú kí tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí ọ̀kan lára àṣẹ tí Ọlọ́run gbá kalẹ̀. Ó kó obìnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Éfà sí àdánwò bó ṣe ní kó jẹ nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú, èyí tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ. (Jẹ́n. 3:1-5; Ìṣí. 12:9) Sátánì tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé Ọlọ́run kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso lórí àwọn ẹ̀dá Rẹ̀. Kódà nígbà tó yá, Sátánì tún sọ pé torí ohun tí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń rí gbà lọ́wọ́ Rẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sìn ín.—Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5.
6 Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí Sátánì fẹ̀sùn kàn án nínú ọgbà Édẹ́nì? Ká sóòótọ́, tí Ọlọ́run bá pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn run, ìyẹn ì bá paná ọ̀tẹ̀ náà. Àmọ́, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa fi àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ onígbọràn kún ayé kò ní lè ní ìmúṣẹ. Dípò tí Ẹlẹ́dàá wa tó jẹ́ ọlọgbọ́n á fi pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn run lójú ẹsẹ̀, ṣe ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan tó máa fi rí i dájú pé gbogbo ìlérí tó ṣe nípa ayé ní ìmúṣẹ títí dórí bíńtín. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ni ìlérí tó ṣe ní ọgbà Édẹ́nì.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15.
7. Kí ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú ọgbà Édẹ́nì mú kó dá wa lójú nípa ejò náà àti irú-ọmọ rẹ̀?
7 Ìlérí tí Jèhófà ṣe ní ọgbà Édẹ́nì ló fi ṣe ìdájọ́ fún ejò náà àti irú-ọmọ rẹ̀, ìyẹn Sátánì Èṣù àti gbogbo àwọn tó gbà pẹ̀lú rẹ̀ pé Ọlọ́run kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Ọlọ́run tòótọ́ fún irú-ọmọ obìnrin rẹ̀ tó wà ní ọ̀run láṣẹ láti pa Sátánì run. Torí náà, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe ní ọgbà Édẹ́nì jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹni tó dáná ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì àti gbogbo aburú tí ọ̀tẹ̀ náà dá sílẹ̀ kò ní sí mọ́, ìyẹn nìkan kọ́ o, ìlérí náà tún jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ṣẹlẹ̀.
8. Kí la mọ̀ nípa obìnrin náà àti irú-ọmọ rẹ̀?
8 Tá ni irú-ọmọ obìnrin náà? Níwọ̀n bí irú-ọmọ náà ti máa fọ́ orí ejò náà, ìyẹn ni pé ó máa sọ Sátánì Èṣù tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí “di asán,” á jẹ́ pé irú-ọmọ náà ní láti jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí. (Héb. 2:14) Bákan náà, obìnrin tó máa bí irú-ọmọ náà pàápàá ní láti jẹ́ ẹni ẹ̀mí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú-ọmọ ejò náà ń yára pọ̀ sí i, obìnrin náà àti irú-ọmọ rẹ̀ jẹ́ àdììtú fún ohun tí ó tó ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin [4,000] lẹ́yìn ìlérí tí Jèhófà ṣe nínú ọgbà Édẹ́nì. Àmọ́, Jèhófà dá onírúurú májẹ̀mú tó máa jẹ́ ká mọ irú-ọmọ náà, májẹ̀mú yìí sì máa mú kó dá àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ lójú pé Ọlọ́run máa lo irú-ọmọ náà láti fòpin sí gbogbo àjálù tí Sátánì ti fà bá ìran aráyé.
MÁJẸ̀MÚ TÓ MÁA JẸ́ KÁ MỌ IRÚ-ỌMỌ NÁÀ
9. Májẹ̀mú wo ni Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá, ìgbà wo ló sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́?
9 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] lẹ́yìn tí Jèhófà dájọ́ ikú fún Sátánì, Jèhófà ní kí baba ńlá náà Ábúráhámù kúrò ní ìlú Úrì nílẹ̀ Mesopotámíà, kí ó lọ sílẹ̀ Kénáánì. (Ìṣe 7:2, 3) Jèhófà sọ fún un pé: “Bá ọ̀nà rẹ lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ àti kúrò ní ilé baba rẹ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́; èmi yóò sì mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára rẹ, èmi yóò sì bù kún ọ, èmi yóò sì mú kí orúkọ rẹ di ńlá; kí ìwọ fúnra rẹ sì jẹ́ ìbùkún. Èmi yóò sì súre fún àwọn tí ń súre fún ọ, ẹni tí ó sì ń pe ibi sọ̀ kalẹ̀ wá sórí rẹ ni èmi yóò fi gégùn-ún, gbogbo ìdílé orí ilẹ̀ yóò sì bù kún ara wọn dájúdájú nípasẹ̀ rẹ.” (Jẹ́n. 12:1-3) Èyí ni ibi àkọ́kọ́ tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ìgbà tí Jèhófà kọ́kọ́ bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú, ohun tá a mọ̀ ni pé májẹ̀mú náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1943 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Èyí sì jẹ́ ìgbà tí Ábúráhámù kúrò nílùú Háránì tó sì sọdá Odò Yúfírétì lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75].
10. (a) Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ tó dájú nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run? (b) Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wo ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí payá díẹ̀díẹ̀ nípa irú-ọmọ obìnrin náà?
10 Jèhófà tún ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù sọ láwọn ìgbà mélòó kan, bẹ́ẹ̀ ló sì ń fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé kan kún un. (Jẹ́n. 13:15-17; 17:1-8, 16) Ábúráhámù fi hàn pé òun nígbàgbọ́ tó dájú nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run nípa bó ṣe múra tán láti fi ọmọkùnrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó bí rúbọ. Èyí ló mú kí Jèhófà wá ṣe ìlérí kan tí kò lè yí pa dà láti fìdí májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá múlẹ̀. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18; Hébérù 11:17, 18.) Lẹ́yìn tí májẹ̀mú náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa irú-ọmọ obìnrin náà payá díẹ̀díẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kedere pé ìlà ìdílé Ábúráhámù ni irú-ọmọ náà ti máa wá, irú-ọmọ náà máa pọ̀, ó máa di ọba, ó máa pa gbogbo ọ̀tá run, á sì jẹ́ ìbùkún fún ọ̀pọ̀ èèyàn.
11, 12. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ní ìmúṣẹ tẹ̀mí, àǹfààní wo sì ló ṣe fún wa?
11 Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ṣẹ sára àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n jogún Ilẹ̀ Ìlérí. Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ohun tó rọ̀ mọ́ májẹ̀mú náà tún jẹ́ kó ní ìmúṣẹ nípa tẹ̀mí. (Gál. 4:22-25) Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti ṣàlàyé ohun tí ìmúṣẹ májẹ̀mú náà nípa tẹ̀mí jẹ́, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Kristi ni apá àkọ́kọ́ lára irú-ọmọ Ábúráhámù, nígbà tí àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] jẹ́ apá kejì lára irú-ọmọ náà. (Gál. 3:16, 29; Ìṣí. 5:9, 10; 14:1, 4) Láìsí àní-àní, obìnrin tí ó bí irú-ọmọ náà ni “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” ìyẹn apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà, tó ní nínú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí adúróṣinṣin. (Gál. 4:26, 31) Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá fi hàn pé Ọlọ́run ṣèlérí pé irú-ọmọ obìnrin náà yóò bù kún aráyé.
12 Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ọlọ́run máa gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lókè ọ̀run, ó sì mú kó ṣeé ṣe fún Ọba Ìjọba náà àtàwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ láti jogún Ìjọba náà. (Héb. 6:13-18) Títí dìgbà wo ni májẹ̀mú yìí á fi wà lẹ́nu iṣẹ́? Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 17:7 sọ pé ó jẹ́ “májẹ̀mú fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ó máa wà lẹ́nu iṣẹ́ títí dìgbà tí Ìjọba Mèsáyà bá pa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run, tí gbogbo aráyé sì rí ìbùkún gbà. (1 Kọ́r. 15:23-26) Àwọn tí yóò gbé lórí ilẹ̀ ayé nígbà yẹn yóò máa rí oríṣiríṣi ìbùkún gbà títí láé. Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá yìí jẹ́ kó hàn pé Jèhófà ti pinnu láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, pé àwọn èèyàn tó bá jẹ́ olódodo máa “kún ilẹ̀ ayé”!—Jẹ́n. 1:28.
MÁJẸ̀MÚ TÓ MÚ KÓ DÁJÚ PÉ ÌJỌBA NÁÀ MÁA WÀ TÍTÍ LÁÉ
13, 14. Kí ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá mú kó dá wa lójú?
13 Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe ní ọgbà Édẹ́nì àti májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá jẹ́ ká mọ ohun pàtàkì kan, pé Jèhófà gbé ìṣàkóso rẹ̀ lé orí àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Ìlànà yìí kan náà ló sì lò láti fìdí Ìjọba Mèsáyà múlẹ̀. (Sm. 89:14) Ǹjẹ́ ó lè ṣẹlẹ̀ pé kí ìṣàkóso Mèsáyà gba ìgbàkugbà láyè, kó sì wá di dandan pé kí Ọlọ́run pa á run? Májẹ̀mú míì tí Ọlọ́run dá mú kó dájú pé irú rẹ̀ kò lè ṣẹlẹ̀ láé.
14 Ọlọ́run ṣèlérí kan fún Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì, ìlérí yẹn ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá. (Ka 2 Sámúẹ́lì 7:12, 16.) Jèhófà bá Dáfídì dá májẹ̀mú yìí nígbà tí Dáfídì ń ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Jèhófà sì ṣèlérí fún un nípasẹ̀ májẹ̀mú náà pé Mèsáyà máa wá láti ìlà ìdílé rẹ̀. (Lúùkù 1:30-33) Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ sọ ohun kan tó ṣe tààràtà nípa ìdílé tí irú-ọmọ náà ti máa wá. Jèhófà sọ pé ajogún Dáfídì kan ló máa ní “ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin” sí ìtẹ́ Ìjọba Mèsáyà. (Ìsík. 21:25-27) Jèhófà máa tipasẹ̀ Jésù mú kí ìṣàkóso Dáfídì ‘fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.’ Àní sẹ́, irú-ọmọ Dáfídì “yóò wà . . . fún àkókò tí ó lọ kánrin àti ìtẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oòrùn.” (Sm. 89:34-37) Ó ti wá ṣe kedere pé ìṣàkóso Mèsáyà kò ní di ìdàkudà láé, a ó sì máa jàǹfààní Ìjọba yìí títí láé!
MÁJẸ̀MÚ TÍ ỌLỌ́RUN DÁ PÉ ÀLÙFÁÀ MÁA WÀ
15-17. Gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pé Jésù yóò di àlùfáà bíi ti Melikisédékì, iṣẹ́ míì wo ni irú-ọmọ náà tún máa ṣe, kí sì nìdí?
15 Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá àti èyí tó bá Dáfídì dá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé irú-ọmọ obìnrin náà máa jọba, àmọ́ kí gbogbo èèyàn tó lè rí ìbùkún gbà, ó ní láti ṣe ju kó kàn jẹ́ ọba. Kí aráyé tó lè gba ìbùkún, wọ́n gbọ́dọ̀ bọ́ lọ́wọ́ ipò ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n wà, kí wọ́n sì láǹfààní láti di ara ìdílé Jèhófà. Kí èyí lè ṣeé ṣe, irú-ọmọ náà gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ àlùfáà. Ẹlẹ́dàá wa tó jẹ́ ọlọgbọ́n dá májẹ̀mú míì, èyí ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pé Jésù yóò di àlùfáà bíi ti Melikisédékì.
16 Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípasẹ̀ Dáfídì Ọba pé Òun máa bá Jésù nìkan dá májẹ̀mú. Májẹ̀mú náà máa jẹ́ alápá méjì. Àkọ́kọ́ ni pé, Jésù máa “jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún” Ọlọ́run níbi tó ti máa láṣẹ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. Èkejì sì ni pé, ó máa “jẹ́ àlùfáà fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì.” (Ka Sáàmù 110:1, 2, 4.) Kí nìdí tó fi jẹ́ “ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì”? Ìdí ni pé tipẹ́tipẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí ni Melikisédékì tó jẹ́ ọba Sálẹ́mù ti jẹ́ “àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ.” (Héb. 7:1-3) Jèhófà fúnra rẹ̀ ló yàn án pé kó máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà. Òun nìkan ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé ó jẹ́ ọba àti àlùfáà. Bákan náà, Bíbélì ò sọ bóyá ẹnì kan wà ṣáájú tàbí lẹ́yìn rẹ̀ tó nírú àǹfààní yẹn, torí náà a lè pè é ní “àlùfáà títí lọ fáàbàdà” tàbí títí láé.
17 Májẹ̀mú tí Jèhófà bá Jésù nìkan dá yìí ló fi yàn án gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, yóò sì “jẹ́ àlùfáà títí láé ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì.” (Héb. 5:4-6) Èyí ṣe kedere pé Jèhófà ti fi àdéhùn fìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé Ìjọba Mèsáyà ni òun máa lò láti mú ohun tí òun ní lọ́kàn ṣẹ fún aráyé.
ÀWỌN MÁJẸ̀MÚ TÓ FÌDÍ ÌJỌBA NÁÀ MÚLẸ̀
18, 19. (a) Kí làwọn májẹ̀mú tá a jíròrò yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba náà? (b) Ìbéèrè wo la ò tíì rí ìdáhùn sí?
18 A ti rí i bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn májẹ̀mú tá a gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣe tan mọ́ Ìjọba Mèsáyà àti bí Ọlọ́run ṣe tipasẹ̀ àdéhùn fìdí Ìjọba náà múlẹ̀. Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe ní ọgbà Édẹ́nì mú kó dájú pé Jèhófà máa lo irú-ọmọ obìnrin náà láti mú ohun tó ní lọ́kàn fún ayé àti ẹ̀dá èèyàn ṣẹ. Ta ni irú-ọmọ náà, iṣẹ́ wo ló sì máa ṣe? Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dà ló pèsè ojútùú sí èyí.
19 Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá jẹ́ ká mọ ìsọfúnni tó ṣe tààràtà nípa ìdílé tí apá àkọ́kọ́ lára irú-ọmọ náà ti máa wá. Májẹ̀mú náà tún jẹ́ kí Jésù ní ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso lé ayé lórí, èyí sì máa jẹ́ kí àwọn ohun tí Ìjọba náà ṣe láṣeparí wà títí láé. Májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pé Jésù yóò di àlùfáà bíi ti Melikisédékì ló fi yan Jésù gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. Àmọ́ o, Jésù nìkan kọ́ ló máa sọ aráyé di pípé. Ọlọ́run yan àwọn míì láti jẹ́ àwọn ọba àti àlùfáà. Ibo ni wọ́n ti máa wá? A máa jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.