Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
Njẹ Farao fẹ Sera, aya Aburahamu nitootọ, gẹgẹ bi o ti farahan ninu itumọ Jẹnẹsisi 12:19 ninu awọn awọn ẹ̀dà itumọ Bibeli kan?
Bẹẹkọ, Farao ni a dí lọwọ lati mu Sera (Serai) gẹgẹ bi aya rẹ̀. Fun idi yii, iyì ati ọla Sera ni a kò fi wọ́lẹ̀.
A ran wa lọwọ lati ri eyi nipa ṣiṣayẹwo ipo naa ninu ọrọ ayika rẹ̀. Ìyàn kan fipa mu Aburahamu (Aburamu) lati wá ibi isadi ni Ijibiti fun igba diẹ. Ó bẹru pe iwalaaye oun yoo wà ninu ewu nibẹ nitori Sera, aya rẹ̀ ti ó lẹ́wà. Aburahamu kò tii bi ọmọkunrin kan sibẹ nipasẹ Sera, nitori naa bi o bá pade iku ni Ijibiti, ila Iru-ọmọ naa ni yoo já, Iru-ọmọ nipasẹ ẹni ti a o bukun gbogbo idile ilẹ-aye. (Jẹnẹsisi 12:1-3) Nitori naa Aburahamu dari Sera lati fi araarẹ han gẹgẹ bi arabinrin oun, nitori pe ọmọbinrin baba rẹ̀ ni nitootọ.—Jẹnẹsisi 12:10-13; 20:12.
Ibẹru rẹ̀ kii ṣe alaini ipilẹ. Ọmọwe August Knobel ṣalaye pe: “Aburamu bẹ Serai lati fi araarẹ han gẹgẹ bi arabinrin rẹ̀ ni Ijibiti ki a ma baa pa á. Bi a bá wò ó gẹgẹ bi abilékọ kan, ọwọ ará Ijibiti kan lè tẹ̀ ẹ́ kiki nipa pípa ọkọ ati olowo-ori rẹ̀; bi a ba wò ó gẹgẹ bi arabinrin kan, ṣiṣeeṣe naa wà pe ki a jere rẹ̀ lati ọdọ arakunrin rẹ̀ ni ọna pẹ̀lẹ́tù.”
Bi o ti wu ki o ri, awọn ọmọ-ọba Ijibiti kò wọnu ìdúnàádúrà pẹlu Aburahamu nipa fifẹ́ ti Farao fẹ́ Sera. Wọn wulẹ mu Sera arẹwa lọ sinu ile Farao ni, alakooso Ijibiti sì fun Aburahamu, ti a lerope o jẹ arakunrin rẹ̀, ni awọn ẹbun. Ṣugbọn tẹle eyi, Jehofa fi ìyọnu ńlá yọ agbo ile Farao lẹnu. Nigba ti ipo tootọ naa di eyi ti a ṣipaya fun Farao ni ọna kan ti a kò sọ, ó sọ fun Aburahamu pe: “Eeṣe ti iwọ fi sọ pe, ‘Arabinrin mi ni oun,’ debi pe emi ti fẹ́ mú un gẹgẹ bi aya mi? Ati nisinsinyi aya rẹ niyi. Mú un ki o si lọ!”—Jẹnẹsisi 12:14-19, NW.
The New English Bible ati awọn itumọ Bibeli miiran tumọ apa ti a kọ wínníwínní ninu ẹsẹ ti o wà loke yii ní “debi pe emi mu un gẹgẹ bi aya kan” tabi ni awọn ọrọ ti o farajọra. Nigba ti kò fi dandan jẹ́ iṣetumọ ti kò tọna, iru awọn ọrọ bẹẹ lè funni ni ero pe Farao ti fẹ́ Sera niti gidi, pe igbeyawo naa jẹ́ otitọ ti a fidii rẹ̀ mulẹ. A lè ṣakiyesi i pe ni Jẹnẹsisi 12:19 ọrọ-iṣe Heberu naa ti a tumọ si “mu” wà ni ipo iṣe ti kò tii pari, eyi ti o fi igbesẹ kan ti kò tii pari han. Bibeli Yoruba tumọ ọrọ-iṣe Heberu yii ni ibamu pẹlu ayika ọrọ ati ni ọna kan ti o fi ipo ọrọ-iṣe yẹn han kedere—bẹẹ ni emi ìbá fẹ́ ẹ ni aya mi.”a Bi o tilẹ jẹ pe Farao ni “ìbá fẹ́” Sera gẹgẹ bi aya, oun kò tii la ọna igbesẹ tabi ayẹyẹ yoowu ti ó lè wémọ ọn kọja.
Aburahamu ni a ti maa ń ṣariwisi rẹ̀ fun ọna ti o gba bojuto ọran naa, ṣugbọn ó gbegbeesẹ nitori ire Iru-ọmọ ileri naa ati nipa bayii nitori gbogbo araye.—Jẹnẹsisi 3:15; 22:17, 18; Galatia 3:16.
Ninu iṣẹlẹ kan ti o farajọra nibi ti ewu ti lè jẹyọ, Isaaki jẹ́ ki aya rẹ̀, Rebeka, yẹra fun sisọ ipo abilékọ rẹ̀. Ni akoko yẹn ọmọkunrin wọn Jakọbu, nipasẹ ẹni ti ila Iru-ọmọ naa yoo ti wá, ni a ti bi ati ni kedere ó jẹ́ ọdọmọkunrin kan. (Jẹnẹsisi 25:20-27; 26:1-11) Laifi eyiini pe, ète isunniṣe ti o wà lẹhin ọgbọn-ẹwẹ ti o duroṣanṣan yii ni o ti lè jẹ́ bakan naa pẹlu ti Aburahamu. Lakooko ìyàn kan Isaaki ati idile rẹ̀ ń gbe ninu ipinlẹ ọba Filisitini ti orukọ rẹ̀ ń jẹ Abimeleki. Bi ó ba mọ pe Rebeka ni aya Isaaki, Abimeleki ìbá ti lé ipa-ọna apaniyan kan lodisi gbogbo iyoku idile Isaaki, eyi ti ìbá ti tumọ si iku fun Jakọbu. Ni ọna yii pẹlu, Jehofa dá si i lati daabobo awọn iranṣẹ rẹ̀ ati ila Iru-ọmọ naa.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Itumọ lati ọwọ J. B. Rotherham (Gẹẹsi) kà pe: “Nitori naa eeṣe ti iwọ fi sọ pe, Arabinrin mi ni; ati nipa bayii emi ti fẹrẹẹ mu un lati jẹ́ aya mi?”