Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì—Apá Kejì
ÌWÉ Jẹ́nẹ́sísì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín egbèjìlá dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n [2,369] ọdún ìtàn ìran èèyàn èyí tó bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí Ọlọ́run dá Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ sí ìgbà ikú Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù. Ẹ̀dà ìwé ìròyìn yìí tó jáde ṣáájú èyí sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìṣẹ̀dá sí ìgbà tí wọ́n kọ́ ilé gogoro Bábélì tí ìtàn nípa rẹ̀ wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní sí orí kẹwàá àti orí kọkànlá ẹsẹ kìíní sí ẹsẹ ìkẹsàn án Jẹ 1:1–11:9.a Àpilẹ̀kọ yìí dá lórí àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àwọn orí yòókù nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, nípa àjọṣe tó wà láàárín Ọlọ́run àti Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù pẹ̀lú Jósẹ́fù.
ÁBÚRÁHÁMÙ DI Ọ̀RẸ́ ỌLỌ́RUN
Ní nǹkan bí àádọ́ta dín nírínwó [350] ọdún lẹ́yìn Ìkún Omi, a bí ọkùnrin kan tó wá di ààyò lójú Ọlọ́run sí ìlà ìdílé Ṣémù ọmọ Nóà. Ábúrámù ni orúkọ rẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá, a yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ábúráhámù. Ọlọ́run ní kí Ábúrámù kúrò ní ìlú Úrì ti ilẹ̀ Kálídíà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ló bá dẹni tó ń gbé nínú àgọ́ ní ilẹ̀ tí Jèhófà sọ pé òun yóò fún òun àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Nítorí tí Ábúráhámù jẹ́ onígbàgbọ́ àti onígbọràn, ó dẹni tá à ń pè ní “ọ̀rẹ́ Jèhófà.”—Jákọ́bù 2:23.
Jèhófà pa àwọn èèyàn búburú tó ń gbé ní Sódómù àtàwọn ìlú tó wà lágbègbè rẹ̀ run, àmọ́ ó dá Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ sí. Ìbí Ísákì ọmọ Ábúráhámù mú ìlérí Ọlọ́run ṣẹ. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà dán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò nígbà tó ní kó fi ọmọ rẹ̀ rúbọ. Ábúráhámù ṣe tán láti fọmọ rẹ̀ rúbọ, àmọ́ áńgẹ́lì kan dá a dúró. Ó dájú pé ẹni ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, a sì mú kó dá a lójú pé nípasẹ̀ irú ọmọ rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò bù kún ara wọn. Ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ Ábúráhámù nígbà tí Sárà aya rẹ̀ ọ̀wọ́n kú.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
12:1-3—Ìgbà wo ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ó sì wà títí dìgbà wo? Májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúrámù dá, pé “gbogbo ìdílé orí ilẹ̀ yóò . . . bù kún ara wọn dájúdájú nípasẹ̀ [Ábúrámù]” bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà tí Ábúrámù sọdá odò Yúfírétì nígbà tó ń lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. Èyí sì ní láti jẹ́ ní Nísàn 14, 1943 ṣááju Sànmánì Tiwa, ìyẹn ọgbọ̀n lé nírínwó [430] ọdún ṣáájú kí a tó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì. (Ẹ́kísódù 12:2, 6, 7, 40, 41) “Májẹ̀mú fún àkókò tí ó lọ kánrin” ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá yìí. Yóò sì wà títí dìgbà tí Ọlọ́run máa bù kún gbogbo ìdílé orí ilẹ̀ ayé tí yóò sì pa gbogbo àwọn ọ̀tá Rẹ̀ run.—Jẹ́nẹ́sísì 17:7; 1 Kọ́ríńtì 15:23-26.
15:13—Ìgbà wo ni irínwó ọdún tá a sọ tẹ́lẹ̀ pé àtọmọdọ́mọ Ábúrámù á fi rí ìpọ́njú parí? Àkókò ìpọ́njú náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1913 ṣááju Sànmánì Tiwa nígbà tí wọ́n já Ísákì ọmọ Ábúráhámù lẹ́nu ọmú ní nǹkan bí ọmọ ọdún márùn ún, tí Íṣímáẹ́lì ọmọ bàbá rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ń fi í “dá àpárá.” (Jẹ́nẹ́sísì 21:8-14; Gálátíà 4:29) Ìgbà tí a dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè lóko ẹrú àwọn ará Íjíbítì ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa ni àkókò ìpọ́njú náà parí.
16:2—Ǹjẹ́ ó tọ̀nà bí Sáráì ṣe fún Ábúrámù ní Hágárì ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ láti fi ṣaya? Ohun tí Sáráì ṣe yìí jẹ́ àṣà wọn láyé ìgbà yẹn, ìyẹn ni pé, ó jẹ́ ọ̀ranyàn fún aya tó bá yàgàn láti wá wáhàrì fún ọkọ rẹ̀ kó bàa lè ní ajogún. Ìlà ìdílé Kéènì ni àṣà ìkóbìnrinjọ ti bẹ̀rẹ̀. Nígbà tó ṣe, àwọn èèyàn wá sọ ọ́ dàṣà láti máa kó obìnrin jọ, àwọn kan nínú àwọn olùjọsìn Jèhófà sì kó àṣà yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 4:17-19; 16:1-3; 29:21-28) Àmọ́ ṣá o, Jèhófà ò fìgbà kan rí fọwọ́ rọ́ ìlànà ọkọ-kan-aya-kan tó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. (Jẹ́nẹ́sísì 2:21, 22) Ó hàn kedere pé oníyàwó kan ṣoṣo ni Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí Ọlọ́run tún àṣẹ náà pa fún pé ‘ẹ máa so èso, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.’ (Jẹ́nẹ́sísì 7:7; 9:1; 2 Pétérù 2:5) Jésù Kristi tún wá tún ìlànà ọkọ-kan-aya-kan yìí sọ.—Mátíù 19:4-8; 1 Tímótì 3:2, 12.
19:8—Ǹjẹ́ ó tọ̀nà kí Lọ́ọ̀tì fi àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ lé àwọn ará Sódómù lọ́wọ́? Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ará Ìlà Oòrùn Ayé, ojúṣe ẹni tó gbàlejò ni láti dáàbò bo àwọn àlejò rẹ̀, kó gbèjà wọn àní dójú ikú pàápàá tó bá jẹ́ pé ohun tọ́ràn náà gbà nìyẹn. Lọ́ọ̀tì ṣe tán láti ṣèyẹn. Ó jáde, ó ti ilẹ̀kùn lẹ́yìn tó jáde, ó sì lọ kojú àwọn èèyànkéèyàn náà lóun nìkan. Nígbà tí Lọ́ọ̀tì sọ pé òun máa fi àwọn ọmọbìnrin òun lé wọn lọ́wọ́, Lọ́ọ̀tì ti ní láti mọ̀ pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run làwọn àlejò náà, ó sì ti ní láti rò ó pé Ọlọ́run lè dáàbò bo àwọn ọmọ òun bó ṣe dáàbò bo Sárà tó jẹ́ aya ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì. (Jẹ́nẹ́sísì 12:17-20) Lóòótọ́, Ọlọ́run sì dáàbò bo Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀.
19:30-38—Ǹjẹ́ Jèhófà fọwọ́ sí mímu tí Lọ́ọ̀tì mutí para tó sì fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì lóyún tí wọ́n fi bímọ fún un? Jèhófà ò fàyè gba ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan àti ìmutípara. (Léfítíkù 18:6, 7, 29; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ó dájú pé inú Lọ́ọ̀tì kò dùn sí “ìṣe àìlófin” àwọn ará Sódómù. (2 Pétérù 2:6-8) Fífún táwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì fún bàbá wọn ní ọtí mu títí tó fi mu àmupara fi hàn pé àwọn ọmọ náà mọ̀ pé bàbá àwọn ò lè jẹ́ lajú rẹ̀ sílẹ̀ kó bá àwọn lò pọ̀ láìjẹ́ pé ó mutí yó. Àmọ́, nítorí pé àtìpó làwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì jẹ́ ní ilẹ̀ náà, wọ́n gbà pé ohun kan ṣoṣo táwọn lè ṣe nìyẹn tí ìdílé Lọ́ọ̀tì ò fi ní run. A kọ ìtàn yìí sínú Bíbélì kí a lè mọ báwọn ará Móábù (nípasẹ̀ Móábù) àtàwọn ọmọ Ámónì (nípasẹ̀ Bẹni-ámì) ṣe bá àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tan.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
13:8, 9. Àpẹẹrẹ rere nípa béèyàn ṣe lè yanjú aáwọ̀ ni Ábúráhámù fi lélẹ̀ yìí o! Ẹ má ṣe jẹ́ ká torí owó tàbí ohun tó wù wá tàbí ẹ̀mí ìgbéraga ba àlááfíà tó wà láàárín wa jẹ́.
15:5, 6. Nígbà tí Ábúráhámù ń darúgbó lọ tí ò sì tíì lọ́mọ kankan, ó bá Ọlọ́run rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn náà. Jèhófà sì fi í lọ́kàn balẹ̀. Kí ló wá yọrí sí? Ábúráhámù “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.” Bí a bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún Jèhófà nínú àdúrà, tá a tẹ́wọ́ gba àwọn ọ̀rọ̀ tí ń fọkàn ẹni balẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, tá a sì ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára sí i.
15:16. Jèhófà dúró kí ìran mẹ́rin kọjá kó tó dá àwọn Ámórì (tàbí àwọn ọmọ Kénáánì) lẹ́jọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé Ọlọ́run tó ní sùúrù ni Jèhófà. Ó mú sùúrù títí tó fi rí i pé àwọn èèyàn náà ò lè yí ìwà wọn padà mọ́. Bíi ti Jèhófà, ó yẹ kí àwa náà máa ní sùúrù.
18:23-33. Jèhófà kì í pa àwọn ẹni rere pọ̀ mọ́ àwọn òṣìkà. Ó máa ń dáàbò bo àwọn olódodo.
19:16. Lọ́ọ̀tì “ń lọ́ra ṣáá,” ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé fífà làwọn áńgẹ́lì náà fa òun àti aya rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ jáde kúrò nílùú Sódómù. Bá a ṣe ń fojú sọ́nà kí ayé burúkú yìí dópin, yóò jẹ́ ìwà ọgbọ́n tí a kò bá dẹra nù.
19:26. Ẹ ò ri pé ìwà òmùgọ̀ gbáà ló máa jẹ́ tá a bá jẹ́ káwọn nǹkan tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn nínú ayé mú wa ní ìpínyà ọkàn tàbí tí ọkàn wa bá ń fà sáwọn nǹkan wọ̀nyẹn!
JÉKỌ́BÙ NÍ ỌMỌKÙNRIN MÉJÌLÁ
Ábúráhámù ṣètò bí Ísákì ṣe máa fi Rèbékà, ìyẹn ọmọbìnrin kan tó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà ṣaya. Rèbékà bí ìbejì, àwọn ni Ísọ̀ àti Jékọ́bù. Ogún ìbí Ísọ̀ kò jámọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀, ló bá tà á fún Jékọ́bù, ẹni tó wá gba ìre lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Jékọ́bù sá lọ sí Padani-árámù, níbi tó ti gbé Léà àti Rákélì níyàwó tó sì fi ogún ọdún tọ́jú agbo ẹran bàbá wọn kó tó wá ṣí kúrò níbẹ̀ tòun ti ìdílé rẹ̀. Léà, Rákélì àtàwọn ìránṣẹ́bìnrin wọn méjèèjì bí ọmọkùnrin méjìlá àti ọmọbìnrin kan fún Jékọ́bù. Jékọ́bù bá áńgẹ́lì kan wọ ìjàkadì, ó rí ìbùkún gbà, a sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ísírẹ́lì.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
28:12, 13—Kí ni ìjẹ́pàtàkì àlá tí Jékọ́bù lá nípa “àkàsọ̀ kan”? “Àkàsọ̀” yìí tó ṣeé ṣe kó rí bí àtẹ̀gùn òkúta fi hàn pé àwọn tó ń bẹ lọ́run àtàwọn tí ń bẹ láyé máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. Báwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣe ń gòkè tí wọ́n ń sọ̀ kalẹ̀ lórí àtẹ̀gùn yìí fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń jíṣẹ́ láwọn ọ̀nà pàtàkì kan láàárín Jèhófà àtàwọn èèyàn tínú rẹ̀ dùn sí.—Jòhánù 1:51.
30:14, 15—Kí nìdí tí Rákélì fi torí èso máńdírékì yááfì àǹfààní tó ní láti sùn ti ọkọ rẹ̀ kó lè lóyún? Ní ayé ìgbàanì, wọ́n máa ń fi èso máńdírékì ṣe oògùn apàrora àti oògùn tó máa ń mú kí iṣan dẹ̀. Wọ́n tún gbà pé èso náà lè mú kí ìbálòpọ̀ máa wu èèyàn àti pé ó lè jẹ́ kéèyàn lè lóyún tàbí kó rí ọmọ bí. (Orin Sólómọ́nì 7:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ohun tó mú kí Rákélì ṣe pàṣípààrọ̀ yìí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Rákélì rò ni pé èso máńdírékì á mú kóun lóyún, kí ẹ̀gàn yíyà tó yàgàn lè kúrò. Bó ti wú kó rí, ó ṣì tó ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà kí Jèhófà tó “ṣí ilé ọlẹ̀ rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 30:22-24.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
25:23. Jèhófà lágbára tó lè fi mọ apilẹ̀ àbùdá oyún inú àtèyí tó lè fi mọ nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú kó sì yan ẹni tóun máa lò láti ṣe àwọn nǹkan tóun fẹ́. Síbẹ̀, kì í dá kádàrá mọ́ ẹnikẹ́ni.—Hóséà 12:3; Róòmù 9:10-12.
25:32, 33; 32:24-29. Àníyàn tí Jékọ́bù ṣe nípa bí yóò ṣe rí ogún ìbí gbà àti ìjàkadì tó bá áńgẹ́lì kan wọ̀ ní òru mọ́jú kó bàa lè rí ìbùkún gbà fi hàn pé ó mọyì àwọn nǹkan tó jẹ́ mímọ́. Jèhófà ti fi ọ̀pọ̀ nǹkan tó jẹ́ mímọ́ sí ìkáwọ́ wa, irú bí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú òun àti ètò àjọ rẹ̀, ìràpadà náà, Bíbélì àti Ìjọba Ọlọ́run tá à ń retí. Ǹjẹ́ kí a ṣe bíi ti Jékọ́bù, ká máa fi hàn pé a mọrírì nǹkan wọ̀nyẹn.
34:1, 30. Ohun tó fa wàhálà tó “mú ìtanùlẹ́gbẹ́” wá sórí Jékọ́bù ni lílọ tí Dínà lọ bá àwọn èèyàn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́. Kò yẹ ká máa kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́.
JÈHÓFÀ BÙ KÚN JÓSẸ́FÙ NÍ ÍJÍBÍTÌ
Owú jíjẹ ló sún àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù ta Jósẹ́fù àbúrò wọn sóko ẹrú. Jósẹ́fù lọ ṣẹ́wọ̀n nílẹ̀ Íjíbítì nítorí fífi tó fi ìṣòtítọ́ àti ìgboyà rọ̀ mọ́ ìlànà ìwà rere tí Ọlọ́run là kalẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n mú un jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n pé kó wá túmọ̀ àlá tí Fáráò lá, èyí tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé oúnjẹ á pọ̀ rẹpẹtẹ ní ọdún méje àkọ́kọ́, àmọ́ ìyàn á mú ní ọdún méje tí yóò tẹ̀ lé e. Wọ́n wá fi Jósẹ́fù ṣe alákòóso oúnjẹ ní Íjíbítì. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wá oúnjẹ lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì nítorí ìyàn náà. Ìdílé wọn tún padà wà pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n sì wá tẹ̀ dó sí Góṣénì tó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá. Kí Jékọ́bù tó gbẹ́mìí mì, ó súre fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó mú kó dájú hán-ún pé ìbùkún yàbùgà-yabuga ń bẹ lọ́jọ́ iwájú. Wọ́n gbé òkú Jékọ́bù lọ sin sí ilẹ̀ Kénáánì. Nígbà tí Jósẹ́fù kú ní ẹni àádọ́fà ọdún, wọ́n kun òkú rẹ̀ lọ́ṣẹ, wọ́n wá gbé e lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.—Ẹ́kísódù 13:19.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
43:32—Èé ṣe táwọn ará Íjíbítì fi kà á sóhun ìríra láti bá àwọn Hébérù jẹun? Lájorí ohun tó fà á lè jẹ́ nítorí ẹ̀tanú ìsìn tàbí nítorí ẹ̀mí ẹ̀yà-tèmi-lọ̀gá tí wọ́n ní. Àwọn ará Íjíbítì kórìíra àwọn olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú. (Jẹ́nẹ́sísì 46:34) Kí ló fà á? Ó lè jẹ́ nítorí pé ipò àwọn olùsọ́ àgùntàn rẹlẹ̀ láwùjọ ní ilẹ̀ Íjíbítì. Tàbí kẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ sí fáwọn èèyàn láti dáko, èyí mú káwọn ará Íjíbítì fojú ẹ̀gàn wo àwọn tí wọ́n ń wá pápá tí wọ́n á ti máa da ẹran.
44:5—Ṣé lóòótọ́ ni Jósẹ́fù máa ń lo ife láti fi mọ àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀? Ó dájú pé, ọgbọ́n arúmọjẹ ni wọ́n fi ife fàdákà yìí àtohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ dá. Jósẹ́fù jẹ́ ẹnì kan tó ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà. Kì í ṣe pé ó ń lo ife láti fi mọ àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀, ńṣe lọ̀ràn náà rí bíi ti Bẹ́ńjámínì tí kì í ṣe pé ó jalè lóòótọ́.
49:10—Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ọ̀pá aládé” àti “ọ̀pá àṣẹ” túmọ̀ sí? Ọ̀pá aládé ni ọ̀pá kúkúrú táwọn alákòóso máa ń mú dání tó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọba aláṣẹ ni wọ́n. Ọ̀pá àṣẹ ni ọ̀pá gbọọrọ tó fi hàn pé wọ́n lágbára láti pàṣẹ. Pé Jékọ́bù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀pá yìí fi hàn pé àṣẹ àti agbára yóò wà lọ́wọ́ ẹ̀yà Júdà títí dìgbà tí Ṣílò yóò dé. Jésù Kristi ni àtọmọdọ́mọ Júdà yìí, òun ni Jèhófà gbé ìjọba ọ̀run lé lọ́wọ́. Ọba aláṣẹ ni Kristi, ó lágbára láti pàṣẹ.—Sáàmù 2:8, 9; Aísáyà 55:4; Dáníẹ́lì 7:13, 14.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
38:26. Júdà jẹ̀bi ìwà tó hù sí Támárì aya ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ opó. Àmọ́ nígbà tí wọ́n sọ fún Júdà pé òun ló ni oyún inú obìnrin náà, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé òun ti ṣe àṣìṣe. Ó yẹ kí àwa náà tètè máa gba àṣìṣe wa.
39:9. Èsì tí Jósẹ́fù fún aya Pọ́tífárì fi hàn pé Jósẹ́fù mọ èrò Ọlọ́run nípa ìwà tó dára àti pé àwọn ìlànà Ọlọ́run ló ń darí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀ bí ìmọ̀ pípéye tá a ní nípa òtítọ́ tí túbọ̀ ń pọ̀ sí i?
41:14-16, 39, 40. Jèhófà lè yí ipò nǹkan padà fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀. Nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, yóò jẹ́ ìwà ọgbọ́n ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká sì máa bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́ sí i.
Wọ́n Ní Ìgbàgbọ́ Tí Kò Yẹ̀
Ẹni ìgbàgbọ́ tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù àti Jósẹ́fù. Ìtàn ìgbésí ayé wọn tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ohun tó lè mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára sí i, ó sì kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ púpọ̀ tó ṣàǹfààní.
O lè jàǹfààní nínú ìtàn yìí bó o ṣe ń ka Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Gbígbé àwọn ìtàn yìí yẹ̀ wò yóò mú kí ìtàn náà dà bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì—Apá Kìíní” nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2004.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Jèhófà bù kún Jósẹ́fù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ẹni ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọlọ́run dá Lọ́ọ̀tì olódodo àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ sí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Jékọ́bù mọyì àwọn nǹkan tó jẹ́ mímọ́. Ǹjẹ́ o mọyì rẹ̀?