“Nípa Ìgbàgbọ́ Ni Àwa Ń Rìn, Kì Í Ṣe Nípa Ohun Tí A Rí”
“Nípa ìgbàgbọ́ ni àwa ń rìn, kì í ṣe nípa ohun tí a rí.”—KỌ́RÍŃTÌ KEJÌ 5:7.
1. Kí ni ‘rírìn nípa ìgbàgbọ́’ túmọ̀ sí?
GBOGBO ìgbà tí a bá ń gbàdúrà ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni tí a là sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ń fi hàn pé, ó kéré tán, a ní ìwọ̀n ìgbàgbọ́ díẹ̀. A tún ń fi ìgbàgbọ́ hàn nígbà tí a bá ń jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tí a sì ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a ń fẹ̀rí hàn pé ìfẹ́ inú wa ni láti ‘rìn nípa ìgbàgbọ́,’ ìyẹn ni pé, láti lépa ọ̀nà ìgbésí ayé tí ìgbàgbọ́ ń ṣàkóso.—Kọ́ríńtì Kejì 5:7; Kólósè 1:9, 10.
2. Èé ṣe tí kíkópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ kò fi dandan jẹ́ ẹ̀rí pé ẹnì kan ní ìgbàgbọ́?
2 Bí a óò bá gbé ìgbésí ayé ní irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́, a nílò ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. (Hébérù 11:1, 6) Ọ̀pọ̀ ènìyàn fà mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ní ti ìwà híhù àti ìfẹ́ tí wọ́n rí láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí. Ìgbésẹ̀ yẹn dára, ṣùgbọ́n kò túmọ̀ sí pé irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ní ìgbàgbọ́. Àwọn mìíràn lè ní alábàá-ṣègbéyàwó tàbí òbí tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú hánhán, wọ́n sì lè nípìn-ín nínú díẹ̀ lára àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tí ẹni tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ yẹn ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Níní irú ipa bẹ́ẹ̀ lórí ilé ẹni jẹ́ ìbùkún kan ní tòótọ́, ṣùgbọ́n èyí pẹ̀lú kò dípò ìfẹ́ tí ẹnì kan ní láti ní fún Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ tí ó ní láti lò nínú rẹ̀.—Lúùkù 10:27, 28.
3. (a) Fún wa láti ní ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ìdánilójú wo ni àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ní láti ní nípa Bíbélì? (b) Èé ṣe tí àwọn ènìyàn kan fi ń tètè gbà gbọ́ dájú pé Bíbélì jẹ́ ìwé tí a mí sí ju àwọn ẹlòmíràn lọ?
3 Àwọn tí ń rìn nípa ìgbàgbọ́ ní tòótọ́ ní ìdánilójú hán-únhán-ún pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ yanturu ẹ̀rí wà pé “Ọlọ́run mí sí” Ìwé Mímọ́ ni tòótọ́.a (Tímótì Kejì 3:16) Mélòó nínú ẹ̀rí yìí ni a gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò kí ẹnì kan tó lè ní ìdánilójú? Ìyẹn lè sinmi lórí ipò àtilẹ̀wá rẹ̀. Ohun tí yóò mú ẹnì kan gbà gbọ́ pátápátá lè ṣàìyí ẹlòmíràn lérò pa dà rárá. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, bí a bá tilẹ̀ fi ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro han ẹnì kan, síbẹ̀, ó ṣì lè kọ ìparí èrò tí ẹ̀rí náà ń tọ́ka sí. Èé ṣe? Nítorí àwọn ìfẹ́ ọkàn jíjinlẹ̀ tí ó wà ní inú rẹ̀ lọ́hùn-ún. (Jeremáyà 17:9) Nípa báyìí, bí ẹnì kan tilẹ̀ lè sọ pé òun ní ọkàn ìfẹ́ nínú ète Ọlọ́run, ọkàn àyà rẹ̀ lè máa yán hànhàn fún ojú rere àwọn ènìyàn ayé. Ó lè máà fẹ́ fi ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó ta ko àwọn ìlànà Bíbélì sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí ebi òtítọ́ bá ń pa ẹnì kan ní tòótọ́, bí kò bá tan ara rẹ̀ jẹ, bí ó bá sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kì yóò pẹ́ tí yóò fi rí i pé, Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
4. Kí ní ń béèrè níhà ọ̀dọ̀ ẹnì kan láti lè ní ìgbàgbọ́?
4 Lọ́pọ̀ ìgbà, láàárín oṣù díẹ̀ péré, àwọn tí a ń ràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń mọ̀ pé àwọn ti rí ìdí tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ tó pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí èyí bá sún wọn láti ṣí ọkàn àyà wọn payá láti jẹ́ kí Jèhófà kọ́ wọn, nígbà náà, àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ yóò máa darí èrò inú wọn lọ́hùn-ún, ìfẹ́ ọkàn wọn, àti ìsúnniṣe wọn ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. (Orin Dáfídì 143:10) Róòmù 10:10 sọ pé “ọkàn àyà ni” ẹnì kan fi ń lo ìgbàgbọ́. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ń fi bí ẹni náà ṣe ń ronú gan-an nínú lọ́hùn-ún hàn, yóò sì fara hàn gbangba nínú ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀.
Nóà Ṣiṣẹ́ Lórí Ìgbàgbọ́ Tí Ó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin
5, 6. Orí kí ni Nóà gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kà?
5 Nóà jẹ́ ẹnì kan tí ó ní ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. (Hébérù 11:7) Kí ni ó gbé e kà? Nóà ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe èyí tí a kọ sílẹ̀, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ fún un. Jẹ́nẹ́sísì 6:13 wí pé: “Ọlọ́run . . . wí fún Nóà pé, Òpin gbogbo ènìyàn dé iwájú mi; nítorí tí ayé kún fún ìwà agbára láti ọwọ́ wọn.” Jèhófà pàṣẹ fún Nóà láti kan áàkì kan, ó sì pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí yóò ṣe kàn án. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run fi kún un pé: “Àti èmi, wò ó, èmi ń mú kíkún omi bọ̀ wá sí ayé, láti pa gbogbo ohun alààyè run, tí ó ní ẹ̀mí ààyè nínú kúrò lábẹ́ ọ̀run; ohun gbogbo tí ó wà ní ayé ni yóò sì kú.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:14-17.
6 Òjò ha ti rọ̀ rí ṣáájú àkókò yí bí? Bíbélì kò sọ. Jẹ́nẹ́sísì 2:5 sọ pé: “OLÚWA Ọlọ́run kò ṣáà tí ì rọ̀jò sí ilẹ̀.” Ṣùgbọ́n ọ̀nà tí Mósè, tí ó gbé ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ nìyí nígbà tí ó sọ nípa àkókò gígùn ṣáájú ọjọ́ Nóà, kì í ṣe nípa ọjọ́ Nóà. Gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn ní Jẹ́nẹ́sísì 7:4, Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa òjò nígbà tí ó ń bá Nóà sọ̀rọ̀, ó sì hàn gbangba pé Nóà lóye ohun tí ó ní lọ́kàn. Síbẹ̀, Nóà kò fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ sínú ohun tí ó lè rí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, a “fún [Nóà] ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tí ì rí.” Ọlọ́run sọ fún Nóà pé Òun yóò mú “àkúnya omi,” tàbí “ibú omi ọ̀run,” gẹ́gẹ́ bí àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé nínú Bíbélì New World Translation ṣe sọ ọ́ nínú Jẹ́nẹ́sísì 6:17, wá sórí ilẹ̀ ayé. Títí di àkókò yẹn, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n gbogbo ìṣẹ̀dá tí Nóà lè fojú rí jẹ́ ẹ̀rí tí ó hàn gbangba gbàǹgbà fún un pé Ọlọ́run lè mú irú àkúnya tí ń ṣèparun bẹ́ẹ̀ wá ní ti gidi. Níwọ̀n bí ìgbàgbọ́ ti sún un ṣiṣẹ́, Nóà kan áàkì náà.
7. (a) Kí ni Nóà kò nílò láti lè ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún un? (b) Báwo ni gbígbé ìgbàgbọ́ Nóà yẹ̀ wò ṣe ṣe wá láǹfààní, báwo sì ni ìgbàgbọ́ tiwa ṣe lè jẹ́ ìbùkún fún àwọn ẹlòmíràn?
7 Ọlọ́run kò tí ì sọ ọjọ́ tí Àkúnya náà yóò bẹ̀rẹ̀ fún Nóà. Ṣùgbọ́n Nóà kò lo ìyẹn gẹ́gẹ́ bí àwíjàre fún níní ìṣarasíhùwà ká-ṣì-máa-wò-ó-ná, ní fífi kíkan áàkì àti wíwàásù sí ipò kejì nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ní àkókò tí ó pọ̀ tó, Ọlọ́run sọ ìgbà tí Nóà yóò wọnú áàkì náà fún un. Láàárín àkókò náà, “Nóà . . . bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe gẹ́gẹ́ bíi gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:22, NW) Nóà rìn nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa ohun tí ó rí. Ẹ wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó pé òun ṣe bẹ́ẹ̀! Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀, a wà láàyè lónìí. Ní tiwa pẹ̀lú, ìgbàgbọ́ tí a bá fi hàn lè ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ohun tí ọjọ́ ọ̀la ní ní ìpamọ́ fún wa, kì í ṣe fún àwa nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn ọmọ wa àti fún àwọn ẹlòmíràn tí ó wà láyìíká wa pẹ̀lú.
Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù
8, 9. (a) Orí kí ni Ábúráhámù gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kà? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà “fara han” Ábúráhámù?
8 Ẹ gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò—ìyẹn ni ti Ábúráhámù. (Hébérù 11:8-10) Kí ni Ábúráhámù gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kà? Àgbègbè tí òun ti dàgbà ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà kún fún ìbọ̀rìṣà àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì. Ṣùgbọ́n, àwọn ohun mìíràn nípa lórí ojú ìwòye Ábúráhámù. Kò sí iyè méjì pé ó lè bá Ṣémù, ọmọkùnrin Nóà kẹ́gbẹ́, ẹni tí ó ṣì lo 150 ọdún láyé lẹ́yìn tí a bí Ábúráhámù. Ábúráhámù gbà gbọ́ dájú pé, Jèhófà ni “Ọlọ́run ọ̀gá ògo, tí ó ni ọ̀run òun ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 14:22.
9 Ohun mìíràn ní ipa jíjinlẹ̀ lórí Ábúráhámù. Jèhófà “fara han Ábúráhámù . . . nígbà tí ó wà ní Mesopotámíà, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní Háránì, ó sì wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ kí o sì wá sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.’” (Ìṣe 7:2, 3) Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà “fara han” Ábúráhámù? Ábúráhámù kò rí Ọlọ́run lójúkojú. (Ẹ́kísódù 33:20) Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kí Jèhófà ti fara han Ábúráhámù nínú àlá, nípa ìfihàn ògo tí ó ré kọjá agbára ẹ̀dá, tàbí nípasẹ̀ áńgẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀, tàbí aṣojú rẹ̀. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 18:1-3; 28:10-15; Léfítíkù 9:4, 6, 23, 24.) Ọ̀nà yòó wù kí Jèhófà gbà fara han Ábúráhámù, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ yẹn ní ìgbọ́kànlé pé àǹfààní ṣíṣeyebíye kan ni Ọlọ́run ń gbé ka iwájú òun. Ábúráhámù fi ìgbàgbọ́ hùwà pa dà.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe fún ìgbàgbọ́ Ábúráhámù lókun?
10 Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù kò sinmi lórí pé kí ó mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ilẹ̀ tí Ọlọ́run ń darí rẹ̀ sí. Kò sinmi lórí pé kí ó mọ ìgbà tí a óò fún un ní ilẹ̀ náà. Ó ní ìgbàgbọ́ nítorí tí ó mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Olódùmarè. (Ẹ́kísódù 6:3) Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé yóò bímọ, ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, Ábúráhámù ṣe kàyéfì bí ìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe. Ó ti ń di arúgbó. (Jẹ́nẹ́sísì 15:3, 4) Jèhófà fún ìgbàgbọ́ Ábúráhámù lókun nípa sísọ fún un pé kí ó wo àwọn ìràwọ̀ lókè, kí ó sì ka iye wọn bí ó bá lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni irú ọmọ rẹ yóò rí.” Èyí wú Ábúráhámù lórí gidigidi. Ó ṣe kedere pé Ẹlẹ́dàá àwọn ohun amúnikúnfún-ẹ̀rù, tí ń bẹ lójú ọ̀run wọ̀nyẹn, lè mú ohun tí ó ti ṣèlérí ṣẹ. Ábúráhámù “gba OLÚWA gbọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:5, 6) Ábúráhámù kò wulẹ̀ gbà gbọ́ nítorí pé ohun tí ó ń gbọ́ dùn mọ́ ọn; ó ní ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.
11. (a) Bí ó ti ń súnmọ́ ẹni 100 ọdún, báwo ni Ábúráhámù ṣe dáhùn pa dà sí ìlérí Ọlọ́run pé Sárà arúgbó yóò bí ọmọkùnrin kan? (b) Irú ìgbàgbọ́ wo ni Ábúráhámù fi kojú ìdánwò tí ó ní í ṣe pẹ̀lú mímú ọmọkùnrin rẹ̀ lọ sí Òkè Mòráyà láti lọ fi rúbọ?
11 Nígbà tí Ábúráhámù fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni 100 ọdún, tí ìyàwó rẹ̀, Sárà, sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni 90 ọdún, Jèhófà tún sọ ìlérí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i pé, Ábúráhámù yóò ní ọmọkùnrin kan, Sárà ni yóò sì jẹ́ ìyá rẹ̀. Ábúráhámù ronú nípa ipò wọn ní ti gidi. “Ṣùgbọ́n nítorí ìlérí Ọlọ́run òun kò mikàn nínú àìnígbàgbọ́, ṣùgbọ́n ó di alágbára nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó ń fi ògo fún Ọlọ́run ó sì gbà gbọ́ dájú ní kíkún pé ohun tí ó ti ṣèlérí ni ó lè ṣe pẹ̀lú.” (Róòmù 4:19-21) Ábúráhámù mọ̀ pé ìlérí Ọlọ́run kò lè kùnà. Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀, Ábúráhámù lẹ́yìn ìgbà náà ṣègbọràn nígbà tí Ọlọ́run sọ fún un láti mú Aísíìkì, ọmọkùnrin rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Mòráyà, kí ó sì fi rúbọ. (Jẹ́nẹ́sísì 22:1-12) Ábúráhámù ní ìgbọ́kànlé kíkún pé, Ọlọ́run tí ó lè mú kí a bí ọmọ náà lọ́nà ìyanu lè tún mú un pa dà wá sí ìyè láti lè mú kí àwọn ìlérí mìíràn tí Òun ti ṣe, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọmọkùnrin náà ní ìmúṣẹ.—Hébérù 11:17-19.
12. Títí di ìgbà wo ni Ábúráhámù fi ń bá a lọ láti rìn nípa ìgbàgbọ́, èrè wo sì ni ó ń dúró de òun àti àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ tí ó fi ìgbàgbọ́ lílágbára hàn?
12 Ábúráhámù fi hàn pé kì í ṣe ní àwọn àkókò kan pàtó ni ìgbàgbọ́ ń darí òun, ṣùgbọ́n jálẹ̀ ìgbésí ayé òun. Nígbà tí ó fi wà láàyè, Ábúráhámù kò rí apá èyíkéyìí lára Ilẹ̀ Ìlérí náà gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ogún. (Ìṣe 7:5) Síbẹ̀, Ábúráhámù kò káàárẹ̀, kí ó sì pa dà sí Úrì ti àwọn ará Kálídíà. Fún 100 ọdún, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, ó gbé nínú àwọn àgọ́ ní ilẹ̀ tí Ọlọ́run darí rẹ̀ sí. (Jẹ́nẹ́sísì 25:7) Ní ti òun àti Sárà, aya rẹ̀, ọmọkùnrin wọn Aísíìkì, àti ọmọ ọmọ wọn Jékọ́bù, Hébérù 11:16 wí pé: “Wọn kò ti Ọlọ́run lójú, pé kí a máa ké pè é gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wọn, nítorí tí ó ti pèsè ìlú ńlá kan sílẹ̀ fún wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ní ibì kan fún wọn ní àgbègbè ilẹ̀ ayé ti Ìjọba Mèsáyà rẹ̀.
13. Àwọn wo lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí ni ó fẹ̀rí hàn pé àwọn ní irú ìgbàgbọ́ bíi ti Ábúráhámù?
13 Àwọn kan wà lára àwọn ènìyàn Jèhófà lónìí tí wọ́n dà bí Ábúráhámù. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n ti rìn nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. Nínú okun tí Ọlọ́run ń fúnni, wọ́n ti borí àwọn ìṣòro tí ó dà bí òkè. (Mátíù 17:20) Wọn kò tìtorí pé wọn kò mọ ìgbà náà gan-an tí Ọlọ́run yóò fún wọn ní ogún tí ó ti ṣèlérí kí wọ́n mikàn nínú ìgbàgbọ́. Wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jèhófà kò lè kùnà, wọ́n sì ka wíwà lára Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ sí àǹfààní ṣíṣeyebíye. Ṣé bí ìwọ náà ṣe nímọ̀lára nìyẹn?
Ìgbàgbọ́ Tí Ó Sún Mósè Ṣiṣẹ́
14. Báwo ni a ṣe fi ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ Mósè lélẹ̀?
14 Mósè jẹ́ àpẹẹrẹ mìíràn ní ti ìgbàgbọ́. Kí ni ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀? A fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ nígbà tí ó wà ní ọmọdé jòjòló. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin Fáráò rí Mósè nínú àpótí kan tí a fi òrépèté hun ní etí Odò Náílì, tí ó sì fi í ṣe ọmọ rẹ̀, Jókébédì, ìyá Mósè gan-an tí ó jẹ́ Hébérù ni ó tọ́jú ọmọdékùnrin náà, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ó sì gbé ní ìgbà ọmọdé. Ó ṣe kedere pé Jókébédì kọ́ ọ dáradára, ní gbígbin ìfẹ́ fún Jèhófà àti ìmọrírì fún àwọn ìlérí tí Ó ti ṣe fún Ábúráhámù sí i lọ́kàn. Lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà agboolé Fáráò, a “fún [Mósè] ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì.” (Ìṣe 7:20-22; Ẹ́kísódù 2:1-10; 6:20; Hébérù 11:23) Síbẹ̀, láìka ipò aláǹfààní tí ó wà sí, ọkàn Mósè wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí a ti sọ di ẹrú.
15. Kí ni kíka ara rẹ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Jèhófà túmọ̀ sí fún Mósè?
15 Nígbà tí ó di ẹni 40 ọdún, Mósè pa ará Íjíbítì kan láti gba ọmọ Ísírẹ́lì kan tí a bá lò lọ́nà tí kò tọ́ sílẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ yí fi ojú tí Mósè fi wo àwọn ènìyàn Ọlọ́run hàn. Ní ti gidi, “nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí ó dàgbà, kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ọmọbìnrin Fáráò.” Dípò rírọ̀mọ́ “jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀” gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà ìdílé ọba Íjíbítì, ìgbàgbọ́ sún un láti jẹ́ kí a mọ òun gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí a ń bá lò lọ́nà tí kò tọ́.—Hébérù 11:24, 25; Ìṣe 7:23-25.
16. (a) Iṣẹ́ wo ni Jèhófà fún Mósè láti ṣe, báwo sì ni Ọlọ́run ṣe ràn án lọ́wọ́? (b) Ní mímú iṣẹ́ rẹ̀ ṣe, báwo ni Mósè ṣe fi ìgbàgbọ́ hàn?
16 Mósè hára gàgà láti gbé ìgbésẹ̀ láti mú ìtura bá àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n àkókò Ọlọ́run láti dá wọn nídè kò tí ì tó. Mósè ní láti sá kúrò ní Íjíbítì. Ó tó 40 ọdún lẹ́yìn náà kí Jèhófà, nípasẹ̀ áńgẹ́lì kan, tó pàṣẹ fún Mósè láti pa dà sí Íjíbítì láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní ilẹ̀ yẹn. (Ẹ́kísódù 3:2-10) Báwo ni Mósè ṣe hùwà pa dà? Òun kò ṣiyè méjì nípa agbára tí Jèhófà ní láti dá Ísírẹ́lì nídè, ṣùgbọ́n ó ronú pé òun kò tóótun fún iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé ka òun níwájú. Lọ́nà onífẹ̀ẹ́, Jèhófà pèsè ìṣírí tí Mósè nílò. (Ẹ́kísódù 3:11–4:17) Ìgbàgbọ́ Mósè lágbára sí i. Ó pa dà sí Íjíbítì, ó sì kìlọ̀ fún Fáráò lójúkojú léraléra nípa ìyọnu tí yóò wá sórí Íjíbítì nítorí pé alákòóso náà kọ̀ láti jẹ́ kí Ísírẹ́lì lọ jọ́sìn Jèhófà. Mósè kò dá agbára kan ní láti fa àwọn ìyọnu wọ̀nyẹn. Ó rìn nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa ohun tí ó rí. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ wà nínú Jèhófà àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Fáráò halẹ̀ mọ́ Mósè. Ṣùgbọ́n Mósè dúró gangan nínú ìgbàgbọ́. “Nípa ìgbàgbọ́ ni ó fi Íjíbítì sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò bẹ̀rù ìbínú ọba, nítorí tí ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni náà tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:27) Mósè kì í ṣe ẹni pípé. Ó ṣe àṣìṣe. (Númérì 20:7-12) Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti yan iṣẹ́ fún un, ìgbàgbọ́ darí gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀.
17. Kí ni rírìn nípa ìgbàgbọ́ yọrí sí fún Nóà, Ábúráhámù, àti Mósè, àní bí ayé tuntun Ọlọ́run kò tilẹ̀ ṣe ojú wọn?
17 Ǹjẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ dà bíi ti Nóà, Ábúráhámù, àti Mósè. Òtítọ́ ni pé wọn kò rí ayé tuntun Ọlọ́run ní ọjọ́ wọn. (Hébérù 11:39) Àkókò tí Ọlọ́run yàn kò tí ì tó; àwọn apá mìíràn ṣì wà nínú ète rẹ̀ tí ó ṣì ní láti mú ṣẹ. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò mì, orúkọ wọn sì wà nínú ìwé ìyè Ọlọ́run.
18. Fún àwọn tí a pè sí ìyè ti ọ̀run, èé ṣe tí ó fi pọn dandan láti rìn nípa ìgbàgbọ́?
18 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run ti rí ohun dídára jù kan tẹ́lẹ̀ fún wa.” Ìyẹn ni pé, Ọlọ́run rí ohun dídára jù kan fún àwọn tí a ti pè sí ìyè ti ọ̀run pẹ̀lú Kristi, gẹ́gẹ́ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (Hébérù 11:40) Àwọn wọ̀nyí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ní pàtàkì nígbà tí ó fi kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú Kọ́ríńtì Kejì 5:7 pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni àwa ń rìn, kì í ṣe nípa ohun tí a rí.” Nígbà tí ó fi kọ ọ̀rọ̀ yẹn, kò sí èyíkéyìí lára wọn tí ó tí ì rí èrè wọn ti ọ̀run gbà. Wọn kò lè fi ojúyòójú wọn rí i, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. A ti jí Kristi dìde kúrò nínú òkú, àkọ́so èso nínú àwọn tí a óò fi ìyè ti ọ̀run jíǹkí. Àwọn tí ó sì fojú rí i kí ó tó gòkè re ọ̀run lé ní 500. (Kọ́ríńtì Kíní 15:3-8) Wọ́n ní ìdí púpọ̀ láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ yẹn darí gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé wọn. Àwa pẹ̀lú ní ìdí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún rírìn nípa ìgbàgbọ́.
19. Bí a ti fi hàn nínú Hébérù 1:1, 2, nípasẹ̀ ta ni Ọlọ́run ti bá wa sọ̀rọ̀?
19 Lónìí, Jèhófà kì í bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ áńgẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún Mósè níbi tí igbó ti ń jó. Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀. (Hébérù 1:1, 2) Ohun tí Ọlọ́run sọ nípasẹ̀ rẹ̀, Ó ti mú kí a kọ ọ́ sínú Bíbélì, ti a ti tú sí àwọn èdè tí àwọn ènìyàn yí ká ayé ń sọ.
20. Lọ́nà wo ni ipò wa fi dára lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ti Nóà, Ábúráhámù, àti Mósè?
20 A ní púpọ̀ ju Nóà, Ábúráhámù, tàbí Mósè lọ. A ní odindi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ sì ti ní ìmúṣẹ. Lójú ìwòye gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí tòótọ́ fún Jèhófà lójú onírúurú àdánwò, Hébérù 12:1 rọni pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.” Ìgbàgbọ́ wa kì í ṣe ohun tí a ní láti fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ mú. Àìnígbàgbọ́ ni “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” Ó ń béèrè ìjà líle bí a óò bá máa bá a lọ ní ‘rírìn nípa ìgbàgbọ́.’
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo The Bible—God’s Word or Man’s?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Kí ni ‘rírìn nípa ìgbàgbọ́’ ní nínú?
◻ Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní nínú ọ̀nà tí Nóà gbà fi ìgbàgbọ́ hàn?
◻ Báwo ni ọ̀nà tí Ábúráhámù gbà lo ìgbàgbọ́ ṣe ràn wá lọ́wọ́?
◻ Èé ṣe tí Bíbélì fi tọ́ka sí Mósè gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ábúráhámù rìn nípa ìgbàgbọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Mósè àti Áárónì fi ìgbàgbọ́ hàn nígbà tí wọ́n wà níwájú Fáráò