Ìṣẹ̀dá Ń polongo Ògo Ọlọ́run!
“Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”—SÁÀMÙ 19:1.
1, 2. (a) Kí nìdí tí ẹ̀dá èèyàn ò fi lè rí ògo Ọlọ́run ní tààràtà? (b) Báwo làwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ṣe ń fi ògo fún Ọlọ́run?
“ÌWỌ kò lè rí ojú mi, nítorí pé kò sí ènìyàn tí ó lè rí mi kí ó sì wà láàyè síbẹ̀.” (Ẹ́kísódù 33:20) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jèhófà lò láti fi kìlọ̀ fún Mósè. Nítorí pé ẹlẹ́ran ara ni èèyàn, wọn ò lẹ́mìí rẹ̀ rárá láti fi ojúyòòjú wo ògo Ọlọ́run ní tààràtà. Àmọ́, a fi ìran kan tó jẹ́ àrímáleèlọ nípa bí Jèhófà ṣe rí lórí ìtẹ́ Rẹ̀ ológo han àpọ́sítélì Jòhánù.—Ìṣípayá 4:1-3.
2 Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwa ẹ̀dá èèyàn, àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ adúróṣinṣin lè rí ojú Jèhófà ní tiwọn. Lára wọn ni “àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún” tí Jòhánù rí nínú ìran ọ̀run tá a fi hàn án, àwọn wọ̀nyí wọ́n dúró fún ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. (Ìṣípayá 4:4; 14:1-3) Ọ̀rọ̀ wo ni ó ti ẹnu wọn jáde nígbà tí wọ́n rí ògo Ọlọ́run? Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 4:11 ti wí, wọ́n polongo pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”
Ìdí Tí Wọn Kò Fi “Ní Àwíjàre”
3, 4. (a) Kì nìdí tí gbígbà pé Ọlọ́run wà kì í fi í ṣe ohun tí kò bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu? (b) Nígbà mìíràn, kí nìdí táwọn èèyàn kan máa fi ń sọ pé Ọlọ́run kò sí?
3 Ǹjẹ́ kì í wu ìwọ náà láti fi ògo fún Ọlọ́run? Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn ni kì í wù láti ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn kan ò tiẹ̀ gbà pé Ọlọ́run wà rárá. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà kọ̀wé pé: “Ṣé Ọlọ́run ló gbé ìgbésẹ̀ tó sì fara balẹ̀ ṣẹ̀dá ayé òun ìsálú ọ̀run fún àǹfààní wa? . . . Èrò tó ga nìyẹn. Àmọ́ ẹ̀tàn pátápátá ni mo ka ìyẹn sí o. . . . Mi ò gbà pé Ọlọ́run ló ṣe é.”
4 Ìwọ̀nba ni ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣe lórí ọ̀ràn yìí, ìwádìí wọn ò lè kọjá ohun téèyàn lé fojú rí tàbí èyí téèyàn lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóò wulẹ̀ jẹ́ àbá èrò orí tàbí ìméfò lásán. Nítorí pé “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,” kò sí béèyàn ṣe lè fi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lásán wádìí rẹ̀. (Jòhánù 4:24) Nítorí náà, ìgbéraga ló jẹ́ láti sọ pé gbígbàgbọ́ pe Ọlọ́run wà kì í ṣe ohun tó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Vincent Wigglesworth láti Yunifásítì Cambridge sọ pé ìlànà sáyẹ́ǹsì pàápàá “ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́.” Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? “Ó gba pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára láti lè gbà pé [àwọn nǹkan ìṣẹ̀dá bíi òjò àti ìsẹ̀lẹ̀] ń tẹ̀ lé ‘ìlànà.’” Nítorí náà, nígbà tẹ́nì kan bá sọ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà, ṣé kì í ṣe pé onítọ̀hún wulẹ̀ ń fi ìgbàgbọ́ kan pààrọ̀ òmíràn ni? Nígbà mìíràn, ńṣe ni àìgbà pé Ọlọ́run wà máa ń dà bíi mímọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ohun tó jẹ́ òtítọ́. Onísáàmù kọ̀wé pé: “Ẹni burúkú, gẹ́gẹ́ bí ìruga rẹ̀, kò ṣe ìwádìí kankan; gbogbo èrò-ọkàn rẹ̀ ni pé: ‘Kò sí Ọlọ́run.’”—Sáàmù 10:4.
5. Kí nìdí tí kò fi sí àwíjàre fún àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà?
5 Gbígbà pé Ọlọ́run wà kì í ṣe ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, nítorí pé àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà pọ̀ jaburata. (Hébérù 11:1) Allan Sandage, tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà, sọ pé: “Ó ṣòro fún mi láti gbà pé àtinú ìdàrúdàpọ̀ kan ni àwọn nǹkan tó wà létòlétò [ní ayé òun ìsálú ọ̀run] ti jáde wá. Àwọn ìlànà kan tó wà létòlétò ló ní láti jẹ́ orísun wọn. Lójú tèmi ò, àwámárìídìí ni Ọlọ́run, àmọ́ òun ló ṣe iṣẹ́ ìyanu wíwà táwọn nǹkan wà, òun ló mọ bí àwọn nǹkan ṣe wà.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ní Róòmù pé “àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí [àwọn aláìgbàgbọ́] kò [fi] ní àwíjàre.” (Róòmù 1:20) Látìgbà “ìṣẹ̀dá ayé,” pàápàá látìgbà tá a ti dá àwọn onílàákàyè ẹ̀dá ènìyàn, tó lè mọ̀ pé Ọlọ́run wà ni ẹ̀rí ti wà pé Ẹlẹ́dàá kan tó ní agbára ńlá ńbẹ, ìyẹn Ọlọ́run tó yẹ ká fi gbogbo ọkàn sìn. Ìdí nìyẹn táwọn tó kùnà láti mọyì ògo Ọlọ́run kò fi ní àwíjàre kankan. Àwọn ẹ̀rí wo la rí látinú ìṣẹ̀dá?
Ọ̀run Òun Ayé Ń Polongo Ògo Ọlọ́run
6, 7. (a) Báwo làwọn ọ̀run ṣe ń polongo ògo Ọlọ́run? (b) Kí ni ète tí àwọn ọ̀run fi rán “okùn ìdíwọ̀n” wọn jáde?
6 Sáàmù 19:1 dáhùn nípa sísọ pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” Dáfídì fòye mọ̀ pé àwọn ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń fara hàn látinú “òfuurufú,” tàbí ní ojú ọ̀run, ń fi ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro hàn pé Ọlọ́run ológo kan wà. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ọjọ́ kan tẹ̀ lé ọjọ́ mìíràn ń mú kí ọ̀rọ̀ ẹnu tú jáde, òru kan tẹ̀ lé òru mìíràn sì ń fi ìmọ̀ hàn.” (Sáàmù 19:2) Ojoojúmọ́ àti gbogbo òru ni àwọn ọ̀run ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run àti agbára ìṣẹ̀dá rẹ̀ hàn. Ńṣe ló dà bíi pé àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fi ìyìn fún Ọlọ́run ń “tú jáde” látinú àwọn ọ̀run.
7 Àmọ́ ṣá o, ó gba pé kéèyàn jẹ́ olóye kó tó lè gbọ́ ẹ̀rí tí wọ́n ń jẹ́ yìí. “Wọn kò sọ ohunkóhun, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀rọ̀; a kò gbọ́ ohùn kankan láti ọ̀dọ̀ wọn.” Síbẹ̀ ẹ̀rí tí àwọn ọ̀run ń jẹ́ láìfọhùn yìí lágbára púpọ̀. “Okùn ìdiwọ̀n wọn ti jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, àsọjáde wọn sì ti jáde lọ sí ìkángun ilẹ̀ eléso.” (Sáàmù 19:3, 4) Ńṣe ló dà bíi pé àwọn ọ̀run rán “okùn ìdíwọ̀n” wọn jáde láti rí i dájú pé ẹ̀rí tí wọ́n ń jẹ́ láìfọhùn dé igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.
8, 9. Kí ni àwọn ohun tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nípa oòrùn?
8 Ẹ̀yìn ìyẹn ni Dáfídì tún ṣàpèjúwe ohun ìyanu mìíràn nínú ìṣẹ̀dá Jèhófà, ó ní: “Inú wọn [ìyẹn ojú ọ̀run] ni ó ti pa àgọ́ fún oòrùn, ó sì dà bí ọkọ ìyàwó nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀ láti inú ìyẹ̀wù ìgbà ìgbéyàwó rẹ̀; ó ń yọ ayọ̀ ńláǹlà gẹ́gẹ́ bí alágbára ńlá ènìyàn ti ń ṣe láti sáré ní ipa ọ̀nà. Láti ìkángun kan ọ̀run ni ìjáde lọ rẹ̀, àlọyíká rẹ̀ sì dé àwọn ìkángun rẹ̀ yòókù; kò sì sí nǹkan kan tí ó pa mọ́ kúrò nínú ooru rẹ̀.”—Sáàmù 19:4-6.
9 Kékeré ni oòrùn jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìràwọ̀ mìíràn. Síbẹ̀, ìràwọ̀ kan tó pabanbarì ni débi pé ńṣe làwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí po rẹ̀ dà bí èyí tó kéré gan-an. Ìwé kan sọ pé oòrùn tóbi ju ayé yìí lọ ní ìlọ́po ẹgbàá márùnlélọ́gọ́jọ [330,000]. Ìtóbi oòrùn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àpapọ̀ òun fúnra rẹ̀ àti gbogbo pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yípo rẹ̀! Agbára òòfà oòrùn ló jẹ́ kí ayé máa yí po rẹ̀ ní àádọ́jọ [150] mílíọ̀nù kìlómítà sí ibi tí oòrùn wà láìsí pé ó jìnnà sí i jù tí kò sì sún mọ́ ọn jù. Ìwọ̀nba díẹ̀ bíńtín ni èyí tó ń dé ayé lára agbára oòrùn, síbẹ̀ ìyẹn tó láti gbé ẹ̀mí ró.
10. (a) Báwo ni oòrùn ṣe ń wọlé tó sì ń jáde látinú “àgọ́” rẹ̀? (b) Báwo ló ṣe ń sáré bí “alágbára ńlá ènìyàn”?
10 Onísáàmù náà fi èdè ìṣàpẹẹrẹ sọ̀rọ̀ nípa oòrùn, ó pè é ní “alágbára ńlá ènìyàn” tó ń sáré láti ìpẹ̀kun kan sí ìpẹ̀kun kejì ní ojú mọmọ tá á sì lọ sùn sínú “àgọ́ kan” lóru. Béèyàn bá wo ìràwọ̀ ńlá yìí bó ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ, ńṣe ló máa ń dà bíi pé ó ń lọ sí “àgọ́ kan” tó fẹ́ lọ sinmi. Ó máa ń dà bíi pé ó jáde lójijì ní òwúrọ̀, tí yóò máa tàn yòò “bí ọkọ ìyàwó nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀ láti inú ìyẹ̀wù lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀.” Jíjẹ́ tí Dáfídì jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ti jẹ́ kó mọ bí òtútù ṣe máa ń mú gan-an ní ọ̀gànjọ́ òru. (Jẹ́nẹ́sísì 31:40) Ó rántí bí ìtànṣán oòrùn yóò ṣe mú kí ara òun àti ojú ilẹ̀ tó yí òun ká móoru. Ó hàn kedere pé àárẹ̀ kì í mú oòrùn nítorí “ìrìn àjò” tó ń rìn láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dà bí “alágbára ńlá ènìyàn,” ó múra tán láti tún ìrìn àjò náà rìn.
Àwọn Àgbàyanu Ìràwọ̀ Àtàwọn Ìṣùpọ̀ Ìràwọ̀
11, 12. (a) Kí ló pabanbarì nípa bí Bíbélì ṣe fi àwọn ìràwọ̀ wé àwọn egunrín iyanrìn? (b) Báwo ni ayé òun ìsálú ọ̀run tiẹ̀ ṣe gbòòrò tó?
11 Láìlo awò-awọ̀nàjíjìn, ó ṣeé ṣe fún Dáfídì láti rí ìwọ̀nba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìràwọ̀ bíi mélòó kan péré. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí ṣe fi hàn, iye ìràwọ̀ tá a lè fi awò-awọ̀nàjíjìn ti òde òní rí nínú ìsálú ọ̀run jẹ́ àádọ́rin bílíọ̀nù lọ́nà bílíọ̀nù lọ́nà ẹgbẹ̀rún! Ńṣe ni Jèhófà ń jẹ́ ká mọ̀ pé iye ìràwọ̀ ò lóǹkà nígbà tó fi wọn wé “àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun.”—Jẹ́nẹ́sísì 22:17.
12 Ó ti pẹ́ gan-an táwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà ti kíyè sí ohun tí wọn ṣàpèjúwe pé ó jẹ́ “apá ibi kékeré kan tó mọ́lẹ̀ tó rí bíríkítí, tí ìrísí rẹ̀ kò hàn kedere.” Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà pé “òbíríkítí ìràwọ̀ tó dà bí òkòtó” wọ̀nyí jẹ́ ara ohun tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà (Milky Way galaxy) tiwa. Ní ọdún 1924, wọ́n ṣàwárí pé èyí tó sún mọ́ wa jù lọ nínú òbíríkítí ìràwọ̀ tó dà bí òkòtó yẹn fúnra rẹ̀ jẹ́ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀, ìyẹn á sì gba ìmọ́lẹ̀ ní ohun tí ó tó mílíọ̀nù méjì ọdún kó tó dé ibi tí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí wà!a Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fojú bù ú báyìí pé ó lé ní ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà, ìràwọ̀ tó sì wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò lóǹkà. Síbẹ̀ Jèhófà ń “ka iye àwọn ìràwọ̀; gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ wọn pè.”—Sáàmù 147:4.
13. (a) Kí ni ohun pípabanbarì nípa àgbájọ ìràwọ̀? (b) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kò tíì mọ “àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ọ̀run”?
13 Jèhófà bi Jóòbù pé: “Ìwọ ha lè so àwọn ìdè àgbájọ ìràwọ̀ Kímà pinpin, tàbí ìwọ ha lè tú àní àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì?” (Jóòbù 38:31) Àgbájọ ìràwọ̀ ni àwọn ìràwọ̀ bíi mélòó kan tó fara hàn láti mú bátànì kan jáde. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí àwọn ìràwọ̀ wà lè jìnnà sí ara wọn, síbẹ̀ ńṣe ló máa ń dà bíi pé ibì kan náà ni wọ́n wà téèyàn bá ń wò wọ́n láti ayé. Nítorí pé ipò táwọn ìràwọ̀ wà kì í yí padà, òun ni wọ́n ṣe jẹ́ “atọ́nà tó wúlò gan-an fún àwọn tó ń wakọ̀ lójú omi, fún àwọn tó ń fi ọkọ̀ àgbéresánmà rìnrìn àjò lọ sínú gbalasa òfuurufú, ó sì tún wúlò fún dídá àwọn ìràwọ̀ mọ̀ lóríṣiríṣi.” (The Encyclopedia Americana) Síbẹ̀, kò sẹ́ni tó mọ “àwọn ìdè” tó so àgbájọ ìràwọ̀ pa pọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni o, di bá a ti ń wí yìí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kò tíì lè dáhùn ìbéèrè tó wà nínú Jóòbù 38:33 pé: “Ìwọ ha ti wá mọ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ọ̀run?”
14. Báwo ni ọ̀nà tí ìmọ́lẹ̀ gbà ń pín ara rẹ̀ ṣe jẹ́ àwámárìídìí?
14 Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kò tún lè dáhùn ìbéèrè mìíràn tá a bi Jóòbù pé: “Ibo wá ni ọ̀nà tí ìmọ́lẹ̀ gbà ń pín ara rẹ̀ wà?” (Jóòbù 38:24) Òǹkọ̀wé kan pe ìwádìí nípa ìmọ́lẹ̀ yìí ní “ìbéèrè jíjinlẹ̀ táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ń béèrè.” Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì kan gbà pé inú ojú èèyàn ni ìmọ́lẹ̀ ti wá. Ní ayé òde òní, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan rò pé àwọn ohun tín-tìn-tín kan wà nínú ìmọ́lẹ̀. Àwọn mìíràn gbà pé ó máa ń bá ìgbì rìn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà gbọ́ pé ìmọ́lẹ̀ rí bí ìgbì àti bí àwọn ohun tín-tìn-tín náà. Síbẹ̀, a ò tíì mọ bí ìmọ́lẹ̀ ṣe rí gan-an àti ọ̀nà tó ń gbà “pín ara rẹ̀.”
15. Bíi ti Dáfídì, báwo ló ṣe yẹ kó rí lára wa nígbà tá a bá ń wo àwọn ohun tó wà ní ojú ọ̀run?
15 Téèyàn bá ronú lórí gbogbo èyí, kò sí bí kò ṣe ní í ní irú ìmọ̀lára tí Dáfídì onísáàmù ní, ẹni tó sọ pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?”—Sáàmù 8:3, 4.
Ayé Àtàwọn Ẹ̀dá Inú Rẹ̀ Ń Fi Ògo fún Jèhófà
16, 17. Báwo ni àwọn ẹ̀dá inú “ibú omi” ṣe ń yin Jèhófà?
16 Sáàmù 148 tún mẹ́nu kan àwọn ọ̀nà mìíràn táwọn ẹ̀dá gbà ń fi ògo fún Ọlọ́run. Ẹsẹ ìkeje kà pé: “Ẹ yin Jèhófà láti ilẹ̀ ayé, ẹ̀yin ẹran ńlá abàmì inú òkun àti gbogbo ẹ̀yin ibú omi.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn “ibú omi” kún fún àwọn ohun ìyanu tó fi ọgbọ́n Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ hàn. Ẹranmi àbùùbùtán kan wúwo tó egbèjìlá [2,400] àpò sìmẹ́ǹtì—ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí ọgbọ̀n erin! Ọkàn ẹranmi yìí nìkan wúwo tó ìwọ̀n àpò sìmẹ́ǹtì mẹ́sàn-án, ẹ̀jẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ sì ń tú gba inú gbogbo iṣan ara rẹ̀ ń lọ sí nǹkan bíi ẹgbàá mẹ́ta ó lé irínwó [6,400] kìlógíráàmù! Ǹjẹ́ àwọn ẹran mùmùrara yìí máa ń rìndìn tí wọ́n kì í sì í yára kánkán nínú omi? Rárá o. Ìròyìn kan tí European Cetacean Bycatch Campaign ṣe sọ pé: “Eré ń bẹ lẹ́sẹ̀ àwọn ẹranmi àbùùbùtán bí wọ́n ṣe ń lọ láti ibì kan síbòmíràn nínú agbami òkun” lọ́nà tó wúni lórí gan-an. Sátẹ́láìtì tó wà fún ṣíṣọ́ ìrìnsí fi hàn pé “ẹranmi àbùùbùtán kan rin ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún [16,000] kìlómítà láàárín oṣù mẹ́wàá.”
17 Ẹranmi lámùsóò onímú sọnsọ [bottlenosed dolphin] sábà máa ń fò sókè tá á sì tún wọnú omi lọ síbi tó jìn tó mítà márùnlélógójì nísàlẹ̀ omi, àmọ́ ẹranmi lámùsóò tá a gbọ́ pé ó lọ sísàlẹ̀ omi jù lọ ni èyí tó lọ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta [547] mítà! Báwo ni ẹranmi yìí ṣe lè ṣe fò sókè kó tún wẹ̀ lọ sísàlẹ̀ omi jìnnà tó bẹ́ẹ̀? Ìlùkìkì ọkàn rẹ̀ máa ń dín kù nígbà tó bá ń lọ sísàlẹ̀ omi náà, ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ á sì darí gba inú ọkàn, ẹ̀dọ̀fóró, àti ọpọlọ rẹ̀. Bákan náà ni àwọn iṣu ẹran ara rẹ̀ tún ní kẹ́míkà kan tó ń kó afẹ́fẹ́ ọ́síjìn pa mọ́. Àwọn ẹja elephant seal àti ẹranmi àbùùbùtán tí wọ́n ń pè ní sperm whale tún lè wẹ̀ lọ sísàlẹ̀ omi jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwé ìròyìn Discover sọ pé: “Dípò kí wọ́n máa mí gúlegúle, ńṣe ni wọ́n máa ń séèémí pátápátá.” Inú iṣu ẹran ara wọn ni wọ́n máa ń fi èyí tó pọ̀ jù lọ nínú afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tí wọ́n ń lò pa mọ́ sí. Láìsí àní-àní, àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí tó ṣeé fojú rí tó fi ọgbọ́n Ọlọ́run alágbára gbogbo hàn!
18. Báwo ni omi òkun ṣe ń fi ọgbọ́n Jèhófà hàn?
18 Àní omi òkun pàápàá ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn. Ìwé Scientific American sọ pé: “Ẹ̀kán omi kọ̀ọ̀kan látinú nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mítà láti òkè sí ìsàlẹ̀ díẹ̀ máa ń ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ohun alààyè tí a kò lè fi ojúyòójú rí.” Àwọn “ewé inú omi tí a kò lè fi ojúyòójú rí yìí” máa ń fọ afẹ́fẹ́ mọ́ tónítóní nípa fífa ọ̀kẹ́ àìmọye tọ́ọ̀nù afẹ́fẹ́ carbon dioxide kúrò nínú afẹ́fẹ́. Àwọn ewé inú omi tí a kò lè fi ojúyòójú rí yìí ló ń pèsè èyí tó ju ìdajì lára afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tá a ń mí símú.
19. Báwo ni iná àti ìrì dídì ṣe ń mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ?
19 Sáàmù 148:8 sọ pé: “Ẹ̀yin iná àti yìnyín, ìrì dídì àti èéfín nínípọn, ìwọ ẹ̀fúùfù oníjì líle, tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà tún ń lo àwọn ohun tí kò lẹ́mìí tí wọ́n jẹ́ ipá àdánidá láti mú ète rẹ̀ ṣẹ. Gbé ọ̀ràn iná yẹ̀ wò. Kìkì ohun tó ń pa nǹkan run làwọn èèyàn ka iná sí ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún sẹ́yìn. Àwọn olùṣèwádìí ti wá gbà gbọ́ báyìí pé iná ń kó ipa pàtàkì ní àyíká wa, ó ń jó àwọn igi tó ti gbó tàbí tó ti kú dà nù, ó ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ irúgbìn tètè hù, ó ń jẹ́ kí àlòtúnlò àwọn èròjà ilẹ̀ ṣeé ṣe, ó sì máa ń dín ewu iná runlérùnnà kù. Ìrì dídì náà tún ṣe pàtàkì púpọ̀, ó máa ń bomi rin ilẹ̀ ó sì máa ń jẹ́ kí ilẹ̀ jí, ó máa ń jẹ́ kí odò kún sí i, kì í jẹ́ kí òtútù tó lè pa àwọn ewéko àtàwọn ẹranko wọlé sí wọn lára.
20. Ọ̀nà wo làwọn òkè ńlá àtàwọn igi gbà ń ṣe aráyé láǹfààní?
20 Sáàmù 148:9 sọ pé: “Ẹ̀yin òkè ńláńlá àti gbogbo ẹ̀yin òkè kéékèèké, ẹ̀yin igi eléso àti gbogbo ẹ̀yin kédárì.” Àwọn òkè ọlọ́lá ńlá ń jẹ́rìí sí agbára ńlá tí Jèhófà ní. (Sáàmù 65:6) Àmọ́ wọ́n tún ń kó ipa tó ṣe pàtàkì gan-an. Ìròyìn tó wá láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Nípa Ilẹ̀ Ayé nílùú Bern, Switzerland, sọ pé: “Inú àwọn òkè ńlá ni gbogbo omi àwọn odò ńláńlá tó wà lágbàáyé ti ń wá. Èyí tó pọ̀ ju ìdajì lára àwọn èèyàn tó wà láyé ló gbára lé omi tó ń wá látinú àwọn òkè ńlá. . . . Àwọn ‘àgbá omi inú òkè ńlá’ yìí ṣe pàtàkì gan-an fún ire ẹ̀dá ènìyàn.” Kódà àwọn igi tá à ń rí káàkiri pàápàá jẹ́ ògo fún Olùṣẹ̀dá wọn. Ìròyìn kan tí Ètò Àbójútó Àyíká ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè gbé jáde sọ pé àwọn igi “ṣe pàtàkì fún ire àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. . . . Ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ àwọn igi kan ṣe pàtàkì gan-an fún ọrọ̀ ajé, nítorí ohun tí wọ́n ń mú jáde bíi gẹdú, èso, oríṣiríṣi ẹ̀pà, oje igi, àti gọ́ọ̀mù. Bílíọ̀nù méjì èèyàn jákèjádò ayé ló gbára lé igi fún síse oúnjẹ àti fún dídá iná.”
21. Ṣàlàyé ọ̀nà tí ewé gbà fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ iṣẹ́ ọ̀nà kan.
21 Ẹ̀rí pé Ẹlẹ́dàá jẹ́ ọlọgbọ́n la rí nínú ọ̀nà tó gbà ṣe igi. Yẹ ewé kan wo. Ó ní ohun kan lára tó ń jẹ́ kí ara rẹ̀ dán, èyí ni kì í jẹ́ kí ewé náà tètè gbẹ dà nù. Abẹ́ ohun tó ń dán yìí gan-an ni àwọn sẹ́ẹ̀lì kan wà tó ní chloroplast nínú. Àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ní èròjà chlorophyll tó ń fa ìtànṣán oòrùn mọ́ra. Ewé á wá di “ilé iṣẹ́ oúnjẹ” nípasẹ̀ ọ̀nà kan tá a ń pè ní photosynthesis. Ńṣe ni igi máa ń fi gbòǹgbò rẹ̀ fa omi lọ sí ara àwọn ewé nípasẹ̀ “ọ̀nà ìfami” dídíjú kan. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún “ihò” kéékèèké (tá à ń pè ní stomata) lára ewé kan máa ń ṣí tó sì máa ń pa dé, kí afẹ́fẹ́ carbon dioxide lè rọ́nà wọlé. Ìmọ́lẹ̀ ló ń pèsè agbára tí omi àti afẹ́fẹ́ carbon dioxide fi ń para pọ̀ láti mú oúnjẹ onítááṣì jáde. Ewéko náà yóò wá jẹ oúnjẹ tí òun fúnra rẹ̀ pèsè. Síbẹ̀, ńṣe ni “ilé iṣẹ́ tó ń pèsè oúnjẹ” yìí máa ń dákẹ́ minimini, ó sì lẹ́wà. Dípò tí ì bá fi ba àyíká jẹ́, ńṣe ló máa ń tú afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tá a nílò jáde!
22, 23. (a) Àwọn ànímọ́ àrà ọ̀tọ̀ wo ni àwọn ẹyẹ kan àtàwọn ẹranko kan ní? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká tún gbé yẹ̀ wò?
22 Sáàmù 148:10 sọ pé: “Ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ àti gbogbo ẹ̀yin ẹran agbéléjẹ̀, ẹ̀yin ohun tí ń rákò àti ẹ̀yin ẹyẹ abìyẹ́lápá.” Ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko orí ilẹ̀ àtàwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ló ń pitú lọ́nà tó yani lẹ́nu. Ẹyẹ Laysan albatross lè fo ọ̀nà jíjìn gan-an (ìgbà kan wà tí ẹyẹ yìí fo ọ̀kẹ́ méjì kìlómítà láàárín àádọ́rùn-ún ọjọ́ péré). Ẹyẹ ìbákà olórí dúdú fò láti ìhà Àríwá Amẹ́ríkà dé ìhà Gúúsù Amẹ́ríkà, tó ń fi ọgọ́rin wákàtí fò láìdúró rárá. Ràkúnmí máa ń tọ́jú omi pa mọ́, kì í ṣe sínú iké ẹ̀yìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti rò, àmọ́ ó máa ń tọ́jú omi pa mọ́ sí ibi tí oúnjẹ rẹ̀ ti ń dà, èyí sì máa ń jẹ́ kó máa rìn lọ fún àkókò gígùn gan-an tí òùngbẹ kò sì ní í gbẹ ẹ́. Abájọ táwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ máa ń fara balẹ̀ wo àwọn ẹranko dáadáa nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ẹ̀rọ àti nǹkan tuntun mìíràn jáde. Òǹkọ̀wé Gail Cleere sọ pé: “Tó o bá fẹ́ ṣe ohun kan tó o fẹ́ kó ṣiṣẹ́ dáadáa . . . kó má sì ṣe ìpalára fún àyíká rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o rí àpẹẹrẹ rere kan tó o lè tẹ̀ lé nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá.”
23 Dájúdájú, ìṣẹ̀dá ń polongo ògo Ọlọ́run ní tòótọ́! Látorí àwọn ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀ títí dórí àwọn ewéko àtàwọn ẹranko ni olúkúlùkù wọn ń yin Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ní ọ̀nà tirẹ̀. Àmọ́ àwa èèyàn wá ńkọ́? Báwo la ṣe lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí nínú kíkọ orin ìyìn sí Ọlọ́run?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìmọ́lẹ̀ máa ń rìn jìnnà tó ọ̀kẹ́ márùndínlógún [300, 000] kìlómítà ní ìṣẹ́jú àáyá kan ṣoṣo.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí táwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà kò fí ní àwíjàre kankan?
• Ọ̀nà wo ni àwọn ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì gbà ń fi ògo fún Ọlọ́run?
• Báwo ni òkun àtàwọn ẹranko orí ilẹ̀ ṣe ń fi ẹ̀rí hàn pé Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ kan wà?
• Báwo ni àwọn ipá ìṣẹ̀dá tí kò lẹ́mìí ṣe ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fojú díwọ̀n rẹ̀ pé iye ìràwọ̀ tó wà jẹ́ àádọ́rin bílíọ̀nù lọ́nà bílíọ̀nù lọ́nà ẹgbẹ̀rún!
[Credit Line]
Frank Zullo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ẹranmi lámùsóò onímú sọnsọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìrì dídì
[Credit Line]
snowcrystals.net
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ẹyẹ “Laysan albatross” kékeré