Ìwọ̀nba Làwọn Tó Máa Ṣàkóso, Ọ̀pọ̀ Ló Máa Jàǹfààní
LÁTÌGBÀ ayé àwọn àpọ́sítélì ni Ọlọ́run ti ń yan àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni olóòótọ́, tó sì ń sọ wọ́n dọmọ. Ìyípadà táwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ yìí ní ò kù síbì kan rárá, abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé ńṣe ni wọ́n di àtúnbí. Ìdí tí wọ́n sì fi di àtúnbí ni pé káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí lè ṣàkóso lọ́run. (2 Tímótì 2:12) Kí èyí lè ṣeé ṣe, Ọlọ́run máa jí wọn dìde sí ìwàláàyè lọ́run. (Róòmù 6:3-5) Nígbà tí wọ́n bá dókè ọ̀run, àwọn àti Kristi “yóò . . . ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:10; 11:15.
Àmọ́ ṣá o, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún sọ pé àwọn míì, yàtọ̀ sáwọn tó ti di àtúnbí, máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Bíbélì (nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì) sọ pé àwùjọ àwọn èèyàn méjì ni Ọlọ́run ti pinnu láti gbà là, ìyẹn ni ìwọ̀nba àwọn tó máa ṣàkóso lọ́run àti àwùjọ ọ̀pọ̀ èèyàn tó máa jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba náà tí wọ́n á máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sóhun tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọ́n sì ti di àtúnbí. Ó sọ nípa Jésù pé: “Òun . . . ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa [àwùjọ èèyàn díẹ̀] nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé [àwùjọ ọ̀pọ̀ èèyàn] pẹ̀lú.”—1 Jòhánù 2:2.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà kọ̀wé pé: “Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá [àwùjọ ọ̀pọ̀ èèyàn] ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run [àwùjọ èèyàn díẹ̀].” (Róòmù 8:19-21) Kí lọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù àti ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù túmọ̀ sí gan-an? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé: Àwọn tí wọ́n bá ti di àtúnbí máa ṣàkóso lọ́run. Kí nìdí tí wọ́n fi máa lọ ṣàkóso lọ́run? Kí wọ́n lè mú ìbùkún ayérayé bá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, ìyẹn àwọn tó máa jẹ́ ọmọ abẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run tí wọ́n á máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.
Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù náà sọ̀rọ̀ nípa àwọn àwùjọ èèyàn méjì tó máa nígbàlà. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sóhun tí Jèhófà sọ fún Ábúráhámù tó jẹ́ baba ńlá Jésù, ó ní: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ [ìyẹn àwùjọ èèyàn díẹ̀] sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé [àwùjọ ọ̀pọ̀ èèyàn] yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Dájúdájú, “irú ọmọ” Ábúráhámù ló máa bù kún gbogbo ayé.
Ta ni “irú ọmọ” yìí? Jésù Kristi àtàwọn tó ti di àtúnbí, ìyẹn àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ ló para pọ̀ jẹ́ “irú ọmọ” yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, ẹ̀yin jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù ní ti tòótọ́.” (Gálátíà 3:16, 29) Kí wá làwọn ìbùkún tó máa bá gbogbo aráyé nípasẹ̀ “irú-ọmọ” yìí? Wọ́n máa láǹfààní láti pa dà rójú rere Ọlọ́run, wọ́n á sì tún gbádùn ìgbésí ayé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29; Aísáyà 45:18; Ìṣípayá 21:1-5.
Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé, ìwọ̀nba làwọn tó máa ṣàkóso lọ́run, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé ló máa jàǹfààní látinú ìṣàkóso náà títí láé, ìyẹn àǹfààní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé àtàwọn ìbùkún míì tó máa tẹ̀ lé e. A gbà á ládùúrà pé kíwọ àtàwọn ìdílé ẹ wà lára àwọn tó máa gbádùn àwọn ìbùkún ayérayé tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn máa gbádùn ìgbésí ayé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ṣé wàá wà lára wọn?