Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Májẹ̀mú
“Èmi óò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun.”—JEREMÁYÀ 31:31.
1, 2. (a) Ayẹyẹ wo ni Jésù dá sílẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa? (b) Májẹ̀mú wo ni Jésù tọ́ka sí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ikú rẹ̀?
NÍ ALẸ́ Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù ṣayẹyẹ Ìrékọjá pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ 12. Níwọ̀n bí ó ti mọ̀ pé èyí ni yóò jẹ́ oúnjẹ àjẹkẹ́yìn pẹ̀lú wọn àti pé àwọn ọ̀tá òun yóò pa òun láìpẹ́, Jésù lo àǹfààní ayẹyẹ náà láti ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan pàtàkì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí ó sún mọ́ ọn jù lọ.—Jòhánù 13:1–17:26.
2 Ní àkókò yí, lẹ́yìn tí ó ti yọ̀ǹda fún Júdásì Ísíkáríótù láti jáde, ni Jésù dá ayẹyẹ ìsìn ọdọọdún kan ṣoṣo tí a pa láṣẹ fún àwọn Kristẹni sílẹ̀—Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Bí wọ́n ti ń jẹun lọ, Jésù mú ìṣù búrẹ́dì kan, lẹ́yìn sísúre, ó sì bù ú, ní fífi í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí pé: ‘Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mú ife kan àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín; nítorí èyí túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.’” (Mátíù 26:26-28) Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní láti ṣe ìrántí ikú rẹ̀ lọ́nà tí ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí ó sì wuyì. Jésù sì tọ́ka sí májẹ̀mú kan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ikú rẹ̀. Nínú àkọsílẹ̀ Lúùkù, a pè é ní “májẹ̀mú tuntun.”—Lúùkù 22:20.
3. Àwọn ìbéèrè wo ni a béèrè nípa májẹ̀mú tuntun?
3 Kí ni májẹ̀mú tuntun náà? Bí ó bá jẹ́ májẹ̀mú tuntun, ìyẹn ha túmọ̀ sí pé májẹ̀mú láéláé wà bí? Àwọn májẹ̀mú mìíràn ha wà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú rẹ̀ bí? Ìwọ̀nyí jẹ́ ìbéèrè pàtàkì nítorí Jésù wí pé a óò ta ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú náà sílẹ̀ “fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” Gbogbo wa pátá nílò irú ìdáríjì bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.—Róòmù 3:23.
Májẹ̀mú Tí A Bá Ábúráhámù Dá
4. Ìlérí láéláé wo ni ó ràn wá lọ́wọ́ láti lóye májẹ̀mú tuntun náà?
4 Láti lóye májẹ̀mú tuntun náà, a ní láti pa dà sẹ́yìn sí nǹkan bí 2,000 ọdún ṣáájú ìgbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, sí ìgbà tí Térà àti ìdílé rẹ̀—títí kan Ábúrámù (tí ó di Ábúráhámù lẹ́yìn náà) àti aya Ábúrámù, Sáráì (tí ó di Sárà lẹ́yìn náà)—fẹsẹ̀ rìn láti Úrì ilẹ̀ aláásìkí, ti àwọn ará Kálídíà, lọ sí Háránì ní àríwá Mesopotámíà. Ibẹ̀ ni wọ́n wà títí tí Térà fi kú. Lẹ́yìn náà, lábẹ́ àṣẹ Jèhófà, Ábúráhámù ọmọ ọdún 75 ré Odò Yúfírétì kọjá, ó sì rìnrìn àjò gba ìhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn wọ ilẹ̀ Kénáánì, láti gbé ìgbésí ayé aṣíkiri nínú àgọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 11:31–12:1, 4, 5; Ìṣe 7:2-5) Ìyẹn jẹ́ ní ọdún 1943 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ábúráhámù ṣì wà ní Háránì nígbà tí Jèhófà wí fún un pé: “Èmi óò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi óò sì bù sí i fún ọ, èmi óò sì sọ orúkọ rẹ di ńlá; ìbùkún ni ìwọ óò sì já sí: Èmi óò bù kún fún àwọn tí ń súre fún ọ, ẹni tí ó ń fi ọ́ ré ni èmi óò sì fi ré; nínú rẹ ni a óò ti bù kún fún gbogbo ìdílé ayé.” Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí Ábúráhámù ti ré kọjá sí Kénáánì, Jèhófà fi kún un pé: “Irú ọmọ rẹ ni èmi óò fi ilẹ̀ yí fún.”—Jẹ́nẹ́sísì 12:2, 3, 7.
5. Àsọtẹ́lẹ̀ ìtàn wo ni ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù so mọ́?
5 Ìlérí tí a ṣe fún Ábúráhámù ní í ṣe pẹ̀lú ìlérí mìíràn tí Jèhófà ṣe. Ní tòótọ́, ó mú kí Ábúráhámù di ẹni pàtàkì nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, ògúnná gbòǹgbò kan nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tí a kọ sílẹ̀. Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà kéde ìdájọ́ rẹ̀ lórí àwọn méjèèjì, ní àkókò kan náà, ó wí fún Sátánì, tí ó ṣi Éfà lọ́nà, pé: “Èmi óò . . . fi ọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sáàárín irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ rẹ̀: òun óò fọ́ ọ ní orí, ìwọ ó sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá fi hàn pé ìlà baba ńlá yẹn ni Irú Ọmọ náà tí a óò tipasẹ̀ rẹ̀ sọ àwọn iṣẹ́ Sátánì di asán yóò ti jáde wá.
6. (a) Nípasẹ̀ ta ni ìlérí Jèhófà fún Ábúráhámù yóò gbà ní ìmúṣẹ? (b) Kí ni májẹ̀mú Ábúráhámù?
6 Níwọ̀n bí ìlérí Jèhófà ti ní í ṣe pẹ̀lú irú ọmọ kan, Ábúráhámù nílò ọmọkùnrin kan tí Irú Ọmọ náà yóò tipasẹ̀ rẹ̀ wá. Ṣùgbọ́n òun àti Sárà ti darúgbó, wọ́n kò sì tí ì bí ọmọ kankan. Ṣùgbọ́n, nígbẹ̀yìngbẹ́yín Jèhófà bù kún wọn, ní mímú kí agbára ìbímọ wọn pa dà gbéṣẹ́ lọ́nà ìyanu, Sárà sì bí ọmọkùnrin kan, Aísíìkì, fún Ábúráhámù, a sì tipa báyìí mú kí ìlérí irú ọmọ tí a ṣe di èyí tí yóò lè ṣẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 17:15-17; 21:1-7) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, lẹ́yìn dídán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò—àní títí dórí mímúratán láti fi ọmọkùnrin rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n, Aísíìkì, rúbọ—Jèhófà tún ìlérí rẹ̀ fún Ábúráhámù sọ pé: “Ní bíbùkún èmi óò bù kún fún ọ, àti ní bíbí sí i èmi óò mú irú ọmọ rẹ bí sí i bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, àti bí iyanrìn etí òkun; irú ọmọ rẹ ni yóò sì ni ẹnubodè àwọn ọ̀tá wọn; àti nínú irú ọmọ rẹ ni a óò bù kún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé: nítorí tí ìwọ ti gba ohùn mi gbọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18) Ìlérí gbígbòòrò yí ni a sábà máa ń pè ní májẹ̀mú Ábúráhámù, májẹ̀mú tuntun tí ó sì jẹyọ lẹ́yìn rẹ̀ yóò so mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí.
7. Báwo ni irú ọmọ Ábúráhámù ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i, àyíká ipò wo sì ni ó sún wọn dé dídi olùgbé ní Íjíbítì?
7 Bí àkókò ti ń lọ, Aísíìkì bí ìbejì, tí wọ́n jẹ́ ọmọkùnrin, Ísọ̀ àti Jékọ́bù. Jèhófà yan Jékọ́bù láti jẹ́ baba ńlá fún Irú Ọmọ Tí A Ṣèlérí. (Jẹ́nẹ́sísì 28:10-15; Róòmù 9:10-13) Jékọ́bù ní ọmọkùnrin 12. Ó ṣe kedere pé àkókò ti tó wàyí fún irú ọmọ Ábúráhámù láti máa pọ̀ sí i. Nígbà tí àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù dàgbà, tí ọ̀pọ̀ ní ìdílé tiwọn, ìyàn mú kí gbogbo wọn ṣí lọ sí Íjíbítì níbi tí Jósẹ́fù, ọmọkùnrin Jékọ́bù, ti ṣètò fún wọn, lábẹ́ ìdarí àtọ̀runwá. (Jẹ́nẹ́sísì 45:5-13; 46:26, 27) Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ìyàn ilẹ̀ Kénáánì dáwọ́ dúró. Ṣùgbọ́n ìdílé Jékọ́bù dúró sí Íjíbítì—lákọ̀ọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí àlejò ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bí ẹrú. Ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, 430 ọdún lẹ́yìn tí Ábúráhámù ti ré Yúfírétì kọjá, ni Mósè tó ṣáájú àwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù jáde kúrò ní Íjíbítì láti gbòmìnira. (Ẹ́kísódù 1:8-14; 12:40, 41; Gálátíà 3:16, 17) Wàyí o, Jèhófà yóò fún májẹ̀mú tí ó bá Ábúráhámù dá ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀.—Ẹ́kísódù 2:24; 6:2-5.
“Májẹ̀mú Láéláé”
8. Kí ni Jèhófà dá pẹ̀lú àwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù ní Sínáì, kí sì ni èyí ní í ṣe pẹ̀lú májẹ̀mú Ábúráhámù?
8 Nígbà tí Jékọ́bù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ṣí lọ sí Íjíbítì, wọ́n jẹ́ ìdílé amẹ́bímúbàátan, ṣùgbọ́n àwọn àtọmọdọ́mọ wọn fi Íjíbítì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ẹ̀yà rẹpẹtẹ. (Ẹ́kísódù 1:5-7; 12:37, 38) Kí Jèhófà tó mú wọn wá sí Kénáánì, ó mú wọn gba ìhà gúúsù lọ sí ẹsẹ̀ òkè tí a pè ní Hórébù (tàbí, Sínáì) ní Arébíà. Níbẹ̀, ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú wọn. Èyí ni a ń pè ní “májẹ̀mú láéláé” ní ìbámu pẹ̀lú “májẹ̀mú tuntun.” (Kọ́ríńtì Kejì 3:14) Nípasẹ̀ májẹ̀mú láéláé náà, Jèhófà mú ìlérí májẹ̀mú tí ó bá Ábúráhámù dá ṣẹ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.
9. (a) Ohun mẹ́rin wo ni Jèhófà ṣèlérí nípasẹ̀ májẹ̀mú Ábúráhámù? (b) Àwọn ìrètí mìíràn wo ni májẹ̀mú tí Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá mú wá, ipò wo sì ni a gbé e lé?
9 Jèhófà ṣàlàyé ohun tí májẹ̀mú yìí ní nínú fún Ísírẹ́lì: “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ gba ohùn mi gbọ́ ní tòótọ́, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin óò jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo ènìyàn lọ: nítorí gbogbo ayé ni ti èmi. Ẹ̀yin óò sì máa jẹ́ ìjọba àlùfáà fún mi, àti orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Jèhófà ti ṣèlérí pé irú ọmọ Ábúráhámù yóò (1) di orílẹ̀-èdè ńlá, (2) ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn, (3) jogún ilẹ̀ Kénáánì, àti (4) jẹ́ ọ̀nà tí ìbùkún yóò máa gbà wá fún àwọn orílẹ̀-èdè. Wàyí o, ó ṣí i payá pé, bí wọ́n bá ṣègbọràn sí àṣẹ òun, àwọn alára lè jogún àwọn ìbùkún wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ọ̀tọ̀ tòun, Ísírẹ́lì, “ìjọba àlùfáà . . . àti orílẹ̀-èdè mímọ́.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ha gbà láti wọnú májẹ̀mú yìí bí? Wọ́n dáhùn papọ̀ pé: “Ohun gbogbo tí OLÚWA wí ni àwa óò ṣe.”—Ẹ́kísódù 19:8.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè kan, kí sì ni ó retí láti ọ̀dọ̀ wọn?
10 Nítorí náà, Jèhófà sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè kan. Ó fún wọn ní òfin tí yóò darí ìjọsìn àti ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́. Ó tún pèsè àgọ́ àjọ (lẹ́yìn náà, tẹ́ńpìlì kan ní Jerúsálẹ́mù) àti ẹgbẹ́ àlùfáà láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nínú àgọ́ àjọ náà. Pípa májẹ̀mú náà mọ́ túmọ̀ sí ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin Jèhófà àti, ní pàtàkì, jíjọ́sìn òun nìkan ṣoṣo. Àkọ́kọ́ nínú Òfin Mẹ́wàá tí ó jẹ́ apá pàtàkì jù lọ nínú àwọn òfin wọnnì ni pé: “Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Íjíbítì, láti oko ẹrú jáde wá. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.”—Ẹ́kísódù 20:2, 3.
Àwọn Ìbùkún Nípasẹ̀ Májẹ̀mú Òfin
11, 12. Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn ìlérí inú májẹ̀mú láéláé gbà ní ìmúṣẹ sí Ísírẹ́lì lára?
11 Àwọn ìlérí inú májẹ̀mú Òfin ha ṣẹ sí Ísírẹ́lì lára bí? Ísírẹ́lì ha di “orílẹ̀-èdè mímọ́” bí? Gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Ádámù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 5:12) Síbẹ̀, lábẹ́ Òfin, wọ́n rúbọ láti dí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nípa àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú ní Ọjọ́ Ètùtù, Jèhófà wí pé: “Ní ọjọ́ náà ni a óò ṣètùtù fún yín, láti wẹ̀ yín mọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín níwájú OLÚWA.” (Léfítíkù 16:30) Nítorí náà, nígbà tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́, Ísírẹ́lì jẹ́ orílẹ̀-èdè mímọ́, tí a wẹ̀ mọ́ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ṣùgbọ́n ipò ìjẹ́mímọ́ yìí sinmi lórí ṣíṣègbọràn sí Òfin àti bíbá a nìṣó láti máa rúbọ.
12 Ísírẹ́lì ha di “ìjọba àlùfáà” bí? Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, ó jẹ́ ìjọba kan, tí Jèhófà jẹ́ Ọba rẹ̀ ọ̀run. (Aísáyà 33:22) Síwájú sí i, májẹ̀mú Òfin náà yọ̀ǹda fún ipò ọba ti ẹ̀dá ènìyàn, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí ó yá àwọn ọba tí ń ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù ṣojú fún Jèhófà. (Diutarónómì 17:14-18) Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ha jẹ́ ìjọba àlùfáà bí? Tóò, ó ní ẹgbẹ́ àlùfáà tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nínú àgọ́ àjọ. Àgọ́ àjọ náà (lẹ́yìn náà, tẹ́ńpìlì) ni ojúkò fún ìjọsìn mímọ́ gaara fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú. Orílẹ̀-èdè náà sì ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí a gbà ṣí òtítọ́ payá fún aráyé. (Kíróníkà Kejì 6:32, 33; Róòmù 3:1, 2) Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olùṣòtítọ́ pátá, ni “ẹlẹ́rìí” Jèhófà, kì í ṣe àwọn àlùfáà ọmọ Léfì nìkan. Ísírẹ́lì jẹ́ “ìránṣẹ́” Jèhófà, tí a ṣètò láti ‘fi ìyìn rẹ̀ hàn.’ (Aísáyà 43:10, 21) Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè onírẹ̀lẹ̀ ọkàn rí agbára Jèhófà lórí àwọn ènìyàn rẹ̀, ìjọsìn mímọ́ gaara fà wọ́n mọ́ra. Wọ́n di aláwọ̀ṣe. (Jóṣúà 2:9-13) Ṣùgbọ́n ẹ̀yà kan ṣoṣo péré ní ti gidi ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn.
Àwọn Aláwọ̀ṣe ní Ísírẹ́lì
13, 14. (a) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé àwọn aláwọ̀ṣe kò kópa nínú májẹ̀mú Òfin? (b) Báwo ni àwọn aláwọ̀ṣe ṣe wá sábẹ́ májẹ̀mú Òfin?
13 Ipò wo ni irú àwọn aláwọ̀ṣe bẹ́ẹ̀ wà? Nígbà tí Jèhófà dá májẹ̀mú rẹ̀, Ísírẹ́lì nìkan ni ó bá dá a; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn “ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó dàpọ̀ mọ́ wọn” wà níbẹ̀, a kò pè wọ́n ní olùkópa. (Ẹ́kísódù 12:38; 19:3, 7, 8) A kò ka àwọn àkọ́bí wọn mọ́ ọn nígbà tí a ṣírò iye owó ìràpadà fún àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Númérì 3:44-51) Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún lẹ́yìn náà, nígbà tí a pín ilẹ̀ Kénáánì fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, a kò pín ohunkóhun fún àwọn onígbàgbọ́ tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. (Jẹ́nẹ́sísì 12:7; Jóṣúà 13:1-14) Èé ṣe? Nítorí a kò bá àwọn aláwọ̀ṣe dá májẹ̀mú Òfin. Ṣùgbọ́n láti ṣègbọràn sí Òfin, a kọlà fún àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ aláwọ̀ṣe. Wọ́n pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́, wọ́n sì jàǹfààní láti inú àwọn ìpèsè rẹ̀. Àwọn aláwọ̀ṣe àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá sábẹ́ májẹ̀mú Òfin.—Ẹ́kísódù 12:48, 49; Númérì 15:14-16; Róòmù 3:19.
14 Fún àpẹẹrẹ, bí aláwọ̀ṣe kan bá ṣèèṣì pa ẹnì kan, ó lè sá lọ sí ìlú ààbò gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ísírẹ́lì kan yóò ti ṣe. (Númérì 35:15, 22-25; Jóṣúà 20:9) Ní Ọjọ́ Ètùtù, wọ́n máa ń rúbọ “fún gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì.” Gẹ́gẹ́ bí ara ìjọ náà, àwọn aláwọ̀ṣe máa ń kópa nínú àwọn ààtò náà, ìrúbọ náà sì ń bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Léfítíkù 16:7-10, 15, 17, 29; Diutarónómì 23:7, 8) Àwọn aláwọ̀ṣe ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ísírẹ́lì lábẹ́ Òfin tó bẹ́ẹ̀ débi pé ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nígbà tí a lo ‘kọ́kọ́rọ́ ìjọba náà’ àkọ́kọ́ fún àwọn Júù, àwọn aláwọ̀ṣe pẹ̀lú jàǹfààní. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, “Níkóláọ́sì, aláwọ̀ṣe kan ará Áńtíókù,” di Kristẹni, ó sì wà lára “àwọn ọkùnrin méje tí a jẹ́rìí gbè,” tí a yàn láti bójú tó àìní ìjọ Jerúsálẹ́mù.—Mátíù 16:19; Ìṣe 2:5-10; 6:3-6; 8:26-39.
Jèhófà Bù Kún Irú Ọmọ Ábúráhámù
15, 16. Báwo ni a ṣe mú májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá ṣẹ lábẹ́ májẹ̀mú Òfin?
15 Níwọ̀n bí ó ti sọ àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù di orílẹ̀-èdè kan lábẹ́ Òfin, Jèhófà bù kún wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún baba ńlá wọn. Ní ọdún 1473 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jóṣúà, arọ́pò Mósè, ṣáájú Ísírẹ́lì lọ sí Kénáánì. Pípín ilẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà náà lẹ́yìn àkókò yí mú ìlérí Jèhófà láti fún irú ọmọ Ábúráhámù ní ilẹ̀ náà ṣẹ. Nígbà tí Ísírẹ́lì jẹ́ olùṣòtítọ́, Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ láti mú kí wọn ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn ṣẹ. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì nígbà ìṣàkóso Ọba Dáfídì. Nígbà tí yóò fi di àkókò Sólómọ́nì, ọmọkùnrin Dáfídì, apá kẹta nínú ìlérí tí a ṣe fún Ábúráhámù ti ní ìmúṣẹ. “Júdà àti Ísírẹ́lì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí òkun ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá.”—Àwọn Ọba Kìíní 4:20.
16 Ṣùgbọ́n, báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣe bù kún ara wọn nípasẹ̀ Ísírẹ́lì, irú ọmọ Ábúráhámù? Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án níṣàájú, Ísírẹ́lì jẹ́ ènìyàn ọ̀tọ̀ fún Jèhófà, aṣojú rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Kété ṣáájú kí Ísírẹ́lì tó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ wọnú Kénáánì, Mósè wí pé: “Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.” (Diutarónómì 32:43) Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè dáhùn pa dà. “Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó dàpọ̀ mọ́ wọn,” ti ó ti tẹ̀ lé Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì tẹ́lẹ̀, fojú rí agbára Jèhófà nínú aginjù, wọ́n sì gbọ́ ìkésíni Mósè láti kún fún ayọ̀. (Ẹ́kísódù 12:37, 38) Lẹ́yìn náà, Rúùtù, ọmọbìnrin Móábù, fẹ́ Bóásì ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì di ìyá ńlá Mèsáyà náà. (Rúùtù 4:13-22) Jèhónádábù ọmọ Kénì àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ àti Ebedi-mélékì ará Etiópíà ya ara wọn sọ́tọ̀ nípa rírọ̀ mọ́ àwọn ìlànà títọ́ nígbà tí ọ̀pọ̀ ọmọ Ísírẹ́lì àbínibí di aláìṣòótọ́. (Àwọn Ọba Kejì 10:15-17; Jeremáyà 35:1-19; 38:7-13) Lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Páṣíà, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè di aláwọ̀ṣe, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì ní bíbá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jagun.—Ẹ́sítérì 8:17, NW, àlàyé ẹsẹ̀ ìwé.
A Nílò Májẹ̀mú Tuntun
17. (a) Èé ṣe tí Jèhófà fi kọ ìjọba àríwá àti gúúsù ti Ísírẹ́lì? (b) Kí ni ó fa kíkọ̀ tí a kọ àwọn Júù sílẹ̀ níkẹyìn?
17 Síbẹ̀, láti lè rí ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ gbà, orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ ti Ọlọ́run ní láti jẹ́ olùṣòtítọ́. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, a rí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n nígbàgbọ́ tí ó ga lọ́lá. (Hébérù 11:32–12:1) Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni orílẹ̀-èdè náà yíjú sí àwọn òrìṣà, ní ríretí àǹfààní ohun ti ara. (Jeremáyà 34:8-16; 44:15-18) Àwọn kọ̀ọ̀kan nínú wọn ṣi Òfin náà lò tàbí kí wọ́n tilẹ̀ pa á tì. (Nehemáyà 5:1-5; Aísáyà 59:2-8; Málákì 1:12-14) Lẹ́yìn ikú Sólómọ́nì, a pin Ísírẹ́lì sí ìjọba àríwá àti gúúsù. Nígbà tí ìjọba àríwá fi hàn pé òun jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ paraku, Jèhófà kéde pé: “Nítorí ìwọ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀, èmi óò sì kọ̀ ọ́, tí ìwọ kì yóò ṣe àlùfáà mi mọ́.” (Hóséà 4:6) Ìjọba gúúsù pẹ̀lú jìyà gidigidi nítorí pé ó da májẹ̀mú náà. (Jeremáyà 5:29-31) Nígbà tí àwọn Júù kọ Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, Jèhófà pẹ̀lú kọ̀ wọ́n. (Ìṣe 3:13-15; Róòmù 9:31–10:4) Níkẹyìn, Jèhófà ṣe ètò tuntun kan láti mú májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù ṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.—Róòmù 3:20.
18, 19. Ètò tuntun wo ni Jèhófà ṣe kí májẹ̀mú Ábúráhámù lè nímùúṣẹ ní kíkún?
18 Ìṣètò tuntun náà ni májẹ̀mú tuntun. Jèhófà ti sọ èyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ó wí pé: “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí èmi óò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun. . . . Èyí ni májẹ̀mú tí èmi óò bá ilé Ísírẹ́lì dá; Lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì, ni Olúwa wí, èmi óò fi òfin mi sí inú wọn, èmi óò sì kọ ọ́ sí àyà wọn; èmi óò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, àwọn óò sì jẹ́ ènìyàn mi.”—Jeremáyà 31:31-33.
19 Èyí ni májẹ̀mú tuntun tí Jésù tọ́ka sí ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ní àkókò yẹn, ó ṣí i payá pé a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dá májẹ̀mú tí a ṣèlérí náà láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun àti Jèhófà, tí Jésù yóò sì jẹ́ alárinà wọn. (Kọ́ríńtì Kíní 11:25; Tímótì Kíní 2:5; Hébérù 12:24) Nípasẹ̀ májẹ̀mú tuntun yìí, ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù yóò túbọ̀ ní ìmúṣẹ ológo, tí yóò wà pẹ́ títí, gẹ́gẹ́ bí a óò ti rí i nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Kí ni Jèhófà ṣèlérí nínú májẹ̀mú Ábúráhámù?
◻ Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí májẹ̀mú Ábúráhámù ṣẹ sí Ísírẹ́lì nípa ti ara lára?
◻ Báwo ni àwọn aláwọ̀ṣe ṣe jàǹfààní nínú májẹ̀mú láéláé?
◻ Èé ṣe tí a fi nílò májẹ̀mú tuntun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Nípasẹ̀ májẹ̀mú Òfin, Jèhófà mú ìlérí májẹ̀mú tí ó bá Ábúráhámù dá ṣẹ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ