Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Wíwá Aya fún Aísíìkì
Ó TI rẹ ọkùnrin àgbàlagbà tí ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri náà tẹnutẹnu. Òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìbakasíẹ wọn mẹ́wàá ti rin ọ̀nà jínjìn láti sàkáání Bíá-Ṣébà sí àríwá Mesopotámíà—ìrìn-àjò tí ó ju 800 kìlómítà.a Nísinsìnyí tí wọ́n ti dé ibi tí wọ́n ń lọ, arìnrìn-àjò tí àárẹ̀ ti mú yìí dúró láti ronú lórí iṣẹ́ ìjíhìn rẹ̀ tí ó le koko. Ta ni ọkùnrin yìí, èé sì ti ṣe tí ó fi dágbá lé ìrìn-àjò atánnilókun yìí?
Ìránṣẹ́ Ábúráhámù ni ọkùnrin náà, “àgbà ilé rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 24:2) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò dárúkọ rẹ̀ nínú ìròyìn náà, ó hàn gbangba pé, ẹni yìí jẹ́ Élíésérì, ẹni tí Ábúráhámù tọ́ka sí nígbà kan gẹ́gẹ́ bí ‘ọmọkùnrin ilé òun,’ ẹni tí òun sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó wà ní ìlà láti ‘ṣe àrólé òun.’ (Jẹ́nẹ́sísì 15:2, 3) Àmọ́ ṣáá o, ìyẹn jẹ́ nígbà tí Ábúráhámù àti Sárà kò tí ì bímọ. Nísinsìnyí, ọmọkùnrin wọn, Aísíìkì, jẹ́ ẹni 40 ọdún, bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé Élíésérì kì í ṣe àrólé pàtàkì fún Ábúráhámù mọ́, ó ṣì jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ síbẹ̀. Nítorí náà, kò janpata nígbà tí Ábúráhámù ṣe ìbéèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kan tí ń peni níjà. Kí ni ohun náà?
Iṣẹ́ Ìjíhìn Tí Ń Peni Níjà
Ní ọjọ́ Ábúráhámù, kì í ṣe ìdílé nìkan ni ìgbéyàwó kan máa ń nípa lé lórí, ṣùgbọ́n ó máa ń nípa lórí ẹ̀yà kan, tàbí àwùjọ baba ńlá kan látòkè délẹ̀. Nítorí náà, ó jẹ́ àṣà fún àwọn òbí láti yan alábàáṣègbéyàwó fún àwọn ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n, ní wíwá aya fún ọmọ rẹ̀ Aísíìkì, Ábúráhámù dojú kọ ẹtì kan. Ọ̀nà àìwàbí-Ọlọ́run ti àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Kénáánì mú kí bíbá ọ̀kan lára wọn ṣe ìgbéyàwó máa ṣeé ṣe. (Diutarónómì 18:9-12) Bí ó sì ti jẹ́ àṣà fún ọkùnrin kan láti fẹ́ lára ẹ̀yà tirẹ̀, àwọn ìbátan Ábúráhámù ń gbé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà jìnnàjìnnà ní àríwá Mesopotámíà. Kò wulẹ̀ lè mú kí Aísíìkì tún lọ tẹ̀ dó sọ́hùn-ún, nítorí Jèhófà ti ṣèlérí fún Ábúráhámù pé: “Irú-ọmọ rẹ ni èmi óò fi ilẹ̀ yí fún,” ilẹ̀ Kénáánì. (Jẹ́nẹ́sísì 24:7, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Nítorí náà, Ábúráhámù sọ fún Élíésérì pé: “Lọ sí ilẹ̀ mi, àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ará mi, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún Aísíìkì, ọmọ mi.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:4.
Lẹ́yìn píparí ìrìn-àjò gígùn náà, Élíésérì sinmi níbi kàǹga bí ó ti ń ronú nípa iṣẹ́ ìjíhìn rẹ̀. Ó mọ̀ pé láìpẹ́, àwọn obìnrin yóò máa wá sí ibi kàǹga náà láti pọn omi fún lílò lálẹ́. Nítorí náà, ó bẹ Jèhófà pé: “Ọmọdan tí èmi óò wí fún pé, Èmí bẹ̀ ọ́, sọ ládugbó rẹ kalẹ̀, kí èmi kí ó mu; tí òun óò sì wí pé, Mu, èmi óò sì fi fún àwọn ìbakasíẹ rẹ̀ mu pẹ̀lú: òun náà ni kí ó jẹ́ ẹni tí ìwọ́ yàn fún Aísíìkì ìránṣẹ́ rẹ; nípa èyí ni èmi óò sì mọ̀ pé, ìwọ́ ti ṣe ore fún olúwa mi.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:14.
Nígbà tí ó ṣì ń gbàdúrà lọ́wọ́, ọ̀dọ́bìnrin kan tí ó fani mọ́ra, tí ń jẹ́ Rèbékà, dé síbẹ̀. Élíésérì wí fún un pé: “Èmí bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n mu omi díẹ̀ nínú ládugbó rẹ.” Rèbékà ṣe bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn náà, ó sì wí pé: “Èmi óò pọn fún àwọn ìbakasíẹ rẹ̀ pẹ̀lú, títí wọn óò fi mu tán.” Ìpèsè ọlọ́làwọ́ kan ni èyí jẹ́, níwọ̀n bí ìbakasíẹ kan tí òùngbẹ ń gbẹ ti lè mú omi tí ó tó lítà 95 láàárín ìṣẹ́jú mẹ́wàá péré! Bóyá òùngbẹ ń gbẹ àwọn ìbakasíẹ Élíésérì tó ìyẹn tàbí kò gbẹ wọ́n tó bẹ́ẹ̀, Rèbékà ti ní láti mọ̀ pé iṣẹ́ tí òun yọ̀ǹda láti ṣe yóò nira. Ní tòótọ́, ó “yára, ó sì tú ládugbó rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sì tún pa dà súré lọ sí kàǹga láti pọn omi, ó sì pọn fún gbogbo ìbakasíẹ rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:15-20.
Bí ó ti kíyè sí ìdarí Jèhófà, Élíésérì fún Rèbékà ní òrùka wúrà méjì tí a ń kì bọ imú àti ìgbànú oníwúrà méjì, tí ó tó 1,400 dọ́là ní ìníyelórí tòní. Nígbà tí Rèbékà sọ fún un pé ọmọ-ọmọ Náhórì, arákùnrin Ábúráhámù ni òun, Élíésérì gbàdúrà ọpẹ́ sí Ọlọ́run. Ó wí pé: “OLÚWA fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà ilé àwọn arákùnrin bàbá mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 24:22-27) A mú Élíésérì wá sí ọ̀dọ̀ ìdílé Rèbékà. Láìpẹ́, Rèbékà di aya Aísíìkì, ó sì ní àǹfààní dídi ìyá ńlá Mèsáyà náà, Jésù.
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Jèhófà bù kún ìsapá Élíésérì tí ó kún fún àdúrà láti rí alábàáṣègbéyàwó tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù-Ọlọ́run fún Aísíìkì. Ṣùgbọ́n, rántí pé, ìgbéyàwó Aísíìkì ní ìsopọ̀ tààràtà pẹ̀lú ète Ọlọ́run láti pèsè irú-ọmọ kan nípasẹ̀ Ábúráhámù. Nítorí náà, àkọsílẹ̀ yìí kò yẹ kí ó mú wa parí èrò pé gbogbo ẹni tí ó bá gbàdúrà fún alábàáṣègbéyàwó ní a óò fún ní ọ̀kan lọ́nà ìyanu. Síbẹ̀, bí a bá dìrọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Jèhófà, òun yóò fún wa lókun láti fara da ìpèníjà tí ń bá ipò méjèèjì nínú ìgbésí ayé rìn—ìgbéyàwó tàbí ipò àpọ́n.—Kọ́ríńtì Kíní 7:8, 9, 28; fi wé Fílípì 4:11-13.
Élíésérì ní láti sapá gidigidi láti ṣe àwọn nǹkan lọ́nà ti Jèhófà. Àwa pẹ̀lú lè rí i pé fífara mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà kì í fi ìgbà gbogbo rọrùn. Fún àpẹẹrẹ, ó lè ṣòro láti rí iṣẹ́ tí kì yóò ṣèdíwọ́ fún ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run, alábàáṣègbéyàwó tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù-Ọlọ́run, àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tí ń gbéni ró, èrè ìnàjú tí kì í sọni dìbàjẹ́. (Mátíù 6:33; Kọ́ríńtì Kíní 7:39; 15:33; Éfésù 4:17-19) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jèhófà lè mú àwọn tí wọ́n bá kọ̀ láti fi àwọn ìlànà Bíbélì báni dọ́rẹ̀ẹ́ dúró. Bíbélì ṣèlérí pé: “Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa; má sì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ. Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀: òun óò sì máa tọ́ ipa-ọ̀nà rẹ.”—Òwe 3:5, 6.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí a bá wo bí àwọn ìbakasíẹ ti lè sáré tó ní ìpíndọ́gba, ó ti lè gbà tó ọjọ́ 25 láti parí ìrìn-àjò náà.