ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò Tí wọn Ò Láyọ̀ Ló “Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì”
    Ilé Ìṣọ́—2007 | October 1
    • Àwọn Ọmọ Rákélì

      Láyé ìgbà yẹn, ìṣòro ńlá ni wọ́n ka àìlèbímọ sí. Ọlọ́run ti ṣèlérí fún Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù pé látinú ìdílé wọn ni “irú ọmọ” tí gbogbo ìdílé ayé yóò tipasẹ̀ rẹ̀ bù kún ara wọn ti máa jáde wá. (Jẹ́nẹ́sísì 26:4; 28:14) Síbẹ̀, Rákélì ò bímọ. Jékọ́bù gbà pé Ọlọ́run nìkan ló lè fún Rákélì lọmọ, kó bàa lè nípìn-ín nínú irú ìbùkún bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ojú ń kán Rákélì. Ó sọ fún Jékọ́bù pé: “Bílíhà ẹrúbìnrin mi rèé. Ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí ó lè bímọ lórí eékún mi àti pé kí èmi, àní èmi, lè ní àwọn ọmọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 30:2, 3.

      Ó lè má rọrùn fún wa láti lóye ohun tí Rákélì ṣe yìí. Àmọ́, àwọn àdéhùn ìgbéyàwó ayé ìgbàanì tí wọ́n rí láwọn àgbègbè Ìlà Oòrùn ayé fi hàn pé àṣà tí gbogbo èèyàn tẹ́wọ́ gbà ni pé kí aya tó bá yàgàn mú ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún ọkọ rẹ̀ kó lè bímọ tó máa jogún wọn.a (Jẹ́nẹ́sísì 16:1-3) Nígbà míì, ìyàwó ni wọ́n á sì gbà pé ó ní àwọn ọmọ tí ẹrúbìnrin náà bá bí.

      Nígbà tí Bílíhà bí ọmọkùnrin kan, inú Rákélì dùn gan-an, ó sì sọ pé: “Ọlọ́run ti ṣe bí onídàájọ́ fún mi, ó sì tún ti fetí sí ohùn mi, tí ó fi jẹ́ pé ó fi ọmọkùnrin kan fún mi.” Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì, tó túmọ̀ sí “Onídàájọ́.” Èyí fi hàn pé òun náà ti gbàdúrà nípa ìṣòro tó ní. Nígbà tí Bílíhà bí Náfútálì, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kejì, tórúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Ìjàkadì mi,” Rákélì sọ pé: “Gídígbò tí a jà ní àjàkú-akátá ni mo bá arábìnrin mi jà. Mo sì ti mókè!” Àwọn orúkọ wọ̀nyẹn fi hàn pé ìjà orogún wà láàárín wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 30:5-8.

      Ó ṣeé ṣe kí Rákélì rò pé òun ń ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tóun gbà nígbà tó mú Bílíhà fún Jékọ́bù, àmọ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run máa gbà fún un lọ́mọ kọ́ nìyẹn. Ẹ̀kọ́ kan lèyí jẹ́ fún wa. A ò gbọ́dọ̀ kánjú nígbà tá a bá ń bẹ Jèhófà fún ohun kan. Ó lè dáhùn àdúrà wa láwọn ọ̀nà tá ò fọkàn sí àti nígbà tá ò retí rẹ̀ rárá.

  • Àwọn Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò Tí wọn Ò Láyọ̀ Ló “Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì”
    Ilé Ìṣọ́—2007 | October 1
    • a Irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú Nuzi, lórílẹ̀-èdè Iraq kà pé: “Wọ́n ti mú Kelim-ninu fún Shennima láti fi ṣaya. . . . Tí Kelim-ninu ò bá bímọ, Kelim-ninu yóò ra obìnrin kan [ẹrúbìnrin kan] tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Lullu gẹ́gẹ́ bí aya fún Shennima.”

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́