TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | JÓSẸ́FÙ
“Ẹ Jọ̀wọ́, Ẹ Fetí sí Àlá Tí Mo Lá”
JÓSẸ́FÙ ń wo apá ìlà oòrùn lọ́hùn-ún bíi kó sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n kó o lẹ́rú. Ọ̀ọ́kán ibi tó ń wò ni ìlú Hébúrónì wà, ibẹ̀ ló ń gbé pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀. Ní báyìí, oòrùn ti ń wọ̀, Jékọ́bù bàbá rẹ̀ á sì ti máa retí rẹ̀ láì mọ̀ pé aburú kan ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin rẹ̀ tó fẹ́ràn jù. Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé kò ní rí bàbá rẹ̀ àtàtà yìí mọ́. Ńṣe ni inú àwọn tó kó o lẹ́rú ń dùn ṣìnkìn pé ọwọ́ àwọn ti ba gbẹ̀mù. Bí wọ́n ṣe ń da àwọn ràkúnmí wọn gba gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá gúúsù lọ, wọn ò jẹ́ kí ojú wọn kúrò lára rẹ̀ rárá torí tí wọ́n bá fi mú ọmọkùnrin yìí dé Íjíbítì, owó ńlá ni wọ́n máa tà á.
Jósẹ́fù kò ju ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún lọ lákòókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé. Oòrùn ti ń wọ̀ lọ́jọ́ náà, ó ṣeé ṣe kí Jósẹ́fù fún ojú pọ̀ bó ṣe ń wo apá ìwọ̀ oòrùn níbi tí Òkun Ńlá wà lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, á sì máa ṣe kàyéfì pé, ṣé ibi tí òun máa parí ìgbésí ayé òun sí nìyí. Ó ṣeé ṣe kí omi máa bọ́ lójú rẹ̀ bó ṣe ń rántí báwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe fẹ́ pa á àti bí wọ́n ṣe tà á sóko ẹrú. Ní báyìí, kò mọ bí ọjọ́ iwájú ṣe fẹ́ rí fún òun.
Báwo ni Jósẹ́fù ṣe bá ara rẹ̀ ní irú ipò yìí? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú bó ṣe lo ìgbàgbọ́ láìka bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe ṣe ẹ̀tanú sí i?
ÌDÍLÉ TÓ TI WÁ KÒ FARA RỌ
Ìdílé ńlá ni Jósẹ́fù ti wá, àmọ́ ìdílé náà kò sí ní ìṣọ̀kan, wọn ò sì láyọ̀. Ohun tí Bíbélì ròyìn nípa ìdílé Jékọ́bù jẹ́ ká mọ̀ pé ewu ń bẹ nílé olórogún. Ohun tó sì wọ́pọ̀ nígbà náà nìyẹn torí pé àwọn ọkùnrin sábà máa ń ní ju ìyàwó kan lọ. Nígbà tó yá ni Jésù là á mọ́lẹ̀ pé ìyàwó kan ló yẹ kéèyàn máa ní. (Mátíù 19:4-6) Ìyàwó mẹ́rin ni Jékọ́bù ní. Orúkọ wọn ni Rákélì àti Léà, àtàwọn ẹrúbìnrin wọn tó ń jẹ́ Sílípà àti Bílíhà. Lápapọ̀, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin bí ó kéré tán ọmọ mẹ́rìnlá fún Jékọ́bù. Látìbẹ̀rẹ̀, Rákélì ni ọkàn Jékọ́bù yàn láti fẹ́, kò fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn Léà tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Rákélì. Àmọ́ àwọn ẹbí ìyàwó da nǹkan rú mọ́ ọn lọ́wọ́, bó ṣe di pé ó fẹ́ Léà nìyẹn. Torí náà, kò sí ìrẹ́pọ̀ láàárín Rákélì àti Léà, aáwọ̀ yìí sì gbóná débi pé ó ran àwọn ọmọ wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 29:16-35; 30:1, 8, 19, 20; 37:35.
Rákélì yàgàn fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ níkẹyìn ó rọ́mọ bí, ó bí Jósẹ́fù. Inú Jékọ́bù ọkọ rẹ̀ dùn débi pé ààyò ló fi ọmọ ọjọ́ ogbó rẹ̀ yìí ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jékọ́bù ń kó ìdílé rẹ̀ lọ pàdé Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀, ó dọ́gbọ́n fi Rákélì àti Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀ sọ́wọ́ ẹ̀yìn níbi tí ewu kankan kò ti lè wu wọ́n. Ó dájú pé Jósẹ́fù kò lè gbàgbé bí bàbá rẹ̀ ṣe dáàbò bò ó lọ́jọ́ náà. Ẹ wo bó ṣe máa dun Jósẹ́fù tó nígbà tó jí láàárọ̀ ọjọ́ kan tó sì rí bàbá rẹ̀ tó ń tẹ̀ kẹ́ńjẹ́-kẹ́ńjẹ́. Ẹnu á wá yà á nígbà tó gbọ́ pé áńgẹ́lì ni bàbá òun bá wọ̀yá ìjà láti alẹ́ mọ́jú ọjọ́ kejì tó fi di pé kò lè rìn dáadáa! Ìdí tí bàbá àgbàlagbà yìí fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ gba ìbùkún lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run. Ìbùkún tí Jékọ́bù sì rí gbà ni pé Jèhófà yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Ísírẹ́lì. Ìyẹn ni pé orúkọ rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè kan yóò máa jẹ́! (Jẹ́nẹ́sísì 32:22-31) Jósẹ́fù wá mọ̀ pé láti ara Ísírẹ́lì, ìyẹn bàbá òun ni gbogbo àwọn tó máa di ẹ̀ya orílẹ̀-èdè náà yóò ti wá!
Nígbà tó yá, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó bani nínú jẹ́ wáyé ní ìgbésí ayé Jósẹ́fù, ọ̀dọ́ ló ṣì wà nígbà tí ẹni tó fẹ́ràn jù lọ láyé kú láìrò tẹ́lẹ̀. Ìyá rẹ̀ ló kú nígbà tó fẹ́ bí Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀. Ikú yìí sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jékọ́bù pàápàá. Ẹ lè fojú inú wo bí Jékọ́bù ṣe ń nu omijé nù kúrò lójú Jósẹ́fù, tó sì ń tù ú nínú pẹ̀lú ìrètí àjíǹde tó tu Ábúráhámù baba ńlá rẹ̀ náà nínú nígbà tó ń ṣọ̀fọ̀ Sárà lọ́jọ́ kìíní àná. Ó dájú pé á tu Jósẹ́fù nínú gan-an nígbà tó mọ̀ pé lọ́jọ́ iwájú, òun ṣì máa rí ìyá òun nígbà tí Jèhófà bá jí i dìde nínú Párádísè! Èyí á mú kó túbọ̀ mọyì inú rere “Ọlọ́run . . . àwọn alààyè.” (Lúùkù 20:38; Hébérù 11:17-19) Látìgbà tí Rákélì ìyàwó rẹ̀ ọ̀wọ́n ti kú ni Jékọ́bù ti nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ sí Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.—Jẹ́nẹ́sísì 35:18-20; 37:3; 44:27-29.
Tó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ míì ni, irú ọwọ́ tí bàbá wọn fi mú wọn lè mú kí wọ́n máa yọ ayọ̀ pọ̀rọ́. Àmọ́ Jósẹ́fù gbé àwọn ìwà rere tó kọ́ lára àwọn òbí rẹ̀ yọ, ó sì di ẹni tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, èyí sì mú kó lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Kò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún lọ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í ran àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ́wọ́ níbi tí wọ́n ti ń ṣọ́ àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀. Nígbà tó kíyè sí pé wọ́n ń hùwà tí kò dáa, kíá ló ti sọ fún bàbá rẹ̀. Kò tìtorí ojúure tó lè rí gbà lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi ọ̀rọ̀ náà ṣe bójú-rí-ẹnu-á-dákẹ́. Ó mọ̀ pé bí òun ṣe sọ ọ̀rọ̀ náà fún bàbá òun ló tọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 37:2) Ohun tó ṣe yẹn gba ìgboyà, ó sì dájú pé ìwà rẹ̀ fi ọkàn Jékọ́bù balẹ̀ pé ọmọ gidi ni òun ní. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ Kristẹni lónìí! Tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan dẹ́ṣẹ̀, kódà kó jẹ́ àbúrò tàbí ọ̀rẹ́ wa àtàtà, ó yẹ ká fara wé Jósẹ́fù, ká sì lọ sọ fún àwọn tá a bá mọ̀ pé ó máa ran ẹni náà lọ́wọ́.—Léfítíkù 5:1.
Ẹ̀kọ́ míì wà tá a lè kọ́ lára ìdílé Jósẹ́fù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Kristẹni kì í kó ìyàwó jọ lónìí, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ìdílé ni nǹkan ti yí pa dà fún. Bí àpẹẹrẹ, àwọn míì ń gbé pẹ̀lú ọmọ ọkọ tàbí aya tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́, tàbí kó jẹ́ àwọn ọmọ ló ń gbé pẹ̀lú ẹni tí bàbá tàbí ìyá wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́. Téèyàn bá ń ṣe ojúṣàájú nínú ìdílé, ó lè da ìdílé rú. Ẹ̀yin òbí, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá tàbí ìyá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló bí àwọn ọmọ tó wà nínú ìdílé yín, ó yẹ kẹ́ ẹ fọgbọ́n ṣeé, kí ẹ máa fọkàn àwọn ọmọ yín balẹ̀ pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ ọmọ gidi, àti pé ẹ fẹ́ràn wọn gan-an.—Róòmù 2:11.
OWÚ BẸ̀RẸ̀
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Jósẹ́fù ṣe fìgboyà ṣe ohun tó tọ́ ló jẹ́ kí Jékọ́bù bàbá rẹ̀ dá a lọ́lá. Ó ṣe ẹ̀wù gígùn, abilà tí ó dà bí ṣẹ́ẹ̀tì fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 37:3) Àwọn kan máa ń pe aṣọ náà ní ẹ̀wù àwọ̀lékè aláràbarà, àmọ́ ohun tá a mọ̀ ni pé ẹ̀wù kan tó gùn dé apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ ni. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ irú ẹ̀wù tí àwọn olóyè tàbí ọmọ ọba máa ń wọ̀ ni.
Ohun tó dáa ló kúkú wà lọ́kàn Jékọ́bù tó fi ṣe ohun tó ṣe yẹn, ó dájú pé ohun tí bàbá rẹ̀ ṣe yìí mú orí Jósẹ́fù wú, á sì fi í lọ́kàn balẹ̀ pé bàbá òun nífẹ̀ẹ́ òun gan-an. Ṣùgbọ́n àfàìmọ̀ kò má jẹ́ pé ẹ̀wù yìí ló ṣì máa dá wàhálà sílẹ̀ fún un. Ṣé ẹ rántí pé iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ni ọmọ náà ń ṣe. Iṣẹ́ àṣelàágùn sì ni. Ẹ wá fojú wo bó ṣe máa rí tí ọmọ náà bá wọ aṣọ aláràbarà yìí, tó wá ń la inú igbó kiri, tó sì ń gun òkè láti lọ wá àgùntàn tó ti há síbi igi ẹ̀gún. Èyí tó tiẹ̀ máa le jù ni pé irú ojú wo làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi máa wò ó nítorí ẹ̀wù àrà ọ̀tọ̀ tí bàbá wọn ṣe fún òun nìkan?
Ẹ gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ, ó ní: “Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ wá rí i pé baba àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ju gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra rẹ̀, wọn kò sì lè bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà àlàáfíà.”a (Jẹ́nẹ́sísì 37:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè fa owú lóòótọ́, àmọ́ kò yẹ kí àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù jẹ́ kí ìlara wọ àwọn lọ́kàn. (Òwe 14:30; 27:4) Ṣé o ti bá ara rẹ ní irú ipò bẹ́ẹ̀ rí, tó jẹ́ pé ńṣe lo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara ẹnì kan torí pé àwọn èèyàn gba tiẹ̀ tàbí wọ́n fi nǹkan kan dá a lọ́lá? Rántí àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù. Owú tó jọba nínú ọkàn wọn jẹ́ kí wọ́n gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan tí wọ́n kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn. Ìránnilétí àti ẹ̀kọ́ ńlá ni àpẹẹrẹ wọn jẹ́ fún àwa Kristẹni lónìí. Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé ká máa “yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀.”—Róòmù 12:15.
Jósẹ́fù náà ti fura pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti ń bínú òun. Ṣé ó wá tọ́jú ẹ̀wù aláràbarà tí bàbá rẹ̀ fún un káwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ má bàa rí? Ó ṣeé ṣe kí ìbẹ̀rù mú kó fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ẹ rántí pé Jékọ́bù fẹ́ kí ẹ̀wù náà jẹ́ àmì pé ààyò ọmọ ni Jósẹ́fù jẹ́, òun sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Jósẹ́fù náà fẹ́ kí inú bàbá òun máa dùn tó bá ń rí ẹ̀wù yẹn lára òun, ni òun náà bá ń wọ ẹ̀wù náà kiri. Àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn jẹ́ fáwa náà lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Baba wa ọ̀run kì í ṣe ojúṣàájú, àmọ́ nígbà míì, ó máa ń dìídì ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lóore. Ó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn tó jẹ́ oníwà pálapàla àti onímàgòmágó nínú ayé yìí. Bí ẹ̀wù Jósẹ́fù ṣe mú kó dá yàtọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà àwa Kristẹni tòótọ́ ṣe mú ká yàtọ̀ sí àwọn tó yí wa ká. Èyí sì lè mú káwọn èèyàn ayé bẹ̀rẹ̀ sí í jowú wa tàbí kí wọ́n máa bínú wa. (1 Pétérù 4:4) Bí Jósẹ́fù kò ṣe fi ẹ̀wù àmúyangàn rẹ̀ pamọ́ torí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni kò yẹ kí Kristẹni kan fi ìwà rẹ̀ pamọ́ tàbí kó máa díbọ́n kí àwọn èèyàn má bàa rí sí i.—Lúùkù 11:33.
ÀWỌN ÀLÁ JÓSẸ́FÙ
Nígbà tó ṣe, Jósẹ́fù lá àwọn àlá méjì tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Nínú àlá àkọ́kọ́, Jósẹ́fù rí i pé òun àti àwọn ẹ̀gbọ́n òun ń di ìtí. Àmọ́ ìtí Jósẹ́fù dìde, ìtí tàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í pagbo yí ìtí rẹ̀ ká, wọ́n sì ń tẹrí ba fún un. Nínú àlá kejì, Jósẹ́fù rí i tí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ mọ́kànlá ń tẹrí ba fún òun. (Jẹ́nẹ́sísì 37:6, 7, 9) Kí ló yẹ kí Jósẹ́fù ṣe nípa àwọn àlá àràmàǹdà yìí?
Jèhófà ló fi àlá yẹn hàn-án lójú oorun. Àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni Jèhófà fi hàn an, ó sì fẹ́ kó sọ ọ́ fáwọn ara ilé rẹ̀. Lọ́nà kan, ohun tí Jèhófà fẹ́ kí Jósẹ́fù ṣe jọ ohun táwọn wòlíì tó gbáyé lẹ́yìn rẹ̀ ṣe, ìyẹn ni pé wọ́n jíṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn tó jẹ́ aláìgbọràn.
Jósẹ́fù wá fọgbọ́n sọ fáwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fetí sí àlá tí mo lá yìí.” Ìtúmọ̀ àlá náà yé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, èyí sì mú kí inú túbọ̀ bí wọn. Wọ́n wá sọ fún un pé: ‘Ìwọ yóò ha jọba lé wa lórí kó o sì jẹ gàba lé wa lórí dájúdájú bí?’ Àkọsílẹ̀ náà wá fi kún un pé: “Nítorí náà, wọ́n rí àkọ̀tun ìdí láti kórìíra rẹ̀ lórí àwọn àlá rẹ̀ àti lórí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀.” Nígbà tí Jósẹ́fù wá rọ́ àlá kejì fún bàbá rẹ̀ àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ńṣe ni wọ́n tún kẹ́nu bò ó. Bíbélì sọ pé: “Baba rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí lọ́nà mímúná, pé: “Kí ni àlá tí o lá yìí túmọ̀ sí? Èmi àti ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ pẹ̀lú yóò ha wá tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún ọ dájúdájú bí?’” Àmọ́ Jékọ́bù bàbá rẹ̀ ò yé ro ọ̀rọ̀ náà pé àbí Jèhófà ló ń bá ọmọ náà sọ̀rọ̀ ni?—Jẹ́nẹ́sísì 37:6, 8, 10, 11.
Jósẹ́fù kọ́ ló máa kọ́kọ́ jíṣẹ́ Ọlọ́run tó bí àwọn èèyàn nínú, òun sì kọ́ ló máa jẹ́ irú ẹ̀ kẹ́yìn. Jésù Kristi ni ọ̀gá nínú àwọn tó jẹ́ irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòhánù 15:20) Gbogbo Kristẹni lọ́mọdé lágbà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìgboyà Jósẹ́fù.
ÌKÓRÌÍRA NÁÀ WÁ DÓJÚ Ẹ̀
Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Jékọ́bù rán Jósẹ́fù níṣẹ́ kan tó gbẹgẹ́. Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù da àgùntàn lọ sí ìtòsí ìlú Ṣékémù níbi tí wọ́n ti lọ jà níjelòó. Ọkàn bàbá wọn ò sì balẹ̀ rárá nítorí ibi tí wọ́n lọ, ló bá ní kí Jósẹ́fù lọ wò ó bóyá àlàáfíà làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wà. Fojú inú wo bí ọkàn Jósẹ́fù á ṣe máa lù kìkì, táyà rẹ̀ á sì máa já. Torí ó mọ̀ pé wọ́n kórìíra òun gan-an, wọn ò sì fẹ́ rí òun sójú. Ó lè ti máa ro ohun táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ á sọ sí i pé ‘ìwọ tún ni, ìwọ lẹ́nu ẹ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ àbí.’ Àmọ́ Jósẹ́fù mọ̀ pé kò sí ṣíṣe kò sí àìṣe, òun ò gbọ́dọ̀ kọṣẹ́ bàbá òun, ló bá kọrí síbi tí wọ́n rán-an.—Jẹ́nẹ́sísì 34:25-30; 37:12-14.
Ìlú Ṣékémù yìí jìnnà díẹ̀, ó tó nǹkan bíi ọgọ́rin [80] kìlómítà sí àríwá ìlú Hébúrónì, ó sì máa ń gbà tó ìrìn ọjọ́ mẹ́rin sí márùn-ún kéèyàn tó débẹ̀. Àmọ́ nígbà tí Jósẹ́fù dé ìlú Ṣékémù, ó gbọ́ pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti tún da ẹran lọ sí ọ̀nà àríwá ní ìlú Dótánì tí ó tó nǹkan bí i kìlómítà méjìlélógún [22] síbẹ̀. Bí Jósẹ́fù ṣe sún mọ́ Dótánì làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti rí i lọ́ọ̀ọ́kán. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ojú wọ́n pọ́n, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i wò ó bọ̀ tìkà-tẹ̀gbin. Bíbélì wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ní: “Nítorí náà, wọ́n wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: ‘Wò ó! Alálàá yẹn ní ń bọ̀ yìí. Wàyí o, ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì gbé e sọ sínú ọ̀kan nínú àwọn kòtò omi; àwa yóò sì sọ pé ẹranko ẹhànnà abèṣe ni ó pa á jẹ. Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a rí ohun tí àwọn àlá rẹ̀ yóò dà.’” Àmọ́, Rúbẹ́nì ẹ̀gbọ́n wọn àgbà ò fẹ́ kí wọ́n pa á, ó wá dọ́gbọ́n sọ fáwọn ìyókù pé káwọn jù ú sínú kòtò náà láàyè kó lè ríbi gbà á lẹ̀ tó bá yá.—Jẹ́nẹ́sísì 37:19-22.
Jósẹ́fù ò mọ ohun tí wọ́n ń gbèrò lọ́kàn, ó lè máa rò ó pé bóyá àwọn á tiẹ̀ rẹ́ lọ́tẹ̀ yìí. Àmọ́ ibi tó fojú sí ọ̀nà ò gba bẹ̀. Ńṣe làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣùrù bò ó, tí wọ́n sì fìbínú bọ́ ẹ̀wù tí bàbá rẹ̀ fún un kúrò lọ́rùn rẹ̀. Àfi jùà! Ni wọ́n gbé e sọ sínú kòtò náà! Bí Jósẹ́fù ṣe ń pa rìdàrìdà nínú kòtò yẹn ló ń sapá láti pọ́n ògiri náà pa dà sókè, ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe. Ojú ọ̀run nìkan ló ń rí, ó sì ń gbọ́ ohùn àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí i bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣàánú òun àmọ́ wọn ò dá a lóhùn. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n dáná, wọ́n jẹun, wọ́n tún nu ẹnu nù. Nígbà tí wọ́n rí i pé Rúbẹ́nì ò sí láàárín àwọn, wọ́n tún gbèrò láti pa á àmọ́ Júdà dábàá pé kàkà káwọn pa á, á dáa káwọn kúkú tà á fáwọn oníṣòwò tó bá kọjá. Ìlú Dótánì ò jìnnà sí ọ̀nà táwọn oníṣòwò tó ń lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì máa ń gbà kọjá, torí náà, kò pẹ́ táwọn oníṣòwò ìlú Mídíánì àti àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì fi gba ibẹ̀ kọjá. Kí Rúbẹ́nì tó pa dà dé, wọ́n ti ta àbúrò wọn sóko ẹrú fún ogún ṣékélì péré.b—Jẹ́nẹ́sísì 37:23-28; 42:21.
Bí Jósẹ́fù ṣe bá ara rẹ̀ ní ipò tá a ṣàlàyé látìbẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Báwọn oníṣòwò náà ṣe ń mú un gba ọ̀nà gúúsù tó lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì, ó ṣeé ṣe kó máa ronú pé, ‘ó tán wàyí! Bóyá ni màá gbúròó ilé mọ́.’ Ó mà ṣe o, Jósẹ́fù ò ní fojú kan àwọn ẹbí rẹ̀ mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, kò ní mọ bí Rúbẹ́nì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà ṣe fara ya nígbà tó pa dà dé tí ò sì rí i mọ́; kò tún ní mọ ọgbẹ́ ọkàn tó bá bàbá rẹ̀ nígbà tí wọ́n parọ́ fún un pé Jósẹ́fù ààyò ọmọ rẹ̀ ti kú, kò sì ní gbúròó Ísákì bàbá-bàbá rẹ̀ tó ṣì wà láàyè àti Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀ ọ̀wọ́n mọ́. Àmọ́, ṣé gbogbo ohun tí Jósẹ́fù ní náà ló pàdánù?—Jẹ́nẹ́sísì 37:29-35.
Jósẹ́fù ṣì ní ohun kan táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ò lè tà láéláé, ìyẹn ni ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó ti mọ Jèhófà, ìgbàgbọ́ tó sì ní nínú rẹ̀ lágbára gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rí àwọn ẹbí rẹ̀ mọ́, tí ẹ̀mí rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ kí wọ́n tó rìn dé Íjíbítì, wọ́n tún kàn-án lábùkù gẹ́gẹ́ bí ẹrú nílé ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Pọ́tífárì tó rà á nílẹ̀ Íjíbítì, síbẹ̀ náà, ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run ò yẹ̀ rárá. (Jẹ́nẹ́sísì 37:36) Kódà ńṣe ni ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù àti ìpinnu rẹ̀ láti ṣèfẹ́ Ọlọ́run túbọ̀ ń lágbára sì i bó ṣe ń kojú onírúurú ìṣòro. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó máa jáde lọ́jọ́ iwájú, a máa rí bí ìgbàgbọ́ tí Jósẹ́fù ní ṣe mú kó túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àtàwọn ẹbí rẹ̀ tí ìdààmú bá. Ìwà ọgbọ́n ló máa jẹ́ fáwa náà láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù!
a Àwọn olùwádìí kan sọ pé ohun tó wà lọ́kàn àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ni pé bí Jékọ́bù bàbá àwọn ṣe dá Jósẹ́fù lọ́lá yẹn fi hàn pé ó fẹ́ gbé ipò àkọ́bí fún Jósẹ́fù. Wọ́n mọ̀ pé Jósẹ́fù ni àkọ́bí ìyàwó tí Jékọ́bù fẹ́ràn jù, ìyá Jósẹ́fù sì ni bàbá wọn ì bá kọ́kọ́ fẹ́. Bákan náà, Rúbẹ́nì tó jẹ́ àkọ́bí Jékọ́bù ti ba ara ẹ̀ lórúkọ jẹ́, ó sì pàdánù ogun rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i àkọ́bí nígbà tó bá ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó bàbá rẹ̀ sùn tó sì tipa bẹ́ẹ̀ dójú ti bàbá rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 35:22; 49:3, 4.
b Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun tó wà nínú Bíbélì yẹn. Àwọn àkájọ ìwé tí wọ́n kọ lásìkò yẹn fi hàn pé ogún ṣékélì ni iye tí wọ́n ń ta ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì.