Bí Ìràpadà Ṣe Lè Gbà Wá Là
“Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè, ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.”—JÒH. 3:36.
1, 2. Kí ni ọ̀kan lára ìdí tí wọ́n fi kọ́kọ́ ń tẹ ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower?
“KÒ SÍ ẹni tó fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí kò ní rí bí ikú Kristi ti ṣe pàtàkì tó.” Èyí ni gbólóhùn tó wà nínú ẹ̀dà kẹrin ìwé ìròyìn yìí tí wọ́n ṣe jáde lóṣù October, lọ́dún 1879. Gbólóhùn tó ń múni ronú jinlẹ̀ tó parí àpilẹ̀kọ náà wá sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra fún ohunkóhun tí kò bá ka ikú Kristi sí tàbí tó fọwọ́ rọ́ ọ tì sẹ́yìn pé kì í ṣe ìrúbọ tó ra ẹ̀ṣẹ̀ pa dà.”—Ka 1 Jòhánù 2:1, 2.
2 Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí wọ́n fi kọ́kọ́ tẹ ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower jáde ní July 1879 ni kí wọ́n lè lò ó láti gbèjà ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ìràpadà. Àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,’ torí pé ní apá ìparí àwọn ọdún 1800, àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa bí ikú Jésù ṣe lè jẹ́ ìràpadà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Mát. 24:45) Àti pé nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ ló ń gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́, èyí tó ta ko òtítọ́ náà pé aráyé ti di aláìpé. Àwọn onímọ̀ ẹfolúṣọ̀n ń kọ́ni pé ipò aráyé ń sunwọ̀n sí i fúnra rẹ̀ torí náà wọn kò nílò ìràpadà. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí ìkìlọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì fi ṣe pàtàkì gan-an nígbà yẹn. Ó sọ pé: “Máa ṣọ́ ohun tí a tò jọ ní ìtọ́júpamọ́ sọ́dọ̀ rẹ, yẹra fún àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ àti fún àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’ Nítorí ní ṣíṣe àṣehàn irúfẹ́ ìmọ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn kan ti yapa kúrò nínú ìgbàgbọ́.”—1 Tím. 6:20, 21.
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò báyìí?
3 Ó dájú pé o kò fẹ́ láti “yapa kúrò nínú ìgbàgbọ́.” Kí ìgbàgbọ́ rẹ bàa lè máa lágbára, ó máa dára kó o gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò: Kí nìdí tí mo fi nílò ìràpadà? Kí ló ná Ọlọ́run àti Jésù láti pèsè rẹ̀? Báwo ni mo ṣe lè jàǹfààní látinú ìpèsè ṣíṣeyebíye tó lè gbà mí lọ́wọ́ ìrunú Ọlọ́run yìí?
A Gbà Wá Lọ́wọ́ Ìrunú Ọlọ́run
4, 5. Kí ló fi hàn pé ìrunú Ọlọ́run ṣì wà lórí ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí?
4 Bíbélì àtàwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn fi hàn pé látìgbà tí Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀ ni ìrunú Ọlọ́run ‘ti wà lórí’ ìràn ẹ̀dá èèyàn. (Jòh. 3:36) A sì rí ẹ̀rí èyí kedere ní ti pé bó ti wù kéèyàn pẹ́ láyé tó, ikú ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀. Àkóso tí Sátánì gbé kalẹ̀ láti ta ko Ọlọ́run ti kùnà ní gbogbo ọ̀nà torí pé kò lè dáàbò bo aráyé kúrò lọ́wọ́ àwọn ìyọnu àjálù tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí, kò sì sí ìjọba èèyàn kankan tó lè pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí tí gbogbo àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí nílò. (1 Jòh. 5:19) Ìyẹn ni ogun, ìwà ọ̀daràn àti òṣì fi ń fojú aráyé rí màbo.
5 Torí náà, ó ṣe kedere pé ìbùkún Jèhófà kò sí lórí ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí. Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìrunú Ọlọ́run ni a ń ṣí payá láti ọ̀run lòdì sí gbogbo àìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (Róòmù 1:18-20) Torí náà, àwọn tí kò ronú pìwà dà, tí wọ́n ń bá a nìṣó láti máa gbé ìgbésí ayé tó lòdì sí ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, kò ní ṣaláì jìyà àbájáde ìwà wọn. Lónìí, ìrunú Ọlọ́run ni à ń sọ di mímọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tí à ń tú jáde bí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn sórí ayé Sátánì, a sì máa ń gbé irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ jáde nínú àwọn ìwé wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì.—Ìṣí. 16:1.
6, 7. Iṣẹ́ wo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń múpò iwájú nínú rẹ̀ báyìí, àǹfààní wo ni àwọn tó ṣì jẹ́ apá kan ayé Sátánì ní?
6 Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ó ti pẹ́ jù fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láti já ara rẹ̀ gbà kúrò lábẹ́ ìdarí Sátánì kó sì rí ojú rere Ọlọ́run? Rárá o, àǹfààní ṣì wà láti bá Jèhófà rẹ́. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí wọ́n jẹ́ “ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi,” ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún gbogbo èèyàn. Wọ́n sì ń tipasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí pàrọwà fún àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n “padà bá Ọlọ́run rẹ́.”—2 Kọ́r. 5:20, 21.
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù “dá wa nídè kúrò nínú ìrunú tí ń bọ̀.” (1 Tẹs. 1:10) Nígbà tí Jèhófà bá tú èyí tó gbẹ̀yìn lára ìrunú rẹ̀ jáde, ó máa yọrí sí ìparun àìnípẹ̀kun fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà. (2 Tẹs. 1:6-9) Ta ló máa yè bọ́? Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè, ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.” (Jòh. 3:36) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn tó bá wà láàyè tí wọ́n sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù àti ìràpadà máa yè bọ́ nígbà tí Ọlọ́run bá tú èyí tó gbẹ̀yìn lára ìrunú rẹ̀ jáde.
Iṣẹ́ Tí Ìràpadà Ń Ṣe
8. (a) Àǹfààní àgbàyanu wo ló wà níwájú Ádámù àti Éfà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé Ọlọ́run tí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ jẹ́ pípé ni òun?
8 Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà ní pípé. Ká ní wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run ni, ayé ì bá ti kún fún àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ń fi ayọ̀ gbé pẹ̀lú wọn nínú Párádísè. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run. Nítorí èyí, Ọlọ́run dájọ́ ikú ayérayé fún wọn, ó sì lé wọn kúrò nínú Párádísè ìpilẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí Ádámù àti Éfà fi máa bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ, ẹ̀ṣẹ̀ ti ń nípa lórí aráyé. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ di arúgbó wọ́n sì kú. Èyí fi hàn pé Jèhófà mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ó ṣe tán, Ọlọ́run tí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ jẹ́ pípé ni Jèhófà. Ó ti kìlọ̀ fún Ádámù pé tó bá jẹ nínú èso tí òun kà léèwọ̀ yẹn ńṣe ló máa kú, ikú náà ló sì yọrí sí fún un.
9, 10. (a) Kí ló fà á tí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù fi ń kú? (b) Báwo la ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ikú ayérayé?
9 Gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Ádámù, a ti jogún ara àìpé tó máa ń fẹ́ láti dẹ́ṣẹ̀, tó sì máa ń kú. Lẹ́yìn tí Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀ ló tó bẹ̀rẹ̀ sí í bí wa, nípa bẹ́ẹ̀ àwa náà jogún ẹ̀ṣẹ̀. Torí náà, ẹjọ́ ikú tí Ọlọ́run dá fún wọn kan àwa náà. Bí Jèhófà bá ní láti yí ègún yìí pa dà láìsí pé a rà wá pa dà, ó máa já sí pé kò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Kódà, ọ̀rọ̀ tó kan gbogbo wa ni Pọ́ọ̀lù ń sọ nígbà tó wí pé: “A mọ̀ pé Òfin jẹ́ ti ẹ̀mí; ṣùgbọ́n èmi jẹ́ ẹlẹ́ran ara, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?”—Róòmù 7:14, 24.
10 Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè gbé ìlànà tó bá òfin mu kálẹ̀, èyí tí yóò fi lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá tí yóò sì fi gbà wá lọ́wọ́ ikú ayérayé tó yẹ kó jẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó ṣe èyí nípa rírán Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n láti ọ̀run tá a sì bí i sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé, tó máa lè fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Jésù kò jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ sọ òun di aláìpé bíi ti Ádámù. Kódà, “kò [tiẹ̀] dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pét. 2:22) Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún Jésù láti bí àwọn ọmọ tó máa di ìran èèyàn pípé. Àmọ́, dípò bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run pa òun kó bàa lè gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù ṣọmọ, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lára wọn láti rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run kan ni ó wà, àti alárinà kan láàárín Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn, ọkùnrin kan, Kristi Jésù, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fúnni ní ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tím. 2:5, 6.
11. (a) Báwo la ṣe lè ṣàkàwé àwọn àǹfààní tó wà nínú ìràpadà? (b) Àwọn wo ló máa jàǹfààní látinú ìràpadà?
11 Iṣẹ́ tí ìràpadà ń ṣe la lè fi wé ipò táwọn èèyàn máa bá ara wọn bí ilé ìfowópamọ́ kan tí wọ́n ti ń hùwà ìbàjẹ́ bá lù wọ́n ní jìbìtì tó sì sọ wọ́n di ajigbèsè. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n fi òfin gbé àwọn tó ni ilé ìfowópamọ́ náà, tí wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n, àwọn tí owó wọ́n há sílé ìfowópamọ́ náà ńkọ́? Wọ́n wọ gbèsè nìyẹn, kò sì sí ohun tí wọ́n lè ṣe àyàfi tí ọkùnrin olówó kan tó jẹ́ aláàánú bá gba ilé ìfowópamọ́ náà, tó dá owó àwọn oníbàárà pa dà fún wọn, ni wọ́n tó lè bọ́ nínú gbèsè náà. Ní ọ̀nà kan náà, Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ti ra àwọn ọmọ Ádámù pa dà ó sì ti wọ́gi lé gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wọn lọ́lá ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rúbọ. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Jòhánù Oníbatisí fi lè sọ nípa Jésù pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” (Jòh. 1:29) Ẹ̀ṣẹ̀ aráyé tí Jésù kó lọ kì í ṣe tàwọn alààyè nìkan, ó tún kó ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó ti kú lọ pẹ̀lú.
Ohun Tí Ìràpadà Ná Ọlọ́run àti Jésù
12, 13. Kí la lè rí kọ́ látinú bí Ábúráhámù ṣe fínnúfíndọ̀ fẹ́ láti fi Ísáákì rúbọ?
12 Kò ṣeé ṣe fún wa láti lóye ohun tí ìràpadà ná Baba wa ọ̀run àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Àmọ́, Bíbélì sọ àwọn ìrírí tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àṣàrò lórí ọ̀ràn yìí. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bó ṣe máa rí lára Ábúráhámù nígbà tó rin ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ta lọ sí ilẹ̀ Móráyà ní ìgbọràn sí àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún un pé: “Jọ̀wọ́, mú ọmọkùnrin rẹ, ọmọkùnrin rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi, Ísákì, kí o sì rìnnà àjò lọ sí ilẹ̀ Móráyà, kí o sì fi í rúbọ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè ńlá tí èmi yóò tọ́ka sí fún ọ.”—Jẹ́n. 22:2-4.
13 Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ábúráhámù dé ibi tí Ọlọ́run tọ́ka sí fún un. Wo bó ṣe máa bà á nínú jẹ́ tó láti de Ísáákì tọwọ́ tẹsẹ̀ kó sì gbé e sórí pẹpẹ tí òun fúnra rẹ̀ tẹ́. Ó ti ní láti ba Ábúráhámù lọ́kàn jẹ́ gan-an nígbà tó mú ọ̀bẹ láti fi dúńbú ọmọ rẹ̀! Ronú nípa bí ọ̀ràn náà á ṣe rí lára Ísáákì lórí pẹpẹ tí wọ́n tẹ́ ẹ sí, tó ń retí bí òun á ṣe máa jẹ̀rora nígbà tí bàbá rẹ̀ bá da ọ̀bẹ dé e láti dúńbú rẹ̀. Kí Ábúráhámù tó dúńbú Ísáákì ni áńgẹ́lì Jèhófà ti dá a dúró. Ohun tí Ábúráhámù àti Ísáákì ṣe ní àkókò yẹn jẹ́ ká mọ bó ṣe máa rí lára Jèhófà nígbà tó yọ̀ọ̀da fún àwọn aṣojú Sátánì láti pa Ọmọ Rẹ̀. Bí Ísáákì ṣe fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù ṣàpẹẹrẹ bí Jésù ṣe fínnú fíndọ̀ gbà láti jìyà àti láti kú nítorí wa.—Héb. 11:17-19.
14. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jékọ́bù tó jẹ́ ká mọrírì ohun tí ìràpadà ná Ọlọ́run?
14 A tún lè fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jékọ́bù ṣàpèjúwe bí ìràpadà náà ṣe rí lára Jèhófà. Nínú gbogbo ọmọ tí Jékọ́bù bí, Jósẹ́fù ló fẹ́ràn jù lọ. Àmọ́, àwọn arákùnrin Jósẹ́fù ń jowú rẹ̀, wọ́n sì kórìíra rẹ̀. Síbẹ̀, Jósẹ́fù múra tán láti jẹ́ kí Jékọ́bù rán òun láti lọ wo àlàáfíà àwọn arákùnrin òun. Nígbà yẹn, wọ́n ń ṣe olùṣọ́ àwọn àgbo àgùntàn bàbá wọn ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà ní àríwá ilé wọn ní Hébúrónì. Ronú nípa bí ọ̀ràn náà á ṣe rí lára Jékọ́bù nígbà tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú aṣọ Jósẹ́fù dé, tí aṣọ náà sì ti rin gbingbin fún ẹ̀jẹ̀! Ó figbe ta pé: “Ẹ̀wù gígùn ọmọkùnrin mi ni! Ẹranko ẹhànnà abèṣe ti ní láti pa á jẹ! Dájúdájú, Jósẹ́fù ni a ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ!” Gbogbo èyí dun Jékọ́bù wọra gan-an ni, ó sì ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ nítorí Jósẹ́fù. (Jẹ́n. 37:33, 34) Bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn kọ́ ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà. Síbẹ̀, bá a bá ṣe àṣàrò lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jékọ́bù yìí, ó lè ràn wá lọ́wọ́ dé ìwọ̀n àyè kan, láti lóye bí ọ̀ràn ṣe ní láti rí lára Ọlọ́run nígbà tí wọ́n fìyà jẹ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n tí wọ́n sì pa á nípa ìkà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn lórí ilẹ̀ ayé.
Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìràpadà
15, 16. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba ìràpadà náà? (b) Àwọn àǹfààní wo lo ti rí gbà látinú ìràpadà?
15 Jèhófà Ọlọ́run jí Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ dìde pẹ̀lú ara tẹ̀mí tó jẹ́ ológo. (1 Pét. 3:18) Fún ogójì ọjọ́, lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti jí i dìde, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń fún ìgbàgbọ́ wọn lókun, ó sì múra wọn sílẹ̀ dé iṣẹ́ ìjíhìnrere tí wọ́n máa tó dáwọ́ lé. Lẹ́yìn náà ló gòkè re ọ̀run. Níbẹ̀, ó gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó fi ṣèrúbọ fún Ọlọ́run, kí Ọlọ́run lè máa wo ọlá rẹ̀ mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn tòótọ́ lára, bí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìtóye ẹbọ ìràpadà náà. Jèhófà Ọlọ́run fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìràpadà Kristi nígbà tó yàn án láti tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n pé jọ sí Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni.—Ìṣe 2:33.
16 Àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi yìí bẹ̀rẹ̀ sí í rọ àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn láti gba ara wọn kúrò lọ́wọ́ ìrunú Ọlọ́run nípa ṣíṣe batisí ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Ka Ìṣe 2:38-40.) Láti ọjọ́ mánigbàgbé yẹn títí di òní yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè la ti mú wọnú àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. (Jòh. 6:44) Níbi tá a bá ìjíròrò yìí dé, ó yẹ ká gbé ìbéèrè méjì míì yẹ̀ wò: Ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni nínú wa tó jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ rere rẹ̀ ló máa mú kó jogún ìyè àìnípẹ̀kun? Bá a sì ti ní ìrètí àgbàyanu yìí, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún wa láti pàdánù rẹ̀?
17. Ojú wo ló yẹ kó o máa fi wo ìbùkún àgbàyanu tó wà nínú jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
17 A kò lẹ́tọ̀ọ́ sí ìràpadà. Àmọ́, nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lónìí ti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ní ìrètí láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ ṣá o, dídi ọ̀rẹ́ Jèhófà kò fi hàn pé àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ á máa bá a nìṣó títí láé. Ká bàa lè yè bọ́ nígbà ìrunú Ọlọ́run tó ń bọ̀ wá, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti fi ìmọrírì tó jinlẹ̀ hàn fún “ìràpadà tí Kristi Jésù san.”—Róòmù 3:24; ka Fílípì 2:12.
Máa Bá A Nìṣó Láti Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Ìràpadà
18. Kí ló wé mọ́ lílo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà?
18 Ẹsẹ Bíbélì tí ẹṣin ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ yìí dá lé, ìyẹn Jòhánù 3:36, fi hàn pé lára ohun tó wé mọ́ lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi Olúwa ni pé ká máa ṣègbọràn sí i. Ìmọrírì tá a ní fún ìràpadà gbọ́dọ̀ mú ká máa gbé ìgbé ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni, tó fi mọ́ àwọn ohun tó sọ nípa ìwà híhù. (Máàkù 7:21-23) “Ìrunú Ọlọ́run . . . ń bọ̀” lórí gbogbo àwọn tí kò bá ronú pìwà dà, tí wọ́n sì ń lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà bí àgbèrè, ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn àti “ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo,” tó fi mọ́ wíwo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe.—Éfé. 5:3-6.
19. Àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ wo ló yẹ ká gbà fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà?
19 Ìmọrírì tá a ní fún ìràpadà gbọ́dọ̀ mú ká jẹ́ kí ọwọ́ wa dí fún “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Pét. 3:11) Ẹ jẹ́ ká máa ya àkókò tó pọ̀ tó sọ́tọ̀ déédéé fún gbígbàdúrà látọkànwá, ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sí ìpàdé, ìjọsìn ìdílé àti fífi ìtara lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ká má sì ṣe gbàgbé “rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.”—Héb. 13:15, 16.
20. Ìbùkún wo ni gbogbo àwọn tó ń bá a nìṣó láti máa lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà lè máa retí láti rí gbà lọ́jọ́ iwájú?
20 Nígbà tí Jèhófà bá tú ìrunú rẹ̀ jáde sórí ètò àwọn nǹkan búburú yìí, ẹ wo bí ayọ̀ wa ṣe máa pọ̀ tó pé a ti lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà, tá a sì ń bá a nìṣó láti máa fi ìmọrírì hàn fún un! Àti pé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, títí ayérayé la ó fi máa kún fún ọpẹ́ nítorí ìpèsè àgbàyanu tó gbà wá lọ́wọ́ ìrunú Ọlọ́run yìí.—Ka Jòhánù 3:16; Ìṣípayá 7:9, 10, 13, 14.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tá a fi nílò ìràpadà?
• Kí ni ìràpadà ná Ọlọ́run àti Jésù?
• Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú ìràpadà?
• Báwo la ṣe ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àǹfààní ṣì wà láti bá Jèhófà rẹ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Bá a bá ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ábúráhámù, Ísáákì àti Jékọ́bù, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì bí ohun tí ìràpadà ná Ọlọ́run àti Jésù ṣe pọ̀ tó