TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | JÓSẸ́FÙ
“Èmi Ha Wà ní Ipò Ọlọ́run Bí?”
JÓSẸ́FÙ nà ró nínú ọgbà rẹ̀ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Ó ṣeé ṣe kó rí àwọn igi ọ̀pẹ déètì àtàwọn igi eléso míì àti àwọn odò tó ní ewéko etí omi, ó sì ṣeé ṣe kó rí díẹ̀ lára ààfin Fáráò lápá iwájú lẹ́yìn ògiri. Wo bí ẹ̀rín Éfúráímù ọmọ Jósẹ́fù á ṣe máa ta sí Jósẹ́fù létí díẹ̀díẹ̀ bí Mánásè ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe ń bá a ṣeré. Jósẹ́fù ń ro ohun tó ṣeé ṣe kó máa ṣẹlẹ̀ nínú ilé bí àwọn ọmọ yẹn ṣe ń pa ìyá wọn lẹ́rìn-ín. Ó rẹ́rìn-ín músẹ́. Ó rí i pé Ọlọ́run ti bù kún òun.
Jósẹ́fù pe àkọ́bí rẹ̀ ní Mánásè torí orúkọ yìí tọ́ka sí ìgbàgbé. (Jẹ́nẹ́sísì 41:51) Ó dájú pé bí Ọlọ́run ṣe bù kún Jósẹ́fù láwọn ọdún àìpẹ́ yìí ti mú kí ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń ní tó bá rántí ilé rọlẹ̀, pàápàá tó bá ń rántí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti bàbá rẹ̀. Ìkórìíra táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní sí i ti yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà. Wọ́n fìyà jẹ ẹ́, wọ́n gbèrò láti pa á, wọ́n sì tà á bí ẹrú fún àwọn olówò arìnrìn àjò. Àtìgbà yẹn ló ti di pé bó ṣe ń paná ìṣòro kan nínú ayé rẹ̀ ni òmíì ń rú. Lẹ́nu nǹkan bí ọdún méjìlá, ó lọ sóko ẹrú, ó sì fìgbà kan wà nínú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́wọ̀n. Àmọ́ ní báyìí, òun rèé ní Íjíbítì, ó ti di igbá kejì Fáráò tó jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè ńlá yìí!a
Ọdún mélòó kan kọjá, Jósẹ́fù ti ń rí bí àwọn nǹkan ṣe ń ṣẹlẹ̀ bí Jèhófà ṣe sọ gẹ́lẹ́. Ọdún méje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ máa wà ti bẹ̀rẹ̀ ní Íjíbítì, Jósẹ́fù sì ti ń bójú tó bí wọ́n ṣe ń tọ́jú gbogbo oúnjẹ tó ṣẹ́ kù lórílẹ̀-èdè náà. Láàárín àkókò yìí, òun àti ìyàwó rẹ̀, Ásénátì ti bí ọmọkùnrin méjì. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà lọkàn rẹ̀ máa ń fà sọ́dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, pàápàá Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀ àti Jékọ́bù, bàbá rẹ̀ ọ̀wọ́n. Ó ṣeé ṣe kí Jósẹ́fù ti máa ṣàníyàn nípa bóyá àlàáfíà ni wọ́n wà. Ó sì ti lè máa ṣe kàyéfì nípa bóyá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti yí ìwà búburú wọn pa dà àti pé ṣé òun á tún lè wà pa pọ̀ pẹ̀lú ìdílé bàbá òun.
Tí owú, ìwà ọ̀dàlẹ̀ tàbí ìkórìíra bá ti dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìdílé rẹ rí, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ rẹ àti ti Jósẹ́fù jọra. Kí la rí kọ́ lára Jósẹ́fù nínú bó ṣe ní ìgbàgbọ́ tó sì pèsè fún ìdílé rẹ̀?
“Ẹ LỌ BÁ JÓSẸ́FÙ”
Ọwọ́ Jósẹ́fù dí jọjọ, ọdún sì ń yára gorí ọdún. Àmọ́ ìyípadà kan ṣàdédé wáyé lẹ́yìn ọdún keje tí irè oko fi pọ̀ wọ̀ǹtìwọnti gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe fi han Fáráò lójú àlá. Irè oko ò ṣe dáadáa mọ́! Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú ní gbogbo ilẹ̀ tó yí wọn ká. Àmọ́ Bíbélì fi hàn pé, “oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.” (Jẹ́nẹ́sísì 41:54) Ó dájú pé ohun tí Ọlọ́run mí sí Jósẹ́fù láti sọ tẹ́lẹ̀ àti àpẹẹrẹ bó ṣe ṣètò nǹkan lọ́nà tó dára ṣe àwọn ará Íjíbítì láǹfààní.
Ó ṣeé ṣe kí àwọn ará Íjíbítì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jósẹ́fù pé ó kú àgbàálẹ̀ àwọn, kí wọ́n sì máa kan sáárá sí ọ̀nà tó ń gbà ṣètò nǹkan. Ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ló máa fẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún dípò òun. Tá a bá fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ lo ẹ̀bùn èyíkéyìí tá a ní nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ó máa lò wá láwọn ọ̀nà tá ò tiẹ̀ ronú kàn.
Nígbà tó yá, ọwọ́ ebi tẹ àwọn ará Íjíbítì, ìyàn dé! Wọ́n ké pe Fáráò pé kó ran àwọn lọ́wọ́, àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ bá Jósẹ́fù. Ohun yòówù tí ó bá wí fún yín ni kí ẹ ṣe.” Torí náà, Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí àwọn àká ọkà tí wọ́n kó oúnjẹ pa mọ́ sí, àwọn èèyàn náà sì ń wá ra ohun tí wọ́n fẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 41:55, 56.
Àmọ́ kò sí oúnjẹ láwọn ìlú tó yí wọn ká. Kódà ní ilẹ̀ Kénáánì tó jìnnà gan-an sí Íjíbítì, ìyà ti bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ìdílé Jékọ́bù. Jékọ́bù ti darúgbó lásìkò yìí, nígbà tó gbọ́ pé oúnjẹ wà ní Íjíbítì, ó rán àwọn ọmọ rẹ̀ lọ síbẹ̀ láti ra oúnjẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 42:1, 2.
Jékọ́bù rán mẹ́wàá lára àwọn ọmọ rẹ̀, àmọ́ kò rán Bẹ́ńjámínì, àbígbẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú wọn. Jékọ́bù rántí pé ní ìjelòó tí òun rán Jósẹ́fù, ọmọ òun ọ̀wọ́n nìkan pé kó lọ bẹ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wò, àlọ rẹ̀ lòún rí òun ò rí àbọ̀ rẹ̀. Ẹ̀wù rẹ̀ ẹlẹ́wà tó ti ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí ẹ̀jẹ̀ sì ti yí gbogbo rẹ̀ làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mú wálé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìfẹ́ tí bàbá rẹ̀ ní sí i àti bó ṣe jẹ́ ààyò ọmọ fún un ló jẹ́ kó fún un lẹ́wù yìí. Wọ́n parọ́ fún bàbá wọn tó ti darúgbó yìí pé ẹranko ẹhànnà ló pa Jósẹ́fù jẹ, èyí sì bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an.—Jẹ́nẹ́sísì 37:31-35.
“LẸ́SẸ̀KẸSẸ̀, JÓSẸ́FÙ RÁNTÍ”
Ìrìn-àjò kékeré kọ́ làwọn ọmọ Jékọ́bù rìn kí wọ́n tó dé Íjíbítì. Nígbà tí wọ́n béèrè ibi tí wọ́n ti máa ra oúnjẹ, ọ̀dọ̀ aláṣẹ gíga kan tó ń jẹ́ Safenati-pánéà ni wọ́n darí wọn sí. (Jẹ́nẹ́sísì 41:45) Ǹjẹ́ wọ́n mọ̀ pé òun ni Jósẹ́fù nígbà tí wọ́n rí i? Rárá o. Lójú wọn, aláṣẹ gíga kan nílẹ̀ Íjíbítì tí wọ́n fẹ́ kó ran àwọn lọ́wọ́ ló jẹ́. Kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún un, wọ́n ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe: Wọ́n “tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún un, ní dídojúbolẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 42:5, 6.
Ṣé Jósẹ́fù dá wọn mọ̀ ní tiẹ̀? Ojú ẹsẹ̀ ló dá wọn mọ̀! Síwájú sí i, nígbà tó rí wọn tí wọ́n tẹrí ba fún un, ó rántí ìgbà tó wà lọ́mọdé. Ìtàn náà fi hàn pé “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jósẹ́fù rántí àwọn àlá” tí Jèhófà jẹ́ kó lá nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé, àwọn àlá yìí sọ nípa ìgbà kan lọ́jọ́ iwájú táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ máa tẹrí ba mọ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe níwájú rẹ̀ báyìí! (Jẹ́nẹ́sísì 37:2, 5-9; 42:7, 9) Kí ni Jósẹ́fù máa ṣe? Ṣé ó máa gbá wọn mọ́ra ni? Àbí ó máa gbẹ̀san?
Jósẹ́fù mọ̀ pé bó ti wù kó rí, òun ò gbọ́dọ̀ fi bí nǹkan ṣe rí lára òun hùwà. Ó ṣe kedere pé Jèhófà ló jẹ́ káwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí wáyé bẹ́ẹ̀. Ohun tó ní lọ́kàn ló ń ṣẹlẹ̀. Ó ti ṣèlérí pé òun máa sọ irú ọmọ Jékọ́bù di orílẹ̀-èdè ńlá. (Jẹ́nẹ́sísì 35:11, 12) Táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù bá ṣì jẹ́ oníwà ipá, onímọtara-ẹni-nìkan àti oníwà àìdáa, ohun tí èyí máa yọrí sí ì bá burú jáì! Yàtọ̀ síyẹn, tí Jósẹ́fù ò bá fara balẹ̀, ó lè ṣe ohun tó máa bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nínú, kí wọ́n sì lọ fìkanra ṣe bàbá rẹ̀ àti Bẹ́ńjámínì léṣe. Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ ṣì wà láàyè? Jósẹ́fù pinnu láti máà jẹ́ káwọn ẹ̀gbọ́n òun dá òun mọ̀ kó bàa lè dán wọn wò kó sì mọ̀ bóyá wọ́n ti yíwà wọn pa dà. Nípa bẹ́ẹ̀, á lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe.
Ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù yìí má ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Síbẹ̀, gbọ́nmi-si omi-ò-to àti ìyapa sábà máà ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé lóde òní. Tí irú ìṣòro yìí bá dé bá wa, a lè fẹ́ ṣe ohunkóhun tó bá wá sọ́kàn wa, ká sì fi bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa hùwà. Ohun tó dára jù ni pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, ká sì gbìyànjú láti mọ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká bójú tó ọ̀rọ̀ náà. (Òwe 14:12) Máa rántí pé bó ti ṣe pàtàkì pé kí àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn mẹ́ńbà ìdílé wa, bẹ́ẹ̀ náà ló túbọ̀ ṣe pàtàkì pé kí àlàáfíà wà láàárín àwa, Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀.—Mátíù 10:37.
“A ÓÒ DÁN YÍN WÒ”
Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí í dán àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wò lóríṣiríṣi ọ̀nà kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Kò bá wọn sọ̀rọ̀ ní tààràtà, ẹnì kan ló ń túmọ̀ ohun tó ń sọ fún wọn. Ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ líle sí wọn, ó fẹ̀sùn kàn wọ́n pé amí ni wọ́n wá ṣe láti ilẹ̀ òkèèrè. Nígbà tí wọ́n ń ṣàlàyé ara wọn, wọ́n sọ fún un nípa ìdílé wọn, kódà wọ́n mẹ́nu bà á pé àwọn ṣì ní àbúrò kan tó wà nílé. Inú Jósẹ́fù dùn, àmọ́ ó pa á mọ́ra. Ǹjẹ́ òótọ́ ni pé àbúrò rẹ̀ ṣì wà láàyè? Jósẹ́fù ti wá mọ ohun tó máa ṣe báyìí. Ó ní: “Èyí ni a óò fi dán yín wò,” ó wá sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ mú àbíkẹ́yìn yìí wá kóun lè rí i. Nígbà tó yá, ó gbà kí wọ́n pa dà sílé lọ mú àbúrò wọn pátápátá wá, kìkì tí ẹnì kan lára wọn bá gbà kí wọ́n mú òun sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 42:9-20.
Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ́bi fún ara wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọ́n dá lógún [20] ọdún sẹ́yìn, àmọ́ wọn ò mọ̀ pé gbogbo ohun táwọn ń sọ ni Jósẹ́fù ń gbọ́. Wọ́n sọ pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, a jẹ̀bi nípa arákùnrin wa, nítorí pé a rí wàhálà ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ìyọ́nú lọ́dọ̀ wa, ṣùgbọ́n àwa kò fetí sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wàhálà yìí fi dé bá wa.” Jósẹ́fù gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, torí náà ó ní láti kúrò lọ́dọ̀ wọn kí wọ́n má bàa rí i pé ó ń sunkún. (Jẹ́nẹ́sísì 42:21-24) Síwájú sí i, ó mọ̀ pé kéèyàn ronú pìwà dà tinútinú kọjá kéèyàn wulẹ̀ máa kábàámọ̀ àbájáde iṣẹ́ ibi tó ti ṣe tẹ́lẹ̀. Torí náà, ó ń bá a lọ láti dán wọn wò.
Ó jẹ́ kí wọ́n pa dà sílé, àmọ́ ó fi Síméónì sí àhámọ́. Ó tún mú kí wọ́n dá owó wọn pa dà sínú àwọn àpò tí wọ́n fi gbé oúnjẹ lọ sílé. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pa dà sílé, wọ́n sì bẹ bàbá wọn títí tó fi gbà kí wọ́n mú Bẹ́ńjámínì, ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n lọ sí Íjíbítì. Gbàrà tí wọ́n dé Íjíbítì, wọ́n jẹ́wọ́ fún ìránṣẹ́ Jósẹ́fù tó ń bá a mójú tó nǹkan pé àwọn rí owó oúnjẹ táwọn rà nínú àpò àwọn, wọ́n sì ní kó jẹ́ káwọn san gbogbo owó náà pa dà. Ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí dára púpọ̀, àmọ́ Jósẹ́fù ṣì ní láti mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn gan-an. Nígbà tó rí Bẹ́ńjámínì, ó ní kí wọ́n wá jẹ àsè, ṣe ló fi èyí bojú kí wọ́n má bàa mọ bínú rẹ̀ ṣe dùn tó. Lẹ́yìn ìyẹn, ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọ́n pa dà sílé, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ó ní kí ìránṣẹ́ tó ń bá a bójú tó ilé fi ife fàdákà òun sínú àpò Bẹ́ńjámínì.—Jẹ́nẹ́sísì 42:26–44:2.
Jósẹ́fù wá dẹkùn mú àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó ní kí ìránṣẹ́ tó ń bá òun bójú tó ilé lé wọn bá, kó mú wọn, kó sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ti jí ife òun. Nígbà tí wọ́n rí ife náà nínú àpò Bẹ́ńjámínì, wọ́n dá gbogbo wọn pa dà sọ́dọ̀ Jósẹ́fù. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fún Jósẹ́fù láǹfààní láti mọ irú ẹni táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jẹ́. Júdà gbẹnu sọ fún gbogbo wọn, ó sì bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n ṣàánú àwọn, kódà ó ní kí wọ́n jẹ́ kí gbogbo àwọn mọ́kànlá yìí di ẹrú ní Íjíbítì. Jósẹ́fù kọ̀ jálẹ̀ pé kí gbogbo àwọn tó kù máa lọ sílé, ṣùgbọ́n Bẹ́ńjámínì gbọ́dọ̀ di ẹrú ní Íjíbítì.—Jẹ́nẹ́sísì 44:2-17.
Ọ̀rọ̀ yìí ká Júdà lára gan-an débi tó fi sọ pé: “Òun nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù fún ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí ti ní láti wọ Jósẹ́fù lọ́kàn torí pé òun ni àkọ́bí Rákélì, ìyàwó tí Jékọ́bù fẹ́ràn jù, bẹ́ẹ̀ ìgbà tí Rákélì ń bí Bẹ́ńjámínì ló kú. Bó ṣe jẹ́ pé Jékọ́bù ò lè gbàgbé Rákélì, bákan náà lọ̀rọ̀ ṣe rí lára Jósẹ́fù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé okùn ìyá kan náà tó so Jósẹ́fù pọ̀ mọ́ Bẹ́ńjámínì ló mú kó fẹ́ràn rẹ̀ gan-an.—Jẹ́nẹ́sísì 35:18-20; 44:20.
Ṣe ni Júdà túbọ̀ múra sí ẹ̀bẹ̀ tó ń bẹ Jósẹ́fù pé kó má sọ Bẹ́ńjámínì dẹrú. Ó tiẹ̀ sọ pé òun ni kó sọ dẹrú dípò Bẹ́ńjámínì. Ó wá fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn yìí parí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó ní: “Báwo ni èmi yóò ṣe lọ sọ́dọ̀ baba mi láìsí ọmọdékùnrin náà pẹ̀lú mi, kí ó má bàa wá di pé èmi yóò wo ìyọnu àjálù tí yóò dé bá baba mi?” (Jẹ́nẹ́sísì 44:18-34) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé ó ti yí pa dà. Èyí fi hàn pé kì í ṣe pé ó ronú pìwà dà nìkan ni, ó tún fi hàn pé ó lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, pé kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan àti pé ó lójú àánú.
Jósẹ́fù ò lè pa á mọ́ra mọ́. Gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀ ti dé góńgó. Ó ní káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde síta, ó wá bú sẹ́kún. Ẹkún yìí pọ̀ débi pé wọ́n gbọ́ láàfin Fáráò. Níkẹyìn, ó jẹ́wọ́ fún wọn pé: “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín.” Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, síbẹ̀ ó gbá wọn mọ́ra, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ti dárí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe sóun jì wọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 45:1-15) Ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, ẹni tó máa ń dárí jini fàlàlà. (Sáàmù 86:5) Ṣé àwa náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?
‘O ṢÌ WÀ LÁÀYÈ’!
Nígbà tí Fáráò gbọ́ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé Jósẹ́fù, ó sọ fún un pé kó ránṣẹ́ sí bàbá rẹ̀ tó ti dàgbà pé kóun àti gbogbo ìdílé wọn máa bọ̀ ní Íjíbítì. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí bàbá Jósẹ́fù dé, òun àti ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n sì tún jọ wà pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Jékọ́bù sunkún, ó sì sọ pé: “Ní báyìí, mo múra tán láti kú, nísinsìnyí tí mo ti rí ojú rẹ, níwọ̀n bí o ti wà láàyè síbẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 45:16-28; 46:29, 30.
Ọdún mẹ́tàdínlógún [17] ni Jékọ́bù lò sí i ní Íjíbítì kó tó kú. Ó pẹ́ láyé débi pé ó súre fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjìlá. Àmọ́ ìbùkún ìlọ́po méjì tí wọ́n sábà máa ń fún àkọ́bí ló fún Jósẹ́fù, ọmọ rẹ̀ kọkànlá. Ẹ̀yà méjì ló máa wá látọ̀dọ̀ rẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Júdà, tó jẹ́ ọmọ kẹrin, tí ọ̀rọ̀ ká lára ju àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, tó sì fi hàn pé òun ti ronú pìwà dà? Ìbùkún ńlá ló rí gbà torí pé ìlà ìdílé rẹ̀ ni Mèsáyà ti máa wá!—Jẹ́nẹ́sísì, orí 48 àti 49.
Nígbà tí Jékọ́bù kú lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́jọ [147], ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù pé àbúrò àwọn tágbára ti tẹ̀ lọ́wọ́ yìí lè fẹ́ gbẹ̀san. Àmọ́ Jósẹ́fù fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé òun kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ti pẹ́ tó ti wà lọ́kàn rẹ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé Jèhófà ló mú kí gbogbo ìdílé náà ṣí wá sílẹ̀ Íjíbítì, torí náà ó yẹ káwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yé dá ara wọn lẹ́bi ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Ó wá bi wọ́n ní ìbéèrè pàtàkì yìí pé: “Èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí?” (Jẹ́nẹ́sísì 15:13; 45:7, 8; 50:15-21) Jósẹ́fù gbà pé Jèhófà ni Onídàájọ́ pípé. Báwo ni tòun ṣe jẹ́ tóun á máa wá fìyà jẹ àwọn tí Jèhófà ti dárí jì?—Hébérù 10:30.
Ǹjẹ́ ó ti nira fún ẹ rí láti dárí ji ẹnì kan? Ó lè ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé ṣe lẹni náà dìídì ṣèkà sí wa. Ṣùgbọ́n tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára pé tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, a máa dárí jì í látọkàn wá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgbẹ́ lèyí máa jẹ́ kó san, àní títí kan tiwa fúnra wa. Èyí á sì fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù àti àpẹẹrẹ Baba rẹ̀ aláàánú, Jèhófà.
a Ka àwọn àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 2014; November 1, 2014; àti February 1, 2015.