Idi Ti Ìpín Aláròyé kìí Fií Ṣe Ọ̀kan Ti Ó Jẹ́ Alayọ
AYỌ ti yipada di ainireti ní kìkì iwọnba ọsẹ diẹ. Idunnu ṣubu lu ayọ akọkọ ti awọn ọmọ Israeli ní nitori ominira wọn ti wọn ṣẹṣẹ rí gbà kuro ninu igbekun awọn ará Egipti ti yingin di ikunsinu aláìníláárí nitori ounjẹ. Ni oṣu keji lẹhin ti wọn ti fi Egipti silẹ, orilẹ-ede ti a jakulẹ naa sọ pe awọn yoo yan ìpín ẹrú kan ju igbesi-aye lilekoko ninu aginju lọ. Ni awọn oṣu ti o tẹle e, ẹmi àròyé yii sọ ipinnu wọn lati ṣegbọran si Jehofa di alailagbara ti ó sì pa ifojusọna wiwọnu Ilẹ Ileri iran naa run.—Eksodu 16:1-3; Numeri 14:26-30.
Dajudaju, àròyé ni kò mọ sọdọ kìkì iran kan tabi iru awọn eniyan kanṣoṣo. Ta ni kìí ṣàròyé lẹẹkọọkan nipa iṣẹ́, ounjẹ, oju-ọjọ, awọn ọmọ, awọn aladuugbo tabi owó igbọbukata igbesi-aye? Ó dabi ẹni pe aipe eniyan ń mú ki ẹnikan ni ìtẹ̀sí lati ṣàròyé.—Romu 5:12; Jakọbu 3:2.
Eeṣe ti a fi ń yára ṣàròyé bẹẹ? Boya a ń nimọlara irẹwẹsi, ijakulẹ, tabi aisan. Ṣíṣàròyé lè jẹ́ ọ̀nà abajade kan fun ijakulẹ wa, tabi ó lè jẹ́ ọ̀nà ti kò ṣe taarata kan fun sisọ pe: “Emi yoo ṣe iṣẹ yẹn lọna ti o dara ju!” Nigba miiran àkópọ̀-ànímọ́ awọn eniyan ti o yatọsira ni o maa ń bu epo si iná àròyé. Lẹhin naa pẹlu, awọn ọ̀ràn ẹ̀dùn ti wọn jẹ́ ojulowo wà.
Ohun yoowu ki sábàbí naa jẹ́, gẹgẹ bi apẹẹrẹ awọn ọmọ Israeli ti a mẹnukan ni iṣaaju ti fihàn, ṣíṣàròyé lè ṣeparun bi ó bá ń ba a lọ laidawọduro. Ẹnikan lè di aláròyé paraku, ní kíkùn nipa ọ̀nà ìgbàṣe awọn nǹkan Jehofa paapaa. Eeṣe ti iyẹn fi lewu tobẹẹ? Bawo sì ni a ṣe gbọdọ bojuto awọn aroye titọna lọna yiyẹ?
Awọn Àròyé Titọna
Bi ọ̀ràn ẹ̀dùn kan kìí bá ṣe ọ̀kan ti o lekenka, ibeere akọkọ ti a gbọdọ beere ni pe, Mo ha lè fi ifẹ gbójúfò ó dá bi? Loootọ, a lè ní idi ti ó fẹsẹmulẹ fun ṣíṣàròyé lodisi ẹnikan, boya onigbagbọ ẹlẹgbẹ-ẹni kan paapaa. Oun lè ti bá wa lò lọna ailaanu tabi lọna aitọ. Bi o tilẹ ri bẹẹ, ǹjẹ́ ṣíṣàròyé fun awọn ẹlomiran nipa ibalo alaitọ naa yoo ha mu awọn ọ̀ràn sunwọn sii bi? Bawo ni Bibeli ṣe damọran pe ki a huwapada? Kolosse 3:13 sọ pe: “Ẹ maa farada a fun araayin, ẹ sì maa dariji araayin bi ẹnikẹni bá ní ẹsun si ẹnikan: bi [Jehofa, NW] ti dariji yin, gẹgẹ bẹẹ ni ki ẹyin ki o maa ṣe pẹlu.” Nitori naa nigba ti o jẹ pe ìṣàròyé lè jẹ́ eyi ti o tọna paapaa, Iwe Mimọ damọran iṣarasihuwa onidaariji dipo ẹmi àròyé ṣiṣe.—Matteu 18:21, 22.
Ki ni bi ọ̀ràn naa bá lékenkà ju lati gbojufoda? Idi rere lè wà fun ṣíṣàròyé. Nigba ti ‘igbe àròyé’ ti ó fẹsẹmulẹ goke tọ Jehofa lọ nipa ilẹ̀ Sodomu ati Gomorra, ó gbé igbesẹ lati wá nǹkan ṣe si ipo alaibọla funni ninu awọn ilu-nla onibajẹ wọnni. (Genesisi 18:20, 21) Àròyé titọna miiran dide laipẹ lẹhin Ajọ-irekọja 33 C.E. Nigba ti a pín ounjẹ fun awọn opó alaini, ojuṣaaju ni a fihàn si awọn obinrin ti ń sọ èdè Heberu. Lọna ti ó lè yeni, eyi fa kurungbun laaarin awọn opó ti ń sọ èdè Griki. Lẹhin-ọ-rẹhin, àròyé naa dé etigbọ awọn aposteli, wọn sì tete ṣeto ẹgbẹ́ awọn ọkunrin titootun kan lati ṣatunṣe iṣoro naa.—Iṣe 6:1-6.
Awọn Kristian alagba ti a yàn sipo lonii bakan naa kò gbọdọ fọ̀rọ̀ falẹ̀ ninu gbigbe awọn igbesẹ ti o yẹ nigba ti a bá mú awọn ọ̀ràn lílékenkà wá si afiyesi wọn. Owe 21:13 sọ pe: “Ẹnikẹni ti o bá di etí rẹ̀ si igbe olupọnju, oun tikaraarẹ yoo ké pẹlu: ṣugbọn a kì yoo gbọ́.” Dipo ṣíṣàì ka àròyé titọna kan sí, awọn alagba gbọdọ fi igbatẹniro tẹtisilẹ. Ni ọwọ keji ẹwẹ, gbogbo wa lè fọwọsowọpọ nipa didari awọn àròyé lílékenkà si awọn alagba, dipo sisọ wọn ni asọtunsọ fun tonílétàlejò.
Bi o tilẹ ri bẹẹ, ọpọ julọ ninu wa yoo gbà ni gbangba pe awọn akoko kan wà nigba ti aipe eniyan maa ń mú ki a ṣàròyé lainidii. Titubọ gbé ihuwasi awọn ọmọ Israeli ninu aginju yẹwo yoo ràn wá lọwọ lati rí ewu jijẹki ẹjọ́-wẹ́wẹ́ ẹẹkọọkan lọ soke dori didi ẹmi àròyé ṣiṣe.
Oju-Iwoye Ọlọrun Nipa Awọn Aláròyé
Ìráhùn awọn ọmọ Israeli nipa ipese ounjẹ fi ewu meji ti ń bá ṣíṣàròyé rìn hàn. Lakọọkọ, ṣíṣàròyé a maa gbèèràn. Akọsilẹ naa sọ pe “gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli sì ń kùn si Mose ati si Aaroni ni ijù naa.” (Eksodu 16:2) O ṣeeṣe ki o jẹ́ pe iwọnba diẹ ni awọn ti o bẹrẹ sii ṣàròyé nipa aito ounjẹ, ti gbogbo wọn sì gba àròyé naa kan lẹhin naa.
Lẹẹkeji, aláròyé naa sábà maa ń sàsọdùn iṣoro naa. Ninu ọ̀ràn yii, awọn ọmọ Israeli tẹnumọ ọn pe ìbá ti sàn fun awọn jù ni Egipti, nibi ti wọn ti lè jẹ burẹdi ati ẹran ti ó pọ̀ tó bi wọn ṣe fẹ́. Wọn ṣàròyé pe a ti dari awọn sinu aginju kìkì lati kú lati ọwọ́ ebi.—Eksodu 16:3.
Ǹjẹ́ ipo awọn ọmọ Israeli wọnni ha lékenkà tobẹẹ niti gidi bi? Ó ṣeeṣe ki ìkójọ ounjẹ wọn ti maa dinku, ṣugbọn Jehofa ti rí iṣoro yẹn ṣiwaju, ati ni akoko ti o wọ̀ ó pese manna lati tẹ́ aini wọn nipa ti ara lọrun. Awọn àròyé alásọdùn wọn fi aini igbẹkẹle patapata ninu Ọlọrun hàn. Lọna ti o bá ẹ̀tọ́ mu wọn ti ṣàròyé nipa awọn ipo lilekoko nigba ti wọn wà ni Egipti. (Eksodu 2:23) Ṣugbọn nigba ti Jehofa sọ wọn dominira kuro ninu oko ẹrú, wọn bẹrẹ sii ṣàròyé nipa ounjẹ. Iyẹn jẹ́ kíkùn ti kò sí idi fun. “Kíkùn yin kìí ṣe sí wa bikoṣe si OLUWA,” ni Mose kilọ.—Eksodu 16:8.
Ẹmi àròyé ti awọn ọmọ Israeli yii wáyé leralera. Laaarin ọdun kan manna naa funraarẹ di okunfa àròyé. (Numeri 11:4-6) Laipẹ lẹhin naa irohin buburu lati ọ̀dọ̀ 10 ninu awọn amí ọmọ Israeli 12 ṣipaya ìbòsí nipa awọn ewu ti wọn rò pe iṣẹgun Ilẹ Ileri naa yoo ní ninu. Awọn eniyan naa lọ jinna debi sisọ pe: “Awa ìbá kúkú ti kú ni ilẹ Egipti! Tabi awa ìbá kú ni aginju yii!” (Numeri 14:2) Ainimọriri lílékenkà gbáà ni eyi jẹ́! Kò yanilẹnu pe, Jehofa sọ fun Mose pe: “Awọn eniyan yii yoo ti kẹ́gàn mi pẹ́ tó? yoo sì ti pẹ́ tó ti wọn ó ṣe aláìgbà mí gbọ́?” (Numeri 14:11) Awọn aláròyé alainimọriri wọnni ni a dalẹbi lati rìn kiri ninu aginju fun 40 ọdun titi di ìgbà ti iran yẹn fi kọja lọ.
Aposteli Paulu rán wa leti apẹẹrẹ yii. Ó kilọ fun awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ lati maṣe dabi awọn ọmọ Israeli wọnni ti wọn di olùráhùn, kìkì lati parun sinu aginju. (1 Korinti 10:10, 11) Lọna ti ó ṣe kedere, kíkùn ti kò nidii ati ẹmi àròyé lè jin igbagbọ wa lẹsẹ ki o sì ṣamọna si àìrínúdídùn Jehofa.
Sibẹ, Jehofa mú suuru pẹlu awọn iranṣẹ rẹ̀ ti wọn lè maa ṣàròyé lóòrèkóòrè nitori awọn ayika ipo ti ń kó irẹwẹsi bani. Nigba ti Elija sa lọ si Oke Horebu nitori inunibini lati ọ̀dọ̀ Ayaba Jesebeli buburu, oun ni a fi lọ́kàn balẹ̀ pe iṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi wolii kan ni ó ti dé opin. Ó fi iṣina rò pe oun ni olujọsin Jehofa kanṣoṣo ti o ṣẹku ni ilẹ naa. Lati fun igbagbọ Elija lokun, Ọlọrun kọkọ fi agbara atọrunwa Rẹ̀ hàn án. Wolii naa ni a sọ fun lẹhin naa pe 7,000 awọn iranṣẹ oluṣotitọ ti Jehofa ṣì wà ni Israeli ati pe iṣẹ pupọ ṣì wà fun un lati ṣe. Gẹgẹ bi abajade, Elija gbagbe àròyé rẹ̀ ó sì tẹsiwaju pẹlu okun ti a sọ dọtun. (1 Ọba 19:4, 10-12, 15-18) Bi awọn Kristian alagba ti ń lo iwoyemọ, awọn bakan naa lè fi itunu sọrọ fun awọn aduroṣinṣin, ní ríràn wọn lọwọ lati rí ipa tiwọn ninu iṣiṣẹyọri ète Ọlọrun.—1 Tessalonika 5:14.
Bibori Ẹmi Àròyé
Bawo ni a ṣe lè bori ẹmi àròyé? Ó dara, awọn wọnni ti a ń fun ni ẹ̀rí nipa ipalara tí tábà ń ṣe fun ara ní ìwúrí ti o lagbara lati dáwọ́ siga mimu duro. Bakan naa, liloye idi ti ẹmi àròyé fi jẹ́ eyi ti ń panilara tobẹẹ lè sún wa lati dawọ aṣa àròyé ṣiṣe eyikeyii duro.
Awọn anfaani wo ni ń jẹ jade fun awọn wọnni ti wọn bá bori ẹmi àròyé? Anfaani pataki kan ti awọn wọnni ti wọn bá bori ṣíṣàròyé ń gbadun ni pe wọn lè wo awọn ọ̀ràn lọna ti ó ba Iwe Mimọ mu ati lọna ti o tubọ jẹ ti aláìfẹ̀tanú gbè sapakan. Agbara káká ni aláròyé kan fi maa ń duro lati ronu nipa iṣoro kan lati oju-iwoye Jehofa. Awọn ọmọ Israeli aláròyé gbagbe pe Jehofa Ọlọrun ti dá wọn silẹ lominira kuro ninu igbekun ti o sì ti fi iṣẹ iyanu pín awọn omi Òkun Pupa níyà fun wọn. Èrò òdì wọn fọ́ wọn loju si agbara Ọlọrun ó sì já ayọ wọn gbà mọ́ wọn lọwọ. Gẹgẹ bi abajade, igbẹkẹle wọn ninu Jehofa di eyi ti kò si mọ.
Siwaju sii, ẹnikan ti ó lè ṣe igbeyẹwo aláìfẹ̀tanú gbè sapakan nipa awọn iṣoro rẹ̀ ń fi iwoye mọ ìgbà ti aṣiṣe oun funraarẹ ti jẹ́ gbongbo okunfa awọn ipo lilekoko rẹ̀. Oun ni o lè má ṣeeṣe fun lati tun ṣe iru aṣiṣe kan-naa lẹẹkan sii. Jeremiah kilọ fun awọn ọmọ Israeli ẹlẹgbẹ rẹ̀ lati maṣe ṣàròyé nipa inira ti wọn ń niriiri rẹ̀ lẹhin iparun Jerusalemu. Ijiya wọn jẹ abajade ẹṣẹ ti awọn funraawọn ni taarata, iyẹn sì jẹ́ ohun kan ti wọn nilo lati loye ki wọn baa lè ronupiwada ki wọn sì yipada si Jehofa. (Ẹkún Jeremiah 3:39, 40) Lọna kan-naa, Juda ọmọ-ẹhin naa fi aitẹwọgba hàn si “awọn alaiwa-bi-Ọlọrun” ti wọn kọ idari Jehofa silẹ ti wọn sì jẹ́ “aláròyé” paraku.—Juda 3, 4, 16.
Gẹgẹ bi ọlọgbọn Ọba Solomoni ṣe ṣakiyesi nigba kan ri, “inu didun mú imularada rere wá: ṣugbọn ibinujẹ ọkàn mu egungun gbẹ.” (Owe 17:22) Ẹmi àròyé ṣíṣe ń tán wa lokun niti ero-imọlara ó sì ń gba ayọ lọwọ wa. Ó fi aifojusọna fun rere hàn, kìí ṣe ifojusọna fun rere. Ṣugbọn awọn wọnni ti wọn kẹkọọ lati ronu ki wọn sì sọrọ nipa ‘awọn ohun iyin’ ní ọkàn alayọ, eyi ti o tilẹ lè mu ki wọn nimọlara ti o sàn ju paapaa.—Filippi 4:8.
Laiṣe iyemeji, igbesi-aye wa yoo jẹ́ eyi ti o tubọ lọ́ràá sii bi a bá ṣakiyesi iwatitọ awọn eniyan dipo awọn ikuna wọn. Awa ni a o gbé ga bi a bá tẹwọgba awọn ipo lilekoko ti a sì ń baa lọ lati jẹ́ ẹni ti o tújúká dipo ki a maa kùn nipa awọn iṣoro wa. Àní awọn adanwo paapaa lè jẹ́ idi fun ayọ bi a bá wò wọn gẹgẹ bi anfaani kan lati fun igbagbọ wa lokun ki a sì mu ki ifarada wa lagbara sii.—Jakọbu 1:2, 3.
Ó tun ṣe pataki lati ranti pe nigba ti a bá ń kùn awa kò pa araawa nikan lara. Nipa fifi gbogbo ìgbà ṣàròyé, a lè jin igbagbọ awọn ẹlomiran lẹsẹ pẹlu. Irohin buburu awọn amí ọmọ Israeli mẹwaa naa mú ki gbogbo orilẹ-ede naa foju wo iṣẹgun Ilẹ Ileri gẹgẹ bi idagbale alailekẹsẹjari kan. (Numeri 13:25–14:4) Ni akoko iṣẹlẹ miiran, Mose ni ọkàn rẹ̀ bajẹ tobẹẹ gẹẹ nitori ìráhùn alaidabọ awọn eniyan naa ti o fi beere lọwọ Jehofa lati gba iwalaaye rẹ̀. (Numeri 11:4, 13-15) Ni ọwọ keji ẹwẹ, bi a bá sọrọ nipa awọn ọ̀ràn ni ọ̀nà ti ń gbeniro, ó lè ṣeeṣe fun wa lati fun igbagbọ awọn ẹlomiran lokun ki a sì pa kun ayọ wọn.—Iṣe 14:21, 22.
Bi o tilẹ jẹ pe a lè dán wa wò lati ṣàròyé nipa awọn oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ wa, awọn ọ̀rẹ́ wa, idile wa, tabi awọn alagba ijọ paapaa, Jehofa fẹ́ ki awọn eniyan oun ‘ni ifẹ ti o gbona laaarin araawọn.’ Iru ifẹ bẹẹ ń sun wa lati bo aṣiṣe awọn ẹlomiran mọlẹ dipo titẹnumọ awọn aṣiṣe wọn. (1 Peteru 4:8) Ọpẹ́ ni pe Jehofa ń ranti pe a jẹ́ erupẹ lásánlàsàn ti kìí sìí ṣọ́ awọn aṣiṣe wa. (Orin Dafidi 103:13, 14; 130:3) Bi gbogbo wa bá ń gbiyanju lati ṣafarawe apẹẹrẹ rẹ̀, laiṣiyemeji iwọnba ni a o ṣe àròyé mọ.
Nigba ti a bá mu iran-eniyan padabọ si ijẹpipe, kò sí ẹni ti yoo ni idi lati ṣàròyé nipa ìpín rẹ̀ ninu igbesi-aye mọ́. Titi di akoko ti iyẹn yoo dé, a nilati yẹra fun idẹwo naa lati ṣàròyé nipa awọn ẹlomiran tabi nipa awọn ipo tiwa funraawa ti ń danniwo. Lati fihàn pe a nigbẹkẹle ninu Jehofa ti a sì nifẹẹ awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa, ẹ jẹ ki a “maa ṣe ohun gbogbo ni aisi ìkùnsínú.” (Filippi 2:14) Eyi yoo tẹ́ Jehofa lọ́rùn yoo sì ṣanfaani fun wa lọpọlọpọ. Fun ire-alaafia tiwa funraawa ati ti awọn ẹlomiran, nigba naa, ẹ maṣe jẹ ki a gbagbe pe ìpín aláròyé kìí ṣe eyi ti o jẹ́ alayọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àní ipese manna Ọlọrun lọna iṣẹ-iyanu paapaa di okunfa fun àròyé