Awọn Kristian Ha Nilati Pa Ọjọ́ Isinmi Mọ́ Bi?
JUNE ti jẹ akoko ojo lọna kikọyọyọ. Nitori eyi, aṣa-atọwọdọwọ ọlọjọ pipẹ ti ayé kan ni a ṣẹ̀sí nigba idije àṣemọ̀gá ti eré tẹniisi Wimbledon ni 1991. Fun ìgbà akọkọ ninu ìtàn awọn idije ni a ṣe ni ọjọ́ Sunday kan lati fi dí akoko ti a ti padanu. Yatọ si ṣiṣaika awọn ilana sí lẹẹkọọkan bii ti eleyii, ọjọ́ Sunday ń baa lọ lati jẹ́ ọjọ́ isinmi mimọ ọlọ́wọ̀ kan ni England, ati bakan naa ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede miiran.
Awọn eniyan kan pa ọjọ́ isinmi yiyatọ kan mọ́. Awọn Ju kaakiri agbaye ń pa Ọjọ́-ìsinmi (Sábáàtì) mọ́ lati ìgbà yíyọ oorun ni ọjọ́ Friday titi di ìgbà wíwọ̀ oorun ni ọjọ́ Saturday. Lakooko Ọjọ́-ìsinmi, ọkọ̀ irin-ajo ofuurufu ti orilẹ-ede Israeli kìí gbéra, ati ni awọn ilu kan bayii awọn ọkọ̀ ni gbogbogboo kìí ṣiṣẹ. Ni Jerusalemu awọn ti wọn gbagbọ ninu aṣa-atọwọdọwọ ń dí awọn opopona kan bayii lati lè dí awọn ọkọ̀ ti wọn kà sí atàpá si ofin lọwọ rírìn.
Otitọ naa pe ọpọlọpọ isin ṣì ń pa ọjọ́ isinmi ọsọọsẹ tabi sábáàtì kan mọ́ gbé oniruuru ibeere dide. Ǹjẹ́ pipa Ọjọ́-ìsinmi mọ́ ha wà fun awọn Ju nikanṣoṣo bi? Eeṣe ti ọpọ julọ awọn isin Kristẹndọm fi tẹwọgba ọjọ́ isinmi yiyatọ kan? Ǹjẹ́ pipa ọjọ́ isinmi ọsọọsẹ kan mọ ha ń baa lọ lati jẹ́ ohun abeerefun ti o bá Bibeli mu lonii bi?
Ọjọ́-ìsinmi Ha Ti Figba Gbogbo Wà Bi?
A rí ibi akọkọ ti Iwe Mimọ ti mẹnukan ọjọ́-isinmi ninu iwe Eksodu. Nigba ti awọn ọmọ Israeli wà ninu aṣálẹ̀, wọn gba Manna, ounjẹ iyanu kan, lati ọwọ́ Jehofa. Ni ọjọ́ kẹfàkẹfà ọsẹ kọọkan, wọn nilati kó ilọpo meji nitori pe ọjọ́ keje ni ó nilati jẹ́ “ọjọ́-ìsinmi fun Oluwa,” ninu eyi ti a ti ka gbogbo iṣẹ léèwọ̀.—Eksodu 16:4, 5, 22-25.
Siwaju sii, awọn ọmọ Israeli ni a fun ni Ọjọ́-ìsinmi naa lati rán wọn létí pe wọn ti jẹ́ ẹrú ni ilẹ Egipti. Irannileti yii ni kì bá ti jẹ́ alaifi bẹẹ jamọ pataki bi wọn bá ti tẹle iru ofin kan bẹẹ tẹlẹ. Nitori naa, awọn àṣẹ ti ń ṣakoso Ọjọ́-ìsinmi ni a fifun Israeli nikan.—Deuteronomi 5:2, 3, 12-15.
Awọn Aṣa Àfìṣọ́raṣe ti Ó Sì Nira
Nitori pe Ofin Mose kò sọ kulẹkulẹ nipa Ọjọ́-ìsinmi, awọn rabbi la ọpọ ọrundun já gbé awọn oniruuru èrò kalẹ, ti ń ka gbogbo iru iṣẹ eyikeyii ni Ọjọ́-ìsinmi léèwọ̀ ni pataki. Ni ibamu pẹlu Mishnah, iṣẹ ti a kàléwọ̀ naa ni a pín si isọri 39 pataki. Iru bii ríránṣọ, kikọwee, ati iṣẹ oko. Ọpọ ninu awọn àṣẹ wọnyi ni a kò gbekari Bibeli. Ni titọka si Mishnah, iwe gbedegbẹyọ Encyclopædia Judaica gbà pe wọn dabi “dùgbẹ̀dùgbẹ̀ ti a fi fọ́nrán irun kan so rọ̀, nitori pe iwọn diẹ ni ó wà ninu Iwe Mimọ lori kókó-ọ̀rọ̀ naa sibẹ awọn ofin naa pọ̀.”
Lati fi ofin naa silo pe ọkunrin kan kò gbọdọ “kuro ni ipo rẹ̀ ni ọjọ́ keje,” pátápinrá gígùn ọ̀nà kan ni a pinnu, eyi ni a sì pe ni “ààlà Ọjọ́-ìsinmi.” Gẹgẹ bi awọn orisun kan ti wi, ó jẹ́ deedee ẹgbẹrun meji ìgbọ̀nwọ́, tabi nǹkan bii 900 mita. (Eksodu 16:29) Bi o ti wu ki o ri, àṣẹ yii ni a lè fi ẹ̀sọ̀ rekọja: Ni alẹ́ ti ó ṣaaju, ounjẹ Ọjọ́-ìsinmi ni a lè gbé si ọ̀nà ti o jìn tó ẹgbẹrun meji igbọnwọ si ile. Ọgangan yii ni a lè kà si imugbooro ile idile naa nigba naa, ti a sì lè ka ẹgbẹrun meji igbọnwọ miiran lati ọgangan yẹn.
Ọpọlọpọ ninu awọn ikalọwọko atọwọda eniyan wọnyi ni a ń mulo ni ọjọ́ Jesu. Nipa bayii, awọn aṣaaju isin kẹ́gàn awọn ọmọlẹhin rẹ̀ fun yíya ti wọn ya ìpẹ́ ọkà lati jẹ bi wọn ti ń kọja la inu oko ọkà naa kọja. Awọn ni a fẹsun ṣiṣẹ si Ọjọ́-ìsinmi kàn—yíya ọkà ni a kà si kikore, rírà á ni a sì wò gẹgẹ bi pípa tabi lílọ̀. Jesu bu ẹnu àtẹ́ lu oju-iwoye wọn alaṣeregee yii ni ọpọlọpọ ìgbà, nitori pe wọn kò ṣoju fun ẹmi ofin Jehofa lọna títọ́.—Matteu 12:1-8; Luku 13:10-17; 14:1-6; Johannu 5:1-16; 9:1-16.
Lati Ọjọ-Isinmi Saturday kan si ti Sunday
“Awọn ọjọ́ Sunday ni a o pamọ fun ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun tọkantọkan.” Iru iyẹn ni Ofin Kẹrin lori Ọjọ́-ìsinmi gẹgẹ bi Ṣọọṣi Katoliki ṣe gbé e kalẹ. Iwe Catéchisme pour adultes ti a tẹjade lẹnu aipẹ yii ni èdè Faranse ṣalaye pe: “Ọjọ́ Sunday ti Kristian ni a ń ṣayẹyẹ rẹ̀ ni ọjọ́ kan lẹhin Ọjọ́-ìsinmi: ni ọjọ́ kẹjọ, iyẹn ni pe, ni ọjọ́ akọkọ iṣẹda titun naa. O tẹwọgba awọn apá ṣiṣekoko Ọjọ́-ìsinmi ṣugbọn a gbekari Ajọ-irekọja ti Kristi.” Bawo ni ìṣẹ́rípadà bìrí yii lati ori ọjọ́-ìsinmi Saturday kan, si ti Sunday ṣe wáyé?
Àní bi o tilẹ jẹ pe ọjọ́ Sunday ni ọjọ́ naa ti a jí Jesu dide, fun awọn Kristian ijimiji ó jẹ́ ọjọ́ iṣẹ kan gẹgẹ bi awọn ọjọ́ miiran. Ṣugbọn ipinnu kan lati ọwọ́ igbimọ ṣọọṣi Laodekia kan (ni aarin sí ọrundun kẹrin C.E. ipari rẹ̀) ṣipaya pe bi akoko ti ń lọ, Ọjọ́-ìsinmi awọn Ju ni Saturday ni a fi ọjọ́-ìsinmi “Kristian” ni Sunday rọ́pò. Ilana ti gbogbo eniyan gba yii “ka awọn Kristian léèwọ̀ lati maṣe tẹwọgba igbagbọ ati aṣa awọn Ju ati pe lati jẹ́ alaiṣiṣẹ ni Ọjọ́-ìsinmi [awọn Ju], ati ni ọjọ́ Oluwa [ọjọ́ naa ninu ọsẹ ti a jí i dide] ni a gbọdọ bọla fun ni ọ̀nà kan ti o jẹ ti Kristian.” Lati ìgbà naa lọ awọn alatilẹhin igbagbọ Kristẹndọm nilati ṣiṣẹ ni awọn ọjọ́ Saturday ki wọn sì yẹra kuro ninu iṣẹ ṣiṣe ni awọn ọjọ́ Sunday. Lẹhin naa, a beere lọwọ wọn lati lọ si Mass ni ọjọ́ Sunday.
Pẹlu itilẹhin awọn alaṣẹ ayé, iṣẹ ni awọn ọjọ́ Sunday ni a kàléèwọ̀ laipẹ ninu gbogbo Kristẹndọm. Lati ọrundun kẹfa lọ siwaju, awọn olurelanakọja ni a ń bu owó ìtaràn fun tabi nà lọ́rẹ́, ti a sì lè gba maluu wọn mọ́ wọn lọwọ. Ni ìgbà miiran, awọn ẹlẹṣẹ alaironupiwada ni a lè rẹ̀nípòwálẹ̀ dori didi iranṣẹ.
Ni ọ̀nà itumọ kan, awọn ofin ti wọn tanmọ iṣẹ ti o ṣetẹwọgba ni awọn ọjọ́ Sunday lọjupọ mọra gẹgẹ bii ti awọn aṣa-atọwọdọwọ ti ń ṣakoso Ọjọ́-ìsinmi awọn Ju. Iwe atumọ-ọrọ naa Dictionnaire de théologie catholique funni ni awọn àlàyé gígùn jàn-ànnà-jan-anna nipa mimu ọ̀nà kan dagba ninu ṣọọṣi fun yiyanju awọn ibeere nìpa ohun ti o tọ́ ati eyi ti kò tọ́ nipasẹ ifisilo awọn ilana ti o si mẹnukan an pe, lara awọn ohun ti a kàléèwọ̀ ni iṣẹ bọ̀íbọ̀í, iṣẹ oko, awọn igbẹjọ ofin, ọjà, ati dídẹgbó wà.
Lọna ti o takora, Ọjọ́-ìsinmi awọn Ju ni a tọka si gẹgẹ bi idalare fun awọn ìkàléèwọ̀ wọnyi. New Catholic Encyclopedia mẹnukan awọn ofin Olu-ọba Charlemagne nipa ọjọ́ Sunday pe: “Èrò igbagbọ Ọjọ́-ìsinmi, tí Jerome Mímọ́ kọ̀ silẹ ni kedere tí Igbimọ ti Orléans ni 538 sì dẹbi fun gẹgẹ bi eyi ti o jẹ ti awọn Ju ti kìí sii ṣe ti Kristian, ni a sọ ni kedere ninu ofin Charlemagne ti 789, eyi ti ó ka gbogbo iṣẹ́-òpò ni ọjọ́ Sunday léèwọ̀ gẹgẹ bi ìtàpá si [awọn Ofin Mẹwaa].” Nipa bayii, bi o tilẹ jẹ pe ó tẹ́ ṣọọṣi naa lọ́rùn lati rí i ki awọn alaṣẹ ti ilu gbé ọjọ́ isinmi Sunday kan kalẹ, ó fààyè gba awọn alaṣẹ ti ayé yii lati dá awọn ìkàléèwọ̀ wọnyi láre lori ipilẹ ti ofin ti ó kọ̀, iyẹn ni, ofin Mose nipa Ọjọ́ìsinmi.
Iduro ti Kìí Ṣe Ti Iwe Mimọ
Ni ọpọ ọrundun ṣaaju, awọn Baba Ṣọọṣi melookan, ati Augustine ni pataki, fi ẹ̀tọ́ polongo pe Ọjọ́-ìsinmi jẹ́ iṣeto onigba kukuru kan ti a yasọtọ fun awọn Ju. Ni ṣiṣe bẹẹ, awọn Baba Ṣọọṣi wọnni wulẹ gba ohun ti Iwe Mimọ Kristian Lede Griki ṣalaye ni, iyẹn ni pe Ọjọ́-ìsinmi jẹ́ apakan ninu majẹmu Ofin ti a wọ́gilé nipasẹ ẹbọ Jesu.—Romu 6:14; 7:6; 10:4; Galatia 3:10-14, 24, 25.
Ninu Vocabulaire biblique ti ode-oni, ẹlẹkọọ-isin Protẹstanti Oscar Cullmann ni a ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe ó gbà pe “nitori pe Jesu wá, kú, ti ó sì jí dide, awọn ajọdun inu M[ajẹmu] L[aelae] ni a ti muṣẹ nisinsinyi, lati pa wọn mọ́ sì ‘tumọsi pipada si majẹmu laelae, bi ẹni pe Kristi kò tíì wá.’” Bi a ti gbé kókó ti ó fẹsẹmulẹ yii yẹwo, ó ha ṣeeṣe lati dá pipa Ọjọ́-ìsinmi kàn-ńpá láre bi?
Lonii, awọn onkọwe Katoliki ni gbogbogboo wá itilẹhin ninu Iṣe 20:7, eyi ti ó sọ nipa “ọjọ́ ìkínní ọsẹ” (Sunday), nigba ti Paulu pade pọ̀ pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ lati ṣajọpin ounjẹ kan pẹlu wọn. Bi o ti wu ki o ri, eyi wulẹ jẹ́ kókó kan nipa kulẹkulẹ ọ̀rọ̀ ni. Kò sí ohunkohun ninu ọrọ-ẹsẹ iwe mimọ yii tabi ninu awọn ẹsẹ Bibeli miiran ti ó fihàn pe akọsilẹ yii ni a ní lọ́kàn lati jẹ́ apẹẹrẹ ti awọn Kristian nilati tẹle, dajudaju kìí ṣe iṣẹ-aigbọdọmaṣe. Bẹẹni, pipa Sunday ti ọjọ́-ìsinmi kan mọ́ kò ní itilẹhin ti ó bá Iwe Mimọ mu.
Isinmi Wo Ni Ó Wà fun Awọn Kristian?
Bi o tilẹ jẹ pe awọn Kristian ni a kò sọ́ di aigbọdọmaṣe fun lati pa ọjọ́ isinmi ọsọọsẹ kan mọ́, bi o ti wu ki o ri awọn ni a késí lati pa iru isinmi miiran kan mọ. Paulu ṣalaye eyi fun awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ ti wọn jẹ́ Ju, ni sisọ pe: “Nitori naa isinmi kan kù fun awọn eniyan Ọlọrun. . . . Nitori naa ẹ jẹ ki a mura giri lati wọ inu isinmi naa.” (Heberu 4:4-11) Awọn Ju wọnyi, ṣaaju ki wọn tó di Kristian, ti tẹle Ofin Mose ní kínníkínní bi wọn ṣe lè ṣe tó ni iṣaaju. Nisinsinyi Paulu kò fun wọn niṣiiri mọ́ lati wá igbala nipasẹ awọn iṣẹ ṣugbọn kaka bẹẹ lati “sinmi” kuro ninu awọn òkú iṣẹ wọn. Lati isinsinyi lọ, wọn nilati ní igbagbọ ninu ẹbọ Jesu, eyi ti ó jẹ́ ọ̀nà kanṣoṣo nipasẹ eyi ti araye lè gbà jẹ́ olododo loju Ọlọrun.
Bawo lonii ni a ṣe lè fi igbeyẹwo kan-naa hàn fun oju-iwoye Ọlọrun? Bi awọn eniyan ẹlẹgbẹ wọn, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, gẹgẹ bi eniyan ọlọgbọn, mọriri ọjọ́ isinmi ọsọọsẹ kuro ninu iṣẹ ti ayé eyi ti o wà lẹnu iṣẹ ni ọpọlọpọ orilẹ-ede. Eyi fun wọn láàyè fun ajọṣepọ idile ati itura. Ṣugbọn ni pataki jù, ó ti jásí sáà akoko kan fun awọn ilepa Kristian miiran. (Efesu 5:15, 16) Iwọnyi ní awọn ipade ati kikopa ninu iṣẹ-ojiṣẹ itagbangba ninu, ṣiṣebẹwo sọdọ awọn aladuugbo wọn lati ṣajọpin isọfunni Bibeli nipa akoko ti ó wọlé dé tán nigba ti araye onigbagbọ yoo gbadun alaafia kari ilẹ̀-ayé. Bi iwọ yoo bá fẹ́ lati mọ̀ nipa eyi, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo layọ lati ràn ọ lọwọ, yala iyẹn jẹ́ ni ọjọ́ Saturday, Sunday, tabi ọjọ́ eyikeyii miiran ninu ọsẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Jesu pa ofin Ọjọ́-ìsinmi mọ́ lọna pípé dipo aṣa-atọwọdọwọ awọn Ju
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Awọn ilepa Kristian pese itura ni awọn ọjọ́ isinmi kuro lẹnu iṣẹ ayé