-
Ṣé Jèhófà Lo Tẹjú Mọ́?Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018 | July
-
-
5-7. Ìṣòro wo ló jẹyọ lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, báwo sì ni Mósè ṣe yanjú ọ̀rọ̀ náà?
5 Kò pé oṣù méjì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì ni ìṣòro ńlá kan jẹyọ, kódà wọn ò tíì dé Òkè Sínáì tí wàhálà náà fi ṣẹlẹ̀. Àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn pé kò sómi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè. Ọ̀rọ̀ yẹn le débi pé Mósè ké jáde sí Jèhófà pé: “Kí ni èmi yóò ti ṣe ti àwọn ènìyàn yìí sí? Ní ìgbà díẹ̀ sí i, wọn yóò sọ mí lókùúta!” (Ẹ́kís. 17:4) Jèhófà dá Mósè lóhùn, ó sì fún un ní ìtọ́ni tó ṣe kedere. Jèhófà sọ pé kó mú ọ̀pá rẹ̀, kó lu àpáta tó wà ní Hórébù, omi á sì jáde nínú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ ní ojú àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mu omi débi tó tẹ́ wọn lọ́rùn, ìṣòro náà sì yanjú.—Ẹ́kís. 17:5, 6.
-
-
Ṣé Jèhófà Lo Tẹjú Mọ́?Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018 | July
-
-
11. Bí Mósè ṣe lu àpáta yẹn, kí ló ṣeé ṣe káwọn èèyàn yẹn máa rò nípa iṣẹ́ ìyanu náà?
11 Ohun míì tún wà tó ṣeé ṣe kó fà á. Akọ òkúta làwọn àpáta tó wà ní Mẹ́ríbà àkọ́kọ́. Kò sí béèyàn ṣe lè lù ú tó tí omi máa jáde nínú rẹ̀. Àmọ́ òkúta ẹfun tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára làwọn àpáta tó wà ní Mẹ́ríbà kejì. Torí pé òkúta ẹfun kì í fi bẹ́ẹ̀ lágbára, omi sábà máa ń wà nínú rẹ̀, àwọn èèyàn sì lè fa omi náà jáde. Bí Mósè ṣe lu àpáta tí kò lágbára yẹn lẹ́ẹ̀mejì, ṣé kò ní dà bíi pé àpáta yẹn ló mú omi inú rẹ̀ jáde fúnra rẹ̀, pé kì í ṣe Jèhófà ló ṣe iṣẹ́ ìyanu náà? Bí Mósè ṣe lu àpáta yẹn dípò kó bá a sọ̀rọ̀, ṣé àwọn èèyàn náà máa gbà pé Jèhófà ló ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí?b A ò lè fi gbogbo ẹnu sọ.
-