“Israeli Ọlọrun” àti “Ogunlọ́gọ̀ Ńlá”
“Mo rí, sì wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹni kankan kò lè kà.”—ÌṢÍPAYÁ 7:9.
1-3. (a) Ìfojúsọ́nà ológo wo ní ọ̀run ni àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ní? (b) Báwo ni Satani ṣe gbìyànjú láti pa ìjọ ọ̀rúndún kìn-ínní run? (d) Kí ni ó ṣẹlẹ̀ ní 1919 tí ó fi hàn pé ìsapá Satani láti sọ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró dìbàjẹ́ ti kùnà?
PÍPILẸ̀ “Israeli Ọlọrun” ní 33 C.E. jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì kan nínú ìṣiṣẹ́yọrí àwọn ète Jehofa. (Galatia 6:16) Àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ẹni-àmì-òróró ní ìrètí dídi ẹ̀dá ẹ̀mí aláìleèkú kí wọ́n sì ṣàkóso pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba Ọlọrun ní ọ̀run. (1 Korinti 15:50, 53, 54) Nínú ipò náà wọ́n ń mú ipò iwájú nínú sísọ orúkọ Jehofa di mímọ́ àti fífọ́ orí Elénìní ńlá náà, Satani Èṣù. (Genesisi 3:15; Romu 16:20) Abájọ tí Satani fi sa gbogbo agbára rẹ̀ láti pa ìjọ titun yìí run, nípa ṣíṣe inúnibíni síi àti nípa gbígbìyànjú láti sọ ọ́ di ìbàjẹ́!—2 Timoteu 2:18; Juda 4; Ìṣípayá 2:10.
2 Nígbà tí àwọn aposteli wàláàyè, Satani kò ṣàṣeyọrí. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn ikú wọn, ìpẹ̀yìndà tàn kálẹ̀ láìdáwọ́dúró. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, lójú ìwòye ẹ̀dá ènìyàn, ìjọ Kristian mímọ́ gaara tí Jesu dá sílẹ̀ dàbí èyí tí a ti sọ dìbàjẹ́ nígbà tí Satani mú àwọn ayédèrú ìsìn apẹ̀yìndà tí a mọ̀ lónìí sí Kristẹndọm wá. (2 Tessalonika 2:3-8) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìsìn Kristian tòótọ́ ń báa lọ láìdáwọ́dúró.—Matteu 28:20.
3 Nínú àpèjúwe rẹ̀ nípa àlìkámà àti àwọn èpò, Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé àwọn Kristian tòótọ́ yóò dàgbà fún àkókò gígùn papọ̀ pẹ̀lú “awọn èpò,” tàbí àwọn èké Kristian; èyí sì rí bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ó tún sọ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, “àwọn ọmọ ìjọba” ni a óò yà sọ́tọ̀ lọ́nà tí ó ṣe é fojúrí kúrò lára “àwọn èpò.” (Matteu 13:36-43) Èyí pẹ̀lú rí bẹ́ẹ̀. Ní 1919 àwọn ojúlówó Kristian ẹni-àmì-òróró jáde wá láti inú oko-òǹdè Babiloni. A mọ̀ wọ́n látọ̀runwá gẹ́gẹ́ bí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” wọ́n sì fi tìgboyà tìgboyà ṣètò wíwàásù ìhìnrere Ìjọba náà. (Matteu 24:14, 45-47; Ìṣípayá 18:4) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo wọn ni Kèfèrí; ṣùgbọ́n nítorí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ ti Abrahamu, wọ́n di ‘ọmọ Abrahamu’ níti gidi. Wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà “Israeli Ọlọrun.”—Galatia 3:7, 26-29.
“Ogunlọ́gọ̀ Ńlá” Náà
4. Ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn Kristian wo ni ó wá di mímọ̀, pàápàá ní pàtàkì ní àwọn ọdún 1930?
4 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn wọnnì tí wọ́n dáhùnpadà sí ìwàásù àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró wọ̀nyí náà di ọmọ Israeli nípa tẹ̀mí, àwọn tí ó ṣẹ́kù lára àwọn 144,000, tí wọ́n ní ìrètí ti ọ̀run. (Ìṣípayá 12:17) Bí ó ti wù kí ó rí, pàápàá ní pàtàkì láti àwọn ọdún 1930, ẹgbẹ́ àwùjọ mìíràn ni a ṣàkíyèsí. Àwọn wọ̀nyí ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn “àgùtàn mìíràn” nínú àkàwé agbo àgùtàn. (Johannu 10:16) Àwọn ni ọmọ-ẹ̀yìn Kristi tí wọ́n ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí paradise ilẹ̀-ayé. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn ni ọmọ nípa tẹ̀mí fún àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró. (Isaiah 59:21; 66:22; fiwé 1 Korinti 4:15, 16.) Wọ́n mọ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú, àti bíi ti àwọn arákùnrin wọn ẹni-àmì-òróró, wọ́n ní ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ fún Jehofa, ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jesu, ìtara fún yíyin Ọlọrun, àti ìmúratán láti jìyà nítorí òdodo.
5. Báwo ni ipò àwọn àgùtàn mìíràn ṣe di èyí tí a lóye dáradára sí i ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀?
5 Lákọ̀ọ́kọ́ ipò àwọn àgùtàn mìíràn wọ̀nyí ni a kò lóye rẹ̀ dáradára, ṣùgbọ́n bí àkókò ti ń lọ, àwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ síí ṣe kedere. Ní 1932 àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ni a fún ní ìṣírí láti rọ àwọn àgùtàn mìíràn láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù—ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn àgùtàn mìíràn ti ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Ní 1934 àgùtàn mìíràn ni a fún ní ìṣírí láti juwọ́sílẹ̀ fún ìrìbọmi nínú omi. Ní 1935 a fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti inú Ìṣípayá orí 7. Ní 1938 a késí wọn láti wá síbi Ìṣe-Ìrántí ikú Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí òǹwòran. Ní 1951 a fòye mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tí ó dàgbàdénú láàárín wọn wà lára àwọn “ọmọ aládé” tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí “ibi ìlùmọ́ kúrò lójú ẹ̀fúùfù, àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì.” (Orin Dafidi 45:16; Isaiah 32:1, 2) Ní 1953, ètò-àjọ Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé—èyí tí apá tí ó pọ̀ jù nínú rẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún papọ̀ jẹ́ àwọn àgùtàn mìíràn—ni a rí gẹ́gẹ́ bí apá pàtàkì ẹgbẹ́ ti orí ilẹ̀-ayé tí yóò wà nínú ayé titun náà. Ní 1985 a lóye rẹ̀ pé lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jesu, àwọn àgùtàn mìíràn ni a pè ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọrun àti pẹ̀lú ìrètí líla Armageddoni já.
6. Kí ni ipò tí ó ní ààlà ti àwọn ẹni-àmì-òróró àti àwọn àgùtàn mìíràn lónìí, àwọn ìbéèrè wo ni èyí sì yọrí sí?
6 Nísinsìnyí, ní apá tí ó kẹ́yìn “awọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn 144,000 ti kú wọ́n sì ti gba èrè wọn ní ọ̀run. (2 Timoteu 3:1; Ìṣípayá 6:9-11; 14:13) Àwọn Kristian tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀-ayé ni wọ́n ń ṣe èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìnrere náà nísinsìnyí, wọ́n sì kà á sí àǹfààní láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni-àmì-òróró arákùnrin Jesu nínú èyí. (Matteu 25:40) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ẹni-àmì-òróró wọ̀nyí ni olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú nípasẹ̀ ẹni tí a gbà ń pèsè oúnjẹ nípa tẹ̀mí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Kí ni yóò jẹ́ ààyè àwọn àgùtàn mìíràn nígbà tí gbogbo àwọn ẹni-àmì-òróró bá ti gba èrè tiwọn ní ọ̀run? Ìṣètò wo ni a óò ṣe nígbà náà fún àwọn àgùtàn mìíràn? Àyẹ̀wò ráńpẹ́ nípa Israeli ìgbàanì yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn.
Àpẹẹrẹ Irú “Ìjọba Àwọn Àlùfáà”
7, 8. Dé àyè wo ni àwọn Israeli ìgbàanì fi jẹ́ ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ lábẹ́ májẹ̀mú Òfin?
7 Nígbà tí Jehofa yan Israeli gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè àkànṣe rẹ̀, ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, wí pé: “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ gba ohùn mí gbọ́ nítòótọ́, tí ẹ óò sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin óò jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo ènìyàn lọ: nítorí gbogbo ayé ni ti èmi. Ẹyin óò sì máa jẹ́ ìjọba àlùfáà fún mi, àti orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Eksodu 19:5, 6) Israeli jẹ́ àwọn ènìyàn àkànṣe fún Jehofa lórí ìpìlẹ̀ májẹ̀mú Òfin. Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni ìlérí tí ó ní ín ṣe pẹ̀lú ìjọba àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ yóò ṣe ní ìmúṣẹ?
8 Nígbà tí wọ́n bá jẹ́ olùṣòtítọ́, Israeli máa ń jẹ́wọ́ ipò ọba-aláṣẹ Jehofa wọ́n sì máa ń tẹ́wọ́gbà á gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn. (Isaiah 33:22) Nípa báyìí, wọ́n jẹ́ ìjọba kan. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣí i payá lẹ́yìn náà, ìlérí náà nípa “ìjọba kan” yóò túmọ̀ sí ju ìyẹn pàápàá lọ. Síwájú síi, nígbà tí wọ́n bá ṣègbọràn sí Òfin Jehofa, wọ́n máa ń mọ́ tónítóní, tí wọ́n sì máa ń ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè mímọ́. (Deuteronomi 7:5, 6) Wọ́n ha jẹ́ ìjọba àlùfáà bí? Tóò, ní Israeli ìran Lefi ni a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́-ìsìn ní tẹmpili, láàárín ẹ̀yà náà sì ni ẹgbẹ́ àlùfáà Lefi wà. Nígbà tí a fìdí Òfin Mose lọ́lẹ̀, àwọn ọmọkùnrin Lefi ni a fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún àwọn àkọ́bí gbogbo ìdílé tí kì í ṣe ti Lefi.a (Eksodu 22:29; Numeri 3:11-16, 40-51) Nípa báyìí, gẹ́gẹ́ bí a ti lè sọ pé ó jẹ́, gbogbo ìdílé ní Israeli ni a ṣojú fún nínú iṣẹ́-ìsìn ní tẹmpili. Èyí ni ipò tí ó fara jọ ipo àlùfáà jùlọ tí orílẹ̀-èdè náà ní. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣojú fún Jehofa níwájú àwọn orílẹ̀-èdè. Àjèjì yòówù tí ó bá fẹ́ láti jọ́sìn Ọlọrun òtítọ́ náà níláti ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Israeli.—2 Kronika 6:32, 33; Isaiah 60:10.
9. Kí ni ó mú Jehofa kọ ìjọba àríwá Israeli sílẹ̀ ‘nínú ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún un’?
9 Lẹ́yìn ikú Solomoni, àwọn ènìyàn Ọlọrun pín sí orílẹ̀-èdè àríwá ti Israeli lábẹ́ Ọba Jeroboamu àti orílẹ̀-èdè gúúsù ti Juda lábẹ́ Ọba Rehoboamu. Níwọ̀n bí tẹmpili náà, àárín gbùngbùn ìjọsìn mímọ́gaara, ti wà ní ìpínlẹ̀ Juda, Jeroboamu dá ìjọsìn tí kò bófinmu sílẹ̀ nípa gbígbé àwọn ère ẹgbọrọ màálù kalẹ̀ sí agbègbè ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè tirẹ̀. Síwájú sí i, “ó . . . kọ́ ilé ibi gíga wọnnì, ó sì ṣe àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn, tí kì í ṣe inú àwọn ọmọ Lefi.” (1 Awọn Ọba 12:31) Orílẹ̀-èdè àríwá rì sínú ìjọsìn èké nígbà tí Ọba Ahabu yọ̀ọ̀da kí aya rẹ̀ àjèjì, Jesebeli, dá ìjọsìn Baali sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà. Ní ìkẹyìn, Jehofa kéde ìdájọ́ lé ìjọba ọlọ̀tẹ̀ náà lórí. Nípasẹ̀ Hosea, ó sọ pé: “A ké àwọn ènìyàn mi kúrò nítorí àìní ìmọ̀: nítorí ìwọ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀, èmi óò sì kọ̀ ọ́, tí ìwọ kì yóò ṣe àlùfáà mi mọ́.” (Hosea 4:6) Kété lẹ́yìn náà, àwọn ará Assiria pa ìjọba àríwá Israeli run.
10. Báwo ni ìjọba gúúsù Juda, nígbà tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, ṣe ṣojú fún Jehofa níwájú àwọn orílẹ̀-èdè?
10 Kí ni níti Juda, orílẹ̀-èdè gúúsù? Ní àwọn ọjọ́ Hesekiah, Jehofa sọ fún wọn nípasẹ̀ Isaiah pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, . . . àti ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn: . . . Àwọn ènìyàn [tí] mo ti mọ̀ fún ara mi; wọn óò fi ìyìn mi hàn.” (Isaiah 43:10, 21; 44:21) Nígbà tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, ìjọba gúúsù ṣiṣẹ́sìn láti polongo ògo Jehofa fún àwọn orílẹ̀-èdè àti láti pe àwọn ọlọ́kàn-títọ́ láti jọ́sìn rẹ̀ nínú tẹmpili rẹ̀ kí ẹgbẹ́ àlùfáà Lefi tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí i sì máa ṣèránṣẹ́ fún un.
Àwọn Àjèjì ní Israeli
11, 12. Dárúkọ díẹ̀ lára àwọn àjèjì tí wọ́n wá láti ṣiṣẹ́sin Jehofa ní ìkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Israeli.
11 Níti àwọn àjèjì tí wọ́n dáhùnpadà sí ìjẹ́rìí kárí orílẹ̀-èdè yìí, a ṣètò fún wọn nínú Òfin tí a fúnni nípasẹ̀ Mose—ẹni tí ìyàwó rẹ̀, Sippora, jẹ́ ará Midiani. “Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó dàpọ̀ mọ́ wọn” tí wọn kì í ṣe ọmọ Israeli fi Egipti sílẹ̀ pẹ̀lú Israeli wọ́n sì wà níbẹ̀ nígbà tí a fúnni ní Òfin náà. (Eksodu 2:16-22; 12:38; Numeri 11:4) Rahabu àti ìdílé rẹ̀ ni a gbàlà kúrò ní Jeriko tí a sì tẹ́wọ́gbà wọ́n sínú ìjọ Júù lẹ́yìn náà. (Joṣua 6:23-25) Kété lẹ́yìn náà, àwọn ará Gibeoni wá àlááfíà pẹ̀lú Israeli a sì fún wọn ní iṣẹ́ ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àgọ́.—Joṣua 9:3-27; tún wo 1 Awọn Ọba 8:41-43; Esteri 8:17.
12 Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn àjèjì ṣiṣẹ́sìn ní ipò gíga. Uria ará Hitti, ọkọ Batṣeba, wà lára àwọn tí a kà sí “àwọn ọkùnrin akọni” Dafidi, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Saleki ará Ammoni. (1 Kronika 11:26, 39, 41; 2 Samueli 11:3, 4) Ebedmeleki, ará Etiopia, ṣiṣẹ́sìn nínú ààfin ó sì ní àǹfààní láti dé ọ̀dọ̀ ọba. (Jeremiah 38:7-9) Lẹ́yìn tí Israeli ti padà dé láti ìgbèkùn ní Babiloni, àwọn Netinimu tí wọn kì í ṣe ọmọ Israeli ni a fún ni ẹrù-iṣẹ́ tí ó pọ̀ síi ní ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn àlùfáà. (Esra 7:24) Níwọ̀n bí a ti ka àwọn kan lára àwọn àjèjì olùṣòtítọ́ wọ̀nyí, tàbí àwọn àtìpó, sí àwọn tí ń ṣàpẹẹrẹ àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá lónìí, àyè wọn jẹ́ ohun tí a nífẹ̀ẹ́ ọkàn sí.
13, 14. (a) Kí ni àǹfààní àti ẹrù-iṣẹ́ àwọn aláwọ̀ṣe ní Israeli? (b) Ojú wo ni àwọn ọmọ Israeli fi níláti wo àwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́?
13 Àwọn bẹ́ẹ̀ jẹ́ aláwọ̀ṣe, àwọn olùjọsìn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jehofa lábẹ́ Òfin Mose àwọn tí a yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn orílẹ̀-èdè papọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israeli. (Lefitiku 24:22) Wọ́n ń rúbọ, wọ́n takété sí ìjọsìn èké, wọ́n sì yẹra fún ẹ̀jẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israeli ti ṣe. (Lefitiku 17:10-14; 20:2) Wọ́n ṣèrànwọ́ nínú kíkọ́ tẹmpili Solomoni wọ́n sì darapọ̀ nínú mímú ìjọsìn tòótọ́ padàbọ̀sípò lábẹ́ Ọba Asa àti Ọba Hesekiah. (1 Kronika 22:2; 2 Kronika 15:8-14; 30:25) Nígbà tí Peteru lo kọ́kọ́rọ́ àkọ́kọ́ ti Ìjọba náà ní Pentekosti 33 C.E., àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “àwọn Júù àti [àwọn tí kì í ṣe Júù] àwọn aláwọ̀ṣe” gbọ́. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, àwọn kan lára àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta tí a batisí ní ọjọ́ náà jẹ́ aláwọ̀ṣe. (Ìṣe 2:10, 41) Kété lẹ́yìn náà, aláwọ̀ṣe kan ará Etiopia ni Filipi batisí—ṣáájú kí Peteru tó lo kọ́kọ́rọ́ Ìjọba náà tí ó kẹ́yìn fún Korneliu àti ìdílé rẹ̀. (Matteu 16:19; Ìṣe 8:26-40; 10:30-48) Ó hàn kedere pé, àwọn aláwọ̀ṣe ni a kò fojú wò gẹ́gẹ́ bí àwọn Kèfèrí.
14 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ipò àwọn aláwọ̀ṣe ilẹ̀ náà kò rí bíi ti àwọn ọmọ Israeli àbínibí. Àwọn aláwọ̀ṣe kò ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, àwọn àkọ́bí wọn ni a kò sì ṣojú fún nínú ẹgbẹ́ àlùfáà Lefi.b Àwọn aláwọ̀ṣe kò sì ní ilẹ̀ àjogúnbá ní Israeli. Síbẹ̀, àwọn ọmọ Israeli ni a pàṣẹ fún pé kí wọ́n gba ti àwọn olùṣòtítọ́ aláwọ̀ṣe rò kí wọ́n sì fojúwò wọ́n gẹ́gẹ́ bí arákùnrin.—Lefitiku 19:33, 34.
Orílẹ̀-Èdè Tẹ̀mí
15. Kí ni àbájáde rẹ̀ nígbà tí Israeli àbínibí kọ̀ láti tẹ́wọ́gba Messia náà?
15 A ṣètò Òfin láti mú kí Israeli wà ní mímọ́ tónítóní, kí wọ́n yà ara wọn sọ́tọ̀ kúró lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Ṣùgbọ́n ó tún wà fún ète mìíràn. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè polongo wa ní olódodo nitori ìgbàgbọ́.” (Galatia 3:24) Ó ṣeniláàánú pé, èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn ọmọ Israeli kùnà láti jẹ́ kí Òfin sìn wọ́n lọ sọ́dọ̀ Kristi. (Matteu 23:15; Johannu 1:11) Nítorí náà Jehofa Ọlọrun kọ orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ó sì mú kí a bí “Israeli Ọlọrun.” Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó nawọ́ ìkésíni náà sí àwọn tí kì í ṣe Júù láti di ará ìlú nínú Israeli titun yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. (Galatia 3:28; 6:16) Lórí orílẹ̀-èdè titun yìí ni ìlérí Jehofa nínú Eksodu 19:5, 6 nípa ẹgbẹ́ àlùfáà aládé ti ní ìmúṣẹ rẹ̀ àgbàyanu, tí ó kẹ́yìn. Báwo?
16, 17. Ní ọ̀nà wo ní àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró lórí ilẹ̀-ayé fi jẹ́ “aládé”? “ẹgbẹ́ àlùfáà” kan?
16 Peteru fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Eksodu 19:6 nígbà tí ó kọ̀wé sí àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró nígbà ayé rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà-ìran àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, awọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.’” (1 Peteru 2:9) Kí ni èyí túmọ̀ sí? Àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró lórí ilẹ̀-ayé ha jẹ́ ọba bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, ipò-ọba wọn ṣì jẹ́ lọ́jọ́ iwájú. (1 Korinti 4:8) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ “aládé” níti pé a ti yàn wọ́n fún àǹfààní aládé ní ọjọ́-iwájú. Nísinsìnyí pàápàá wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan lábẹ́ ọba kan, Jesu, tí Ọba-Aláṣẹ Gíga Jùlọ náà, Jehofa Ọlọrun yàn sípò. Paulu kọ̀wé pé: “[Jehofa] dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ọlá-àṣẹ òkùnkùn ó sì ṣí wa nípò lọ sínú ìjọba Ọmọkùnrin ìfẹ́ rẹ̀.”—Kolosse 1:13.
17 Àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró lórí ilẹ̀-ayé ha jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà bí? Bẹ́ẹ̀ni, ní àwọn ọ̀nà kan. Gẹ́gẹ́ bí ìjọ, wọ́n ń ṣe ojúṣe àwọn àlùfáà tí kò ṣeé jáníkoro. Peteru ṣàlàyé èyí nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ̀yin fúnra yín . . . ni a ń gbéró gẹ́gẹ́ bí ilé ti ẹ̀mí fún ète iṣẹ́ àlùfáà mímọ́.” (1 Peteru 2:5; 1 Korinti 3:16) Lónìí, àṣẹ́kù àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ní àpapọ̀ ni “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” ipa ọ̀nà fún pípín oúnjẹ tẹ̀mí. (Matteu 24:45-47) Bí ó ti rí ní Israeli àtijọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti jọ́sìn Jehofa níláti ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró wọ̀nyí.
18. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àlùfáà, ẹrù-iṣẹ́ pàtàkì wo ni ìjọ Kristian ẹni-àmì-òróró lórí ilẹ̀-ayé ní?
18 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró gba àǹfààní ti wíwàásù nípa ìtóbilọ́lá Jehofa láàárín àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ Israeli. Àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé nígbà tí Peteru pe àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ní ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, iṣẹ́ ìwàásù náà ni ó ní lọ́kàn. Nítòótọ́, ó pa ìlérí Jehofa nínú Eksodu 19:6 pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sí Israeli nínú Isaiah 43:21 pọ̀ nínú ìtọ́kasí kanṣoṣo nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ̀yin jẹ́ . . . ‘ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, . . . kí ẹ̀yin lè polongo káàkiri awọn ìtayọlọ́lá’ ẹni naa tí ó pè yín jáde kúrò ninu òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Peteru 2:9) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Paulu sọ̀rọ̀ nípa ìpolongo ìtayọlọ́lá Jehofa gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ tẹmpili. Ó kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ [Jesu] ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.”—Heberu 13:15.
Ìmúṣẹ ti Ọ̀run
19. Kí ni ìmúṣẹ kíkọyọyọ, tí ó kẹ́yìn níti ìlérí náà pé Israeli yóò jẹ́ ìjọba àlùfáà?
19 Bí ó ti wù kí ó rí, Eksodu 19:5, 6 ní ìmúṣẹ ológo tí ó pabanbarì ní ìkẹyìn. Nínú ìwé Ìṣípayá, aposteli Johannu gbọ́ àwọn ẹ̀dá ní ọ̀run tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ yìí sílò bí wọ́n ti ń yin Jesu tí a jí dìde náà pé: “A fikúpa ọ́ iwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra awọn ènìyàn fún Ọlọrun lati inú gbogbo ẹ̀yà ati ahọ́n ati awọn ènìyàn ati orílẹ̀-èdè, iwọ sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan ati àlùfáà fún Ọlọrun wa, wọn yoo sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀-ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:9, 10) Nígbà náà, ní àkótán, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé náà ni Ìjọba Ọlọrun ní ọ̀run, ìṣàkóso ọlá-àṣẹ tí Jesu kọ́ wa láti gbàdúrà fún. (Luku 11:2) Gbogbo àwọn 144,000 Kristian ẹni-àmì-òróró tí wọ́n bá lo ìfaradà gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ dé òpin yóò ní ipa nínú ètò Ìjọba náà. (Ìṣípayá 20:4, 6) Ẹ wo irú ìmúṣẹ àgbàyanu ti ìlérí tí a ti ṣe ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn nípasẹ̀ Mose!
20. Ìbéèrè wo ni ó ṣì wà láti dáhùn?
20 Kí ni gbogbo èyí ní ín ṣe pẹ̀lú àyè àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá àti ọjọ́-iwájú wọn nígbà tí gbogbo àwọn ẹni-àmì-òróró bá ti gba ogún àgbàyanu wọn náà? Èyí yóò ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó gbẹ̀yìn nínú ọ̀wọ́ yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí a fìdí ipò àlùfáà Israeli lọ́lẹ̀, àwọn ọmọkùnrin àkọ́bí tí kì í ṣe láti ìran Lefi ti Israeli àti àwọn ọmọkùnrin láti ìran Lefi ni a kà. Àkọ́bí 273 ni ó fi lé sí ti àwọn ọmọkùnrin Lefi. Nítorí ìdí èyí, Jehofa pàṣẹ pé kí a san ṣékélì márùn-ún lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn 273 náà gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún èyí tí ó fi lé.
b Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó dàpọ̀ mọ́ wọn tí wọn kì í ṣe ọmọ Israeli ni wọ́n wà níbẹ̀ nígbà tí a fìdí Òfin náà lọ́lẹ̀ ní 1513 B.C.E., ṣùgbọ́n àwọn àkọ́bí wọn ni a kò fi kún un nígbà tí a mú àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí pàṣípààrọ̀ fún àkọ́bí Israeli. (Wo ìpínrọ̀ 8.) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ Lefi ni a kò mú ní pàṣípààrọ̀ fún àkọ́bí àwọn wọ̀nyí tí kì í ṣe ọmọ Israeli.
O Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Báwo ni ipò àwọn àgùtàn mìíràn ṣe di èyí tí a lóye dáradára sí i ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀?
◻ Èéṣe tí Jehofa fi kọ ìjọba àríwá Israeli sílẹ̀ nínu ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún un?
◻ Nígbà tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, kí ni ipò Juda níwájú àwọn orílẹ̀-èdè?
◻ Kí ni ipò àwọn aláwọ̀ṣe olùṣòtítọ́ ní Israeli?
◻ Báwo ni ìjọ àwọn ẹni-àmì-òróró ṣe ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ìjọba àlùfáà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ń polongo ògo Jehofa lórí ilẹ̀-ayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìmúṣẹ Eksodu 19:6 tí ó kẹ́yìn ni Ìjọba náà