Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣó Yẹ Ká Máa Fi Ère Jọ́sìn Ọlọ́run?
“Wọ́n fi kọ́ mi pé ère máa jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.”—Mack.
“Ère ìsìn pọ̀ nílé wa. A rò pé ìyẹn ló máa jẹ́ kínú Ọlọ́run dùn sí wa.”—Herta.
“A máa ń forí balẹ̀ fáwọn ère kan. A ò tiẹ̀ ronú nípa ojú tí Ọlọ́run máa fi wo ohun tá à ń ṣe yìí.”—Sandra.
KÍ LO ti rí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé ère ìsìn ló máa ń jẹ́ káwọn jọ́sìn Ọlọ́run bó ṣe tọ́. Ṣóòótọ́ nìyẹn? Ojú wo tiẹ̀ ni Ọlọ́run fi ń wo àṣà yẹn? Gbé ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ yẹ̀ wò.
Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Lílo Ère Nínú Ìjọsìn
Ère ìsìn ni ohun táwọn èèyàn fi ń ṣe àmì ẹ̀sìn tàbí ohun tí wọ́n ń júbà fún, dípò Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ ère ìsìn ni àgbélébùú tàbí àwòrán ohunkóhun tó wà láyé tàbí lọ́run.a Wọ́n tún máa ń jọ́sìn àsíá.
Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn ti ń lo ère nínú ìjọsìn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí Ọlọ́run ń fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní Òfin Mẹ́wàá, ó sọ ojú tóun fi ń wo lílo ère nínú ìjọsìn, ó ní: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, nítorí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.”—Ẹ́kísódù 20:4, 5.
Kíyè sí i pé ohun méjì ni Ọlọ́run kà léèwọ̀: Àkọ́kọ́ ni pé, ó ní káwọn èèyàn òun má ṣe ère fún ìjọsìn; èkejì sì ni pé kí wọ́n má ṣe “tẹrí ba fún wọn” tàbí kí wọ́n sìn wọ́n. Kí nìdí tí Ẹlẹ́dàá wa fi ka ṣíṣe ère léèwọ̀? Ìdí kan tí kò fi yẹ ká gbẹ́ ère Ọlọ́run ni pé “kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.” Jèhófà kì í ṣe èèyàn bíi tiwa, ẹni ẹ̀mí ni, ibùgbé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló sì ń gbé. (Jòhánù 1:18; 4:24) Ìdí míì tá ò fi gbọ́dọ̀ ṣe àwòrán ohunkóhun fún ìjọsìn ni pé Ọlọ́run ń béèrè “ìfọkànsìn tá a ya sọ́tọ̀ gedegbe.” Ó sọ pé: “Èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn mi fún àwọn ère fífín.” (Aísáyà 42:8) Èyí tún fi hàn pé kò dáa ká máa gbẹ́ ère tàbí ya àwòrán ká lè fi jọ́sìn Ọlọ́run. Nígbà tí aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Áárónì ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà bínú sí wọn gan-an.—Ẹ́kísódù 32:4-10.
Kí Nìdí Tá Ò Fi Gbọ́dọ̀ Tẹrí Ba fún Wọn?
Bíbélì sọ nípa àwọn ère pé: “Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ̀rọ̀; wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò lè ríran; wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè gbọ́ran.” Ó wá fi ìkìlọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ yìí kún un pé: “Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóò dà bí àwọn gan-an,” ìyẹn ni pé àwọn náà máa di aláìlẹ́mìí!—Sáàmù 115:4-8.
Ìwà ìrẹ́nijẹ làwọn tó ń lo ère láti jọ́sìn Ọlọ́run ń hù. Bi ara ẹ pé, ‘Báwo ló ṣe máa rí lára mi tí mo bá fún ọmọ mi ní ẹ̀bùn tó ṣeyebíye, àmọ́ tó jẹ́ pé àjèjì kan tàbí ohun kan tí ò lẹ́mìí ló lọ ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀?’ Ó ṣeé ṣe kíyẹn jẹ́ kó o mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Ẹlẹ́dàá wa àti Olùfúnni-Ní-Ìyè nígbà táwọn ère tí ò lẹ́mìí bá ń gba oríyìn àti ìjọsìn tó tọ́ sí i.—Ìṣípayá 4:11.
Tún wá ronú nípa bó ṣe bu èèyàn tí Ọlọ́run dá ní àwòrán ara ẹ̀ kù tó láti máa jọ́sìn ohun aláìlẹ́mìí! (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Wòlíì Aísáyà kọ̀wé nípa àwọn kan tó ṣe bẹ́ẹ̀ pé: “Iṣẹ́ ọwọ́ ara ẹni sì ni wọ́n ń tẹrí ba fún, èyí tí ìka ara ẹni ṣe. Ará ayé sì tẹrí ba, ènìyàn sì di rírẹ̀sílẹ̀, ìwọ [Jèhófà Ọlọ́run] kò sì lè dárí jì wọ́n rárá.”—Aísáyà 2:8, 9.
Ohun tó tún wá mú kí Ọlọ́run túbọ̀ kórìíra ìsìn èké ni pé ìjọsìn àwọn ẹ̀mí èṣù, ìyẹn àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, ló jẹ́. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ Jèhófà sílẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn ère, ìwé Diutarónómì 32:17 sọ pé “wọ́n ń bá a lọ láti máa rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe sí Ọlọ́run.”
Ṣé ìgbà kankan tiẹ̀ wà táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ṣe àwọn ère tàbí tí wọ́n lò wọ́n láti jọ́sìn Ọlọ́run? Rárá o! Jòhánù, ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.” (1 Jòhánù 5:21) Ìwé kan tó dá lórí ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì, ìyẹn Early Church History to the Death of Constantine, sọ pé: “Kò sóhun tó máa kó àwọn ọmọlẹ́yìn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ nírìíra tó kí wọ́n máa fi ère jọ́sìn Ọlọ́run.”
Ìjọsìn Tó Tọ́
Jésù sọ pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23) Bọ́ràn ṣe rí gan-an nìyẹn, Ọlọ́run fẹ́ ká mọ òun gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, ká mọ ohun tóun fẹ́ àtohun tóun kórìíra, àwọn ìlànà òun àti ìdí tóun fi dá wa sáyé. (Jòhánù 17:3) Kódà, ìdí nìyẹn tó fi lo àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì. (2 Tímótì 3:16) Bákan náà, torí pé Ọlọ́run “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa,” a lè gbàdúrà sí i nígbàkigbà, níbikíbi, a ò sì nílò àwọn ère ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 17:27.
Sandra tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Nígbà tí mo wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mi ò rí ère kankan tí wọ́n fi ń jọ́sìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí fàwọn ànímọ́ Ọlọ́run àtàwọn nǹkan tó ń béèrè lọ́wọ́ wa hàn mí látinú Bíbélì. Torí náà, mo kọ́ bí mo ṣe lè máa gbàdúrà kí Ọlọ́run lè gbọ́ mi. Mo ti wá rí i báyìí pé mo ti mọ ẹni tí Ẹlẹ́dàá jẹ́ gan-an, mo sì ti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀.” Bó ṣe rí nìyẹn, Sandra kọ́ bí òtítọ́ inú Bíbélì ṣe ń tuni nínú tó sì ń dáni sílẹ̀ lómìnira gan-an. (Jòhánù 8:32) Ọ̀ràn tìẹ náà lè dà bíi ti Sandra.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ tó ní àkọlé náà, “Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú sí Lóòótọ́?” tó wà nínú Jí! April–June 2006.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ yẹra fún gbogbo onírúurú ère nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run?—Sáàmù 115:4-8; 1 Jòhánù 5:21.
◼ Báwo ló ṣe yẹ ká máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́?—Jòhánù 4:24.
◼ Báwo lo ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, báwo lo sì ṣe lè jàǹfààní látinú ṣíṣe bẹ́ẹ̀? —Jòhánù 8:32; 17:3.