ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Ha Lòdì Láti Máa Pe Orúkọ Ọlọ́run Bí?
    Jí!—1999 | March 8
    • FÚN ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni ìsìn àwọn Júù ti ń fi kọ́ni pé orúkọ àtọ̀runwá náà, Jèhófà, jẹ́ mímọ́ ju ohun tí a lè máa pè lọ.a (Sáàmù 83:18) Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ló ti ronú pé kò fi ọ̀wọ̀ hàn láti pe Ẹlẹ́dàá ológo lọ́nà kan ṣáá bẹ́ẹ̀, tàbí pé ó tilẹ̀ jẹ́ rírú òfin kẹta nínú Òfin Mẹ́wàá tí ó ka ‘pípe orúkọ Olúwa lásán’ léèwọ̀. (Ẹ́kísódù 20:7, King James Version) Ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa, Mishnah polongo pé “ẹnikẹ́ni tó bá pe Orúkọ àtọ̀runwá náà bí a ṣe kà á jáde lọ́kọ̀ọ̀kan” kò ní ní “ìpín kankan nínú ayé tí ń bọ̀.”—Sanhedrin 10:1.

  • Ó Ha Lòdì Láti Máa Pe Orúkọ Ọlọ́run Bí?
    Jí!—1999 | March 8
    • Òfin Kẹta Náà

      Àmọ́, ìkàléèwọ̀ tí a mẹ́nu kàn nínú òfin kẹta nínú àwọn Òfin Mẹ́wàá ńkọ́? Ẹ́kísódù 20:7 sọ ní kedere pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí, nítorí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tí ó lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò ní láárí.”

      Kí ló túmọ̀ sí gan-an láti lo orúkọ Ọlọ́run “lọ́nà tí kò ní láárí”? Ìwé The JPS Torah Commentary, tí Jewish Publication Society tẹ̀ jáde, ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí a lò lókè yìí bíi “lọ́nà tí kò ní láárí” (lash·shaw’ʹ) lè túmọ̀ sí “ní ẹ̀tàn” tàbí “láìnídìí, lásán.” Ìwé kan náà sọ síwájú sí i pé: “Àìṣetààrà [ọ̀rọ̀ Hébérù yìí] mú kí a lè ká àwọn tí ń jẹ́jọ́ lọ́wọ́ kò [kà á léèwọ̀ fún wọn] láti má ṣe jẹ́rìí èké, tàbí búra èké, kí wọ́n má sì lo Orúkọ àtọ̀runwá náà láìyẹ tàbí lọ́nà ṣiréṣiré.”

      Ìwé àlàyé àwọn Júù yìí tẹnu mọ́ ọn lọ́nà tí ó tọ́ pé ‘lílo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò ní láárí’ wé mọ́ lílo orúkọ náà lọ́nà tí kò yẹ. Síbẹ̀, ǹjẹ́ a lè sọ pé pípe orúkọ Ọlọ́run nígbà tí a bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀ tàbí nígbà tí a bá ń gbàdúrà sí Baba wa ọ̀run jẹ́ ‘àìyẹ tàbí ṣiréṣiré’? Jèhófà sọ èrò rẹ̀ jáde nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Sáàmù 91:14 pé: “Nítorí pé òun darí ìfẹ́ni rẹ̀ sí mi, èmi pẹ̀lú yóò pèsè àsálà fún un. Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.”

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́