“Bí Ẹ Bá Mọ Nǹkan Wọ̀nyí, Aláyọ̀ Ni Yín Bí Ẹ Bá Ń Ṣe Wọ́n”
“Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.”—JÒH. 4:34.
1. Àkóbá wo ni ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tó kúnnú ayé yìí lè ṣe fún wa?
KÍ NÌDÍ tó fi máa ń ṣòro láti fi àwọn ohun tá a kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò? Ìdí kan ni pé, ó gba ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kéèyàn tó lè ṣe ohun tó tọ́. Kò rọrùn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí torí pé àwọn “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera” àti “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu” ló yí wa ká. (2 Tím. 3:1-3) Torí pé a jẹ́ èèyàn Ọlọ́run, a mọ̀ pé àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ò dáa. Ṣùgbọ́n, ó jọ pé àwọn tó ń hu àwọn ìwà yìí gan-an ló ń gbádùn ayé wọn, tá ò bá sì ṣọ́ra a lè bẹ̀rẹ̀ sí í jowú wọn. (Sm. 37:1; 73:3) A lè máa ronú pé: ‘Ṣé àǹfààní tiẹ̀ wà nínú kéèyàn máa fi ire àwọn míì ṣáájú tara ẹ̀? Ṣé àwọn èèyàn ò ní máa fojú pa mí rẹ́ tí mo bá ń ṣe bí “ẹni tí ó kéré jù”?’ (Lúùkù 9:48) Tá a bá jẹ́ kí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tó kúnnú ayé yìí kéèràn ràn wá, àjọṣe àwa àtàwọn ará ìjọ lè má gún régé mọ́, ó sì lè ṣòro fáwọn èèyàn láti mọ̀ pé Kristẹni ni wá. Kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa, á dáa ká kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì, ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.
2. Kí la lè kọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà àtijọ́?
2 Tá a bá fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà àtijọ́, ó yẹ ká ṣàṣàrò lórí ohun tí wọ́n ṣe tó mú kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Báwo ni wọ́n ṣe di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Kí ló mú kí Jèhófà fojúure hàn sí wọn? Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run? Irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára.
OÚNJẸ TẸ̀MÍ KỌJÁ KÉÈYÀN KÓ ÌMỌ̀ JỌ
3, 4. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà fún wa ní ìtọ́ni? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí kọjá kéèyàn kàn kó ìmọ̀ jọ?
3 Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà ń gbà fún wa láwọn ìtọ́ni tó lè ṣe wá láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, à ń rí àwọn ìtọ́ni yìí nínú Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa, a sì tún ń rí i lórí ìkànnì wa àti nínú Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń gba àwọn ìtọ́ni yìí láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa. Síbẹ̀, Jésù sọ ohun kan nínú Jòhánù 4:34 tó jẹ́ ká mọ̀ pé jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí kọjá kéèyàn kàn kó ìmọ̀ jọ. Jésù sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.”
4 Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ dà bí oúnjẹ fún òun. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Bó ṣe jẹ́ pé tá a bá jẹ oúnjẹ aṣaralóore, a máa ní okun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára tá a bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó lè rẹ̀ wá nígbà míì, kó sì máa ṣe wá bíi pé ká má lọ sóde ẹ̀rí. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà tá a bá tiraka láti lọ, inú wa máa ń dùn, ara wa sì máa ń yá gágá bá a ṣe ń pa dà bọ̀. Ǹjẹ́ irú ẹ̀ ti ṣe ìwọ náà rí?
5. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n?
5 Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà bá ní ká ṣe, a máa jẹ́ ọlọ́gbọ́n. (Sm. 107:43) Àǹfààní tá a sì máa rí tá a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n kọjá àfẹnusọ. Bíbélì sọ pé ọgbọ́n “ṣe iyebíye ju iyùn, a kò sì lè mú gbogbo àwọn nǹkan mìíràn tí í ṣe inú dídùn rẹ bá a dọ́gba. . . . Ó jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀.” (Òwe 3:13-18) Jésù náà sọ pé: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.” (Jòh. 13:17) Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù á máa láyọ̀ kìkì tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Jésù fún wọn. Àwọn ìtọ́ni yìí kì í ṣe ohun tí wọ́n kàn máa tẹ̀ lé lẹ́ẹ̀kan tí wọ́n á sì dáwọ́ dúró, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé e jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn.
6. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti máa fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ sílò lójoojúmọ́?
6 Lónìí, ó ṣe pàtàkì káwa náà sapá ká lè máa fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, mẹkáníìkì kan lè ní irinṣẹ́ tó nílò, kó sì tún mọṣẹ́ dáadáa. Àmọ́ irinṣẹ́ àti ìmọ̀ tó ní kò ní ṣe é láǹfààní kankan tí kò bá lò wọ́n. Ó lè mọṣẹ́ náà dáadáa nígbà tó kọ́ ọ, àmọ́ kò sígbà tí kò ní gbàgbé rẹ̀ tí kò bá máa ṣe iṣẹ́ náà lóòrèkóòrè. Lọ́nà kan náà, inú wa dùn gan-an nígbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. Àmọ́ kí ayọ̀ náà tó lè bá wa kalẹ́, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà lójoojúmọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.
7. Kí la máa kọ́ lára àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì?
7 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò onírúurú nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ tó lè mú kó ṣòro fún wa láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. A sì máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ayé àtijọ́ ṣe nígbà tí wọ́n bá ara wọn nínú àwọn ipò yìí. Àmọ́ kò yẹ ká kàn ka àwọn ìtàn yìí nìkan. Ó tún yẹ ká ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìtàn náà, ká sì fi àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ sílò láìjáfara.
MÁ ṢE RÒ PÉ O SÀN JU ÀWỌN MÍÌ LỌ
8, 9. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 14:8-15, kí la rí kọ́ lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ká mọ̀ pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
8 Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé ká gba “gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Irú ojú wo lo fi máa ń wo onírúurú àwọn ènìyàn tí wọn ò tíì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń wá àwọn Júù lọ sínú sínágọ́gù kó lè wàásù fún wọn, síbẹ̀ kó fi ìwàásù rẹ̀ mọ sọ́dọ̀ àwọn Júù nìkan, ó tún wàásù fáwọn abọ̀rìṣà. Àmọ́ ohun táwọn abọ̀rìṣà yẹn ṣe lẹ́yìn tó wàásù fún wọn máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá Pọ́ọ̀lù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
9 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà rìnrìn-àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́, wọ́n dé ìlú Lísírà. Ńṣe làwọn ará ìlú yẹn fẹ́ sọ àwọn méjèèjì di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, wọ́n rò pé àwọn méjèèjì ni òòṣà Súúsì àti Hẹ́mísì tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀. Ṣé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wá jẹ́ kíyẹn kó sí wọn lórí débi tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe fọ́ńté? Àbí wọ́n fi àǹfààní yẹn jayé orí wọn, ó kúkú ṣe tán àtakò ni wọ́n kojú láwọn ìlú méjì tí wọ́n ti kúrò? Ṣé wọ́n ronú pé báwọn èèyàn ṣe ń yẹ́ àwọn sí yìí máa jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ ìhìn rere? Rárá o! Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n gbọn ẹ̀wù wọn ya, wọ́n sì ké jáde pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn tí ó ní àwọn àìlera kan náà tí ẹ̀yin ní.”—Ìṣe 14:8-15.
10. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ò fi ronú pé àwọn sàn ju àwọn ará ìlú Lísírà lọ?
10 Lóòótọ́, ẹ̀sìn àwọn èèyàn náà yàtọ̀ sí ti Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀ pé aláìpé bíi tiwọn làwọn náà. Jèhófà ló dìídì yan Pọ́ọ̀lù àti Bánábà láti jẹ́ míṣọ́nnárì. (Ìṣe 13:2) Òun náà ló fẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n, tó sì fún wọn ní ìrètí àgbàyanu. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ò ronú pé àwọn sàn ju àwọn ará ìlú yẹn lọ torí wọ́n mọ̀ pé àwọn èèyàn náà lè nírú àwọn àǹfààní kan náà tí wọ́n bá tẹ́wọ́ gba ìhìn rere.
11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Pọ́ọ̀lù tá a bá ń wàásù?
11 Báwo la ṣe lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Pọ́ọ̀lù? Àkọ́kọ́, kò yẹ ká jẹ́ káwọn èèyàn máa gbé wa gẹ̀gẹ̀ torí àwọn àṣeyọrí tá a ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó ṣe tán kò sí ohun tá a lè dá ṣe láìsí ìtìlẹyìn Jèhófà. Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Irú ojú wo ni mo fi ń wo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù mi? Ṣé kì í ṣe pé mo máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn kan ládùúgbò mi torí pé àwọn èèyàn kì í ka irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sí?’ Inú wa dùn pé kárí ayé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá onírúurú èèyàn tó fẹ́ gbọ́ ìhìn rere níbikíbi tí wọ́n bá wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Nígbà míì, a tiẹ̀ máa ń kọ́ èdè àti àṣà àwọn míì táwọn èèyàn máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ká lè wàásù fún wọn. A kì í ronú pé a sàn ju irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa ń sún mọ́ wọn ká lè mọ̀ wọ́n dáadáa, ká sì wàásù fún wọn lọ́nà táá wọ̀ wọ́n lọ́kàn.
MÁA GBÀDÚRÀ FÁWỌN MÍÌ
12. Báwo ni Epafírásì ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ òun lọ́kàn?
12 Ọ̀nà kejì tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ni pé ká máa gbàdúrà fún àwọn Kristẹni bíi tiwa. (2 Pét. 1:1) Ohun tí Epafírásì máa ń ṣe nìyẹn. Ẹ̀ẹ̀mẹta péré ni Bíbélì dárúkọ rẹ̀, inú àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù ló sì ti fara hàn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní àtìmọ́lé ní Róòmù, ó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè pé: “Nígbà gbogbo ni [Epafírásì] ń tiraka nítorí [wọn] nínú àwọn àdúrà rẹ̀.” (Kól. 4:12) Ìyẹn nìkan kọ́ o, Epafírásì tún mọ àwọn ará dáadáa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Epafírásì náà ní àwọn ìṣòro tiẹ̀ torí pé Pọ́ọ̀lù pè é ní “òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi.” Síbẹ̀, ó máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ òun lọ́kàn. (Fílém. 23) Ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ran àwọn ará lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ẹ ò rí i pé ànímọ́ àtàtà ni Epafírásì ní! Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa, kódà ká máa dárúkọ wọn nínú àdúrà wa torí pé Jèhófà máa ń gbọ́ irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀.—2 Kọ́r. 1:11; Ják. 5:16.
13. Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Epafírásì tó o bá ń gbàdúrà?
13 Ẹ jẹ́ ká ronú nípa àwọn tá a lè forúkọ wọn sádùúrà. Bíi ti Epafírásì, ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló máa ń gbàdúrà fáwọn ará ìjọ tó ń kojú àwọn ìṣòro tó le tàbí kí wọ́n gbàdúrà fáwọn ìdílé tó níṣòro àtijẹ-àtimu. Àwọn míì máa ń gbàdúrà fáwọn tá a to orúkọ wọn sínú àpilẹ̀kọ náà, “Wọ́n Fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́” lórí ìkànnì jw.org. (Wo abẹ́ ÌRÒYÌN >Ọ̀RÀN ẸJỌ́.) Láfikún, ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn téèyàn wọn kú tàbí àwọn tí ogun àtàwọn àjálù míì ṣẹlẹ̀ lágbègbè wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn míì tọ́rọ̀ àtijẹ-àtimu ṣòro fún. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló nílò àdúrà wa. Tá a bá ń gbàdúrà fún wọn, à ń jẹ́ kí ire àwọn míì jẹ wá lọ́kàn nìyẹn. (Fílí. 2:4) Ó sì dájú pé Jèhófà máa gbọ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀.
“YÁRA NÍPA Ọ̀RỌ̀ GBÍGBỌ́”
14. Báwo ni Jèhófà ṣe fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn míì?
14 Ọ̀nà míì tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ni pé ká máa tẹ́tí sí àwọn míì. Jákọ́bù 1:19 sọ pé ká “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́.” Jèhófà ló fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn míì. (Jẹ́n. 18:32; Jóṣ. 10:14) Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ìjíròrò tó wáyé nínú Ẹ́kísódù 32:11-14. (Kà á.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pọn dandan kí Jèhófà gbọ́ tẹnu Mósè kó tó ṣe ohun tó ní lọ́kàn, síbẹ̀ ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí Mósè, kí Mósè lè sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lọ́kàn rẹ̀. Tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan máa ń ṣàṣìṣe, a lè má fẹ́ tẹ́tí sírú ẹni bẹ́ẹ̀ débi tá a fi máa ṣiṣẹ́ lórí ohun tó sọ. Síbẹ̀, Jèhófà máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí gbogbo àwọn tó bá ń ké pè é tí wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.
15. Báwo la ṣe lè yẹ́ àwọn míì sí bíi ti Jèhófà?
15 Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé: ‘Tí Jèhófà bá lè rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kó lè tẹ́tí sí àwọn èèyàn bí Ábúráhámù, Rákélì, Mósè, Jóṣúà, Mánóà, Èlíjà àti Hesekáyà, ṣé kò yẹ kí èmi náà máa tẹ́tí sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi? Ṣé mo lè túbọ̀ yẹ́ wọn sí, kí n gbọ́ èrò wọn, tó bá sì ṣeé ṣe kí n ṣiṣẹ́ lórí àwọn àbá tó dáa tí wọ́n bá mú wá? Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ mi tàbí nínú ìdílé mi tó yẹ kí n tẹ́tí sí? Báwo ni mo ṣe lè ran ẹni náà lọ́wọ́?’—Jẹ́n. 30:6; Oníd. 13:9; 1 Ọba 17:22; 2 Kíró. 30:20.
“BÓYÁ JÈHÓFÀ YÓÒ FI OJÚ RẸ̀ RÍ I”
16. Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tí Ṣíméì múnú bí i?
16 Ọ̀nà kẹrin tá a lè gbà fi hàn pé a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ni pé ká máa kó ara wa níjàánu nígbà táwọn míì bá ṣẹ̀ wá. (Éfé. 4:2) Àpẹẹrẹ kan tó ta yọ wà nínú 2 Sámúẹ́lì 16:5-13. (Kà á.) Ṣíméì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí Ọba Sọ́ọ̀lù bú Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kódà ó tiẹ̀ ń sọ òkúta lù wọ́n. Síbẹ̀, Dáfídì fara dà á láìka pé ó láṣẹ láti pa Ṣíméì lẹ́nu mọ́. Kí ló mú kí Dáfídì lè kóra ẹ̀ níjàánu? Ohun tó wà nínú Sáàmù kẹta jẹ́ ká mọ ohun tó ran Dáfídì lọ́wọ́.
17. Kí ló mú kí Dáfídì lè kóra ẹ̀ níjàánu, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
17 Àkọlé tó wà ní Sáàmù kẹta jẹ́ ká mọ̀ pé Dáfídì ló kọ orin yẹn nígbà tó ń “fẹsẹ̀ fẹ ní tìtorí Ábúsálómù ọmọkùnrin rẹ̀.” Ẹsẹ 1 àti 2 bá ohun tó wà ní Sámúẹ́lì Kejì orí 16 mu gẹ́lẹ́. Sáàmù 3:4 wá jẹ́ ká rí i pé Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó ní: “Èmi yóò fi ohùn mi pe Jèhófà, òun yóò sì dá mi lóhùn láti orí òkè ńlá mímọ́ rẹ̀.” Táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó dùn wá, ó yẹ káwa náà gbàdúrà sí Jèhófà bíi ti Dáfídì. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, èyí á sì jẹ́ ká lè fara dà á. Ǹjẹ́ o lè ronú àwọn nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé kó o kó ara rẹ níjàánu tàbí kó o tiẹ̀ dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́? Ṣé ó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́?
‘ỌGBỌ́N NI OHUN TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ LỌ’
18. Tá a bá ń fi àwọn ìtọ́ni Jèhófà sílò, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wá?
18 Tá a bá ń ṣe àwọn ohun tá a mọ̀ pé ó tọ̀nà, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa lọ́pọ̀ yanturu. Abájọ tí Òwe 4:7 fi sọ pé: “Ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ”! Òótọ́ ni pé ìmọ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn gbọ́n, àmọ́ ó dìgbà téèyàn bá ṣe ìpinnu tó tọ́ ká tó lè pe irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní ọlọ́gbọ́n. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèrà máa ń ṣe ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n gbọ́n. Ìdí ni pé wọ́n máa ń fọgbọ́n kó oúnjẹ jọ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de àsìkò òjò. (Òwe 30:24, 25) Gbogbo ìgbà ni Kristi tí Bíbélì pè ní “ọgbọ́n Ọlọ́run” máa ń ṣe ohun tó tẹ́ Baba rẹ̀ lọ́rùn. (1 Kọ́r. 1:24; Jòh. 8:29) Ká fi sọ́kàn pé ká kàn mọ ohun tó tọ́ nìkan ò tó, Ọlọ́run tún fẹ́ ká máa ṣe ohun tó tọ́. Ó sì dájú pé ó máa bù kún àwọn tó bá ń ṣe ohun tó tọ́, tí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì ń fara dà á. (Ka Mátíù 7:21-23.) Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí ara lè tu àwọn tó wà nínú ìjọ, kí wọ́n sì lè máa fìrẹ̀lẹ̀ sin Jèhófà nìṣó. Ká sòótọ́, ó máa ń gba àkókò àti sùúrù ká tó lè ṣe àwọn ohun tá a mọ̀ pé ó tọ̀nà, àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Tá a bá sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a máa láyọ̀ lónìí, títí láé layọ̀ wa á sì máa pọ̀ sí i.