Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Níwọ̀n bí gbogbo àwọn ọkùnrin lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì á ti wà níbi Àjọyọ̀ Àwọn Àkàrà Aláìwú kí ìkórè ọkà bálì tó lè bẹ̀rẹ̀, ta ló máa ń lọ kórè àkọ́so ọkà bálì tí wọ́n máa ń gbé wá sínú ibùjọsìn lọ́jọ́ àjọyọ̀ náà?
Òfin Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún, kí gbogbo tìrẹ tí ó jẹ́ ọkùnrin fara hàn níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí òun yóò yàn: ní àjọyọ̀ àwọn àkàrà aláìwú àti ní àjọyọ̀ àwọn ọ̀sẹ̀ àti ní àjọyọ̀ àwọn àtíbàbà.” (Diutarónómì 16:16) Látìgbà ayé Sólómọ́nì Ọba, tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni ibi tí Ọlọ́run yàn pé kí wọ́n ti máa fara hàn níwájú òun.
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé ni wọ́n máa ń ṣe èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ lára àwọn àjọyọ̀ náà. Àjọyọ̀ Àwọn Àkàrà Aláìwú ni wọ́n ń pè é. Nísàn 15, ìyẹn ọjọ́ tó tẹ̀ lé àjọyọ̀ Ìrékọjá tí wọ́n máa ń ṣe ní Nísàn14, ló máa ń bẹ̀rẹ̀, ó sì máa ń parí ní ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, ìyẹn Nísàn 21. Ọjọ́ kejì tí Àjọyọ̀ Àwọn Àkàrà Aláìwú yìí bẹ̀rẹ̀, ìyẹn Nísàn 16, ni ìkórè àkọ́kọ́ nínú ọdún máa ń bẹ̀rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú kàlẹ́ńdà tí Ọlọ́run fún wọn. Lọ́jọ́ náà, àlùfáà àgbà á mú “ìtí àkọ́so” ọkà bálì tí wọ́n kórè, yóò sì fì í “síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà” nínú ibùjọsìn. (Léfítíkù 23:5-12) Àmọ́, nígbà tó jẹ́ pé gbogbo ọkùnrin ni Òfin Mósè sọ pé kó pésẹ̀ síbi Àjọyọ̀ Àwọn Àkàrà Aláìwú, ta ló lọ kórè àkọ́so ọkà bálì tí wọ́n fì níwájú Jèhófà yìí?
Orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ ni Jèhófà pàṣẹ fún pé kó mú àkọ́so ọkà bálì wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ nígbà Àjọyọ̀ Àwọn Àkàrà Aláìwú. Òfin náà ò sọ pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkórè kó sì fúnra rẹ̀ mú àkọ́so náà wá sínú ibùjọsìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn aṣojú tí wọ́n yàn ló máa ń lọ kórè àkọ́so ọkà bálì tí wọ́n máa mú wá sínú ibùjọsìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ. Nítorí náà, wọ́n lè rán àwọn aṣojú lọ gé ìtí ọkà bálì tí wọ́n máa lò níbi Àjọyọ̀ Àwọn Àkàrà Aláìwú náà ní oko ọkà bálì tó bá wà nítòsí. Lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé: “Tí wọ́n bá rí oko ọkà bálì tó ti tó kórè lágbègbè Jerúsálẹ́mù wọ́n á lọ síbẹ̀ lọ gé èyí tí wọ́n máa lò níbi àjọyọ̀ náà, bí kò bá wá sí, wọ́n lè lọ gé e wá láti ibikíbi ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ọkùnrin mẹ́ta ló máa ń lọ gé e wá, kálukú tòun ti dòjé àti apẹ̀rẹ̀ rẹ̀.” Wọ́n á wá gbé ìtí ọkà bálì wá fún àlùfáà àgbà yóò sì fi fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ.
Bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n fi àkọ́so ìkórè wọn rúbọ, àǹfààní ńlá nìyẹn jẹ́ fún wọn láti fẹ̀mí ìmoore hàn sí Ọlọ́run fún bó ṣe bù kún ilẹ̀ wọn àti irè oko wọn. (Diutarónómì 8:6-10) Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jùyẹn lọ ni pé, àjọyọ̀ yìí jẹ́ “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀.” (Hébérù 10:1) Lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú, Nísàn 16 tó jẹ́ ọjọ́ tí wọ́n máa ń fi àkọ́so ìkórè fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ni Jésù Kristi jíǹde lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù, ó kọ̀wé pé: “A ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú, àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú. . . . Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 15:20-23) Ìtí àkọ́so tí àlùfáà àgbà máa ń fì síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi lẹ́yìn tí Ọlọ́run jí i dìde, òun sì lẹni tó kọ́kọ́ jíǹde sí ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù wá tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìdáǹdè aráyé kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ṣeé ṣe.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
© 2003 BiblePlaces.com