Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JANUARY 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 20-21
“Jèhófà Fẹ́ Káwọn Èèyàn Rẹ̀ Yàtọ̀”
it-1 1199
Ogún
Ohun tí ẹnì kan bá fún ọmọ rẹ̀ kó tó kú tàbí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ipò rẹ̀; ohunkóhun tí ọmọ tàbí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ipò bá gbà lẹ́yìn tí oní-nǹkan kú. Ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tí wọ́n ń lò fún ogún ni na·chalʹ (ọ̀rọ̀ orúkọ tí wọ́n ń lò fún un ni na·chalahʹ). Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti ṣàpèjúwe ohun tẹ́nì kan gbà tàbí tí wọ́n bá fún ẹnì kan, wọ́n sì sábà máa ń fi nǹkan náà léni lọ́wọ́ láti ìran dé ìran tẹ́ni náà bá lẹ́tọ̀ọ́ sí i. (Nọ 26:55; Isk 46:18) Nígbà míì, wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà ya·rashʹ láti sọ fún ẹnì kan pé ó máa “jogún ohun” tẹ́nì kan ní, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti sọ fẹ́nì kan pé ohun ìní ẹlòmíì ‘màá di’ tiẹ̀ láìjẹ́ pé ó lẹ́tọ̀ọ́ sí i. (Jẹ 15:3; Le 20:24) Ó tún lè túmọ̀ sí “lé kúrò,” ìyẹn nígbà táwọn ọmọ ogun bá lé àwọn èèyàn kan kúrò lórí ilẹ̀ wọn. (Di 2:12; 31:3) Ogún ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà kleʹros túmọ̀ sí. Àmọ́ níbẹ̀rẹ̀, “kèké” ni wọ́n máa ń lò ó fún, lẹ́yìn náà wọ́n tún lò ó fún “ìpín.” Ìgbà tó yá ni wọ́n lò ó fún “ogún.”—Mt 27:35; Iṣe 1:17; 26:18.
it-1 317 ¶2
Ẹyẹ
Lẹ́yìn Ìkún Omi, Nóà fi àwọn “ẹ̀dá tó ń fò tó sì mọ́” àti àwọn ẹranko rúbọ sí Jèhófà. (Jẹ 8:18-20) Àtìgbà yẹn ni Jèhófà ti ní káwọn èèyàn máa jẹ ẹyẹ, tí wọn ò bá ṣáà ti jẹ ẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀. (Jẹ 9:1-4; fi wé Le 7:26; 17:13.) Torí náà, ohun tó máa pinnu bóyá ẹyẹ kan “mọ́” ni tó bá wà lára àwọn ẹyẹ tí Jèhófà gbà pé kí wọ́n fi rúbọ; Bíbélì fi hàn pé gbogbo ẹyẹ làwọn èèyàn lè jẹ tẹ́lẹ̀, àmọ́ Òfin Mósè ló jẹ́ kí wọ́n ka àwọn ẹyẹ kan sí “èyí tí kò mọ́.” (Le 11:13-19, 46, 47; 20:25; Di 14:11-20) Bíbélì ò sọ àwọn ohun pàtó kan tá a máa fi mọ̀ bóyá ẹyẹ kan mọ́ tàbí “kò mọ́.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ẹyẹ ló ń ṣọdẹ, tó sì ń jẹ òkú, ọ̀pọ̀ lára irú àwọn ẹyẹ yìí ni Bíbélì kà sí aláìmọ́. (Wo ÀGBÌGBÒ.) Òfin yìí kásẹ̀ nílẹ̀ lẹ́yìn tí májẹ̀mú tuntun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, Ọlọ́run sì fi ẹ̀rí èyí hàn nínú ìran tó fi han Pétérù.—Iṣe 10:9-15.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 563
Kéèyàn Kọ Ara Rẹ̀ Lábẹ
Òfin Ọlọ́run dìídì sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ kọ ara wọn lábẹ torí ẹni tó kú. (Le 19:28; 21:5; Di 14:1) Ìdí tí Jèhófà fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé èèyàn mímọ́ àti ohun ìní pàtàkì ni wọ́n jẹ́ fún un. (Di 14:2) Tí wọ́n bá pa Òfin yìí mọ́, wọn ò ní lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà èyíkéyìí. Yàtọ̀ síyẹn, kò bójú mu rárá kí àwọn tó mọ òótọ́ nípa ipò táwọn òkú wà àti ìrètí àjíǹde tún máa bara jẹ́ tóyẹn nígbà tẹ́nì kan bá kú débi tí wọ́n á fi máa kọ ara wọn lábẹ. (Da 12:13; Heb 11:19) Bákan náà, Òfin tí Jèhófà ṣe yìí máa jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì túbọ̀ mọyì ara tí Ẹlẹ́dàá fún wa, kí wọ́n sì ṣìkẹ́ rẹ̀.
JANUARY 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 22-23
“Ohun Tí Àjọyọ̀ Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Kọ́ Wa”
it-1 826-827
Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú
Àpéjọ ọlọ́wọ̀ ni ọjọ́ àkọ́kọ́ Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú, ọjọ́ sábáàtì ló sì máa ń bọ́ sí. Ní ọjọ́ kejì, ìyẹn Nísàn 16, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń mú ìtì àkọ́so ọkà báálì, tó jẹ́ irúgbìn tí wọ́n máa ń kọ́kọ́ kórè nílẹ̀ Palẹ́sìnì, wá fún àlùfáà. Ṣáájú àjọyọ̀ yìí, wọn ò ní lè jẹ ọkà tuntun èyíkéyìí, wọn ò sì ní lè fi ṣe búrẹ́dì tàbí kí wọ́n yan án. Àlùfáà máa fi ọkà náà rúbọ sí Jèhófà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó máa fì í síwá sẹ́yìn níwájú rẹ̀. Á sì fi ọmọ àgbò ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá rú ẹbọ sísun, pẹ̀lú ọrẹ ọkà tí wọ́n pò mọ́ òróró àti ọrẹ ohun mímu. (Le 23:6-14) Nígbà tó yá, àwọn àlùfáà bẹ̀rẹ̀ sí í sun ọkà tàbí ìyẹ̀fun rẹ̀ lórí pẹpẹ, àmọ́ kò sí òfin kankan tó ní kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe àwọn èèyàn náà lápapọ̀ nìkan ni Jèhófà retí pé kó fi àkọ́so wọn rúbọ sí òun, kódà àwọn ìdílé tàbí ẹnì kọ̀ọ̀kan tó bá ní nǹkan ọ̀gbìn láǹfààní láti rú ẹbọ yìí, kí wọ́n lè fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lásìkò àjọyọ̀ yìí.—Ẹk 23:19; Di 26:1, 2; wo ÀKỌ́SO.
Ohun Tó Ṣàpẹẹrẹ. Bí wọ́n ṣe ń jẹ búrẹ́dì aláìwú nígbà àjọyọ̀ yìí fi hàn pé wọ́n ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jèhófà fún Mósè nínú Ẹ́kísódù 12:14-20. Ní ẹsẹ 19, Jèhófà pàṣẹ fún wọn pé: “Kò gbọ́dọ̀ sí àpòrọ́ kíkan nínú ilé yín rárá fún ọjọ́ méje.” Ní Diutarónómì 16:3, Bíbélì tún pe búrẹ́dì aláìwú ní “oúnjẹ ìpọ́njú” torí pé ọdọọdún tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀ yìí ló máa ń rán wọn létí bí wọ́n ṣe kánjú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì (ìyẹn nígbà tí wọn ò lè dúró fi ìwúkàrà sí ìyẹ̀fun wọn [Ẹk 12:34]). Torí náà, àjọyọ̀ yẹn máa ń rán wọn létí bí àwọn ará Íjíbítì ṣe fìyà jẹ wọ́n àti bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n sílẹ̀, ìyẹn sì bá ohun tí Jèhófà sọ mu pé, “kí o lè máa rántí ọjọ́ tí o kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì” ní gbogbo ìgbà tí o bá fi wà láàyè. Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dùn pé wọ́n wà lómìnira, wọ́n sì mọyì bí Jèhófà ṣe dá wọn nídè. Torí náà, ó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú tó jẹ́ àkọ́kọ́ lára àjọyọ̀ pàtàkì mẹ́ta tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún.—Di 16:16.
it-2 598 ¶2
Pẹ́ńtíkọ́sì
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi àkọ́so wíìtì rúbọ sí Jèhófà lọ́jọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì. Àmọ́ ohun tí wọ́n máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá kórè àkọ́so wíìtì yàtọ̀ sí ti àkọ́so ọkà bálì. Wọ́n máa po ìwúkàrà mọ́ ìyẹ̀fun wíìtì tó kúnná tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà, (ìyẹn Lítà 4.4) wọ́n á sì fi ṣe búrẹ́dì méjì. Jèhófà ní kí wọ́n mú un wá ‘láti ibi tí wọ́n ń gbé,’ ìyẹn ni pé wọ́n máa ṣe búrẹ́dì náà bí wọ́n ṣe máa ń ṣe èyí tí wọ́n ń jẹ nínú ilé wọn, kì í ṣe pé wọ́n máa ṣe é lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fún ohun mímọ́. (Le 23:17) Àsìkò yìí kan náà ni wọ́n máa ń rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì máa ń mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì wá láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀. Àlùfáà máa fi búrẹ́dì àti ọ̀dọ́ àgùntàn náà níwájú Jèhófà, ó máa gbé búrẹ́dì àti ẹran náà dání, á sì fì wọ́n síwá sẹ́yìn láti fi hàn pé òun mú wọn wá síwájú Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ẹran àti búrẹ́dì yẹn máa di ti àlùfáà, á sì jẹ ẹ́ bó ṣe máa ń jẹ ẹbọ ìrẹ́pọ̀.—Le 23:18-20.
JANUARY 25-31
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 24-25
“Ọdún Júbílì Ṣàpẹẹrẹ Òmìnira Ọjọ́ Iwájú”
it-1 871
Òmìnira
Ọlọ́run Tó Ń Fúnni Lómìnira. Ọlọ́run tó ń gbani sílẹ̀ ni Jèhófà. Ó gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko ẹrú ní Íjíbítì. Ó sì sọ fún wọn pé tí wọ́n bá ń ṣègbọràn sí òun délẹ̀délẹ̀ òun máa pèsè gbogbo ohun tí wọ́n nílò. (Di 15:4, 5) Dáfídì sọ pé odi Jerúsálẹ́mù máa “wà láìséwu.” (Sm 122:6, 7) Nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì níbẹ̀rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà “wà láìséwu” tún lè túmọ̀ sí “òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn.” Síbẹ̀, Òfin Ọlọ́run sọ pé ẹnì kan tó jẹ́ òtòṣì lè sọ ara rẹ̀ di ẹrú kó lè pèsè ohun tí òun àti ìdílé rẹ̀ nílò. Àmọ́, Òfin yẹn tún sọ pé kí wọ́n dá ẹni náà sílẹ̀ lóko ẹrú lẹ́yìn ọdún keje. (Ẹk 21:2) Ní ọdún Júbílì (tó máa ń wáyé lẹ́yìn àádọ́ta [50] ọdún), àwọn tó ń gbé Ísírẹ́lì máa ń kúrò lóko ẹrú. Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹrú máa gbòmìnira, wọ́n sì máa pa dà gba àwọn ohun ìní wọn.—Le 25:10-19.
it-1 1200 ¶2
Ogún
Ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ wà láti ìran dé ìran, torí náà wọn kì í tà á. Ṣe ni wọ́n máa ń yá ara wọn nílẹ̀, bí ilẹ̀ náà bá ṣe dáa sí ni wọ́n fi máa ń ṣírò iye tí wọ́n máa dá lé e. Ohun míì tí wọ́n fi ń pinnu iye tí wọ́n máa dá lé ilẹ̀ ni iye ọdún tó kù kí Júbílì pé, torí ilẹ̀ náà máa pa dà di ti ẹni tó ni í tí wọn ò bá tiẹ̀ rà á pa dà ṣáájú ìgbà yẹn. (Le 25:13, 15, 23, 24) Òfin yìí tún kan àwọn ilé gbígbé tí kò ní ògiri tó yí i ká, ìdí ni pé wọ́n ka irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ sí ara ilẹ̀ tó wà ní ìgbèríko. Tó bá jẹ́ ilé tó wà nínú ìlú olódi ni, ẹni tó tà á lẹ́tọ̀ọ́ láti tún un rà láàárín ọdún kan gbáko, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ilé náà máa di tẹni tó rà á títí láé. Àmọ́, ní ti ilé àwọn ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú wọn, wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti ra ilé náà pa dà nígbàkigbà torí pé wọn ò pín ilẹ̀ míì fún wọn.—Le 25:29-34.
it-2 122-123
Júbílì
Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n ṣe lọ́dún Júbílì, ọ̀rọ̀ wọn máa yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lónìí, níbi tó ti jẹ́ pé àwọn èèyàn kan lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ táwọn míì sì tòṣì paraku. Gbogbo èèyàn ni òfin náà máa ń ṣe láǹfààní, kò sí pé ẹnì kan tòṣì débi tí ò fi ní níṣẹ́ lọ́wọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni gbogbo àwọn ará ìlú á máa lo ohun tí kálukú wọn mọ̀ ọ́n ṣe láti mú kí nǹkan máa lọ dáadáa nílùú. Bí Jèhófà bá ṣe ń bù kún ohun tí wọ́n gbìn, tí wọ́n sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, nǹkan á ṣẹnuure fún wọn, wọ́n sì máa gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún míì tó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà nìkan nirú ẹ̀ ti lè wá.—Ais 33:22.
FEBRUARY 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 26-27
“Bá A Ṣe Lè Rí Ìbùkún Jèhófà”
it-1 223 ¶3
Ọ̀wọ̀ Tó Jinlẹ̀
Jèhófà mú kí Mósè ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó lágbára, Jèhófà sì fi ọwọ́ agbára rẹ̀ hàn nípasẹ̀ Mósè. Torí náà, Mósè jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i pé ó yẹ kí wọ́n máa bẹ̀rù Jèhófà, kí wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ (moh·raʼʹ lédè Hébérù) fún un. (Di 34:10, 12; Ẹk 19:9) Àwọn tó nígbàgbọ́ tó lágbára lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe gbogbo ohun tí Mósè sọ. Torí wọ́n mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà lohun tó ń sọ ti wá. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ Jèhófà. (Le 19:30; 26:2) Ìyẹn ni pé, kí wọ́n máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́, kí wọ́n sì máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-2 617
Àjàkálẹ̀ Àrùn
Àrùn Tó Kọ Lu Àwọn Èèyàn Torí Pé Wọn Ò Tẹ̀ Lé Òfin Ọlọ́run. Jèhófà kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọn ò bá pa májẹ̀mú òun mọ́, òun máa ‘rán àrùn sí àárín wọn.’ (Le 26:14-16, 23-25; Di 28:15, 21, 22) Nínú Bíbélì, àwọn tó rí ojú rere Jèhófà máa ń ní ìlera tó dáa nípa tara àti nípa tẹ̀mí (Di 7:12, 15; Sm 103:1-3; Owe 3:1, 2, 7, 8; 4:21, 22; Ifi 21:1-4), àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ló máa ń fa àìsàn tàbí àrùn. (Ẹk 15:26; Di 28:58-61; Ais 53:4, 5; Mt 9:2-6, 12; Jo 5:14) Lóòótọ́, àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ fi àrùn kọ lu èèyàn ní tààràtà, irú bí ìgbà tó fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọ lu Míríámù, Ùsáyà àti Géhásì (Nọ 12:10; 2Kr 26:16-21; 2Ọb 5:25-27), síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún tàbí ìyà ẹ̀ṣẹ̀ táwọn kan dá ni wọ́n jẹ tàbí kó jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tí orílẹ̀-èdè kan dá ló mú kí wọ́n ṣàìsàn tàbí kí àrùn kọ lù wọ́n. Ohun tí wọ́n gbìn ni wọ́n ká; ó máa hàn sí gbogbo èèyàn pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni wọ́n ń jẹ. (Ga 6:7, 8) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń lọ́wọ́ sí ìbálòpọ̀ tí kò níjàánu, ó sọ pé “Ọlọ́run fi wọ́n sílẹ̀ fún ìwà àìmọ́, kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, kí wọ́n sì tàbùkù sí ẹran ara wọn . . . wọ́n sì ń jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìyà tó yẹ ìṣìnà wọn.”—Ro 1:24-27.
FEBRUARY 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 1-2
“Jèhófà Fẹ́ Káwọn Èèyàn Rẹ̀ Wà Létòlétò”
Ipò Tó Yẹ Kó O Fi Ìjọsìn Jèhófà Sí Láyé Rẹ
Ká sọ pé o wo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì látòkèèrè níbi tí wọ́n pàgọ́ sí nínú aginjù, kí lo máa rí? Wàá rí àwọn àgọ́ tó wà létòlétò, tó ṣeé ṣe káwọn tó ń gbébẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n pín wọn ní ẹ̀yà mẹ́ta-mẹ́ta sí àríwá, gúúsù, ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn. Yàtọ̀ síyẹn, wàá rí àwọn àgọ́ mẹ́rin kéékèèké tó sún mọ́ àárín ibùdó. Àwọn ẹ̀yà Léfì ló ń gbébẹ̀. Wàá tún rí àgọ́ mí ì tó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn àgọ́ tó kù, àgọ́ yìí ló wà láàárín, wọ́n sì fi aṣọ ṣe ògiri yí i ká. “Àwọn tó mọṣẹ́” dáadáa lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló kọ́ ọ, ohun tí Jèhófà sì ní kí wọ́n ṣe ni wọ́n ṣe gẹ́lẹ́. “Àgọ́ ìpàdé” tàbí àgọ́ ìjọsìn ni wọ́n ń pè é.—Nọ́ńbà 1:52, 53; 2:3, 10, 17, 18, 25; Ẹ́kísódù 35:10.
it-1 397 ¶4
Àgọ́
Ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ sí fẹ̀ gan-an. Gbogbo àwọn tó forúkọ sílẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550) ọkùnrin ogun, yàtọ̀ sáwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé, àwọn àgbàlagbà, àwọn aláàbọ̀ ara, àtàwọn ọmọ Léfì tó tó ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) àti “oríṣiríṣi èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ” tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, lápapọ̀ ó ṣeé ṣe kí gbogbo wọn tó mílíọ̀nù mẹ́ta (3,000,000) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Ẹk 12:38, 44; Nọ 3:21-34, 39) A ò mọ bí ibi tí wọ́n pàgọ́ sí ṣe fẹ̀ tó, torí ẹnu àwọn èèyàn ò kò lórí ẹ̀. Nígbà tí wọ́n pàgọ́ sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jẹ́ríkò, Bíbélì sọ pé ibi tí wọ́n pàgọ́ sí fẹ̀ “láti Bẹti-jẹ́ṣímótì títí lọ dé Ebẹli-ṣítímù.”—Nọ 33:49.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-2 764
Ìforúkọsílẹ̀
Ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ti ìdílé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀yà tàbí agbo ilé. Èyí kọjá kí wọ́n ṣe ètò ìkànìyàn láti mọ iye àwọn èèyàn. Àwọn ìforúkọsílẹ̀ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn tún máa ń wúlò fún àwọn nǹkan míì, bí àpẹẹrẹ ó máa jẹ́ kí wọ́n ṣètò báwọn èèyàn ṣe máa san owó orí, bí wọ́n ṣe máa yan àwọn tó fẹ́ wọṣẹ́ ológun tàbí (nínú ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Léfì) bí wọ́n ṣe máa yan àwọn tó máa sìn nínú ibi mímọ́.
FEBRUARY 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 3-4
“Iṣẹ́ Ìsìn Àwọn Ọmọ Léfì”
it-2 683 ¶3
Àlùfáà
Ohun Tí Májẹ̀mú Òfin Sọ. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lóko ẹrú ní Íjíbítì, Jèhófà ní kí wọ́n ya ọmọkùnrin wọn tó jẹ́ àkọ́bí sọ́tọ̀ fún òun nígbà tó fi ìyọnu kẹwàá pa àkọ́bí àwọn ará Íjíbítì. (Ẹk 12:29; Nọ 3:13) Ti Jèhófà làwọn àkọ́bí yìí, torí náà ó fẹ́ kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ sin òun lọ́nà àkànṣe. Ìyẹn ni pé, Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa sìn nípò àlùfáà, kí wọ́n sì máa bójú tó ibi mímọ́. Àmọ́, Jèhófà rí i pé àwọn ọkùnrin tó wà nínú ẹ̀yà Léfì ló máa tóótun fún iṣẹ́ yìí. Torí náà, Jèhófà gbà káwọn ọmọ Ísírẹ́lì yan àwọn ọkùnrin tó wà nínú ẹ̀yà Léfì dípò àwọn àkọ́bí ọmọkùnrin ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì (ẹ̀yà méjì ni wọ́n pín àwọn ọmọ Jósẹ́fù sí, ìyẹn Éfúrémù àti Mánásè). Nígbà kan tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àkọ́bí ọmọkùnrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi igba ó lé mẹ́tàléláàádọ́rin (273) pọ̀ ju àwọn ọkùnrin tó wà nínú ẹ̀yà Léfì lọ, torí náà Ọlọ́run ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì san ṣékélì márùn-ún (ìyẹn dọ́là mọ́kànlá [$11]) láti fi ṣe owó ìràpadà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan igba ó lé mẹ́tàléláàádọ́rin (273) tí wọ́n fi pọ̀ ju àwọn ọmọ Léfì lọ. Ọlọ́run ní kí wọ́n kó owó náà fún Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀. (Nọ 3:11-16, 40-51) Ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà ti yan àwọn ọkùnrin tó wà nínú ìdílé Áárónì látinú ẹ̀yà Léfì pé kí wọ́n máa wà nípò àlùfáà ní Ísírẹ́lì.—Nọ 1:1; 3:6-10.
it-2 241
Àwọn Ọmọ Léfì
Iṣẹ́ Wọn. Ìdílé mẹ́ta ló wà nínú ẹ̀yà Léfì, àwọn sì ni Gẹ́ṣónì (Gẹ́ṣómù), Kóhátì àti Mérárì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì. (Jẹ 46:11; 1Kr 6:1, 16) Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdílé yìí ló pàgọ́ sítòsí àgọ́ ìjọsìn nínú aginjù. Áárónì tó wá látinú ẹ̀yà Kóhátì pàgọ́ síwájú àgọ́ ìjọsìn lápá ìlà oòrùn. Apá gúúsù ni ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì tó kù pàgọ́ sí, ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì pàgọ́ sí ìwọ̀ oòrùn, nígbà tí ìdílé àwọn ọmọ Mérárì pàgọ́ sí àríwá. (Nọ 3:23, 29, 35, 38) Àwọn ọmọ Léfì ló máa ń to àgọ́ ìjọsìn, tí wọ́n á tú u palẹ̀, tí wọ́n á sì gbé e láti ibì kan sí ibòmíì. Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fẹ́ ṣí àgọ́ ìjọsìn kúrò níbi tó wà, Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ máa tú aṣọ ìdábùú tó pààlà sáàárín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ, wọ́n á sì bo àpótí Ẹ̀rí, pẹpẹ àtàwọn ohun èlò míì tí wọ́n ń lò nínú àgọ́ ìjọsìn. Àwọn ọmọ Kóhátì á wá gbé àwọn nǹkan èlò yìí. Ní ti àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì iṣẹ́ wọn ni láti gbé aṣọ àgọ́, àwọn ìbòrí, àwọn aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí àgbàlá àtàwọn okùn àgọ́ (ìyẹn okùn tí wọ́n fi ń pàgọ́). Àwọn ọmọ Mérárì ní tiwọn máa ń bójú tó àwọn férémù, àwọn òpó, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò, àwọn èèkàn àgọ́ àtàwọn okùn àgọ́ náà (ìyẹn àwọn okùn tí wọ́n máa ń lò ní àgbàlá tó yí àgọ́ ìjọsìn ká).—Nọ 1:50, 51; 3:25, 26, 30, 31, 36, 37; 4:4-33; 7:5-9.
it-2 241
Àwọn Ọmọ Léfì
Nígbà ayé Mósè, ọmọ Léfì kan gbọ́dọ̀ pé ẹni ọgbọ̀n ọdún (30) kí wọ́n tó lè yan iṣẹ́ fún un, ìyẹn láti gbé àwọn ohun èlò àgọ́ ìjọsìn nígbà tí wọ́n bá ń ṣí láti ibì kan lọ sí ibòmíì. (Nọ 4:46-49) Nígbà míì, ẹni tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) lè ṣe iṣẹ́ kan nínú àgọ́ ìjọsìn, àmọ́ kò ní jẹ́ àwọn iṣẹ́ tó gba agbára bí èyí tí wọ́n máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń gbé àwọn ohun èlò àgọ́ ìjọsìn. (Nọ 8:24) Nígbà tó yá, Ọba Dáfídì gbà kí àwọn ọmọ Léfì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lẹ́ni ogún (20) ọdún. Ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé wọn ò nílò láti máa gbé àgọ́ ìjọsìn kiri mọ́ (torí wọ́n máa tó fi tẹ́ńpìlì rọ́pò rẹ̀). Àwọn ọmọ Léfì máa ń fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n bá ti pé ẹni àádọ́ta (50) ọdún. (Nọ 8:25, 26; 1Kr 23:24-26; wo ỌJỌ́ ORÍ.) Àwọn ọmọ Léfì tún gbọ́dọ̀ mọ Òfin Ọlọ́run dáadáa, torí lọ́pọ̀ ìgbà àwọn ni wọ́n máa ń pè láti wá ka Òfin náà fún àwọn èèyàn ní gbangba, kí wọ́n sì kọ́ wọn.—1Kr 15:27; 2Kr 5:12; 17:7-9; Ne 8:7-9.
FEBRUARY 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 5-6
“Báwo Lo Ṣe Lè Fìwà Jọ Àwọn Násírì?”
it-2 477
Násírì
Àwọn nǹkan kan wà táwọn tó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di Násírì ò gbọ́dọ̀ ṣe, àmọ́ ohun mẹ́ta yìí ló ṣe pàtàkì jù: (1) Wọn ò gbọ́dọ̀ mu ohunkóhun tó ní ọtí nínú; bákan náà, wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tí wọ́n fi àjàrà ṣe, yálà ó ti pọ́n tàbí kò pọ́n, èyí tó ti gbẹ tàbí omi àjàrà tí wọ́n fún jáde, bóyá èyí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fún tàbí èyí tó ti kan. (2) Wọn ò gbọ́dọ̀ gé irun orí wọn. (3) Wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan òkú èèyàn èyíkéyìí, kódà kó jẹ́ ti mọ̀lẹ́bí wọn, bàbá, ìyá, arákùnrin tàbí arábìnrin wọn.—Nọ 6:1-7.
Ẹ̀jẹ́ Pàtàkì. Ẹni tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì yìí máa “di Násírì [tó túmọ̀ sí yà sí mímọ́ tàbí yà sọ́tọ̀] fún Jèhófà.” Ẹni náà ò ní jẹ́jẹ̀ẹ́ yìí torí káwọn èèyàn lè máa kan sárá sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láì kọ́kọ́ ronú nípa ohun tó máa ná an. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní láti “jẹ́ mímọ́ sí Jèhófà” ní “gbogbo ọjọ́ tó bá fi jẹ́ Násírì.”—Nọ 6:2, 8 àlàyé ìsàlẹ̀.
Òfin tó wà fún ẹni tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti di Násírì ṣe pàtàkì gan-an nínú ìjọsìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, torí iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí àlùfáà àgbà ń ṣe, Jèhófà sọ pé kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan òkú èèyàn, kódà tí ẹni náà bá jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀, ohun tí Jèhófà sọ fáwọn Násírì náà nìyẹn. Bákan náà, torí iṣẹ́ pàtàkì tí àlùfáà àgbà àtàwọn àlùfáà tó kù ń ṣe, Jèhófà sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ohun mímu míì tó ní ọtí nígbàkigbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ níwájú Jèhófà.—Le 10:8-11; 21:10, 11.
Yàtọ̀ síyẹn, ẹni tó bá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di Násírì (na·zirʹ lédè Hébérù) gbọ́dọ̀ “jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn títí . . . kó lè máa jẹ́ mímọ́,” irun yẹn máa jẹ́ káwọn èèyàn tètè mọ̀ pé ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà láti di Násírì. (Nọ 6:5) Ọ̀rọ̀ Hébérù yìí, ìyẹn na·zirʹ ni wọ́n máa ń lò fún àjàrà tí wọn “ò tíì rẹ́wọ́” ẹ̀ nígbà Sábáàtì mímọ́ àti lọ́dún Júbílì. (Le 25:5, 11) Ohun míì ni pé, orúkọ tí wọ́n máa ń pe irin pẹlẹbẹ tí wọ́n fi wúrà ṣe tí wọ́n kọ “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà” sára rẹ̀ ni “àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́ [ìyẹn neʹzer lédè Hébérù, tó wá látinú ọ̀rọ̀ kan náà pẹ̀lú na·zirʹ].” Irin yìí ló wà lára láwàní tí àlùfáà àgbà máa ń wé. (Ẹk 39:30, 31) Wọ́n tún ń pe adé táwọn ọba Ísírẹ́lì máa ń dé ní neʹzer, torí pé Jèhófà ló yan àwọn ọba yẹn. (2Sa 1:10; 2Ọb 11:12; wo ADÉ; ÌYÀSÍMÍMỌ́.) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni pé, Ọlọ́run fún àwọn obìnrin ní irun gígùn dípò ìbòrí. Èyí á jẹ́ káwọn obìnrin máa rántí pé wọ́n yàtọ̀ sáwọn ọkùnrin, wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ipò orí tí Ọlọ́run ṣètò. Torí náà, báwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ láti di Násírì ṣe máa ń dá irun wọn sí (bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò bójú mu káwọn ọkùnrin máa ṣe bẹ́ẹ̀), tí wọn kì í mu ọtí rárá, tí wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa wà ní mímọ́ nígbà gbogbo, wọ́n á máa rántí bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti máa fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn, kí wọ́n sì múra tán láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà.—1Kọ 11:2-16; wo IRUN; ÌBÒRÍ; BÍ ỌLỌ́RUN ṢE DÁ WA.