Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Númérì
LẸ́YÌN táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, Ọlọ́run ṣètò wọn, ó sì sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè. Gbàrà tí wọ́n kúrò ni wọn ì bá ti wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àmọ́ kò ṣeé ṣe fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń rìn kiri fún nǹkan bí ogójì ọdún nínú “aginjù ńlá” kan tó tún jẹ́ “amúnikún-fún-ẹ̀rù.” (Diutarónómì 8:15) Kí nìdí? Ìtàn inú ìwé Númérì nínú Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa. Ìtàn yìí yóò tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run ká sì bọ̀wọ̀ fún àwọn aṣojú rẹ̀.
Mósè ló kọ ìwé Númérì nínú aginjù, ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, ó sì gbà á ní ọdún méjìdínlógójì àti oṣù mẹ́sàn-án, ìyẹn láti ọdún 1512 sí ọdún 1473 ṣáájú Sànmánì Tiwa. (Númérì 1:1; Diutarónómì 1:3) Orúkọ ìwé yìí dá lórí ètò ìkànìyàn méjì tó wáyé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tí wọ́n ṣe ní nǹkan bí ọdún méjìdínlógójì síra wọn. (Orí 1 sí 4, 26) Apá mẹ́ta ni ìtàn náà pín sí. Apá àkọ́kọ́ sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lórí Òkè Sínáì. Apá kejì jẹ́ ká mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń rìn kiri nínú aginjù. Nígbà tí apá tó kẹ́yìn dá lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù. Bó o ti ń ka ìtàn yìí, o lè máa bi ara rẹ pé: ‘Ẹ̀kọ́ wo làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí kọ́ mi? Ǹjẹ́ àwọn ìlànà kan wà nínú ìwé yìí tó lè ṣe mi láǹfààní lọ́jọ́ òní?’
LÓRÍ ÒKÈ SÍNÁÌ
Àkọ́kọ́ nínú ètò ìkànìyàn méjì náà wáyé nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì wà lẹ́bàá Òkè Sínáì. Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ogún ọdún sókè, láìka àwọn ọmọ Léfì, jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélẹ́gbẹ̀ta àti àádọ́ta dín lẹ́gbẹ̀ta [603,550]. Ó dájú pé nítorí àtilọ sógun ní ètò ìkànìyàn náà ṣe wáyé. Ó ṣeé ṣe kí gbogbo àwùjọ náà, títí kan àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn.
Lẹ́yìn ètò ìkànìyàn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ìtọ́ni nípa bí wọ́n á ṣe máa ṣí lọ, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ojúṣe àwọn ọmọ Léfì àti iṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ ìjọsìn, òfin lórí ìsémọ́ nítorí àrùn, òfin lórí ọ̀ràn owú jíjẹ, àtàwọn ẹ̀jẹ́ táwọn Násírì máa ń jẹ́. Orí Keje sọ nípa ọrẹ táwọn ìjòyè ẹ̀yà mú wá nígbà ayẹyẹ yíya pẹpẹ sí mímọ́, orí Kẹsàn-án sì sọ nípa bí wọ́n á ṣe máa ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá. Àpéjọ náà tún gba ìtọ́ni nípa bí wọ́n a ṣe máa pabùdó àti bí wọ́n a ṣe máa ṣí kúrò.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
2:1, 2—Kí làwọn “àmì” táwọn ẹ̀yà mẹ́ta-mẹ́ta tá a pín pọ̀ máa ń tẹ̀ lé láti mọ ibi tí wọ́n á pabùdó sí nínú aginjù? Bíbélì kò sọ ohun táwọn àmì wọ̀nyí jẹ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò wo àwọn àmì náà bí ohun mímọ́ tàbí kí wọ́n máa kíyè sí wọn nínú ìjọsìn. Ohun pàtàkì tí àwọn àmì náà wà fún ni láti jẹ́ kí kálukú mọ àyè rẹ̀ nínú ibùdó.
5:27—Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé “itan” ìyàwó kan tó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ‘yóò joro?’ Ẹ̀ya ìbímọ ni ọ̀rọ̀ náà “itan,” dúró fún lọ́nà tá a gbà lò ó níhìn-ín. (Jẹ́nẹ́sísì 46:26) ‘Jíjoro tí yóò joro’ túmọ̀ sí pé àwọn ẹ̀ya ara wọ̀nyí ‘kò ní ṣiṣẹ́ mọ́, èyí tó túmọ̀ sí pé kò ní ṣeé ṣe fún un láti lóyún.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
6:1-7. Àwọn Násírì kò gbọ́dọ̀ fẹnu kan ohun tó bá wá láti ara àjàrà àti gbogbo ohun mímú tó lè pani bí ọtí, ìyẹn sì gba ìsẹ́ra ẹni. Wọ́n ní láti fi irun wọn sílẹ̀ kó gùn—èyí tí í ṣe àmì ìtẹríba fún Jèhófà, gẹ́gẹ́ báwọn obìnrin ṣe ní láti wà ní ìtẹríba fún ọkọ̀ wọn tàbí bàbá wọn. Àwọn Násírì ní láti máa wà ní mímọ́ nípa yíyẹra fún òkú ohunkóhun, kódà òkú èèyàn wọn tó sún mọ́ wọn pàápàá. Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lónìí náà ń fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn nípa sísẹ́ ara wọn àti wíwà ní ìtẹríba fún Jèhófà àtàwọn ìṣètò rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ ìsìn kan lè béèrè pé kí wọ́n lọ sí orílẹ̀-èdè jíjìn, èyí tó lè mú kó ṣòro tàbí kó má tiẹ̀ ṣeé ṣe láti padà wálé fún ìsìnkú èèyàn wọn kan tó sún mọ́ wọn gan-an.
8:25, 26. Láti rí i dájú pé àwọn ọkùnrin tó jáfáfá ló ń bójú tó ẹrù iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì àti nítorí ọjọ́ orí wọn, a pàṣẹ fáwọn ọkùnrin tó ti ń dàgbà láti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tó jẹ́ dandan gbọ̀n. Àmọ́ ṣá o, wọ́n ṣì lè yọ̀ọ̀da ara wọn láti ran àwọn ọmọ Léfì yòókù lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ pípolongo Ìjọba Ọlọ́run lónìí, ìlànà inú òfin yìí kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Bí ara tó ti ń dara àgbà ò bá jẹ́ kí Kristẹni kan lè bójú tó àwọn ojúṣe kan mọ́, ó lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn tí agbára rẹ̀ gbé.
LÁTI IBÌ KAN SÍ ÒMÍRÀN NÍNÚ AGINJÙ
Nígbà tí àwọsánmà tó wà lókè àgọ́ ìjọsìn bá gbéra sókè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á bẹ̀rẹ̀ ìrìn wọn, èyí tó máa wá mú wọn gúnlẹ̀ sí aṣálẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù ní ọdún méjìdínlógójì àti oṣù kan tàbí méjì lẹ́yìn náà. Wàá jàǹfààní tó o bá wo àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lọ nínú àwòrán ilẹ̀ tó wà lójú ìwé 9 nínú ìwé pẹlẹbẹ Wo Ilẹ̀ Dáradára Náà tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Nígbà tí wọ́n wà lójú ọ̀nà sí Kádéṣì, ní Aginjù Páránì, ó kéré tán, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ráhùn. Ìráhùn àkọ́kọ́ dópin nígbà tí Jèhófà rán iná tó jó àwọn kan lára àwọn èèyàn náà run. Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí sunkún ẹran, Jèhófà sì pèsè àparò fún wọn. Míríámù àti Áárónì ráhùn nípa Mósè, èyí tó mú kí Míríámù dẹni tí ẹ̀tẹ̀ bò fún ìgbà díẹ̀.
Nígbà tí wọ́n pabùdó sí Kádéṣì, Mósè rán àwọn ọkùnrin méjìlá jáde láti lọ ṣe amí Ilẹ̀ Ìlérí. Wọ́n padà dé ní ogójì ọjọ́ lẹ́yìn náà. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ìròyìn burúkú tí mẹ́wàá lára àwọn amí náà mú wá gbọ́, wọ́n sì fẹ́ sọ Mósè, Áárónì, àtàwọn amí méjì yòókù tó jẹ́ olóòótọ́, ìyẹn Jóṣúà àti Kálébù, lókùúta pa. Jèhófà pinnu láti rán àjàkálẹ̀ àrùn sáwọn èèyàn náà, àmọ́ Mósè bá wọn bẹ̀bẹ̀, Ọlọ́run sì sọ pé wọ́n yóò tàràkà kiri nínú aginjù fún ogójì ọdún, títí gbogbo àwọn tí wọ́n kà nígbà ètò ìkànìyàn á fi kú tán pátá.
Jèhófà tún fún wọn ní àwọn ìlànà mìíràn. Kórà àtàwọn mìíràn ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì, àmọ́ iná jó àwọn kan lára àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run nígbà tí ilẹ̀ lanu tó sì gbé àwọn kan mì. Lọ́jọ́ kejì, gbogbo àpéjọ náà tún bẹ̀rẹ̀ sí ráhùn nípa Mósè àti Áárónì. Fún ìdí yìí, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [14,700] ló kú nínú àjàkálẹ̀ àrùn kan tó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá. Ọlọ́run mú kí ọ̀pá Áárónì yọ òdòdó káwọn èèyàn náà lè mọ ẹni tí òun yàn ní àlùfáà àgbà. Lẹ́yìn náà, Jèhófà tún fún wọn láwọn òfin mìíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ojúṣe àwọn ọmọ Léfì àti ìwẹ̀mọ́ àwọn èèyàn náà. Lílo eérú màlúù pupa ṣàpẹẹrẹ ìwẹ̀mọ́ nípasẹ̀ ẹbọ Jésù.—Hébérù 9:13, 14.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́rí padà sí Kádéṣì níbi tí Míríámù kú sí. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí ráhùn nípa Mósè àti Áárónì. Kí ni wọ́n sọ pé ó ń mú káwọn máa ráhùn? Wọ́n ní kò sí omi. Nítorí pé Mósè àti Áárónì kò ya orúkọ Jèhófà sí mímọ́ nígbà tí wọ́n ń pèsè omi lọ́nà ìyanu, wọ́n pàdánù àǹfààní wíwọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ísírẹ́lì ṣí kúrò ní Kádéṣì, Áárónì sì kú ní Òkè Hóórì. Níbi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń rìn yí po Édómù, àárẹ̀ mú wọn wọ́n sì sọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run àti Mósè. Jèhófà rán ejò olóró sí wọn láti fìyà jẹ wọ́n. Mósè tún bá wọn bẹ̀bẹ̀, Ọlọ́run sì sọ fún un pé kó ṣe ejò idẹ kan kó sì gbé e kọ́ sára òpó kí àwọn tí ejò bù jẹ lè rí ìmúláradá nípa wíwo ejò náà. Ejò yìí ṣàpẹẹrẹ kíkàn tí wọ́n kan Jésù Kristi mọ́gi fún àǹfààní wa ayérayé. (Jòhánù 3:14, 15) Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn Ọba Ámórì, ìyẹn Síhónì àti Ógù, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
12:1—Kí nìdí tí Míríámù àti Áárónì fi ń ráhùn nípa Mósè? Ó hàn gbangba pé olórí ohun tó fa ìráhùn wọn ni pé Míríámù ń fẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ máa wárí fún òun. Nígbà tí Sípórà, ìyàwó Mósè padà wá bá a láginjù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Míríámù ń bẹ̀rù pé àwọn èèyàn ò ní máa wo òun bí aṣáájú àwọn obìnrin nínú ibùdó mọ́.—Ẹ́kísódù 18:1-5.
12:9-11—Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Míríámù nìkan ni ẹ̀tẹ̀ bò? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni abẹnugan nínú ìráhùn náà tó sì wá fa Áárónì wọ̀ ọ́. Áárónì ní tirẹ̀ ṣe ohun tó dára, ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
21:14, 15—Ìwé wo ni ìwé tá a dárúkọ níhìn-ín? Ìwé Mímọ́ tọ́ka sí onírúurú ìwé táwọn òǹkọ̀wé Bíbélì gbé àkọsílẹ̀ wọn kà. (Jóṣúà 10:12, 13; 1 Àwọn Ọba 11:41; 14:19, 29) Ọ̀kan lára irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ ni “ìwé Àwọn Ogun Jèhófà.” Ìtàn ogun táwọn èèyàn Jèhófà jà ló wà nínú rẹ̀.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
11:27-29. Àpẹẹrẹ tó dára gan-an ni Mósè jẹ́ ní ti bó ṣe yẹ ká ṣe nígbà táwọn mìíràn bá rí àwọn àǹfààní kan gbà nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Dípò kí Mósè máa ṣèlara kó sì máa wá ògo fún ara rẹ̀, ńṣe ni inú rẹ̀ dùn nígbà tí Ẹ́lídádì àti Médádì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wòlíì.
12:2, 9, 10; 16:1-3, 12-14, 31-35, 41, 46-50. Jèhófà fẹ́ káwọn olùjọ́sìn òun máa bọ̀wọ̀ fáwọn tó fún ní ọlá àṣẹ.
14:24. Ohun pàtàkì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún bí ayé ṣe ń múni hùwà àìtọ́ ni pé ká ní “ẹ̀mí tí ó yàtọ̀” tàbí èrò inú tó yàtọ̀. Èrò inú wa gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí ti ayé.
15:37-41. Ohun tí ìṣẹ́tí àrà ọ̀tọ̀ tó wà létí aṣọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà fún ni láti máa rán wọn létí pé èèyàn tí Ọlọ́run yà sọ́tọ̀ fún ìjọsìn rẹ̀ ni wọ́n àti pé wọ́n ní láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run kí èyí sì mú wa yàtọ̀ sí ayé?
NÍ PẸ̀TẸ́LẸ̀ MÓÁBÙ
Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù tó jẹ́ aṣálẹ̀, ìbẹ̀rùbojo mú àwọn ọmọ Móábù. Èyí mú kí Bálákì Ọba Móábù lọ háyà Báláámù láti gégùn-ún fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́ Jèhófà mú kí Báláámù súre fún wọn. Ni wọ́n bá lo àwọn obìnrin Móábù àti Mídíánì láti tan àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sínú ìṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà. Àbájáde rẹ̀ ni pé, Jèhófà pa ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún èèyàn tó lọ́wọ́ nínú ìwà àìtọ́ náà rùn. Ìgbà tí Fíníhásì fi hàn pé òun kò fàyè gba bíbá Jèhófà díje ni àrùn náà tó dáwọ́ dúró.
Ìkànìyàn ẹlẹ́ẹ̀kejì fi hàn pé kò sí èyí tó wà láàyè mọ́ nínú àwọn ọkùnrin tí wọ́n kà nígbà ìkànìyàn àkọ́kọ́, àyàfi Jóṣúà àti Kálébù nìkan. Ọlọ́run yan Jóṣúà láti rọ́pò Mósè. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ìlànà nípa bí wọ́n á ṣe máa ṣe onírúurú ìrúbọ àti ìtọ́ni nípa ẹ̀jẹ́ jíjẹ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún gbẹ̀san lára àwọn ọmọ Mídíánì. Ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè tẹ̀dó sí apá ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì. Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n á ṣe sọdá Jọ́dánì tí wọ́n á sì gba ilẹ̀ náà. Ó ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ibi tí àwọn ààlà ìpínlẹ̀ yóò dé. Kèké ni wọn yóò fi pín ogún. Ìlú ńlá méjìdínlógójì ni wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì, mẹ́fà lára àwọn ìlú wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìlú ààbò.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
22:20-22—Kí nìdí tí ìbínú Jèhófà fi ru sí Báláámù? Jèhófà ti sọ fún wòlíì Báláámù pé kò gbọ́dọ̀ gégùn-ún fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Númérì 22:12) Àmọ́ wòlíì yìí tẹ̀ lé àwọn èèyàn Bálákì nítorí ó ṣì ní in lọ́kàn láti gégùn-ún fún Ísírẹ́lì. Báláámù fẹ́ ṣe ohun tó dùn mọ́ ọba Móábù nínú kó sì gba èrè. (2 Pétérù 2:15, 16; Júúdà 11) Kódà, lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti mú Báláámù súre fún Ísírẹ́lì dípò kó gégùn-ún fún wọn, ó ṣì ń wá ojú rere ọba náà nípa dídábàá pé kó lo àwọn obìnrin tó ń jọ́sìn Báálì láti mú àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀. (Númérì 31:15, 16) Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tó mú kí Ọlọ́run bínú sí wòlíì Báláámù ni ojúkòkòrò rẹ̀ tó bùáyà.
30:6-8—Ǹjẹ́ Kristẹni ọkùnrin kan lè fagi lé ẹ̀jẹ́ ìyàwó rẹ̀? Lákòókò tiwa yìí Jèhófà ń bá àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lò lẹ́nìkọ̀ọ̀kan tó bá kan ọ̀ràn ẹ̀jẹ́ jíjẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ìyàsímímọ́ jẹ́ ẹ̀jẹ́ téèyàn fúnra rẹ̀ jẹ́ fún Jèhófà. (Gálátíà 6:5) Ọkọ kan kò láṣẹ láti fagi lé irú ẹ̀jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, aya kan ní láti yẹra fún jíjẹ́ ẹ̀jẹ́ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ta kò tàbí tí kò ní jẹ́ kó ṣe ojúṣe rẹ̀ sí ọkọ rẹ̀.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
25:11. Ẹ ò ri pé àpẹẹrẹ tó dára gan-an ni Fíníhásì jẹ́ fún wa pé ká ní ìtara fún ìjọsìn Jèhófà! Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìfẹ́ láti mú kí ìjọ wà ní mímọ́ sún wa láti fi ìwà pálapàla tó burú jáì tí ẹnì kan hù tá a sì mọ̀ nípa rẹ̀ tó àwọn alàgbà nínú ìjọ létí?
35:9-29. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹni tó pààyàn láìmọ̀ọ́mọ̀ ní láti fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ kó sì sá lọ sí ìlú ààbò fún sáà kan, èyí kọ́ wa pé, ohun mímọ́ ni ìwàláàyè jẹ́ àti pé a gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún un.
35:33. Ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ nìkan la máa fi ṣètùtù fún ayé tí wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ sọ di aláìmọ́. Ẹ ò ri pé ó bójú mu pé Jèhófà yóò pa àwọn ẹni ibi run kúrò kó tó wá sọ ayé di Párádísè!—Òwe 2:21, 22; Dáníẹ́lì 2:44.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára
A gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún Jèhófà àtàwọn tó yàn sípò láti bójú tó ẹrù iṣẹ́ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Ìwé Númérì mú kí kókó yìí túbọ̀ ṣe kedere. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ pàtàkì lèyí jẹ́ fún wa lónìí, kí àlàáfíà àti ìfẹ́ lè jọba nínú ìjọ!
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá a sọ nípa wọn nínú ìwé Númérì fi hàn bó ṣe rọrùn tó fáwọn tí kò fọwọ́ gidi mú ipò tẹ̀mí wọn láti hùwà àìtọ́, bí ìráhùn, ìṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà. A lè lo àwọn kan lára àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé Bíbélì yìí láwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn nígbà tá a bá ń bójú tó apá tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ. Láìsí àní-àní, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára” nínú ìgbésí ayé wa.—Hébérù 4:12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Nípasẹ̀ àwọsánmà tó máa ń wà lórí àgọ́ ìjọsìn lọ́nà ìyanu, Jèhófà ń darí báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń pabùdó àti bí wọ́n ṣe ń ṣí kúrò
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ó yẹ ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ló sì retí pé ká bọ̀wọ̀ fáwọn aṣojú òun