Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
Bi Kristian kan ba ń ṣaisan tabi ti o ń rinrin-ajo ti kò si tipa bẹẹ lè wà nibi ajọdun Iṣe-iranti, oun ha nilati ṣajọdun rẹ̀ ni oṣu kan lẹhin naa bi?
Ni Israeli igbaani Ajọ-irekọja ni a ń ṣe lọdọọdun ni ọjọ kẹrinla oṣu kin-in-ni, ti a ń pe ni Nisan (tabi, Abibu). Ṣugbọn a ri ipese akanṣe kan ti a gbekalẹ ni Numeri 9:10, 11 pe: “Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, bi ẹnikẹni ninu yin, tabi ninu iran yin bá ti ipa oku di alaimọ, tabi bi o bá wà ni ọ̀nà ajo jíjìnréré, sibẹ oun ó pa ajọ-irekọja mọ́ fun OLUWA. Ni ọjọ kẹrinla oṣu keji [ti a ń pe ni Iyyar, tabi Ziv], ni aṣalẹ ni ki wọn ki o pa á mọ́; ki wọn sì fi akara alaiwu jẹ ẹ ati ewébẹ̀ kikoro.”
Ṣakiyesi pe eyi kò fidii ọjọ yiyatọsira meji mulẹ fun Ajọ-irekọja naa (Nisan 14 tabi Ziv 14), ninu eyi ti ọmọ Israeli tabi agbo-ile eyikeyii ti lominira lati yàn, ni didalori bi o bá ṣe rọrùn si. Ipese ounjẹ Ajọ-irekọja ni oṣu keji ni o láàlà. Ayafi kan ni o jẹ́ fun ọmọ Israeli kan ti o jẹ aláìmọ́ lọna ti ayẹyẹ ni Nisan 14 tabi ti o wà ni ọ̀nà jíjìn sibi ti a ti ṣe ajọdun ti a ń ṣe deedee naa.
Kiki apẹẹrẹ kanṣoṣo ti a kọsilẹ nipa eyi ti a ń lo ni gbogboogbo jẹ́ ni akoko ti Ọba Hesekiah oluṣotitọ mú akiyesi Ase Akara Alaiwu sọji. Kò si akoko lati murasilẹ fun oṣu kin-in-ni (bi awọn alufaa kò ti wà ni imuratan ti awọn eniyan naa kò sì pejọpọ), nitori naa á ṣe e ni ọjọ kẹrinla oṣu keji.—2 Kronika 29:17; 30:1-5.
Yatọ si iru awọn ipo ara-ọtọ bẹẹ, awọn Ju ń pa Ajọ-irekọja mọ ni ọjọ ti Ọlọrun yan fun un. (Eksodu 12:17-20, 41, 42; Lefitiku 23:5) Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣajọdun gẹgẹ bi Ofin ṣe beere fun, laifi ọwọ́ yẹpẹrẹ mu ọjọ yii. Luku rohin pe: “Ọjọ aiwukara pé, nigba ti wọn kò lè ṣe aiṣẹbọ irekọja. [Jesu] si rán Peteru oun Johannu, wi pe, ẹ lọ pese irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ.”—Luku 22:7, 8.
Ni ìgbà iṣẹlẹ yẹn Jesu fi ajọdun ọdọọdun kan lélẹ̀ ti awọn Kristian mọ gẹgẹ bi Ounjẹ Alẹ Oluwa. Iniyelori pipesẹ ti awọn Kristian ń pesẹ sibẹ ni a kò lè tẹnumọ jù. Eyi ni iṣẹlẹ naa ti o ṣe pataki julọ ninu ọdun fun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Awọn ọ̀rọ̀ Jesu fihàn wa idi ti o fi ri bẹẹ; o sọ pe: “Ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi.” (Luku 22:19) Nipa bayii, ọkọọkan ninu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbọdọ wewee ni ọpọ oṣu ṣaaju lati maṣe mu ki adehun eyikeyii miiran dí ọjọ ajọdun naa lọwọ. Ounjẹ Alẹ Oluwa ni a o ṣajọdun rẹ̀ ni Tuesday, April 6, 1993, lẹhin ti oorun ba wọ̀ ni adugbo kọọkan.
Ninu awọn ọ̀ràn kan ti o ṣọwọn ipo alairotẹlẹ pato kan, iru bi amodi tabi ìlọ́júpọ̀ irin-ajo, lè di Kristian kan lọwọ pipesẹ gẹgẹ bi oun lọkunrin tabi lobinrin ti wewee. Ki ni ohun ti a gbọdọ ṣe ninu iru ipo kan bẹẹ?
Nigba ajọdun naa akara alaiwu ati waini pupa ni a maa ń gbe kọja, ti awọn wọnni ti a ti fi ami-ororo yàn pẹlu ẹmi mimọ Ọlọrun ti a si yàn fun iwalaaye ninu ọrun yoo si ṣajọpin. (Matteu 26:26-29; Luku 22:28-30) Bi ẹnikan ti o ti ń fi ọdọọdun ṣajọpin bá di ẹni ti a sémọ́ ori ibusun àárẹ̀ nile tabi ni ile-iwosan kan, awọn alagba ijọ adugbo yoo ṣeto fun ọ̀kan ninu wọn lati mú diẹ ninu akara ati waini naa lọ fun ẹni ti ń ṣaisan naa, lati jiroro ọ̀rọ̀ Bibeli ti o bojumu lori koko naa, ati lati gbé ami iṣapẹẹrẹ naa fun un. Bi Kristian ẹni-ami-ororo kan ba jinna si ijọ rẹ̀, o gbọdọ ṣeto lati lọ si ijọ kan ni adugbo ti oun yoo wà ni ọjọ naa.
Ni oju-iwoye eyi, yoo jẹ́ labẹ awọn ipo ti o ṣara-ọtọ ni Kristian ẹni-ami-ororo kan yoo ti ṣajọdun Ounjẹ Alẹ Oluwa ni 30 ọjọ lẹhin naa (oṣu oloṣupa kan), ni ibamu pẹlu aṣẹ inu Numeri 9:10, 11 ati apẹẹrẹ inu 2 Kronika 30:1-3, 15.
Awọn wọnni ti wọn jẹ ti ẹgbẹ́ “agutan miiran” ti Jesu, pẹlu ireti ìyè ayeraye ninu paradise ori ilẹ̀-ayé kan, kò si labẹ àṣẹ lati ṣajọpin akara ati waini naa. (Johannu 10:16) O ṣe pataki lati pesẹ sibi ajọdun ọlọdọọdun naa, ṣugbọn wọn kìí ṣajọpin ninu ohun iṣapẹẹrẹ naa. Nitori naa bi ọ̀kan ninu wọn bá ń ṣaisan tabi rinrin-ajo ati nipa bayii ti kò sí pẹlu ijọ eyikeyii ni alẹ ọjọ yẹn, oun lọkunrin tabi lobinrin lè ka awọn iwe mimọ yiyẹ ni oun nikan (eyi ti o ni ninu irohin nipa bi Jesu ṣe gbe ajọdun naa kalẹ) ki o sì gbadura fun ibukun Jehofa lori iṣẹlẹ naa kaakiri agbaye. Ṣugbọn ninu ọ̀ràn yii kò si idi fun afikun iṣeto eyikeyii fun ipade tabi ijiroro Bibeli akanṣe kan ni oṣu kan lẹhin naa.