Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JULY 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 11-12
“Bí Jèhófà Ṣe Fẹ́ Ká Máa Sin Òun”
it-2 1007 ¶4
Ara
Kéèyàn Fi Gbogbo Ara Sìn. Bá a ṣe sọ ṣáájú, ohun tí “ara” túmọ̀ sí ni odindi èèyàn. Àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tún sọ pé ká wá Ọlọ́run, ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká sì sìn ín pẹ̀lú ‘gbogbo ọkàn wa àti gbogbo ara wa’ (Di 4:29; 11:13, 18), Diutarónómì 6:5 náà sọ pé: “Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” Jésù sọ pé ó ṣe pàtàkì ká fi gbogbo ara wa àti gbogbo okun wa sin Jèhófà, ó tún fi kún un pé ká fi “gbogbo èrò” wa sìn ín. (Mk 12:30; Lk 10:27) Ìbéèrè kan ni pé kí nìdí táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí fi sọ̀rọ̀ nípa ara, tó tún sọ̀rọ̀ nípa èrò, okun àti ọkàn nígbà tó jẹ́ pé inú ara ni gbogbo ẹ̀ wà? Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ lọ́nà yìí: Tí ẹnì kan bá ta ara ẹ̀ láti di ẹrú ẹlòmíì, ó máa di ti ẹni tó rà á. Àmọ́ ó ṣeé ṣe kó má fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sin ọ̀gá ẹ̀, kó má sì wù ú láti ṣe ohun tí ọ̀gá ẹ̀ fẹ́, torí náà ó lè má lo gbogbo okun ẹ̀ tàbí gbogbo agbára ẹ̀ láti ṣiṣẹ́ fún ọ̀gá ẹ̀. (Fi wé Ef 6:5; Kol 3:22.) Torí náà, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa èrò, okun àti ọkàn ká lè máa rántí pé ó yẹ ká tún lo gbogbo wọn nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run, torí òun ló ni wá, Ọmọ ẹ̀ ló sì fi ẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà. Kéèyàn sin Ọlọ́run “tọkàntọkàn” túmọ̀ sí kéèyàn fi gbogbo ara sìn ín láìfi ẹ̀yà ara kankan sílẹ̀.—Fi wé Mt 5:28-30; Lk 21:34-36; Ef 6:6-9; Flp 3:19; Kol 3:23, 24.
it-1 84 ¶3
Pẹpẹ
Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n wó àwọn pẹpẹ òrìṣà, kí wọ́n sì fọ́ ọwọ̀n tí wọ́n sábà máa ń kọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn túútúú. (Ẹk 34:13; Di 7:5, 6; 12:1-3) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ ṣe òpó òrìṣà, wọn ò sì gbọ́dọ̀ sun àwọn ọmọ wọn nínú iná bíi tàwọn ará Kénáánì. (Di 12:30, 31; 16:21) Dípò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì á fi mọ pẹpẹ lóríṣiríṣi, pẹpẹ kan ṣoṣo ni wọ́n gbọ́dọ̀ mọ fún ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́, ibi tí Jèhófà bá sì yàn ni wọ́n gbọ́dọ̀ mọ ọ́n sí. (Di 12:2-6, 13, 14, 27; ìyẹn yàtọ̀ sí tàwọn ará Bábílónì tí wọ́n mọ pẹpẹ ọgọ́sàn-án (180) fún òrìṣà Íṣítà nìkan.) Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá odò Jọ́dánì, Jèhófà ní kí wọ́n fi òkúta tí wọn ò fi irin gbẹ́ mọ pẹpẹ kan (Di 27:4-8), Jóṣúà ló sì mọ pẹpẹ yìí lórí Òkè Ébálì. (Joṣ 8:30-32) Lẹ́yìn tí wọ́n gba ilẹ̀ ìlérì tí wọ́n sì pín in, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè mọ pẹpẹ kan tó tóbi, tó sì fani mọ́ra sẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù nínú, àmọ́ ìbínú wọn rọlẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé pẹpẹ tí wọ́n mọ yẹn ò túmọ̀ sí pé wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀, ṣe ni wọ́n kàn mọ ọ̀n kí wọ́n lè máa rántí pé Jèhófà nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn, torí òun ni Ọlọ́run tòótọ́.—Joṣ 22:10-34.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 925-926
Òkè Gérísímù
Kété lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun ìlú Áì, Jóṣúà ṣe ohun tí Mósè sọ, ó ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ síwájú Òkè Gérísímù àti Òkè Ébálì. Ibẹ̀ ni Jóṣúà ti ka àwọn ìbùkún tí wọ́n máa rí tí wọ́n bá ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn nǹkan burúkú tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn tí wọ́n bá ṣàìgbọràn. Ẹ̀yà Síméónì, Léfì, Júdà, Ísákà, Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì dúró síwájú Òkè Gérísímù. Àwọn ọmọ Léfì wà ní àfonífojì òkè méjèèjì, wọ́n tún gbé àpótí májẹ̀mú síbẹ̀, àwọn ẹ̀yà mẹ́tà tó kù sí dúró síwájú Òkè Ébálì. (Di 11:29, 30; 27:11-13; Joṣ 8:28-35) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà tó wà níwájú Òkè Gérísímù ló dáhùn nígbà tí Jóṣúà ka ìbùkún tó wà nínú Òfin yẹn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà tó dúró síwájú Òkè Ébálì ló dáhùn nígbà tó ka ègún. Àwọn kan gbà pé torí pé Òkè Gérísímù rẹwà tó sì lọ́ràá ni Jóṣúà fi kọjú síbẹ̀ nígbà tó ń ka àwọn ìbùkún, wọ́n sì gbà pé ó kọjú sí Òkè Ébálì nígbà tó ń ka ègún torí pé ilẹ̀ olókè ni, nǹkan kan ò sì hù níbẹ̀. Àmọ́ a ò rí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì. Jóṣúà ka Òfin náà sókè “níwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, títí kan àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé àtàwọn àjèjì tó ń gbé láàárín wọn.” (Joṣ 8:35) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó dúrò síwájú òkè méjèèjì yẹn pọ̀ gan-an, síbẹ̀ gbogbo wọn ló gbọ́ ohun tí Jóṣúà kà jáde. Ọ̀kan lára ohun tó mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti gbọ́rọ̀ ẹ̀ ni pé ohùn máa ń rìn jìnnà lágbègbè yẹn.—Wo ÒKÈ ÉBÁLÌ.
JULY 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 13-15
“Òfin Tí Jèhófà Ṣe Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Aláìní”
it-2 1110 ¶3
Ìdá Mẹ́wàá
Ó jọ pé ìdá mẹ́wàá míì tún wà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń mú wá, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni wọ́n máa ń mú un wá, ó sì yàtọ̀ séyìí tí wọ́n máa ń mú wá lóòrèkóòrè láti ti àwọn àlùfáà lẹ́yìn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Léfì máa ń lò lára ìdá mẹ́wàá kejì yìí, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lèyí tó pọ̀ jù lára ẹ̀ wà fún, wọ́n sì máa ń lò ó tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àjọyọ̀ ńlá pa pọ̀. Àmọ́ tílé ẹnì kan bá jìnnà sí Jerúsálémù, tí ò sì ní rọrùn fún un láti mú ìdá mẹ́wàá náà lọ síbẹ̀, ó lè sọ ọ́ dowó, á sì mú owó náà dání láti fi ra àwọn nǹkan tí ìdílé ẹ̀ máa nílò kí wọ́n lè gbádùn ara wọn nígbà àjọyọ̀ náà. (Di 12:4-7, 11, 17, 18; 14:22-27) Nǹkan míì tún ni pé, lópin ọdún kẹta àti ìkẹfà láàárín ọdún méje tó jẹ́ ọdún sábáàtì, wọ́n máa ń lo ìdá mẹ́wàá kejì yìí láti bójú tó àwọn ọmọ Léfì, àjèjì, opó àtàwọ́n ọmọ aláìníbaba tó wà nílùú wọn dípò tí wọ́n á fi lò ó nígbà àjọyọ̀.—Di 14:28, 29; 26:12.
it-2 833
Ọdún Sábáàtì
Wọ́n tún máa ń pe ọdún Sábáàtì ní “ọdún ìtúsílẹ̀ [hash·shemit·tahʹ].” (Di 15:9; 31:10) Wọ́n máa ń jẹ́ kílẹ̀ wọn sinmi lọ́dún yẹn, wọn ò ní ro ó, wọn ò sì ní gbin nǹkan kan sórí ẹ̀. (Ẹk 23:11) Bákan náà, tẹ́nì kan bá jẹ gbèsè, wọ́n máa ń fagi lé e lọ́dún yẹn, wọn ò ní sìn ín mọ́. Wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti bọlá fún Jèhófà, torí náà “ìtúsílẹ̀ fún Jèhófà” ni wọ́n máa ń pè é. Onírúurú nǹkan làwọn èèyàn ń sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn kan gbà pé wọn kì í fagi lé gbèsè náà pátápátá, àmọ ó kàn jẹ́ pé tó bá jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ló jẹ gbèsè náà wọn ò ní béèrè lọ́wọ́ ẹ̀, torí pé èrè kankan ò ní wọlé fáwọn àgbẹ̀ lọ́dún yẹn; àmọ́ tó bá jẹ́ pé àjèjì ló jẹ wọ́n ní gbèsè, wọ́n á sìn ín. (Di 15:1-3) Àwọn rábì kan gbà pé tẹ́nì kan bá yá òtòṣì lówó láti ràn án lọ́wọ́, ó máa fagi lé gbèsè yẹn, àmọ́ tó bá yá ẹnì kan lówó láti ṣòwò, ó máa gbà á pa dà. Wọ́n sọ pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Hillel gbé ìlànà kan kalẹ̀ pé tẹ́nì kan bá fẹ́ yáni lówó, tó sì máa gbà á dandan, òun àtẹni tó fẹ́ yá lówó gbọ́dọ̀ lọ sílé ẹjọ́ láti ṣàdéhùn kó lè rówó ẹ̀ gbà pa dà.—The Pentateuch and Haftorahs, tí J. Hertz ṣàtúnṣe rẹ̀, London, 1972, pp. 811, 812.
it-2 978 ¶6
Ẹrú
Òfin nípa bí ọ̀gá á ṣe máa ṣe sẹ́rú. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe sí ẹrú tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe máa ń ṣe sí ẹrú tó jẹ́ àjèjì. Tó bá jẹ́ pé àjèjì ni ẹrú kan, ó máa di ohun ìní ọ̀gá ẹ̀ títí láé, ọmọ ọ̀gá náà sì lè jogún ẹ̀ (Le 25:44-46), àmọ́ tó bá jẹ́ pé ọmọ Ísírẹ́lì ni ẹrú náà, ọ̀gá ẹ̀ máa dá a sílẹ̀ yálà lẹ́yìn ọdún keje tàbí ọdún Júbílì, èyí tó bá kọ́kọ́ pé nínú ọdún méjèèjì yìí ni wọ́n máa dá a sílẹ̀. Ní gbogbo àsìkò tí ọmọ Ísírẹ́lì náà bá fi wà lọ́dọ̀ ọ̀gá ẹ̀, ọ̀gá náà gbọ́dọ̀ mú un bí alágbàṣe. (Ẹk 21:2; Le 25:10; Di 15:12) Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá ta ara ẹ̀ fún àjèjì tàbí àlejò kan tàbí fún ọ̀kan lára mọ̀lẹ́bí àjèjì náà, ìgbàkigbà làwọn mọ̀lẹ́bí ẹrú náà lè tún un rà, òun fúnra ẹ̀ náà lè tún ara ẹ̀ rà. Iye ọdún tó kù kí ọdún Júbílì pé tàbí iye ọdún tó kù kí ọdún keje tó fẹ́ lò lọ́dọ̀ ọ̀gá ẹ̀ pé ní wọ́n máa fi ṣírò iye tí wọ́n máa san láti rà á pa dà. (Le 25:47-52; Di 15:12) Tẹ́nì kan bá tú ẹrú ẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, ó gbọ́dọ̀ fún un ní oríṣiríṣi nǹkan kó lè fi bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. (Di 15:13-15) Tí ẹrú náà bá mú ìyàwó wá sílé ọ̀gá ẹ̀, ìyàwó náà máa bá a lọ tí wọ́n bá tú u sílẹ̀. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ọ̀gá ẹ̀ ló fún un níyàwó, ìyàwó náà àtàwọn ọmọ ẹ̀ máa di ti ọ̀gá yẹn (ẹ̀rí fi hàn pé àjèjì tí wọn ò ní tú sílẹ̀ lọ́dún keje nìyàwó yìí máa jẹ́). Nírú ipò yìí, ọmọ Ísírẹ́lì yẹn lè yàn láti má kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá ẹ̀. Ọ̀gá náà á wá fi òòlu dá etí ẹrú yẹn lu láti fi hàn pé á máa sin ọ̀gá náà títí láé.—Ẹk 21:2-6; Di 15:16, 17.
JULY 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 16-18
“Béèyàn Ṣe Lè Dájọ́ Lọ́nà Tó Tọ́”
it-1 343 ¶5
Ìfọ́jú
Ọlọ́run ò fẹ́ kéèyàn máa fi igbá kan bọ̀kan nínú tó bá dọ̀rọ̀ ìgbẹ́jọ́ tàbí kéèyàn máa ṣègbè. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ẹni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ wé ẹni tó dijú sí òtítọ́ tàbí afọ́jú. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Òfin Mósè rọ àwọn aṣáájú tàbí àwọn adájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọn ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn nǹkan yìí lè mú kí wọ́n gbé ẹ̀bi fún aláre, kí wọ́n sì gbé àre fún ẹlẹ́bi. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí àwọn tó ríran kedere lójú.” (Ẹk 23:8) Níbòmíì, ó sọ pé: “Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí ọlọ́gbọ́n lójú.” (Di 16:19) Tí adájọ́ kan bá tiẹ̀ jẹ́ olóòótọ́, tó sì mẹjọ́ dá, tó bá fi lè gba ẹ̀bùn, ó lè yí ìdájọ́ po láìfura tàbí kó tiẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ torí ẹ̀bùn tó ti gbà. Abájọ tí Òfin Ọlọ́run fi kìlọ̀ fáwọn onídàájọ́ pé kí wọ́n kíyè sára, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ èrò wọn nípa ẹnì kan tàbí ẹ̀bùn táwọn èèyàn ń fún wọn lè mú kí wọ́n yí ìdájọ́ po. Òfin yẹn sọ pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ rẹ́ aláìní jẹ tàbí kí ẹ ṣe ojúsàájú sí ọlọ́rọ̀.” (Le 19:15) Torí náà, adájọ́ kan ò gbọ́dọ̀ gbé àre fún olówó torí èrò tó ní nípa ẹ̀ tàbí káwọn èèyàn lè gba tiẹ̀.—Ẹk 23:2, 3.
it-2 511 ¶7
Nọ́ńbà
Méjì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń lo méjì tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa òfin. Wọ́n máa ń fìdí ọ̀rọ̀ kan múlẹ̀ tí ohun táwọn méjì sọ lórí ẹ̀ bá bára mu. Wọ́n máa ń nílò àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n bá fẹ́ fìdí ọ̀rọ̀ kan múlẹ̀ nílé ẹjọ́. A tún máa ń tẹ̀ lé ìlànà yìí nínú ìjọ Kristẹni. (Di 17:6; 19:15; Mt 18:16; 2Kọ 13:1; 1Ti 5:19; Heb 10:28) Ìlànà yìí kan náà ni Ọlọ́run lò nígbà tó yọ̀ǹda Ọmọ ẹ̀ pé kó gba àwa èèyàn là. Jésù sọ pé: “A kọ ọ́ sínú Òfin yín pé: ‘Òótọ́ ni ẹ̀rí ẹni méjì.’ Mò ń jẹ́rìí nípa ara mi, Baba tó rán mi sì ń jẹ́rìí nípa mi.”—Jo 8:17, 18.
it-2 685 ¶6
Àlùfáà
Àwọn àlùfáà ni Jèhófà dìídì yàn láti máa kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin Ọlọ́run, wọ́n tún wà lára àwọn tó ń dájọ̀. Nínú àwọn ìlú tí wọ́n yàn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n yan àwọn àlùfáà sí ìlú kọ̀ọ̀kan láti ran àwọn adájọ́ lọ́wọ́, àwọn àlùfáà yìí tún máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn adájọ́ láti bójú tó àwọn ẹjọ́ tó ṣòroó dá. (Di 17:8, 9) Àwọn àlùfáà tún gbọ́dọ̀ wà ní ṣẹpẹ́ pẹ̀lú àwọn àgbààgbà ìlú láti bójú tó ọ̀rọ̀ òkú tí wọ́n rí, tí wọn ò sì mẹni tó pa á, kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tó yẹ láti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kúrò lórí ìlú náà. (Di 21:1, 2, 5) Tọ́kùnrin kan bá ń jowú, tó sì fẹ̀sùn kan ìyàwó ẹ̀ pé ó ṣèṣekúṣe, ọkùnrin náà máa mú ìyàwó ẹ̀ wá síbi mímọ́, àlùfáà á wá ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn á jẹ́ kí Jèhófà bójú tó ọ̀rọ̀ yẹn fúnra ẹ̀, wọ́n á sì mọ̀ bóyá obìnrin náà jẹ̀bi àbí kò jẹ̀bi. (Nọ 5:11-31) Gbogbo ẹjọ́ táwọn adájọ́ àtàwọn àlùfáà bá dá làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ fara mọ́; ṣe ni wọ́n máa ń pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣorí kunkun, tí kò sì fara mọ́ ìdájọ́ tí wọ́n ṣe.—Nọ 15:30; Di 17:10-13.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 787
Lé Jáde
Lábẹ́ Òfin Mósè, ó kéré tán èèyàn méjì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí lòdì sí ẹnì kan kí wọ́n tó pa ẹni náà. (Di 19:15) Àwọn ẹlẹ́rìí yìí ló sì máa kọ́kọ́ sọ ẹni tó jẹ̀bi náà lókùúta. (Di 17:7) Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa fi hàn pé wọ́n nítara fún Òfin Ọlọ́run, wọ́n sì fẹ́ kí Ísírẹ́lì wà ní mímọ́, ó tún máa dà bí ìkìlọ̀ fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jẹ́rìí èké, kò sì ní jẹ́ kẹ́nì kan jẹ́rìí láìronú jinlẹ̀.
Máa Lo Ara Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
it-1 519 ¶4
Ìgbẹ́jọ́
Ìjọ Kristẹni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sáwọn tó ń fi ẹjọ́ dídá ṣe iṣẹ́, tí wọ́n sì ń gba owó lórí ẹ̀ nínú ìjọ Kristẹnì, àmọ́ a máa ń fún ẹni tó bá fẹ́ da ìjọ rú níbàáwí, tó bá ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Bíbélì, a sì lè yọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò nínú ìjọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún ìjọ, ìyẹn àwọn aṣojú tàbí àwọn tó ń múpò iwájú pé kí wọ́n máa ṣèdájọ́ àwọn tó wà nínú ìjọ. (1Kọ 5:12, 13) Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù àti Pétérù kọ sáwọn alàgbà ìjọ, wọ́n sọ pé àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ máa bójú tó àwọn ará, kí wọ́n rí i pé àwọn ará ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, kí wọ́n sì ran ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣẹsẹ̀ gbẹ́ lọ́wọ́. (2Ti 4:2; 1Pe 5:1, 2; fi wé Ga 6:1.) Kí wọ́n kìlọ̀ fún ẹni tó bá ń fa ìyapa lẹ́ẹ̀mejì, kí wọ́n tó bá a wí. (Tit 3:10, 11) Àmọ́ kí wọ́n yọ ẹni tí kò bá jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nínú ìjọ. Ìyẹn ò ní jẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe bó ṣe wù wọ́n, á sì tún jẹ́ kẹ́ni tó bá fẹ́ hùwà àìtọ́ mọ̀ pé ìjọ ò fàyè gba irú ìwà bẹ́ẹ̀. (1Ti 1:20) Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ pé kí wọ́n kóra jọ láti ṣedájọ́ ẹni tó bá hùwà àìtọ́. (1Kọ 5:1-5; 6:1-5) Ó dìgbà tí wọ́n bá gbọ́ ẹjọ́ látẹnu ẹlẹ́rìí méjì sí mẹ́ta kí wọ́n tó lè gbà pé òótọ́ lẹ́nì kan hùwà àìtọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò gbogbo ẹ̀rí táwọn èèyàn mú wá kí wọ́n tó dá ẹjọ́, wọn ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú.—1Ti 5:19, 21.
Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé tí aáwọ̀ bá ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn méjì, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ẹ̀ láàárín ara wọn. Àmọ́ tọ́rọ̀ náà bá le, tí ò sì yanjú, kí wọ́n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ìjọ, kí wọ́n lè bá wọn yanjú ẹ̀ (ìyẹn àwọn tí Ọlọ́run yàn láti máa múpò iwájú nínú ìjọ). Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn ẹjọ́ tó le, dípò tí wọ́n á fi máa gbé ara wọn lọ sílé ẹjọ́.—Mt 18:15-17; 1Kọ 6:1-8; wo Ọ̀RỌ̀ ẸJỌ́.
JULY 26–AUGUST 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 19-21
“Ẹ̀mí Èèyàn Ṣeyebíye Lójú Jèhófà”
it-1 344
Ẹ̀jẹ̀
Ọlọ́run fẹ́ káwa èèyàn máa gbádùn ẹ̀mí tó fún wa, ẹnikẹ́ni tó bá sì gba ẹ̀mí ẹlòmíì máa jíhìn fún Ọlọ́run. Bí Ọlọ́run ṣe béèrè lọ́wọ́ Kéènì nígbà tó pa àbúrò ẹ̀ nìyẹn, Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ń ké jáde sí mi láti inú ilẹ̀.” (Jẹ 4:10) Kódà tẹ́nì kan bá kórìíra arákùnrin ẹ̀ débi tó fi ń wù ú pé kó kú, bóyá tó bà á lórúkọ jẹ́ tàbí tó jẹ́rìí lòdì sí i, tíyẹn sì mú kí wọ́n gbẹ̀mí ẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ arákùnrin ẹ̀.—Le 19:16; Di 19:18-21; 1Jo 3:15.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 518 ¶1
Ìgbẹ́jọ́
Ẹnubodè ìlú làwọn àgbààgbà ti ń gbọ́ ẹjọ́. (Di 16:18; 21:19; 22:15, 24; 25:7; Rut 4:1) Ibi gbalasa téèyàn máa rí tó bá wọnú ìlú, nítòsí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ni wọ́n ń pè ní “ẹnubodè.” Ẹnubodè yìí ni wọ́n ti máa ń ka Òfin fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ne 8:1-3) Tẹ́nì kan bá fẹ́ ta ohun ìní tàbí ṣe àwọn nǹkan míì, ó máa rọrùn láti rí ẹlẹ́rìí ní ẹnubodè yìí, torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbabẹ̀ kọjá. Bákan náà, torí pé àwọn èèyàn máa ń pọ̀ lẹ́nubodè yìí, àwọn adájọ́ máa ń rí i pé àwọn fara balẹ̀ ṣèwádìí, wọ́n á sì rí i pé wọ́n ṣe ìdájọ́ òdodo. Ó dájú pé wọ́n ṣètò ibì kan sítòsí ẹnubodè ìlú táwọn adájọ́ ti ń gbọ́ ẹjọ́. (Job 29:7) Bí àpẹẹrẹ, Sámúẹ́lì máa ń rìnrìn àjò yí ká Bẹ́tẹ́lì, Gílígálì àti Mísípà, ó sì ń “ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní gbogbo ibí yìí,” ó tún máa ń ṣèdájọ́ tó bá pa dà sílé ẹ̀ ní Rámà.—1Sa 7:16, 17.
AUGUST 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 22-23
“Òfin Tí Jèhófà Ṣe Fi Hàn Pé Ẹ̀mí Àwọn Ẹranko Ṣe Pàtàkì Sí I”
it-1 375-376
Ẹrù
Ẹranko ni wọ́n sábà máa ń fi gbé ẹrù láyé àtijọ́, Jèhófà sì sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tó kórìíra wọn tó ṣubú sábẹ́ ẹrù tó gbé, dípò kí wọ́n fi í sílẹ̀, ṣe ni kí wọ́n “bá a gbé ẹrù náà kúrò.” (Ẹk 23:5) Iye nǹkan tí ẹranko kan lè gbé ni wọ́n máa ń pè ní ẹrù, àpẹẹrẹ kan ni “ẹrù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì.”—2Ọb 5:17.
it-1 621 ¶1
Diutarónómì
Ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn ẹranko nínú ìwé Diutarónómì fi hàn pé ó kà wọ́n sí. Jèhófà sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ mú ẹyẹ tó ń sàba, torí ṣe ló ń dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀, ì bá ti fò lọ ká ní kò sàba. Wọ́n lè kó àwọn ọmọ ẹ̀, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ fi ìyá sílẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ìyá yẹn láti bí àwọn ọmọ míì. (Di 22:6, 7) Jèhófà tún sọ pé àwọn àgbẹ̀ ò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túlẹ̀ pa pọ̀, kí ìnira má bàa pọ̀ jù fún èyí tí ò lágbára nínú wọn. (Di 22:10) Wọn ò tún gbọ́dọ̀ di ẹnu akọ màlúù nígbà tó bá ń pa ọkà, kó má bàa di pé oúnjẹ á wà nítòsí ẹ̀, ebi á sì máa pá, àmọ́ kò ní lè jẹun torí pé wọ́n ti di ẹnu ẹ̀ pa, bẹ́ẹ̀ sì rèé gbogbo agbára ẹ̀ ló fi ń ṣiṣẹ́.—Di 25:4.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 600
Gbèsè, Onígbèsè
Tẹ́nì kan bá yá nǹkan, tí ò sì tíì dá a pa dà tàbí ṣe ohun kan láti san án pa dà, ó ti di gbèsè nìyẹn. Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, àwọn èèyàn sábà máa ń jẹ gbèsè tí wọn ò bá ti lówó lọ́wọ́. Tọ́mọ Ísírẹ́lì kan bá jẹ gbèsè, nǹkan tí ò dáa ni wọ́n kà á sí, torí ṣe ló máa di ẹrú ẹni tó jẹ ní gbèsè. (Owe 22:7) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọ́n gbọ́dọ̀ lawọ́, kí wọ́n má ro tara wọn nìkan tí wọ́n bá fẹ́ yá ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ aláìní lówó, kí wọ́n má sì gba èlé lọ́wọ́ ẹni tíyà ń jẹ. (Ẹk 22:25; Di 15:7, 8; Sm 37:26; 112:5) Àmọ́ wọ́n lè gba èlé lọ́wọ́ àjèjì. (Di 23:20) Nígbà táwọn Júù kan ń sàlàyé bí nǹkan ṣe rí nígbà yẹn, wọ́n ní ẹni tó bá yáwó ṣòwò ni wọ́n máa ń gba èlé lọ́wọ́ ẹ̀, kì í ṣe àwọn aláìní. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń gba èlé lọ́wọ́ àwọn àjèjì, torí pé òwò ló sabá máa ń gbé wọn wá, àti pé àwọn náà máa ń gba èlé tí wọ́n bá yá èèyàn lówó.
AUGUST 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 24-26
“Òfin Tí Jèhófà Ṣe Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Obìnrin”
it-2 1196 ¶4
Obìnrin
Kódà òfin tí Jèhófà ṣe pé ọkùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbèyàwó ò gbọ́dọ̀ lọ sójú ogun fi hàn pé Jèhófà gba ti ìyàwò àti ọkọ rò. Òfin yìí á jẹ́ kí tọkọtaya náà lè bímọ, ọmọ yẹn á sì jẹ́ ìtùnú fún obìnrin náà nígbà tí ọkọ ẹ̀ ò bá sí nílé tàbí tó bá kú sójú ogun.—Di 20:7; 24:5.
it-1 963 ¶2
Pípèéṣẹ́
Ètò tí Jèhófà ṣe fáwọn aláìní yìí fi hàn pé Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ọ̀làwọ́, kí wọ́n máa gba tàwọn míì rò, kí wọ́n sì fọkàn tán Jèhófà pé ó máa bù kún wọn, àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé ó fẹ́ káwọn aláìní ya ọ̀lẹ. Ó jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí Dáfídì sọ pé: “Mi ò tíì rí i kí a pa olódodo tì, tàbí kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” (Sm 37:25) Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣe ohun tí Òfin yìí sọ, àwọn òtòṣì á ṣiṣẹ́ kára, àwọn àtàwọn ọmọ wọn ò sì ní wá oúnjẹ kiri.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 640 ¶5
Ìkọ̀sílẹ̀
Ìwé Ẹ̀rí Ìkọ̀sílẹ̀. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn ṣi òfin nípa ìkọ̀sílẹ̀ lóye nígbà tó yá, àmọ́ kò yẹ kéèyàn rò pé Òfin náà mú kó rọrùn fún ọkọ kan láti kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀. Torí àwọn nǹkan kan wà tó gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ó máa kọ́kọ́ buwọ́ lùwé, kó lè “kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ fún” obìnrin náà. Á wá ‘fi lé e lọ́wọ́, á sì ní kó kúrò ní ilé òun.’ (Di 24:1) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tọ́kùnrin náà máa ṣe, àmọ́ ó dájú pé ó máa fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn àgbààgbà, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n kọ́kọ́ gbìyànjú láti bá àwọn méjèèjì yanjú ọ̀rọ̀ náà. Torí pé ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò láti ṣètò ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ àti láti fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lábẹ́ òfin, ìyẹn lè mú kí ọkùnrin tó fẹ́ kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ tún èrò ẹ̀ pa lórí ọ̀rọ̀ náà. Ọkùnrin kan ò lè dédé kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ láìnídìí, táwọn tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ náà bá ṣe gbogbo ohun tófin sọ, àwọn èèyàn á máa ronú jinlẹ̀ kí wọ́n tó pinnu pé àwọn fẹ́ kọ ìyàwó wọn sílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọkàn àwọn obìnrin á balẹ̀, wọn ò sì ní máa bẹ̀rù pé wọ́n á lé àwọn kúrò nílé ọkọ láìnídìí. Bíbélì ò sọ àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń kọ sínú “ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.”
AUGUST 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 27-28
“Gbogbo Ìbùkún Yìí Máa . . . Bá Ọ”
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 360
Ààlà
Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ sún ààlà ọmọnìkejì wọn sẹ́yìn. (Di 19:14; tún wo Owe 22:28.) Kódà, Jèhófà gégùn-ún fún ẹni tó bá sún “ààlà ọmọnìkejì rẹ̀” sẹ́yìn. (Di 27:17) Lọ́pọ̀ ìgbà, irè oko táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá gbìn sórí ilẹ̀ wọn ni wọ́n máa ń jẹ, torí náà tẹ́nì kan bá sún ààlà ẹlòmíì, ṣe ló ń gba ìjẹ lẹ́nu onítọ̀hún. Ojú ẹni tó jalé ni wọ́n sì fi ń wo ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ láyé àtijọ́. (Job 24:2) Àmọ́ àwọn oníwàkiwà kan máa ń ṣe bẹ́ẹ̀, kódà Bíbélì fi àwọn olórí Júdà nígbà ayé Hósíà wé àwọn tó ń sún ààlà sẹ́yìn.—Ho 5:10.
AUGUST 23-29
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 29-30
“Kò Nira Jù Láti Sin Jèhófà”
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 665 ¶3
Etí
Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà pe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olóríkunkun àti aláìgbọràn ní ‘aláìkọlà etí.’ (Jer 6:10; Iṣe 7:51) Ṣe ló dà bí ìgbà tí nǹkan dí etí wọn. Jèhófà ò ṣí etí wọn, torí pé òun ló máa ń ṣí etí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí wọ́n lè lóye, kí wọ́n sì ṣègbọràn, àmọ́ ó tún máa ń jẹ́ kí etí àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ di, kí wọ́n má bàa fọkàn sí ohun tí wọ́n ń gbọ́. (Di 29:4; Ro 11:8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà táwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni á yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́, tí wọn ò ní fẹ́ fetí sí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ wọ́n á máa tẹ́tí sáwọn olùkọ́ èké, kí wọ́n lè máa fi ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́ “rin wọ́n ní etí.” (2Ti 4:3, 4; 1Ti 4:1) Yàtọ̀ síyẹn, etí ẹnì kan lè máa “hó yee” tó bá gbọ́ ìròyìn burúkú, ní pàtàkì ìròyìn àjálù.—1Sa 3:11; 2Ọb 21:12; Jer 19:3.