-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́—2000 | October 15
-
-
Jèhófà tó ni ẹ̀mí wa pàṣẹ pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Nínú òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì ìgbàanì, ó fi ààlà sí ìlò ẹ̀jẹ̀ nítorí pé ó dúró fún ìwàláàyè. Ó pàṣẹ pé: “Ọkàn [tàbí ìwàláàyè] ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀, èmi tìkára mi sì ti fi sórí pẹpẹ fún yín láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.” Tí ẹnì kan bá wá pa ẹran fún jíjẹ ńkọ́? Ọlọ́run sọ pé: “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde, kí ó sì fi ekuru bò ó.”a (Léfítíkù 17:11, 13) Léraléra ni Jèhófà pa àṣẹ yìí. (Diutarónómì 12:16, 24; 15:23) Ìwé Júù náà, Soncino Chumash sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ gbé pa mọ́ àmọ́ a ní láti sọ ọ́ di aláìwúlò nípa dídà á sórí ilẹ̀.” Kò sí ọmọ Ísírẹ́lì kankan tó gbọ́dọ̀ fa ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá mìíràn, tí ìwàláàyè rẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kí ó tọ́jú rẹ̀ pa mọ́, kó sì wá lò ó.
-
-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́—2000 | October 15
-
-
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, dókítà kan lè rọ aláìsàn kan pé kó fà lára ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ pa mọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ ṣáájú iṣẹ́ abẹ, (Títọ́jú ẹ̀jẹ̀ ara ẹni pa mọ́ ṣáájú iṣẹ́ abẹ, táwọn oníṣègùn ń pè ní PAD), tó fi jẹ́ pé bí ọ̀ràn bá dójú ẹ̀, dókítà lè fa ẹ̀jẹ̀ aláìsàn náà tó ti fi pa mọ́ sí i lára padà. Bó ti wù kó rí, irú gbígba ẹ̀jẹ̀, títọ́jú rẹ̀ pa mọ́ àti fífà á síni lára bẹ́ẹ̀ tako ohun tí Léfítíkù àti Diutarónómì sọ ní tààràtà. A kò gbọ́dọ̀ tọ́jú ẹ̀jẹ̀ pa mọ́; a ní láti dà á nù ni—kí ó padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, Òfin Mósè kọ́ ni à ń lò nísinsìnyí. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà tí Ọlọ́run là sílẹ̀ nínú rẹ̀, wọ́n sì pinnu láti ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀.’ Nítorí náà, a kì í fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kì í tójú ẹ̀jẹ̀ ara wa tó yẹ ká ‘dà jáde’ pa mọ́ fún fífà sára. Àṣà yẹn kò bá òfin Ọlọ́run mu.
-
-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́—2000 | October 15
-
-
a Ọ̀jọ̀gbọ́n Frank H. Gorman kọ̀wé pé: “Dída ẹ̀jẹ̀ jáde ní a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwà ọ̀wọ̀ kan tó ń fi hàn pé èèyàn bọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè ẹran náà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, ẹni tó ṣẹ̀dá ìwàláàyè tó sì tún ń bá a lọ ní títọ́jú rẹ̀.”
-