Ẹ̀KỌ́ 24
Ohun Tó Yẹ Ká Mọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì
Jèhófà fẹ́ ká mọ ìdílé rẹ̀ tó wà lọ́run. Lára àwọn tó wà nínú ìdílé náà ni àwọn áńgẹ́lì tí Bíbélì pè ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Jóòbù 38:7) Kí ni Bíbélì sọ nípa àwọn áńgẹ́lì? Kí ni wọ́n lè ṣe fáwa èèyàn? Ṣé gbogbo àwọn áńgẹ́lì ló jẹ́ ara ìdílé Ọlọ́run?
1. Àwọn wo ni áńgẹ́lì?
Jèhófà ti dá àwọn áńgẹ́lì kó tó dá ayé. Ẹ̀mí ni Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì, ọ̀run ni wọ́n sì ń gbé. (Hébérù 1:14) Àìmọye àwọn áńgẹ́lì ló wà lọ́run, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ síra. (Ìfihàn 5:11) Wọ́n ń ‘ṣe ohun tí Jèhófà sọ, wọ́n sì ń fetí sí ohùn rẹ̀.’ (Sáàmù 103:20) Láyé àtijọ́, Jèhófà máa ń rán àwọn áńgẹ́lì láti lọ jíṣẹ́ fáwọn èèyàn, láti fún wọn lókun, àti láti gbà wọ́n sílẹ̀ nígbà ìṣòro. Lóde òní, àwọn áńgẹ́lì máa ń darí àwọn Kristẹni lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run.
2. Ta ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù?
Àwọn áńgẹ́lì kan ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Áńgẹ́lì àkọ́kọ́ tó ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà ni “ẹni tí à ń pè ní Èṣù àti Sátánì, tó ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà.” (Ìfihàn 12:9) Sátánì fẹ́ máa darí àwọn èèyàn, torí náà ó mú kí ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí Jèhófà, nígbà tó yá ó tún mú kí àwọn áńgẹ́lì míì náà ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí la wá mọ̀ sí àwọn ẹ̀mí èṣù. Jèhófà wá mú ká lé wọn kúrò lọ́run wá sí ayé, wọ́n sì máa pa run láìpẹ́.—Ka Ìfihàn 12:9, 12.
3. Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù lè gbà ṣi àwa èèyàn lọ́nà?
Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù máa ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n máa ń mú káwọn èèyàn da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn tàbí àwọn abẹ́mìílò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn awòràwọ̀, àwọn woṣẹ́woṣẹ́, àwọn aríran, àwọn adáhunṣe tàbí àwọn babaláwo. Táwọn kan bá ń ṣàìsàn, wọ́n máa ń wá ìtọ́jú lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn. Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé wọ́n lè bá àwọn òkú sọ̀rọ̀. Àmọ́, Jèhófà kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ má tọ àwọn abẹ́mìílò lọ. Ẹ má sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn woṣẹ́woṣẹ́.” (Léfítíkù 19:31) Ìdí tí Jèhófà fi fún wa ní ìkìlọ̀ yìí ni pé ó fẹ́ dáàbò bò wá lọ́wọ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù. Ọ̀tá Ọlọ́run ni wọ́n, ńṣe ni wọ́n sì fẹ́ pa wá lára.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tó dáa táwọn áńgẹ́lì máa ń ṣe, ewu tó wà nínú bíbá àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn da nǹkan pọ̀ àti bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù.
4. Àwọn áńgẹ́lì máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà
Àwọn áńgẹ́lì kọ́ ló ń wàásù fáwọn èèyàn ní tààràtà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń darí àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ sọ́dọ̀ àwọn tó bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Ka Ìfihàn 14:6, 7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tá a fi nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn áńgẹ́lì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
Ṣé inú ẹ dùn bó o ṣe mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì lè darí ẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
5. Má ṣe da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn
Ọ̀tá Jèhófà ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù. Wọ́n tún jẹ́ ọ̀tá tiwa náà. Ka Lúùkù 9:38-42, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí làwọn ẹ̀mí èṣù máa ń ṣe fáwọn èèyàn?
A ò gbọ́dọ̀ da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù lọ́nàkọnà. Ka Diutarónómì 18:10-12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń ṣì wọ́n lọ́nà? Àwọn ọ̀nà wo làwọn èèyàn máa ń gbà lọ́wọ́ sí ẹ̀mí òkùnkùn ládùúgbò yín?
Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ pé ká má ṣe bá àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn da nǹkan pọ̀? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Ṣé o rò pé ó léwu bí Palesa ṣe so ońdè mọ́ ọmọ ẹ̀ lọ́wọ́? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Kí ló yẹ kí Palesa ṣe tí kò bá fẹ́ káwọn ẹ̀mí èṣù máa da òun láàmù?
Ọjọ́ pẹ́ táwọn Kristẹni ti ń máa ń gbéjà ko àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù. Ka Iṣe 19:19 àti 1 Kọ́ríńtì 10:21, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tó o bá ní ohunkóhun lọ́wọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí òkùnkùn, kí nìdí tó fi yẹ kó o dáná sun ún?
6. Tó o bá dojú kọ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù, wọ́n máa sá lọ
Sátánì ni alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù. Àmọ́ Máíkẹ́lì ni olórí àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́. Máíkẹ́lì yìí ni orúkọ míìràn tí Jésù ń jẹ́. Báwo ni Máíkẹ́lì ṣe lágbára tó? Ka Ìfihàn 12:7-9, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ta ló lágbára jù nínú Máíkẹ́lì pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ àti Sátánì pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù?
Ṣé o rò pé ó yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa bẹ̀rù Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù?
Tó o bá dojú kọ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù, wọ́n máa sá lọ. Ka Jémíìsì 4:7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e:
Kí lo lè ṣe láti dáàbò bo ara ẹ lọ́wọ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa gbá géèmù tàbí kó máa wo fíìmù ẹlẹ́mìí òkùnkùn. Eré lásán ni.”
Kí nìdí tí èrò yìí fi léwu?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ máa ń ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀tá Jèhófà ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù, wọ́n sì máa ń fi ẹ̀mí òkùnkùn ṣi àwọn èèyàn lọ́nà.
Kí lo rí kọ́?
Báwo ni àwọn áńgẹ́lì ṣe máa ń ran àwon èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?
Ta ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù?
Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí òkùnkùn?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù ni Máíkẹ́lì olú áńgélì.
Ka ìwé yìí kó o lè rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Èṣù kì í ṣe ìwà burúkú tó ń gbé inú èèyàn.
Ka ìwé yìí kó o lè rí bí obìnrin kan ṣe bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.
Ka ìwé yìí kó o lè rí bí Sátánì ṣe máa ń fi ẹ̀mí òkùnkùn ṣi àwọn èèyàn lọ́nà.
“Àṣírí Iṣẹ́ Òkùnkùn” (Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ìsọ̀rí 5)