“Yan Ìyè, Kí o Lè Máa Wà Láàyè Nìṣó”
“Èmi ń fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí, pé èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó.” —DIUTARÓNÓMÌ 30:19.
1, 2. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀?
“JẸ́ KÍ a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa, ní ìrí wa.” Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ yìí wà nínú orí àkọ́kọ́ nínú Bíbélì. Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27 sọ pé “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a.” Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ yàtọ̀ sí gbogbo ohun yòókù tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé. Ó jọ Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ó sì ń fara wé Ọlọ́run nínú bó ṣe ń ronú, nínú bó ṣe ń fi ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti agbára hàn. Ó ní ẹ̀rí ọkàn tó ń ràn án lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tí yóò ṣe é láǹfààní, tí yóò sì mú inú Bàbá rẹ̀ ọ̀run dùn. (Róòmù 2:15) Ní ṣókí, Ádámù ní òmìnira láti yan ohun tó wù ú. Nígbà tí Jèhófà ṣàkíyèsí ọ̀nà tó gbà dá ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, ó sọ èrò rẹ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ yìí, ó ní: “Wò ó! ó dára gan-an ni.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:31; Sáàmù 95:6.
2 Gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Ádámù, àwòrán Ọlọ́run la dá àwa náà, a sì jọ ọ́. Àmọ́, ǹjẹ́ a lómìnira láti yan ohun tó bá wù wá? Bẹ́ẹ̀ ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lè mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, síbẹ̀ kò kádàrá ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe àtohun tí ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa yọrí sí. Ọlọ́run kò kádàrá ìgbésí ayé àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Ká lè lóye bó ti ṣe pàtàkì tó láti lo òmìnira tá a ní láti máa ṣe ìpinnu tó tọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ kan lára orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.—Róòmù 15:4.
Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Lómìnira Láti Yan Ohun Tó Wù Wọ́n
3. Èwo ni òfin kìíní nínú Òfin Mẹ́wàá, báwo sì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ ṣe yàn láti ṣègbọràn sófin náà?
3 Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé àwọn ẹrú.” (Diutarónómì 5:6) Lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nídè lọ́nà ìyanu kúrò lóko ẹrú tí wọ́n wà ní Íjíbítì. Nítorí náà, kò sídìí fún wọn láti máa ṣiyèméjì nípa ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ yẹn. Nínú òfin kìíní lára Òfin Mẹ́wàá, Jèhófà tipasẹ̀ Mósè tó jẹ́ agbẹnusọ rẹ̀ sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn níṣojú mi.” (Ẹ́kísódù 20:1, 3) Lákòókò yẹn, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì yàn láti ṣègbọràn. Gbogbo ọkàn wọn ni wọ́n fi sin Jèhófà.—Ẹ́kísódù 20:5; Númérì 25:11.
4. (a) Àwọn ohun wo ni Mósè fi síwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti yàn? (b) Kí làwa náà lè yàn lónìí?
4 Ní nǹkan bí ogójì ọdún lẹ́yìn náà, taratara ni Mósè fi rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbà yẹn létí ìpinnu tí wọ́n ní láti ṣe. Ó sọ pé: “Èmi ń fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí, pé èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ.” (Diutarónómì 30:19) Lónìí bákan náà, àwa náà lè yan ohun tó wù wá. Bẹ́ẹ̀ ni, a lè yàn láti fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà ká sì máa retí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú, tàbí ká yàn láti ṣàìgbọràn ká sì jìyà ohun tó bá tibẹ̀ yọ. Gbé àpẹẹrẹ méjì yẹ̀ wò nípa àwọn tó yan ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
5, 6. Kí ni Jóṣúà yàn, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
5 Lọ́dún 1473 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jóṣúà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Nínú ọ̀rọ̀ ìyànjú fífakíki tí Jóṣúà sọ kó tó kú, ó pàrọwà fún gbogbo orílẹ̀-èdè náà pé: “Wàyí o, bí ó bá burú ní ojú yín láti máa sin Jèhófà, lónìí yìí, ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín, yálà àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín tí wọ́n wà ní ìhà kejì Odò tẹ́lẹ̀ sìn ni tàbí àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì ní ilẹ̀ àwọn ẹni tí ẹ ń gbé.” Lẹ́yìn náà, ó wá sọ̀rọ̀ nípa ìdílé rẹ̀, ó ní: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”—Jóṣúà 24:15.
6 Ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà ti rọ Jóṣúà pé kó jẹ́ onígboyà kó sì jẹ́ alágbára, kó sì máa ṣègbọràn sí Òfin Ọlọ́run. Ó ní kí Jóṣúà máa ka ìwé Òfin náà ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ lọ́sàn-án àti lóru, èyí yóò sì mú kí ọ̀nà rẹ̀ yọrí sí rere. (Jóṣúà 1:7, 8) Bẹ́ẹ̀ gan-an ló sì rí. Ohun tí Jóṣúà yàn mú kó rí ìbùkún gbà. Jóṣúà polongo pé: “Kò sí ìlérí kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí dáradára tí Jèhófà ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ni ó ṣẹ.”—Jóṣúà 21:45.
7. Lọ́jọ́ Aísáyà, kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì yàn, kí ló sì yọrí sí fún wọn?
7 Àmọ́ àwọn kan ṣe ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí ti Jóṣúà. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn yẹ̀ wò. Lákòókò yẹn, àṣà àwọn kèfèrí lọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń tẹ̀ lé. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ tó kẹ́yìn ọdún, àwọn èèyàn máa ń kóra jọ sídìí tábìlì kan tó kún fún oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn àti ọtí wáìnì dídùn. Èyí kì í kàn án ṣe àpèjẹ ìdílé lásán. Ayẹyẹ ìsìn táwọn abọ̀rìṣà fi ń bọlá fún àwọn òrìṣà méjì kan ni. Wòlíì Aísáyà sọ ojú tí Ọlọ́run fi wo ìwà àìṣòótọ́ yìí, ó ní: “Ẹ̀yin jẹ́ àwọn tí ń fi Jèhófà sílẹ̀, àwọn tí ń gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi, àwọn tí ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire, àti àwọn tí ń bu àdàlù wáìnì kún dẹ́nu fún ọlọ́run Ìpín.” Wọ́n gbà pé “Ọlọ́run Oríire” àti “ọlọ́run Ìpín” tí wọ́n ń tù lójú ló ń mú káwọn rí irè oko tó pọ̀ lọ́dọọdún, wọn ò gbà pé ìbùkún Jèhófà ni. Ká sòótọ́, ńṣe ni ọ̀nà ìṣọ̀tẹ̀ tí wọ́n tọ̀ yẹn àti ohun tí wọ́n yàn yẹn mú kí wọ́n kàgbákò. Jèhófà polongo pé: “Ṣe ni èmi yóò yàn yín sọ́tọ̀ fún idà, gbogbo yín yóò sì tẹrí ba fún ìfikúpa; nítorí ìdí náà pé mo pè, ṣùgbọ́n ẹ kò dáhùn; mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀; ẹ sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú mi, ohun tí èmi kò sì ní inú dídùn sí ni ẹ yàn.” (Aísáyà 65:11, 12) Ohun tí kò bọ́gbọ́n mu tí wọ́n yàn mú ìparun wá sórí wọn, ọlọ́run Ìpín àti ọlọ́run Oríire kò sì lágbára láti dáàbò bò wọ́n.
Bá A Ṣe Lè Yan Ohun Tó Tọ́
8. Gẹ́gẹ́ bí Diutarónómì 30:20 ti wí, kí la lè ṣe láti yan ohun tó tọ́?
8 Nígbà tí Mósè rọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti yan ìyè, ó sọ ohun mẹ́ta tí wọ́n ní láti ṣe, ó ní: “Nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn.” (Diutarónómì 30:20) Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn nǹkan wọ̀nyí yẹ̀ wò ká bàa lè yan ohun tó tọ́.
9. Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà hàn?
9 Nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa: Àwa fúnra wa la yàn láti sin Jèhófà nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ìkìlọ̀ làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ fún wa lónìí. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fún gbogbo ohun tó lè sún wa ṣèṣekúṣe, yóò sì tún mú ká yẹra fun gbígbé ìgbésí ayé tó máa ń múni kó sínú páńpẹ́ ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. (1 Kọ́ríńtì 10:11; 1 Tímótì 6:6-10) Yóò jẹ́ ká lè rọ̀ mọ́ Jèhófà ká sì máa pa ìlànà rẹ̀ mọ́. (Jóṣúà 23:8; Sáàmù 119:5, 8) Ṣáájú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè rọ̀ wọ́n pé: “Wò ó, mo ti kọ́ yín ní àwọn ìlànà àti àwọn ìpinnu ìdájọ́, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run mi ti pàṣẹ fún mi gan-an, fún yín láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní àárín ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń lọ gbà. Kí ẹ sì pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì tẹ̀ lé wọn, nítorí tí èyí jẹ́ ọgbọ́n ní ìhà ọ̀dọ̀ yín àti òye ní ìhà ọ̀dọ̀ yín, lójú àwọn ènìyàn tí yóò gbọ́ nípa gbogbo ìlànà wọ̀nyí.” (Diutarónómì 4:5, 6) Àkókò nìyí láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nípa fífi ìfẹ́ rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa. Dájúdájú, a óò rí ìbùkún gbà tá a bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Mátíù 6:33.
10-12. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Nóà?
10 Nípa fífetí sí ohùn Ọlọ́run: Nóà jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (2 Pétérù 2:5) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn èèyàn tó wà ṣáájú ìkún omi ni ọkàn wọn pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, tí wọn ò sì “fiyè sí” ìkìlọ̀ tí Nóà ń ṣe. Kí ni àbájáde rẹ̀? ‘Ìkún omi dé, ó sì gbá gbogbo wọn lọ.’ Jésù kìlọ̀ pé bí ọjọ́ wa, ìyẹn ìgbà “wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn” yóò ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Nóà jẹ́ ìkìlọ̀ tó lágbára fáwọn èèyàn òde òní tí wọ́n yàn láti má ṣe fiyè sí ohun tí Ọlọ́run ń sọ.—Mátíù 24:39.
11 Ó yẹ káwọn tó ń yínmú sí ìkìlọ̀ táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń kéde lóde òní mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ táwọn bá kọ̀ láti fetí sí ìkìlọ̀ náà. Àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa àwọn olùyọṣùtì yẹn pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn, òtítọ́ yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí wọn, pé àwọn ọ̀run wà láti ìgbà láéláé àti ilẹ̀ ayé kan tí ó dúró digbí-digbí láti inú omi àti ní àárín omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; àti nípasẹ̀ ohun wọnnì, ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 3:3-7.
12 Ohun tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ yàn yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn èèyàn yẹn. “Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà, lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí, fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì.” Nóà fiyè sí ìkìlọ̀, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fáwọn ará ilé rẹ̀ láti rí ìgbàlà. (Hébérù 11:7) Ẹ jẹ́ ká máa yára tẹ́tí sí ohun tí Ọlọ́run ń sọ ká sì máa pa á mọ́ tọkàntọkàn.—Jákọ́bù 1:19, 22-25.
13, 14. (a) Kì nìdí tí ‘fífà mọ́ Jèhófà’ fi ṣe pàtàkì? (b) Ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ kí Jèhófà, “Ẹni tó mọ wá,” tún ìwà wa ṣe?
13 Nípa fífà mọ́ Jèhófà: Láti ‘yan ìyè ká sì máa wà láàyè nìṣó,’ kì í ṣe ọ̀ràn pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ká sì máa fetí sí i nìkan, àmọ́ a tún gbọ́dọ̀ máa ‘fà mọ́ Jèhófà,’ ìyẹn ni pé ká máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nìṣó. Jésù sọ pé: “Nípasẹ̀ ìfaradà níhà ọ̀dọ̀ yín ni ẹ ó fi jèrè ọkàn yín.” (Lúùkù 21:19) Ká sòótọ́, ohun tá a bá yàn ló ń fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Òwe 28:14 sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ń ní ìbẹ̀rùbojo nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n ẹni tí ó sé ọkàn-àyà rẹ̀ le yóò ṣubú sínú ìyọnu àjálù.” Ẹnì kan tó sé ọkàn rẹ̀ le bẹ́ẹ̀ ni Fáráò ti ilẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì. Bí ọ̀kọ̀ọ̀kan Ìyọnu Mẹ́wàá ṣe ń kọ lu Íjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni Fáráò ń sé ọkàn rẹ̀ le dípò kó fi hàn pé òun bẹ̀rù Ọlọ́run. Kì í ṣe Jèhófà ló mú kí Fáráò ya aláìgbọràn, àmọ́ ó kàn yọ̀ǹda kí olùṣàkóso tó jẹ́ agbéraga yẹn yan ohun tó wù ú ni. Ohun yòówù kó jẹ́, ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ojú tí Jèhófà fi wo Fáráò, ó ní: “Fún ìdí yìí gan-an ni mo ṣe jẹ́ kí o máa wà nìṣó, pé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí èmi lè fi agbára mi hàn, àti pé kí a lè polongo orúkọ mi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Róòmù 9:17.
14 Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nídè kúrò lọ́wọ́ Fáráò, wòlíì Aísáyà sọ pé: “Jèhófà, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni Ẹni tí ó mọ wá; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Aísáyà 64:8) Bá a ti ń fún Jèhófà láyè láti mọ wá nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti fífi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣèwàhù, bẹ́ẹ̀ la ó máa dẹni tó ń gbé ànímọ́ tuntun wọ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àá wá dẹni tó túbọ̀ níwà tútù àtẹni tó ṣeé darí, èyí á sì mú kó rọrùn fún wa láti rọ̀ mọ́ Jèhófà tọkàntọkàn nítorí pé a fẹ́ láti múnú rẹ̀ dùn.—Éfésù 4:23, 24; Kólósè 3:8-10.
“Kí O sì Sọ Wọ́n Di Mímọ̀”
15. Gẹ́gẹ́ bí Diutarónómì 4:9 ṣe sọ, ohun méjì pàtàkì wo ni Mósè rán orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì létí pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe?
15 Nígbà tó kù díẹ̀ kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè sọ fún wọn níbi tí wọ́n pé jọ sí pé: “Kìkì pé kí o ṣọ́ra rẹ, kí o sì ṣọ́ ọkàn rẹ gidigidi, kí o má bàa gbàgbé àwọn ohun tí ojú rẹ ti rí àti pé kí wọ́n má bàa lọ kúrò nínú ọkàn-àyà rẹ ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ; kí o sì sọ wọ́n di mímọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ.” (Diutarónómì 4:9) Káwọn èèyàn náà lè rí ìbùkún Jèhófà kí nǹkan sì lè dáa fún wọn nílẹ̀ tí wọ́n fẹ́ jogún náà, ohun méjì pàtàkì kan wà tí Jèhófà Ọlọ́run wọn sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe. Wọn kò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe lójú wọn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ fi wọ́n kọ́ àwọn àtọmọdọ́mọ wọn. Àwa tá a jẹ́ èèyàn Ọlọ́run lónìí ní láti ṣe ohun kan náà bí a bá fẹ́ ‘yan ìyè ká sì máa wà láàyè nìṣó.’ Kí la ti fojú ara wa rí tí Jèhófà ṣe nítorí wa?
16, 17. (a) Kí làwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti gbéṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run? (b) Mẹ́nu kan àpẹẹrẹ àwọn tó o mọ̀ tí wọ́n ń fìtara bá iṣẹ́ náà lọ?
16 Inú wa ń dùn gan-an bá a ti ń rí i tí Jèhófà ń bù kún wa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe. Látìgbà tá a ti ṣí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1943 làwọn míṣọ́nnárì ti ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè. Látìgbà yẹn wá, àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ilé ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀ ṣì ń fìtara wàásù Ìjọba náà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wọn ti ń dara àgbà. Àìlera kò sì jẹ́ kí ara àwọn kan lára wọn gbé kánkán mọ́. Àpẹẹrẹ rere kan ni Mary Olson, tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1944. Ó kọ́kọ́ sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì, ní Uruguay, lẹ́yìn náà ní Kòlóńbíà, ó sì ń bá iṣẹ́ náà lọ báyìí ní Puerto Rico. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìlera tọ́jọ́ ogbó ń fà kò jẹ́ kí Arábìnrin Olson lè ṣe tó bó ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́, síbẹ̀ ó ṣì nítara fún iṣẹ́ ìwàásù. Nítorí pé ó mọ èdè Sípéènì sọ, ó ṣètò àkókò rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti máa bá àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù.
17 Ọdún 1947 ni Nancy Porter tó ti di opó báyìí kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, síbẹ̀ ó ṣì ń sìn ní Bahamas títí di ìsinsìnyí. Òun náà jẹ́ míṣọ́nnárì tọ́wọ́ rẹ̀ dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Arábìnrin Porter sọ nínú ìtàn ìgbésí ayéa rẹ̀ pé: “Kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́ Bíbélì ti jẹ́ orísun ayọ̀ fún mi lọ́nà àkànṣe. Ó jẹ́ kí n ní ìgbòkègbodò tẹ̀mí tó wà létòlétò, èyí tó jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀, kí ó sì lójú.” Nígbà tí Arábìnrin Porter àtàwọn mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá ronú nípa iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, wọn ò jẹ́ gbàgbé ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn. Àwa náà ńkọ́? Ǹjẹ́ à ń fi ẹ̀mí ìmoore hàn nítorí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bù kún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lágbègbè wa?—Sáàmù 68:11.
18. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú kíka ìtàn ìgbésí ayé àwọn míṣọ́nnárì?
18 Ohun táwọn tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọ̀nyí ti gbéṣe àtohun tí wọ́n ń gbéṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ ń múnú wa dùn gan-an. Kíka ìtàn ìgbésí ayé wọn jẹ́ ìṣírí ńláǹlà fún wa nítorí pé rírí tá à ń rí ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn olóòótọ́ wọ̀nyí ń mú ká túbọ̀ pinnu láti sin Jèhófà. Ǹjẹ́ ó máa ń ka irú ìtàn tó ń mórí ẹni wú yìí nínú Ilé Ìṣọ́, ṣé o sì máa ń ronú lé e lórí?
19. Ọ̀nà tó dáa wo làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni lè gbà lo ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn Ọlọ́run tá a kọ sínú Ilé Ìṣọ́?
19 Mósè rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé wọn kò gbọ́dọ̀ gbàgbé gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn, àti pé àwọn nǹkan wọ̀nyí kò gbọ́dọ̀ kúrò lọ́kàn wọn ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. Ó tún wá fi kún un pé: “Kí o sì sọ wọ́n di mímọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ.” (Diutarónómì 4:9) Àwọn ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń wu èèyàn kà gan-an. Àwọn ọ̀dọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà nílò àpẹẹrẹ rere. Àwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ àwọn arábìnrin tó ti dàgbà tí ìtàn ìgbésí ayé wọn wà nínú Ilé Ìṣọ́. Iṣẹ́ ìsìn táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ń ṣe láwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè lórílẹ̀-èdè wọn ń fún wọn láǹfààní láti jẹ́ kọ́wọ́ wọn dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. Ẹ̀yin òbí tó jẹ́ Kristẹni, ẹ ò ṣe máa lo ìtàn ìgbésí ayé àwọn míṣọ́nnárì olóòótọ́ tí wọ́n jáde nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì àti tàwọn ẹlòmíràn láti fún àwọn ọmọ yín níṣìírí kí wọ́n lè fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún ṣe iṣẹ́ tí wọ́n máa fi ìgbésí ayé wọn ṣe?
20. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti “yan ìyè”?
20 Báwo wá lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè “yan ìyè”? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa lílo ẹ̀bùn àgbàyanu tí Jèhófà fún wa, ìyẹn òmìnira yíyan ohun tó wuni, láti fi han pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó tún jẹ́ nípa ṣíṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tó ṣì fún wa láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. “Nítorí,” pé Jèhófà ‘ni ìyè wa àti gígùn ọjọ́ wa,’ gẹ́gẹ́ bí Mósè ṣe polongo.—Diutarónómì 30:19, 20.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ yìí, “Ayọ̀ Mi Kún, Ẹnu Mi Ò sì Gbọpẹ́, Láìka Àdánù Ńláǹlà Sí,” èyí tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ ti June 1, 2001, ojú ìwé 23 sí 27.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ àwọn tó yan ohun tó yàtọ̀ síra tá a ti gbé yẹ̀ wò?
• Àwọn ohun wo la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè “yan ìyè”?
• Ohun pàtàkì méjì wo la rọ̀ wá láti ṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
“Èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Fífetí sí ohùn Ọlọ́run mú kí Nóà àti ìdílé rẹ̀ rí ìgbàlà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Mary Olson
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Nancy Porter