-
Bí Ohun Tí Mósè Gbélé Ayé Ṣe Ṣe Kàn Ọ́Jí!—2004 | April 8
-
-
Wòlíì Kan Bíi Mósè
Àkókò tí nǹkan ò fara rọ là ń gbé. Ó dájú pé aráyé nílò aṣáájú kan bíi Mósè, ẹni kan tí kì í ṣe agbára àti ọlá àṣẹ nìkan ló ní, àmọ́ tó tún jẹ́ oníwà títọ́, onígboyà, aláàánú, tó sì nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ fún ìdájọ́ òdodo. Nígbà tí Mósè kú, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ aráyé á tún rẹ́ni bíi ti Mósè mọ́?’ Mósè fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè náà.
Àwọn ìwé tí Mósè kọ ṣàlàyé ohun náà gan-an tó fa àìsàn àti ikú àti ìdí tí Ọlọ́run fi yọ̀ǹda kí ìwà ibi ṣì máa bá a lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-19; Jóòbù, orí 1, 2) Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ó jẹ́ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé bópẹ́ bóyá, ibi ò ní sí mọ́! Lọ́nà wo? Àsọtẹ́lẹ̀ náà fi hàn pé a óò bí ẹnì kan tí a ó tipasẹ̀ rẹ̀ rí ìgbàlà. Ìlérí yìí ló mú ká nírètí pé Mèsáyà kan yóò dìde tí yóò gba aráyé là. Ṣùgbọ́n, ta ni yóò jẹ́ Mèsáyà náà? Lọ́nà tí kò mú iyèméjì dání, Mósè jẹ́ ká mọ ẹni tí yóò jẹ́.
Nígbà tó kù díẹ̀ kó kú, Mósè sọ àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ yìí: “Wòlíì kan láti àárín ìwọ fúnra rẹ, ní àárín àwọn arákùnrin rẹ, bí èmi, ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò gbé dìde fún ọ—òun ni kí ẹ̀yin fetí sí.” (Diutarónómì 18:15) Nígbà tó ṣe, àpọ́sítélì Pétérù fi hàn pé Jésù ni àwọn ọ̀rọ̀ náà ń tọ́ka sí ní tààràtà.—Ìṣe 3:20-26.
Ńṣe ni ọ̀pọ̀ lára àwọn alálàyé Júù máa ń fi gbogbo ara ta kò ó bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi Mósè àti Jésù wéra. Wọ́n máa ń jiyàn pé àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí lè tọ́ka sí wòlíì tòótọ́ èyíkéyìí lára àwọn tó wá lẹ́yìn Mósè. Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì Tanakh—The Holy Scriptures tí Ẹgbẹ́ Òǹṣèwé Àwọn Júù gbé jáde ṣe sọ, Diutarónómì 34:10 sọ pé: “Wòlíì kan kò sì dìde mọ́ ní Ísírẹ́lì bíi Mósè—ẹni tí OLÚWA dá yà sọ́tọ̀, ní ojúkojú.”
Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì olùṣòtítọ́, bí Aísáyà àti Jeremáyà, dìde lẹ́yìn Mósè. Ṣùgbọ́n kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó ní irú àgbàyanu àjọṣe tí Mósè ní pẹ̀lú Ọlọ́run, ìyẹn ni ti bíbá tó ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ “ní ojúkojú.” Nítorí náà, ó dájú pé ẹnì kan ṣoṣo ni ìlérí tí Mósè ṣe nípa wòlíì kan ‘bíi tòun’ gbọ́dọ̀ tọ́ka sí, ìyẹn ni Mèsáyà náà! Ó tún yẹ ká kíyè sí i pé ṣáájú kí ìsìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀, àti ṣáájú kí inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni èké tó wáyé, báwọn Júù tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà ṣe rò pé ó yẹ kí nǹkan rí nìyẹn. A lè rí ohun tó fara jọ èyí nínú ìwé táwọn Júù kọ, irú bí ìwé Midrash Rabbah, èyí tó ṣàpèjúwe Mósè gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a rán ṣíwájú “Olùràpadà tó ń bọ̀,” tàbí Mèsáyà.
Kò sẹ́ni tó jẹ́ sọ pé bíbá tí Jésù àti Mósè bára dọ́gba ní ọ̀nà tó pọ̀, kì í ṣòótọ́. (Wo àpótí náà, “Jésù—Wòlíì Tó Dà Bíi Mósè.”) Jésù ní agbára àti ọlá àṣẹ. (Mátíù 28:19) Jésù jẹ́ “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà.” (Mátíù 11:29) Jésù kórìíra ìwà ta-ni-yóò-mú-mi àti ìwà ìrẹ́nijẹ. (Hébérù 1:9) Nítorí náà, ó lè ṣe aṣáájú wa lọ́nà tá à ń fẹ́ gan-an! Òun ló máa tó palẹ̀ ìwà ibi mọ́ tí yóò sì mú àwọn ipò tó dà bíi Párádísè tí Bíbélì ṣàpèjúwe wá sórí ilẹ̀ ayé.b
-