Ṣé Òótọ́ Lo Mọrírì Ìgbéyàwó Tó Jẹ́ Ẹ̀bùn Ọlọ́run?
“Kí Jèhófà fún yín ní ẹ̀bùn, kí ẹ sì rí ibi ìsinmi, olúkúlùkù ní ilé ọkọ rẹ̀.”—RÚÙTÙ 1:9.
WÁ ÌDÁHÙN SÍ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́ mọrírì ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run?
Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà fi ọwọ́ pàtàkì mú irú ẹni tá a bá yàn láti bá ṣègbéyàwó?
Ìmọ̀ràn Bíbélì wo lo fẹ́ máa tẹ̀ lé nínú ìgbésí ayé rẹ lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó?
1. Sọ ohun tí Ádámù ṣe nígbà tí Ọlọ́run fún un ní ìyàwó.
“NÍGBẸ̀YÌN-GBẸ́YÍN, èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi. Obìnrin ni a óò máa pe èyí, nítorí pé láti ara ọkùnrin ni a ti mú èyí wá.” (Jẹ́n. 2:23) Inú Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ dùn gan-an ni nígbà tí Ọlọ́run fún un ní ìyàwó! Abájọ tó fi kọ orin ewì yẹn! Lẹ́yìn tí Jèhófà ti mú kí Ádámù sun oorun àsùnwọra, Ó mú ọ̀kan lára àwọn egungun ìhà ọkùnrin náà ó sì fi dá obìnrin tó rẹwà yìí. Lẹ́yìn náà ni Ádámù pe orúkọ rẹ̀ ní Éfà. Ọlọ́run so àwọn méjèèjì pọ̀ nínú ìgbéyàwó aláyọ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé egungun ìhà Ádámù ni Jèhófà fi dá obìnrin náà, Ádámù àti Éfà sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí ju tọkọtaya èyíkéyìí tó wà lóde òní lọ.
2. Kí nìdí tí àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin fi máa ń nífẹ̀ẹ́ síra wọn?
2 Ọgbọ́n Jèhófà tí kò láfiwé mú kó dá òòfà ìfẹ́ mọ́ àwa èèyàn, èyí ló sì ń mú kí àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin máa nífẹ̀ẹ́ síra wọn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ọkùnrin àti obìnrin tó ti ṣègbéyàwó lè ní ìbálòpọ̀, kí òòfà ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn méjèèjì sì máa wà títí lọ.” Èyí sì ti ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà láìmọye ìgbà.
WỌ́N MỌYÌ ÌGBÉYÀWÓ TÓ JẸ́ Ẹ̀BÙN ỌLỌ́RUN
3. Báwo ni Ísákì ṣe rí ìyàwó rẹ̀?
3 Ábúráhámù tó jẹ́ olóòótọ́ ní ọ̀wọ̀ tó ga fún ìgbéyàwó. Nítorí náà, ó rán èyí tó dàgbà jù lọ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí ìlú Mesopotámíà pé kó lọ wá ìyàwó fún Ísákì. Àdúrà tí ìránṣẹ́ yẹn gbà mú kó ṣe àṣeyọrí. Rèbékà tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run di aya ọ̀wọ́n fún Ísákì, ó sì di ọ̀kan lára àwọn tí irú ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù tipasẹ̀ rẹ̀ wá. (Jẹ́n. 22:18; 24:12-14, 67) Kò wá yẹ ká torí èyí ronú pé ó yẹ kí ẹnì kan sọ ara rẹ̀ di ọ̀yọjúràn tó ń báni wá ọkọ tàbí aya, bó ti wù kí ohun tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní lọ́kàn dára tó. Nínú àwùjọ òde òní, ńṣe ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fúnra wọn yan ẹni tí wọ́n máa bá ṣègbéyàwó. Ohun kan ni pé, Ọlọ́run kọ́ ló máa ń báni yan ẹni téèyàn máa fẹ́, àmọ́ bí àwọn Kristẹni bá gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó tọ́ àwọn sọ́nà, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ máa darí wọn, ó máa tọ́ wọn sọ́nà bí wọ́n bá fẹ́ ṣègbéyàwó àti nínú ohun mìíràn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe nínú ìgbésí ayé wọn.—Gál. 5:18, 25.
4, 5. Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Ṣúlámáítì àti olùṣọ́ àgùntàn náà ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ síra wọn?
4 Ọmọbìnrin rírẹwà kan tó ń jẹ́ Ṣúlámáítì ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì kò fẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ òun ti òun láti di ọ̀kan lára àwọn ìyàwó rẹpẹtẹ tí Sólómọ́nì Ọba fẹ́. Ó sọ pé: “Mo ti mú kí ẹ wá sábẹ́ ìbúra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, pé kí ẹ má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.” (Orin Sól. 8:4) Síbẹ̀, Ṣúlámáítì àti olùṣọ́ àgùntàn kan báyìí ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ síra wọn. Ó fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Ìtànná sáfúrónì lásán-làsàn ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ etí òkun ni mo jẹ́, òdòdó lílì ti àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀.” Àmọ́, olùṣọ́ àgùntàn náà fèsì pé: “Bí òdòdó lílì láàárín àwọn èpò ẹlẹ́gùn-ún, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi láàárín àwọn ọmọbìnrin”! (Orin Sól. 2:1, 2) Wọ́n fẹ́ràn ara wọn ní tòótọ́.
5 Torí pé Ṣúlámáítì àti olùṣọ́ àgùntàn náà nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, ó dájú pé ìgbéyàwó wọn máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. Kódà, ọmọbìnrin Ṣúlámáítì náà sọ fún olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀ yẹn pé: “Gbé mi lé ọkàn-àyà rẹ gẹ́gẹ́ bí èdìdì, gẹ́gẹ́ bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí pé ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìfidandanlé ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe sì jẹ́ aláìjuwọ́sílẹ̀ bí Ṣìọ́ọ̀lù. Jíjó rẹ̀ jẹ́ jíjó iná, ọwọ́ iná Jáà [torí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ló ti wá]. Omi púpọ̀ pàápàá kò lè paná ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn odò alára kò lè gbé e lọ. Bí ọkùnrin kan yóò bá fi gbogbo àwọn ohun tí ó níye lórí nínú ilé rẹ̀ fún ìfẹ́, dájúdájú àwọn ènìyàn yóò tẹ́ńbẹ́lú wọn.” (Orin Sól. 8:6, 7) Bí ìránṣẹ́ Jèhófà kan bá ń gbèrò láti ṣègbéyàwó, ǹjẹ́ ó yẹ kó fẹ́ ẹnì kan tí kò ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí i?
YÍYÀN TÁ A BÁ ṢE KAN ỌLỌ́RUN
6, 7. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run fi ọwọ́ pàtàkì mú irú ẹni tá a bá yàn láti bá ṣègbéyàwó?
6 Ọwọ́ pàtàkì ni Jèhófà fi mú irú ẹni tó o bá yàn láti bá ṣègbéyàwó. Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé ní ilẹ̀ Kénáánì pé: “Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ bá wọn dána. Ọmọbìnrin rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi fún ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ sì ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú fún ọmọkùnrin rẹ. Nítorí òun yóò yí ọmọ rẹ padà láti má ṣe tọ̀ mí lẹ́yìn, dájúdájú, wọn yóò sì máa sin àwọn ọlọ́run mìíràn; ní tòótọ́, ìbínú Jèhófà yóò sì ru sí yín, dájúdájú, òun yóò sì pa ọ́ rẹ́ ráúráú ní wéréwéré.” (Diu. 7:3, 4) Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, Ẹ́sírà àlùfáà polongo pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ti ṣe àìṣòótọ́ ní ti pé ẹ fi ibùgbé fún àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè láti lè fi kún ẹ̀bi Ísírẹ́lì.” (Ẹ́sírà 10:10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì sọ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Aya ni a dè ní gbogbo àkókò tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá sùn nínú ikú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹni tí ó bá fẹ́, kìkì nínú Olúwa.”—1 Kọ́r. 7:39.
7 Bí ìránṣẹ́ Jèhófà kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ bá fẹ́ aláìgbàgbọ́, ńṣe ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ hùwà àìgbọràn sí Ọlọ́run. Nígbà ayé Ẹ́sírà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hùwà àìṣòótọ́ nípa fífi “ibùgbé fún àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè,” kò sì tọ́ pé kéèyàn fi ojú tẹ́ńbẹ́lú àlàyé kedere tí Ìwé Mímọ́ ṣe nípa ọ̀rọ̀ náà. (Ẹ́sírà 10:10; 2 Kọ́r. 6:14, 15) Kristẹni kan tó bá ṣègbéyàwó pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ kì í ṣe àpẹẹrẹ rere, kò sì ní ìmọrírì tòótọ́ fún ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run. Bí ẹnì kan bá wọnú irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tó ti ṣe ìrìbọmi ó lè ṣàì kúnjú ìwọ̀n fún àwọn àǹfààní kan láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Kò sì ní bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn máa retí ìbùkún Ọlọ́run, síbẹ̀ kó máa gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, ńṣe ni mo mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí ọ. Àmọ́, mo ṣì fẹ́ kó o bù kún mi.’
BABA WA Ọ̀RUN LÓ MỌ OHUN TÓ DÁRA JÙ LỌ
8. Ṣàlàyé ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nípa ìgbéyàwó.
8 Ó dájú pé ẹni tó ṣe ẹ̀rọ kan mọ bí ẹ̀rọ náà ṣe ń ṣiṣẹ́. Bí ìdí bá wà láti to irú ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ pọ̀, ẹni tó ṣe ẹ̀rọ náà lè pèsè gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ tá a nílò. Ṣùgbọ́n tá a bá kọ̀ láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni rẹ̀ tá a sì to ẹ̀rọ náà bá a ṣe fẹ́ ńkọ́? Bí ẹ̀rọ náà bá tiẹ̀ ṣiṣẹ́ rárá, ó lè fa ìjàǹbá tó lé kenkà. Bí ìgbéyàwó náà ṣe rí nìyẹn, kó tó lè fún wa láyọ̀, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ fún wa.
9. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà mọ ohun tó túmọ̀ sí fún èèyàn láti dá nìkan wà àti bí ìgbéyàwó ṣe lè fúnni láyọ̀?
9 Kò sí ohun tí Jèhófà kò mọ̀ nípa àwa èèyàn àti nípa ìgbéyàwó. Ó dá èèyàn lọ́nà tí wọ́n fi lè ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n lè “máa so èso, kí [wọ́n] sì di púpọ̀.” (Jẹ́n. 1:28) Ọlọ́run mọ ohun tó túmọ̀ sí fún èèyàn láti dá nìkan wà, torí pé kó tó dá obìnrin àkọ́kọ́, ó sọ pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” (Jẹ́n. 2:18) Jèhófà sì tún ní òye kíkún nípa bí ìgbéyàwó ṣe lè fúnni láyọ̀.—Ka Òwe 5:15-18.
10. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí tọkọtaya Kristẹni máa fi sọ́kàn lórí ọ̀rọ̀ àjọṣe lọ́kọláya?
10 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tí ìran èèyàn ti jogún látọ̀dọ̀ Ádámù nígbà tó dẹ́ṣẹ̀, kò sí ìgbéyàwó kankan tí kò lábùkù lákòókò tá a wà yìí. Àmọ́, láàárín àwa ìránṣẹ́ Jèhófà, ìgbéyàwó lè mú ká ní ojúlówó ayọ̀ tá a bá tẹ̀ lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ìtọ́ni tó ṣe kedere tí Pọ́ọ̀lù fúnni nípa ìbálòpọ̀ láàárín tọkọtaya. (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:1-5.) Ìwé Mímọ́ kò sọ pé torí ọmọ bíbí nìkan ṣoṣo ni tọkọtaya fi lè ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ara wọn. Irú àjọṣe lọ́kọláya bẹ́ẹ̀ lè wáyé kí tọkọtaya lè ní ìfararora tímọ́tímọ́ kí wọ́n sì fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn síra wọn. Àmọ́, ìbálòpọ̀ lọ́nà òdì kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Láìsí àní-àní, àwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ Kristẹni yóò fẹ́ láti fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú apá pàtàkì yìí nínú ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n sì mú kó jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí ara wọn. Síbẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ sá fún ṣíṣe ohunkóhun tí wọ́n bá mọ̀ pé ó máa bí Jèhófà nínú.
11. Báwo ni Rúùtù ṣe rí ìbùkún gbà torí pé ó ṣe àwọn nǹkan ní ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́?
11 Ńṣe ló yẹ kí ìgbéyàwó máa fúnni láyọ̀, kò yẹ kó máa bani nínú jẹ́ tàbí kó dà bí iṣẹ́ tí kò gbádùn mọ́ni. Ní pàtàkì jù lọ, ibi ìsinmi àti àlàáfíà ló yẹ kí ilé Kristẹni jẹ́. Ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún sẹ́yìn nígbà tí opó tó jẹ́ àgbàlagbà náà, Náómì àti àwọn aya àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì táwọn náà jẹ́ opó, Ópà àti Rúùtù, wà lójú ọ̀nà tó ti Móábù lọ sí Júdà. Náómì rọ àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn wọn. Rúùtù tó jẹ́ ará Móábù kò fẹ́ fi Náómì sílẹ̀, ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run òtítọ́, a sì mú kó dá a lójú pé ‘owó ọ̀yà pípé wà fún un láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, lábẹ́ ìyẹ́ apá ẹni tó wá láti wá ìsádi.’ (Rúùtù 1:9; 2:12) Torí pé Rúùtù ní ìmọrírì àtọkànwá fún ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run, ó di ìyàwó Bóásì tó jẹ́ àgbàlagbà tó sì tún jẹ́ olùjọsìn tòótọ́ fún Jèhófà. Nígbà tí Rúùtù bá jíǹde nínú ayé tuntun Ọlọ́run, inú rẹ̀ máa dùn láti mọ̀ pé òun di ìyá ńlá Jésù Kristi. (Mát. 1:1, 5, 6; Lúùkù 3:23, 32) Ẹ wo bí ìbùkún tó rí gbà ṣe pọ̀ tó torí pé ó ṣe àwọn nǹkan ní ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́!
ÌMỌ̀RÀN TÓ GBÉṢẸ́ NÍPA BÍ ÌGBÉYÀWÓ ṢE LÈ YỌRÍ SÍ RERE
12. Ibo la ti lè rí ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ nípa ìgbéyàwó?
12 Ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ sọ ohun tó yẹ ká mọ̀ fún wa nípa bí ìgbéyàwó ṣe lè yọrí sí rere. Kò sí èèyàn kankan tí ìmọ̀ rẹ̀ tó ti Ọlọ́run. Gbogbo ìgbà ni Bíbélì máa ń tọ̀nà, ọ̀nà kan ṣoṣo tí ẹnikẹ́ni sì lè gbà máa fiyè sí ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó ni pé kó rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfé. 5:33) Kò sí ohunkóhun nínú ìtọ́ni Bíbélì yẹn tí àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn kò lè lóye. Ṣùgbọ́n ibi tí ọ̀rọ̀ wà ni pé, Ǹjẹ́ wọ́n máa fi Ọ̀rọ̀ Jèhófà sílò? Wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n mọrírì ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run.a
13. Kí ló lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ tí a kò bá fi ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Pétérù 3:7 sílò?
13 Ńṣe ló yẹ kí ọkọ tó jẹ́ Kristẹni máa fi ìfẹ́ bá aya rẹ̀ lò. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo, níwọ̀n bí ẹ tún ti jẹ́ ajogún ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí pẹ̀lú wọn, kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.” (1 Pét. 3:7) Àdúrà ọkọ kan lè ní ìdènà bí kò bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà. Ìyẹn lè ṣe ìpalára fún àjọṣe tí àwọn méjèèjì ní pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sì lè mú kí nǹkan má fara rọ nínú ìdílé, kí ìjà máa ṣẹlẹ̀, kí wọ́n sì máa le koko mọ́ ara wọn.
14. Bí ìyàwó bá jẹ́ ẹni tó ń fi ìfẹ́ hàn, ipa wo ni ìyẹn lè ní lórí ìdílé?
14 Ìyàwó tó bá ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Jèhófà àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ máa darí òun lè ṣe púpọ̀ láti mú kí ilé rẹ̀ jẹ́ ibi àlàáfíà àti ayọ̀. Ó bá ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá wa mu pé kí ọkọ tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ kó sì máa dáàbò bò ó nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ìyàwó náà á fẹ́ kí ọkọ òun máa fìfẹ́ hàn sí òun, èyí tó fi hàn pé ìyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ṣeé fìfẹ́ hàn sí. Òwe 14:1 sọ pé: “Obìnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ òmùgọ̀ a fi ọwọ́ ara rẹ̀ ya á lulẹ̀.” Ìyàwó tó gbọ́n tó sì ń fi ìfẹ́ hàn máa ń ṣe ohun táá mú kí ìdílé rẹ̀ ṣe àṣeyọrí kí ayọ̀ sì gbilẹ̀ níbẹ̀. Ó tún máa ń fi hàn pé lóòótọ́ ni òun mọrírì ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run.
15. Ìmọ̀ràn wo ló wà nínú Éfésù 5:22-25?
15 Bí àwọn tọkọtaya bá wà ní ìṣọ̀kan torí pé wọ́n ń fi ọ̀nà tí Jésù gbà bá ìjọ rẹ̀ lò ṣe àwòkọ́ṣe, ìyẹn á fi hàn pé wọ́n ń fi ìmoore hàn fún ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run. (Ka Éfésù 5:22-25.) Ẹ sì wo bí ìbùkún tí àwọn tọkọtaya máa gbádùn á ṣe pọ̀ tó bí wọ́n bá ní ojúlówó ìfẹ́ síra wọn tí wọn kò sì jẹ́ kí ìgbéraga, bíbára ẹni yan odì tàbí àwọn ìwà míì tí kò yẹ ká bá lọ́wọ́ Kristẹni ba ìgbéyàwó àwọn jẹ́!
KÍ ẸNIKẸ́NI MÁ ṢE YÀ WỌ́N SỌ́TỌ̀
16. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni kan kò fi ṣègbéyàwó?
16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń wu ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn pé kí wọ́n ṣègbéyàwó, síbẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan wà tí kò ṣègbéyàwó torí pé wọn kò rí ẹni tó wù wọ́n láti fẹ́ tó sì tún ṣètẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run. Àwọn míì sì wà tí wọ́n ní ẹ̀bùn wíwà láìlọ́kọ tàbí aya, èyí tó mú kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà láìsí ìpínyà ọkàn tí ìgbéyàwó máa ń fà. Àmọ́ ṣá o, àwọn tí kò bá ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn kò ré ìlànà Jèhófà kọjá.—Mát. 19:10-12; 1 Kọ́r. 7:1, 6, 7, 17.
17. (a) Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jésù sọ nípa ìgbéyàwó tó yẹ ká fi sọ́kàn? (b) Bí Kristẹni èyíkéyìí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ojúkòkòrò ọkọ tàbí aya ẹlòmíì, kí ló yẹ kó ṣe ní kíámọ́sá?
17 Yálà a ṣègbéyàwó tàbí a kò ṣègbéyàwó, gbogbo wa la gbọ́dọ̀ fi ọ̀rọ̀ Jésù sọ́kàn. Ó ní: “Ẹ kò ha kà pé [Ọlọ́run] tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’? Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:4-6) Ṣíṣe ojúkòkòrò ọkọ tàbí ìyàwó ẹlòmíì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. (Diu. 5:21) Bí irú ìfẹ́ búburú yìí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sọ́kàn Kristẹni èyíkéyìí, ńṣe ni kó yára mú un kúrò lọ́kàn ní kíámọ́sá, kódà, bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá tiẹ̀ mú kó ní ìrora ọkàn tó pọ̀ torí pé òun ló ti kọ́kọ́ fàyè gba irú ìfẹ́ ìmọtara-tara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀. (Mát. 5:27-30) Ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn wá nǹkan ṣe sí irú èrò bẹ́ẹ̀ kó sì mú ìfẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó wá látinú ọkàn-àyà tó ṣe àdàkàdekè yìí kúrò.—Jer. 17:9.
18. Ojú wo lo rò pé ó yẹ ká máa fi wo ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run?
18 Kódà, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó jẹ́ pé díẹ̀ ni wọ́n mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu látọ̀dọ̀ rẹ̀ tàbí tí wọn kò tilẹ̀ mọ̀ nípa rẹ̀ rárá ti fi hàn dé ìwọ̀n àyè kan pé àwọn mọyì ètò tí Ọlọ́run ṣe pé kí ọkùnrin àti obìnrin máa fẹ́ra. Mélòómélòó wá ni àwa tá a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà “Ọlọ́run aláyọ̀”? Ńṣe ló yẹ ká máa yọ̀ nítorí gbogbo ohun tí Jèhófà ti pèsè fún wa ká sì fi ẹ̀rí hàn pé lóòótọ́ la mọrírì ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run!—1 Tím. 1:11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìgbéyàwó, wo orí 10 àti 11 nínú ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.’
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Ìgbéyàwó tó dára máa ń fi ọlá fún Jèhófà ó sì lè mú kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ní ayọ̀ tó pọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Rúùtù fi ìmọrírì hàn fún ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ǹjẹ́ ò ń fi hàn pé òótọ́ lo mọrírì ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Jèhófà?