“Bójú Tó Àjàrà Yìí”!
ÀWỌN amí méjìlá kan rìn jákèjádò Ilẹ̀ Ìlérí. Mósè ló rán wọn pé kí wọ́n lọ wo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà kí wọ́n sì mú lára àwọn èso ibẹ̀ wá. Èso wo ló wù wọ́n jù láti mú wá? Èso àjàrà tí wọ́n rí nínú ọgbà àjàrà kan nítòsí ìlú Hébúrónì ni. Èso rẹ̀ tóbi débi pé àwọn amí méjì ló ru òṣùṣù àjàrà kan ṣoṣo. Àwọn amí yìí pe ilẹ̀ ọlọ́ràá tí wọ́n ti rí àjàrà náà ní “àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Éṣíkólì,” ìyẹn àfonífojì Òṣùṣù Èso Àjàrà, nítorí bí èso ibẹ̀ ṣe tóbi tó sì dára tó.—Númérì 13:21-24.
Ní nǹkan bí igba ọdún sẹ́yìn, ẹnì kan tó ṣèbẹ̀wò sí ilẹ̀ Palẹ́sínì ròyìn pé: “Àjàrà ṣì pọ̀ lọ súà ní Éṣíkólì tàbí àfonífojì Èso Àjàrà, . . . èso àjàrà wọ̀nyẹn ló tóbi jù tó sì tún dára jù ní ilẹ̀ Palẹ́sínì.” Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àjàrà Éṣíkólì ló ta yọ ní gbogbo ilẹ̀ Palẹ́sínì, àmọ́ ibi tó pọ̀ jù lọ ni àjàrà ti ń ṣe dáadáa gan-an lágbègbè náà. Kódà àkọsílẹ̀ àwọn ará Íjíbítì fi hàn pé àwọn ọba ilẹ̀ Íjíbítì máa ń ránṣẹ́ lọ ra wáìnì ní ilẹ̀ Kénáánì.
Ìwé The Natural History of the Bible sọ pé: “Jíjẹ́ táwọn ilẹ̀ ẹ̀bá òkè [ní Palẹ́sínì] jẹ́ ilẹ̀ olókùúta àti iyanrìn tí oòrùn ń ràn sí dáadáa, tí wọ́n sì tún jẹ́ ibi tó máa ń móoru nígbà ẹ̀ẹ̀rùn tí kì í sì í gba omi òjò dúró pẹ́ nígbà òtútù, ló mú kí ibẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ àjàrà.” Ìwé Aísáyà fi hàn pé àwọn ibì kan níbẹ̀ ní igi àjàrà tó pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún.—Aísáyà 7:23.
“Ilẹ̀ Àjàrà”
Mósè sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé ilẹ̀ “àjàrà àti ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì” ni wọ́n ń lọ. (Diutarónómì 8:8) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Baker Encyclopedia of Bible Plants sọ pé: “Àjàrà pọ̀ gan-an nílẹ̀ Palẹ́sínì ayé ọjọ́un débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ibi tí wọ́n bá ti walẹ̀ ni wọ́n ti máa ń rí kóró èso àjàrà.” Àjàrà Ilẹ̀ Ìlérí máa ń so dáadáa gan-an, tó fi jẹ́ pé nígbà táwọn ọmọ ogun Nebukadinésárì sọ ilẹ̀ Júdà dahoro lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ Júdà ṣì “kó wáìnì àti èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn jọ ní ìwọ̀n púpọ̀ rẹpẹtẹ.”—Jeremáyà 40:12; 52:16.
Kí àwọn àgbẹ̀ ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó lè rí wáìnì púpọ̀ látinú àjàrà wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ tọ́jú àwọn igi àjàrà náà dáadáa. Ìwé Aísáyà sọ̀rọ̀ nípa bí ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olùrẹ́wọ́ àjàrà ṣe máa ń walẹ̀ ẹ̀bá òkè, tí yóò sì kó àwọn òkúta ńláńlá ibẹ̀ kúrò kó tó gbin “ààyò àjàrà pupa” sínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó lè wá fi àwọn òkúta tó kó kúrò yẹn mọ ògiri yí ọgbà àjàrà náà ká. Ògiri yẹn kò ní jẹ́ kí àwọn ẹran ọ̀sìn máa tẹ ọgbà àjàrà náà mọ́lẹ̀, kò sì ní jẹ́ kí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, ìmàdò àtàwọn olè lè ráyè wọlé. Olóko tún lè gbẹ́ ibi ìfúntí wáìnì síbẹ̀, kó sì kọ́ ilé gogoro kékeré kan tí yóò jẹ́ ibi tó tutù tí yóò máa wà nígbà ìkórè tó jẹ́ ìgbà tí àjàrà ń fẹ́ ààbò gan-an. Ìgbà tó bá ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí tán ló tó lè máa retí pé kí àjàrà òun so wọ̀ǹtì-wọnti.—Aísáyà 5:1, 2.a
Àwọn àgbẹ̀ tó lóko àjàrà máa ń rẹ́wọ́ àwọn àjàrà náà déédéé kí wọ́n lè so dáadáa, wọ́n sì máa ń roko rẹ̀ kí èpò àti ẹ̀gún má bàa bò ó. Wọ́n lè bomi rin ọgbà àjàrà náà nígbà ẹ̀rùn tí òjò ò bá pọ̀ tó nígbà òjò.—Aísáyà 5:6; 18:5; 27:2-4.
Ìgbà ayọ̀ yíyọ̀ gidi ni ìgbà ìkórè àjàrà máa ń jẹ́ ní ìparí ìgbà ẹ̀rùn. (Aísáyà 16:10) Lára ohun tí wọ́n kọ sí àkọlé orí mẹ́ta nínú ìwé Sáàmù ni, “lórí Gítítì.” (Sáàmù 8, 81 àti 84) Bíbélì Septuagint pe èdè àwọn olórin tí ìtumọ̀ rẹ̀ ó dá wa lójú yìí ní “àwọn ibi ìfúntí wáìnì,” èyí tó fi hàn pé ó lè jẹ́ ìgbà ìkórè àjàrà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọ àwọn sáàmù yìí. Wáìnì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi èso àjàrà ṣe ní pàtàkì àmọ́ wọ́n tún máa ń jẹ èso àjàrà tó bá pọ́n tàbí kí wọ́n sá a títí yóò fi gbẹ, èyí tí wọ́n lè fi ṣe ìṣù èso àjàrà.—2 Sámúẹ́lì 6:19; 1 Kíróníkà 16:3.
Àjàrà Ísírẹ́lì
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni Bíbélì fi àwọn èèyàn Ọlọ́run wé àjàrà, ìyẹn sì jẹ́ àfiwé tó bá a mu gan-an tá a bá wo bí àjàrà ṣe ṣe pàtàkì sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó. Nínú Sáàmù ọgọ́rin, Ásáfù fi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wé àjàrà tí Jèhófà gbìn sí ilẹ̀ Kénáánì. Ńṣe ni Jèhófà pa ilẹ̀ Kénáánì mọ́ kí àjàrà náà, ìyẹn Ísírẹ́lì, lè ta gbòǹgbò kó sì dàgbà dáadáa. Àmọ́ bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ògiri tó dáàbò bò ó wó lulẹ̀. Ìyẹn ni pé nígbà tí orílẹ̀-èdè náà kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà mọ́, òun náà ò dáàbò bò wọ́n mọ́. Làwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá bá bẹ̀rẹ̀ sí í kó ọrọ̀ Ísírẹ́lì bí ìgbà tí ìmàdò já wọ ọ̀gbà àjàrà tó sì ba ibẹ̀ jẹ́. Ìdí nìyẹn tí Ásáfù fi gbàdúrà pé kí Jèhófà gba orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ kó lè tún padà ní irú ògo tó ní tẹ́lẹ̀. Ó pàrọwà sí Ọlọ́run pé kó “bójú tó àjàrà yìí.”—Sáàmù 80:8-15.
Aísáyà fi “ilé Ísírẹ́lì” wé ọgbà àjàrà tó di èyí tó ń so “èso àjàrà ìgbẹ́” tàbí èso kíkẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. (Aísáyà 5:2, 7) Èso àjàrà ìgbẹ́ máa ń kéré gan-an sí èso àjàrà táwọn àgbẹ̀ máa ń gbìn, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ níṣu lára torí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kóró ló ń gba gbogbo inú rẹ̀. Àjàrà ìgbẹ́ kò dára fún wáìnì ṣíṣe, bẹ́ẹ̀ ni kò dára fún jíjẹ. Irú àjàrà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tó dára gan-an láti fi ṣàpèjúwe orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà náà, èyí tó kún fún ìwà ìrúfin dípò kó máa so èso òdodo. Síso tí wọ́n ń so èso tí kò wúlò kì í ṣe ẹ̀bi Jèhófà tó jẹ́ olóko. Gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe ni Jèhófà ti ṣe kí orílẹ̀-èdè náà lè méso jáde. Ìyẹn ló fi béèrè pé: “Kí ni ó tún kù tí ó yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà mi tí n kò tíì ṣe sínú rẹ̀?”—Aísáyà 5:4.
Níwọ̀n bí àjàrà Ísírẹ́lì, ìyẹn àwọn èèyàn Jèhófà, kò ti so èso, Jèhófà sọ fún wọn pé òun máa wó ògiri tóun mọ láti fi dáàbò bò wọ́n. Ó lóun ò ní rẹ́wọ́ àjàrà ìṣàpẹẹrẹ náà mọ́, òun ò sì ní roko rẹ̀ mọ́. Òjò tí àjàrà náà nílò kò ní rọ̀, ẹ̀gún àti epò yóò sì kún bo ọgbà àjàrà náà.—Aísáyà 5:5, 6.
Mósè sọ tẹ́lẹ̀ pé tí Ísírẹ́lì bá di apẹ̀yìndà, kódà ọgbà àjàrà gidi tí wọ́n ní pàápàá yóò gbẹ dà nù. Ó ní: “Àwọn ọgbà àjàrà ni ìwọ yóò gbìn, tí ìwọ yóò sì ro dájúdájú, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní mu wáìnì kankan, ìwọ kò sì ní kó nǹkan kan wọlé, nítorí pé kòkòrò mùkúlú yóò jẹ ẹ́ tán.” (Diutarónómì 28:39) Àjàrà lè gbẹ dà nù láàárín ọjọ́ mélòó kan bí kòkòrò bá kó wọnú igi rẹ̀ tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ẹ́ nínú.—Aísáyà 24:7.
“Àjàrà Tòótọ́”
Bí Jèhófà ṣe fi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wé àjàrà ni Jésù náà lo àjàrà láti fi ṣe àfiwé kan. Nígbà tí Jésù ń fi ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni aroko.” (Jòhánù 15:1) Jésù fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wé ẹ̀ka àjàrà yìí. Bí àwọn ẹ̀ka àjàrà gidi ṣe gbára lé igi àjàrà náà làwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀. Jésù ní: “Láìsí mi, ẹ kò lè ṣe nǹkan kan rárá.” (Jòhánù 15:5) Bí àwọn àgbẹ̀ ṣe máa ń gbin àjàrà tìtorí èso rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ń retí pé káwọn èèyàn òun so èso nípa tẹ̀mí. Ìyẹn ni yóò múnú Ọlọ́run tó loko dùn, tí yóò sì gbé e ga.—Jòhánù 15:8.
Kí àjàrà gidi tó lè so dáadáa, olùrẹ́wọ́ àjàrà ní láti rẹ́wọ́ rẹ̀ kó sì tún jẹ́ kí ara rẹ̀ mọ́. Jésù tọ́ka sí ohun méjèèjì tí olùrẹ́wọ́ àjàrà máa ń ṣe yìí nínú àpèjúwe rẹ̀. Ó lè rẹ́wọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún kó lè so èso tó bó ṣe yẹ. Ní àsìkò òtútù, ó lè gé èyí tó pọ̀ gan-an lára ẹ̀ka àjàrà rẹ̀ dà nù. Ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀ka tó hù lọ́dún tó kọjá lọ ni yóò rẹ́ kúrò lára rẹ̀. Ó lè wá fi ẹ̀ka ńláńlá mẹ́ta tàbí mẹ́rin tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ máa ní èèhù kan tàbí méjì sílẹ̀ lára igi àjàrà náà. Àwọn èèhù yìí, tó máa rí bí èyí tó wà lára àjàrà náà lọ́dún tó kọjá lọ, ni yóò mú èso jáde nígbà ẹ̀ẹ̀rùn tó máa dé lẹ́yìn náà. Tí olùrẹ́wọ́ àjàrà bá rẹ́ àwọn ẹ̀ka náà tán, yóò wá dáná sun àwọn tó rẹ kúrò náà.
Jésù sọ̀rọ̀ nípa rírẹ́ tí wọ́n máa ń rẹ́ èyí tó pọ̀ gan-an lára ẹ̀ka àjàrà dà nù yìí, ó ní: “Bí ẹnikẹ́ni kò bá dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, a ó ya á dànù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kan, a sì gbẹ; àwọn ènìyàn a sì kó ẹ̀ka wọnnì jọ, wọn a sì gbé wọn sọ sínú iná, wọn a sì jóná.” (Jòhánù 15:6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ka àjàrà náà máa dín kù gan-an lẹ́yìn tí wọ́n bá rẹ́wọ́ rẹ̀ tán, síbẹ̀ wọ́n tún ṣì máa rẹ́ àwọn kọ̀ọ̀kan lára ẹ̀ka yòókù dà nù nígbà ìrúwé.
Jésù sọ pé: “Gbogbo ẹ̀ka tí ń bẹ nínú mi tí kì í so èso ni ó ń mú kúrò.” (Jòhánù 15:2) Ó lè jẹ́ pé èyí tí wọ́n máa ń gé dà nù nígbà tó bá yá yìí ni Jésù ń wí. Èyí máa ń jẹ́ lásìkò tí àwọn èèhù míì ti yọ jáde dáadáa lára àjàrà náà táwọn òṣùṣù èso àjàrà sì ti ń fara hàn dáadáa. Olùrẹ́wọ́ àjàrà máa fẹ̀sọ̀ yẹ ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan wò lásìkò náà láti wo èyí tó léso àti èyí tí kò ní. Tó bá fi èyí tí kò léso sílẹ̀ lára àjàrà náà, yóò kàn máa gba omi àti oúnjẹ ara igi àjàrà lásán ni. Nítorí náà, olóko yóò rẹ́ gbogbo ẹ̀ka tí kò léso yẹn dà nù kí gbogbo oúnjẹ tí àjàrà náà bá rí lè wà fún kíkí àwọn ẹ̀ka tó léso.
Níkẹyìn Jésù wá sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa ń mú kí ara ẹ̀ka àjàrà mọ́. Ó ní: “Gbogbo èyí tí ó sì ń so èso ni ó ń wẹ̀ mọ́, kí ó lè so èso púpọ̀ sí i.” (Jòhánù 15:2) Lẹ́yìn tí olùrẹ́wọ́ àjàrà bá ti rẹ́ àwọn ẹ̀ka tí kò léso kúrò, yóò wá fẹ̀sọ̀ wo ẹ̀ka tó léso lọ́kọ̀ọ̀kan. Àwọn èèhù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ sábà máa ń wà nídìí àwọn ẹ̀ka yẹn tó yẹ kó rẹ́ kúrò pẹ̀lú. Tó bá fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n dàgbà, wọ́n á máa fa oúnjẹ àti omi ara àjàrà náà tó yẹ kó mú èso rẹ̀ tóbi dáadáa. Ó tún lè gé lára àwọn ewé rẹ̀ tó bá tóbi kúrò kí oòrùn lè túbọ̀ ta sí àwọn èso àjàrà tó ń dàgbà náà lára. Gbogbo nǹkan yìí ló máa ṣe sí àwọn ẹ̀ka eléso náà kó bàa lè so èso púpọ̀ gan-an.
‘Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Síso Èso Púpọ̀’
Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló dúró fún àwọn ẹ̀ka ìṣàpẹẹrẹ tí “àjàrà tòótọ” ní. Síbẹ̀ “àwọn àgùntàn mìíràn” náà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn náà jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi tó ń mésò jáde. (Jòhánù 10:16) Ó ṣeé ṣe fáwọn náà láti “so èso púpọ̀” kí wọ́n sì máa gbé ògo Baba wọn ọ̀run ga. (Jòhánù 15:5, 8) Àpèjúwe àjàrà tóòtọ́ tí Jésù lò ń mú ká rántí pé ẹni tí yóò bá rí ìgbàlà ní láti wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi kó sì máa so èso dáadáa nípa tẹ̀mí. Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 15:10.
Nígbà ayé Sekaráyà, Ọlọ́run ṣèlérí fáwọn àṣẹ́kù tó jẹ́ olóòótọ́ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé “irú-ọmọ àlàáfíà” yóò padà wà ní ilẹ̀ wọn, àti pé “àjàrà yóò mú èso rẹ̀ wá, ilẹ̀ pàápàá yóò sì mú èso rẹ̀ jáde.” (Sekaráyà 8:12) Bákan náà, Bíbélì fi àjàrà ṣàpèjúwe àlàáfíà tí àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò ní nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi. Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.”—Míkà 4:4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ pé àwọn àgbẹ̀ ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ràn àjàrà tó máa ń so èso pupa rẹ́súrẹ́sú tí wọ́n ń pè ní sorek, irú èyí tó jọ pé Aísáyà 5:2 ń sọ. Wáìnì pupa tó dùn ni wọ́n máa ń rí látinú irú èso àjàrà yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àjàrà kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àjàrà tí wọ́n rẹ́wọ́ rẹ̀ nígbà òtútù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Wọ́n ń jó àwọn ẹ̀ka tí wọ́n gé kúrò