Bó O Ṣe Lè Fi Ọgbọ́n Ọlọ́run Yọ Àwọn Ọmọ Rẹ Nínú Ewu
OJOOJÚMỌ́ ni ìwàyá ìjà ń lọ nínú àgọ́ ara wa. Ara wa ní láti gbógun ti àwọn kòkòrò tá ò lè fojú rí tó ń fa àrùn. A dúpẹ́ pé wọ́n bí ohun tó ń dènà àrùn nínú ara mọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ wa. Èyí ni kò jẹ́ ká máa kó oríṣiríṣi àrùn.
Lọ́nà kan náà, àwa Kristẹni ò gbọ́dọ̀ fàyè gba àwọn èrò àtàwọn ìwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu àtàwọn ẹ̀tàn Sátánì tó lè ba tiwa jẹ́ nípa tẹ̀mí. (2 Kọ́ríńtì 11:3) Ká má bàa juwọ́ sílẹ̀ fáwọn èròkérò tó ń wá sí wa lọ́kàn lójoojúmọ́ yìí, ó ṣe pàtàkì ká mọ àwọn ọ̀nà tá a lè gbà dáàbò bo ara wa nípa tẹ̀mí.
Àwọn ọmọ wa gan-an ló nílò ààbò yìí jù, nítorí pé a ò bí àwọn ohun tí wọ́n lè fi dènà ẹ̀mí ayé mọ́ wọn. (Éfésù 2:2) Báwọn ọmọ ṣe ń dàgbà, ó ṣe pàtàkì káwọn òbí ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dáàbò bo ara wọn nípa tẹ̀mí. Báwo la ṣe lè rí ààbò yìí? Bíbélì ṣàlàyé pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; . . . yóò sì máa ṣọ́ ọ̀nà àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.” (Òwe 2:6, 8) Ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá lè ṣọ́ àwọn èwe, àwọn tó jẹ́ pé láìní ọgbọ́n yìí, wọ́n lè lọ máa kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe máa darí wọn, tàbí kí wọ́n máa ṣe àwọn eré ìnàjú tí kò yẹ ọmọlúwàbí. Báwo làwọn òbí ṣe lè tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà kí wọ́n sì gbin ọgbọ́n Ọlọ́run sọ́kàn àwọn ọmọ wọn?
Bí Wọ́n Ṣe Lè Rí Alábàákẹ́gbẹ́ Rere
A mọ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ láti wà pẹ̀lú àwọn ojúgbà wọn, àmọ́ bó bá jẹ́ àwọn ọ̀dọ́ bí tiwọn nìkan ni wọ́n ń bá rìn, kò ní ṣeé ṣe fún wọn láti ní ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá kí wọ́n sì lò ó. Ìwé Òwe kìlọ̀ pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.” (Òwe 22:15) Ọ̀nà wo làwọn òbí kan ti wá gbà ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti lo ọgbọ́n nínú ọ̀ràn yíyan alábàákẹ́gbẹ́ rere?
Bàbá kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Dona sọ pé: “Àwọn ọmọ wa ọkùnrin àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn jọ máa ń ṣeré dáadáa. Inú ilé wa ni wọ́n ti máa ń ṣeré jù, a sì máa ń rí i pé a wà níbẹ̀. A máa ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ lálejò nínú ilé wa. A máa ń fún wọn lóunjẹ a ò sì ń fi nǹkan kan ni wọ́n lára. A ò jẹ́ kí ariwo àwọn ọmọ náà àti bí wọ́n ṣe ń sá sókè sá sódò nínú ilé bí wa nínú, torí pé a fẹ́ kí wọ́n gbádùn ara wọn níbi tójú wa á ti lè tó wọn.”
Ọmọ mẹ́ta ni Brian àti Mary bí, àwọn ọmọ náà sì ń ṣe dáadáa, síbẹ̀ wọ́n sọ pé kò rọrùn rárá láti tọ́ àwọn ọmọ náà. Tọkọtaya náà sọ pé: “Nínú ìjọ wa, kò fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ tí ọmọ wa obìnrin tó ń jẹ́ Jane lè máa bá rìn. Ṣùgbọ́n ó lọ́rẹ̀ẹ́ kan tó ń jẹ́ Susan. Ara ọmọbìnrin náà yá mọ́ni ó sì jẹ́ ẹnì kan tó bẹ. Ṣùgbọ́n ọwọ́ táwa fi mú Jane kọ́ làwọn òbí Susan fi mú ọmọ tiwọn. Àwọn òbí rẹ̀ kì í sọ̀rọ̀ tó bá pẹ́ níta, tó bá wọ síkẹ́ẹ̀tì péńpé, tó bá gbọ́ orinkórin tàbí tó bá lọ wo àwọn sinimá tí kò bójú mu. Àmọ́ àwa ò fàyè irú ìyẹn gba Jane ní tiwa, ó sì pẹ́ kí ohun tá à ń sọ tó yé Jane. Lójú ẹ̀, àwọn òbí Susan rọ́ọ̀ọ́kán jù wá lọ, èrò ẹ̀ ni pé a ti le jù. Àmọ́ ìgbà tí Susan kan ìdin nínú iyọ̀ ni Jane tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé ààbò ńlá ló jẹ́ fóun bá ò ṣe gba ìgbàkugbà láyè. Inú wa dùn gan-an pé a ò fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ọmọ wa.”
Bíi ti Jane, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ti rí i pé ó bọ́gbọ́n mu káwọn jẹ́ kí àwọn òbí àwọn tọ́ àwọn sọ́nà nínú ọ̀ràn irú ẹni tó yẹ́ kí àwọ́n máa bá rìn. Ìwé Òwe sọ pé: “Etí tí ń fetí sí ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ìyè a máa gbé láàárín àwọn ọlọ́gbọ́n.” (Òwe 15:31) Ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá yóò jẹ́ káwọn èwe mọ irú ẹni tó yẹ kí wọ́n máa bá rìn.
Bí Àwọn Ọmọ Ṣe Lè Borí Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe
Yàtọ̀ sí ìṣòro alábàákẹ́gbẹ́, ìṣòro mìíràn tó tún wà ní fífẹ́ láti ṣe bí àwọn mìíràn. Ìgbà gbogbo làwọn ọmọ wa ń kojú ìṣòro yìí. Níwọ̀n bí àwọn ọ̀dọ́ ti sábà máa ń fẹ́ káwọn ẹlẹgbẹ́ wọn gba tiwọn, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun táráyé kà sí nǹkan gidi.—Òwe 29:25.
Bíbélì rán wa létí pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (1 Jòhánù 2:17) Nípa bẹ́ẹ̀, kò yẹ káwọn òbí gba àwọn ọmọ wọn láyé láti máa ṣe ohun táyé ń ṣe. Báwo ni wọ́n ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti máa ronú lọ́nà tó yẹ Kristẹni?
Richard sọ pé: “Irú aṣọ táwọn ọmọ mìíràn ń wọ̀ lọmọ mi obìnrin máa ń fẹ́ wọ̀. Nítorí náà, tó bá lóun fẹ́ irú aṣọ kan, a máa ń fi sùúrù ṣàlàyé ibi tí aṣọ náà dára sí àti ibi tí kò dára sí. Kódà, ní ti àwọn aṣọ tá a sọ pé kò burú pàápàá, ìmọ̀ràn kan tá a gbọ́ lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn là ń tẹ̀ lé. Ìmọ̀ràn náà ni pé, ‘Ọlọ́gbọ́n èèyàn kì í yára bẹ́ mọ́ àṣà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé kì í sì í gbẹ̀yìn sídìí rẹ̀.’”
Ọ̀nà tí ìyá kan tó ń jẹ́ Pauline gbà ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe yàtọ̀. Ó ní: “Tí n bá rí i pé àwọn ọmọ mi nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan kan, mo máa ń fẹ́ láti mọ̀ nípa nǹkan náà, ìgbà gbogbo ni mo sì máa ń lọ sínú yàrá wọn láti bá wọn sọ̀rọ̀. Bá a ṣe jọ máa ń sọ̀rọ̀ gan-an yìí jẹ́ kí n láǹfààní láti tọ́ wọn sọ́nà kí n sì jẹ́ kí wọ́n rí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa gbà wo nǹkan.”
Ìfẹ́ láti ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe ò ní kúrò lọ́kàn àwọn ọmọ o. Ìyẹn ló fi pọn dandan káwọn òbí máa sapá láti ‘dojú àwọn ìrònú ayé yìí dé’ lọ́kàn àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìrònú wọn “wá sí oko òǹdè, láti ṣègbọràn sí Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 10:5) Nítorí náà, báwọn òbí àtàwọn ọmọ bá ń “ní ìforítì nínú àdúrà,” Ọlọ́run á fún wọn ní okun láti borí ìṣòro ńlá yìí.—Róòmù 12:12; Sáàmù 65:2.
Bí Eré Ìnàjú Ṣe Lágbára Tó
Ìṣòro mìíràn tó lè má rọrùn fáwọn òbí láti bójú tó ni ọ̀rọ̀ eré ìnàjú. Àwọn ọmọdé fẹ́ràn eré gan-an. Àwọn ọmọ tó ti dàgbà náà sì máa ń wá ohun tí wọ́n á fi dára wọn lára yá. (2 Tímótì 2:22) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ọ̀nà tí kò tọ́ ni wọ́n ń gbà ṣe é, èyí lè ṣàkóbá fún wọn nípa tẹ̀mí. Ọ̀nà méjì pàtàkì ni ewu yìí máa ń gbà yọjú.
Àkọ́kọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan táráyé kà sí eré ìnàjú ló jẹ́ pé ìwà ẹ̀gbin wọn ló ń gbé yọ. (Éfésù 4:17-19) Síbẹ̀, wọ́n máa ń ṣe é lọ́nà táwọn èèyàn á fi gbádùn rẹ̀ tá sì fà wọ́n mọ́ra. Ewu ńlá lèyí jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ o, torí pé wọ́n lè máà rí àwọn ìṣòro náà.
Èkejì, àkókò téèyàn ń lò nídìí eré ìnàjú tún lè fa ọ̀pọ̀ ìṣòro. Eré ṣíṣe ti di nǹkan pàtàkì nígbèésí ayé àwọn kan débi pé, àkókò àti okun tí wọ́n máa ń lo nídìí ẹ̀ máa ń pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Ìwé Òwe kìlọ̀ pé “jíjẹ oyin ní àjẹjù kò dára.” (Òwe 25:27) Bákan náà ló rí pẹ̀lú eré ìnàjú, bó bá ti pọ̀ jù, ebi tẹ̀mí ò ní fi bẹ́ẹ̀ pani mọ́, èèyàn ò sì ní lè ronú nípa nǹkan mìíràn mọ́. (Òwe 21:17; 24:30-34) Táwọn ọ̀dọ́ bá làwọn fẹ́ jẹ ayé yìí dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, kò ní jẹ́ kí wọ́n lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” ìyẹn ìyè ayérayé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀. (1 Tímótì 6:12, 19) Ọ̀nà wo làwọn òbí kan ti gbà kápá ìṣòro yìí?
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Mari Carmen tó lọ́mọ obìnrin mẹ́ta sọ pé: “A fẹ́ káwọn ọmọ wa gbádùn eré ìnàjú tó dára kí inú wọn sì dùn. Fún ìdí yìí, a jọ máa ń ṣeré jáde látìgbàdégbà, wọ́n sì máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn nínú ìjọ. Ṣùgbọ́n a ò jẹ́ kí àṣejù wọ̀ ọ́. Bí ohun ìpápánu la ka eré ìnàjú sí, èèyàn máa ń gbádùn ẹ̀, àmọ́ òun kọ́ lolórí oúnjẹ. Àwọn ọmọ wa mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ nínú ilé, ní iléèwé àti nínú ìjọ.”
Don àti Ruth ò ka eré ìnàjú sí ohun tí kò ṣe pàtàkì. Wọ́n sọ pé: “A ya ọjọ́ Sátidé sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tá a máa ń gbádùn ara wa nínú ìdílé wa. Àá lọ sóde ìwàásù láàárọ̀, àá lọ lúwẹ̀ẹ́ lọ́sàn-án, a ó sì jẹ àkànṣe oúnjẹ lálẹ́.”
Gbólóhùn àwọn òbí wọ̀nyí jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì káwa Kristẹni wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ká máa ṣe eré ìtura tó bójú mu ká má sì jẹ́ kó ṣèdíwọ́ fún nǹkan tẹ̀mí nínú ìgbésí ayé wa.—Oníwàásù 3:4; Fílípì 4:5.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
Síbẹ̀, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ọdún káwọn ọmọ tó lè ní ọgbọ́n tí wọ́n á fi dáàbò bò ara wọn nípa tẹ̀mí. Kò sóògùn ajẹ́bíidán tó lè gbin ọgbọ́n Ọlọ́run sọ́kàn àwọn ọmọ wa, tó máa jẹ́ kí wọ́n nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú Baba wọn ọ̀run. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn òbí ní láti “máa bá a nìṣó ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo túmọ̀ sí pé káwọn òbí máa ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti rí nǹkan lọ́nà tí Ọlọ́run gbà rí i. Báwo làwọn òbí ṣe lè ṣe èyí?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé tó ń wáyé déédéé loògùn rẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ‘máa ń la àwọn ọmọ lójú sí àwọn ohun àgbàyanu inú òfin Ọlọ́run.’ (Sáàmù 119:18) Diego kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, èyí sì jẹ́ kó lè ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà. Ó sọ pé: “Mo máa ń múra sílẹ̀ dáadáa fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Mó máa ń ṣèwádìí nínú àwọn ìwé tó dá lórí Ìwé Mímọ́, màá sì ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tó máa fi dà bíi pé àwọn ọmọ mi ń fojú rí àwọn èèyàn tí Bíbélì dárúkọ. Mo máa ń ní kí wọ́n wò ó bóyá ìgbésí ayé wọn jọ tàwọn olóòótọ́ wọ̀nyí. Èyí jẹ́ kí ohun tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí ṣe kedere sáwọn ọmọ mi kí wọ́n sì máa rántí wọn dáadáa.”
Kì í ṣe ìgbà tá a bá pe àwọn ọmọ jókòó nìkan ni wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́. Mósè rọ àwọn òbí pé kí wọ́n máa sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn ọmọ wọn ‘nígbà tí wọ́n bá jókòó nínú ilé àti nígbà tí wọ́n bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí wọ́n bá dìde.’ (Diutarónómì 6:7) Bàbá kan sọ pé: “Kò rọrùn fún ọmọ mi láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Àmọ́ bá a ṣe jọ wá ń rìn jáde tá a sì jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, ó ti wá rọrùn fún un láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún mi. Láwọn àkókò wọ̀nyí, a máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó jinlẹ̀ gan-an to sì ń ṣe àwa méjèèjì láǹfààní.”
Àdúrà àwọn òbí tún máa ń nípa lórí àwọn ọmọ wọn gan-an. Gbígbọ́ táwọn ọmọ ń gbọ́ táwọn òbí wọn ń bẹ Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ àti ìdáríjì máa ń mú kí wọ́n “gbà gbọ́ pé [Jèhófà] ń bẹ.” (Hébérù 11:6) Ọ̀pọ̀ àwọn òbí tó ti tọ́mọ ní àtọ́yanjú ló sọ pé ó ṣe pàtàkì kí ìdílé máa gbàdúrà pa pọ̀. Lára àwọn ohun tí wọ́n sì lè máa gbàdúrà nípa rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn nǹkan mìíràn tó máa ń dààmú ọkàn àwọn ọmọ wọn. Bàbá kan sọ pé ìgbà gbogbo ni ìyàwó òun máa ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn kí wọ́n tó lọ síléèwé.—Sáàmù 62:8; 112:7.
“Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí A Juwọ́ Sílẹ̀ ní Ṣíṣe Ohun Tí Ó Dára”
Kò sí òbí tí kì í ṣàṣìṣe, wọ́n sì lè máa kábàámọ̀ ọ̀nà tí wọ́n ti gbà ṣe àwọn nǹkan kan sẹ́yìn. Síbẹ̀, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa sapá nìṣó, ká má ṣe “juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára.”—Gálátíà 6:9.
Ṣùgbọ́n nígbà míì, ó lè máa ṣe àwọn òbí bíi pé kí wọ́n juwọ́ sílẹ̀ nígbà tọ́rọ̀ àwọn ọmọ wọn ò bá yé wọn mọ́. Ó lè rọrùn láti sọ pé àwọn ọmọ òde ìwòyí yàtọ̀ àti pé kò rọrùn láti tọ́ wọn. Àmọ́ ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kùdìẹ̀-kudiẹ táwọn ọmọ ayé òde òní ní náà làwọn tàtijọ́ ní, àwọn ìdẹwò tó sì kojú àwọn ọmọ àtijọ́ ló ń kojú àwọn tòní náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tó ń múni dẹ́ṣẹ̀ lè ti pọ̀ sí i. Èyí ló mú bàbá kan fohùn pẹ̀lẹ́ sọ fọ́mọ rẹ̀ ọkùnrin lẹ́yìn tó ti bá a wí tán pé: “Ṣé o rí i, ohun tó wà lọ́kàn rẹ láti ṣe yìí ló máa ń wà lọ́kàn tèmi náà nígbà tí mo wà bíi tìẹ.” Àwọn òbí lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ bí kọ̀ǹpútà ṣe ń ṣiṣẹ́, àmọ́ wọ́n mọ àwọn ohun tí ẹran ara máa ń fẹ́ ti àwọn ọmọ ṣe.—Mátíù 26:41; 2 Kọ́ríńtì 2:11.
Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ kan má ka ìtọ́sọ́nà àwọn òbí wọn sí, kí wọ́n tiẹ̀ máa yarí tí wọ́n bá ń bá wọn wí pàápàá. Àmọ́ bá a ṣe sọ níṣàájú, ìfaradà ṣe pàtàkì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ kan lè máa kọ etí ikún sáwọn òbí wọn tẹ́lẹ̀ kí wọ́n má sì kà wọ́n sí, ọ̀pọ̀ lára wọn ló máa ń ṣe dáadáa nígbà tó bá yá. (Òwe 22:6; 23:22-25) Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Matthew, tó ń sìn ní ọ̀kan lára ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́langba, mo máa ń rò pé òfin àwọn òbí mi ti le jù. Màá máa rò ó lọ́kàn mi pé ṣebí àwọn òbí àwọn ọmọ míì ń gbà wọ́n láyè láti ṣe àwọn nǹkan kan, kí ló dé tí tàwọn òbí mi fi yàtọ̀? Inú máa ń bí mi gan-an nígbà míì tí mo bá ṣẹ̀ tí wọn ò sì jẹ́ kí n lọ fi ọkọ̀ ojú omi ṣeré, mo sì fẹ́ràn eré yẹn gan-an. Ṣùgbọ́n tí n bá wá ronú padà sẹ́yìn báyìí, mo rí i pé ìbáwí táwọn òbí mi fún mi ràn mí lọ́wọ́ gan-an mo sì nílò rẹ̀. Mo dúpẹ́ pé wọ́n fún mi ní ìtọ́sọ́nà náà lákòókò tí mo nílò rẹ̀.”
Òótọ́ kan tó dájú ni pé, báwọn ọmọ wa ò bá tiẹ̀ kọ́kọ́ ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí, wọ́n ṣì lè di Kristẹni tó ń ṣe dáadáa bí wọ́n ti ń dàgbà. Bí Bíbélì ti ṣèlérí, ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá lè jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dáàbò bò ara wọn nípa tẹ̀mí. “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá, agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, láti dá ọ nídè kúrò ní ọ̀nà búburú.”—Òwe 2:10-12.
Kí obìnrin fi oṣù mẹ́sàn-án ru oyún kò rọrùn. Kí ọmọ náà sì tó wá pé ogún ọdún rèé, kò sọ́gbọ́n tí ohun tó máa ba òbí nínú jẹ́ ò fi ní wáyé. Ṣùgbọ́n nítorí pé àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n máa ń sa gbogbo ipá wọn láti fi ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá dáàbò bò wọ́n. Bọ́rọ̀ ṣe rí lára àpọ́sítélì Jòhánù tó jẹ́ arúgbó nípa àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí ló rí lára àwọn òbí náà. Jòhánù sọ pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”—3 Jòhánù 4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
“A máa ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ lálejò nínú ilé wa”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ó yẹ káwọn òbí fẹ́ láti mọ̀ nípa nǹkan táwọn ọmọ wọn nífẹ̀ẹ́ sí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
“Mo máa ń múra sílẹ̀ dáadáa fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà”