“Ohun Tí O Jẹ́jẹ̀ẹ́, San Án”
‘O gbọ́dọ̀ san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Jèhófà.’—MÁT. 5:33.
1. (a) Kí ni Jẹ́fútà Onídàájọ́ àti Hánà fi jọra? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
AṢÁÁJÚ tó jẹ́ akínkanjú ni Jẹ́fútà, jagunjagun tí kì í bẹ̀rù sì ni. Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Hánà, ó ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ Ẹlikénà, ó sì mọ ilé tọ́jú. Olùjọ́sìn Jèhófà ni Jẹ́fútà Onídàájọ́ àti Hánà. Yàtọ̀ síyẹn, kí lohun míì táwọn méjèèjì tún fi jọra? Àwọn méjèèjì ló jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ. Àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tá a yàn láti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún un. Àmọ́, àwọn ìbéèrè kan wà tó yẹ ká béèrè: Kí ló túmọ̀ sí tá a bá léèyàn jẹ́jẹ̀ẹ́? Báwo ni ẹ̀jẹ́ téèyàn jẹ́ fún Ọlọ́run ṣe lágbára tó? Kí la rí kọ́ lára Jẹ́fútà àti Hánà?
2, 3. (a) Kí ló túmọ̀ sí tá a bá léèyàn jẹ́jẹ̀ẹ́? (b) Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa ẹ̀jẹ́ téèyàn jẹ́ fún Ọlọ́run?
2 Nínú Bíbélì, téèyàn bá jẹ́jẹ̀ẹ́ ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún ṣèlérí fún Ọlọ́run lẹ́yìn tó ti ronú dáadáa pé òun á gbé ìgbésẹ̀ kan tàbí pé òun á fún Ọlọ́run ní ohun kan tàbí pé òun á ṣe àkànṣe iṣẹ́ kan. Ó sì lè jẹ́ pé òun á máa yàgò fún àwọn nǹkan kan. Wọn kì í fipá mú ẹnikẹ́ni jẹ́jẹ̀ẹ́. Síbẹ̀ lójú Ọlọ́run, ohun mímọ́ ni ẹ̀jẹ́ tẹ́nì kan jẹ́, àìgbọ́dọ̀máṣe sì ni. Ìdí ni pé téèyàn bá jẹ́jẹ̀ẹ́, ṣe lonítọ̀hún búra pé òun máa ṣe ohun kan tàbí pé òun ò ní ṣe é. (Jẹ́n. 14:22, 23; Héb. 6:16, 17) Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa bí ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ fún Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó?
3 Òfin Mósè sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà tàbí tí ó ṣe ìbúra kan . . . , kí ó má ṣẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó jáde ní ẹnu rẹ̀ ni kí ó ṣe.” (Núm. 30:2) Nígbà tó yá, ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí Sólómọ́nì sọ pé: “Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti san án, nítorí pé kò sí níní inú dídùn sí àwọn arìndìn. Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án.” (Oníw. 5:4) Jésù náà jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹ̀jẹ́ jíjẹ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré nígbà tó sọ pé: “A sọ ọ́ fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ búra láìmúṣẹ, ṣùgbọ́n ìwọ gbọ́dọ̀ san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Jèhófà.’ ”—Mát. 5:33.
4. (a) Kí nìdí tá a fi sọ pé kéèyàn jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré? (b) Kí la máa kọ́ nípa Jẹ́fútà àti Hánà?
4 Ó ṣe kedere pé kéèyàn jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré rárá. Ọwọ́ tá a bá fi mú ẹ̀jẹ́ wa lè mú kí Ọlọ́run fojúure wò wá tàbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀. Dáfídì sọ pé: ‘Ta ní lè gun orí òkè ńlá Jèhófà, ta sì ni ó lè dìde ní ibi mímọ́ rẹ̀? Ẹni tí kò búra ẹ̀tàn.’ (Sm. 24:3, 4) Ẹ̀jẹ́ wo ni Jẹ́fútà àti Hánà jẹ́, báwo ló sì ṣe rọrùn fún wọn tó láti san án?
WỌ́N SAN Ẹ̀JẸ́ TÍ WỌ́N JẸ́ FÚN ỌLỌ́RUN
5. Ẹ̀jẹ́ wo ni Jẹ́fútà jẹ́, kí ló sì wá ṣẹlẹ̀?
5 Jẹ́fútà ṣe ohun tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà nígbà tó fẹ́ lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jagun, torí pé ó pẹ́ tí wọ́n ti ń fojú pọ́n àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Oníd. 10:7-9) Ó wu Jẹ́fútà gan-an pé kó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì, ló bá jẹ́jẹ̀ẹ́ pé: “Bí o bá fi àwọn ọmọ Ámónì lé mi lọ́wọ́ láìkùnà, yóò sì ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú pé ẹni tí ó bá ń jáde bọ̀, tí ó jáde wá láti àwọn ilẹ̀kùn ilé mi láti pàdé mi nígbà tí mo bá padà dé ní àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, òun pẹ̀lú yóò di ti Jèhófà.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Jẹ́fútà ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì, ó sì ṣẹlẹ̀ pé ọmọbìnrin kan ṣoṣo tí Jẹ́fútà bí ló sáré wá pàdé rẹ̀ nígbà tó dé. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ọmọbìnrin náà máa “di ti Jèhófà.” (Oníd. 11:30-34) Kí nìyẹn máa gba pé kí ọmọbìnrin náà ṣe?
6. (a) Báwo ló ṣe rọrùn tó fún Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ láti san ẹ̀jẹ́ tí Jẹ́fútà jẹ́? (b) Kí ni Diutarónómì 23:21, 23 àti Sáàmù 15:4 kọ́ ẹ tó bá di pé kó o jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run?
6 Kí Jẹ́fútà tó lè san ẹ̀jẹ́ tó jẹ́, ó máa gba pé kí ọmọ rẹ̀ fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn. Ṣé Jẹ́fútà kò ronú jinlẹ̀ kó tó jẹ́jẹ̀ẹ́ yẹn ni? Ó dájú pé ó rò ó dáadáa. Ó lè ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ọmọ òun náà ló máa jáde wá pàdé òun. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá, torí pé ó máa gba pé káwọn méjèèjì yááfì ohun kan. Nígbà tí Jẹ́fútà rí ọmọbìnrin rẹ̀, ṣe ló ‘fa ẹ̀wù ara rẹ̀ ya’ ó sì sọ pé ọ̀rọ̀ náà kó ẹ̀dùn ọkàn bá òun. Ọmọbìnrin náà wá lọ “sunkún lórí ipò wúńdíá” rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jẹ́fútà kò lọ́mọ ọkùnrin, ọmọbìnrin kan ṣoṣo tó ní yìí kò sì ní lọ́kọ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé á bímọ. Torí náà, bí Jẹ́fútà kò ṣe ní lọ́mọ-ọmọ túmọ̀ sí pé orúkọ ìdílé rẹ̀ lè pa rẹ́. Àmọ́, kì í ṣe ìyẹn ló ṣe pàtàkì jù sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́fútà sọ pé: ‘Mo ti la ẹnu mi sí Jèhófà, èmi kò sì lè yí i pa dà.’ Ọmọ náà wá fèsì pé: “Ṣe sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó ti ẹnu rẹ jáde.” (Oníd. 11:35-39) Kò sí àní-àní pé adúróṣinṣin làwọn méjèèjì, ohun tó sì wà lọ́kàn wọn ni bí wọ́n ṣe máa mú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ fún Ọlọ́run Olódùmarè ṣẹ, láìka ohun tó máa ná wọn sí.—Ka Diutarónómì 23:21, 23; Sáàmù 15:4.
7. (a) Ẹ̀jẹ́ wo ni Hánà jẹ́, kí sì nìdí tó fi jẹ́jẹ̀ẹ́ náà? Kí ló wá ṣẹlẹ̀? (b) Kí ni ẹ̀jẹ́ tí Hánà jẹ́ máa gba pé kí Sámúẹ́lì ṣe? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
7 Àpẹẹrẹ ẹlòmíì tó ṣe ohun tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà ni Hánà. Nǹkan ò dẹrùn fún un lásìkò tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà torí pé kò rọ́mọ bí, bẹ́ẹ̀ sì ni orogún rẹ̀ ń fojú pọ́n ọn. (1 Sám. 1:4-7, 10, 16) Hánà sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Jèhófà, ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, láìkùnà, bí ìwọ yóò bá wo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ níṣẹ̀ẹ́, tí o sì rántí mi ní ti tòótọ́, tí ìwọ kì yóò sì gbàgbé ẹrúbìnrin rẹ, tí o sì fún ẹrúbìnrin rẹ ní ọmọ tí ó jẹ́ ọkùnrin ní ti tòótọ́, èmi yóò fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ fẹ́lẹ́ kì yóò sì kan orí rẹ̀.”a (1 Sám. 1:11) Ọlọ́run gbọ́ àdúrà Hánà, ó sì bímọ ọkùnrin. Ẹ wo bí ìyẹn ṣe máa múnú rẹ̀ dùn tó! Síbẹ̀, kò gbàgbé ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún Ọlọ́run. Nígbà tó bí ọmọ náà, ó sọ pé: “Ọwọ́ Jèhófà ni mo ti béèrè rẹ̀.”—1 Sám. 1:20.
8. (a) Báwo ló ṣe rọrùn tó fún Hánà láti mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ? (b) Báwo lọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 61 ṣe rán ẹ létí àpẹẹrẹ rere tí Hánà fi lélẹ̀?
8 Gbàrà tí Hánà já Sámúẹ́lì lẹ́nu ọmú nígbà tó pé nǹkan bí ọdún mẹ́ta, ó mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún Ọlọ́run ṣẹ. Kò tiẹ̀ rò ó pé ẹ̀ẹ̀mejì. Ó mú Sámúẹ́lì lọ bá Élì Àlùfáà Àgbà tó wà níbi àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò, ó wá sọ pé: “Ọmọdékùnrin yìí ni mo gbàdúrà nípa rẹ̀ pé kí Jèhófà yọ̀ǹda ìtọrọ tí mo ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀. Èmi, ẹ̀wẹ̀, sì ti wín Jèhófà. Ní gbogbo ọjọ́ tí ó bá wà, ẹni tí a béèrè fún Jèhófà ni.” (1 Sám. 1:24-28) Níbẹ̀, ‘Sámúẹ́lì ń bá a lọ ní dídàgbà lọ́dọ̀ Jèhófà.’ (1 Sám. 2:21) Àmọ́ báwo nìyẹn ṣe rí lára Hánà? Ó dájú pé ó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ gan-an, àmọ́ kò ní sí pẹ̀lú rẹ̀ bó ṣe ń dàgbà. Ká ló wà pẹ̀lú rẹ̀ ni, á ní ìrírí táwọn ìyá tó ń tọ́mọ máa ń ní, bí wọ́n ṣe ń gbé ọmọ wọn mọ́ra, tí wọ́n ń bá a ṣeré, tí wọ́n ń tọ́jú rẹ̀, tí wọ́n sì ń rí bọ́mọ náà ṣe ń sáré síbí sọ́hùn-ún. Láìka gbogbo ìyẹn sí, Hánà kò kábàámọ̀ pé òun mú ẹ̀jẹ́ òun ṣẹ. Ṣe ló ń yọ̀ nínú Jèhófà.—1 Sám. 2:1, 2; ka Sáàmù 61:1, 5, 8.
9. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn báyìí?
9 Ní báyìí tá a ti mọ̀ pé ẹ̀jẹ́ téèyàn jẹ́ fún Ọlọ́run kì í ṣe ohun ṣeréṣeré, ẹ jẹ́ ká wá jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Irú ẹ̀jẹ́ wo làwa Kristẹni máa ń jẹ́? Bákan náà, ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú ẹ̀jẹ́ tá a bá jẹ́?
Ẹ̀JẸ́ ÌYÀSÍMÍMỌ́ RẸ
10. Ẹ̀jẹ́ wo ló ṣe pàtàkì jù tí Kristẹni kan lè jẹ́, kí nìyẹn sì máa gba pé kó ṣe?
10 Ẹ̀jẹ́ tó ṣe pàtàkì jù tí Kristẹni kan lè jẹ́ lèyí tó jẹ́ nígbà tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, onítọ̀hún máa gbàdúrà sí Jèhófà lóun nìkan, á sì ṣèlérí fún Jèhófà pé òun á fi ayé òun sìn ín títí láé láìka ohun tó máa ná òun sí. Bí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, onítọ̀hún máa ‘sẹ́ ara rẹ̀,’ tó túmọ̀ sí pé kì í ṣe òun ló ni ara rẹ̀ mọ́ àti pé ìjọsìn Ọlọ́run ló máa ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé rẹ̀. (Mát. 16:24) Àtọjọ́ yẹn ló ti “jẹ́ ti Jèhófà.” (Róòmù 14:8) Ọwọ́ gidi ló yẹ kí ẹni tó bá ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà fi mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́, bí onísáàmù ṣe fọwọ́ gidi mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún Ọlọ́run. Onísáàmù náà sọ pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀? Àwọn ẹ̀jẹ́ mi ni èmi yóò san fún Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni, ní iwájú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.”—Sm. 116:12, 14.
11. Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tó o ṣèrìbọmi?
11 Ṣé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ṣó o sì ti ṣèrìbọmi láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ hàn? Tó o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, nǹkan ńlá lo ṣe yẹn! Rántí pé lọ́jọ́ tó o ṣèrìbọmi, ojú gbogbo èèyàn tó pé jọ ni wọ́n ti béèrè bóyá o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o sì mọ̀ pé “ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi rẹ ń fi hàn pé o jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú ètò tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí.” Bó o ṣe dáhùn ketekete níwájú gbogbo èèyàn fi hàn pé tọkàntọkàn lo ya ara rẹ sí mímọ́, ó sì dájú pé o tóótun láti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ tí Jèhófà yàn. Kò sí àní-àní pé ohun tó o ṣe yẹn múnú Jèhófà dùn gan-an!
12. (a) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa? (b) Àwọn ànímọ́ wo ni Pétérù sọ pé ó yẹ ká ní?
12 Àmọ́ o, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni ìrìbọmi jẹ́. Lẹ́yìn ìrìbọmi, ó yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa níbàámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa bá a ṣe ń fòótọ́ inú sin Ọlọ́run. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mò ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run látìgbà tí mo ti ṣèrìbọmi? Ṣé tọkàntọkàn ni mo fi ń sin Jèhófà? (Kól. 3:23) Ṣé mo máa ń gbàdúrà, ṣé mo sì ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ṣé mo máa ń lọ sípàdé déédéé, ṣé mo sì máa ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé? Àbí mo ti ń dẹwọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò yìí?’ Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé téèyàn ò bá fẹ́ di aláìṣiṣẹ́mọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ máa fi ìmọ̀, ìfaradà àti ìfọkànsìn Ọlọ́run kún ìgbàgbọ́ tó ní.—Ka 2 Pétérù 1:5-8.
13. Kí ló yẹ kí Kristẹni kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fi sọ́kàn?
13 Téèyàn bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà, kò lè wọ́gi lé ẹ̀jẹ́ náà. Tẹ́nì kan bá sọ pé ìjọsìn Ọlọ́run ti sú òun tàbí pé òun ò fẹ́ máa gbé ìgbé ayé Kristẹni mọ́, kò lè sọ pé òun ò fìgbà kankan ya ara òun sí mímọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè sọ pé ìrìbọmi òun kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́.b Ó ṣe kedere pé gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé onítọ̀hún ti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Torí náà, tó bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ó máa jíhìn fún Jèhófà àti ìjọ. (Róòmù 14:12) Ǹjẹ́ kí wọ́n má sọ nípa wa láé pé a ‘ti fi ìfẹ́ tá a ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí Jésù sọ nípa wa pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ, àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ pọ̀ ju àwọn ti ìṣáájú.” (Ìṣí. 2:4, 19) Torí náà, ẹ jẹ́ ká sapá láti máa gbé ìgbé ayé wa níbàámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa, tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá múnú Jèhófà dùn.
Ẹ̀JẸ́ ÌGBÉYÀWÓ RẸ
14. Ẹ̀jẹ́ pàtàkì míì wo lèèyàn lè jẹ́, kí sì nìdí?
14 Ẹ̀jẹ́ míì tó tún ṣe pàtàkì gan-an téèyàn lè jẹ́ ni ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ohun mímọ́ ni ìgbéyàwó jẹ́. Ìṣojú àwọn ẹlẹ́rìí ni tọkọtaya náà ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ara wọn. Wọ́n máa ń ṣèlérí pé wọ́n á nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n á máa ṣìkẹ́ ara wọn, wọ́n á sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Wọ́n máa ń sọ pé àwọn á ṣe bẹ́ẹ̀ “níwọ̀n ìgbà tí [àwọn] méjèèjì bá fi jọ wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ṣe.” Ọ̀rọ̀ táwọn míì sọ lè yàtọ̀ sí èyí, àmọ́ àwọn náà ṣì jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa ń kéde pé wọ́n ti di tọkọtaya àti pé títí lọ gbére ló fi yẹ kí wọ́n jọ wà. (Jẹ́n. 2:24; 1 Kọ́r. 7:39) Jésù sọ pé, “nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀,” kódà ọkọ tàbí aya tàbí ẹlòmíì kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, àwọn tọkọtaya tó ń ṣègbéyàwó kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé bọ́rọ̀ ò bá wọ̀, àwọn á kọ ara àwọn sílẹ̀.—Máàkù 10:9.
15. Kí nìdí tí kò fi yẹ káwa Kristẹni fi irú ọwọ́ táwọn èèyàn ayé fi ń mú ìgbéyàwó mú un?
15 Kò sí bí tọkọtaya ṣe lè mọ̀ ọ́n ṣe tó táwọn kùdìẹ̀ kudiẹ kan ò ní máa jẹ yọ nínú ìgbéyàwó wọn. Ìdí sì ni pé aláìpé làwọn méjèèjì. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé àwọn tó ṣègbéyàwó á máa “ní ìpọ́njú.” (1 Kọ́r. 7:28) Ó ṣeni láàánú pé àwọn èèyàn ayé yìí ò fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó mọ́. Kí ìṣòro má tíì yọjú nínú ìgbéyàwó wọn, wọ́n á sọ pé àwọn ò ṣe mọ́, wọ́n á sì fi ẹnì kejì wọn sílẹ̀. Àmọ́, kò yẹ kí Kristẹni ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ńṣe lẹni tó bá da ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ̀ pa irọ́ fún Ọlọ́run, a sì mọ̀ pé Ọlọ́run kórìíra àwọn òpùrọ́! (Léf. 19:12; Òwe 6:16-19) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí o bá ti gbé ìyàwó, má ṣe wá ọ̀nà láti kọ aya rẹ.” (1 Kọ́r. 7:27, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Pọ́ọ̀lù sọ bẹ́ẹ̀ torí ó mọ̀ pé Jèhófà kórìíra kéèyàn dọ́gbọ́n kọ aya tàbí ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.—Mál. 2:13-16.
16. Kí ni Bíbélì sọ nípa ìkọ̀sílẹ̀ àti ìpínyà?
16 Jésù sọ pé ohun kan ṣoṣo tó bá Ìwé Mímọ́ mu tó lè mú kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀ ni pé tí ẹnì kan lára wọn bá ṣe panṣágà tí ẹnì kejì kò sì dárí jì í. (Mát. 19:9; Héb. 13:4) Kí ló wá lè mú kí tọkọtaya pínyà? Ohun tí Bíbélì sọ ṣe kedere. (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:10, 11.) Bíbélì ò sọ àwọn nǹkan tó lè mú kí tọkọtaya pínyà. Àmọ́ o, àwọn Kristẹni kan tó ti ṣègbéyàwó máa ń yàn láti pínyà torí àwọn ìdí kan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tí ọkọ tàbí aya wọn jẹ́ aluni tàbí apẹ̀yìndà gbà pé ẹ̀mí àwọn wà nínú ewu látàrí lílù tí ẹnì kejì wọn ń lù wọ́n, tàbí pé onítọ̀hún mú kó nira gan-an fún wọn láti jọ́sìn Ọlọ́run. Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n pinnu pé àwọn á pínyà.c
17. Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè mú kí ìgbéyàwó wọn ládùn kó sì lóyin?
17 Táwọn tọkọtaya bá lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà pé kí wọ́n ran àwọn lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro táwọn ní, á dáa káwọn alàgbà náà bi wọ́n bóyá wọ́n ti wo fídíò Kí Ni Ìfẹ́ Tòótọ́? kí wọ́n sì tún béèrè bóyá wọ́n ti jọ ṣàyẹ̀wò ìwé Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn ìtẹ̀jáde yìí ní àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ láti mú kí ìgbéyàwó wọn túbọ̀ lágbára. Tọkọtaya kan sọ pé: “Àtìgbà tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí la ti túbọ̀ ń láyọ̀.” Obìnrin kan tó ti wà lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ fún ọdún méjìlélógún [22], tí ìgbéyàwó wọn sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tú ká sọ pé: “Lóòótọ́ àwa méjèèjì ti ṣèrìbọmi, síbẹ̀ a kì í gbọ́ra wa yé rárá. Àwa gan-an ni wọ́n ṣe fídíò náà fún! Látìgbà tá a ti ń fi ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò la ti ń gbádùn ara wa.” Ṣé ìwọ náà ti ṣègbéyàwó? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò nínú ìgbéyàwó rẹ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ ṣe tayọ̀tayọ̀!
Ẹ̀JẸ́ ÀWỌN TÓ Ń ṢE ÀKÀNṢE IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN
18, 19. (a) Kí ni ọ̀pọ̀ òbí Kristẹni ti ṣe? (b) Kí la lè sọ nípa àwọn tó wà nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?
18 Ǹjẹ́ o mọ ohun míì tí Jẹ́fútà àti Hánà fi jọra? Ẹ̀jẹ́ táwọn méjèèjì jẹ́ mú káwọn ọmọ wọn ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ lọ́nà àkànṣe nínú àgọ́ ìjọsìn. Ìyẹn sì mú kí wọ́n gbádùn ìgbésí ayé wọn gan-an. Lóde òní, ọ̀pọ̀ òbí Kristẹni ló ń rọ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, kí wọ́n sì rí i pé ìjọsìn Ọlọ́run lohun àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. Ó yẹ ká gbóríyìn fáwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀.—Oníd. 11:40; Sm. 110:3.
19 Lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67,000] ni Àwọn Tó Ń Ṣe Àkànṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Lára Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn kan ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn kan ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé, àwọn kan jẹ́ alábòójútó àyíká, àwọn kan jẹ́ olùkọ́ tó ń sìn ní pápá, àwọn míì sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tàbí míṣọ́nnárì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan jẹ́ ìránṣẹ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ tàbí ìránṣẹ́ tó ń sìn láwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run. Gbogbo wọn pátá ló ti tọwọ́ bọ ìwé “Vow of Obedience and Poverty,” téèyàn fi ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun á máa ṣègbọràn, òun á sì máa gbé ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ. Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tá a yàn fún wọn nínú ètò Ọlọ́run, wọ́n á máa gbé ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ, wọn ò sì ní ṣiṣẹ́ míì tó ń mówó wọlé láìgbàṣẹ. Iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe ló jẹ́ àkànṣe, kì í ṣe àwọn fúnra wọn. Wọ́n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn máa fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ mú ẹ̀jẹ́ táwọn jẹ́ ṣẹ ní gbogbo ìgbà táwọn bá wà nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.
20. Kí ló yẹ ká máa ṣe “ní ọjọ́ dé ọjọ́,” kí sì nìdí?
20 Mélòó lára àwọn ẹ̀jẹ́ yìí lo ti jẹ́ fún Jèhófà? Ṣé ẹyọ kan ni tàbí méjì àbí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta? Ó yẹ kó o mọ̀ pé ọwọ́ pàtàkì ló yẹ kó o fi mú àwọn ẹ̀jẹ́ tó o jẹ́. (Òwe 20:25) Téèyàn ò bá mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún Jèhófà ṣẹ, ohun tó máa gbẹ̀yìn rẹ̀ kò ní dáa. (Oníw. 5:6) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fayọ̀ ‘kọ orin atunilára sí orúkọ Jèhófà títí láé, bá a ṣe ń san àwọn ẹ̀jẹ́ wa ní ọjọ́ dé ọjọ́.’—Sm. 61:8.
a Ẹ̀jẹ́ tí Hánà jẹ́ fi hàn pé ọmọ náà máa jẹ́ Násírì jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé a máa ya ọmọ náà sọ́tọ̀, á sì fi gbogbo ọjọ́ ayé ẹ̀ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà.—Núm. 6:2, 5, 8.
b Torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn alàgbà gbé yẹ̀ wò kí wọ́n tó gbà pé ẹnì kan tóótun láti ṣèrìbọmi, ó ṣọ̀wọ́n gan-an ká tó rí ẹni tó máa sọ pé ìrìbọmi òun kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́.
c Wo ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run,’ Àfikún “Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀ àti Ìpínyà.”