Nípa Ìgbàgbọ́, Bárákì Ṣẹ́gun Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Alágbára Kan
FOJÚ inú wò ó pé o dojú kọ ọ̀wọ́ ọmọ ogun tó jẹ́ òkú òǹrorò kan. Wọ́n fi àwọn ohun ìjà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde dìhámọ́ra, wọ́n sì ti gbára dì láti lò wọ́n. Ìwọ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ kàn wà níwájú wọn ni láìní ohun ìjà kankan tí ẹ fẹ́ fi gbèjà ara yín.
Bárákì, Dèbórà, àti ẹgbàárùn-ún [10,000] àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ohun tá a sọ lókè yìí ṣẹlẹ̀ sí nígbà ayé àwọn onídàájọ́ Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ ogun Kénáánì tí ọ̀gágun Sísérà ń darí ló fẹ́ gbéjà kò wọ́n. Àwọn ohun ìjà bíi kẹ̀kẹ́ ẹṣin, àgbá kẹ̀kẹ́ tó ní dòjé irin aṣekúpani ní wọ́n sì fẹ́ lò. Òkè Ńlá Tábórì àti àfonífojì olójú ọ̀gbàrá Kíṣónì ni wọ́n ti ja ìjà náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ fi Bárákì hàn gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tó jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́. Jẹ́ ká gbé àwọn ohun tó fa ìjà náà yẹ̀ wò.
Ísírẹ́lì Ké Jáde sí Jèhófà
Ìwé Àwọn Onídàájọ́ sọ fún wa nípa báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kọ ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀ léraléra àtàwọn àbájáde búburú tó tibẹ̀ jáde. Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti fi òótọ́ inú bẹ̀bẹ̀ fún àánú Ọlọ́run ló máa ń yan olùgbàlà kan fún wọn tí wọ́n á sì rí ìdáǹdè, ṣùgbọ́n ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, wọ́n á tún ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀tẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, “àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà nísinsìnyí tí Éhúdù [onídàájọ́ tó gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnilára àwọn ọmọ Móábù] ti kú.” Àní, “wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yan àwọn ọlọ́run tuntun.” Kí ni ìyẹn wá yọrí sí? “Jèhófà tà wọ́n sí ọwọ́ Jábínì ọba Kénáánì, ẹni tí ó jọba ní Hásórì; olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sì ni Sísérà . . . Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Jèhófà, nítorí [Sísérà] ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun onídòjé irin, òun fúnra rẹ̀ sì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára lọ́nà lílekoko fún ogún ọdún.”—Àwọn Onídàájọ́ 4:1-3; 5:8.
Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìgbésí ayé ní Ísírẹ́lì pé: “[Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn] kò sí èrò ní ọ̀nà, àwọn arìnrìn-àjò ní àwọn òpópónà a sì rin ìrìn àjò gba àwọn ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ. Àwọn olùgbé ilẹ̀ gbalasa kásẹ̀ nílẹ̀.” (Àwọn Onídàájọ́ 5:6, 7) Jìnnìjìnnì bo àwọn èèyàn nítorí àwọn oníkẹ̀kẹ́ ẹṣin tó fẹ́ ṣe wọ́n bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú yìí. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Inú ìbẹ̀rù làwọn èèyàn ń gbé ní Ísírẹ́lì, gbogbo nǹkan ló dẹnu kọlẹ̀, kò sì tún sí olùgbèjà fún wọn.” Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ṣìbáṣìbo ti bá yáa ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn.
Jèhófà Yan Aṣáájú Kan
Ìnilára látọ̀dọ̀ àwọn Ọmọ Kénáánì yìí ló kó gbogbo Ísírẹ́lì sínú wàhálà. Ọlọ́run lo Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin láti polongo ìdájọ́ rẹ̀ àti láti fún àwọn èèyàn nítọ̀ọ́ni. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà fún un láǹfààní láti ṣe bí ìyá fún Ísírẹ́lì.—Àwọn Onídàájọ́ 4:4; 5:7.
Dèbórà ránṣẹ́ pe Bárákì, ó sì sọ fún un pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kò ha ti pàṣẹ? ‘Lọ, kí o sì tan ara rẹ ká orí Òkè Ńlá Tábórì, kí o sì mú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin láti inú àwọn ọmọ Náfútálì àti láti inú àwọn ọmọ Sébúlúnì pẹ̀lú rẹ. Dájúdájú, èmi yóò sì fa Sísérà olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jábínì àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ wá bá ọ ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì, èmi yóò sì fi í lé ọ lọ́wọ́.’” (Àwọn Onídàájọ́ 4:6, 7) Nípa sísọ pé ‘Jèhófà kò ha ti pàṣẹ?’ Ó fi hàn pé Dèbórà gbà pé òun kò ní ọlá àṣẹ kankan lórí Bárákì. Ó wulẹ̀ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí àṣẹ àtọ̀runwá gbà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ni. Kí ni ohun tí Bárákì ṣe?
Bárákì sọ pé: “Bí ìwọ yóò bá bá mi lọ, èmi yóò lọ dájúdájú; ṣùgbọ́n bí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.” (Àwọn Onídàájọ́ 4:8) Kí ló dé tí Bárákì fi lọ́tìkọ̀ láti gba iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un? Ṣé ó ṣojo ni? Ṣé kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run ni? Kì í kúkú ṣe bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe pé Bárákì kọ iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé kò ṣègbọràn sí Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣe fi hàn pé kò dá ara rẹ̀ lójú pé òun nìkan lè dá ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kí òun ṣe. Bí ẹnì kan tó jẹ́ aṣojú Ọlọ́run bá wà nítòsí, yóò mú kí òun àti àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìgbọ́kànlé àti ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò tọ́ wọn sọ́nà. Nítorí náà, dípò tá à bá fi sọ pé ojo ni Bárákì, ohun tó ṣe fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára.
A lè fi ohun tí Bárákì ṣe yìí wé ohun tí Mósè, Gídíónì, àti Jeremáyà ṣe. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí náà kò gbà pé àwọn lè dá ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún àwọn. Ṣùgbọ́n a kò torí ìyẹn kà wọ́n sí ẹni tí kò nígbàgbọ́. (Ẹ́kísódù 3:11–4:17; 33:12-17; Àwọn Onídàájọ́ 6:11-22, 36-40; Jeremáyà 1:4-10) Ó dára, kí ni ká wá sọ nípa ohun tí Dèbórà ṣe? Kò gbìyànjú láti gba iṣẹ́ Bárákì ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Ó sọ fún Bárákì pé “láìkùnà, èmi yóò bá ọ lọ.” (Àwọn Onídàájọ́ 4:9) Ó ṣe tán láti fi ilé sílẹ̀, ìyẹn ibi tó láàbò, kó sì dara pọ̀ mọ́ Bárákì fún ogun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ náà. Dèbórà náà jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà ní ti ìgbàgbọ́ àti ìgboyà.
Ìgbàgbọ́ Ló Mú Kí Wọ́n Tẹ̀ Lé Bárákì
Òkè ńlá Tábórì tí agbo ọmọ ogun Ísírẹ́lì ti pàdé kò fara sìn rárá. Ibi tí wọ́n ti pàdé yẹn dára gan-an ni. Ibẹ̀ làwọn ẹ̀yà Náfútálì àti Sébúlúnì tó ń gbé nítòsí ti máa ń pàdé. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ló yọ̀ǹda ara wọn, Dèbórà náà sì tẹ̀lé Bárákì dé orí òkè ńlá yìí.
Gbogbo àwọn tó dara pọ̀ mọ́ Bárákì ní láti ní ìgbàgbọ́. Lóòótọ́ ni Jèhófà ti ṣèlérí fún Bárákì pé yóò ṣẹ́gun àwọn ará Kénáánì, ṣùgbọ́n ohun ìjà wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní? Àwọn Onídàájọ́ 5:8 sọ pé: “A kò rí apata kan, tàbí aṣóró kan, láàárín ọ̀kẹ́ méjì ní Ísírẹ́lì.” Ohun ìjà táṣẹ́rẹ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, aṣóró àti apata tí wọ́n ní kò lè tu irun kan lára kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun tó ní dòjé irin. Bí Sísérà ṣe gbọ́ pé Bárákì ti gorí Òkè Ńlá Tábórì, kíákíá ló pe gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ jọ sí àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì. (Àwọn Onídàájọ́ 4:12, 13) Ohun tí kò yé Sísérà ni pé Ọlọ́run Olódùmarè lòun fẹ́ bá jà.
Bárákì Ṣẹ́gun Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Sísérà
Nígbà tí ìjà fẹ́ bẹ̀rẹ̀, Dèbórà sọ fún Bárákì pé: “Dìde, nítorí èyí ni ọjọ́ tí Jèhófà yóò fi Sísérà lé ọ lọ́wọ́ dájúdájú. Jèhófà ha kọ́ ni ó ti jáde lọ níwájú rẹ?” Bárákì àtàwọn èèyàn rẹ̀ gbọ́dọ̀ sọ̀ kalẹ̀ láti orí Òkè Ńlá Tábórì wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ibẹ̀ ni kẹ̀kẹ́ ẹṣin Sísérà yóò ti tètè tẹ̀ wọ́n rẹ́. Báwo ni ì bá ṣe rí lára rẹ ká sọ pé o wà lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bárákì? Ṣé wàá múra tán láti ṣègbọràn, tí wàá sì rántí pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìtọ́ni yẹn ti wá? Bárákì àtàwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ ẹgbàárùn-ún ọkùnrin ṣègbọràn. “Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà kó Sísérà àti gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti gbogbo ibùdó náà sínú ìdàrúdàpọ̀ níwájú Bárákì.”—Àwọn Onídàájọ́ 4:14, 15.
Bárákì ṣẹ́gun ẹgbẹ́ ọmọ ogun Sísérà nítorí pé Jèhófà wà lẹ́yìn rẹ̀. Àkọsílẹ̀ ogun yẹn kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀. Àmọ́, orin ìṣẹ́gun tí Bárákì àti Dèbórà kọ sọ pé ‘ọ̀run àti àwọsánmà kán omi tótó.’ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òjò ńlá kan tó rọ̀ ló mú kí kẹ̀kẹ́ ẹṣin Sísérà rì sínú ẹrẹ̀, tí ìyẹn sì jẹ́ kí agbára Bárákì ká a. Olórí ohun ìjà táwọn ọmọ Kénáánì gbẹ́kẹ̀ lé ló wá kó wọn sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Orin yẹn sọ nípa òkú àwọn ọmọ ogun Sísérà pé: “Ọ̀gbàrá Kíṣónì gbá wọn lọ.”—Àwọn Onídàájọ́ 5:4, 21.
Ṣé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣeé gbà gbọ́? Àfonífojì olójú ọ̀gbàrá Kíṣónì jẹ́ omi aṣálẹ̀, ìyẹn odò kékeré tó ní omi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ ti ń ṣàn. Lẹ́yìn ìjì tàbí òjò ńlá, irú odò kékeré bẹ́ẹ̀ máa ń ṣàdédé di ọ̀gbàrá ńlá tó ń yára ṣàn, tó sì léwu púpọ̀. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wọ́n sọ̀ pé òjò ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré tó rọ̀ sórí ilẹ̀ amọ̀ tó wà ní ibi tí à ń sọ yìí ni kò jẹ́ kí agbo ọmọ ogun kan ṣàṣeyọrí. Àkọsílẹ̀ nípa ìjà orí Òkè Ńlá Tábórì tó wáyé ní April 16, 1799 láàárín Napoleon àti Turks ròyìn pé “ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ogun Turks ló rì nígbà tí wọ́n ń gbìyànjú láti sá àsálà kí wọ́n sì sọdá apá kan pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí àkúnya omi Kíṣónì ti bò mọ́lẹ̀.”
Òpìtàn Júù ni, Flavius Josephus sọ nípa ìgbà táwọn ọmọ ogun Sísérà àti Bárákì pàdé pé, “ìjì ńlá kan tó mú òjò àti yìnyín dání ṣẹlẹ̀, atẹ́gùn yẹn ló fẹ́ òjò lu àwọn ọmọ Kénáánì lójú tí wọn kò sì ríràn mọ́ débi pé àwọn ọfà àti kànnàkànnà wọn kò wúlò fún wọn mọ́.”
Àwọn Onídàájọ́ 5:20 sọ pé “Àwọn ìràwọ̀ jà láti ọ̀run, láti àwọn ipa ọ̀nà ìyípo wọn ni wọ́n ti bá Sísérà jà.” Báwo ni àwọn ìràwọ̀ ṣe bá Sísérà jà? Àwọn kan wo ọ̀rọ̀ yìí bí ìrànlọ́wọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn mìíràn sọ pé ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn áńgẹ́lì ni, àwọn kan sọ pé ìpẹ́pẹ́ ìràwọ̀ ló já bọ́ látọ̀run nígbà táwọn kan sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ àwọn awòràwọ̀ tí Sísérà gbójú lé ló já sí pàbó. Níwọ̀n ìgbà tí Bíbélì kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí àwọn ìràwọ̀ ṣe ja ìjà yìí, a lè lóye rẹ̀ sí pé Ọlọ́run sáà jà fún àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì lọ́nà kán ṣá. Gbogbo bó ti wù kó jẹ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lo àǹfààní tí wọ́n ní lásìkò yẹn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. “Bárákì sì lépa àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun . . . tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ibùdó Sísérà ti ojú idà ṣubú. Ẹyọ kan kò ṣẹ́ kù.” (Àwọn Onídàájọ́ 4:16) Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Sísérà tó jẹ́ olórí ogun?
Aninilára Náà Ṣubú sí “Ọwọ́ Obìnrin”
Bíbélì sọ pé “Ní ti Sísérà, [ó sá kúrò lójú ogun] ó fi ẹsẹ̀ sá lọ sí àgọ́ Jáẹ́lì aya Hébà tí í ṣe Kénì, nítorí àlàáfíà wà láàárín Jábínì ọba Hásórì àti agbo ilé Hébà tí í ṣe Kénì.” Jáẹ́lì pe Sísérà tó ti rẹ̀ wá sínú àgọ́ rẹ̀, ó fún ni wàrà mu, ó sì fi aṣọ bò ó, bí ìyẹn ṣe sùn lọ nìyẹn. Lẹ́yìn to sùn tán ni Jáẹ́lì “mú ìkànlẹ̀ àgọ́, ó sì fi òòlù sí ọwọ́,” àwọn ohun yìí jẹ́ ohun tí ẹni tó ń gbé inú àgọ́ máa ń lò déédéé. “Nígbà náà ni ó yọ́ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì gbá ìkànlẹ̀ náà wọnú àwọn ẹ̀bátí rẹ̀, ó sì gbá a wọ ilẹ̀, bí ó ti sùn lọ fọnfọn tí àárẹ̀ sì ti mú un. Nítorí náà, ó kú.”—Àwọn Onídàájọ́ 4:17-21.
Jáẹ́lì jáde wá pàdé Bárákì, ó sì sọ fún un pé: “Wá, èmi yóò sì fi ọkùnrin tí ò ń wá hàn ọ.” Àkọsílẹ̀ yẹn fi kún un pé: “Nítorí náà, ó wọlé lọ bá a, sì wò ó! Sísérà rèé tí ó ṣubú síbẹ̀ ní òkú, pẹ̀lú ìkànlẹ̀ náà nínú àwọn ẹ̀bátí rẹ̀.” Ẹ wo bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn yóò ti fún ìgbàgbọ́ Bárákì lókun tó! Ṣáájú àkókò yẹn ni Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin ti sọ fún un pé: “Ohun ẹwà náà kì yóò di tìrẹ ní ọ̀nà tí ìwọ ń lọ, nítorí ọwọ́ obìnrin ni Jèhófà yóò ta Sísérà sí.”—Àwọn Onídàájọ́ 4:9, 22.
Ṣé a lè pe ohun tí Jáẹ́lì ṣe yìí ní ẹ̀tàn? Ojú tí Jèhófà fi wò ó kọ́ nìyẹn. Orin ìṣẹ́gun tí Bárákì àti Dèbórà kọ sọ pé: “Láàárín àwọn obìnrin inú àgọ́, yóò jẹ́ alábùkún jù lọ.” Orin yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé ikú tí Sísérà kú yẹn tọ́ sí i. A ṣàpèjúwe ìyà rẹ̀ pé ó ń hára gàgà pé kó tètè padà dé látojú ogun. Ó béèrè pé, “Èé ṣe tí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ fi jáfara ní dídé?” “Àwọn ọlọ́gbọ́n lára àwọn ọ̀tọ̀kùlú ìyáàfin rẹ̀” gbìyànjú láti fọkàn rẹ̀ balẹ̀, wọ́n ní ó gbọ́dọ̀ máa pín àwọn ìkógun ni, ìyẹn àwọn ẹ̀wù dáradára tí wọ́n kó iṣẹ́ sí lára àti àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n kó wá fún àwọn ọkùnrin. Àwọn obìnrin yẹn béèrè pé: “Kò ha yẹ kí wọ́n pín ohun ìfiṣèjẹ, Ilé ọlẹ̀ kan—ilé ọlẹ̀ méjì [ìyẹn ohun táwọn sójà máa ń pe àwọn wáhàrì tí wọ́n bá kó lẹ́rú, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé ] fún olúkúlùkù abarapá ọkùnrin, ohun ìfiṣèjẹ ti àwọn aṣọ tí a pa láró fún Sísérà . . . Ẹ̀wù kan tí a kó iṣẹ́ ọnà sí lára, aṣọ tí a pa láró, ẹ̀wù méjì tí a kó iṣẹ́ ọnà sí lára fún ọrùn àwọn ènìyàn afohunṣèjẹ?”—Àwọn Onídàájọ́ 5:24, 28-30.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́
Àkọsílẹ̀ nípa Bárákì kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. Ó dájú pé wàhálà àti ìjákulẹ̀ yóò bá ẹni tó bá kọ Jèhófà sílẹ̀. Gbogbo ẹni tó bá yí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tó sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ yóò dòmìnira kúrò lọ́wọ́ onírúurú ìpọ́njú. Ṣé kò wá yẹ ká jẹ́ onígbọràn nígbà náà? Kódà nígbà táwọn ohun tí Ọlọ́run béèrè bá tako ìrònú ènìyàn, ohun tó yẹ kó dá wa lójú ni pé àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run sábà máa ń wà fún ire wa tí yóò wà pẹ́ títí. (Aísáyà 48:17, 18) Kìkì nítorí pé Bárákì lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà tó sì ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni àtọ̀runwá ló jẹ́ kó ‘ṣẹ́gun ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ilẹ̀ òkèèrè.’—Hébérù 11:32-34.
Ìparí orin Dèbórà àti Bárákì tó wọni lọ́kàn yẹn sọ pé: “Báyìí ni kí gbogbo ọ̀tá rẹ ṣègbé, Jèhófà, kí àwọn olùfẹ́ rẹ sì rí bí ìgbà tí oòrùn bá jáde lọ nínú agbára ńlá rẹ̀.” (Àwọn Onídàájọ́ 5:31) Ẹ wo bí èyí yóò ṣe jẹ́ òtítọ́ tó nígbà tí Jèhófà bá mú ayé burúkú ti Sátánì yìí wá sópin!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Dèbórà ni Jèhófà lo láti rán Bárákì níṣẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Odò Kíṣónì kún bò bèbè rẹ̀
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Òkè Ńlá Tábórì