“Idà Jèhófà Àti Ti Gídíónì!”
LÁKÒÓKÒ kan táwọn onídàájọ́ ń ṣàkóso Ísírẹ́lì, ìnira pọ̀ débi pé gbogbo nǹkan tojú sú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn ọ̀tá wọn pọ̀ bí eéṣú, wọn sì ń jẹ ilẹ̀ wọn run. Gbàrà tí irúgbìn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí hù làwọn ará Mídíánì, àwọn ọmọ Ámálékì àtàwọn ará Ìlà Oòrùn máa ń rọ́ dé tàwọn ti ràkúnmí wọn. Àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn aninilára náà á wá ya bo oko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n á jẹ gbogbo ohun tí wọ́n bá rí níbẹ̀ kanlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ò ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, màlúù tàbí àgùntàn kankan. Ọdún méje gbáko làwọn ọ̀tá wọ̀nyí sì fi ni wọ́n lára. Àwọn ará Mídíánì fojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbolẹ̀ gan-an débi pé wọ́n di ẹdun arinlẹ̀. Nígbà tí wọn ò sì ríbi tọ́jú ìwọ̀nba irè oko wọn sí mọ́, wọ́n lọ ń tọ́jú wọn sábẹ́ ilẹ̀ nínú àwọn òkè ńlá, àwọn hòrò àpáta àtàwọn ibi tó ṣòroó dé.
Kí nìdí tí nǹkan fi le fún wọn tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé òrìṣà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n di apẹ̀yìndà ń bọ. Èyí ló mú kí Jèhófà kọ̀ wọ́n sílẹ̀ táwọn aninilára wá ń fìyà jẹ wọ́n. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò lè mú un mọ́ra mọ́, wọ́n ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. Ǹjẹ́ Jèhófà yóò gbọ́ tiwọn? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí?—Àwọn Onídàájọ́ 6:1-6.
Ṣé Àgbẹ̀ Tó Ń Ṣọ́ra Ṣe Ni Gídíónì àbí “Akíkanjú, Alágbára Ńlá”?
Ìta gbangba níbi tí atẹ́gùn wà làwọn àgbẹ̀ ilẹ̀ Ísírẹ́lì ti sábà máa ń fi màlúù àti ohun ìpakà lu àlìkámà kí afẹ́fẹ́ lè fẹ́ ìyàngbò rẹ̀ dà nù kó wá ku àlìkámà nìkan. Àmọ́, bí àwọn ọ̀tá tó fẹ́ jẹ wọ́n kan eegun ṣe ń ni wọ́n lára kó jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ wọn ní ìta gbangba mọ́. Èyí ló fà á tí Gídíónì fi lọ ń lu àlìkámà níbi ìfúntí wáìnì kan táwọn ará Mídíánì ò ti lè rí i. Ó ṣeé ṣe kí ibẹ̀ jẹ́ ibi fífẹ̀ kan tí wọ́n gbẹ́ lára àpáta. (Àwọn Onídàájọ́ 6:11) Ìwọ̀nba ọkà díẹ̀ ni wọ́n lè máa pa níbi yìí. Ọgbọ́n tí Gídíónì dá nìyẹn nítorí bí ipò nǹkan ṣe rí.
Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún Gídíónì nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà wá bá a tó sì sọ fún un pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ akíkanjú, alágbára ńlá.” (Àwọn Onídàájọ́ 6:12) Láìsí àní-àní, Gídíónì á ti ronú pé òun kì í ṣe akíkanjú rárá nítorí pé inú ibi ìfúntí wáìnì kan tó wà níbi kọ́lọ́fín ló ti ń lu àlìkámà. Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì yìí fi hàn pé Ọlọ́run mọ̀ dájú pé Gídíónì lè di akíkanjú aṣáájú ní Ísírẹ́lì. Síbẹ̀ náà, Gídíónì ṣì ń fẹ́ ohun tó máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí dá a lójú.
Nígbà tí Jèhófà yan Gídíónì pé kó lọ “gba Ísírẹ́lì là kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ Mídíánì,” ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní mú kó sọ pé: “Dákun, Jèhófà. Kí ni kí n fi gba Ísírẹ́lì là? Wò ó! Ẹgbẹ̀rún tèmi ni èyí tí ó kéré jù lọ ní Mánásè, èmi sì ni ó kéré jù lọ ní ilé baba mi.” Gídíónì ní kí Ọlọ́run fún òun ní ẹ̀rí tó máa jẹ́ kó dá òun lójú pé yóò ti òun lẹ́yìn láti borí àwọn ará Mídíánì. Ó wu Jèhófà láti ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu tí Gídíónì fẹ́ yìí. Nígbà tí Gídíónì gbé oúnjẹ fún áńgẹ́lì tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, iná là látinú àpáta, ó sì jó oúnjẹ náà lórí àpáta tí áńgẹ́lì náà ní kó gbé e sí. Lẹ́yìn tí Jèhófà ti fi Gídíónì lọ́kàn balẹ̀, Gídíónì mọ pẹpẹ kan sí ọ̀gangan ibẹ̀.—Àwọn Onídàájọ́ 6:12-24.
“Jẹ́ Kí Báálì Gbèjà Ara Rẹ̀ Lábẹ́ Òfin”
Ìyà táwọn ará Mídíánì fi ń jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ ni olórí ìṣòro wọn. Ìjọsìn Báálì tó ti wọ̀ wọ́n lẹ́wù ni. “Ọlọ́run owú” ni Jèhófà, kò sì sẹ́ni tó lè máa sin ọlọ́run mìíràn tó lè rí ojú rere rẹ̀. (Ẹ́kísódù 34:14) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pàṣẹ fún Gídíónì pé kó fọ́ pẹpẹ tí bàbá rẹ̀ ti ń rúbọ sí Báálì kó sì wo òpó ọlọ́wọ̀ ibẹ̀ lulẹ̀. Ẹ̀rù tó ń ba Gídíónì nípa ohun tí bàbá rẹ̀ àtàwọn ẹlòmíì máa ṣe tó bá jẹ́ pé ọ̀sán ló ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ yìí ló jẹ́ kó lọ ṣe é lóru, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mẹ́wàá ló sì ràn án lọ́wọ́.
Ká sòótọ́, ohun tí Gídíónì ṣe yìí gba ọgbọ́n àti ìṣọ́ra nítorí pé nígbà táwọn aráàlú tí wọ́n ń sin Báálì rí ohun tó ṣe, èyí tí wọ́n kà sí títàbùkù sí ohun mímọ́, ńṣe ni wọ́n fẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀. Àmọ́ nígbà tí Jóáṣì bàbá Gídíónì máa sọ̀rọ̀, ó sọ fún wọn pé ká ní Báálì jẹ́ Ọlọ́run ni ó yẹ kó lè gba ara rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tí kò ṣeé já ní koro tó sọ yìí mú kí ẹnu wọn wọhò. Ìyẹn ni Jóáṣì sì fi pe ọmọ rẹ̀ ní Jerubáálì tó túmọ̀ sí “Jẹ́ kí Báálì Gbèjà Ara Rẹ̀ Lábẹ́ Òfin.”—Àwọn Onídàájọ́ 6:25-32, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW.
Ọlọ́run máa ń bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bí wọ́n bá jẹ́ onígboyà kí wọ́n lè ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn. Nígbà táwọn ará Mídíánì àtàwọn olùgbèjà wọn tún gbógun ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ‘ẹ̀mí Jèhófà bo Gídíónì.’ (Àwọn Onídàájọ́ 6:34) Ẹ̀mí Ọlọ́run yìí sì mú kó kó àwọn ọmọ ogun jọ látinú ẹ̀yà Mánásè, Áṣérì, Sébúlúnì àti Náfútálì.—Àwọn Onídàájọ́ 6:35.
Wọ́n Múra Ogun
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Gídíónì ti kó àwọn ọmọ ogun tó tó ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n [32,000] jọ, ó ṣì ń fẹ́ kí Ọlọ́run ṣe iṣẹ́ àmì kan fún òun. Ó ní bí Ọlọ́run bá lè jẹ́ kí ìrì sẹ̀ sórí irun àgùntàn tí òun fi sí ilẹ̀ ìpakà àmọ́ tí gbogbo ilẹ̀ gbẹ, èyí á jẹ́ kóun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò lo òun láti gba Ísírẹ́lì là. Jèhófà ṣe ohun ìyanu yìí, Gídíónì sì tún sọ pé kí Jèhófà fún òun ní ẹ̀rí ìdánilójú sí i, ìyẹn ni pé kí Jèhófà mú kí ìrì sẹ̀ sórí ilẹ̀ àmọ́ kí irun àgùntàn náà gbẹ táútáú. Ṣé àṣejù ò ti wọ ọ̀rọ̀ Gídíónì báyìí? Rárá o, torí pé Jèhófà ṣe ohun tó fẹ́ yìí. (Àwọn Onídàájọ́ 6:36-40) A ò retí pé kí irú àwọn ohun ìyanu bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ lónìí. Síbẹ̀, a lè rí ìtọ́sọ́nà Jèhófà àti ẹ̀rí ìdánilójú pé ó ń tì wá lẹ́yìn nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ọlọ́run wá sọ pé àwọn tó fẹ́ lọ bá Gídíónì jagun ti pọ̀ jù. Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá borí àwọn ọ̀tá wọn bí wọ́n ṣe pọ̀ yẹn, wọ́n lè máa fọ́nnu pé ọwọ́ ara wọn làwọn fi gba ara wọn sílẹ̀. Àmọ́ Jèhófà ló yẹ kó gba ògo nígbà tí wọ́n bá ṣẹ́gun. Kí ló máa wá yanjú ọ̀rọ̀ yìí? Gídíónì ní láti tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Òfin Mósè, ìyẹn ni pé kó sọ fún àwọn tí ẹ̀rù ń bà pé kí wọ́n padà sílé. Látàrí èyí, ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] lára wọn padà, ó sì ṣẹ́ ku ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá.—Diutarónómì 20:8; Àwọn Onídàájọ́ 7:2, 3.
Síbẹ̀ náà, àwọn èèyàn náà ṣì pọ̀ jù lójú Ọlọ́run. Ọlọ́run wá sọ fún Gídíónì pé kí ó kó wọn lọ sódò kan. Òpìtàn Júù tó ń jẹ́ Josephus sọ pé ìgbà tí oòrùn mú janjan ni Ọlọ́run sọ fún Gídíónì pé kó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí odò kan. Ì báà jẹ́ ọ̀sán ni wọ́n lọ tàbí àkókò míì, Gídíónì ṣáà ń wo àwọn ọkùnrin náà bí wọ́n ṣe ń mu omi. Àwọn ọ̀ọ́dúnrún péré ló ń fọwọ́ kan bu omi mu, tí wọ́n sì tún wà lójúfò torí pé àwọn ọ̀tá lè gbéjà kò wọ́n lójijì. Ọ̀ọ́dúnrún èèyàn tó wà lójúfò yìí nìkan ló máa bá Gídíónì lọ sógun. (Àwọn Onídàájọ́ 7:4-8) Fojú inú wò ó pé o wà lára wọn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀kẹ́ méje ó dín ẹgbẹ̀rún márùn-ún [135,000] làwọn ọ̀tá tẹ́ ẹ fẹ́ lọ bá jà, ó dájú pé wàá gbà pé ẹ ò lè fi agbára yín ṣẹ́gun, àfi agbára Jèhófà nìkan ló lè mú kẹ́ ẹ borí!
Ọlọ́run wá sọ fún Gídíónì pé kó mú ìránṣẹ́ kan dání kí wọ́n jọ lọ ṣamí àgọ́ àwọn ará Mídíánì. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Gídíónì gbọ́ tí ẹnì kan ń rọ́ àlá fún ẹnì kejì rẹ̀. Ẹni tí wọ́n ń rọ́ àlá fún náà sì ṣàlàyé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé ìtumọ̀ àlá náà ni pé Ọlọ́run ti pinnu láti fi àwọn ará Mídíánì lé Gídíónì lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Gídíónì fẹ́ gbọ́ gan-an nìyẹn. Ó ti wá dá a lójú báyìí pé Jèhófà yóò jẹ́ kí òun àtàwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà borí àwọn ará Mídíánì.—Àwọn Onídàájọ́ 7:9-15.
Bí Wọ́n Ṣe Ja Ogun Náà
Gídíónì pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà sí ẹgbẹ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọgọ́rùn-ún ọmọ ogun nínú ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan. Ó fún gbogbo wọn ní ìwo àti òfìfo ìṣà títóbi kọ̀ọ̀kan. Ògùṣọ̀ kan sì wà nínú àwọn ìṣà náà. Ohun tí Gídíónì sọ pé kí wọ́n kọ́kọ́ ṣe nìyí: ‘Ẹ máa wò mí, kẹ́ ẹ sì ṣe ohun tí mo bá ṣe. Bí mo bá fun ìwo tèmi, kí ẹ̀yin náà fun tiyín, kẹ́ ẹ sì pariwo pé “Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!”’—Àwọn Onídàájọ́ 7:16-18, 20.
Àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọmọ ogun Ísírẹ́lì rọra yọ́ lọ sí etí ibùdó àwọn ọ̀tá. Nǹkan bí aago mẹ́wàá alẹ́ ni, ìyẹn ní kété lẹ́yìn táwọn ẹ̀ṣọ́ gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn. Ó jọ pé ìgbà tó dára jù nìyí káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọlé sáwọn ọ̀tá lára, nítorí pé ó máa ṣe díẹ̀ kí àwọn ẹ̀ṣọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbaṣẹ́ náà tó ríran dáadáa nínú òkùnkùn náà.
Jìnnìjìnnì tó bo àwọn ará Mídíánì ò ṣeé sọ rárá! Ariwo sọ lójijì lásìkò tí gbogbo nǹkan pa lọ́lọ́ náà, nígbà táwọn jagunjagun yìí fọ́ ọ̀ọ́dúnrún ìṣà mọ́lẹ̀, tí wọ́n fun ọ̀ọ́dúnrún ìwo, tí gbogbo àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà sì pariwo lẹ́ẹ̀kan náà. Gbogbo èyí kó ìpayà bá àwọn ará Mídíánì, pàápàá ariwo “idà Jèhófà àti ti Gídíónì!” tí wọ́n gbọ́, làwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè, ariwo wá gba gbogbo ibẹ̀ kan. Nínú gbogbo rúkèrúdò yìí, kò ṣeé ṣe láti mọ ọ̀tá yàtọ̀ sí ọ̀rẹ́. Àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà dúró sí àyè wọn bí Ọlọ́run ṣe mú kí àwọn ọ̀tá máa fi idà wọn pa ara wọn. Àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wá mú kí àwọn tó wà ní ibùdó Mídíánì sá kìjokìjo, wọn tún dínà mọ́ wọn níwájú. Wọ́n wá ń lépa àwọn ọ̀tá tó kù títí wọ́n fi rẹ́yìn wọn. Gbogbo ìyà tí wọ́n ti fi ń jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń pa wọ́n nípakúpa látọjọ́ pípẹ́ wá dópin wàyí.—Àwọn Onídàájọ́ 7:19-25; 8:10-12, 28.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì borí àwọn ọ̀tá wọn, síbẹ̀síbẹ̀ Gídíónì kò jẹ́ kí èyí kó sí òun lórí nítorí pé onírẹ̀lẹ̀ ẹ̀dá ni. Nígbà táwọn ọkùnrin ẹ̀yà Éfúráímù fẹ́ bá Gídíónì jà torí pé wọ́n gbà pé Gídíónì ò ka àwọn sí ni kò ṣe pe àwọn nígbà tó fẹ́ lọ jagun, ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ ló fi dá wọn lóhùn. Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yìí ló mú kí ìbínú àwọn ọkùnrin ẹ̀yà Éfúráímù rọlẹ̀, tí wọ́n sì fọwọ́ wọ́nú.—Àwọn Onídàájọ́ 8:1-3; Òwe 15:1.
Ní báyìí tí àlàáfíà ti jọba nílẹ̀ Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé kí Gídíónì wá jọba. Ìdẹwò ńlá mà lèyí o! Ṣùgbọ́n Gídíónì ò gbà sí wọn lẹ́nu. Ó rántí pé kì í ṣe fúnra òun ni òun ṣẹ́gun àwọn ará Mídíánì. Ó sọ fún wọn pé: “Èmi fúnra mi kì yóò ṣàkóso lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni ọmọkùnrin mi kì yóò ṣàkóso lórí yín. Jèhófà ni ẹni tí yóò ṣàkóso lórí yín.”—Àwọn Onídàájọ́ 8:23.
Àmọ́ o, nítorí pé aláìpé ni Gídíónì, kì í ṣe gbogbo ìgbà náà ló ń ṣe ohun tó mọ́gbọ́n dání. Gídíónì fi lára àwọn ẹrù tí wọ́n kó ti ogun bọ̀ ṣe éfódì, ó sì gbé e sójú táyé ní ìlú rẹ̀, ṣùgbọ́n Bíbélì ò sọ ìdí tó fi ṣe ohun tó ṣe yìí. Àlàyé tí Bíbélì ṣe ni pé gbogbo Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí ní “ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe” pẹ̀lú éfódì náà. Wọ́n ń sìn ín, èyí sì di ìdẹkùn fún Gídíónì àtàwọn aráalé rẹ̀. Síbẹ̀, ìyẹn ò sọ Gídíónì di abọ̀rìṣà torí pé Ìwé Mímọ́ sọ pé ó ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.—Àwọn Onídàájọ́ 8:27; Hébérù 11:32-34.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa
Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ni ìtàn Gídíónì jẹ́ fún wa torí pé bó ṣe jẹ́ ìkìlọ̀ náà ló tún jẹ́ ìṣírí. Ó jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa pé bí Jèhófà bá gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lára wa tí kò sì fi ojú rere hàn sí wa nítorí ìwà búburú wa, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ kò ní gún régé, ńṣe ni ipò tẹ̀mí wa yóò sì dà bíi tàwọn òtòṣì tó ń gbé ilẹ̀ táwọn eéṣú ti jẹ run. Àkókò tí nǹkan nira gan-an là ń gbé yìí, torí náà a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ìbùkún Jèhófà “ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” (Òwe 10:22) Ọlọ́run yóò bù kún wa tá a bá ń “fi ọkàn-àyà pípé pérépéré àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn sìn ín.” Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ńṣe ni yóò ta wá nù.—1 Kíróníkà 28:9.
Ìtàn Gídíónì tún lè jẹ́ ìṣírí fún wa. Ìdí ni pé ó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà lè gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ ewu tàbí ìṣòro èyíkéyìí, àní Jèhófà lè lo àwọn tó dà bíi pé wọn ò lè ṣe nǹkan kan tàbí tí wọ́n jẹ́ aláìlera pàápàá. Bí Gídíónì àtàwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin tó lọ bá a jagun ṣe borí àwọn ọmọ ogun Mídíánì tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó dín ẹgbẹ̀rún márùn-ún [135,000] jẹ́ ẹ̀rí pé agbára Ọlọ́run kọyọyọ. Nígbà míì, gbogbo nǹkan lè tojú sú wa, kó wá dà bíi pé àwọn ọ̀tá wa pọ̀ gan-an jù wá lọ. Síbẹ̀, ìtàn Gídíónì nínú Bíbélì fún wa níṣìírí pé ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹni tó máa bù kún gbogbo àwọn tó bá gbà á gbọ́ tó sì máa gbà wọ́n là.