Jẹ́fútà Mú Ẹ̀jẹ́ Tó Jẹ́ Fún Jèhófà Ṣẹ
BÍ ỌKÙNRIN ajagunṣẹ́gun kan ṣe ń bọ̀ wálé lẹ́yìn tó ṣẹ́gun àwọn tó ń pọ́n orílẹ̀-èdè wọn lójú, ọmọbìnrin rẹ̀ wá pàdé rẹ̀, ó ń jó ijó ayọ̀, ó sì ń lu ìlù tanboríìnì. Àmọ́ dípò kínú ọkùnrin yìí dùn bó ṣe rí ọmọ rẹ̀, ńṣe ló fa ẹ̀wù ọrùn ara rẹ̀ ya. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé kò dùn mọ́ ọn bínú ọmọ rẹ̀ ṣe ń dùn pé ó dé láyọ̀ àti àlàáfíà ni? Ogun wo ló jà lájàṣẹ́gun? Ta tiẹ̀ ni ọkùnrin yìí?
Jẹ́fútà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì ni. Àmọ́ ká tó dáhùn àwọn ìbéèrè yòókù ká sì rí bí ìtàn náà ṣe kàn wá lónìí, ó yẹ ká mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ kí ọmọ rẹ̀ tó wá yọ̀ pàdé rẹ̀ tóun sì wá fa aṣọ ara rẹ̀ ya.
Ìpọ́njú Bá Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì
Àsìkò tí ilẹ̀ Ísírẹ́lì wà nínú ìpọ́njú ni Jẹ́fútà gbé láyé. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jọ jẹ́ èèyàn Jèhófà pa ìjọsìn tòótọ́ tì, wọ́n wá ń bọ òrìṣà àwọn ọmọ Sídónì, Móábù, Ámónì, àti Filísíà. Jèhófà wá fi wọ́n lé àwọn ọmọ Ámónì àtàwọn Filísínì lọ́wọ́, àwọn yẹn sì fojú wọn gbolẹ̀ fún odindi ọdún méjìdínlógún. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ palaba ìyà, àgàgà àwọn tó ń gbé nílùú Gílíádì níhà ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì.a Níkẹyìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i pé àwọn ti ṣẹ̀, wọ́n ronú pìwà dà, wọ́n bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ín, wọ́n sì kó gbogbo òrìṣà ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n ń bọ dà nù.—Àwọn Onídàájọ́ 10:6-16.
Àwọn ọmọ Ámónì pàgọ́ sí ìlú Gílíádì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kóra jọ láti lọ pàdé wọn. Àmọ́, kò sí ọ̀gágun tó máa ṣáájú wọn. (Àwọn Onídàájọ́ 10:17, 18) Lásìkò yẹn sì rèé, Jẹ́fútà láwọn ìṣòro kan. Nítorí ẹ̀mí ìwọra táwọn ọbàkan rẹ̀ ní, wọ́n lé e jáde kí wọ́n lè kó ogún tó tọ́ sí i. Èyí mú kí Jẹ́fútà lọ sí àgbègbè Tóbù tó wà ní ìlà oòrùn Gílíádì, tó jẹ́ ibi tó rọrùn fáwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti wá. Àwọn kan tí Bíbélì pè ní “àwọn ọkùnrin aláìríkan-ṣèkan” wá ń kóra jọ sọ́dọ̀ Jẹ́fútà. Ó ṣeé ṣe káwọn ọkùnrin yìí jẹ́ àwọn tó pàdánù iṣẹ́ wọn nítorí àwọn tó ń pọ́n wọn lójú tàbí kó jẹ́ àwọn tó yarí pé àwọn ò lè sìnrú mọ́. Bíbélì sọ pé ‘wọ́n a bá a jáde lọ,’ tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí pé wọ́n ń tẹ̀ lé Jẹ́fútà bó ṣe ń gbógun ja àwọn ọ̀tá tó wà lágbègbè wọn. Bíbélì pe Jẹ́fútà ni “alágbára ńlá, akíkanjú ọkùnrin,” bóyá nítorí jíjẹ́ tó jẹ́ akọni lójú ogun. (Àwọn Onídàájọ́ 11:1-3) Ta ló máa wá ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú ìjà àwọn àtàwọn ọmọ Ámónì yìí?
“Wá Jẹ Ọ̀gágun Wa”
Àwọn àgbà ọkùnrin ìlú Gílíádì lọ bá Jẹ́fútà, wọ́n ní: “Wá jẹ ọ̀gágun wa.” Tí wọ́n bá rò pé ńṣe ni Jẹ́fútà máa bẹ́ mọ́ ohun tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ yìí kó lè padà sílùú ẹ̀, wọ́n ń tanra wọn jẹ ni o. Jẹ́fútà fèsì pé: “Ẹ̀yin ha kọ́ ni ẹ kórìíra mi tí ẹ fi lé mi jáde ní ilé baba mi? Èé sì ti ṣe tí ẹ fi wá sọ́dọ̀ mi nísinsìnyí, kìkì nígbà tí ẹ wà nínú wàhálà?” Àbẹ́ ẹ̀ rí nǹkan! Wọ́n lé Jẹ́fútà kúrò nílùú, wọ́n tún wá lọ bá a pé kó wá ran àwọn lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé wọn ò nítìjú!—Àwọn Onídàájọ́ 11:4-7.
Jẹ́fútà sọ fún wọn pé tí wọ́n bá fẹ́ kóun ṣáájú wọn nínú ìjà náà, wọ́n gbọ́dọ̀ gbà láti ṣe ohun tóun fẹ́. Ó ní: ‘Tí Jèhófà bá jọ̀wọ́ àwọn ọmọ Ámónì fún mi, èmi, ní tèmi, yóò di olórí yín!’ Ṣíṣẹ́gun tí Jẹ́fútà bá ṣẹ́gun máa fi hàn pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn rẹ̀, àmọ́ Jẹ́fútà tún fẹ́ rí i dájú pé àwọn èèyàn náà ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ lẹ́yìn tí wàhálà náà bá dópin.—Àwọn Onídàájọ́ 11:8-11.
Ó Fẹ́ Yanjú Ọ̀rọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ọmọ Ámónì
Jẹ́fútà gbìyànjú láti bá àwọn ọmọ Ámọ́nì sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí. Ó rán àwọn kan sí ọba àwọn ọmọ Ámónì láti mọ ohun tó ń bí wọn nínú. Ọba náà ní kí wọ́n sọ fún Jẹ́fútà pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣàìdáa sáwọn. Ó sọ pé nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, wọ́n gba ilẹ̀ àwọn, òun sì fẹ́ kí wọ́n dà á padà.—Àwọn Onídàájọ́ 11:12, 13.
Jẹ́fútà sì kúkú mọ ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dáadáa, ló bá fi yé àwọn ọmọ Ámónì pé ọ̀rọ̀ ò rí bí wọ́n ṣe sọ ọ́. Ó sọ fún wọn pé nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, wọ́n ò ṣèpalára kankan fáwọn ọmọ Ámónì, Móábù, àti Édómù. Ó ní lákòókò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, àwọn ọmọ Ámónì kọ́ ló ni ilẹ̀ tí wọ́n wá ń jà nítorí ẹ̀ yìí. Àwọn ọmọ Ámórì ló ni ilẹ̀ náà lákòókò yẹn, àmọ́ Ọlọ́run fi ọba wọn, ìyẹn Síhónì, lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi wà lórí ilẹ̀ náà. Kí ló wá dé tó jẹ́ pé ìsinsìnyí làwọn ọmọ Ámónì wá ń sọ pé àwọn làwọn ni ilẹ̀?—Àwọn Onídàájọ́ 11:14-22, 26.
Jẹ́fútà tún sọ̀rọ̀ lórí kókó kan, tó jẹ́ ìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàápàá fi kó sínú ìṣòro tí wọ́n wà. Kókó náà ni, Ta ni Ọlọ́run tòótọ́? Ṣé àwọn òrìṣà tí wọ́n ń bọ láwọn ilẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà ni, àbí Jèhófà? Tó bá jẹ́ pé òrìṣà Kémóṣì táwọn ọmọ Ámónì ń bọ lágbára ni, ṣé kò ní lo agbára rẹ̀ láti má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gba ilẹ̀ àwọn èèyàn rẹ̀? Ọ̀rọ̀ ló délẹ̀ láàárín ìsìn èké táwọn ọmọ Ámónì ń gbé lárugẹ àti ìsìn tòótọ́ yìí o. Ṣé ìsìn èké ló máa borí ni, àbí ìsìn tòótọ́? Ìyẹn ni Jẹ́fútà fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó bá a mu, ó ní: “Kí Jèhófà Onídàájọ́ ṣe ìdájọ́ lónìí láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Ámónì.”—Àwọn Onídàájọ́ 11:23-27.
Ọba àwọn ọmọ Ámónì ò gba òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Jẹ́fútà sọ. “Ẹ̀mí Jèhófà bà lé Jẹ́fútà wàyí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí la Gílíádì àti Mánásè kọjá,” bóyá tó ń kó àwọn akọni ọkùnrin jọ láti lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jà.—Àwọn Onídàájọ́ 11:28, 29.
Jẹ́fútà Jẹ́ Ẹ̀jẹ́
Jẹ́fútà fi tọkàntara wa ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ìdí rèé tó fi bá Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé: “Bí o bá fi àwọn ọmọ Ámónì lé mi lọ́wọ́ láìkùnà, yóò sì ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú pé ẹni tí ó bá ń jáde bọ̀, tí ó jáde wá láti àwọn ilẹ̀kùn ilé mi láti pàdé mi nígbà tí mo bá padà dé ní àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, òun pẹ̀lú yóò di ti Jèhófà, èmi yóò sì fi ẹni náà rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun.” Ọlọ́run ti Jẹ́fútà lẹ́yìn, ó jẹ́ kó pa àwọn ọmọ Ámónì ní “ìpakúpa púpọ̀ gan-an” tó fi ṣẹ́gun ogún lára àwọn ìlú wọn. Ó sì tipa báyìí borí àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì.—Àwọn Onídàájọ́ 11:30-33.
Nígbà tí Jẹ́fútà ń padà bọ̀ wálé láti ojú ogun, ọmọ kan ṣoṣo tó bí ló wá pàdé rẹ̀! Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ó tajú kán rí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí fa ara rẹ̀ lẹ́wù ya, ó sì wí pé: ‘Págà, ọmọbìnrin mi! O ti mú mi tẹ̀ ba ní tòótọ́, ìwọ fúnra rẹ sì ti di ẹni tí mo ń ta nù lẹ́gbẹ́. Èmi-èmi sì ti la ẹnu mi sí Jèhófà, èmi kò sì lè yí padà.’”—Àwọn Onídàájọ́ 11:34, 35.
Ṣé Jẹ́fútà máa wá fi ọmọ rẹ̀ rúbọ ni? Rárá o. Ìyẹn kọ́ ni ohun tó ní lọ́kàn. Jèhófà kórìíra fífi èèyàn rúbọ, èyí tó jẹ́ ọkàn lára ìwà ìkà táwọn ará Kénáánì ń hù. (Léfítíkù 18:21; Diutarónómì 12:31) Yàtọ̀ sí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń lo Jẹ́fútà lákòókò tó bá Jèhófà jẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí, Jèhófà tún bù kún àwọn nǹkan tó ń ṣe. Bíbélì yin Jẹ́fútà fún ìgbàgbọ́ tó ní àti ipa tó kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. (1 Sámúẹ́lì 12:11; Hébérù 11:32-34) Nítorí náà, Jẹ́fútà ò ní in lọ́kàn rárá láti pààyàn rúbọ. Nígbà náà, kí ni Jẹ́fútà ní lọ́kàn nígbà tó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa fi èèyàn rúbọ sí Jèhófà?
Ẹ̀rí fi hàn pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé òun máa fi ẹni tó bá wá pàdé òun fún Ọlọ́run pé kó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣiṣẹ́ Ọlọ́run. Òfin Mósè sáà sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fèèyàn fún Jèhófà pé kó máa ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn obìnrin máa ń sìn ní àgọ́ ìjọsìn, bóyá kí wọ́n máa pọn omi. (Ẹ́kísódù 38:8; 1 Sámúẹ́lì 2:22) A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ wọ̀nyẹn, kódà a ò mọ̀ bóyá ńṣe ni wọ́n ń ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ títí lọ. Àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé irú àkànṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Jẹ́fútà ní lọ́kàn nígbà tó jẹ́jẹ̀ẹ́ yẹn, ó sì dà bíi pé ìlérí tó ṣe fi hàn pé ńṣe ló fẹ́ kẹ́ni tóun bá fún Jèhófà máa ṣe iṣẹ́ ọ̀hún títí lọ.
Ọmọbìnrin Jẹ́fútà bá bàbá rẹ̀ tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí bàbá rẹ̀ lè mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ ṣẹ. Bákan náà ni ọ̀dọ́mọdé náà Sámúẹ́lì ṣe ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ó bá àwọn òbí tiẹ̀ náà fọwọ́ sowọ́ pọ̀. (1 Sámúẹ́lì 1:11) Nítorí pé ọmọbìnrin Jẹ́fútà jẹ́ ẹnì kan tó ń fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà, ó tẹ́ ẹ lọ́rùn gẹ́gẹ́ bó ṣe tẹ́ bàbá rẹ̀ lọ́rùn, pé kí bàbá òun fi òun fún Jèhófà. Nǹkan ńlá ni ọmọbìnrin yìí yááfì o, nítorí pé ìyẹn máa túmọ̀ sí pé kò ní lọ́kọ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Ó sunkún nítorí ipò wúńdíá tí yóò máa wà títí lọ, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nílẹ̀ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn gbogbo wọn láti ní ọmọ tiwọn kí orúkọ àti ogún ìdílé wọn má bàa pa rẹ́. Ní ti Jẹ́fútà sì rèé, mímú tó bá mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ yóò túmọ̀ sí pé kò ní máa rí ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n kan ṣoṣo yìí déédéé.—Àwọn Onídàájọ́ 11:36-39.
Kì í ṣe pé wúńdíá olóòótọ́ yìí fayé ara rẹ̀ ṣòfò o. Ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún nínú ilé Jèhófà jẹ́ ọ̀nà kan tí kò láfiwé tó sì gbayì tó lè gbà bọlá fún Ọlọ́run, tó sì jẹ́ pé ó tún máa fún un láyọ̀. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé “láti ọdún dé ọdún, àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì a lọ láti gbóríyìn fún ọmọbìnrin Jẹ́fútà tí í ṣe ọmọ Gílíádì.” (Àwọn Onídàájọ́ 11:40) Ó sì dájú pé ó ń láyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ló ń fi ìgbésí ayé wọn ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà, míṣọ́nnárì, alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Nítorí iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe yìí, ó lè má ṣeé ṣe fún wọn láti máa rí àwọn èèyàn wọn bí wọ́n ṣe fẹ́. Síbẹ̀, ohun ayọ̀ ló jẹ́ fún àwọn àtàwọn èèyàn wọn pé wọ́n ń ṣe irú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ bẹ́ẹ̀ sí Jèhófà.—Sáàmù 110:3; Hébérù 13:15, 16.
Wọn Ò Tẹ̀ Lé Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run
Ìtàn ìgbà ayé Jẹ́fútà fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó hàn gbangba pé Jèhófà ń ti Jẹ́fútà lẹ́yìn, àwọn ọmọ Éfúráímù ṣì bínú sí i. Wọ́n ní ó yẹ kó ránṣẹ́ pe àwọn káwọn bá a lọ jagun náà. Àní wọ́n tiẹ̀ gbèrò àtisun ilé ‘mọ́ ọn lórí!’—Àwọn Onídàájọ́ 12:1.
Jẹ́fútà sọ pé òun pè wọ́n, pé wọn ò wá ni. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run jẹ́ kí Jẹ́fútà jàjàṣẹ́gun. Èwo wá ni tinú tó ń bí wọn nísinsìnyí nítorí pé àwọn ọmọ Gílíádì ò ránṣẹ́ sí wọ́n nígbà tí wọ́n fẹ́ yan Jẹ́fútà gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun wọn? Dájúdájú, ńṣe ni inú tó ń bí àwọn ọmọ Éfúráímù sí Jẹ́fútà fi hàn pé wọ́n ti kẹ̀yìn sí Jèhófà, torí náà ó di dandan kí Jẹ́fútà bá wọn jà. Nígbà tí ìjà náà sì délẹ̀, Jẹ́fútà àtàwọn èèyàn rẹ̀ ṣá àwọn ọmọ Éfúráímù balẹ̀. Tí Jẹ́fútà àtàwọn èèyàn rẹ̀ bá rí ẹnì kan tó fẹ́ sá lọ, wọ́n á ní kó pe “Ṣíbólẹ́tì,” tí kò bá sì mọ̀ ọ́n pé, wọ́n á ti mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin Éfúráímù ni, wọ́n á sì pa á. Gbogbo àwọn ọmọ Éfúráímù tí wọ́n pa jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún [42,000].—Àwọn Onídàájọ́ 12:2-6.
Àkókò ìbànújẹ́ làkókò náà jẹ́ nínú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ogun táwọn Onídàájọ́ bíi Ótíníẹ́lì, Éhúdù, Bárákì, àti Gídíónì ti jàjàṣẹ́gun mú àlàáfíà wá. Àmọ́ Bíbélì ò sọ pé ìṣẹ́gun Jẹ́fútà yìí yọrí sí àlàáfíà. Nígbà tí Bíbélì fẹ́ parí ìtàn yìí, ńṣe ló kàn sọ pé: “Jẹ́fútà sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́fà, lẹ́yìn èyí [ó] kú, a sì sin ín sí ìlú ńlá rẹ̀ ní Gílíádì.”—Àwọn Onídàájọ́ 3:11, 30; 5:31; 8:28; 12:7.
Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn yìí kọ́ wa? Ẹ̀kọ́ tó kọ́ wa ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbésí ayé Jẹ́fútà kún fún hílàhílo, ó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Akíkanjú ọkùnrin yìí mẹ́nu kan Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ tó sọ fáwọn àgbà ọkùnrin Gílíádì, àtèyí tó sọ fáwọn ọmọ Ámónì, àtèyí tó sọ fún ọmọbìnrin rẹ̀, àtèyí tó sọ fáwọn ọmọ Éfúráímù, ó sì tún mẹ́nu kan Jèhófà nínú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́. (Àwọn Onídàájọ́ 11:9, 23, 27, 30, 31, 35; 12:3) Ọlọ́run bù kún Jẹ́fútà nítorí ìfọkànsìn rẹ̀, ó sì lo òun àti ọmọbìnrin rẹ̀ láti gbé ìjọsìn tòótọ́ ga. Lákòókò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fọwọ́ rọ́ ìlànà Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ńṣe ni Jẹ́fútà rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run ní tiẹ̀. Ṣé ìwọ náà á máa ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà gbogbo bíi ti Jẹ́fútà?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ọmọ Ámónì máa ń ṣèkà gan-an ni. Léyìí tí kò tó ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn ìgbà tá à ń sọ yìí, wọ́n láwọn máa yọ ojú ọ̀tún gbogbo ará ìlú Gílíádì tí wọ́n ń pọ́n lójú. Wòlíì Ámósì sọ pé ìgbà kan wà táwọn ọmọ Ámónì lanú àwọn aboyún ìlú Gílíádì.—1 Sámúẹ́lì 11:2; Ámósì 1:13.