Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Ọ̀rẹ́ Jèhófà
“Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.”—SÁÀMÙ 25:14.
1-3. (a) Kí ló mú kó dá wa lójú pé a lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? (b) Àwọn wo la máa sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ÌGBÀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Bíbélì pe Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (2 Kíróníkà 20:7; Aísáyà 41:8; Jákọ́bù 2:23) Ábúráhámù nìkan ni Bíbélì dìídì pè ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sí èèyàn míì tó di ọ̀rẹ́ Jèhófà yàtọ̀ sí Ábúráhámù? Rárá o. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo wa la lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà.
2 Ìtàn àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tí wọ́n bẹ̀rù Jèhófà, tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kún inú Bíbélì. (Ka Sáàmù 25:14.) Wọ́n jẹ́ ara “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ wọn. Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ni gbogbo wọn.—Hébérù 12:1.
3 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa mẹ́ta lára àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn: (1) Rúùtù, obìnrin opó kan láti ilẹ̀ Móábù, (2) Hesekáyà, olóòótọ́ ọba Júdà, àti (3) Màríà, obìnrin onírẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ ìyá Jésù. Kí la lè rí kọ́ nínú bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
KÒ FI JÈHÓFÀ SÍLẸ̀
4, 5. Ìpinnu tó lágbára wo ni Rúùtù ní láti ṣe, kí ló sì mú kí ìpinnu náà ṣòro ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
4 Náómì àtàwọn ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀, Rúùtù àti Ópà, ń rìnrìn-àjò gígùn láti ilẹ̀ Móábù lọ sí Ísírẹ́lì. Bí wọ́n ti ń lọ, Ópà lóun á pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn òun nílẹ̀ Móábù. Àmọ́ Náómì ti pinnu pé ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ilẹ̀ ìbílẹ̀ òun lòun á pa dà sí. Kí ni Rúùtù á wá ṣe ní tiẹ̀? Àfi kó yáa ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa kó tó lè ṣèpinnu. Ṣé kó pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ẹ̀ nílẹ̀ Móábù ni àbí kó máa bá Náómì ìyá ọkọ rẹ̀ lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù?—Rúùtù 1:1-8, 14.
5 Ilẹ̀ Móábù làwọn èèyàn Rúùtù ń gbé. Ó lè pa dà sọ́dọ̀ wọn, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀ kí wọ́n sì máa tọ́jú rẹ̀. Kì í kúkú ṣàjèjì wọn, ó gbọ́ èdè wọn dáadáa, ó sì mọ àṣà ilẹ̀ Móábù dunjú. Náómì ò lè fi gbogbo ẹnu sọ bóyá Rúùtù á ní àwọn àǹfààní yìí ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Náómì ò sì lè fọwọ́ sọ̀yà pé òun á rí ọkọ fún Rúùtù tàbí ilé tó máa gbé. Torí náà, Náómì sọ fún un pé kó pa dà sí ilẹ̀ Móábù. Ópà náà ṣáà “ti padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run rẹ̀.” (Rúùtù 1:9-15) Àmọ́ Rúùtù pinnu pé òun ò ní pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn òun àtàwọn ọlọ́run èké tí wọ́n ń sìn.
6. (a) Ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání wo ni Rúùtù ṣe? (b) Kí nìdí tí Bóásì fi sọ pé Rúùtù ń wá ibi ìsádi lábẹ́ ìyẹ́ apá Jèhófà?
6 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọkọ Rúùtù ló kọ́ Rúùtù nípa Jèhófà, ó sì lè jẹ́ Náómì, ìyá ọkọ rẹ̀. Rúùtù mọ̀ pé Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwọn òrìṣà ilẹ̀ Móábù. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì mọ̀ pó yẹ kóun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kóun sì máa jọ́sìn rẹ̀. Torí náà, Rúùtù ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Ó sọ fún Náómì pe: “Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.” (Rúùtù 1:16) Ó máa ń wú wa lórí tá a bá ń ronú nípa ìfẹ́ tó lágbára tí Rúùtù ní sí Náómì. Àmọ́ èyí tó wúni lórí jù lọ ni ìfẹ́ tí Rúùtù ní sí Jèhófà. Ó wú Bóásì náà lórí débi tó fi wá yin Rúùtù fún bó ṣe ‘wá ibi ìsádi lábẹ́ ìyẹ́ apá Jèhófà.’ (Ka Rúùtù 2:12.) Ọ̀rọ̀ tí Bóásì lò yìí mú wa rántí bí òròmọdìyẹ ṣe máa ń sá sábẹ́ ìyẹ́ apá ìyá rẹ̀, kó lè dáàbò bò ó. (Sáàmù 36:7; 91:1-4) Lọ́nà kan náà, Jèhófà dáàbò bo Rúùtù, ó sì san án lẹ́san torí ìgbàgbọ́ tó ní. Rúùtù ò kábàámọ̀ ìpinnu tó ṣe yìí láé.
7. Kí ló lè ran àwọn tí wọn ò tíì fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà lọ́wọ́?
7 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, àmọ́ tí wọn ò sá di í. Wọn ò tíì fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Tó bá jẹ́ bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, á dáa kó o ronú lórí ìdí tó ò fi tíì ṣèrìbọmi. Kò sẹ́ni tí kò ní ọlọ́run tó ń sìn. (Jóṣúà 24:15) Àmọ́, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn sin Ọlọ́run tòótọ́. Tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe lò ń fi hàn pé o nígbàgbọ́ pé Jèhófà á jẹ́ ibi ìsádi fún ẹ. Á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa sìn ín nìṣó láìka ìṣòro èyíkéyìí tó o lè ní sí. Ohun tí Ọlọ́run ṣe fún Rúùtù nìyẹn.
“Ó SÌ Ń BÁ A NÌṢÓ NÍ FÍFÀ MỌ́ JÈHÓFÀ”
8. Irú ilé wo ni Hesekáyà ti wá?
8 Ibi tí Hesekáyà gbé dàgbà yàtọ̀ sí ti Rúùtù. Orílẹ̀-èdè tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni Hesekáyà gbé dàgbà. Àmọ́, àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di aláìṣòótọ́ nígbà tó yá. Ọba burúkú ni Áhásì Ọba tó jẹ́ bàbá Hesekáyà. Ó ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé kò bọ̀wọ̀ fún tẹ́ńpìlì Ọlọ́run, ó sì mú kí àwọn èèyàn náà máa sin àwọn ọlọ́run mìíràn. Kódà, Áhásì dáná sun àwọn kan lára àwọn arákùnrin Hesekáyà lóòyẹ̀, ó sì fi wọ́n rúbọ sí ọlọ́run èké. Ojú Hesekáyà rí tó nígbà tó wà lọ́mọdé!—2 Àwọn Ọba 16:2-4, 10-17; 2 Kíróníkà 28:1-3.
9, 10. (a) Kí ni ì bá ti mú kí Hesekáyà bínú sí Jèhófà? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa bínú sí Ọlọ́run? (d) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká lérò pé irú ilé tá a ti jáde ló máa pinnu irú èèyàn tá a máa jẹ́?
9 Àpẹẹrẹ búburú Áhásì Ọba lè mú kí Hesekáyà ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bínú sí Jèhófà. Lónìí, ohun táwọn kan fara dà ò tiẹ̀ tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Hesekáyà, síbẹ̀ wọ́n rò pé àwọn ní ìdí tó fi yẹ káwọn “kún fún ìhónú sí Jèhófà” tàbí káwọn bínú sí ètò rẹ̀. (Òwe 19:3) Àwọn míì rò pé ilé búburú táwọn ti jáde lè mú káwọn máa gbé ìgbé ayé búburú tàbí kó mú káwọn náà tún ṣe irú àṣìṣe táwọn òbí àwọn ṣe. (Ìsíkíẹ́lì 18:2, 3) Àmọ́, ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lóòótọ́?
10 Irú ìgbé ayé tí Hesekáyà gbé fi hàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀! Kò sídìí tó fi yẹ kí ẹnikẹ́ni bínú sí Jèhófà. Jèhófà kọ́ ló ń fa ohun búburú tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn. (Jóòbù 34:10) Òótọ́ ni pé àpẹẹrẹ táwọn òbí fi lélẹ̀ lè ní ipa rere tàbí ipa búburú lórí àwọn ọmọ wọn. (Òwe 22:6; Kólósè 3:21) Àmọ́ ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé irú ilé tá a ti jáde ló máa pinnu irú èèyàn tá a máa jẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ti fún wa lẹ́bùn kan, ìyẹn òmìnira láti yan ohun tó wù wá, tó túmọ̀ sí pé a lè yàn láti máa ṣe ohun tó dáa tàbí ohun tó burú. (Diutarónómì 30:19) Báwo ni Hesekáyà ṣe lo ẹ̀bùn tó ṣeyebíye yìí?
11. Kí ló mú kí Hesekáyà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba tó dáa jù ní Júdà?
11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn ọba tó burú jù lọ ní Júdà ni bàbá Hesekáyà, Hesekáyà di ọ̀kan lára àwọn ọba tó dáa jù lọ ní ilẹ̀ náà. (Ka 2 Àwọn Ọba 18:5, 6.) Ó yàn láti má ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú bàbá rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí àwọn wòlíì Jèhófà bí Aísáyà, Míkà àti Hóséà. Ó gba ìbáwí àti ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un. Èyí mú kó tún ọ̀pọ̀ nǹkan tí bàbá ẹ̀ ti bà jẹ́ ṣe. Ó fọ tẹ́ńpìlì mọ́, ó bẹ Ọlọ́run pé kó dárí ji àwọn èèyàn náà, ó sì fọ́ àwọn òrìṣà tó wà ní gbogbo ilẹ̀ náà túútúú. (2 Kíróníkà 29:1-11, 18-24; 31:1) Nígbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà halẹ̀ mọ́ Hesekáyà pé òun á gbógun ja Jerúsálẹ́mù, Hesekáyà ṣe ohun tó fi hàn pé ó ní ìgboyà àti ìgbàgbọ́ tó lágbára. Ó nígbàgbọ́ pé Jèhófà á dáàbò bo àwọn, Hesekáyà sì fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun. (2 Kíróníkà 32:7, 8) Nígbà kan, Hesekáyà bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, àmọ́ nígbà tí Jèhófà bá a wí, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀. (2 Kíróníkà 32:24-26) Ó ṣe kedere pé àwòfiṣàpẹẹrẹ ni Hesekáyà jẹ́. Kò jẹ́ kí ilé búburú tó ti jáde sọ ọ́ di dà bí mo ṣe dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé ọ̀rẹ́ Jèhófà lòun.
12. Bíi ti Hesekáyà, báwo lọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń fi hàn lónìí pé ọ̀rẹ́ Jèhófà làwọn?
12 Torí pé ayé táwọn èèyàn ti rorò tí wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn là ń gbé, ọ̀pọ̀ ọmọ ló jẹ́ pé àwọn òbí tó rorò ló tọ́ wọn dàgbà. (2 Tímótì 3:1-5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ilé tí wọn kì í ti í ṣe Kristẹni lọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti wá, wọ́n ti pinnu láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Bíi ti Hesekáyà, wọ́n fi hàn pé ilé táwọn ti jáde kọ́ ló máa pinnu irú èèyàn táwọn máa dà lọ́la. Ọlọ́run ti fún wa lómìnira láti yan ohun tó wù wá, torí náà, a lè pinnu láti sìn ín ká sì máa bọlá fún un bí Hesekáyà ti ṣe.
“WÒ Ó! ẸRÚBÌNRIN JÈHÓFÀ!”
13, 14. Kí nìdí tó fi dà bíi pé iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé Màríà lọ́wọ́ ti nira jù, síbẹ̀ kí ló sọ fún Gébúrẹ́lì?
13 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Hesekáyà gbáyé, obìnrin onírẹ̀lẹ̀ kan tó ń jẹ́ Màríà ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà, Jèhófà sì gbé iṣẹ́ àkànṣe kan lé e lọ́wọ́. Áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ fún un pé ó máa lóyún, á bí Ọmọ Ọlọ́run, á sì tọ́jú rẹ̀ dàgbà! Ó ní láti jẹ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Màríà ó sì fọkàn tán an tó fi lè gbé irú iṣẹ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀ lé e lọ́wọ́. Àmọ́ báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́ nípa iṣẹ́ náà?
14 A sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní ńlá tí Màríà ní. Àmọ́ àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe kó máa ronú nípa rẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún un pé ó máa lóyún láìní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kankan. Àmọ́ Gébúrẹ́lì ò sọ fún Màríà pé òun á bá a ṣàlàyé fáwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn aládùúgbò rẹ̀. Ojú wo wá làwọn yẹn á máa fi wo Màríà? Báwo ló ṣe máa ṣàlàyé fún Jósẹ́fù pé òun ò ṣèṣekúṣe? Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ ńlá ló já lé e léjìká, òun ló máa tọ́ Ọmọ Ọlọ́run dàgbà! A ò mọ gbogbo ohun tó ń jẹ Màríà lọ́kàn, àmọ́ a mọ ohun tó ṣe lẹ́yìn tí Gébúrẹ́lì bá a sọ̀rọ̀ tán. Màríà ní: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.”—Lúùkù 1:26-38.
15. Kí ló mú kí ìgbàgbọ́ Màríà ṣàrà ọ̀tọ̀?
15 Ìgbàgbọ́ Màríà ṣàrà ọ̀tọ̀ lóòótọ́! Ó ṣe tán láti ṣe ohunkóhun tí Jèhófà bá ní kó ṣe, bí ẹrúbìnrin ṣe máa ń ṣe fún ọ̀gá rẹ̀. Ó nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa tọ́jú òun á sì dáàbò bo òun. Kí ló mú kí ìgbàgbọ́ Màríà lágbára tó bẹ́ẹ̀? Kò sẹ́ni tí wọ́n bí ìgbàgbọ́ mọ́. Àmọ́ a lè ní ìgbàgbọ́ tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ní in ká sì máa bẹ Ọlọ́run pé kó bù kún ìsapá wa. (Gálátíà 5:22; Éfésù 2:8) Màríà sapá gan-an kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lè máa lágbára sí i. Báwo la ṣe mọ̀? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ń fetí sílẹ̀ àtàwọn ohun tó sọ.
16. Báwo la ṣe mọ̀ pé Màríà máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa?
16 Màríà máa ń fetí sílẹ̀. Bíbélì sọ pé ká ‘yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, ká sì lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.’ (Jákọ́bù 1:19) Màríà máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń fọkàn sí àwọn ohun tó gbọ́, pàápàá àwọn ohun tó kọ́ nípa Jèhófà. Ó máa ń ronú lórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì yìí. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tó bí Jésù, táwọn olùṣọ́ àgùntàn sì sọ ohun tí áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ nípa ọmọ náà fún un. Òmíràn ni ìgbà tí Jésù pé ọmọ ọdún méjìlá, ó sọ ohun kan tó ya Màríà lẹ́nu gan-an. Ní ìgbà méjèèjì yìí, Màríà fetí sílẹ̀ dáadáa, kò gbàgbé àwọn ohun tó gbọ́, ó sì fara balẹ̀ ronú lé wọn lórí.—Ka Lúùkù 2:16-19, 49, 51.
17. Kí la lè rí kọ́ nínú àwọn ohun tí Màríà sọ?
17 Àwọn ohun tí Màríà sọ. Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ sọ fún wa nípa àwọn ohun tí Màríà sọ. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó gùn jù lọ wà nínú Lúùkù 1:46-55. Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ níbí yìí fi hàn pé ó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa. Lọ́nà wo? Àwọn ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ níbẹ̀ jọ àwọn ọ̀rọ̀ inú àdúrà tí Hánà, ìyá Sámúẹ́lì gbà. (1 Sámúẹ́lì 2:1-10) Ó jọ pé nǹkan bí ìgbà ogún ni Màríà fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́. Ó ṣe kedere pé Màríà fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó kọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, Ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.
18. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Màríà?
18 Bíi ti Màríà, Jèhófà lè gbé àwọn iṣẹ́ kan lé wa lọ́wọ́, àmọ́ nígbà míì a lè máa rò pé iṣẹ́ náà ti le jù. Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Màríà, ká fìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà, ká sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀nà míì tá a lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Màríà ni pé ká máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí Jèhófà, ká sì máa ronú lórí àwọn ohun tá a ti kọ́ nípa rẹ̀ àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. Ìgbà yẹn la tó lè fayọ̀ sọ àwọn ohun tá a ti kọ́ fáwọn èèyàn.—Sáàmù 77:11, 12; Lúùkù 8:18; Róòmù 10:15.
19. Kí ló dá wa lójú bá a ṣe ń tẹ̀ lé àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ títayọ tó wa nínú Bíbélì?
19 Ó ṣe kedere pé ọ̀rẹ́ Jèhófà ni Ábúráhámù, ọ̀rẹ́ Jèhófà sì ni Rúùtù, Hesekáyà àti Màríà náà. Wọ́n wà lára “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀,” táwọn náà láǹfààní láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé irú àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ títayọ bẹ́ẹ̀. (Hébérù 6:11, 12) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà títí láé!