Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”
RÚÙTÙ kúnlẹ̀ níbi tí àwọn ìtí ọkà bálì tó ti ń ṣà jọ látàárọ̀ wà, láti bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn ọkà náà. Ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ní gbogbo àgbègbè ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ọ̀pọ̀ àwọn tó lọ ṣiṣẹ́ ní oko sì ti wà lọ́nà ilé nígbà yẹn, wọ́n rọra ń gòkè lọ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ lójú ọ̀nà tó wọ ẹnubodè ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìyẹn ìlú kékeré tó wà lórí òkè nítòsí ibẹ̀. Ó dájú pé yóò ti rẹ Rúùtù gan-an torí iṣẹ́ tó ti ń ṣe bọ̀ látàárọ̀ láìfi bẹ́ẹ̀ sinmi. Síbẹ̀, ó tẹra mọ́ ọkà rẹ̀ tó ń pa, ó ń fi ọ̀pá lu àwọn ìtí ọkà náà kí ọkà inú rẹ̀ lè gbọ̀n jáde. Nǹkan ṣáà ti ṣẹnuure fún un, kódà ó tiẹ̀ tún kọjá bó ṣe lè retí pé ó máa dáa tó lọ́jọ́ náà.
Àbí nǹkan ti bẹ̀rẹ̀ sí í lójú bọ̀ díẹ̀díẹ̀ fún ọmọbìnrin opó yìí ni? Ọmọbìnrin náà kúkú ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ohunkóhun kò ní ya òun àti ìyá ọkọ òun Náómì torí èkùrọ̀ ni alábàákú ẹ̀wà, ó sì sọ pé Jèhófà, Ọlọ́run tí Náómì ń sìn náà ni yóò jẹ́ Ọlọ́run òun. Àwọn opó méjèèjì tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ yìí sì jọ wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti ilẹ̀ Móábù. Kò pẹ́ tí Rúùtù ará Móábù náà fi mọ̀ pé nínú Òfin Jèhófà, ètò kan tó dára gan-an, tó buyì kúnni, wà fún àwọn tálákà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, títí kan àwọn àjèjì.a Ó sì ti wá fojú ara rẹ̀ rí i wàyí, pé àwọn kan nínú àwọn èèyàn Jèhófà, tí Òfin náà wà fún, ti fi hàn nípa ìwà wọn àti inúure wọn pé àwọn ń tẹ̀ lé òfin Jèhófà, èyí sì mú kí ọgbẹ́ ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í san.
Ọ̀kan lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni Bóásì, àgbà ọkùnrin tó jẹ́ ọlọ́rọ̀, tí Rúùtù wá pèéṣẹ́ ọkà ní oko rẹ̀. Bóásì sì ṣe bíi baba fún un lónìí. Ṣe ni inú Rúùtù ń dùn tó sì ń rẹ́rìn-ín sínú bó ṣe ń rántí gbogbo bó ṣe ń yìn ín fún títọ́jú Náómì àgbàlagbà àti bó ṣe wá fi abẹ́ ìyẹ́ apá Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, ṣe ibi ìsádi.—Rúùtù 2:11-13.
Síbẹ̀ náà, ó ṣeé ṣe kí Rúùtù máa ronú nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀. Kó máa rò ó pé, òun ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó jẹ́ aláìní, tí kò ní ọkọ tàbí ọmọ, báwo ni òun á ṣe lè máa gbọ́ bùkátà òun àti Náómì tó bá di ọjọ́ iwájú? Ṣé pípèéṣẹ́ nìkan máa tó láti gbọ́ bùkátà àwọn? Ta ló máa wá tọ́jú òun fúnra òun tí òun náà bá dàgbà? Kò lè yani lẹ́nu tí irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ bá ń wá sí i lọ́kàn. Lóde òní tí ètò ọrọ̀ ajé ò fi bẹ́ẹ̀ fara rọ, ọ̀pọ̀ èèyàn ni irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ ń gbé lọ́kàn sókè. Bí a bá mọ bí ìgbàgbọ́ Rúùtù ṣe ràn án lọ́wọ́ lójú irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ gidi ló máa jẹ́ fún wa.
Àwọn Wo La Lè Kà sí Ìdílé?
Nígbà tí Rúùtù pa ọkà náà tán, tó kó o jọ, ó rí i pé ọkà tí òun pèéṣẹ́ jẹ́ nǹkan bí òṣùwọ̀n eéfà kan ọkà bálì, ìyẹn nǹkan bí ìdajì àpò ìrẹsì. Ẹ ò rí i pé ẹrù gidi ni! Bóyá aṣọ ló tiẹ̀ fi dì í tó wá gbé e rù, tó sì gba ọ̀nà ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lọ bí oòrùn ṣe ń wọ̀.—Rúùtù 2:17.
Inú Náómì dùn láti rí aya ọmọ rẹ̀ àtàtà yìí, bóyá ẹnu tiẹ̀ yà á gan-an bó ṣe rí ẹrù ọkà bálì tí Rúùtù rù wá. Rúùtù tún mú wálé lára èyí tó ṣẹ́ kù nínú oúnjẹ tí Bóásì pèsè fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, àwọn méjèèjì sì jọ pín in jẹ. Náómì wá béèrè pé: “Ibo ni o ti pèéṣẹ́ lónìí, ibo sì ni o ti ṣiṣẹ́? Kí ẹni tí ó kíyè sí ọ di alábùkún.” (Rúùtù 2:19) Náómì tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, torí ó mọ̀ pé kò lè rí ẹrù ọkà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan ti rí i pé opó ni tó sì dìídì ṣàánú rẹ̀.
Bí àwọn méjèèjì ṣe ń bọ́rọ̀ lọ, Rúùtù sọ gbogbo bí Bóásì ṣe ṣe inúure sí òun fún un. Inú Náómì dùn gan-an, ó ní: “Ìbùkún ni fún un láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹni tí kò dẹ́kun inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ sí àwọn alààyè àti àwọn òkú.” (Rúùtù 2:19, 20) Ó rí i pé Jèhófà ló mú kí Bóásì ṣe inúure yẹn, torí òun ló ń mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ọ̀làwọ́, tó sì tún ṣe ìlérí pé òun máa san ẹ̀san fún àwọn èèyàn òun tó bá ń ṣe oore.b—Òwe 19:17.
Náómì wá gba Rúùtù níyànjú pé kó ṣe bí Bóásì ṣe sọ, ìyẹn ni pé kó máa lọ pèéṣẹ́ nínú oko rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin agboolé rẹ̀ kí àwọn olùkórè má bàa fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ọ́. Rúùtù tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà. Bákan náà, ó “ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀.” (Rúùtù 2:22, 23) Gbólóhùn yẹn tún jẹ́ ká rí èyí tó ta yọ lára ìwà Rúùtù, ìyẹn sì ni pé ó jẹ́ ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Àpẹẹrẹ rẹ̀ lè mú kí àwa náà bi ara wa bóyá à ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀mí ìṣọ̀kan nínú ìdílé, bóyá a ń fi tinútinú ṣètìlẹyìn fún àwọn èèyàn wa, tí a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ bó ṣe yẹ. Tí a bá ń lo irú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa san wá ní ẹ̀san.
Ǹjẹ́ a tiẹ̀ lè sọ pé Náómì àti Rúùtù nìkan jẹ́ ìdílé kan? Àwọn ẹ̀yà kan gbà pé tí àwùjọ èèyàn kan kò bá ní ẹni tó jẹ́ ọkọ, aya, ọmọkùnrin, ọmọbìnrin àwọn òbí àgbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ láàárín wọn, wọn kì í lè dá dúró bí ìdílé gidi kan. Àmọ́ ìtàn Náómì àti Rúùtù jẹ́ ká rí i pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lè fi gbogbo ọkàn wa sapá láti jẹ́ kí ìdùnnú, inúure àti ẹ̀mí ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín ìdílé, bó ti wù kí àwọn tó ṣẹ́ kù síbẹ̀ kéré tó. Torí náà ǹjẹ́ o mọyì ìdílé tìrẹ? Jésù rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ létí pé ìjọ Kristẹni lè jẹ́ ìdílé fún àwọn tí kò ní ìdílé pàápàá.—Máàkù 10:29, 30.
“Ó Jẹ́ Ọ̀kan Nínú Àwọn Olùtúnnirà Wa”
Láti ìgbà ìkórè ọkà bálì ní nǹkan bí oṣù April títí wọ ìgbà ìkórè àlìkámà ní nǹkan bí oṣù June, inú oko Bóásì ni Rúùtù ti ń pèéṣẹ́. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó dájú pé Náómì ń ro ohun tí òun tún lè ṣe fún aya ọmọ òun àtàtà yìí. Nígbà tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Móábù, ohun tí Náómì rò ni pé kò sí bí òun ṣe lè rí ọkọ míì fún Rúùtù. (Rúùtù 1:11-13) Ṣùgbọ́n èrò Náómì ti wá bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Ó bá Rúùtù sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọmọbìnrin mi, kò ha yẹ kí èmi wá ibi ìsinmi fún ọ?” (Rúùtù 3:1) Ó jẹ́ àṣà láyé àtijọ́ pé kí àwọn òbí bá ọmọ wọn wá ẹni tó máa fẹ́, Rúùtù sì ti di ọmọ àtàtà fún Náómì. Ó wá fẹ́ bá a “wá ibi ìsinmi,” èyí tó túmọ̀ sí ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀ tí obìnrin sábà máa ń rí nínú ilé ọkọ tirẹ̀. Kí wá ni Náómì lè ṣe?
Nígbà àkọ́kọ́ tí Rúùtù sọ̀rọ̀ nípa Bóásì ni Náómì ti sọ pé: “Ọkùnrin náà bá wa tan. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùtúnnirà wa.” (Rúùtù 2:20) Kí ni ohun tó sọ yẹn túmọ̀ sí? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, àwọn ìṣètò kan wà nínú Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nítorí ti àwọn ìdílé tí ìnira bá dé bá torí pé wọ́n jẹ́ aláìní tàbí torí pé èèyàn wọn kú. Tí obìnrin kan bá di opó láìtíì bímọ, ìbànújẹ́ rẹ̀ máa ń lé kenkà torí pé orúkọ ọkọ rẹ̀ àti gbogbo àtọmọdọ́mọ tó yẹ kó ní máa pa rẹ́, ìran rẹ̀ sì run títí ayé nìyẹn. Àmọ́ Òfin Ọlọ́run yọ̀ọ̀da pé kí arákùnrin ẹni tó kú náà ṣú ìyàwó rẹ̀ lópó, kí obìnrin náà lè bí ọmọ tó máa di ajogún tí yóò máa jẹ́ orúkọ mọ́ ọkọ rẹ̀ tó kú, kó sì máa bójú tó dúkìá ìdílé ọkùnrin náà.c—Diutarónómì 25:5-7.
Náómì bá gbẹ́nu lé ohun tó fẹ́ ṣe kí Rúùtù lè ní ọkọ. A lè fojú inú wo bí ẹnu ṣe máa ya ọmọbìnrin náà bó ṣe ń gbọ́ àlàyé ìyá ọkọ rẹ̀. Bóyá díẹ̀ ló ṣì mọ̀ nínú Òfin Mósè tí Ísírẹ́lì ń tẹ̀ lé, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìlànà rẹ̀ sì máa ṣàjèjì sí i. Ṣùgbọ́n, torí pé ó bọ̀wọ̀ fún Náómì gan-an, ó fetí sí gbogbo ohun tó sọ dáadáa. Ohun tí Náómì ní kí Rúùtù ṣe lè dà bí ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ bára dé, tó ń tini lójú tàbí tó tiẹ̀ lè wọ́ni nílẹ̀, síbẹ̀ ó gbà láti ṣe é. Ó fi inú tútù sọ pé: “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”—Rúùtù 3:5.
Nígbà míì, kì í rọrùn fún àwọn tí kò tíì dàgbà láti gba ìmọ̀ràn àwọn tó dàgbà jù wọ́n tó sì ní ìrírí jù wọ́n lọ. Wọ́n ti máa ń gbà pé àwọn àgbàlagbà ò kúkú mọ àwọn ìnira àti ìṣòro tí àwọn ọ̀dọ́ máa ń ní. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí àpẹẹrẹ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Rúùtù jẹ́ ká máa rántí pé èrè pọ̀ nínú fífetí sí ọgbọ́n àwọn àgbà tó fẹ́ràn wa, tí wọ́n sì ń fẹ́ kí ayé wa dára. Kí wá ni ìmọ̀ràn tí Náómì fún Rúùtù, ṣé ó sì ṣe é láǹfààní nígbà tó tẹ̀ lé e?
Rúùtù Wá sí Ilẹ̀ Ìpakà
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà Rúùtù lọ sí ilẹ̀ ìpakà, ìyẹn ibi títẹ́jú pẹrẹsẹ kan tí wọ́n ki ilẹ̀ rẹ̀ le dáadáa, tí àwọn àgbẹ̀ mélòó kan máa ń kó ọkà tí wọ́n kórè wá láti pa ọkà náà kí wọ́n sì fẹ́ ìyàngbò rẹ̀ kúrò. Ẹ̀gbẹ́ òkè tàbí orí òkè tí atẹ́gùn ibẹ̀ máa ń pọ̀ gan-an lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ ni wọ́n sábà máa ń ṣe ilẹ̀ ìpakà sí. Tí àwọn òṣìṣẹ́ bá máa fẹ́ ìyàngbò kúrò lára ọkà tí wọ́n ti pa, wọ́n máa ń fi àmúga tàbí ṣọ́bìrì ńlá bu ọkà náà sókè sínú afẹ́fẹ́ kí atẹ́gùn lè fẹ́ ìyàngbò fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà náà dà nù, hóró ọkà tó wúwo ju ìyàngbò lọ á wá máa já bọ́ pa dà sórí ilẹ̀ ìpakà.
Rúùtù rọra fara pa mọ́, ó ń wo gbogbo bí wọ́n ṣe ń parí iṣẹ́ wọn lọ́wọ́ alẹ́ náà. Bóásì ló fúnra rẹ̀ bójú tó bí wọ́n ṣe ń fẹ́ ọkà rẹ̀, àti bí wọ́n ṣe rù ú jọ gègèrè. Lẹ́yìn tó sì ti jẹun àjẹgbádùn, ó dùbúlẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ọkà tí wọ́n rù jọ náà. Ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láyé ìgbà yẹn, bóyá láti lè dáàbò bo irè oko wọn tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ kára lé lórí, kúrò lọ́wọ́ àwọn olè àti àwọn onísùnmọ̀mí. Wàyí o, Rúùtù rí ibi tí Bóásì sùn sí. Àkókò tó wàyí kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí Náómì ní kó ṣe.
Bí Rúùtù ṣe rọra ń yọ́ lọ síbẹ̀, àyà rẹ̀ ń já. Àmọ́ ó rí i pé ọkùnrin náà ti sùn wọra. Ló bá ṣe bí Náómì ṣe sọ, ó lọ síbi ẹsẹ̀ ọkùnrin náà, ó ká aṣọ kúrò níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì dùbúlẹ̀ sí ẹgbẹ́ ibẹ̀. Ó wá ń retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Ó wà níbẹ̀ títí, àmọ́ nǹkan kan ò ṣẹlẹ̀. Bí ẹgbẹ̀rún ọdún ni àkókó tó fi wà níbẹ̀ yìí máa rí lójú rẹ̀. Níkẹyìn, ní ààjìn òru, Bóásì yíra pa dà. Òtútù ti wọ̀ ọ́ lára, ara rẹ̀ sì ń gbọ̀n, ó wá tẹ̀ sí iwájú, bóyá láti fa aṣọ bo ẹsẹ̀ rẹ̀ pa dà. Ló bá hàn sí i pé ẹnì kan wà níbẹ̀. Ìtàn náà sọ pé: “Wò ó! obìnrin kan dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀!”—Rúùtù 3:8.
Ni Bóásì bá béèrè pé: “Ta ni ọ́?” Rúùtù sì fèsì, bóyá ohùn rẹ̀ tiẹ̀ ń gbọ̀n, ó ní: “Èmi ni Rúùtù ẹrúbìnrin rẹ, kí o sì na apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ bo ẹrúbìnrin rẹ, nítorí ìwọ jẹ́ olùtúnnirà.” (Rúùtù 3:9) Àwọn alálàyé kan lóde òní fẹ́ gbìyànjú láti túmọ̀ ohun tí Rúùtù ṣe àti ọ̀rọ̀ tó sọ sí pé ṣe ló ń dọ́gbọ́n fi ìbálòpọ̀ lọ Bóásì, àmọ́ ṣe ni wọ́n gbójú fo kókó méjì kan. Kókó àkọ́kọ́ ni pé, àṣà kan tí wọ́n ń tẹ̀ lé ní àtijọ́ àmọ́ tí kò sí mọ́ lóde òní, ni Rúùtù tẹ̀ lé. Torí náà, àṣìṣe ló máa jẹ́ láti máa fi èrò bí ìṣekúṣe ṣe gbilẹ̀ lóde òní ṣàlàyé ohun tó ṣe láyé ìgbà yẹn. Kókó kejì ni pé ohun tí Bóásì ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé ó ka ohun tí Rúùtù ṣe sí nǹkan tó bójú mu tó yẹ kó yìn ín lé lórí.
Nígbà tí Bóásì máa sọ̀rọ̀, ó dájú pé ohùn pẹ̀lẹ́ tó fi sọ̀rọ̀ tu Rúùtù nínú gan-an. Bóásì ní: “Alábùkún ni ìwọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ọmọbìnrin mi. Ìwọ ti fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ hàn lọ́nà tí ó dára ní ìgbà ìkẹyìn ju ti ìgbà àkọ́kọ́ lọ, ní ti pé ìwọ kò tẹ̀ lé àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn yálà ẹni rírẹlẹ̀ tàbí ọlọ́rọ̀.” (Rúùtù 3:10) Ohun tó pè ní “ìgbà àkọ́kọ́” ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Rúùtù ní tó fi bá Náómì pa dà wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó sì ń tọ́jú rẹ̀. Èyí tó pè ní “ìgbà ìkẹyìn” ni ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yìí. Bóásì wò ó pé tó bá jẹ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin míì ni, ọ̀dọ́kùnrin ni wọ́n á máa wá láti fi ṣe ọkọ, yálà ó jẹ́ olówó tàbí tálákà. Ṣùgbọ́n ní ti Rúùtù, ṣe ló fẹ́ ṣe inúure sí Náómì àti ọkọ Náómì tó kú pàápàá ní ti pé kò fẹ́ kí orúkọ ọkùnrin náà run ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìwà ọmọbìnrin tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan yìí máa wú Bóásì lórí gan-an lóòótọ́.
Bóásì wá ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Wàyí o, ọmọbìnrin mi, má fòyà. Gbogbo ohun tí o sọ ni èmi yóò ṣe fún ọ, nítorí gbogbo ẹni tí ó wà ní ẹnubodè àwọn ènìyàn mi mọ̀ pé ìwọ jẹ́ obìnrin títayọ lọ́lá.” (Rúùtù 3:11) Inú rẹ̀ dùn nípa ọ̀rọ̀ fífi Rúùtù ṣe aya; bóyá kò sì yà á lẹ́nu bó ṣe sọ pé kí òun wá ṣe olùtúnnirà rẹ̀. Ṣùgbọ́n olódodo èèyàn ni Bóásì, nítorí náà kò kàn fúnra rẹ̀ yan ohun tó wù ú láti ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà. Ṣe ló sọ fún Rúùtù pé ẹlòmíì ṣì wà tó jẹ́ olùtúnnirà tó tan mọ́ ìdílé Náómì tímọ́tímọ́ ju òun lọ, pé òun máa kọ́kọ́ sọ fún onítọ̀hún, kí ó lè yàn bóyá òun máa fi Rúùtù ṣe aya.
Bóásì wá sọ fún Rúùtù pé kí ó sùn síbẹ̀, kó sinmi di àfẹ̀mọ́jú, kó wá pa dà lọ sílé kí ilẹ̀ tó mọ́. Kò fẹ́ kí àwọn èèyàn fi ojú burúkú wo obìnrin náà àti òun alára, torí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé ó ní láti jẹ́ pé wọ́n ti hu ìwà àìmọ́ kan. Ni Rúùtù bá sùn síbi ẹsẹ̀ ọkùnrin náà pa dà, àmọ́ ọkàn rẹ̀ máa balẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ torí bí Bóásì ṣe bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tura. Ní ìdájí tí ilẹ̀ ò tíì mọ́, Bóásì wọn ọkà bálì tó pọ̀ fún un, Rúùtù sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù pa dà.
Ẹ ò rí i pé ó máa dùn mọ́ Rúùtù gan-an tó bá tún ronú kan ohun tí Bóásì sọ nípa rẹ̀, pé “obìnrin títayọ lọ́lá” ni gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí! Ó sì dájú pé ara ohun tó jẹ́ kó lè ní irú orúkọ rere bẹ́ẹ̀ ni pé ó tara ṣàṣà láti mọ Jèhófà kó sì máa sìn ín. Ó tún lo inúure àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò ńlá sí Náómì àti àwọn èèyàn rẹ̀ bí ó ṣe fínnúfíndọ̀ kọ́ àwọn àṣà àti ìṣe tó dájú pé ó ṣàjèjì sí i tẹ́lẹ̀, tó sì wá ń ṣe wọ́n. Tí a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Rúùtù àti ìgbàgbọ́ rẹ̀, a ó máa fi ọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n, a ó sì máa fọwọ́ pàtàkì mú àwọn àṣà àti ìṣe wọn. Àwa náà á sì wá dẹni tí àwọn èèyàn mọ̀ sí èèyàn dáadáa.
Ibi Ìsinmi fún Rúùtù
Nígbà tí Rúùtù dé ilé ní ìdájí ọjọ́ yẹn, Náómì sọ pé: “Ta ni ọ́, ọmọbìnrin mi?” Ó lè jẹ́ ilẹ̀ tí kò tíì mọ́ ló jẹ́ kí Náómì béèrè bẹ́ẹ̀ o, àmọ́ ó tún fẹ́ mọ̀ bóyá Rúùtù ṣì wà nípò opó tí kò tíì ní ẹnì kankan lọ́kàn tó lè fẹ́, àbí ó ti dẹni tó nírètí pé òun náà máa tó ní ọkọ. Rúùtù wá gbẹ́nu lé gbogbo bí nǹkan ṣe lọ láàárín òun àti Bóásì. Ó tún gbé ọkà bálì ńlá tí Bóásì wọ̀n fún un pé kó gbé fún Náómì kalẹ̀.d—Rúùtù 3:16, 17.
Náómì wá fún Rúùtù ní ìmọ̀ràn tó bọ́gbọ́n mu, ó ní kó jókòó jẹ́ẹ́ sílé lọ́jọ́ náà, kó má lọ pèéṣẹ́ ní oko. Ó fi yé e pé: “Ọkùnrin náà kì yóò sinmi, láìjẹ́ pé ó mú ọ̀ràn náà wá sí òpin lónìí.”—Rúùtù 3:18.
Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Náómì sọ nípa Bóásì. Torí ṣe ni Bóásì lọ sí ẹnubodè ìlú, níbi tí àwọn àgbààgbà ti máa ń pàdé, ó dúró síbẹ̀ títí ìbátan rẹ̀ ọkùnrin, tó tan mọ́ ìdílé Náómì tímọ́tímọ́ jù ú lọ, fi ń kọjá. Bóásì wá pe ọkùnrin náà àti àwọn ẹlẹ́rìí míì, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá yóò fẹ́ láti ṣe olùtúnnirà tó máa fi Rúùtù ṣe aya. Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà kọ̀, ó ní ìyẹn lè run ogún tòun. Bóásì wá sọ níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí wọ́n jọ wà ní ẹnubodè náà pé òun máa tún un rà àti pé òun máa ra gbogbo ohun tó jẹ́ ti Élímélékì ọkọ Náómì tó kú, òun yóò sì fẹ́ Rúùtù opó, aya Málónì ọmọ Élímélékì. Ó sì wá sọ ìdí tó fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní òun máa tipa bẹ́ẹ̀ “gbé orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà dìde lórí ogún rẹ̀.” (Rúùtù 4:1-10) Olódodo èèyàn tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan ni Bóásì jẹ́ lóòótọ́.
Bí Bóásì ṣe fẹ́ Rúùtù nìyẹn. Lẹ́yìn náà, Bíbélì sọ pé: “Jèhófà yọ̀ǹda kí ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan.” Àwọn obìnrin ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù wá súre fún Náómì, wọ́n sì yin Rúùtù pé ó wúlò fún Náómì ju ọmọkùnrin méje lọ pàápàá. Bíbélì sọ pé nígbà tó yá, ọmọkùnrin tí Rúùtù bí di baba ńlá Dáfídì Ọba. (Rúùtù 4:11-22) Dáfídì alára wá di ọ̀kan lára àwọn baba ńlá Jésù Kristi.—Mátíù 1:1.e
Ọlọ́run bù kún Rúùtù gan-an ni, àti Náómì tó bá a tọ́jú ọmọ náà bí ọmọ tòun fúnra rẹ̀. Ìtàn obìnrin méjèèjì yìí á jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń kíyè sí gbogbo àwọn tó ń fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣiṣẹ́ kára láti lè gbọ́ bùkátà àwọn èèyàn wọn, tí wọ́n sì ń fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Bákan náà, Jèhófà kì í ṣàì san ẹ̀san fún àwọn olóòótọ́ èèyàn tó bá ní ìwà títayọ lọ́lá bíi ti Rúùtù.
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn—‘Ibi Tí O Bá Lọ Ni Èmi Yóò Lọ,’” nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2012.
b Bí Náómì ṣe sọ, kì í ṣe ọ̀dọ̀ àwọn alààyè nìkan ni inúure Jèhófà mọ sí, ó nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ti kú pàápàá. Ìdí ni pé, ọkọ Náómì àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì ti kú. Ọkọ Rúùtù náà ti kú. Obìnrin méjèèjì yìí sì fẹ́ràn àwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn gidigidi. Tí ẹnikẹ́ni bá wá ṣe inúure sí Náómì àti Rúùtù, bí ìgbà tí wọ́n ṣe é fún àwọn ọkùnrin yẹn náà ni, torí ká ní wọ́n wà láàyè ni, wọn kò ní fẹ́ kí ìyà kankan jẹ àwọn obìnrin àtàtà náà rárá.
c Ẹ̀rí fi hàn pé ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni tó kú náà ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ fún ní ẹ̀tọ́ láti fi opó náà ṣe aya, ìyẹn láti ṣú u lópó. Tí wọn ò bá wá fẹ́ ẹ, á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá kan mọ̀lẹ́bí rẹ̀ míì tó jẹ́ ọkùnrin. Bí wọ́n sì ṣe máa ṣe ogún rẹ̀ náà nìyẹn.—Númérì 27:5-11.
d Òṣùwọ̀n mẹ́fà ọkà bálì ni Bóásì bù fún Rúùtù, àmọ́ Bíbélì kò sọ bó ṣe wúwo tó. Bóyá ṣe ló fi ìyẹn ṣe àpẹẹrẹ pé bí iṣẹ́ ọjọ́ mẹ́fà ṣe máa ń parí sí ọjọ́ Sábáàtì tí wọ́n máa ń sinmi, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wàhálà Rúùtù gẹ́gẹ́ bí opó látẹ̀yìn wá ṣe máa tó parí, tí yóò sì lọ ‘sinmi’ tòun ti ìfọ̀kànbalẹ̀ ní ilé ọkọ kan. Àmọ́ ṣá, ó tún lè jẹ́ pé ìwọ̀nba ẹrù tí Rúùtù lè gbé ni òṣùwọ̀n mẹ́fà yẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹ̀kún ṣọ́bìrì mẹ́fà.
e Rúùtù jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn obìnrin mẹ́rin tí Bíbélì dárúkọ pé ó jẹ́ ìyá ńlá Jésù. Ráhábù ìyá Bóásì náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin yẹn. (Mátíù 1:3, 5, 6) Òun náà kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì bíi ti Rúùtù.